Saturday, 9 June 2018

EÉGÚN ALÁRÉ


 

Ìyántànfẹ́ẹ́rẹ́[1]

Ìwé yìí dá lórí eégún aláré kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀jẹ́làdé àti ìrìnkèrindò rẹ̀ láàrin àwọn ibi tí ó ti ń pidán tí ó sì ń ṣeré kiri. Ọ̀jélàdé kan àgbákò oríṣiiríṣi níbi tí ó ti ń pidán kiri sùgbọ́n ó borí gbogbo wọn. Ògúnníran kọ ìwé yìí láti gbé àwọn lítírésọ̀ alohùn Yorùbá ga àti láti tàbùkù àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí ó wà láwùjọ, ó sì tún fi ìwé rẹ̀ yìí kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa fífi àwọn ọ̀rọ̀ ò jọ bíi ọ̀rọ̀ ìṣítí-ò-jọ̀kan sẹ́nu àwọn ẹ̀dá ìtàn.

Ìrírí Olùwádìí: Eégún ṣe pàtàkì ńlẹ̀ Yorùbá. Àwọn ìdìlé Ọ̀jẹ̀ ló máa ń gbé eégún. Ohun tí àwọn elégún máa ń wọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ọdún tàbí tí wọ́ bá ń pidán là ń pè ní ẹ̀kú tàbí àgọ́. Kìí ṣe gbogbo àwọn abílọ́jẹ̀ ló máa ń gbé eégún. Eégún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣà ajẹmẹ́sìn nílẹ̀ Yorùbá; eégún ṣíṣe yìí sì jẹ́ ẹ̀sìn fún àwọn Ọ̀jẹ̀. Oríṣiiríṣii eégún ló wà, bí àpẹẹrẹ, eégún aládòko,eégún òkìtì, eégún Ṣakí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn abílọ́jẹẹ̀ tí ó mú ẹ̀sìn eégún bí iṣẹ́ tí wọ́n sì ń pidán káàkiri là ń pè ní eégún aláré. Àwọn Ọ̀jẹ̀ máa ń jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye pàápàá gbà tí wọ́n bá gbé ẹ̀kú wọ̀ tí ará ọ̀run sì bẹ̀rẹ̀ síí ń gùn wọ́n, àwọn ẹ̀dọ̀kì-ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kàǹkà ló ma máa ń ti ẹnu  wọn jádé. Iyì púpọ̀ ló wà fún àwọn Eégún aláré niídìí pipidán kiri yàtọ̀ sí pé ó máa ń sọ èyí tí ó bá dáńtọ́ láàrin wọn di ìlú mọ̀ọ́ká, á sì tún máa ń rí ẹ̀bùn púpọ̀ gbà lọ́wọ àwọn òǹwòràn tí oríi wọn wú. Oríi òǹwòrán mìíràn le wú débi kí ó ṣe oore ńlá bàǹtàbanta fún eégún aláré, àpẹẹrẹ nínu ìwé yìí ni ibi tí ọba ti fi ọmọ rẹ̀ ta Ọ̀jẹ́làdé lọ́rẹ nítorí wí pé ó gbádùn idán náà gidi gan-an.

Ìlò-èdè: Ìlò-èdè jẹ mọ́ sítáì àti ọ̀nà àrọ́ǹdà tí àwọn oníṣẹ́ ọnà fi lo èdè tàbí tí wọ́n fi gbé èdè jáde. Bí lámèyítọ́ kan bá gbá iṣẹ́ ọnà lítírésọ̀ mú, àwọn èròjà tó kún fọ́fọ́ tó sì fi òǹkọ̀wé hàn gẹ́gẹ́ bíi aláronúdá tí lámèyítọ́ rí fàyọ gan-an ló ń jẹ́ ìlò-èdè. Ìmọ̀ ìṣọwọ́lo-èdè máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ ọnà lítírésọ̀ yéni délẹ̀. Ìlò-èdè ń jẹ́ kí ìwúrí wà fún iṣẹ́-ọnà. Ẹ̀yà lítírésọ̀ kọ̀ọ̀kan ló ní ìlò-èdè. Inú ìlò-èdè ni a ti máa ń fa ọnà-èdè yọ. Ìlò-èdè tó jẹyọ jù nínu ìwé yìí ni ẹ̀sà/iwì egúngún nítorí wí pé Láwuyì Ogúnníran lo ìwé yìí láti pa ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ya lítírésọ̀ alohùn Yorùbá mọ́. Ẹ̀sà tàbí iwì egúngún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì láàrin àwọn lítírésọ̀ alohùn Yorùbá. Ó jẹ́ ewì ajẹmẹ́sìn.Àwọn eégún onídán ló máa ń pẹ̀sà jù. Ògúnníran fúnra rẹ̀ sọ pé “ọ̀nà láti má fi jẹ́ẹ́ kí àwọn ọgbọ́n àdáyébá di ohun ìgbàgbé ló mú kí ń ṣe àkọsílẹ̀ ẹ̀sà egúngún tí mo sì  fi ìtàn olóyin mọmọ gbé e jáde”. Yàtọ̀ sí ìlò-èdè ẹ̀sà egúngún èyí tí ó jẹ́ olúborí ọnà-èdè nínu ìwé yìí, àwọn ìlò-èdè bíi orin, oríkì, ọfọ̀, ìwúre àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ náà jẹyọ, ó sì tún lo àwọn ìlò-èdè bíi òwe àti àkànlò-ède. Àpẹẹrẹ ìlò-ède ẹ̀sà (ojú ewé 3-5) níbi tí Ìyádùnúnní ti ń fi ẹ̀sà ki Ọ̀jẹ́lárìnnàká ọkọ rẹ̀:

