ORÍ KÌÍNÍ[1]
Ìbéèrè
1. Sọ àwọn fáwẹ́lì Yorùbá ti a le pin sí
isọri wọ̀nyì
i.
Fáwẹ́lì
aránmúpè
ii.
Fáwẹ́lì
àhànupè
iii.
Fawẹ́lì
àyánupè
iv.
Fáwèẹ́lì
iwájú
v.
Fáwẹ́lì
ẹ̀yìn
Ìdáhùn
i. Fáwẹ́lì aránnúpè: an, ẹn, in, oọn,
un
ii. Fáwẹ́lì àhánupè: i, u, in, un
iii. Fáwẹ́lì àyanupè: a, an
iv. Fáwẹ́lì ìwájú: i, e, ẹ, in, ẹn
v Fáwẹ́lì ẹ̀yìn: u, o, ọ, un, ọn
Ìbéèrè
2. Sọ ìyàtọ̀ tí ó wà láàrìn àwọn fáwẹ́lì
wọ̀nyí
u àti un
i àti u
ẹ àti a
ọ àti ọn
Ìdáhùn
a. “u” àti “un” jẹ́ fáwẹ́lì àhánupè ẹ̀yìn
roboto, ìyàtọ̀ tí o wà níbẹ̀ ní pé “u” jẹ́ àìránmúpè nígbà tí “un” jẹ́
àránmúpè.
b. “i” jẹ́ fáwẹ́lì àhánupè ìwàjú pẹrẹsẹ
nígbà tí “u” náà jẹ́ fáwẹ́lì àhánupè ṣùgbọ́n ‘u’ jẹ́ fáwẹ́lì ẹ̀yin
roboto.
d. “e”
jẹ́ fáwẹ́li ìwàju, ètè rí pẹrẹsẹ nígbà tí a pè é ṣùgbọ́n fáwẹ́li “a” jẹ́
fáwẹ́lì àárin pẹrẹsẹ
e. “ọ” àti “ọn”: “ọ” jẹ́ fáwẹ́li èyin
roboto “ọn” jẹ́ fáwẹ́lì èyìn roboto ìyàtọ wọn ni pé, “ọ” jẹ́ fáwẹ́lì àìrànmúpè
“ọn” jẹ́ fáwẹ́lì àránmúpè.
Ìbéèrè
3. Kín ni ọ̀na mẹ́rin ti a fi máa ń ṣe
àpéjúwe fáwélì
Ìdáhùn
i. Gíga odidi ahọ́n
ii. Giga ìwájú tàbí ẹ̀yìn ahọ́n
iii. Ipò ètè
iv. Ipò àfàsé
Ìbéèrè
4. Ṣe àpèjúwé ìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn fáwẹ́lì
wọ̀nyí:
ẹ, in, ẹn, a, o
Ìdáhùn
e: fáwẹ́lì
àyànudíẹ̀pè, ìwájú, pẹrẹsẹ, àìránmúpè
in: fáwẹ́lì ahánupè, iwájú, pẹrẹṣẹ,
àránmúpè
ẹn: fáwẹ́lì àyanudíẹ̀pè, ìwájù, pẹrẹṣẹ,
àránmúpè
a: fáwẹ́lì àyanupè àárín, pẹrẹsẹ,
àìránmúpè
ọ: fáwẹ́li àyanúdíẹ̀pè, ẹ̀yìn,
roboto, àìránmúpè
Reference
Bamgbose,
A. (1990), Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá.
Ibadan:
University Press Limited.
No comments:
Post a Comment