Saturday, 9 June 2018

Ọ̀RẸ́ Ò GBẸLẸ̀TA


Ìyántànfẹ́ẹ́rẹ[1]

Ìwé yìí  jẹ́ eré-oníṣe tó dá lé lóri àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mẹ́ta kan tó gbà kí ìlara àti owú jíjẹ mú kí ìyapa dé bá àjọṣepọ̀ wọn tó dán mọ́rán tẹ́lẹ̀. Ìlara mú Àlàmú àti Bùrẹ́mọ̀  dìtẹ̀ mọ́ ọ̀rẹ́ẹ wọn kẹta èyí tíí ṣe Àkàngbé, wọ́n sì ṣàkóbá fún un ṣùgbọ́n àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ náà kó o yọ. Àlàmú àti Bùrẹ́mọ̀ padà   jìn sí kòtò tí wọ́n gbẹ́ fun Àkàngbé.

Oríṣìí asọ̀tan: Aṣọ̀tàn Ọ̀rẹ́ ò gbẹlẹ̀ta jẹ́ afarasin-farahàn. Ìdí sì ni wí pé asọ̀tàn kò  kọ́kọ́ fara hàn nínu  ìtàn tí ó ń rọ́ ṣùgbọ́n nígbà tí eré parí tí gbogbo aáwọ̀ inú ìtàn náà di yíyanjú ló wá fara hàn wá. Asọ̀tàn afarasin-farahàn ló jẹ́ nítorí wí pé gbogbo ohun tó ń sẹlẹ̀ ló wà ní àrọ́wọ́tóo rẹ̀. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ìtan ló ń fi han àwa òǹkàwé. Nígbà mìíràn, ó tiẹ̀ ṣe é ti àwa òǹkàwé fi mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá ìtàn ṣaájú ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa ṣẹlẹ̀ sí i. Lẹ́yìn tí eré parí ni ẹ̀dá ìtàn kan wá bọ́ sóde ìyẹn “Akéwì”, àwọn ọ̀rọ̀ kànkà àti ìpèdè tó jọ mọ́ ti èèyàn tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ìtàn náà jẹ́ kó yé wa pé òun ni asọ̀tàn.

Akéwì: Tóò ẹ̀yin ènìyàn

             Ẹ rójú ayé tàbí ẹ ò rí i?

             Àwọn  èèyàn tó yẹ kí a fẹ̀yìn tì

              Ni wọ́n fara ṣẹ̀gún tán pátápátá......

Ìbáṣepọ̀ aṣọ̀tàn àti olùgbọ́tàn: Ìbáṣepọ̀ asọ̀tàn àti olùgbọ́tàn jẹ́ èyí tó yanrantí. Ìbáṣepọ̀ àárin wọn múná dóko. Ìbáṣepọ̀ àárín asọ̀tàn àti àwa olùgbọ́tàn múlẹ̀ dáadáa bó ti wulẹ̀ jẹ́ pé a ò kọ́kọ́ rí i. Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínu  eré ló ń fi hàn wá, kò sí ohun kan tó sókùnkùn sí wa. Asọ̀tàn rọ́ ìtàn náà lọ́nà tó jẹ́ pé a káàánú Àkàngbé tí a sì kórira àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ méjéèjì nítorí ìwà ìkà wọn. A tún lè sọ pé ìbásepọ̀ àárin asọ̀tàn àti olùgbọ́tan dán mọ́rán nítoríi gbogbo àwọn ète tí asọ̀tàn mú lò láti mú kí àwa olùgbọ́tàn ta kété sí ìtàn náà tí a sì tún kọ ìha tí ó ń fi ìtara wa sí ìtàn náà hàn.

Ìlò-ohùn: Ìlò ohùn jẹyọ nígbà púpọ̀ nínu ìwé yìí pàápàá jù lọ nítorí wí pé ìlànà eré-oníṣe ni wọ́n fi gbé ìtàn náà kalẹ̀. Gerard Gennette gbà pé àkíyèsí nípa ìṣọwọ́sọ̀tàn, ìlo ohùn, ìlo ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn dídùn máa ń jẹ́ kí ìtàn ti asọ̀tàn ń rọ́ ó yé àwa òǹgbọ́tàn dé àyè kan. Ohùn tí asọ̀tàn fi sẹ́nu àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ jẹ́ “active voice” nítorí wí pé ìlànà ọ̀rọ̀-ìṣe ni ìtànnà náà gbà wáyé. Láti ẹnu àwọn ẹ̀dá-ìtàn fúnra wọn, à ń rí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́. Àwọn ìpèdé tó ń jáde lẹ́nu wọn ran ìhà ti a  kọ sí ìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́.