Baálé mi, ọkọ mi

Ìrèmògún ọmọ Àwúsẹ̀

Ìrèmògún ará Ìlágbẹ̀dẹ, ọmọ a-wóri-túnrin-rọ

Ọ̀jẹ́láriìnnàká, ọkọ Ìyádùnúnní Eléégún

Bá a rebi àdáni lógún ọdún

Bá a ràjò àdáni lọ́gbọ̀ oṣù

Ọ̀jẹ̀lárìnnàká ń lọ kò dágbà kan

Ọ̀jẹ̀lárìnnàká dákun má gbàgbé mi;

Ọ̀jẹ́láriìnnàká, ọkọ Ìyádùnúnní Eléégún

Orímóògùnjẹ́ ọmọniyì Yan-àlẹ̀-yàn-àlẹ̀:

Ọmọ kẹ́-mi-í-kẹ́ẹ́kẹ́ n ó dégbèje ọkọ

Tè-mi-i-tè-í-tè n ó dégbẹ̀fà;

Kíkẹ́-tai-kẹ́ n ó dẹ́gbẹ̀-ǹ-dínlógún

Ìrèmògún ará Ìlágbẹ̀dẹ, ọmọ a-wóri-túnrin-rọ

Ìrèmògún ọmọ jági-légbò-ṣoògùn

Ọ̀jẹ̀lárìnnàká dákun má gbàgbé mi;

Ọ̀jẹ́láriìnnàká, ọkọ Ìyádùnúnní Eléégún

Ọ̀jẹ̀lárìnnàká dákun má gbàgbé mi;

Ọ̀jẹ̀lárìnnàká bó o dájò o ṣe rántí ilé

Ọ̀jẹ̀lárìnnàká dákun má gbàgbé mi.

Òǹkọ̀wé tún lo àwọn ọ̀rọ̀ àyálò láti mú ède ìwée rẹ̀ dùn sí i. Àpẹẹrẹ: Aálà (Ède Lárúbáwá fún Ọlọ́run), Yárábì (ède Lárúbáwá fún Ọlọ́run), Kááyá (ède Hausa fún ẹrù) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àpẹẹrẹ Àkànlò-èdè: Bọ́wọ́ sórí - burú kọjá àtúnṣe

Kùsátà - súnmọ́ tàbí détòsí

Gbẹ́ kòtò ìjàm̀bá - pète ìjàm̀bá tàbí ìparun fún ẹlòmìíràn

Ìṣèwádìí: Kìí ṣe gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìpèdè tí wọ́n lò nínu ìwé yìí ló yé èèyàn. Ọ̀pọ̀ nínu àwọn ìpèdè náà ló jẹ́ èdè ìkàsìn nítorí náà wọn ò le nítumọ̀ síni láìṣe pé èyàn náà lọ ṣe ìwádìí nípa wọn. Lẹ́yìn tí olúwarẹ̀ bá ṣe ìwádìí ni yóò le ní òye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà. Àpẹẹrẹ:

Òketè: Ó túmọ̀ sí ẹrù tí a dì sínu aṣọ tàbí ápò tí ó rí bàǹbà. Nínu ìwé yìí wọ́n lò ó gẹ́gẹ́ bíi ohun ìpidàn tí wọ́n dì sínu àpò.

