ÌSỌNÍSÓKÍ ỌMỌ OLÓKÙN ẸSIN 
Ṣé àwọn Yorùbá bọ̀, wọ́n ní bí a ó ti ṣe là á wí, ẹnìkan kìí yan àna rẹ̀ lódì. Òwe yìí
ló dífá fún ọmọkùnrin kan tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Àjàyí tí gbogbo ènìyàn mọ̀
sí “Ọmọ-Olókùn ẹsìn”. 
Ìlú Òtu ni ìlú rẹ̀; ìlú Òtu yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú
Ẹkù Osi. Odò Ogun ni ó pín ìlú Òkò àti ọ̀kan nínú àwọn ìlú àmọ́ná rẹ̀ tí ó wà
ní apá ìsàlẹ̀ sí méjì.
Fún àlàyé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní òdì-kejì yìí ni à
ń pè ní Òkè Ògùn tí Òkò sì dá wà. Òkò yìí ló jẹ́ ìlú tí ó ko gbogbo ìlú tó wá
ní Òkè Ògùn yìí sábẹ́. Àwọn ìlú náà nìwọ̀nyìí: Ọ̀yọ́ Mọ̀kọ, Ọ̀yọ́-koro, Ọ̀yọ́
Eléégún, Òtu, Ìṣẹ́yìn, Ṣakí, Ìwéré, Òkèihò, Ìgànnà, Tedé, Ìgbòho, Ìgbẹ́ta,
Kìísí, Òkè Àmù, Ipòpó, Ilerò, Itaṣá, Ìdìkó, Ahá, Ìjío àti Ìràwọ̀.
Gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyìí ni wọ́n jẹ́ ẹrú fún ìlú Òkò. Èyí tí wà láti
ìgbà-ìwásẹ̀. Bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ-ọba Òkò ni wọ́n máa ń wá sí àwọn
ìlú Òkè-Ògùn wọ̀nyìí láti wá gba oríṣìíríṣìí nǹkan àlejò, tí wọn yóò máa ta
ènìyàn ni ìtàkuta bẹ́ẹ̀ wọn kò gbẹ̀yìn ni jíjẹ ayé ìjẹkújẹ.
Wàyí o, ní ọdọọdún tún ni gbogbo àwọn ìlú Òkè Ògùn wọ̀nyìí máa ń ru
àsìngbà lọ sí Òde Òkò. Ní ọjọ́ kan wàyí, oko bẹẹrẹ ni àwọn ará ìlú Òtu wà
níbi tí wọ́n ti ń pa koríko bẹẹrẹ tí wọn yóò rù lọ si Òkò; ọmọkùnrin tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Àjàyí tí í ṣe ọmọ-Olókun ẹṣin
yìí náà wà níbẹ̀; àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà kò sì gbẹ́yìn.
Bẹ́ẹ̀ báálẹ̀ ìlú wọn ti yan ẹni tí yóò ṣe àmójútó wọn lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń
ṣe yìí. Orúkọ ẹni yìí ni a mọ̀ sí Roti.
Kùmọ̀ kò gbẹ́yìn lọ́wọ́ rẹ̀ níbi tí ó ti ń ṣe àmójútó àwọn tó ń ṣiṣẹ́
yìí. Nínà ni ó ń na àwọn tó ń sinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe é. Ṣíṣe tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ dé ọ̀dọ̀ Àjàyí (Ọmọ-Olókùn ẹṣin) ni ó ṣe é
tẹ́. Ṣé ìbá mọ̀, ìbá má ṣe é, ó ṣe é tán, ó dẹ̀tẹ́ ní ọ̀rọ̀ Rótì tíí ṣe
ẹrú báálẹ̀ Òtú.
Gbàrà tí Rótì ṣe àkíyèsí wí pé Àjàyí náà wà lára àwọn tí ó ń sinmi ni
inú bá bí i tí ó sì ń bá ìbínú bọ̀ wá sọ́dọ̀ Àjàyí, ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wí
pé ń ṣe ni ó fara pa nígbà tí Àjàyí yẹ kùmọ̀ tí ó fẹ́ fi nà án. Nígbà tí
àwọn ènìyàn ṣe àkíyèsí wí pé Rótì ti fara pa báyìí láti ọwọ́ Àjàyí ni wọ́n
rá gìrì sí Àjàyí láti lù ú ṣùgbọ́n ń ṣe ni ẹni tí ó kọ́ na ọwọ́ rẹ̀ nínú
wọn náà tún fara pa nípa fífi ọwọ́ kọ́ dòjé tí ń bẹ lọ́wọ́ Àjàyí.
Agbo àwọn tó ń pa oko bẹẹrẹ dàrú. Àjàyí sì dorí kọ ọ̀nà ilé. Nígbà tí
Àjàyí dé ilé, orí oúnjẹ ni ó bá bàbá rẹ̀, gbàrà sì ni bàbá rẹ̀ pa oúnjẹ rẹ̀
tì tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí nií bí Àjàyí, ọmọ rẹ̀, ní àwọn ìbéèrè tí ó mú ìfura lọ́wọ́ nítorí rírí tí ó rí
Àjàyí, ọmọ rẹ̀, ni irú àkókò bẹ́ẹ̀. Ẹnu èyí ni wọ́n wà tí àwọn ẹ̀gbọ́n Àjàyí náà darí dé
láti oko bẹẹrẹ tí wọ́n sì ṣàlàyé gbogbo ohun tí Àjàyí dán wò ní oko
bẹẹrẹ fún bàbá wọn. Ìlù bí i kókú ni bàbá Àjàyí fi ṣe ti Ajayi nígbà tí àlàyé délẹ̀ tán, bẹ́ẹ̀ ìyá Àjàyí náà kò gbẹ́yìn
ní kíki Àjàyí mọ́lẹ̀ nígbà tí òun náà gbọ́ gbogbo àlàyé ọ̀ràn tí Àjàyí dá
lẹ́yìn tí òun náà dáwọ́ tẹlẹ̀ tán.
Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn obìnrin ilé ní ó gba Àjàyí kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀. 
Ṣé àìlómìnira ni ó ṣokùnfà ìwà ọ̀daràn tí Àjàyí rawọ́ lé yìí. Ṣé àwọn
àgbà bọ̀, wọ́n ní a kì í déédé garo ọwọ́ bí kò bá sí ohun tí a rí lọ́bẹ̀. Orí
mímọ ohun tí Àjàyí rí lọ́bẹ̀ tí ó fi garo ọwọ́ ni bàbá Àjàyí àti Àjàyí wà tí
ẹrú báálẹ̀ tí a mọ orúkọ rẹ̀ sí Kí-tọba-ó-ṣẹ wọlé dé láti jíṣẹ́ wí pé
báálẹ̀ ní kí bàbá Àjàyí àti Àjàyí ó yọjú sí òun láàfin.
Ṣé ohun tí ènìyàn bá ti gbára dì fún, bí ó bá dé kìí dé báni lẹ́rù mọ́.
Bàbá Àjàyí ti mọ̀ wí pé ohun tí yóò gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà ni wí pé kí òún yọjú sí
ilé báálẹ̀ nítorí pé olóyè inú ìlú náà ni òun náà, ìyẹn “Olókùn-ẹsin”.
Àṣé kìí ṣe bàbá Àjàyí nìkan ni ó ń gbáradì fún ìpè láti ọ̀dọ̀ báálẹ̀; àwọn ẹ̀gbọ́n àjàyí, ìyá Àjàyí àti àwọn obìnrin ilé náà kò gbẹ́yìn
ṣùgbọ́n nígbà tí bàbá Àjàyí ko fírí wọn, pàápàá, àwọn obìnrin, inú bí i ó sì pàṣẹ wí pé kí wọ́n padà ṣùgbọ́n abiyamọ
ni abiyamọ yóò máa jẹ́, tíkọ́-tíkọ́ ni ẹsẹ̀ iyá Àjàyí kọ́, kò fẹ́ padà sílé.
Nígbà tí bàbá Àjàyí òun Àjàyí àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò fi dé ilé báálẹ̀,
ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún un nítorí pé gbogbo ẹsẹ̀ ti pé sí ilé báálẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì
ni wí pé ẹni tí Àjàyí fi dójé gé lọ́wọ́ kò gbẹ́yìn.
Gbalaja nílẹ̀ ni bàbá Àjàyí nà gbalaja nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ báálẹ̀ tí ó
sì bẹ báálẹ̀ wí pé kí ó gba òun. Ẹnu tí báàlẹ̀ yóò là, òwe ni ó pa, ó ní “A
kì í wí pé ọmọ tí yóò bá hu eyín gan-n-gan kí ó máà hù ú, nígbà tí ó bá hù ú tí kò rí ètè bò ó ni yóò tó mọ̀ wí pé kò dára”.
Pẹ̀lú gbogbo atótónu báálẹ̀ yìí, ẹ̀bẹ̀ náà sì ni bàbá Àjàyí ń bẹ̀.
Ṣà dédé ni ọ̀kan lára àwọn olóyè báálẹ̀ tí a mọ̀ sí Ọ̀dọ̀fin tí inú sì ń
bí náà dá sí ọ̀rọ̀ nígbà tí ó bi Àjàyí wí pé ṣé ó mọ̀ wí pé ọ̀ràn ni ó dá?
Ìdáhùn Àjàyí jọ ni lójú púpọ̀. Ń ṣe ni ó dáhùn wí pé kò ṣèèṣì lọ́wọ́ òun
àti wí pé òún mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe é ni. Àgbálọ-àgbábọ̀, Àjàyí dèrò ẹ̀wọ̀n nílé
báálẹ̀.
Wọ́n fi ọ̀bárá sí Àjàyí lọ́wọ́;
wón fi sẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀
dè é lẹ́ṣẹ̀. Ṣáájú ìgbà yí náà, bàbá Àjàyí ti di ọ̀tá àwọn ìjòyè tó kù
nítorí pé bá mi na ọmọ mi kò dénú ọlọ́mọ. Gbogbo ìrora inú ẹ̀wọ̀n yìí ni
Àjàyí pa mọ́ra títí tí ilẹ̀ fi mọ́ ní ọjọ́ kejì.
Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì ni àwọn ẹrú méjì báálẹ̀ wá mú Àjàyí jáde kúrò ní inú
ilé ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sì gbé e síta láti ṣere tòun tí Ọ̀bárá lọ́wọ́ àti
ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀. Sà dédé ni Àjàyí figbe ta wí pé ebi ń pa òun; wọ́n bá Àjàyí gbé oúnjẹ wá ṣùgbọ́n kí ó ba lè rí ọwọ́ jẹ iṣu tí wọ́n
gbé wá fún un, wọ́n bá a fi ọbẹ̀ já okùn tí wọ́n fi dé ọwọ́
rẹ̀ ní àdìsẹ́yìn. 
