Tuesday, 12 June 2018

Kẹ́ṣinlóró



Ìsọnísókí ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́ṣinlóró

Láti ìgbà tí àwọn ará abúlé Ìnájà tí gbọ́ ọjọ́ ìdájọ́ àwọn adigunjalè tó wáyé ni ìlú Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀ ni wọ́n ti ń fojú sọ́ ikú àwọn ìgárá ọlọ́sà náà. Àwọn adigunjalè náà ti fi ojú àwọn ará ìlú Èjìgbà-ìlẹ̀kẹ̀ àti àwọn ìlú tó yí i ka rí màbo; bí wọ́n tí ń jà wọ́n lólè dúkìá ni wọ́n ń gba ẹ̀mí wọn nítorí ìdí èyí, ayọ̀ wọn kún nígbà tí ọwọ́ pálábá àwọn olè náà ṣegi.

Nínú àlá Àrẹ̀mú ni ó ti bá ara rẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́sà tí wọ́n fẹ́ fẹ̀yìn wọn tàgbá, bí sọ́jà tí na ìbọn sí i lójú àlá ni ó tají sójú ayé tí ẹ̀rù sí bà á gidi gan-an pé kí ni òun ń ṣe láàrin àwọn adigunjalè tí wọ́n ń da ìlú láàmú tí àwọn sọ́jà sì fẹ́ yìnbọn fún. Ìgbà tó yá, ó gbé ọkàn kúrò níbẹ̀, ó sì gbà pé àlá gọ̀.

Inú Arẹ̀mú dùn gan-an láàrọ̀ ọjọ́ kan tí ó jí tí ó sì gbọ́ pé àwọn ológun ti gbé ìjọba padà fún àwọn alágbádá tí wọ́n gba ìjọba lọ́wọ́ wọn nítorí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà àìṣòótọ́ pẹ̀lú ayé fàmí-létè-n-tutọ́ tí àwọn alágbádá ń jẹ kí wọn tó gbàjọba lọ́wọ́ wọn. Ìdí tí inú Àrẹ̀mú fi dùn ni pé bàbá rẹ̀, Adéoyè, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣèlú láyé ìjọba alágbádá kó tó di pé wọn gba ìjọba lọ́wọ́ wọn. Adéoyè jẹ́ olókìkí láàrin ìlú, ó rí tajé ṣe nídìí òṣèlú, bí ó sì ti ń kọjá lọ ni àwọn ènìyàn á máa sà á nítorí gbajúmọ̀ tí ó jẹ́ láàrin ìlú àti nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà; bí wọ́n bá sì ti ń sà á báyìí ni òun náà yóò máa fọ́n owó fún wọn láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì rẹ̀. Ìdí abájọ tí Adéoyè fi ń fọ́n owó fún àwọn ènìyàn ni láti fà wọ́n lójú mọ́ra kí wọ́n le dìbò fún ẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ìbò tó ń bọ̀.

Bí àwọn ènìyàn ti rí owó ni wọ́n ti yí ìpinnu wọn padà láti dìbò fún ẹgbẹ́ Adéoyè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Adéoyè jẹ́ ẹgbẹ́ aláìṣóótọ́ àti kìkì ọ̀jẹ̀lú síbẹ̀, nígbà tí àwọn ènìyàn rí owó, wọ́n pinnu láti dìbò fún un. Gbogbo ohun tí àwọn ẹgbẹ́ oníkòkó, igbákejì ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja, èyí tí i ṣe ẹgbẹ́ Adéoyè ń bá àwọn ènìyàn ìlú sọ láti máà dìbò fún àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja, pàbó ló já sí nítorí Adéoyè ti fi owó dí wọn lẹ́nu. Bí àwọn ẹgbẹ́ oníkòkó ti rí i pé ẹ̀yìn ìgbá ni àwọn ń yín àgbàdo sí lọ́dọ̀ àwọn ará ìlú Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀, wọ́n fẹnu kò láti yẹjù Adéoyè sẹ́yìn kí àwọn ará ìlú le bàa dìbò fún ẹgbẹ́ wọn. Àwọn ẹgbẹ́ oníkòkó dáná sun ilé Adéoyè àwọn ọmọ rẹ̀ méjì sì jóná mọ́lé; bí òun náà ti ń jáde, ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ oníkòkó ló bọ́  wọ́n sì sun ún níná. Àrẹ̀mú àti ìyá rẹ̀ nìkan ló jáde láàyè kúrò nínú ilé tó ń jó, àwọn méjéèjì nìkan ló sì wà láàyè nínú ẹbí Adéoyè. Bí àwọn ẹgbẹ́ oníkòkó ti ṣe rẹ́yìn ọ̀tá wọn nìyí.

Lẹ́yìn ikú ọkọ Adétóún, ìyá Àrẹ̀mú, Adébáyọ̀, àbúrò bàbá Àrẹ̀mú, fẹ́ sú ìyá Àrẹ̀mú lópó ṣùgbọ́n ìyá Àrẹ̀mú kọ̀ jálẹ̀ nítorí pé ọ̀lẹ alápá-má-ṣiṣẹ́ ni Adébáyọ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, o ń fa ojú Agúnbíadé mọ́ra. Àgbẹ̀ ọlọ́kọ́ ńlá ni Agúnbíadé. Láàrin ọdún mẹ́fà tí Adétóún àti Agúnbíadé ti ń ṣe wọlé-wọ̀de bòńkẹ́lẹ́, wọ́n bí ọmọkùnrin méjì fúnra wọn ni Abúbíadé bá kúkú gbà láti gbọ́ bùkátà Adétóún, ó rán Àrẹ̀mú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ onípòkejì, ó tọ́ ọ títí tó fi jáde tí ó sì fi ń siṣẹ́ nílé-ẹ̀kọ́ Pétérù Mímọ́ tó wà ní abúlé Ajébándélé tí ó sì máa ń wa sí abúlé Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀, a sì máa padà ni òwúrọ̀ ọjọ́ ajé sí abúlé tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ olùkọ́.

Ìwé tí Àrẹ̀mú kà sọ ọ́ di ẹni-iyì láwùjọ àti láàrin ẹgbẹ́ rẹ̀. Bí ó ti bí Àjàgbé tí ọmọ rẹ̀ ọ̀ún sì pé ọmọ ọdún mẹ́fà ni ó ti fi i sí ilé-ẹ̀kọ́ ní ìlú wọn.

Ikú gbígbóná tí bàbá Àrẹ̀mú kú nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú kò kọ́ Àrẹ̀mú lọ́gbọ́n, bí wọ́n ti fi ipò kan lọ̀ ọ́ nínú ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja ló ti fi tayọ̀tayọ̀ gbà á. Kìkì aláìsòótọ́ àti ọ̀jẹ̀lú ni ó kún inú àwọn òṣèlú ní Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀. Osùọlálé Àmọ̀rí ni ó ń lọ fún ipò Ààrẹ, ó sì tí ń náwó bí ẹlẹ́dà. Pẹ̀lú gbogbo ìkìlọ̀ tí ìyàwó Àrẹ̀mú ṣe fún un nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú tí ó ń bá kiri, etí ikún ni Àrẹ̀mú kọ sí í. Ìgbà tó yá, wọ́n fi Àrẹ̀mú jẹ baba ìsàlẹ̀ fún ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja torí ẹnu rẹ̀ tó dùn láti yí ọkàn àwọn ènìyàn lọ́kàn padà àti nítorí ọgbọ́n orí Àrẹ̀mú, wọ́n tún ṣèlérí fún un pé bí ẹgbẹ́ àwọn bá fi le wọlé, àwọn yóò fi i jẹ mínísítà epo rọ̀bì. Inú òṣèlú síṣe ni ó ti ṣálàbápàdé ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kilará tí ó sì ṣetán láti fẹ́ ọmọbìnrin náà láìbìkítà ohun tí ìyàwó rẹ̀, Fúnmilọ́lá, máa ṣe. Ọjọ́ tí Àrẹ̀mú gbe Kilará wọlé ní Fúnmilọ́lá, ìyàwó tó bá Àrẹ̀mú jìyà, jáde kúrò nílé pẹ̀lú ìbínú tí ó sì gbọ̀nà Ifẹ̀ lọ; ibẹ̀ ni ó ti ṣàgbákò ikú níbi tí ó ti fẹ́ fònà ní títì márosẹ̀. Àrẹ̀mú parọ́ fún àwọn ènìyàn pé Iléṣà ló ń lọ tí ó fi sàgbákò ikú.

Lẹ́yìn ikú Fúnmilọ́lá, ìyá Àjàgbé, ni Àrẹ̀mú rí àyè mú ìyàwó tó rí níbi òṣèlú, Kilará, wọlé tí ìyẹn sì fi òdì ayé hàn ọmọ rẹ̀ Àjàgbé ṣùgbọ́n torí ìfẹ́ tó ti ru bo Àrẹ̀mú lójú, kì í jẹ́ kí o le sọ̀rọ̀ nígbà tí Kilará bá ń fi ayé ni ọmọ rẹ̀ lára. Kilará bímọ fún Àrẹ̀mú bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ni. Kilará gbìyànjú à tí pa Àjàgbé nígbà tí ó rí i pé ọpọlọ Àjàgbé jí sí ìwé tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi gbé igba orókè láàrin gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ yòókù tí ìjọba si fi òǹtẹ̀ lù ú pé kí ó lọ kọ́ ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ìṣègùn Òyìnbó láti di dókítà lẹ́yìn náà. Gbogbo èròǹgbà Kilará láti pa Àjàgbé, ọmọ ọkọ rẹ̀, pàbó ló já sí nítorí ìdí èyí, ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé òun kò fẹ́ bá Àjàgbé gbé inú ilé pé Àlùfáà kan rína sí òun pe Àjàgbé ló máa pa òun, Àrẹ̀mú kọ́kọ́ kọ̀ jálẹ̀ ṣùgbọ́n Kilará padà lo ọgbọ́n àrékérekè láti jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ le Àjàgbé kúrò nílé.

Àjàgbé gba ọ̀dọ̀ bàbá ìyà rẹ̀ lọ ni Ìnísà; bàbá yìí nìkan ló dá wà lẹ́yìn ti ikú ìyá Àjàgbé, ọmọ rẹ̀, ti ṣe òkùnfà ikú ìyàwó rẹ, Morádéyọ̀. Ìgbà tí Ajéìígbé ri ọmọ-ọmọ rẹ̀, Àjàgbé, ó bi í lèrè ohun tó sẹlẹ̀, onítọ̀hún náà sì kẹ́jọ́, o rò fún un, lẹ́yìn náà ni ó ránsẹ́ sí bàbá Àjàgbé pé kó fojú kàn òun, ṣùgbọ́n Àrẹ̀mú kò fi ìgbà kan ṣebí ẹni pé òun gbọ́. Ajéìígbé gbéra láti lọ bèèrè ohun tó sẹlẹ̀ nígbà tí kò rí eègùn tó ń jẹ Àrẹ̀mú ṣùgbọ́n Àrẹ̀mú fara pamọ́ fún un. Ó sì sọ pé kí ìyàwó òun sọ pé òun kò sí nílé, ó sì ránṣẹ́ sílẹ̀ fún Àrẹ̀mú pé kí ó fojú kan òun bí ó bá dé.

Ìgbà tí ó ku ọ̀sẹ̀ kan tí àwọn túlẹ̀ yóò wọlé ni ilé-ẹ̀kọ́ Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni Àrẹ̀mú ti sọ fún bàbá ìyá rẹ̀ ti Ajéìígbé sì sọ fún un pé kí ó lọ bá bàbá rẹ̀ láti lọ rèé gba owó lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ohun tó bá níbẹ̀, lílé ni bàbá rẹ̀ lé e jáde nígbà ti ó sọ fún un, pẹ̀lú ẹkún ni ó sì fi padà sílé lọ́dọ̀ Ajéìígbé. Ajéìígbé gbìyànjú láti rán Àrẹ̀mú lọ sílé-ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n kò sí owó ní ó bá gba ọ̀dọ̀ Mopélọ́lá aláṣọ lọ, Mopélọ́lá òún ló wá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Yàkúbù Agbégéńdé tí ó lówó ṣùgbọ́n tí kò yọ lára rẹ̀, ó wá ń ṣe ẹrú owó. Yàkúbù gbà láti yá a ní owó, wọ́n sì jọ ni àdéhùn pé bí Àjàgbé bá ti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún méje ni òun yóò wá sanwó rẹ̀ fún un, Mopélọ́lá sì bá a ṣe onídùró tí ó fi ya ọgọ́rùn-ún lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ́wọ́ Agbégéńdé tí ó sì kó o lé Àjàgbé lọ́wọ́ láti fi lọ sílé-ẹ̀kọ́.

Lẹ́yìn tí ìdìbò wáyé ní ìlú Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́ja ló gbégbá orókè bí ó tilẹ jẹ́ pé kìkì òjóóró ni wọ́n ṣe síbẹ̀, wọ́n gbégbá orókè. Wọ́n sọ ẹni to gbégbá orókè ní ipò Ààrẹ, ẹni tó gbégbá orókè ní ipò Gómìnà. Àrẹ̀mú tí ń retì orúkọ rẹ̀ lára àwọn Mínísítà nítorí ohun tó gbé ọkàn lé tó fi lọ kọ iṣẹ́ olùkọ́ sílẹ̀ tí ó sì kọ́ ilé-ìtura. Gbogbo owó tó ní ni ó fi ra ọjà sílé ìtura náà nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ gbé igbá orókè ni ó fi fi gbogbo ọtí àti gbogbo ohun tó rà síbẹ̀ ṣàjọyọ̀ fáwọn alábásìkẹ́ ní ìrètí pé bí òun bá dé ipò Mínísítà tán, òun yóò rí owó gọbọi láti ra òmíràn dí i ṣùgbọ́n ìrètí rẹ̀ forí sánpọ́n nígbà tí wọ́n pé orúkọ àwọn mínísítà tí orúkọ rẹ̀ kò sí níbẹ̀. Àrẹ̀mú múra, ó gba ilé ọ̀gá wọn nínú ẹgbẹ́ lọ pé kó wo òun ṣe láàánú ṣùgbọ́n kàkà tí Gbádégẹsin yóò fi ràn án lọ́wọ́, ariwo olè lo pa lé e lórí. Ibẹ̀ ni Àrẹ̀mú sì gbà dé àgọ́ ọlọ́pàá. Kilará lu gbogbo nǹkan ìní Àrẹ̀mú tà ó sì sá lọ ráúráú sí Ìbàdàn. Àrẹ̀mú kábámọ̀ pé òun ò bá ti máà ṣe é.

Lẹ́yìn tí Àrẹ̀mú parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó wáṣẹ́-wáṣẹ́, kò ríṣẹ́; gbogbo ibi tí ó kọ lẹ́tà sí ni wọ́n ti ń sọ pé à fi ti ó bá mọ ènìyàn kan tí ó jẹ́ olóṣèlú tàbí kí ó mówó wá. Ó gbìyànjú títí ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Ìgbà tí Yàkúbù Agbégéńde ti retí owó tí Ajéìígbé wá yá fún ilé-ẹ̀kọ́ lílọ ọmọ-ọmọ rẹ̀ tí kò ti rí i ní ó wá kó àwọn jàǹdùkù ká a mọ́lé tí wọn sì lu Ajeìígbé bí ẹni lu bààrà; ibẹ̀ ni ó sí gbà kú. Ọ̀rọ̀ náà dun Àjàgbé dé ọkàn ṣùgbọ́n ó padà gba kámú.

Ní ọjọ́ tí bàbá Àrẹ̀mú àgbà kú ni ó gba Èkó lọ, ibẹ̀ ni ó sì ti dara pọ̀ mọ́ àwọn olè tí wọ́n jọ ń fọ́lé kiri nílùú Èkó. Àlàájì Bélò tí wọ́n pa ni ó sọ wọn di èrò abúlé padà nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì níí wá wọn. Àjàgbé ṣe òkú ìyá rẹ̀. Ìgbà tó dé abúlé wọn ni Èjìgbàrà-Ìlẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn èyí ni ó pàdé Kẹ́mi tí ó ti kọ ẹnu ìfẹ́ sí nígbà tó wà ní ilé-ẹ̀kọ́. Àjàgbé kò kọ́kọ́ mọ̀ pé Kẹ́mi ni asẹ́wó ti òún ba ni àjọṣepọ̀, àfi ìgbà tí wọ́n wo ara wọn fín dáadáa. Àrẹ̀mú sọ irú iṣẹ́ ti òun ń ṣe fún Kẹ́mi àti ìdí abájọ tí òun fi n ṣe e; Kẹ́mi náà sọ irú ìṣòro tó n dojú kọ òun náà. Àrẹ̀mú fún Kẹ́mi lówó tó jọjú, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kí ó máa ṣe tú àsírí òun síta. Lẹ́yìn tí Àrẹ̀mú ti ṣe òkú ìyá rẹ̀ tán tí ayé gbọ́ tí ọ̀run mọ̀ ni Ààrẹ náà fẹ́ ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀. Níbi ọjọ́ ibi rẹ̀ ni inú ti bí Àrẹ̀mú àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí orúkọ wọn ń jẹ́ Jìgan, Kọ́bùrù àti Sájẹ́ǹtì tí wọ́n sì ṣekú pa mínísítà Ètò Ìsúná-owó. Nítorí pé kò sí ẹni tí Àjàgbé kò le bù sán ni àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe ń pè é ní ejò.

Ikú Gbádégẹṣin mínísítà ètò ìsúná-owó ló ṣe òkùnfà òun tí wọn fi rí Jìgan, Sájẹ̀ntì àti Kọ́bùrù, Kẹ́mi ni ó lọ ṣe òfófó wọn tí wọ́n fi rí wọn kó. Ìdí tí wọn kò fi rí Àjàgbé kó mọ́ wọn ni pé ó gbé àfẹ́sọ́nà rẹ̀ lọ sílé; ìgbà tí ó ń padà bọ̀ ni ó ń gbúró ìbọn tí ó sì sálọ sí Màdúgùrí. Màdúgùri ni ó ti gba Jésù sáyé rẹ̀ tí ó sì di oníwàásù. Ibi tí ó ti n wàásù kiri ni ó ti ri bàbá rẹ̀ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìgbà tí bàbá rẹ̀ sì mọ̀ pé ọmọ òun ni, ó dákú lọ gbọn-ran-gan-dan. Ibẹ̀ ni ó sì gbà jáde láyé.

Àjàgbé padà lọ sí ìlú Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀. Ó bọ́ sí àsìkò tí wọn máa pa àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Ó wà níbẹ̀ láàfin; àwọn èrò tó ń wòran olè tí wọ́n fẹ̀yìn wọn tàgbá láti yìnbọn fún, lẹ́yìn tí wọn pa wọ́n tán, Àjàgbé sun ẹkú kíkorò. Ààrin èrò yìí ni ó ti mọ̀ pé Kẹ́mi ni ó ṣe òfófó àwọn. Kẹ́mi padà gbé oògùn jẹ, ó sì kú. Ẹgbẹ́ oníkòkó ni Àjàgbé dara pọ̀ mọ́, wọ́n sì yàn án gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò díje fún ipò ààrẹ. Orí pèpéle tí ó tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ni wọ́n ti yìnbọn fún un tí ó sì kú.

 

Ìlò-èdè nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́ṣinlóró

Òwe

Òwe lẹsìn ọ̀rọ̀, bí ọ̀rọ̀ bá sọnù òwe là á fi í wá a. Òwe jẹ òhun tí à ń lò láti sún ọ̀rọ̀ kì, pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ àti láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀.

Nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́ṣinlóró, oríṣiríṣi òwe ni òǹkọ̀wé lò nínú ìwé náà. Díẹ̀ nínú àwọn òwe tí òǹkọ̀wé lò níwọ̀nyí:

1.     Ọ̀rọ̀ tówó bá ṣe tì, ilẹ̀ ló ń gbé. (ojú iwé 5)

2.     Bí iná bá ń jó ní tó tún ń jó ọmọ ẹni, ti ara ẹni ni a kọ́kọ́ ń gbọ̀n dànù (ojú ìwé 6)

3.     Bẹ́yẹ ṣe ń lọ là á sọ̀kò rẹ̀ (ojú-ìwé 8)

4.     Ìdọ̀bálẹ̀ kìí ṣe ìwà ohun tá ó jẹ́ là ń wá (ojú ìwé 11)

 

Ọnà-èdè

Ọnà-èdè ni àwọn èrojà bi ọ̀rọ̀, àpólà tàbí gbólóhùn tí òǹkọ̀wé alátinúdá ń ṣàmúlò láti mú èdè iṣẹ́ wọn dùn. Òǹkọ̀wé máa ń lo ọnà-èdè láti mu ẹwà-èdè wọnù iṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀. Wọn a tún máa lo ọnà-èdè nínú lítíréṣọ̀ láti mú ìtumọ̀ kíkún ba iṣẹ́-ọnà náà lọ́nà tí òǹkàwé yóò fi ní òye, ọgbọ́n àti ìmọ̀ nípa irúfẹ́ iṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀ náà.

Wàyí o, oríṣiríṣi ọnà-èdè ni a le rí nínú ltiiresọ Yorùbá, àwọn bíi: àfiwé tààrà àti ẹlẹ́lọ̀ọ́, ìbéèrè-pèsìjẹ, ẹ̀dà-ọ̀rọ̀, àwítúnwí, ìfohunpènìyàn, gbólóhùn adọ́gba, àsọrégèé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 A ki í lo ọnà-èdè lásán, kókó ọ̀rọ̀ ni a máa ń lò ó fún láti fi ṣe àwàgúnlẹ̀ rẹ̀. Àwọn oríṣiríṣi ọnà-èdè tó jẹ yọ nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́sinlóró nì ìwọ̀nyí:

Àfiwé tààrà: Òun ni àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì ń pè ní “simile”. Èyí ni fífi nǹkan méjì wéra; àwọn ọ̀rọ̀ atọ́ka tí a fi ń dá wọn mọ̀ ni: dàbí, bí, jọ tó. Àwọn àfiwé tààrà nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́sinlóró nì ìwọ̀nyí:

·        Ilé àbẹ̀rẹ̀wọ̀ ilé èkúté (ojú ìwé 6)

·        Osùọlálé Àmọ̀rí tún ti ń náwó ẹlẹ́dà (ojú ìwé 9)

·        Ó wá ń pòsé sùùrù ìgbín tí ó tẹnu bọyọ̀ (ojú ìwé 11)

·        Pẹ̀pẹ̀ ni Àrẹ̀mú ń gbọ̀n kẹ̀kẹ́ alùpùpù tí ọwọ́ Òyìnbó ti kúró lára rẹ̀ (ojú ìwé 25)

·        Ọmọge mìíràn bóra ròbòtò; wọn dàbí ẹja edé (Ojú-ìwé 72)

Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́: Eléyìí ni “metaphor” ni èdè Gẹ̀ẹ́sì. A ń lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ nígbà tí a bá ti gbé àbùdá nǹkan wọ nǹkan mìíràn láìlo atọ́ka àfiwé. Ó gbà àròjinlẹ̀ ju ti àfiwé tààrà lọ.

Àpẹẹrẹ àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́sinlóró ni ìwọ̀nyí:

·        Wọ́n fẹnu kò pé kí wọ́n yẹjú Adéoyè nítorí pé òun ni igi wọ́rọ́kọ́ tó ń da iná rú (ojú-ìwé 5)

·        Ó jẹ́ alóyinlétè tí ó mọ bí a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní ọ̀nà tí yóò fi yí ènìyàn lọ́kàn padà (ojú-ìwé 10)

·        Orí Àjàgbé pé púpọ̀, kò sí ìyàtọ̀ láàrin òun àti alájọ ómólú (ojú-ìwé 28)

Ìbéèrè-pèsìjẹ: èyí ni ìbéèrè tí a béèrè láti mú èdè rẹwà ninú lítíréṣọ̀. Òǹkọ̀wé máa ń dìídì lò ó nínú lítíréṣọ̀ láìsí pé ó nílò ìdáhùn.

Àpẹẹrẹ ìbéèrè-pèsìjẹ tí a rí fàyọ nínú ìwé ìtàn àròsọ ni ìwọ̀nyí:

·        Haa! Irú kí lèyí? (ojú-ìwé 2)

·        Irú ẹ̀gbin wo lèyí? (ojú-ìwé 20

·        Ṣé kìí ṣe pé orí ẹ dàrú? (ojú-ìwé 55)

 

Àsọrégèé: Nígbà tí òǹkọ̀wé alátinúdá bá ṣe àbùmọ́ tàbí àsọdùn ìṣẹ̀lè tàbí ohun kan kọja bí ó ṣe yẹ. A máa ń ṣe àmúlò ọnà-èdè yí láti ṣàpèjúwe bí nǹkan ti mú ni lọ́kàn tó.

Àfàyọ àsọrégèé nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹṣinlóró nìyí:

·        Ẹ̀bùn tí Bọ́láńlé gbà lọ́jọ́ náà ò lóǹkà. (ojú-ìwé 16) 

·        Ọkọ̀ tí ó wọ ìlú Èjìgbà-Ìlẹ̀kẹ̀ lọ́jọ́ náà kọ sísọ (ojú-ìwé 71).

·        Àìmoye màlúù ni wọ́n rógun ọ̀bẹ (ojú-ìwé 71).

·        Òtẹ́ẹ̀lì Ọbẹ̀làwọ̀ kò gbẹsẹ̀ mọ́ (ojú-ìwé 72)

Ifohunpènìyàn: Ọnà-èdè yìí ni kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí kò lẹ́mìí tàbí ẹranko bí i ènìyàn. Ìfohunpènìyàn nínú ìwé ìtàn àròsọ Kẹ́sinlóró ní ìwọ̀nyí:

·        Láti ọjọ́ tí ó ti ku oṣù kan gééré tí àwọn aráàlú yóò dìbò ni ilé Àrẹ̀mú ti ń gba àlejò lójoojúmọ́ (ojú-ìwé 16)

·        Ìgbà tí itọ́ kán sílẹ̀ tí eesin kan kìlọ̀ fún un ni ó tó rántí ara rẹ̀ (ojú-ìwé 53).

·        Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ tí òun àti àwọn ẹ̀fọn ti ń jà ni oorun gbé e lọ (ojú-ìwé 54).

Àwítúnwí : Ó ní í ṣe pẹ̀lú tí tún fóníìmù, sílébù, ọ̀rọ̀, àkùdé gbólóhùn tàbí odidi gbólóhùn sọ nínú iṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀ tàbí nínú afọ̀. Oríṣiríṣi àwítúnwí ló wà àwọn nì ìwọ̀nyí:

Àwítúnwí ẹyọ ọ̀rọ̀: èyí ni sísọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ní ẹ̀ẹ̀mejì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú gbólóhùn.

Àwítúnwí ẹyọ ọ̀rọ̀ nínú Kẹ́sinlóró nìwọ̀nyí:

·        Àrùn ojú ni, kì í ṣe àrùn inú (ojú-ìwé 56)

·        Ó ra fùfú méjì lọ́wọ́ obìnrin kan tí ó ń kiri fùfú (ojú-ìwé 53)

·        Wọ́n fọn fèrè foo foo foo (ojú-ìwé 43)

·        Ọ̀rọ̀ ń ṣe kámi kàmì-kámi (ojú-ìwé 25)

·        Bí ó bá bínu kó máa bínú (ojú-ìwé 21)

 

Àwítúnwí Alákùdé gbólóhùn: Eléyìí ni síṣe àtúnwí àpólà tàbí ìhun ìlà alákùdé. Àwítúnwí alákùdé gbólóhùn nì wọ̀nyí:

·        Wẹ́ẹ̀tì ẹ̀... wẹ́ẹ̀tì ẹ̀ (oú-ìwé 6)

·        Bí mo bá lówó ọ̀hún tán, bí mo bá fún ẹ kí o kọ̀ ọ́ sílẹ̀ (ojú-ìwé 13).

·        Bí ó ṣe ń ran aṣọ obìnrin ni ó ń ran aṣọ ọkùnrin (ojú-ìwé 14)

·        A kì í sọ̀lẹ, a kì í sọlẹ̀ tẹ́lẹ̀ (ojú-ìwé 84)

·        Ẹ ò fi ṣète pa, ẹ ò fi ṣèrò rò. (ojú-ìwé 84)

 

Gbólóhùn adọ́gba: Èyí ni ọnà-èdè tó wọ́pọ̀ nínú iṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀ tí òǹkọ̀wé lo akudé gbólóhùn tàbí gbólóhùn tó jọra ní ìhun àti ìtumọ̀ tó tẹ̀lé ara wọn lọ́nà tí wọn ki ara wọn délé.

Gbólóhùn adọ́gba nínú Kẹ́sinlóró nì wọ̀nyí:

·        Bọ́mọdé bá ń bínú, ẹ bi í, ká mohun tó ń bínú sí, Bágbà bá sìwàwù, ẹ bi i, ohun tó fa sábàbí ọ̀rọ̀. (ojú-ìwé 83)

·        Bàbá yáwó tọ́mọ kọ́mọ ó lè nílárí, ìyá gbàárù tọmọ kọ́mọ ó lè jéèyàn (ojú-ìwé 83)

·        Ẹ̀yin le jọ́mọ ó sòwò, ẹ̀yin lẹ ẹ̀ jọ́mọ ó kérè ọjà délé (ojú-ìwé 84)

·        Ìlú ò fara rọ nígbà tiyín Ayé ò rójú nígbà ẹ bàléfà (ojú-ìwé 84)

Ẹ̀dà ọ̀rọ̀: Èyí ni ìlò ọ̀rọ̀ tàbí àpólà láti fi rọ́pò ọ̀rọ̀ tí kò dùn-ún gbọ́ létí láti fi jẹ́ kó dùn-ún gbọ́. Ẹni tí kò bá gbọ́ èdè jinlẹ̀ kò le gbọ́ ọ tàbí kí ó kà á ní àkàyé.

Ẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú ìwé Kẹ́ṣinlóró nìwọ̀nyí:

·        Gbogbo àwọn èrò ọkọ̀ tí àwọn ọlọ́pàá dá dúró ni wọ́n bẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ tí wọn gba igi rìléè. (ojú-ìwé 66)

·        Àwọn ọlọ́pàá yòókù kò dúró wẹ̀yìn tí wọ́n fi júbà ehoro (ojú-ìwé 66)

·        Baba ọdẹ pa ojú dé, ó kí ayé pé ó dìgbòóṣe (ojú-ìwé 62)

Ìwé Ìtọ́kasí

Oladejo, Odebunmi (2010), Kẹ́ṣinlóró. Ibadan: Worldwide Press.

No comments:

Post a Comment