Ẹ̀sẹ̀ǹtayé: Èyí túmọ̀ sí ẹsẹ̀ tí ọmọ tuntun fi tẹ ayé. Ó tún lè túmọ̀ sí kádàrá àti ohun tí ọmọ tuntun náà máa gbélé ayé ṣe.

Kẹrẹ̀ẹ́: Ó túmọ̀ sí fààfá tíí ṣe irú idán.

Ìkóódẹ: Ó túmọ̀ sí ìru odídẹrẹ́ (ìkó odídẹrẹ́).

Láfíánù: Ó túmọ̀ sí Etí.

Ọnà Èdè: Nítorí wí pé àfojúsùn Ògúnníran nígbà tí ó ń kọ ìwé yìí ni àwọn lítírésọ̀ alohun Yorùbá pàápàá jù lọ ẹ̀sà, kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàmúlò ọnà-èdè. Ògúnníran ṣàmúlò ọnà-èdè àwítúnwí ní àìmọye ìgbà. Ó ṣe àwítúnwíi oríkì Ọ̀jẹ́lárìnnàká ọkọ Ìyádúnúnní ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti lè tẹnu mọ oríkì, ipa àti ìwúlò rẹ̀ fún àwùjọ.

 

Ìjẹyọ Apè tàbí Àdìtú-èdè: Àdìtú èdè túmọ̀ sí èdè tí a “dì” ṣùgbọ́n tí ó ṣe é tú nípa ṣíṣàlàyé ìtumọ̀. Ó túmọ̀ sí àwọn afọ̀ àti ọfọ̀ tí àbàṣe tí ó ní ipa tó ń kó ní ọ̀gangan ipò tí ó ti wáyé tàbí jẹyọ. Nínu ìwée Eégún Aláré àwọn ọfọ̀ tó ń jáde lẹ́nu àwọn eégún aláré nígbà tí wọ́n bá ń pidán ló dúró gẹ́gẹ́ bíi àdìtú-èdè nítorí wí pé èdè ló dìpọ̀ tí ọfọ̀ fi wáyé, ọfọ̀ yìí sì nípa tó kó ní ọ̀gangan ibi tí wọ́n ti pè é. Àpẹẹrẹ  wà lójú ewé kọkànlélógún títí de ojú ewé kejìlélógún níbi tí Ọ̀jẹ́lárinnàká ti ń pọfọ̀ láti sọ ọmọ rẹ̀ Ọ̀jẹ́làdé di èèyàn padà. Bàbá náà ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ ....... Ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń wí àfi ìgbà tí yóò parí ọfọ̀ náà tí ó ké sókè pé:

Ohun tí a wí fún ọbọ́

lọgbọ́ọ́ gbọ́

Ohun tí a sọ fọ́gbà

lọgbàá gbà

Àṣe tákíntólú bá fún ilẹ̀

                                                       nilẹ̀ẹ́ gbọ́      

Ọ̀jẹ́làdé paradà o dènìyàn

Àṣẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀

Torí wí pé wéréwéré làṣẹ ipín ń múgbá

Wàràṣeṣà làṣẹ ọ̀nà ń mẹ́sẹ̀

Ọ̀jẹ́làdé gbéra nílẹ̀ o dìde ọjọ́ ń lọ.

Ọ̀jẹ́lárìnàká tún mórin ẹ́nu:

Ayùnrẹ́ ò igi oko o

Ewé tí o sà kó máa jẹ́

Ayùnrẹ́ ò igi oko o

Ewé tí o sà kó máa jẹ́

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọfọ̀ náà jẹ́ èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ le láti mọ̀ tí ó sì tìtoríi rẹ̀ rí bíi wí pé kò nítumọ̀ ṣùgbọ́n ó ní ìtumọ̀ sí àwọn ẹ̀mí àìrí. Àwọn ẹ̀mí àìrí fi àṣẹ sí ohun tó sọ. Nítorí wí pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ la rí i tí Ọ̀jẹ́làdé tó ti di òjòlá tẹ́lẹ̀ sì le yíra padà da èyàn padà.

 

Ìwé Ìtọ́kasí

Ògúnníran, L. (2010). Eégún Aláré. Ìbàdàn:Macmillan Nigerian Publishers            Limited.

Ọ̀pẹ́fèyítìmí, A. (2014). Tíọ́rì àti Ìṣọwọ́lo-èdè. Ilé-Ifẹ̀: Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University Press.



[1] Oyetunde Blessing Ifeoluwa ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment