Nínú ìran ìṣáájú, a bá bàbá ọgọ́rin ọdún kan pàdé tí
orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bàbá Ìkébò tí ó ń sọ àwọn oríṣiríṣi ẹnà àti òwe tí ó sì
ń ̣sàròyé sí àwọn èrò tí ó wà lọ́dọ̀ọ rẹ̀ nípa rúdu-rùdu tí ilé ayé dà àti
pẹ̀lú bí a ṣe ní àwọn adarí lawùjọ ṣùgbọ́n tí àwọn adarí náà wà bí aláìsí.
Bí ó ṣe ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni àwọn èrò náà ń fi ojú inú wo ọ̀rọ̀ náà kí
wọ́n tó fi aṣọ bo ojú ìtàgé.
A rí olè kan tí àwọn ènìyàn pé jọ láti fi ìyà jẹ àti
pàápàá jù lọ pé kí ọba ṣe
ìdájọ́ fún un ní ààfin rẹ̀. Àwọn ará ìlú Òjòlò ni àwọn wọ̀nyí, ààfin ọba
Ọlọ́jọ̀lọ̀ sì ni wọ́n tí fẹ́ ṣe èyí; gbogbo ibi ni wọ́n ti ń pariwo àti fìyà jẹ ọmọdékùnrin yìí nítorí
wí pé ó jí ewúrẹ́ gbe. Nígbà tí ọba fẹ́ dájọ́ fún un ni ọmọkùnrin kan tí a mọ̀ sí
Olúgbòdì wá láti bá a bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú làákàyè rẹ̀ wí pé kí ọba fi ojú àánú wo
ọmọkùnrin náà, nítorí wí pé àìríṣẹ́ ṣe ni ó fà á tí àwọn ọ̀dọ́ àti ọmọdé
ìlú fí ń hùwàkiwà, wọ́n ní ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni èṣù ń yá lọ. Bí ọba tí gbà sí i lẹ́nu nìyẹn.
A rí Olúgbòdì àti Ìgbẹ́kọ̀yí nínú oko wọn, níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ń kẹ́dùn lórí
àìnílọsíwájú tí ó dé bá ìlú Ọ̀jọ̀lọ̀ tí ó mú kí ìṣẹ́ àti ìyà máa bá tọmọdé-tàgbà
fínra, pẹ̀lú wí pé bí ó ṣe dàbí pé àwọn ìjòyè rẹ̀ o ṣe nǹkan kan sí ọ̀rọ̀
náà.
A rí Dékọ̀yà àti ọmọ rẹ̀, Ọmọ́pé, níbi tí wọ́n
tí ń jiyàn lórí wí pé Dékọ̀yà fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ fẹ́ àwọn olówó àti ọlọ́rọ̀ tí
wọ́n kí í ṣe ọmọ
ìlú Ọ̀jọ̀lọ̀. Ọmọ́pẹ́ kọ̀ jálẹ̀ wí pé ọmọ ìlú Ọ̀jọ̀lọ̀ ni òun yóò fẹ́ àti wí
pé Olúgbòdì ni ọkọ òun tí í sì fa ìjà gidigidi láàrin baba àti ọmọ tí ó mú kí
Ọmọ́pẹ́ fi ìbínú kúrò
lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀.
Ọmọ́pẹ́ lọ bá Olúgbòdì, ó sì sọ fún un wí pé bàbá òun
kò fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àwọn ṣùgbọ́n ìyá òun fara mọ́ ọn. Ibẹ̀ ni
Olúgbòdì tí sọ fún un wí pé bàbá òun ṣe àárẹ̀, ìdí nìyẹn tí òun fi lo ṣe
iṣẹ́ alágbàro kí òun baà lè gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn nígboro.
A tún rí ibi tí ọba ti ń bá àwọn ìjòyè rẹ̀ ṣe ìpàdé
lórí àìnílọsíwájú tí ó wà nínú ìlú. Wọ́n fẹnu kò wí pé ọmọkùnrin abuké àti
ọmọbìnrin tí kò
í tíì bàlágà ni
Ifá béèrè pé àwọn yóò lò.