Bùrẹ́mọ̀: Bóyá bí a bá tilẹ̀ ríbi dọwọ́ rẹ̀ délẹ̀, bùlanga-bùlanga rẹ̀ yóò dínkù díẹ̀.

                Ó yẹ kí a fi lé ayé lọ́wọ́.

Àlàmú:   Koóko tí erin bá ti tẹ̀ ko tiẹ̀ gbọ́dọ̀ gbérí mọ́. Ó yẹ ká bá a kalẹ̀ pátápátá

                ni: bí ẹnú rẹ̀ tilẹ̀ bọ́ sí i dáadáa ni. Màálù tó so ìpá ìdùnnú alápatà ni.

Bùrẹ́mọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni. Bó lè kú, kó kú Àkú-tún-kú rẹ̀. Ìgbà tí kò kú ńkọ́? Kín ni

               aǹfààní alákọríi rẹ̀?

Àlàmú:    Hẹn ẹn o. Ohun tí mo ti rò nípa rẹ̀ ni pé kí a wá ọ̀nà gbé ọmọbìnrin kan

                báyìí tí ó máa ń ra ọjà lọ́dọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́ un pamọ́, kí a wá lọ sọ fún ọba

                 pé ọ̀rẹ́ẹ wa ló gbé ọmọ náà tí ó fẹ́ fi ṣoògùn owó.

Látara ìpèdè àwọn ọ̀rẹ́ méjì yìí àti ohùn ìkà wọn, asọ̀tàn ti ṣàfihàn wọn gẹ́gẹ́ bíi ìkà èyí sì nípa lóri ìhà tí àwa òǹgbọ́tàn kọ sí wọn.

Àhunpọ̀ ìtàn: Àhunpọ̀ ìtàn níí ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí asọ̀tàn gbà hun ìtàn rẹ̀ tó fi mọ́pọlọ wá tí ìtumọ̀ rẹ̀ ò sì sọnù.

a.     Ṣíṣí ìṣẹ̀lẹ̀ láwẹ́láwẹ́: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú eré-oníṣe yìí wáyé tẹ̀lé ara wọn ni. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ló ń bí òmíràn. Nínu eré náà kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láìnídìí, gbogbo àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ló kó ipa pàtàkì nínu eré náà. Bí àpẹẹrẹ, ìtàn náà bẹ̀rẹ̀ níbi tí Àkángbé, Àlàmú àti Bùrẹ́mọ̀ ti ń ro, wọn wo ọ̀rọ wọn dáadáa wọ́n sì rí i pé ìyà tó ń jẹ àwọn ti pọ̀jù, wọ́n wòye pé kí àwọn lọ sí ìlú mìíràn láti lọ máa ṣe okòwò. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ babaláwo fún ìtọ́nà, babaláwo sọ fún wọn pé kí wọ́n rúbọ nítorí ìlara. Etí ikún tí wọ́n kọ sí ọ̀rọ Ifá, tí wọ́n kọ̀ láti rúbọ ló fa gbogbo ohun tó sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àtunbọ̀tán àìgbọnràn wọn.

b.     Ìbojúwẹ̀yin: Ìbojúwẹ̀yìn wáyé níbi tí Àdùnní àti Àdùkẹ́ ti lọ bá bàbá Fárọwọ́mọ nípa ọ̀rọ̀ Àkàngbé.

Fárọwọ́mọ: .....Ẹni tí ẹ toríi rẹ̀ wá yìí ti pe Ifá lékèé. Ọ̀rúnmìlà sọ pé kí ẹni

                   náà rúbọ kò rúbọ.....

Ohun tí bàbá Fárọwọ́mọ sọ níbí bàyìí mú wa rántí ìgbà tí Àkàngbé, Àlàmú àti Bùrẹ́mọ̀ kọ́kọ́ lọ sí ọ̀dọ bàbá Fábíyìí, tí ó ní kí wọ́n rúbọ tí wọ́n sì kọ̀.

c.      Ìmúráde: Ìmúráde ni ìtàn yòówù ó lè jẹ́ tí a bá ń sọ̀rọ̀ bá ìsẹ̀lẹ̀ tí yóò wáyé lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀gangan ipò tí ète ìmúráde ti wáyé ni ibi tí bàbá Fábíyìí ti ní kí wọ́n rúbọ torí ìlara tí wọ́n sì kọ̀, wọ́n kọtí ọ̀gbọyin sẹ́bọ, wọ́n pe Ifá lékèé, wọ́n pèṣù lólè. Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti rú ẹbọ ti mú ohun kan ráde pé wọ́n sì máa jẹ̀yà àìgbọ́nràn wọn nítorí wí pé rírú ẹbọ níí gbeni àìrú kìí gbènìyan. Kání wọ́n rúbọ ìlara ni, ìlara ò bá má fa ìyapa láàrin wọn. Àìrúbọ ọ̀ún ló fa gbogbo aáwọ̀ inú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ibì mìíràn tí ète ìmúráde ti wáye níbi tí Bùrẹ́mọ̀ àti Àlàmú ti ń ṣàlàyé nípa ọ̀nà táwọn fi máa kóbá Àkàngbé.

Ìtúpalẹ̀ ète ìṣẹ̀dá ìpohùn: Ète oríṣiiríṣii ni oǹkọ̀wé lò láti ṣàmúlò àwọn ìpohun tó kó ipa pàtàkì ní ọ̀gangan ipò tí òǹkọ̀wé ti ṣàmúlò wọn. Àwọn ìpohun bíi orin, ìyẹ̀rẹ́-ifá, Odù-ifá àti ewì ni ó ṣàmúlò jù. Ní ìran kìn-ín-ní, Àlàmú ń kọrin pé

iṣẹ́ alákọ̀wé ṣe débi à ń ṣàgbàro

Ọ̀rọ̀ mìíràn dé mo rí tísà tó ń ṣàgbàro....”

Orin yìí bí Àkàngbé nínú nítorí wí pé ọ̀rọ̀ inú orin náà ta bá a. Orin yìí tún ṣàfihàn Àlàmú gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ò náání ọ̀rẹ́.

Bàbá Fábíyìí ki ifá ní ìran kejì pé

“Ọ̀rẹ́ ò gbẹlẹ̀ta

Elèjì lọ̀rẹ́ gbà

Adíá fún ṣẹ̀kẹrẹ̀......”

Odù ifá yìí jẹ́ bíi ìyántànfẹ́ẹ́rẹ́ tó ń ṣe ìmúráde sí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú.

Akéwì bẹ̀rẹ̀ síí kéwì nígbà tí eré parí ní ìran kẹrìnlá. Ó ní

“...Àwọn ẹni tó yẹ kó fẹ́ni lójú

Ni wọ́n ń sáré fata sẹ́nu

Gbogbo ènìyàn

Ẹ fèyí kọ́gbọ́n

Ìwọ ìkà ènìyàn

Tó o tafà sókè tán

Tóo yídó borí......”

Akéwì náà kúrò ní agbo eré ó bẹ̀rẹ̀ síí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ èyí tí àwọn Òyìnbó ń pè ní “didactic elements”. Gbogbo àwọn ìpohun tí òǹkọ̀wé lò nínu ìwé yìí ló níṣẹ kan pàtó tí wọ́n jẹ́.

Ìwé Ìtọ́kasí

Adéṣígbìn, B. (2008). Ọ̀rẹ́ ò Gbẹlẹ̀ta. Ìbàdàn: Ayus Publications

Ọ̀pẹ́fèyítìmí, A. (2014). Tíọ́rì àti Ìṣọwọ́lo-èdè. Ilé-Ifẹ̀: Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University Press.



[1] Oyetunde Blessing Ifeoluwa ni o kọ bébà yìí.

1 comment:

  1. New slots for real money near me - JT Hub
    Play a variety of the popular online 화성 출장마사지 casino slots 경기도 출장샵 and slot machine, table 하남 출장안마 games, 울산광역 출장안마 and live 군포 출장안마 casino game. Visit JTM.com today to find out about the best slots!

    ReplyDelete