Tuesday, 12 June 2018

Egbìnrin Ọ̀tẹ̀


Àwọn òṣèré inú ìwé yìí: Baálẹ̀ Oyèníran, Aya Ayawo-ìyàwó Baálẹ̀, Balógun, Ọ̀gáàlú, Ọ̀túnba, Àjànà (olórí àwọn olórò), Adékúnlé (Ọmọ Adéoyè), Adéoyè (ẹni tí ó bá baálẹ̀ du oyè), Àlàó (ẹ̀gbọ́n Adéoyè), Ọbákolè (Olórí àwọn gbajúmọ̀) Tókí (ìyàwó Ọbákọlè), Kànnìké (Igbákejì Ọbákolè), Odebìjà (Omolẹ́yìn Ọbákolè), Yéwándé (Àna Baálẹ̀), Alá dúgbò, Agẹmọ (Ọmọlẹ́yìn Ọbákọlè), tádé, Bísí, Kọ́bùrù, ọ̀ga ọlọ́pàá, Àwẹ̀lé (wèrè), Ìyálòde, Olórí awo, Yétúndé (ìyàwó adájọ́), Adéọ̀ṣun (Adájọ́), Èrò kan, Ìlèbè (ọ̀rẹ́ Adékúnlé), Ọ̀pọ̀lọ́ (ọ̀rẹ́ Adékúnlé), Agbẹjọ́rọ̀[1].

Ìsọnísókí Egbìnrìn Ọ̀tẹ̀

Oyèníran jẹ́ baálẹ̀ ìlú Ìdomògún lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ rògbòdìyàn tí ó ti ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti Adéoyè nípa oyè jíjẹ. Nígbà tí ó jẹ oyè tán, ó pe ìyàwó rẹ̀ tí í ṣe ayawo, wọ́n sì jọ ń yọ̀ lórí oyè náà. Nínú ìtàkúrọ̀sọ wọn, a rí i wí pé Oyèníran jẹ́ ènìyàn kan tí ó ní ahun. Níbi tí wọ́n ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ni Olóyè Balógun ti dé bá wọn. Balógun kì í kú oríire oyè tí ó jẹ, ó sì jẹ́ kí ó yé e wí pé orí rẹ̀ ni ó gbè é dé orí oyè tí ó jẹ. Ó tún ṣe àfikún wí pé Adéoyè tí ó bá a du oyè kàn fí owó jóná lásán ni, nítorí wí pé oyè náà kò kàn án; kì í ṣe oyè ìdílé bàbá rẹ̀ àti wí pé ọmọ àlè ni. Lẹ́yìn èyí ni ó bá dágbére fún un wí pé òun ti fẹ́ máa lọ. Ó jáde kúrò nílé Baálẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Lẹ́yìn ìgbà tí Balógun lọ yán yan ni Ọ̀gáàlú wọlé. Òun àti Oyèníran (Baálẹ̀) sì jọ ń sọ̀rọ̀. Ó sọ fún baálẹ̀ wí pé iṣẹ́ tí ó rán òun ni òun wá jábọ̀ fún un. Kí ó tó jíṣẹ́ fún Baálẹ̀ ni Ọ̀túnba bá wọlé. Bí ó ṣe dé tí ó kí Ọ̀gáàlú àti baálẹ̀ tán ni ó tún dágbére wí pé òun tí ṣe tán tí òun ti fẹ́ máa lọ. Ṣùgbọ́n Baálẹ̀ kò jẹ́ kí ó lọ, ó sọ fún Ọ̀gáàlú wí pé kí ó sọ ọ̀rọ̀ tí ó fẹ́ sọ náà ní ojú Ọ̀túnba. Ni Ọ̀gáàlú bá kẹnu bọ̀rọ̀ náà. Ọ̀rọ̀ náà dá lórí ọmọ Tápà tí ó sọnù ní òkè Gálílì, ni Adékúnlé ọmọ Adéoyè bá ní àwọn olórò ni wọ́n gbé ọmọ náà pamọ́ tí wọ́n fẹ́ fi ṣe orò tàbí tí wọ́n fẹ́ fi ṣe nǹkan mìíràn. Ó sọ wí pé nítorí wí pé nínú igbó orò ni wọ́n tí rí I, ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé ó rò wí pé àwọn olórò ni ó gbé e. Àti pé nitori wí pé òun ti kọ́kọ́ sọ fún wọn wí pé àwọn ni wọn gbé e ni ó jẹ́ kí wọn ó gbé e sílẹ̀. Ó yà wọ́n lẹ́nu wí pé ẹnu Adékúnlé gbà á wí pé àwọn olórò ni ó gbé e. Inú bí wọn púpọ̀ wọ́n sì rò wí pé ó yẹ kí àwọn kọ́ ọ lọ́gbọ́n ìwà burúkú tí ó hù. Wọ́n fẹnu kò sí orí pé kí orò gbé Adékúnlé, kí orò sì nà án. Wọ́n ránṣẹ́ sí Àjànà tó jẹ́ olórí àwọn olórò.

Ní ọjọ́ kejì, wọ́n ránṣẹ́ pe Adékúnlé, ó sì wá. Wọ́n bi í léèrè ohun tí ó sẹlẹ̀, ó ṣe àlàyé wí pé òótọ ni wí pé òun sọ gbogbo rẹ̀ pátápátá. Baálẹ̀ àti awọn olóyè pàṣẹ wí pé kí Àjànà fi orò gbé e. Bí wọ́n ti ń gbé e lọ ni Adékúnlé ń pariwo tí ó ń bú gbogbo àwọn olóyè àti baálẹ̀ fún ara rẹ̀. Àjànà wọ́ ọ kúrò ní ọ̀dọ̀ Baálẹ̀, ó sì ń wọ́ ọ lọ sí igbórò. Òkìkí kàn bá Adéoyè níbi tí ó wà pé orò ti gbé ọmọ rẹ̀, Adékúnlé. Ó sáré lọ sílé lọ mú àdá rẹ̀, ó sì gba ẹgàn lọ. Bí ó ti dé ibẹ̀ tí ó rí i bí wọn ṣe ń lu Adékúnlé; inú bí i gidigidi bẹ́ẹ̀ ni ó pariwo ‘Ta ni ẹ̀ ń lù!? ‘níbo? Kì í ṣe nílẹ̀ yìí. Bí Àjànà ṣe rí i ni òun náà ti ń jágbe mọ́ ọn, tí ó sì ń rán an létí wí pé òun náà ti lọ́wọ́ sí orò àwọn ọmọ ọlọ́mọ rí. Ó sì tún fi kún un wí pé ẹnikẹ́ni kó fi ọwọ́ kan Adékúlé tí ó fi ń fi ẹnu ara rẹ̀ to ẹjọ, ó sì jẹ̀bi àwọn olórò. Àlàó dá sí ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ wí pé ọ̀rọ̀ náà kò le tó bí wọ́n ṣe mú un tó. Àti wí pé kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n máa jà lé lórí. Ó fi yé Àjànà wí pé ọmọdé ni ó ń ṣe Adékúnlé àti bàbá rẹ̀. Ìdí ni pé ẹni tí a bá fẹ́ sun jẹ́ tí ó fi epo ra ara tí ó tún wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ Adéoyè àti Adékúnlé se rí. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ó bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja fún Àjànà láti forí jì wọ́n. Àjànà sì jẹ́ kí ó yé e wí pé ọ̀rọ̀ kò sí lọ́wọ́ òun nìkan; gbogbo àwọn olóyè gbọ́, wọ́n sọ fún un wí pé àwọn yóò fi ikùnlukùn lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ní ilé Balógun ni àwọn olóyè ti ṣe ìpàdé wọn. Wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà sí ibi wí pé kí wọ́n ó tú Adékúnllé sílẹ̀ kí ó máa alọ. Wọ́n dá ọ̀rọ̀ Oyèníran sílẹ̀, wọ́n sọ nípa ahun rẹ̀. Wọ́n mu ọtí gáàsì. Wọ́n tún mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ Oyèníran padà; wí pé ṣe ni ó ń máa ń lọ sí ọjà fún ara rẹ̀. Ó tún lọ sí odò rí láti lọ fọ ẹran nitori pé kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ó bá òun jẹ níbẹ̀. Wọ́n sọ ẹrù tí Adékúnlé yóò san fún àwọn olórò gẹ́gẹ́ bí i ìtanràn fún orúkọ wọn tí ó bàjẹ́. Ó sì gbọdọ̀ san án pé, àìjẹ́bẹ̀, yóò tún fojú ba orò lẹ́ẹ̀kan sí i.

Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ìlú ti forí ji Adékúnlé tán. Ó pinnu láti ṣe ìjàǹbá fún ọba Oyèníran láti fi da ìlú rú. Ó lọ sọ́dọ̀ àwọn olè lati bẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ fún ìdàlúrú ọ̀ún. Ọ̀gá àwọn olè náà ni ó kọ́kọ́ lọ bá. Orúkọ rẹ̀ sì ní Ọbákolè ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn a máa pè é ní Ọbákọ̀ọ́. Kó ó tó dé ilé Ọbákọ̀ọ́ ni òun àti ìyàwó rẹ̀ tí i ṣe Tókí ti ń tàkurọ̀sọ lórí bí wọn yóò ṣe jẹun lọ́jọ́ náà. Nínú ìtàkurọ̀sọ wọn ni a ó ti mọ̀ wí pé ọlọ́sà gbáà ni ìyàwó àti ọkọ. Lẹ́nu ìtàkùrọsọ̀ wọn ni Kànnìké tí bá wọn. Kànnìké náà jẹ́ olè tí òun àti Ọbákọ̀ọ́ jọ ń ṣiṣẹ́. Òun náà fi ìwà olè hàn nígbà tí ó wọlé tí ó sì gbé àpò kan lọ́wọ́ tí ẹran wà nínú rẹ̀. Èyí fi hàn wí pé ó jalè ẹran náà ni. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ ni Adékúnlé wọlé. Adékúnlé kí wọn dáadáa, ó sì sàlàyé nǹkan tí òun fẹ́ kí wọ́n ṣe fún òun fún wọn. Ọbákòọ́ gbà láti ṣe iṣẹ́ yìí. Adékúnlé kúrò nílé rẹ̀, Kànnìké sì lọ sọ fún awọn ẹgbẹ́ wọn tí ó kù. Ó ku Ọbákọ̀ọ́ àti ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì sì ń sọ̀rọ̀ baálẹ̀ àti àwọn ìwà tí ó ń hù tí ó lè pa àwùjọ lára. Tókí náà sọ díẹ̀ lára àwọn ìwà baálẹ̀ yìí ó ti sojú rẹ̀ rí; ó ní nígbà tí òun lọ sí ọjà lọ́jọ́ kan, òun kò bá ìyá ẹlẹ́ja ní ṣọ́ọ̀bù rẹ̀, ni òun bá kúkú ní kí òun fi ọwọ́ rá ẹja bí i mélòó kan. Lẹ́yìn ìgbà tí òun ti jí ẹja tán ni baálẹ̀ wá dé láti wá ra ẹja. Ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe pé wọ́n mọ̀ baálẹ̀ wí pé kò le jalè ni, wọn ì bá ti lù ú kì ná kí wọ́n ó tó mọ̀ pé òun kọ́. Níbi tí wọ́n ti gbé ń sọ̀rọ̀ ni Adébìjà wọlé; ọ̀kan lára àwọn olè náà ni òun náà. Nígbà tí ó wọlé, Tókí jáde. Ọbákọ̀ọ́ àti Adébìjà náà bá tún tẹnu bọ ọ̀rọ̀ baálẹ̀ àti ìwà rẹ̀. Ibi tí wọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ni Ọbákọ̀ọ́ sùn lọ sí.

Lóru ọjọ́ náà, ọ̀nà mẹ́ta ni olè ti jà ní ìlú Arómògùn ṣugbn tí ilé àna blẹ̀ ni ó pọ̀jù. Wọ́n kó aṣọ, góòlù, owó, irin iṣẹ́ àti àwọn oríṣìíríṣìí nǹkan mìíràn tí ó jẹ́ dúkìá. Nígbà tí baálẹ̀ gbọ́, ó lọ síbẹ̀ àti àwọn ìjòyè díẹ̀. Wọ́n bá Yéwándé kẹ́dùn oun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sì tún ṣe àdúrà fún un wí pé Ọlọ́run yóò fi ọ̀pọ̀ rọ́pò. Níbi tí wọ́n wà yìí náà ni wọ́n tún ti gbọ́ ìròyìn mìíràn wí pé olè tún ti kólé ni ilé Adéagbo. Wọ́n dágbére fún Yéwándé, wọ́n sì tún gba ibòmìíràn lọ. Bí wọ́n ti ń lọ ni àwọn olóyè ti ń fi ọ̀rọ̀ baálẹ̀ létí wí pé kí ó fura sí òun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìlú. Baálẹ̀ náà fèsì sí ọ̀rọ̀ náà, ó sì dá a lábàá wí pé kí àwọn lọ sí igbórò láti lọ jíròrò. Gbogbo wọ́n lọ sí ibẹ̀, àwọn àgbààgbà pátápátá ni ó péjú síbẹ̀, wọ́n sì jíròrò nípa olè tí ó ń fi gbogbo ìgbà jàlú yóò ṣe dúró.