Ibi tí Àjàyí tí ń jẹ iṣu yìí ni ẹnìkan dédé dé sí ẹ̀yìn rẹ̀, àṣé
ọmọbìnrin báálẹ̀ ni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Ìbíwùmí. Ìbíwùmí àti Àjàyí
fomi-jomitoro-ọ̀rọ̀ láàrin ara wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ kòǹgbà-kòǹgbà
ni àwọn méjéèjì fi ń bèrè ìbéèrè tí
wọ́n sì fi ń dáhùn
ọ̀rọ̀ láàárín ara wọn. Nígbẹ̀yìn, Àjàyí kò sàìfi yé Ìbíwùmí wí pé
ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé ni Ọlọ́run dá gbogbo nǹkan láyé. Èéṣe tí àwọn orí kan yóò
fi wá máa sin àwọn orí kan. Àjàyí fi yé Ìbíwùmí wí pé àsìngbà kò tọ́, ó sì
dàbí pé Ìbíwùmí pàápàá ti rí àléébù tí ó wà nínú àìlómìnira. Ṣe kí odi lè
gbọ́rọ̀ ní a ṣe ń sọ ọ́ lójú ọmọ rẹ̀ ni Àjàyí fi ọ̀rọ̀ náà ṣe.
Ní àárọ̀ ọjọ́ yìí náà ni àwọn ìjòyè wá ṣe ìpàdé ni ọ̀dọ̀
báálẹ̀, wọn kò sàìgbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu Àjàyí ni àárọ̀ yìí náà. Ó jọ Àjàyí
lójú nígbà tí ó tún kó fírí Ìbíwùmí tí ó yọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti ṣe òfófó fún
Àjàyí wí pé àwọn ìlú ń gbìmọ̀ láti mú
Àjàyí kúrò ni ibi tí ó wà lọ sí Òkò ní ọ̀la, tí ó sì pàrọwà sí Àjàyí wí pé kí
ó sá lọ ni inú ẹ̀wọ̀n tí ó wà. Lákọ̀ọ́kọ́ tí Àjàyí gbọ́ èyí, ó kọ̀ jálẹ̀ wí pé
òun kò sá lọ ibì kankan, àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Àjàyí rò ó síwá, ó rò ó
sẹ́yìn, ó sì gbà láti sá lọ.
Ìbíwùmí náà ti ṣàwárí ayùn tí yóò fún Àjàyí láti fi tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí
ń bẹ lẹ́ṣẹ̀ rẹ̀ nígbà tí àkókò bá tó láti sá lọ. Ìbíwùmí ko sàìsọ fún
Àjàyí wí pé gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí ipá òun bá ká ni òun yóò ṣe fún Àjàyí àti wí
pé ohun gbogbo tí ojú òun bá rí ní lílọ Àjàyí ni òun yóò fara mọ́ àti wí pé kí
Àjàyí ka òun mọ́ ọmọlẹ́yìn àti onígbèjà rẹ̀.
Nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí ó sọ bàbá Àjàyí di
ọ̀tá àwọn olóyè báálẹ̀ tí ó kù pẹ̀lú ìròyìn tí ó tún ti dé ọ̀dọ̀ Olumòkò ti
ìlú Òkò tí í ṣe olórí (Ọba) gbogbo  
ìlú tí ń bẹ ni Òkè-Ògùn ni ó mú ki Olumòkò fi fìlà ránsẹ́ pé kí Olókùn
ẹsin, tí i ṣe bàbá Àjàyí, fi àásó òun ránṣẹ́ padà tí wọ́n sì ṣe
bẹ́ẹ̀ yọ baba Ajayi lóyè.
Lẹ́yìn tí Àjàyí sá kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ilé báálẹ̀ Òtu tán, Ìgbòho ní ọ̀dọ̀
ọ̀rẹ́ rẹ̀, Àyọ̀wí, tí wọ́n jọ
máa ń sọ̀rọ̀ ìwà ìrẹ́nijẹ tí àwọn ara Òkò máa ń hù sí wọn ni ó gbà lọ.
Nígbà tí Àjàyí dé ọ̀dọ̀ Àyọ̀wí, ó ṣàlàyé ohun gbogbo tó ń ṣẹlẹ̀ fún un tí ó
sì jẹ́ pé, níkẹyìn, Àyọ̀wí náà sìkẹta Àjàyí òun
pẹ̀lú Ìbíwùmí láti ja ìjà ìgbara-ẹni-sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn amúnisìn ìlú Òkò.
Láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ nípa èròǹgbà yìí, Àjàyí àti Àyọ̀wí gbèrò láti
gùn lé ìrìnàjò lọ sí ìlú Ìgbẹ́tì àti Ìràwọ̀, tí í ṣe ìlú àwọn ọ̀rẹ́ wọn, ìyẹn Kọ́lájọ àti Ṣàngódèyí. Ìdíwọ́
ráńpẹ́ kan ṣẹlẹ̀ ni kò jẹ́ kí wọ́n gbéra ní ọjọ́ tí wọn fẹnu-kò sí láti
gùn lé ìrìnàjò yìí.
Nígbà tí yóò fi di ọjọ́ ìyálẹ̀ta, ọjọ́ tí wọ́n ní ìdíwọ́ yìí ni Àjàyí bọ́
sí àgbàlá lẹ́yìn tí ó tají lójú oorun láti fi omi bọ́jú, ̣ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí níí gbọ́ ìró ìlù. Àjàyí gbìyànjú láti rí i pé òun mọ ibi tí ìlù náà ti ń
dún. Ó pàpà ṣàwárí ibẹ̀, àárín ọjà sì ni ó ti bá àwọn onílù náà, àṣé
ọmọọba ni wọ́n ń lùlù fún, nígbà tí Àjàyí mọ èyí tán, ó pàṣẹ kí wọ́n pa
ìlú ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà di ìjà ìgboro débí wí pé Àjàyí kò mọ ìgbà tí
Àyọ̀wí àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dé láti wá gbèjà rẹ̀. Lọ́rọ̀ kan sá, ọjọ́ kejì ni
Àyọ̀wí àti Àjàyí tó lè gbéra ìrìn àjò wọn láti lọ bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn.  
Ohun ìyanu ni ó jẹ́ fún Àjàyí nígbà tí ó dé ìlú Ahá tí ó sì ṣe àkíyèsí wí
pé ń ṣe ni gbogbo ìlú ń hó yùngbà, à ṣé báálẹ̀ ìlú yìí ti kéde fún gbogbo
ìlú pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lọ sí oko kí wọ́n bàa le rí àyè ru
bẹẹrẹ ọdún lọ sí Òkò. Èyí ló sọ Àjàyí níyè wí pé báyìí ni yóò ṣe máa
ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìlú tiwọn náà, ìyẹn ìlú Òtu. Láìro ohun tó ti ṣẹlẹ̀
sí i ní ìlú Òtu, ó pinnu láti gba Òtu lọ, bí ó ti kù díẹ̀ kí Àjàyí dé ìlú wọn
ni ó ṣe alábàápàdé ará ìlú wọn kan, ní ẹni tí ó mọ nípa àwọn ìjọ̀ngbọ̀n tí
Àjàyí ń dá sílẹ̀, Adékànḿbí ni orúkọ rẹ̀. Ó kí Àjàyí, òun náà sì dá a lóhùn.
Ìgbà tí Àjàyí dé ìlú wọn, inú oko bẹẹrẹ ni ó já sí. Alẹ́ ọjọ́ yìí ni
Àjàyí rí i wí pé óún sun àwọn bẹẹrẹ wọ̀nyìí, ó sì mú ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n ní
ọjọ́ kejì.
Ohun ìyàlẹ́nu náà ni ó tún jẹ́ fún Àjàyí nígbà tí ó kó fìrí wí pé
Adékànḿbì àti àwọn mẹ́ta mìíràn ni wọ́n ti dènà de òun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé
Àjàyí náà fara pa, àmọ́ ó ṣẹ́gun wọn nígbẹ̀yìn tí wọn kò sì mọ ibi tí ó
fara pamọ́ sí títí tí wọ́n fi padà lẹ́yìn rẹ̀. Ìlú baba ọdẹ ni Àjàyí rántí
nígbà tí ó ń gba àwọn òkunà, ẹsẹ̀ àlà kiri.
Ọ̀dọ̀ Ọ̀ṣúnjùmọ̀bí tí òun àti Àjàyí ti jọ fìgbà kan singbà rí ni Àjàyí
forí lé. Gbogbo ara ni wọ́n fi gba Àjàyí débi wí pé kí ó tó lọ, báálẹ̀ ránṣẹ́ sí i wí pé kí ó wá túbọ̀ ṣàlàyé nípa ìjà òmìnira tí ó ń
ṣètò nípa rẹ̀. Àwọn ará ìlú náà kò gbẹ́yìn níbi tí Àjàyí ti ń ṣàlàyé fún
wọn nípa ọ̀rọ̀ òmìnira yìí. Ibẹ̀ sì ni àwọn géńdé tí wọ́n wá láti Òtu dé,
wọn kò ṣàìṣe àwọn ènìyàn léṣe, kódà wọn pa àwọn ènìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ ni
ìlú baba ọdẹ ni ọjọ́ tí à ń sọ yìí.
Pẹ̀lú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn géńdé wọ̀nyí rí i pé àwọn gbe
Àjàyí, ó di ìlú Òkò. Nígbà tí wọ́n gbé Àjàyí
dé Òkò ilé Olósì tí í ṣe alábòójútó ilé-ẹ̀wọ̀n fún Olúmokò ni wọ́n gbé Àjàyí
lọ nítorí wí pé ọba Òkò kò ráyè tirẹ̀ ní ọjọ́
náà nítorí pé ọdún bẹẹrẹ ti bẹ̀rẹ̀.
Inú ẹ̀wọ̀n ni Àjàyí ti ṣe alábàápàdé àwọn ènìyàn rẹ̀ ìyẹn Àyọ̀wí,
Kọlájọ àti Ìbíwùmí. Èyí ya Àjàyí lẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì bú sẹ́kún. Ní ibí
yìí ni Àjàyí ti wá ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ni Òtu àti ohun tó gbé
wọn dé inú ẹ̀wọ̀n lólósì.
Ìbíwùmí ni ó kọ́kọ́ mẹ́nu lé ọ̀rọ̀ tí ó sì ṣàlàyé wí pé lẹ́yìn tí òun tú
Àjàyí sílẹ̀ tán ni ọba ìlú Òkò rán àwọn ààrẹ wá láti wá mú Àjàyí ṣùgbọ́n
wọn kò bá Àjàyí nínú túbú tí wọn fi sí mọ́ ni wọn pe òun láti wa jẹ́jọ́.
Lẹ́yìn tí Ìbíwùmí jẹ́wọ́ wí pé òun ni ó tú Àjàyí sílẹ̀, ni ó di èrò ẹ̀wọ̀n nílé
ìyálòde tí í ṣe alábòójútó àwọn ọ̀daràn obìnrin, bẹ́ẹ̀ bàbá Ìbíwùmí ti kọ̀ ọ́ lọ́mọ, ó sì ti lé ìyá rẹ̀ kúrò nílé pẹ̀lú.
Àṣẹ̀yìnwá-àṣẹ̀yìnbọ̀, Ìbíwùmí di
gbígbé lọ wá sí ìlú Òkò ní èyí tí ó ní àfọwọ́sí bàbá rẹ̀ nínú. Ṣùgbọ́n
ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n ń gbé Ìbíwùmí bọ̀ ní Òkò; bàbá Àjàyí àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ni wọ́n wá dánà  de àwọn ẹrú ọba tí wọ́n wá mú Ìbíwùmí yìí.
Ó ṣe ni láàánú wí pé ń ṣe ni àwọn náà dẹni àmúdè; ó di Òkò ṣùgbọ́n ibi pàtó tí wọ́n kó wọn wá ní Òkò kò hàn sí Ìbíwùmí.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Àyọ̀wí ṣàlàyé bí òun náà ṣe dé ilé Olósì. Inú ẹ̀wọ̀n yìí ni
gbogbo wọ́n wa tí ariwo fi ta pé iná ti ran mọ́ ààfin àti ọgbà ẹ̀wọ̀n, pẹ̀lú
gbogbo akitiyan, ọgbà ẹ̀wọ̀n jó, Àyọ̀wì, Àjàyí àti Ìbíwùmí pẹ̀lú àwọn
ẹlẹ́wọ̀n pérete ni wọ́n bórí yọ nínú ìjàǹbá iná yìí. Kódà, ààfin ọba ìlú Òkò ganan náà jóná. Ohun ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ nígbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé Kọ́lájọ wa lára
àwọn tí ìjàǹbá iná yìí mú lọ ọ̀run alákeji.
Ìwádìí fi yé ọba wí pé ohun tó fa ìjàǹbá
iná yìí ni wí pé ń ṣe ni àwọn òrìṣà ń bínú, wọ́n sì fẹ́ kí wọ́n rúbọ sí àwọn. Ọba pàṣẹ
wí pé kí wọ́n kó Àjàyí àti àwọn yòókù lọ sí ilé òrìṣà Nààrì, ibẹ̀ sì ni wọ́n
ti máa ń pa ẹni tí ó bá kàn láti fi bọ òrìṣà. 
Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, wọ́n dájọ́ tí wọn yóò fi Àjàyí àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀
rúbọ ní ìdí Ògún ní ọjà ọba. Kí ó tó di ọjọ́ ìrúbọ yìí ni ọkùnrin kan tí
a mọ̀ sí Akọ́dà wa gba Àjàyí kalẹ̀ ní ibi tí wọn so wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀, irọ́ ni ó pa fun bàbálórìṣà wí pé ọba ni ó ránṣẹ́ pe Àjàyí ṣùgbọ́n
èròǹgbà ọkùnrin yìí ni láti ṣe òfófó ibi tí bàbá Àjàyí wà fún un. Èyí jẹyọ
nítorí ìlérí tí Akọ́dà náà ti ṣe fún Àjàyí
láti ran an lọ́wọ́ nígbà tí àyè bá yọ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Akọ́dà yìí ni o sọ fún
Àjàyí wí pé Òṣòògùn ni bàbá Àjàyí àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wà. 
Àjàyí kò jáfara láti lọ ṣe àgbàálẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí wí pé ọjọ́
náà ni wọ́n fẹ́ fi wọn rúbọ ní ìdí igi àràbà tíí ṣe igi òòṣà. Inú ewu ńlá
ni Àjàyí ti ṣe èyí ṣùgbọ́n Àjàyí yege nínú síṣe èyí nítorí ìrànlọ́wọ́ tí ó rí gba látọwọ Ọbákáyéjá àti Babaáre
tí wọn í ṣe olórí àwọn ẹrú báálẹ̀ Òtu tí Ìbíwùmí rà kalẹ̀ ni ọjọ́
kìíní-àná tí bàbá rẹ̀ kọ̀ ọ́ lọ́mọ tí ó sì pin ogún tirẹ̀ fún un.
Nígbà tí Àjàyí yóò fi padà sí ilé òrìṣà Nàànì tí wọ́n dè wọ́n mọ́ ni ó
ṣàkíyèsí wí pé ọwọ́ ti tẹ Akọ́dà tí ó wá ṣe òfófó fún un. Èyí ba Àjàyí
lọ́kàn jẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n kò si ohun tí ó lè ṣe sí i. Kátówí-kátófọ̀,
ọjọ́ pé tí wọn yóò fi àwọn tí wọ́n wà ní ilé òrìṣà Nàànì rúbọ ní ìdí ògún
ìyẹn ni ọjà Ọba. Gbogbo ètò ti tò láti ṣe èyí, wọn tí fárí gbogbo wọn, kò
sì sí ìrètí níbì kankan fún Àjàyí àti àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù mọ́.
Orí Akọ́dà ni wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ bẹ́ fún Ògún, tí wọ́n sì so àwọn yòókù mọ́
igi láti máa mú wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Ọba àti gbogbo àwọn ará ìlú kò gbẹ́yìn
níbi tí à ń wí yìí.
Bí ààrẹ onídà tí yóò bẹ́ Akọ́dà lórí ti ni kí òún gbé idà wálẹ̀ ni ó tó
hàn pe ààrẹ mìíràn ti fa àdá yọ láti fi dá a dúró, èyí ya gbogbo ènìyàn lẹ́nu
lọ́pọ̀lọpọ̀. 
Lójijì ni àwọn ènìyàn rí ẹnì kan tí ó gun ẹṣin dé pẹ̀lú àìmọye èrò
lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn èrò wọ̀nyìí jẹ́ àpapọ̀ gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Òkè Ògùn,
àwọn pẹ̀lú àwọn báálẹ̀ wọn. Ìdí abájọ tí wọ́n sì fi wá ni wí pé wọ́n wá
láti wá gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ amúnisìn tí ìlú Òkò ń fi wọ́n ṣe ní èyí tí
gbogbo ìlàkàkà Àjàyí àti àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ dá lé lórí. Ṣùgbọ́n wọn kọ́kọ́
pọn ọ́n ní dandan wí pé kí ọba pàṣẹ wí
pé kí wọ́n tú Àjàyí,  Àyọ́wì, Ìbíwùmí,
Akọ́da àti gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ olùwọ̀ tí wọ́n
dè mọ́lẹ̀ sílẹ̀ náà. Èyí sì kọkọ́ rí bẹ́ẹ̀.
Láìfi ọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀-pọ̀ọ̀lọ pejò,
gbogbo àwọn ìlú Òkè Ògùn gba òmìnira ni ọjọ́ yìí. Wọn kò ṣàìṣètò fún ọba
Olúmokò wí pé fún ọdún mẹ́wàá gbáko ni àwọn yóò máa fi àádọ́ta ọ̀kẹ́ ránṣẹ́
sí i àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú málùú méjì (akọ kan àti abo kan) lọ́dọọdún. Wàyí o, wọ́n tún ni àwọn
yóò máa fi ogún ọ̀kẹ́ ránṣẹ́ sí àrẹ̀mọ ọba náà lọ́dọọdún fún ọdún mẹ́wàá.
Lẹ́yìn èyí tí ọ̀rọ̀ ti bùṣe ni wọn padà sí ìlú wọn, bí wọ́n ṣe ń lọ
lójú ọ̀nà ni Àjàyí àti Ìbíwùmí sọ àsọkúnná lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ara
wọn tí ọ̀rọ̀ ìjà òmìnira ko fi àkókò rẹ sílẹ̀ fún wọn láti ṣàfihàn. Àwọn
òbí àwọn méjèèjì fi ọwọ́ sí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọn. Láìfa ọ̀rọ̀ náà gùn, ń ṣe ni
wọn dájọ́ ìgbeyàwó ní ọjọ́ náà. Ó ṣeni láàánú wí pé ọjọ́ tí wọ́n mú yìí ṣe
rẹ́gí pẹ̀lú ọjọ́ ti Arinládé àti ọkọ rẹ̀ náà fi ọjọ́ ìgbéyàwó wọn sí.
Àwọn wọ̀nyìí ni Àyọ́wì àti Kọ́lájọ gbà kalẹ̀ lọ́wọ́ Lágboókùn (ọmọ ọba) tí
ó fẹ́ fipá gbẹ́sẹ̀ lé e. 
Arinládé àti ọkọ rẹ̀ gbà láti sún ọjọ́ ìgbéyàwó wọn síwájú láti fi
bu ọlá fún Àjàyí àti Ìbíwùmí.
Gọngọ sọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ayé òun ọ̀rún mọ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó Àjàyí àti
Ìbíwùmí yìí nítorí pé gbogbo ìlú ni ó pèsẹ̀ síbi ìgbéyàwó yìí. Báyìí ni àwọn
ìlú Òkè Ògùn ṣe gba òmìnira lọ́wọ́ ìlú Òkò tí ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ
gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí ó máa lọ.
Ọnà-èdè nínu Ọmọ-Olókùn Ẹsin
Àfiwé 
Ọnà-èdè kan pàtàkì ni èyí jẹ́, a máa ń ṣe àmúlò àfiwé nínú ìtàn àròsọ
àti àwọn afọ̀ geere mìíràn láti fi ṣe àlàdélẹ̀ àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀
kọ̀ọ̀kan. 
Ìlò àfiwé máa ń jẹ́ kí á mọ bí ènìyàn ṣe mọ àpadé àti àlùdé èdè sí.
Nígbà tí a bá ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ kan bọ̀, tí a sì mú ohun mìíràn tí a mọ̀ bí ẹni
mọ owó láti fi túbọ̀ ṣe àpèjúwe ohun tí à ń sọ yìí ni a mọ̀ sí àfiwé.
Oríṣìí àfiwé méjì ni ó wà, àwọn náà ni:
Àfiwé tààrà
Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
(1)     Àfiwé tààrà
(simile)
·       
ó gbé ọwọ́ tí dòjé gé náà sókè gẹngẹ bí ọwọ́
alágẹmọ (ojú ìwé 7)
·       
pẹ̀lú imú rírán bí
alábahun (ojú ìwé 8)
·       
pẹ́ú ni èmí pàápàá kúkú ń wò ní tèmi, bí èkúté tí
a fi sí àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ọ̀sán gangan (ojú ìwé 8).
·       
Ó ya ẹnu bí ọmọ ẹyẹ tí ìyá rẹ̀ fẹ́ẹ́ fò (ojú ìwé 9)
·       
Bí mo ti ní kí n máa ro ẹjọ́ lọ wòrò wẹẹrẹ báyìí ni
bàbá mi ba súré sí mi, ó ní kí òun gbá mi ní ìkúùkù lẹ́nu, pé kí ń yé
sọ̀sọkúsọ bí ẹja. (ojú ìwé (9)
·       
Bẹ́ẹ̀ ni mo tiiri ọrùn gọ́gọ́ bí ọrùn abínú-ẹni
(ojú ìwé 13)
·       
Mo dákẹ́ mo ṣe bí ẹni pé mo ti ya odi (ojú ìwé 16)
·       
Àwa méjéèjì wá gbé ọ̀pá wa lọ́wọ́ gan gan, gan, bí
ìgbà tí a dènà de ajá (ojú ìwé 45)
·       
Gbogbo rẹ̀ ń ró pàpà, pà! pà! pà! pàpà, bí ìgbà tí àwọn ènìyàn
púpọ̀ ń gé igi aparun lókè-odò (ojú ìwé 47)
·       
Mo lóṣòó, mo yọ ahọ́n síta mo ń mí bí ajá tí ó
ṣẹ̀sẹ pa ehoro tán (ojú ìwé 48)
·       
Gbogbo ojú ibi tí ọ̀pá gbé bá mi wú kándìkàndi bí èso ìbẹ́pẹ (ojú ìwé 49)
·       
Wọ́n kún ẹnu-ìlo bíi bàbà èsùà (ojú ìwé 54)
·       
Aṣọ òdòdó tí ó dà bora ń kọ mọ̀nà bí i díńgí
(ojú ìwé 67)
·       
Mo sọ orí kọ́ bí ẹyẹ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ (ojú ìwé 69)
·       
Orí ni mo dà kodò bí àdán (ojú ìwé 69)
·       
Nítorí pé bí Àyọ́wì ti dárúkọ ọmọ Olókun-ẹsin fún
Kọ́lájọ lẹ́ẹ̀kan ni gbogbo wọn kọ haa! lọ bí ilẹ̀ bí ẹní
(ojú ìwé 71)
·       
Ààrẹ tí ó béèrè ọ̀rọ̀ tún dáhùn bí ẹni pé kò
gbọ́ ohun tí ọ̀dọ̀fin ń wí (ojú ìwé 74)
·       
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n hó lé mi bí ọmọ ẹ̀gà (ojú ìwé 83)
·       
Wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú wa, ní nǹkan bí i
ebè mẹ́ẹ̀dógún sí wa (ojú ìwé 95)
·       
Wọ́n tan iná fìtílà yí agbo ká bí òjùlúgba (ojú
ìwé 106)00
·       
Wọ́n pọ̀ bí ewé rúmọ̀ (ojú ìwé 116)
·       
Ẹnu ni ó yà sílẹ̀ dẹ̀dẹ̀ bí ẹnu ajá mi ló pa á
(ojú ìwé 124)
·       
Ranran ni ó ṣe ojú bí ojú aruwọ (ojú ìwé 136)
·       
Bí gbogbo wọn ti ń hó yọ́ọ̀yọ́ọ̀ nù-un bí ẹ̀gà
(ojú ìwé 143)
·       
Mo wá dàbí àgbò tàbí màlùú tí ó ya ẹhànnà (ojú
ìwé 147)
2.       Àfiwé
Ẹlẹ́lọ̀ọ́ (Metaphor)
·       
Ṣùgbọ́n bí a ti tóbi tó nì, ẹrú ni wa  (ojú ìwé 3)
·       
Àwá gọ̀ ni tiwa (ojú ìwé)
·       
Tóò, o di òmìnira (ojú ìwé 30)
·       
Bí a bá sì rí ọlọ́rọ̀ ẹni, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni à á dà
(ojú ìwé 31)
·       
Ṣùgbọ́n ọ̀tá ni ará Òtu àti ará Baba-ọdẹ (ojú ìwé 50)
·       
Àṣé ọkùnrin kan gúọ́gúọ́ báyìí ni (ojú ìwé 130)
·       
Abuké ni (ojú ìwé 130)
·       
Gbogbo orí wa rí kodoro-kodoro lọ (ojú ìwé 153)
·       
Bẹ́ẹ̀ ni mo gbé ẹsẹ̀ gábá, gàbà, gábá (ojú ìwé 153)
Ìbéèrè pèsìjẹ (Rhetorical Question)
·       
 Ẹrú wo ni ènìyàn
rò pé ó le fi gbogbo inú fẹ́ràn olúwa rẹ̀ délẹ̀? (ojú ìwé 24)
·       
Yẹ̀yẹ́ kínni mo fi ó ṣe? (ojú ìwé 25)
·       
Ará Ìbàdàn kí a ó wá
máa sìn? (ojú ìwé 11)
·       
Àbí o kò mọ̀ pé ọ̀ràn ńlá ni a dá nì nígbà tí a gbìjà
rẹ? (ojú ìwé 40)
·       
Tàbí wọ́n ní kí o mú mi wá bí o bá rí mi ni? (ojú ìwé 41)
Ìfohunpènìyàn (Personification)
Ìfohunpènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọnà-èdè jẹ́ èyí tí à ń ṣàmúlò láti tọ́ka sí
ẹranko, èrò ìfòyemọ̀ tàbí ohun aláìlẹ́mìí, bí ẹni pé ènìyàn ni wọ́n. 
·       
Ẹ̀jẹ̀ rẹ kò ní ja ìjà òmìnira kan lọ pẹ́ẹ̀ (ojú ìwé 26)
·       
Ṣùgbọ́n bi a ti jí tí a sì ń múra pé a o máa lọ ni inú
rírun gbé ẹ̀gbọ́n Àyọ́wì lulẹ̀ (ojú ìwé 33)
·       
Nígbà tí èmi náà ti rí ojú ìjà ní ìlaṣa báyìí
(ojú ìwé 40)
·       
Dídìde ni gbogbo egungun mí dìde (ojú ìwé 49)
·       
Ọkàn mi ko jẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ rẹ (ojú ìwé 28)
Àsọrégèé (Hyperbole)
Ọnà-èdè yìí jẹ́ mọ́ kí á mọ̀ọ́mọ̀ sọ nǹkan kọjá bí ó ti mọ, kí á sọ
àsọdùn ìṣẹ̀lẹ̀
·       
Aró fẹ́rẹ̀ lè máa kán sílẹ̀ láti ara fìlà abetí ajá aláró
tí ó dé (ojú ìwé 67)
Àwítúnwí (Repetition)
·       
 Má pa mí, má pa
mí, èmi kì í ṣe ọ̀daràn (ojú ìwé 5)
·       
Nígbà tí a ó fi de ilé Báálẹ̀, ilẹ̀ ti kún, ilẹ̀
ti ya (ojú ìwé 7
·       
A kìí wí pé ọmọ tí yóò bá hu eyín ganganan kí ó
má hù ú, nígbà tí ó bá hù ú tí kò bá rí ètè fi bò ó ni yóò tó mọ̀
wí pé kò dára (ojú ìwé 8)
·       
“Ọba kò bíni ká rèmẹ́ní
Ọlókùn-ẹsin kò bíni
Ká sàsìngbà” (ojú ìwé 10)
·       
Ká tó tún dé
Ká tó tún dé
Ọmọ yin yóò dàgbà dàgbà
Yóò tógbàá sìn 
Ká tó tún dé (ojú ìwé 34)
·       
Ọwọ́ tí mo nà, déédé ọwọ́ mi ọ̀pá ṣe, ni a bá bẹ̀rẹ̀
sí lọ́ ọ̀pá mọ́ ara wa lọ́wọ́, ó di gìdìgìdì (44)
·       
Bí a bá wí pé kí á wo ti Pẹ̀là, ijó
yóòbàjẹ́ o, bẹ́ẹ̀ ni Pẹ̀là ni ó sì ni ijó (ojú ìwé 14)
·       
Mo sun iṣu jẹ lóko olóko (ojú ìwé 31)
·       
Ọmọ náà nù un, kò gbọdọ lọ, bí ó bá lọ,
ẹ kẹ́ran (ojú ìwé 38)
·       
Gbogbo èyí tí mo rán an àti èyí tí n kò rán an,
gbogbo rẹ̀ ni ó wí (ojú ìwé 52)
·       
Àárẹ̀ ara àti àárẹ̀ ọkàn (ojú ìwé 54)
·       
“Ta ni jẹ́ bímọ tirẹ̀ kó sọ ọ́ lẹ́rú (ojú ìwé 
·       
Ta ní jẹ́ bímọ tirẹ̀ ní ìwọ̀fà?”  (ojú ìwé 85
·       
Lágboókùn, Lágboókùn!
Kòtò rèé!
Gegele rèé!
Òkú kò rí kòtò sá
Gegele rèé!
Kòtò rèé!
·       
“Ìbòsí ayé bàjẹ́ o... o... o... 
Ìbòsí ayé bàjẹ́ o... o... o (ojú ìwé 114)
·       
A kìí sa ginni lọ́gbẹ́
A kìí dàràbà lókùn
A kìí gbọ́wọ́ fújà sálágẹmọ
Ó dèèwọ̀” (ojú ìwé 115)
·       
Báálẹ̀ ìlú kéréje–kéréjé tí kò jìnnà sí òkò ń wọ
ààfin wá láti kí Olúmokò
·       
Arinládé
Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mà tọ́wọ́ rẹ
Arinládé
Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mà tọ́wọ́ rẹ
Ijó tó o jó lánàá
Tóo fi lọ fẹ́nìkan
Arinládé
Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mà tọ́wọ́ rẹ” (ojú ìwé 164)
Àdàpè (Euphemism)
Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí ó jẹ́ wí pé àwọn Yorùbá kìí kàn sábà là mọ́lẹ̀, wọ́n
máa ń da irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pè ní. 
·       
Dáwọ́tẹlẹ̀ (ojú ìwé 6) (Dáwọ́tẹlẹ̀ yìí sì túmọ̀ sí wí
pé kí ènìyàn lọ yàgbẹ́)
Yàtọ̀ sí àwọn ọnà-èdè tí a ṣàmúlò nínú ìwé ìtàn àròsọ yìí, bẹ́ẹ̀ náà ni
a ni àwọn òwe tí òǹkọ̀wé yìí ṣe àmúlò tí ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀
ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé nínú ìwé yìí. Ìwọ̀nyí ni àwọn
òwe náà:
(i)               
“Ṣe ọ̀rọ̀ àròkàn ni ó fa ẹkún àsun-ì-dákẹ́” (ojú ìwé
3)\
(ii)            
“A kìí wí pé ọmọ tí yóò bá hu eyín gangangan kí ó má hù
ú, nígbà tí ó bá hù ú tí kò rí ètè fi bò ó ni yóò tó mọ̀ wí pé kò dára” (ojú
ìwé 8)
(iii)          
“Ẹni tó ní pé kí ará ilé òun máà lówó, ará òde ní íyá
olúwa rẹ ni ìwọ̀fà” (ojú ìwé 11)
(iv)          
“Ọmọ osè níí kó kùmọ̀ bá ìyà rẹ̀” (ojú ìwé 13)
(v)            
“bí a rán ní níṣẹ́ ẹrú, a fi tọmọ jẹ́ ẹ” (ojú ìwé
13)
(vi)          
“Bá mi na ọmọ mi, kò sá dénú ọlọ́mọ” (ojú ìwé 14)
(vii)       
“Ebi kìí wọnú, kí ọ̀rọ̀ míì wọ̀ ọ́” (ojú ìwé 16)
(viii)     
“Ọ̀bẹ kò dára lọ́rùn, kádàrá ni màlúù gbà” (ojú ìwé 22)
(ix)          
“Kí odi lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ní a ṣe sọ ọ́ lójú ọmọ rẹ̀”
(ojú ìwé 23)
(x)            
“Pípẹ́ ni yóò pẹ́, akólòlò yóò pe
baba” (ojú ìwé 24)
(xi)          
“Bí a bá sì rí ọlọ́rọ̀ ẹni, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni à á dà”
(ojú ìwé 31)
(xii)       
“Bólórìṣà kò kú, a kì í gbàbọ rẹ̀ bọ” (ojú ìwé 53)
(xiii)     
“Oorun kò sá mọ ikú, ìpàkọ́ kò gbọ́ sùtì” (ojú ìwé 64)-
“bí 
(xiv)     
Bí a dákẹ́, tara ẹni a báni dákẹ́” (ojú ìwé 102)
(xv)       
“Bájá gbé ogún ọdún láyé, ẹran ògún ni” (ojú ìwé 143)
(xvi)     
“bí ó pẹ́ títí, ogún ọdún ń bọ̀ wá ku ọ̀la” (ojú ìwé
162)
(xvii)  
“Etí tó bá gbọ́ àyún níí gbọ́ àbọ̀” (ojú ìwé 163)
Ìwé ìtọ́kasí
Adébáyọ̀ F. (1970). Ọmo-Olókùn Ẹsin. Heinemann Educational Books
(Nigeria) Plc.
No comments:
Post a Comment