Ṣàdéhùn, to make an agreement[1]
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sàdéhùn pé àwọn yóò
pàdé ní ago mẹ́rin fún ìpàdé náà.
The students made an agreement to
meet by 4pm for the meeting
Ṣàfarawé, to imitate
Bísí sàfarawé Dúpẹ́
Bísí imitated Dúpẹ́
Ṣagbáfẹ́, to look stylish
Ìyàbọ̀
ṣagbáfẹ́ ju Bọ́ṣẹ̀ lọ
Ìyàbọ̀
looks stylish than Bọ́sẹ̀
Ṣàfẹnusí, to have a voice in a
matter
Ọkùnrin
ọlọ́rọ̀ náà sàfẹnusí sí ọ̀rọ̀ tí wón ń sọ nínú ìpàdé náà.
The
rich man had a voice in the matter that was discussed at the meeting
Ṣàfẹ́rí, to be longing for
Adé
ń sàfẹ́rí ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀
Adé
is longing for his fiancée
Ṣàkíyèsí, to take notice of
Mo
sàkíyèsí pé ọmọ mi kò jẹun látàná.
I
noticed that my child has not eaten since yesterday
Ṣàfojúdi, to be impertinent to
Akẹ́kọ̀ọ́
náà sàfojúdi sí olùkọ́ rẹ̀
The
student was impertinent to his teacher
Ṣàfọwọ́rá, to steal
Kàbírá
ṣàfọwọ́rá owó olùkọ́ rẹ̀
Kàbírá
stole her teacher’s money
Ṣagbára, to put more effort
Ọkùnrin
onísòwó náà sagbára sí iṣẹ́ rẹ̀
The
business man put more efforts into his work
Ṣagídí, to behave stubbornly
Kúnlé
ń sagídí sí ẹ̀gbọ́n rẹ̀
Kúnlé
is behaving stubbornly to his brother.
Ṣàgunlá, not to care about
Ọkọ
Yetunde sàgunlá[2] sí i
Yetunde’s
husband did not care about her.
Ṣàgbà, to be older than
Bọ́lá
sàgbà mi
Bọ́lá
is older than me
Ṣàgbàfọ̀, to be a washer man
Bàbá
Túndé ń sàgbàfọ̀
Túnde’s
father is a washer man
Ṣàgbàgún, to pound something as job
Kọ́lá
ń sàgbàgún iyán ní ọjá.
Kọ́lá
is pounding yams as a job in the market.
Ṣàgbàkà, tó be engaged in counting
cowries as a job
Bọ́láńlé
ń sàgbàkà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ
Bọ́láńlé
is engaged in counting cowries for a living.
Ṣàgbákò, to come across as
misfortune or as unfortunate circumstance
Kíké
sàgbákò nídìí okòwò rẹ̀
Kíkẹ́ experienced misfortune in her
business.
No comments:
Post a Comment