Ọ̀gáàlú ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ ní ìpàdé náà. Ó ní ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yìí kò dáa. Ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ tí obìnrin ẹ̀ẹ̀kan sọ nílé Yéwándé. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìlú tú mọ́ Oyèníran lórí. Lẹ́yìn ìgbà tí Ọ̀gáàlú dákẹ́ tán ni Àjànà dábàá wí pé kí orò máa ké lálaalẹ́. Ọ̀túnbá náà fèsì wí pé ǹjẹ́ baálẹ̀ ti rí àwọn gbajúmọ̀ ìlú bí? Baálẹ̀ fèsì wí pé òun kò mọ̀ wí pé àwọn gbajúmọ̀ kan tún wà ní ìlú yàtọ̀ sí baálẹ̀ àti àwọn olóyè ìlú. Àjànà fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí baálẹ̀ wí pé kí ó lọ ṣe ẹgbẹ́ awo. Ó ya baálẹ̀ lẹ́nu wí pé Àjànà ń ba òun sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìbínú. Ó jẹ́ kí ó yé e wí pé kí ó lọ wá nǹkan ṣe kí ìlú má ba à tú mọ́ ọn lórí. Balógun dá sí ọ̀rọ̀ yìí, ó pẹ̀tú sí Àjànà nínú lórí ọ̀rọ̀ náà wí pé sùúrù ni ọ̀rọ̀ náà gbà. Balógun náà fi kún ọ̀rọ̀ tirẹ̀ náà wí pé kí baálẹ̀ ó wá ọ̀nàkọ́nà tí yóò gbà láti máà jẹ́ kí ìlú náà ó tú mọ́ ọn lórí. Àti wí pé láti bí i ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni àwọn tí ń rí ìwé àwọn olè; ṣùgbọ́n tí baálẹ̀ kò gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí ọ̀rọ̀ náà. Àjànà tún já sí ọ̀rọ̀ náà lójijì, ó ní Baálẹ̀ kò mọ oore, nítorí àwọn ni àwọn gbé e dé ipò tí ó wà, ó wá débẹ̀ tán, kò fẹ́ mọ nǹkan tí ó ń ṣe mọ. Ọ̀túnba náà sọ̀rọ̀, ó ní ó yẹ kí baálẹ̀ ó lo làákàyè jù bí àwọn ṣe rò lọ. Àti wí pé orí Baálẹ̀ kò pé rárá. Àjàná tún ní kí wọn ó fi I sílẹ̀, wí pé ipa ẹsẹ̀ àwọn babańlá ni ó ń fẹ́ gbésẹ̀ lé. Inú bí baálẹ̀, ó pe Àjànà ní orúkọ, ó sì sọ pé “Oròtádé!!! Ṣe àlàyé gbólóhùn ní o fún mi. O gọ̀ díẹ̀. Mo rò pé o mẹmu; Àjànà náà tún fún un lésì pé òun mẹmu lóòótọ́ ṣùgbọ́n ìran awọn baba rẹ̀ kò kú sí orí oyè rí. Baálẹ̀ náà dá a lóhùn pé kí ó kúkú wá rọ òun lóyè. Àjànà ní òun kò lè yọ ọ́ lóyè, ṣùgbọ́n ẹni tó dífá afúyẹ́-gẹgẹ féèrà náà ni yóò tún dá ọ̀nà ò gbà fékùrọ́. Baálẹ̀ ní mẹ́tàlá rẹ̀ kò tó bẹ́ẹ̀. Balógun náà fèsì sọ́rọ̀ yìí, ó ní tí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé agbára baálẹ̀ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tí ìlú yóò fi tòrò ni ó yẹ kí ó wá, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìrọnilóyè ni ó yẹ kí ó máa sọ. Ọ̀túnba náà bá tún fèsì wí pé òótọ́ ni, ọ̀nà bí ìlú yóò ṣe dáa ni ó yẹ kí baálẹ̀ ó wá báyìí, pàápàá jù lọ lórí ọ̀rọ̀ àwọn gbajúmọ̀ ìlú. Ó sì dá òun lójú wí pé bí ó bá lè ṣe èyí, àwọn olè náà yóò dá iṣẹ́ aburú náà dúró. Lẹ́yìn tí Ọ̀túnba ti sọ̀rọ̀ tán ni Àlàó bá dìde dúró láti sọ̀rọ̀. Ó kí gbogbo awọn àgbà tí ó wà lórí ìjókòó. Ó kí wọn kú iṣẹ́ ìlú àti kí ìlú lè dára, ó sì ṣàdúrà wí pé ìlú náà kò níí dàrú láéláé. Ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní kí gbogbo àwọn olóyè ó fọwọ́ wọ́nú, kí wọn ó jèbùrẹ́ awo, olùgbẹ́bẹ̀. Kí wọ́n máà ṣe bá ara wọn ja mọ́. Ṣùgbọ́n kí wọ́n ó jẹ́ kí àwọn wá ọ̀nà tí ìlú yòó fi dáa àti ọ̀nà tí àwọn olè yóò fi dá ọwọ́ iṣẹ́ wọn dúró. Ó ní kí wọ́n máà ṣe dá baálẹ̀ lẹ́bi mọ́, àti wí pé àwọn ni àwọn fi jẹ oyè, ó sì yẹ kí àwọn ó gbárùkù tì í láti lè ṣe àṣeyọrí lórí iṣẹ́ ìlú tí ó ń ṣe. Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé bí ìlú bá kúrò lẹ́yìn baálẹ̀, a jẹ́ wí pé ìlú Ìdomògùn ti ṣe tán láti tú nìyẹn. Ó rọ Àjànà, Ọ̀túnba àti Balógun láti fi ọwọ́ wọ́nú. Ó ní kí wọn ó fa baálẹ̀ mọ́ra, kí wọ́n ó sì fi ọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ó tún wá fi gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé ìjà baálẹ̀ àti ti àwọn olóyè dà gẹ́gẹ́ bí òkòtó àti ìgbín nítorí itọ́ ni wọ́n máa ń fi nu ara wọn lára.

Lẹ́yìn ìgbà tí oníkálùkù ti kúrò nígbórò tán, baálẹ̀ délé, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí ronú lórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Ó ro ọ̀rọ̀ tí Àjànà àti Balógun sọ sí òun, ó mi orí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ púpọ̀. Ó rò ó wí pé kò sí ẹni tí òun lè fẹ̀yìn tì láàrin gbogbo àwọn olóyè náà. Ayawo bá a níbi tí ó tí ń dá sọ̀rọ̀, ó sì bí i ni ohun tí ó sẹlẹ̀; ó sì sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún un. Ayawo ní kí ó fi ọkàn ara rẹ̀ balẹ̀ wí pé àgò rẹ̀ ni yóò padà dé adìẹ àwọn olóyè náà ní ìgbẹ̀yìn. Bí àwọn méjèèjì ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Ọbákọ̀ọ́ wọlé, ó kí baálẹ̀, ó sì ní òun ti fẹ́ máa lọ. Baálẹ̀ ní kí ó má ì tí i lọ, òun ni ohun tí òun yóò fi ṣe é ní àlejò. Ó ní kí Ayawo gbé gáàsì wá fún Ọbákọ̀ọ́ kí ó mu ún. Ọbákọ̀ọ́ mu ọtí yó bámú; níbi tí ó ti ń mu ọtí ni ó ti ń jábọ́ fún baálẹ̀ wí pé, olè tí ó ń jà nílù, ejò lọ́wọ́ ń nú. Nígbà tí baálẹ̀ gbọ́ èyí, kò yà á lẹ́nu púpọ̀ nítorí pé òun tí ó fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ náà nìyẹn tí ó fi gbé ọtí fún un. Àti wí pé Ayawo ti gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì ti sọn un wí pé kí wọ́n ó fa ojú Ọbákọ̀ọ́ mọ́ra wí pé yóò sọ tẹnu ẹ. Nígbà tí Ọbákọ̀ọ́ mu ọti náà tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin, ó sì dágbére fún baálẹ̀ wí pé òun ti fẹ́ máa lọ. Nígbà tí ó jáde tán, baalẹ̀ pe Ayawo, ó sì ṣàlàyé ohun tí Ọbákòọ́ sọ fún un. Ayawo tún sọ fún baálẹ̀ wí pé kí ó fà á bọ̀dí kí ó fi lè mọ àṣírí àwọn olè náà dáadáa.