Bẹ́ẹ̀ ni Olúgbòdì ṣe já wọlé tí ó sì sọ fún wọn wí pé àìsìfẹ̀ẹ́ láàrin
àwọn olórí ni ó fa rògbòdìyàn inú ìlú wọn, tí kábíèsí sì gbà sí i lẹ́nu.
Olúgbòdì lọ sí Èkó lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó mú un wọ
ẹgbẹ́ àgbà tí Olúgbòdì náà sì di olówó àti ọlọ́lá. Ó sì hùwà ọmọlúàbí, gbogbo ará ìlú ni ó padà
lọ se fún, tí ó sì mú kí ìlọsíwájú bá ìlú Ọ̀jọ̀lọ̀ láàrin ọdún díẹ̀.
Ọmọ́pẹ́ lọ fi ẹjọ́ sun ìyá rẹ̀ wí pé Olúgbòdì kò ì tíì ṣí òun
láṣọ wò rí láti ọjọ́ tí ó ti gbé òun níyàwó; pẹ̀lú ìtara
ọmọ ni ìyá Ọmọ́pẹ́ ṣe sáré jáde sí ọ̀rọ̀ náà. Àti wí pé lọ́jọ́ ìbí Olùgbòdì
tó ń bọ̀ ni kábíèsí yóò fi jẹ oyè Ṣaṣamùrá tí ìlú Ọ̀jọ̀lọ̀.
Olúgbòdì ń bá Jẹun-jẹ́jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa
ìpalẹ̀mọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun, bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ ni Jẹun-jẹ́jẹ́ ti
rán an létí wí pé kó mọ̀ wí pé òun ò lè súnmọ́ obìnrin mọ́. Olúgbòdì náà ní òun
ò gbàgbé wí pé nǹkan tí òún fún wọn nínú ẹgbẹ́-àgbà nìyẹn.
Lẹ́yìn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àti ìwúyè, Olúgbòdì tí ó ti di
Ṣaṣamùrá ni Arígbábuwó sọ
fún wí pé òún fẹ́ gba ọmọ òun padà. Ìyẹn Ajéṣeré, ọmọ tí
Ọmọ́pẹ́ bí fún Ṣaṣamùrá. Ọ̀rọ̀ náà di yán-na yàn-na tí ó fà á tí Olúgbòdì fi
pa Arígbábuwó àti Adéṣeré. Bí ó ti fẹ́ pa Ọmọ́pẹ́ ni òun náà subú lulẹ̀ ló kú,
lẹ́yìn tí ó jẹ́wọ́ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ fún Olọ́jọ̀lọ̀.
Ìdí ọ̀rọ̀ ni wí pé Arígbábuwó ni ó bá òun bá Ọmọ́pẹ́ sùn tí ó fi bí Adéṣeré
nígbà tí òún ràn án lọ́wọ́ tí kò sì jẹ́ kí ó wọ ẹgbẹ́-àgbà, wọ́n sì jọ
mulẹ̀. Ó jẹ́ kí ó di mímọ̀
wí pé ìfẹ́ tí òún ní sí ìlú Ọ̀jọ̀lọ̀ ni ó jẹ́ kí òún ṣe gbogbo nǹkan tí òún
ṣe.
Ní ìran ìparí, a rí Bàbá Ukèbè tí ó parí ìtàn náà tí ó sì
ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí
Olúgbòdì ní sí àwọn ará ìlú rẹ̀. Wọ́n sì fi orin parí eré náà.
Ọnà-èdè
Ọnà-èdè ni a lè pè ní àwọn ọ̀rọ̀, àpólà tàbí gbólóhùn
tí òǹkọ̀wé alátinúdá máa ń lò láti mú adùn èdè wọnú iṣẹ́ rẹ̀. Ọnà-èdè ni a
tún lè pè àwọn ni ohun àmúṣe ọnà-litiresjo rẹ́wà tí àwọn oníṣẹ́ ọnà
lítíréṣọ̀ máa ń ṣàmúlò nínú iṣẹ́ wọn.
Onírúurú ọnà-èdè ló wà nínú lítíréṣọ̀ èdè Yorùbá tí a
lè tọ́ka sí; lára wọ́n ni
àwítúnwí, ìfohunpènìyàn, àsọrégèé, ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́, àfiwé, ìbéèrè-pèsìjẹ,
gbólóhùn adọ́gba, ẹ̀dà-ọ̀rọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nínú ìwé eré-oníṣe Sasamùrá,
àwọn ọnà-èdè tí Débọ̀ Awẹ́ ṣàmúlò nìwọ̀nyí:
Àfiwé tààrà: Àfiwé tààrà ni símílì tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì pè ní
“simile”. Irúfẹ́ àfiwé yìí kìí fara sin; nínú àfiwé tààrà, à ń fi nǹkan méjì wé ara wọn, àwọn
nǹkan méjì náà sì gbọdọ̀ jọ ara wọn nítorí pé ohun tó bá jọ ohun ni a fi
ń wé ohun.
(Ojú-ìwé 6) Ọ̀rọ̀ gbenu ọlọ́rọ̀ rà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀
(ojú-ìwé 6) Bọ́rọ̀ bá kúnni níkùn bí aboyún
(ojú-ìwé 33) Kọ́mọdé kan ní orí kunkun bíi kàà-sí-nǹkan
(ojú ìwé 33) Ìwọ́ ń dún kán-unkán-un bí agogo
ṣọ́ọ̀sì
(ojú ìwé 33) Ò ń bó bòkobòko bí òbúkọ
(ojú ìwé 43) tó bá jẹ́ròyìn dáadáa ni, kò ní í gbilẹ̀
bẹ́ẹ̀ bí iná agbáko o
(Ojú ìwé 45) ẹ̀ ẹ́ pẹ̀ẹ́ béwé pẹ́pẹ́ ṣe é pẹ́.
Ìbéèrè-pèsìjẹ: Èyí ni ìbéèrè
amú-èdè-rẹwà tí àwọn oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ dìídì bèèrè láìsí pé ó nílò
ìdáhùn sí irúfẹ́ ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
(ojú ìwé 10) kí ló dé tíná wa fi ń jájòó-rẹ̀yìn wẹ́ẹ̀
láé?
(ojú ìwé 10) Kí ló fẹ́ sọ? Ṣé á á lóun ò jí i gbé ni?
(ojú ìwé 23) Omi wo ni wọ́n tiẹ̀ fi ṣẹ̀dá wa lábúlé yìí
gan-an?
(ojú ìwé 31) Ṣe nítorí ìlú rẹ lo ó ṣe kọrùn bọnú
ìyà?
(ojú ìwé 31) Kí ni
kọ́mọ ọsin ti wáá ṣe o?
(Ojú ìwé 36) Bá a sá lo¸ta la fẹ́ sá tọ̀ lọ?
Ìfọ̀rọ̀dárà: Ọnà-èdè ìfọ̀rọ̀dára ni àwọn Gẹ̀ẹ́sì
ń pè ní “pun”. Ìfọ̀rọ̀dára jẹ́ ọnà-èdè tó nílò ìmọ̀-ọnse nínú àmúlò eré.
Ìyẹn ni pé ẹni tí kò bá gbọ́ èdè, tì kò ní ìmọ̀ èdè tó jinlẹ̀ kò le fi ọ̀rọ̀
dára.
(Ojú ìwé 33) Ọ̀lẹ ni wọ́n, wọ́n sì lólè
(ojú ìwé 15) Ó rí rùmúrùmú, ẹ̀yìn rẹ̀ fẹ́ẹ̀ẹ́ gba igbá
dúró
(ojú ìwé 23) Ọmọ náà burú púpọ̀, ó sì bu ògìrì pẹ̀lú.
Àwítúnwí: Àwítúnwí ni irúfẹ́ ọnà-èdè kan nínú
èyí tí à ń tún fónímù, sílébù, ọ̀rọ̀, odidi gbólóhùn tàbí akùdé gbólóhùn wí
nínu afọ̀.
(ojú ìwé 6) ọ̀rọ̀ ni ò pọ̀ níkùn ẹni, la ṣe ń sọ pé
ọ̀rọ̀ gbénú ọlọ́rọ̀ rà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀
(ojú ìwé 16) Olè, abojú wòòkò-wooko
(ojú ìwé 19) Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀ níwájú kábíèsí
(ojú ìwé 20) wótò-wòrò-wótò ń lọ lọ́wọ́
(ojú ìwé 42) Ọmọ ko láyọ̀lé, ẹni ọmọ sin ló bímọ
(ojú ìwé 44) Ààrẹ ń pè ọ́, ò ń dífá, bífá fọre báàrẹ
fọbí ńkọ́?
Ìfohunpènìyàn: Ìfohunpènìyàn ni ọnà-èdè tí àwọn
òǹkọ̀wé alátinúdá máa ń lò láti fi àbùdá ènìyàn wọ ohun tí kì í ṣe ènìyàn
tàbí àbùdá ẹlẹ́mìí fún aláìlẹ́mìí.
(ojú ìwé 13) Àlejò lewúrẹ́ nni
(ojú ìwé 21) Gbogbo ewéko lo n kanra, tí ara n ni wọn,
ti wọn n dun háráhárá
(ojú ìwé 21) Ewéko ìgbẹ́ nìkan kọ́ lará kan gógó o
(ojú ìwé 36) Ibà ńlá kan ló kọ lù ú láé.
(ojú ìwé 39) Òkùtù igi yìí ni, ó fẹ́ dáràn sí mi lọ́run
Gbólóhùn-adọ́gba: Èyí ni
ọnà-èdè tó wọ́pọ̀ nínú ewì nínú èyí tí akéwì ń lò akùdé gbólóhùn tàbí
gbólóhùn tó jọra ní ìhun àti ìtumọ̀ tẹ̀ lé ara wọn.
(ojú ìwé 15) kì í ṣèní, kì í ṣàná rèé tẹ́ran àtadìẹ wa
ti ń pòórá lẹ́yìnkùlé wa.
(Ojú ìwé 15) Ni mo bá fariwo bọnu, ni mo sá tẹ̀lé e
(ojú ìwé 15) Ni mo bá figbe ta, mo pariwo sí i
(ojú ìwé 17) ẹ̀yin ìjòyè, ẹ ṣeun; ẹ̀yin ìlú, mo dúpẹ́
(ojú ìwé 16)Ó kàn ki lápá, ó ki lẹ́sẹ̀ lásán
(ojú ìwé 17) Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ni toni
nǹkan.
Òwe: Òwe lẹṣin ọ̀rọ̀, bọ́rọ̀ bá sọnù,
òwe la máa fi ń wá a.
(ojú ìwé 18) ọ̀wọ́ èyí ò gbọdọ̀ pẹ́ nísà àkéekèe rárá
(Ojú ìwé 16) Ká mọ ohun tó rí lọ́bẹ̀ tó fi waro ọwọ́
(Ojú ìwé 12) Ibi tí a ti rugi oyin nìyí o
(ojú ìwé 8) Òní,
keté jìn sọ́fìn; ọ̀la, àmìnú fọ́ pòó lọ̀rọ̀ wa da.
(ojú ìwé 9) Ènìyàn tá a bú ìpọ̀nrí rẹ̀ tí ò mọ̀, bá a bá
búpọ̀rín-pọngbapọ́n rẹ̀, kò ní í mọ̀
(ojú ìwé 7) Ọmọdé wọ́n jogún ìlù, wọ́n ń yọ̀, láìmọ̀
pé àìmọ̀ọ́lù wọn ló pa Àyàngalú ìṣáájú.
Reference
Awe, Debo (2014), Ṣáṣámùrá. Ileṣa, Nigeria: Elyon
Publishers.
No comments:
Post a Comment