Nígbà tí Ọbákọ̀ọ́ kúrò nílé baálẹ̀ tán, ó pàdé Kànnìké lọ́nà. Kànnìké sọ fún un wí pé òun ti wá a lọ sílé òun kò bá a. Ọbákọ̀ọ́ sọ fún un wí pé òun lọ sílé baálẹ̀ ni, baálẹ̀ sì ṣe òun ní àlejò dáadáa pẹ̀lú. Ó ya Kànnìké lẹ́nu pẹ̀lú nǹkan tí Ọbákọ̀ọ́ sọ. Ọbákọ̀ọ́ fi yé Kànnìké wí pé kìí ṣe bí wọ́n ṣe máa ń sọ̀rọ̀ baálẹ̀ ni ó ṣe rí. Àti wí pé kò ní ahun rárá nítorí pé ó ṣe òun ní àlejò gan-an ni o. Níbi tí wọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ni Òdébìjà ti bá wọn. Ó sọ fún wọn wí pé òun ti ń wá wọn látàárọ̀ nítorí òun ní ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tí òun fẹ́ bá wọn sọ. Wọ́n sì ní kí ó sọ ọ̀rọ̀ náà. Òdebìjà sọ fún wọn wí pé òun rí Agẹmọ láàrin àwọn olóyè nílé Balógun tí ó ń sọ fún wọn wí pé àwọn Ọbákọ̀ọ́ ni ó máa ń jalè lálaalẹ́. Àwọn olóyè sí ní àwọn yóò fa Ọbákọ̀ọ́ àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lé ọlọ́pàá tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé òkè pópó lọ́wọ́. Agẹmọ sì tún ṣe ìlérí wí pé òun yóò jẹ́ kí wọ́n ó mọ ìgbà tí àwọn yóò jáde ní òru òní. Ó ya Ọbákọ̀ọ́ àti Kànnìké lẹ́nu púpọ̀ nítorí wí pé Agẹmọ jẹ́ ọ̀kan gbòógì láàrin wọn. Ọbákọ̀ọ́ sọ wí pé kó burú, àwọn yóò mọ ọ̀nà tí àwọn yóò gbé ọ̀rọ̀ náà gbà. Nígbà tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ Agẹmọ, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bẹ̀rẹ̀ síí fún ara wọn ní oògùn oríṣìíríṣìí gẹ́gẹ́ bí i; ògùn àfẹ́ẹ̀rí, egbé, ayẹta àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn èyí, gbogbo wọ́n túká wọ́n sì gba ilé wọn lọ láti pàdé ní ìrọ̀lẹ́.

Ní ilé baálẹ̀, gbogbo àwọn olóyè ni wọ́n ti péjú síbẹ̀. Ní ìgbà tí ó pẹ́ díẹ̀, Ọ̀túnba dìde, ó sì sọ̀rọ̀. Ó sọ̀rọ̀ lórí bí Baálẹ̀ Oyèníran kò ṣe wá àtúnṣe sí gbogbo bí olè ṣe ń jà lọ́tùn-ún àti lósì. Ó sì fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé kò bà jẹ́ lórí Olúgbọ́n, kò bájẹ́ lórí Arẹ̀sà; ṣùgbọ́n bí Ìdómògùn kò ṣe níí bàjẹ́ kù sọ́wọ́ Baálẹ̀ Oyèníran, bí ó bá fẹ́ kí ó gbọ́, bí ó bá sì tún fẹ́ kí ó máà gbọ́; Ọba tí ó jẹ tí ìlú fi tòrò, orúkọ rẹ̀ kò níí parẹ́, èyí tí ó sì jẹ́ tí ìlú dàrú náà, orúkọ rẹ̀ kò níí parun láé. Nígbà tí Ọ̀túnba sọ̀rọ̀ tán, Balógún dìdé, ó sì ní tí Oyèníran kò bá wá nǹkan kan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà, àwọn yóò fi ìlú sílẹ̀ fún un kí ó máa dá a ṣe. Ọ̀rọ̀ yìí dìjà láàrin Baálẹ̀ àti Balógun nítorí Baálẹ̀ ní òun náà kò jókòó lásán lórí ọ̀rọ̀ náà àti wí pé sé ẹbọ ni wọ́n ní kí òun rú tí òun kò rú ni àbí ètùtù? Lẹ́yìn tí ìjà náà ti rọlẹ̀ tán, Àlàó dìde ó sì sọ̀rọ̀. Ó ní kí Balógun máà ṣe bá Baálẹ̀ jà nítorí iṣẹ́ gbogbo àwọn olóyè náà ni láti máà jẹ́ kí ìlú Ìdómògùn bàjẹ́.

Nígbà tí Àlàó sọ̀rọ̀ tán, ó jókòó. Ṣùgbọ́n ṣe ni Baálẹ̀ àti Balógun ń kọrin bú ara wọn. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n bá ní kí Baálẹ̀ náà sọ̀rọ̀. Wọ́n sì tún sọ fún un wí pé kí ó sọ ìdí tí Ọbákọ̀ọ́ fi wá sílé rẹ̀ lánàá. Baálẹ̀ ní kí ó máà ba à bàjẹ́ náà òun ń bá kiri ni ó ṣe jẹ́ kí òun ó pe Ọbákọ̀ọ́ láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra kí ó si lè jẹ́wọ́ àwọn tí wọ́n rán an níṣẹ́ tí ó ń jẹ́ kiri ìlú. Àti wí pé nígbà tí Ọbákọ̀ọ́ yóò jẹ́wọ́ fún òun, ó ní Adékúnlé àti baba rẹ̀ Adéoyè ni wọ́n ní kí òun máa da ìlú rú. Nígbà tí Adéoyè gbọ́ níbi tí ó jókòó sí, ó yà á lẹ́nu púpọ̀. Ó sọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ nnkankan nípa ẹ̀sùn tí Baálẹ̀ fi kan òun. Agẹmọ náà dá sí ọ̀rọ̀ náà wí pé Adékúnlé gan-an gan-an fún ara rẹ̀ ni ó wá bá àwọn pé kí àwọn máa ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ìlú ní kí wọ́n ó lọ pe Adékúnlé wá, kí Adéoyè sì fún àwọn láyè díẹ̀. Adéoyè jáde pẹ̀lú ìbínú kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. Nígbà tí ó lọ tán, Àlàó dìde láti sọ̀rọ̀. Ó ní kí wọ́n ó máà ṣe dá Baálẹ̀ lẹ́bi gbogbo ìwà tí ó ń hù; bíi kí ó lọ sọ́jà lọ rẹja, kí ó lọ sódò lọ fọ ẹran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé kí wọ́n ó jẹ́ kí àwọn wá ọmọ tí yóò máa ran Baálẹ̀ lọ́wọ́ fún un. Kí wọ́n ó sì jẹ́ kí àwọn ó bẹ̀rẹ̀ síí san ìsákọ́lẹ̀ fún Baálẹ̀ padà. Inú gbogbo ìlú dùn fún àbá tí Àlàó mú wá yìí, wọ́n sì gbà á wọlé tayọ̀tayọ̀. Wọ́n sì kí Baálẹ̀ kú oríire.

Àwọn gbajúmọ̀ ń ṣe ìpàdé láàjìn. Ọbákọ̀ọ́ ni ó dá ọ̀rọ̀ Agẹmọ sílẹ̀ nínú ìpàdé náà. Gbogbo wọ́n pè é ní ọ̀dàlẹ̀. Wọ́n tún pinnu láti máà jalè nínú ìlú Ìdomògùn ní ọjọ́ náà ṣùgbọ́n kí àwọn lọ sí ìlú òdìkeji lọ jalè. Lórí ọ̀rọ̀ Agẹmọ, Kànnìké sọ wí pé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ̀ ẹ nítorí pé ó gbé adìẹ aládìẹ. Ó wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá; kò tíì rí ẹni tí yóò dúró fún un. Ọbákọ̀ọ́ ní ó yẹ kí àwọn lọ dúró fún un, kí àwọn sì mulẹ̀ mìíràn fún un. Kí ó má ba à lè dalẹ̀ àwọn mọ́. Gbogbo wọn gba àbá yìí wọlé ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fẹ́ lọ kojú ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé wá nítorí wọn kò mọ irú ènìyàn tí ó jẹ́. Ọbákọ̀ọ́ ní òun yóò lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá náà láti lọ gba Agẹmọ sílẹ̀. Wọ́n parí ìpàdé, wọ́n sì tú ká. Ní déédé àkókò yìí ni Baálẹ̀ ń bọ̀ láti ọ̀nà òdò pẹ̀lú ọ̀kẹ́ gúlútú kan lọ́wọ́, ó sì pàdé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì kan, wọ́n kí Baálè., wọ́n sì bá ti wọn lọ.

Ọbákọ̀ọ́ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, ó bá Kọ́bùrù lórí kántà, ó béèrè ọ̀gá lọ́wọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n Kọ́bùrù kò fẹ́ kí ó rí ọ̀gá. Nígbà tí ọ̀gá gbọ́ ariwo láti inú ọ́fíìsì rẹ̀, ó ké sí Kọ́bùrù, ó sì béèrè ohun tí ó fa ariwo lọ́wọ́ rẹ̀, ó ní ọ̀gbẹ́ni kan tí ó pe ara rẹ̀ ní Ọbákọ̀ọ́ ni ó ní òun fẹ́ rí i. Ọ̀gá ní kí ó jẹ́ kí ó wọlé. Ọbákọ̀ọ́ wọ inú ọ́fíìsì ọ̀gá, wọ́n kí ara wọn wọ́n sì sọ orúkọ ara wọn. Ọ̀gá ní kí ló gbé Ọbákọ̀ọ́ wá sí àgọ́ àwọn, Ọbákọ̀ọ́ ní òun kàn wá kí ọ̀gá lásán ni àti wí pé nítorí tí ó jẹ wí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé e dé ló fà á. Ó fọ̀rọ̀ wá ọ̀gá lẹ́nu wò nípa ọ̀rọ̀ Agẹmọ. Ọ̀gá sì sọ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe jẹ́ fún ún. Ọbákòọ́ ní kí ọ̀gá máa ké sí òun fún ìrànlọ́wọ́ tí ó bá fẹ́ àti pé onísègùn ni òun, kódà kò sí ògùn tí ó fẹ́ tí òun kò ní lọ́wọ́. Ó tún sọ fún un pé níbí tí ògùn náà pọ̀ dé, òun ní oògùn ẹjọ́. Èyí máa ń ṣiṣẹ́ nígbà tí ènìyàn bá ní ẹjọ́ ní kóòtù tí ó sì fẹ́ kí ẹjọ́ náà parí. Ṣebí ọ̀gá sì ti ní ẹjọ́ líle kan ní kóòtù tẹ́lẹ̀, tí ó ti náwó-náwó lé lórí. Ní ọ̀gá bá kúkú sọ Ọbákọ̀ọ́ di ọ̀rẹ́ àpàpàndodo jẹ́jẹ́. Ó ní kí ó bá òun wá oògùn náà ní kíá kíá. Ọbákọ̀ọ́ ní òun ti gbọ́ ṣùgbọ́n kí ó jọ̀wọ́ kí ó yọ̀ǹda Agẹmọ fún òun kí òun máa mu lọ; òun yóò ṣe onídúró fún un. Ọ̀gá ọlọ́pàá gbà, ó sì pe Kọ́bùrù pé kí ó mú Agẹmọ wá fún Ọbákọ̀ọ́ kí ó máa mú un lọ. Ọbákọ̀ọ́ fi dá ọ̀gá lójú wí pé òun yóò mú oògùn náà wá fún un láìpẹ́. Agẹmọ rí Ọbákọ̀ọ́, ó yà á lẹ́nu. Ọbákọ̀ọ́ sì mú un kúrò ní àgọ́ ọlọ́pàá.

Bísí àti Tádé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lábẹ́ igi nípa ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ní ìlú Ìdómògùn. Ọ̀rọ̀ náà dá lórí Baálẹ̀ àti olè tí ó jà ní Òkè-odò. Nínú ọ̀rọ̀ wọn ni a ti rí i wí pé àwọn ọlọ́pàá ti mú Baálẹ̀ lọ sí àgọ́ wọn; wọ́n fi ẹ̀sùn olè kàn án wí pé òun ló fọ́ ilé tí ó wà ni òkè-odò. Adékúnlé ni ó lọ sọ fún àwọn ọlọ́pàá wí pé Baálẹ̀ ni ó ṣiṣẹ́ náà. Ó sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun (Ìlèbè àti Ọ̀pọ̀tọ́) ni wọ́n rí i nígbà tí ó ń bọ̀ lọ́jọ́ náà láàjìn. Níbi  tí wọ́n tí ń sọ̀rọ̀ yìí ni Adékúnlé ti kọjá. Ó kí wọ́n àwọn náà sì kí i, wọ́n wá bèèrè ibi tí ó ń lọ, ó sì sọ fún wọ́n wí pé àgọ́ àwọn ọlọ́pàá ni òun ń lọ láti lọ jẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Nígbà tí ó lọ tán ni Àwẹ̀lé (wèrè) náà kọjá ní iwájú wọn. Bí ó tí ń kọjá ni ó ń dá sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ Baálẹ̀ Oyèníran ni òun náà ń sọ. Ó ya àwọn méjèèjì lẹ́nu wí pé ọ̀rọ̀ náà ti gbàlú gidigidi. Bísí àti Tádé tún fi kún ọ̀rọ̀ wọn wí pé wọn yóò padà gbé Baálẹ̀ lọ sílé ẹjọ́ ni, nítorí kò ní àwíjàre kankan ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá tí ní bí ẹlẹ́rìí mẹ́ta.

Àwọn ìlú Ìdómògùn péjú sílé Ọ̀túnba láti jíròrò nípa ọ̀rọ̀ Baálẹ̀ Oyèníran. Ọ̀túnba ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, ó ní; “Ẹ kú o, ẹ̀yin Ìdómògùn. Àwọn àgbà ní ọ̀rọ̀ ló bá mokó-morò wá. Àròkàn náà ní í mú àsun-ùndákẹ́ wá. Èyí tí ó délẹ̀ yìí kúrò léré. Gbogbo Ìdòmogun ló kàn. Ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé bí a bá ń bú ẹtù orí a máa ta awó. Nítorí náà, àpéjọ wa yìí, láti doríkodò ni. Ọ̀nà wo la ó gbà fi yọ Oyèníran nínú ọ̀ràn yìí. Bí ó bá ṣe pé abórí-kùró ni ọ̀ràn kàn báyìí, Ìdómògùn lè wí pé kò rá àwọn, ṣùgbọ́n eléyìí yí wa ní gbogbo ara. Baálẹ̀ kò gbọdọ̀ lọ ẹ̀wọ̀n, tú-é! Àsàápàkọ́ bí a bá sáà síwájú á bó. Ọ̀nà tí a bá máa gbé e gbà ni kí ẹ jẹ́ kí á mú rò ó”. Nígbà tí Ọ̀túnba sọ̀rọ̀ tán, Ọ̀gáàlú náà dá sí i. Ó kí Ọ̀túnba wí pé ó kú àbọ̀. Òun náà sì sọ tẹnu ẹ̀. Ó ní kí wọn ó jẹ́ kí àwọn gbé ọ̀rọ̀ náà wò, kí àwọn ó ṣe ìwádìí lórí ẹ̀ dáadáa nítorí wí pé tí ó bá jẹ́ wí pé Baálẹ̀ jalè lóòótọ́, kò sí ohun tí àwọn lè ṣe sí i. Ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí i àwọn ó ṣe ìgbésẹ̀ lórí ẹ ní kíákíá.

Balógun fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gáàlú sọ, ó ní ìgbésẹ̀ náà ni kí àwọn ó gbé ní kíákíá. Ọ̀túnba wá sọ wí pé ọmọ ẹni kò níí burú títí kí a fi i fẹ́kùn pajẹ. Baálẹ̀ Oyèníran láhun kò láhun, Baálẹ̀ Ìdómògùn náà ni o jẹ́. Bí wọ́n tí ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Ìyálóde wọlé. Ó kí wọn, ó sì jókòó, ó dá sí ọ̀rọ̀ wọn, ó sì sọ fún wọn wí pé láti àgọ́ ọlọ́pàá ni òun tí ń bọ̀. Ó ròyìn ohun tí ojú òun rí lórí ọ̀rọ̀ Baálẹ̀, ó sì tún sọ fún wọn wí pé Ọbákọ̀ọ́ náà ń ṣe guduguduméje, yààà mẹ́fà lórí ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí Ìyálóde sọ̀rọ̀ tán, Àjànà mú àbá wá láti jẹ́ kí àwọn ó bifá lórí ọ̀rọ̀ náà. Gbogbo wọn gbà, wọ́n sì ránṣẹ́ sí Olúawo. Níbà tí Olúwo dé, ó kí gbogbo àwọn ìsòròsọ̀pẹ̀, ó sì jókòó. Ó gbé ifá sánlẹ̀ wàà, ó kifá, ó sì ki odù tí ó wà lójú ifá náà fún wọn. Ó ní ayọ̀ ni ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà yóò jásí. Ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ náà bá yanjú tán, kí Oyèníran jáwọ́ nínú àìgbọràn. Ọ̀tún wa béèrè wí pé kín ni ẹbọ? Olúawo tún gbé Ifá ṣánlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì ní Ifá ní kí wọ́n ó fire fóògùn; Ọ̀rúnmìlà ní kí a fire féwé, ìtí ọmọ afòru rìn. Olúawo parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì jáde lọ. Àwọn olóyè ní ohun tí ó bá ti yá kan kì í pẹ́ mọ́, kí gbogbo àwọn ó lọ múra dáadáa, kí onílúlùkù ó lọ gbé òògùn tí ó bá ní jáde, ẹni tí ó bà lè jáwé kó lọ jáwé kí àwọn ó filè ṣẹ́gun yìí.

Ní ọ́fíìsì ọlọ́pàá, ò.gá ń wádìí lẹ́nu Kọ́bùrù rẹ̀ bí wọ́n ó ṣe rí ìdí ọ̀rọ̀ náà sí, ó tún tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọn létí kí ó má dá ọwọ́ ìwádìí dúró títí òdodo yóò fi yọjú. Níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ni ọ̀gá ti lálejò. Àlejò náà wá bẹ̀bẹ̀ fún ọ̀daràn tí ó wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ni. Nígbà tí ọ̀gá ọlọ́pàá padà sí ọ́fíìsì, Kọ́bùrù béèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀gá, ọ̀gá sì sọ fún un wí pé ẹ̀bẹ̀ lásán ni ẹni náà wá bẹ̀ àti wí pé kò wulẹ̀ mú owó lọ́wọ́, ó kàn fẹ́ kí àwọn ó tú ọ̀daràn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ rè é, irọ́ ni ọ̀gá ọlọ́pàá ń pa, ó ti gba owó lọ́wọ́ onítọ̀hún ṣùgbọ́n kò fẹ́ sọ fún Kọ́bùrù kí ó má baà fún un níbẹ̀.

Ní ọjọ́ kejì, Ọbákòlè lọ bá ọ̀gá lọ́fíìsì, Ìyálóde náà sì bá wọn níbẹ̀. Àwọn méjèèjì ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ nípa ọ̀rọ̀ baálẹ̀. Ọ̀gá ọlọ́pàá fi yé wọn wí pé òun kò ní ìrànlọ́wọ́ kankan tí òun lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà, nítorí ó ti dé iwájú adájọ́ ní kóòtù. Ìrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo tí òun lè ṣe ni kí òun ó gba lọ́ọ̀yà fún baálẹ̀. Ó tún sọ fún wọn wí pé ọjọ́ kejì ọjọ́ náà ni Baálẹ̀ yóò fojú ba ilé-ẹjọ́. Adájọ́ tí yóò dá ẹjọ́ náà sì ni Adéọ̀sun. Òun yóò gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn pé kí wọn ó lọ bá Adéọ̀ṣun láti fi ọ̀rọ̀ náà tó o létí. Bí ó ṣe sọ̀rọ̀ rẹ̀ tán ni ó ń bá Ìyálóde ṣàwàdà pé òun yóò wá kí i lálẹ́.

Ní ìdájí ọjọ́ kejì, ìyálóde àti Ọ̀túnba ti jí dé ilé Adéọ̀sun kí ó tó jí kúrò ílé. Ìyàwó rẹ̀, Yétúndé, ni ó kọ́kọ́ yọjú sí wọn nígbà tí wọ́n débẹ̀. Ó sọ fún wọn wí pé Adéọ̀ṣun ń wẹ̀ lọ́wọ́. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wá lọ Yétúndé; kí ó fi lè bá wọn fi ẹnu sí i nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá dé. Ṣùgbọ́n Yétúnde ti sọ fún wọn sílẹ̀ wí pé kò sí ohun tí Adéọ̀ṣun lè ṣe sí i. Ìdí ni wí pé ohun tí agbẹjọ́rò àwọn méjéèjì bá sọ ni òun yóò tẹ̀lé. Lẹ́nu ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n wà tí Adéọ̀sun fi wọlé bá wọn. Nígbà tí ó rí àwọn olóyè méèèjì, ẹnu yà á púpọ̀ pé a kì í réwu lọ́sàn-án. Nígbà tí wọ́n sì kẹ́jọ́ sílẹ̀ tí wọ́n rò fún un, ó yà á lẹ́nu púpọ̀ ṣùgbọ́n ohun tí Yétúndé sọ fún wọn náà ló sọ. Ó sì tún fi kún un fún wọn wí pé ìpàdé di ilé-ẹjọ́.

Nínú kóòtú, àwọn ọlọ́pàá, akọ̀wé àti ọ̀pọ̀ èrò tí dé. Àwọn ará Ìdómògùn àti Ìfìjá kò ku ọ̀kan. Ìlèbé, Ọ̀ọ̀tọ́ àti Adékúnlé tí wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Gbọ̀ngán kóòtù kò gba èrò, àwọn èrò tí wọ́n dúró síta kò níye. Kò pẹ́ tí wọ́n jókòó tán ni Adéọ̀ṣun jáde láti inú ìyàrá kékeré tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kóòtù, tí ó wọ gbọ̀ngá. Bí ó ti wọ gbọ̀ngàn báyìí ni ọlọ́pàá kígbe kóótù, tí gbogbo èrò sì dìde. Adájọ́ bèèrè ẹjọ́ ẹni tí ó kàn; akọ̀wé sì dáhùn wí pé ẹjọ́ Oyèníran tí wọ́n fi ẹ̀sùn olè kàn ni ó kàn. Lẹ́yìn èyí ni àwọn agbẹjẹ́rò méjì wọlé. Wọ́n kí Adájọ́ pẹ̀lú ìtẹríba. Adájọ́ sì dá wọn lóhùn. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n mú Baálẹ̀ jáde tí wọ́n sì fi i sínú koto. Akọ̀wé bèèrè ẹ̀sìn tí ó ń sìn lọ́wọ́ rẹ̀, Baálẹ̀ sì ní ògún ni. Wọ́n gbé irin fún un, ó sì fi búra pé òtítọ́ ni gbogbo ohun tí òun yóò sọ.

Nígbà tí Baálẹ̀ búra tán, Agbẹjọ́rò rẹ̀ dìde ó sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Ó kọ́kọ́ bèèrè wí pé “ọjọ́ wo ni a fi ẹ̀sùn yìí kan oníbàrá mi?” Kọ́bùrù dá a lóhùn wí pé ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá ni. Ó sì tún bèèrè pé ǹjẹ́ àwọn ọlọ́pàá ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà dáadáa. Kọ́bùrù dá a lóhùn wí pé bẹ́ẹ̀ ni. Ó tún bèèrè wí pé ẹlẹ́rìí mélòó ni wọ́n ni. Kọ́bùrù ní ẹlẹ́rìí mẹ́ta. Agbẹ́jọ́rò tún bèèrè wí pé kí wọ́n ó pè wọn jáde bọ́ sínú koto. Kọ́bùrù pe Ìlèbé, Ọ̀pò.tọ̀ àti Adékúnlé jáde. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta búra, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè ọlọ́kan-ò-jọ̀kan lọ́wọ́ wọn. Agbẹ́jọ́rò Baálẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ wọn wí pé ǹjẹ́ wọn rí Baálẹ̀ nígbà tí ó ń kólé? Wọ́n ní rárá, ṣùgbọ́n àwọn rí i lọ́jọ́ náà tí ó ń bọ̀ láti ọ̀nà odò ní ìdájí pẹ̀lú ọ̀kẹ́ kan lọ́wọ́ tí omi ń ro lára rẹ̀. Agbẹjọ́rò tún bèèrè wí pé ǹjẹ́ yàtọ̀ sí ọ̀kẹ́ náà, ṣé baálẹ̀ tún ru ẹrù mìírà. Wọ́n ní rárá, ó tún bèèrè pé ilé tí wọ́n ti jalè, ǹjẹ́ wọ́n sọ bí ẹrù náà ṣe pọ̀ tó? Wọ́n ní ẹrù náà pọ̀ gan-an ni. Agbẹjọ́rò Baálẹ̀ wá fi ìdí ẹjọ́ náà múlẹ̀ wí pé kò sí òdodo nínú ọ̀rọ̀ náà, nítorí pé kò sí ẹ̀rí tí ó dájú fún ẹ̀sùn náà.

Lẹ́yìn tí agbejọ́rò tí sọ̀rọ̀ tán ni Kọ́bùrùbá tọrọ àyè lọ́wọ́ adájọ́ pé òun fẹ́ béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Baálẹ̀. Kọ́bùrù fi ọ̀rọ̀ wá Baálẹ̀ lẹ́nu wò ó sì sọ tẹnu rẹ̀ fún Adájọ́. Adájọ́ dìde fún ìsinmi díẹ̀ ó sì wọlé lọ. Gbogbo àwọn èrò dìde fún adájọ́ tí ó fi jáde. Lẹ́yìn àsìkò díẹ̀, Adájọ́ wọlé padà, àwọn èrò sì tún dìde fún un tí ó fi jókòó. Adájọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, gbogbo àwọn èrò inú kóòtù dákẹ́ rọ́rọ́ láti gbọ́ ìdájọ́ rẹ̀. Adájọ́ ní gbogbo ẹjọ́ tí àwọn agbẹjọ́rò ti rò ni òun ti gbọ́ àti tàwọn ẹlẹ́rìí. Ó ní nínú gbogbo ẹjọ́ náà, ó hàn gedegbe pé kì í ṣe Baálẹ̀ ni ó kó ilé náà àti wí pé wọ́n parọ́ mọ́ ọn ni. Níbi tí Adájọ́ tí ń sọ̀rọ̀ lọ ni wọ́n ti gbọ́ ariwo “olè!”. Adájọ́ bèrè lọ́wọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá wí pé kín ló ń ṣẹlẹ̀, ọ̀gá ọlọ́pàá sọ pé àwọn olè ni ọwọ́ tẹ̀. Adájọ́ bèèrè pé àwọn olè wo? Wọ́n sì ní àwọn olè tí ó fọ́lé lókè odò ni. Adájọ́ ní kí wọ́n ó mú wọn wọlé wá. Adájọ́ ń bá ìdájọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Baálẹ̀ lọ. Ó ní kò sí ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Fún ìdí èyí, Baálẹ̀ kò jẹ́bi ọ̀rọ̀ náà; òun sì dá a sílẹ̀ kí ó máa lọ láyọ̀ àti àláfíà. Lẹ́yìn èyí adájọ́ bèèrè lọ́wọ́ àwọn olè náà pé kín ni ìdí tí wọ́n fi lọ ṣe iṣẹ́ náà. Wọ́n ni nítorí àtijẹ àtimu ni. Adájọ́ sì dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún wọn.

Ariwo sọ nílé ẹjọ́ yèèè, inú wn dùn pé wọ́n ti dá Baálẹ̀ sílẹ̀, wọ́n gbé Baálẹ̀ ní kọ́kọ́lọ́rùn, wọ́n sì ń kọrin fún un wí pé ó kú oríire.

 

Ìlò èdè nínú ìwé Ègbìnrìn Ọ̀tẹ̀

(1)     Òwe: Òǹkọ̀wé ìwé yìí pa òwe tí ó pọ̀ nínú ìwé yìí. Òwe jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí àwọn bàbá wa máa ń gbà fi bá ara wọn sọ̀rọ̀ àsírí tàbí ọ̀rọ̀ tí wọn o bá fẹ́ lo ọ̀rọ̀ geere fún. Bí àpẹẹrẹ:

·        Ó jọ gáté kò jọ gàté, ó fi ẹsẹ̀ méjéèjì tiro

·        Ẹ jẹ́ kí á pe ọkọ́ lọ́kọ́ kí á má pè é ni arugọ̀gọ̀ tí a fi ń túlẹ̀.

·        Àgbà kò jẹ́ ṣubú yẹ̀kẹ kó da ti ikùn sílẹ̀, ohun tí a bá jẹ ní ń bá ni í lọ.

·        Onísàngó tó jó tí kò tàpá, àbùkù ṣàngó kọ́, àbùkù ara rẹ̀ ni.

·        Kí á tó sọ̀rọ̀, ọkà ti jìnnà àti ewédú. Ẹ jẹ́ kí á wé láwàní ọwọ́ ná.

·        Oore wo ni òòṣà ṣe abuké tó bímọ tán tó tún sọ ọ́ ní òòṣàgbèmí?

·        Ẹ̀gàn kò pé kí oyin má dùn.

·        Okó ṣeé ro ni alágbẹ̀dẹ ń kan ọkọ́ tà.

·        Ẹkùn jókòó, ìkóòkò jókòó, erin fẹ̀yìn tí ẹfọ̀n sùn kaakà wọ́n ní kí alábahun lọ bá wọ́n mú nǹkan wá nínú igbó, ó ni ẹ̀rù wo ló tún kù sínú igbó?

·        Àìkọ̀wọ̀ọ́ rìn ejò ní ń ṣekú pa wọ́n.

 

(2)     Ọnà Èdè: Oríṣìí ọnà-èdè ni a ní ṣùgbọ́n àfiwé ni ó jẹyọ jù nínú  ìwé yìí.

1.       Àfiwé: èyí ni kí a fi ohun kan wé òmíràn. Ó lè jẹ́ nǹkan ẹlẹ́mìí ni a fi wé àìlẹ́mìí, bí àpẹẹrẹ: Ni ojú ìwé (18), Àjànà sọ pé:

Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà gẹ́gẹ́ bí i ọ̀rọ̀ ìwọ̀fà Àlàdé. Olówó rẹ̀ ní kí ó lọ mú iṣu wá lóko láti fi gúnyán. Ibi tí ó ti ń lọ ni ó rí orí gbígbẹ ní ilẹ̀, ó kí i pé ‘orí gbígbẹ ó kú ìkàlẹ̀ o. Ṣùgbọ́n orí dá a lóhùn pé ìwọfà Àlàdé ẹnu rẹ ni yóò pa ọ. Èyí ya ìwọ̀fà Àlàdé lẹ́nu ó bá sáré tọ ọba lọ pé òun rí orí gbígbẹ tó ń sọ̀rọ̀. Ó ní kí ọba tẹ̀lé òun láti lọ wò ó, àti pé bí kò bá sọ̀rọ̀ kí ọba ti ojú òun yọ idà kí ó sì ti ẹ̀yìn òun kì í bọ àkọ̀. Ọba tẹ̀lé e àti àwọn ìjòyè, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀ tí ó ké sí orí, orí ò dá ìwọ̀fà Àlàdé lóhùn. Báyìí ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ dá ẹjọ́ ara rẹ̀”.

ii.       Àfiwé tààrà: Èyi jẹ́ irúfẹ́ àfiwé kan tí nǹkan méjì tí a fẹ́ fi wé ara wọn bá wà ní fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Bí àpẹẹrẹ ojú ìwé (43) nígbà tí Àlàó ń sọ̀rọ̀;

Ohun tí ó sẹlẹ̀ lónìí, ìjà ìgbín pẹ̀lú òkòtó ni, itọ́ ni wọ́n máa fi ń nu ara wọn lára.

(3)     Ọfọ̀: a máa ń lo ọfọ̀ fún oríṣìíríṣìí nǹkan ní ilẹ̀ Yorùbá. Ọfọ̀ rere wà, ọfọ̀ búburú náà wà. Bí àpẹẹrẹ: ní ojú ìwé (45) nígbà tí Baálẹ̀ ń sọ̀rọ̀, ó ní

Pẹ́pẹ́yẹ ń lérí lásán ni

Kò leè kọ

Àlàpà lanu lásán ni

Kò leè fọhùn

Orí àléénú lakọ aláǹgbá ń lé

A kì í rídìí òkun

A kì í rídìí ọ̀ṣà

A kì í rídìí ọmọ oní-gèlègélé.

Ojú ìwé (46-47), nígbà tí Ọbákọ̀ọ́ fẹ́ mu omi: 

Ìbà omi,

Omi t’íná mu tó kú

Òun náà lènìyàn mu là

Ọpẹ́lọpẹ́ omi

Bí pẹ́pẹ́yẹ bá mi òkúta

Omi ni ó fi yà.

(4)     Àwàdà: Àwàdà jẹ́ ọ̀nà kan tí a máa ń lò láti fi pa ara wa lẹ́rìn-ín. Bí àpẹẹrẹ: ojú ìwé (8) nígbà tí Ọ̀gáàlú ń sọ̀rọ̀, ó ní:

“Ní gbogbo ibi tí a bá ti ń joyè, ìbáà ṣe ọba Aládé tàbí Baálẹ̀, oyè méjì ní ń bẹ níbẹ̀. Láàrin àwọn méjì tó ń dù ú, ẹnìkan yóò jẹ baálẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bíi tiyín yìí, ẹnìkan yóò jẹ oyè kejì tí í ṣe “Gbèsè”.

 

ÀṢÀ ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ ILẸ̀ YORÙBÁ NÍNÚ ÌWÉ ÈGBÌNRÌN Ọ̀TẸ̀

(1)   Oyè jíjẹ àti oyè dídù nílẹ̀ Yorùbá: Èyí tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin Oyèníran àti Adéoyè nígbà tí wọ́n fẹ́ jẹ Baálẹ̀ ìlú Ìdómògùn.

(2)   Ọjà alẹ́: Lẹ́yìn ọjà ojú mọmọ, ọjà alẹ́ jẹ́ ọ̀nà tí àwọn olólùfẹ́ méjì ti máa ń pàdé ara wọn. Oríṣìíríṣìí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ lóru lẹ́yìn ọjà alẹ́ ni ó ti máa ń ṣelẹ̀. Bí àpẹẹrẹ ojú ìwé (70). Ìpàdé àwọn gbajúmọ̀ ìlú máa ń wáyé lẹ́yìn ọjà alẹ́. Wọ́n ran Kànnìké kí ó lọ yẹ̀ ẹ́ wò, kí wọ́n tó ṣe ìpàdé wọn.

(3)   Orò: Orò jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tí àwọn Yorùbá máa ń fi ṣe ìwọ́de, ẹbọ rírú, ìkìlọ̀ àti fún ìjẹníyà. Bí àpẹẹrẹ, ojú ìwé (16) nígbà tí Adékúnlé parọ́ mọ́ àwọn olórò, àwọn ìlú pinnu láti fi orò jẹ ẹ́ niyà. A tún máa ń rí orin orò nígbà tí orò bá ń lọ lọ́wọ́.

O o o o o o rò o o o

Bàbá ò ò ò ò

Ooorò o o o

Bàbá ò ò ò

Héèpà orò

Orò yé è è

Ìyé é è ẹ ṣé e

Ẹ̀ ṣé é ire,

Ẹ ṣé é

Ẹ ṣé é è

Ẹ ṣé é ire o

Ẹyin ta ayé kàn

E ṣé é ire

(4)   Ifá dídá: Àwọn Yorùbá máa ń dá Ifá fún ìtọ́sọ́nà tàbi láti fi bèèrè fún òhun tí wọ́n bá ń fẹ́. A máa ń ní ẹsẹ̀ Ifá, oríkì Ifá, orin Ifá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ ojú ìwé (107)

Ògúndá méjì ní

Bí a bá wí fún ni

Gbígbà là á gbà

Bí a bá wí fún ni bá à gbọ́

Ó lóhun tíí ṣe fún ni

Ọ́ dá ti ẹ̀ fógunundábèdé

Ògúndá rẹrù rẹ̀ lákòrí

Ó rẹrù kongíro

(5)   Orin: Àwọn Yorùbá máa ń kọrin fún oríṣìíríṣìí nǹkan. Yálà nígbà ìbànújẹ́, ìgbà ìdùnnù, ìgbà ọ̀fọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ Ojú ìwé 150:

Oyèníran ó kú ewu o

Ewu ináá kì í pààwòdì

Àwòdì o kú ewu

Eewu ináá kì í pàwòdì

Ọ̀túnba ẹ kú ewu o

Ewu ináá kìí pàwòdì

Àwòdì o kú ewu

Ìdómògùn ẹ kú ewu o

Ewu ináá kì í pàwòdì

Àwòdì o kú ewu

Ewu iná kì í pàwòdì.

(6)   Oríkì: A máa ń ki oríkì ènìyàn, ẹranko, oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ ojú ìwé (91)

Ọba ò ò

Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú

Rí ń m’igbó kìjikìji

Ẹkùn ọkọ Yéwándé

Ògbójú àdàbà tí ń jẹ láàrin àṣá

À n lé e lẹ́yìn

Ó n lé ará iwájú

Afaláàníhan-ún-rà lọ ọjà

Ariwo ọjà lówá gbọ́

Ìwé Ìtókasí

Olatunji, Babatunde (1978), Egbìnrìn Ọ̀tẹ̀. Ibadan: Les Shraden (Nig.) Ltd.



[1] Kilani Rasheedat ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment