Nínú ìwé iré oníṣe Àtàrí Àjànàkú láti ọwọ́
Lawuyi Ògúnníran kọ dálé ìlú Gbándú tí Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ṣe alákoòso
ìlú náà tí ó wà lábẹ́ ìlú Ọ̀yọ́[1].
Àwọn ìjòyè àti Baálẹ̀ ń ṣe ìpàdé lórí bí wọn yòó ṣe gba àlejò ìlàrí Mábọlájé
tí Aláàfin Ọ̀yọ́ rán sí ìlú Gbándú láti mójú tó ohun tí àwọn Baálẹ̀ àti ìjòyè
bá se ní ìlú kí ó sì jábọ̀ fún Aláàfin Ọ̀yọ́. Nínú ìpàdé yìí ni a ti rí
Jagunlabí tí ó jẹ́ ìránsẹ́ Baálẹ̀ Gbándú, Ọ̀tún Baálẹ̀ Gbándú, Òsì Baálẹ̀
Gbándú, Balógun Baálẹ̀ Gbándú, Ṣéríkí Baálẹ̀ Gbándú àti Ìyálode Baálẹ̀ Gbándú.
Baálẹ̀ àti àwọn ìjoyè rẹ̀ ró gẹ́gẹ́ nínú aṣọ wọn, wọ́n ń retí Mábọlájé tí
se ìlàrí tuntun tí Aláàfin rán sí ìlú wọn, ṣùgbọ́n kí ìlàrí tó dé, àwọn Baálẹ̀
ti se ìpàdé bí ìlàrí tuntun kò se níí dí wọn lówó láti rí ọlá kó jọ, pé owó
tí ìlàrí Mábọlájé bá gbé ni yóò sọ ohun tí wọn yóò se fún, pé bí ìlàrí Mábọlájé
bá gbé ọwọ́kọ́wọ́, wọn yóò ṣe bí wọ́n ṣé ṣe ìlàrí àkọ́kọ́ pé ọ̀nà ọ̀run ni
yóò ti ma pàṣẹ rẹ̀.
Inú ìlàrí Mábọlájé dùn fún ayẹyẹ tí àwọn
Baálẹ̀ àti ìjòyè rè ṣe fún un, àwọn oríṣìí ọtí àti ẹran ni wọ́n fi ṣe
àlejò rẹ̀. Gòngòbíàgbà tí ó jé asojú ìlú Gbándú wà ní ibi ayẹyẹ naa. Mábọlájé
mu ọtí yó bìnàkù, o ń se bí ẹlẹ́gún òrìṣà, àwọn ìjòyè náà ń mu ọtí. Lẹ́yìn
ayẹyẹ tí wọ́n ṣe fún ìlàrí  Mábọlájé,
Baálẹ̀ pe àwọn ìjòyè rè fún ìpàdé lórí ìgbéṣẹ̀ tí ó fẹ́ gbé pé ó yẹ kí òun Baálẹ̀
ní ọlá kún ọlá, dúkìá pàtàkì àti owó pẹ̀lú àwọn ìjòyè òun. Ìgbéṣẹ̀ Baálẹ̀
ni pé kí àwọn ara ìlú Gbándú máa san ìsákọ́lẹ̀ fún Baálẹ̀  ní ẹ̀ẹ̀meji lódún àti pé àwọn ara ìlú yóò
máa dáko nlá kọ̀ọ̀kan fún Baálẹ̀ àti ìyàwó rè, àwọn ìjòyè àti gbogbo ọmọ tí wọ́n
bá bí. Ọ̀kan lára àwọn ìjòyè tí ó ń jé Ọ̀tún kò fara mó ìgbésè tí Baálẹ̀ fé
gbé yìí pé ìyà n je ara ìlú kí wọ́n máà tún gbé ẹrù wúwo lé ara ìlú lóri. Ọ̀rọ̀
yìí dájà sí àárín  Baálẹ̀ àti Ọ̀tún. Lẹ́yìn
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ àti ìpàdé, àwọn ìjòyè fara mọ́ ọ̀rọ̀ Baálẹ̀, wọ́n sì rán
Jagunlabí kí ó lo jísé Baálẹ̀ fún àwọn ara ìlú. Kàkà kí Jagunlabí dé pèlú
ìròyìn, n se ni ó sunkun wọlé, ibi tí Jagunlabí ti n se ìkéde ni àwọn ara ìlú
náà an bí ejò àìjẹ, ó sì ròyìn nnkan tí àwọn ara ìlú sọ.
Lẹ́yìn èyí, àwọn ìlú rán asojú wọn,
Gòngòbíàgbà, kí ó lo sọ fún ìlàrí Mábọlájé ohun tí Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀
dálásà. Gòngòbíàgbà gbéra lo sí ilé ìlàrí láti lọ jísẹ́ tí ìlú ran an. Ìlàrí
ránṣẹ́ pe Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rè láti gbó tenu wọn nítorí èsùn tí àwọn
ara ìlú fi kàn wọ́n. Ìlàrí pe Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ láti sọ nǹkan tí wọ́n
ri tí wọ́n fi gbé ìgbésì tí wọ́n gbé.  Lẹ́yìn
gbogbo ẹjọ́ Baále àti Gòngòbíàgbà, ìlàrí Mábọlájé sọ́ fún Gòngòbíàgbà pé kí ó
sọ fún àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù nípa àbájáde ìpàdé wọn, kí àwọn ọ̀dọ́ sowọ́ pọ̀
pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà kí ìlú baà lè ní ìtẹ̀síwájú, ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí
ìlàrí ṣọ yìí kì í ṣe ohun ti ìlú fẹ́ gbọ́ nítorí ìlàrí ti mọ ohun tí yóò
kan òun nípa ìgbésè tí àwọn Baálẹ̀ fẹ́ gbé.
Àwọn ọ̀dọ́ ìlú bíi Jẹ́nríyìn, Ariwoọlá,
Ayọ́mẹ́yẹ́, Tọ̀yọ́bò, Ìgbàróọlá àti Gòngò tí gbogbo wọ́n jé ọmọ olóyè ìlú
Gbándú ti se ìpàdé lórí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe fún àwọn olóyè àgbà nítorí pé wọ́n
ti gbọ́ nǹkan tí àwọn Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní wọn yóò ṣe sí àwọn ọ̀dọ́
pé pípa ni wọn yóò pa gbogbo wọn. Àbájáde ìpàdé àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí
oníkúlùkù wọn pa bàbá rè kí wọ́n sì bó sí ipò naa. Lẹ́yìn èyí àwọn ọ̀dọ́ gba
ipò baba wọn, wọ́n sì í sèlú ní òye tiwọn. Lẹ́yìn ọdún kan, orísirísi nǹkan
bẹ̀rẹ̀ sí níí ṣẹlẹ̀; àwọn ará ìlú ran aṣojú wọn sí Arápáyagi láti fi ẹ̀dùn
ọkàn wọn hàn wọ́n nítorí ọ̀rọ̀ kò yé àwọn Gòngò àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ mọ́,
ìlú tí bàjẹ́ mọ́ wọn lórí; nǹkan kò lọ dáadáa fún àwọn ara ìlú mọ́, àìsàn
gba gbogbo ìlú. Àwọn ìlú kígbe pé àsà ìlànà ètò ìsèlú tuntun tí àwọn Gòngò
gbé wọ ìlú ló fa gbogbo àjálù burúkú tori pé wọ́n pa gbogbo òrìṣà wọn run, wọn
kò jẹ́ kí wọ́n bọ wọ́n mọ́.
Ní ààfin Aláàfin Ọ̀yọ́, ọba n se
àsekágbá odún bebe. Ọba gúnwà nínú aṣọ ńlá rè, méjì nínú àwọn Ọ̀yọ́mèsì,
Basọ̀run àti Àgbàakin, jókòó sí tọ̀túntòsì rè. Ọ̀tún-Ẹ̀fà di oríṣirísi oògun
mọ́ra ó sì bó sí iwájú ọba láti kéde ètò náà an. Ọba se ìlérí pé òun yóò dá
ẹnikẹ́ni lọ́lá tí ó bá ṣe ohun tí ẹnikẹ́ni kò se rí. Ọkùnrin kan tó ń jé
Ogúnléndé jáde láti pindán ọwọ́ rẹ̀. Ogúnléndé korin, ó pofò lorisiri ó si yege
ìdánwò ti ọba gbe fún un. Níbi ayẹyẹ ni wọ́n wà tí wọ́n gbó ohùn kan tí ó ń ké
bò láàfin pé òtè dé! ikú dé!; àwọn ènìyàn dà gììrì, ìbèrù bojo dé, àwọn ìjòyè
dòsùùrù bo oba, wọ́n rora fèyin pon ọba wolé, ó ku Basórun, Àgbàakin àti
Ogúnléndé sílè ní ìgbáradì. Ìbèrù dé bá àwọn ìjòyè náà pèlú, oníkálùkú ba igun
kọ̀ọ̀kan lọ, ìbẹ̀rù mú Ogúnléndé náà ó wá ibi gó sí. Òná ibi tí Àgbàakin n bá
lo ni eni náà yo gbùlà sí ìgbéjó. Ó ní ìlú Gbándú ti dàrú, àwọn ọ̀dọ́ ti pa
gbogbo àwọn ìjòyè ìlú pátá, wọ́n ti se ohun tí ẹni kan kò ṣe rí, wọ́n sì ti
dá irú ìjọba tí wọ́n n se ní Kónkónbìló sílè. Ọ̀rọ̀ yìí ya gbogbo àwọn ènìyàn
lénu; ọba béèrè lọ́wọ́ ìlàrí tí ó ń ròyìn yìí pé kí ni ohun tí àwọn ọ̀dọ́ ni
àwọn àgbà ṣe fún wọn; ó ní wọ́n sọ pé àwọn náà fẹ́ máa ṣe ìjọba; àwọn
ìjòyè gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí. Aláàfin àti àwọn Ọ̀yọ́mèsì ṣe
ìpàdé lórí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣe ìwádìí abẹ́nú lórí ọ̀rọ̀ náà kí
wọ́n tó lè mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
Aláàfin rán Ọ̀tún-Èfà sí ìlú Gbándú láti
jé isé tí ọba ran sí àwọn ìjòyè pé okùn esin tí wọn fi okà ran ni òun fé gbà
fún ti odún náà, kí wọn sì fi ránṣẹ́ kí ìtàdógún tó pé, bíbẹ́ẹ̀ kó, ìparun ni
yóó gbẹ̀yin rẹ̀. Gòngò àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ kò mọ ohun tí wọn yóò ṣe, wọn
kò mọ ìtumọ̀ okùn ẹsin tí Aláàfin ní kí wọ́n mú wá, Tọ̀yọ́bò mú ìmọ̀ràn kan
pé kí wọ́n ránṣẹ́ sí Aláàfin kí ó fi irú okùn ẹsin tí ó fẹ́ hàn wọ́n. Kò pé
rara, Aláàfin rán Ọ̀tún-Èfà kí ó lo kó àwọn Gòngò àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ wá,
ẹ̀rù ba Gòngò débi pé ó n tò sára, ìránṣẹ́ ọba kó àwọn Gòngò lọ sí ìlú
Ọ̀yọ́ láti lọ sọ ohun tí wọ́n rí tí wọ́n fi wa irú sówó. Nígbà tí àwọn Gòngò,
Tọ̀yọ́bò, Jẹ́nríyìn, Ariwoọlá, Ayọ́mẹ́yẹ, àti Ìgbàróọlá dúró sí gbé kan níwájú
ọba, ìlàrí náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, Aláàfin sì bèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn ohun tí
wọ́n ṣe sí àwọn àgbà ìjòyè ìlú Gbándú; gbogbo wọn sọ tẹnu wọn, yàtọ̀ sí
Tọ̀yọ́bọ̀ tí kò pa baba rè, Ọ̀tún; ọba fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn wọ́n, ṣùgbọ́n
àwọn Ọ̀yọ́mèsì bẹ Aláàfin kí ó dárí jì wọ́n, nítorí pé gbogbo àwọn àgbà
ìjòyè ìlú Gbándú ni ó jẹ̀bi. Yorùbá máa ń pa òwe pé ọmọdé kò lè mọ ẹ̀kọ
jẹ kí ó má yìí lọ́wọ́ pé àìmọ̀ ló ṣe wọ́n, wọn kò mọ̀ pé igi kan kò lè dágbó
ṣe àti ọmọdé àti àgbà ni wọ́n nílò ara wọn kí ìlú bàa lè ní ìtẹ̀síwájú.
 ÀWỌN ÌLÒ ÈDÈ NÍNÚ ÀTÀRÍ ÀJÀNÀKÚ
ORIN:                        Láwú erebe, erebe láwú
Láwú
erebe, erebe láwú
N
bá mọlé, n bá yà
Àìmọ̀lé
ló se mi o
Ẹ
kú àtijọ́!
Ara ò le bí?
Ekú àtijọ́!
Ara ò le bí ?
Gbándú, ẹ kú àtijọ́
Baálẹ̀, e kú àtijọ́
Ọ̀tún, e kú àtijó
Ara ò le bí ?
Igijégédé
Baba Táyélolú !
Ẹnìkan lèsù ó ṣe
Kí ajá ó dúró
Kí ìkookò ó dúró
Ẹnìkan lèsù ó ṣe
Igijẹ́gẹ́dẹ́
Baba Tayelolú !
Bámúbámú la yó
Àwa ò mọ̀, pé ẹbi n pa ọmọ ẹnì kọ́ọ̀kan
Bámúbamú la yó
ÒWE: Nínú  idán kìn-ín-ní, ìran kìn-ín-ní
Ààbò ọ̀rọ̀  sì ti
tó fún ọmọlúàbí, bó bá dé inú rẹ̀, á di odidi
          A kì í lọ́kọ́ nílé ká fọwọ́ kómí
          Àwárí lobìnrin n wá nǹkan ọbẹ̀
          Àgbàlagbà tí kò bá tijú láti gun
kétékété, 
kétékété náà kò ní tijú láti da àgbàlagbà mọ́lẹ̀
         Baba jóná, è n bèèrè irùngbòn
Nínú idán
kejì, ìran kìn-ín-ní
          Ẹni tó rán ni níṣẹ́ là á bẹ̀rù, a
kì í bẹ̀rù ẹni tá a jíṣẹ́ fún
          Bí apá kò bá ṣe é ṣán, à máa ka à
lérí
          Igi kan kì í jẹ́ igbó
                              Ìran kejì
Àìfèteméte, àìfèròmerò ní í mú kí àgbàlagbà mẹ́fà kú sóko
ẹgbaafà
        Àìfàgbà-fẹ́nikan ni kò jáyé ó gún
        Àgbàjọ-ọwọ́ lafi í sọ̀yà
                     
Ìran keta
        Alátiṣe ni í màtiṣe ara rẹ̀
        Bí igi bá wólu igi, tòkè rè la kọ́kọ́
gbé
Nínú idán keta,
ìran kìn-ín-ní
       A kì í fi iná sórí òrùlé sùn 
        Ibi tí ó bá wu ẹ̀fùfùlẹ̀lẹ̀ ní í darí
igbé sí, ibi tó wu olówó ẹni ní í rán ni lọ
       A kì í bá ni tan, ká fa ni ní itan ya 
ÀWỌN ỌNÀ ÈDÈ TÍ Ó WÀ NÍNÚ ÀTÀRÌ ÀJÀNÀKÚ
Àfiwé tààrà
Fi ilẹ̀ bora
bí aṣọ
Ilẹ̀
Babaláàfin ṣe lọ rereere bí ọlá Ọlọ́run 
        Nse ni wọ́n tòsì bí ìtélèdí
        Tójú pọ́n wọn bí kórí isin
Ó n gùn mí gàràgàrà bí alángbá gògiri
Ó n tu kiri bí ejò
            Kó
máa kó wa tà bí àgùtàn
Ogunniran L. (1987). Àtàrí Àjànàkú. Ibadan: Evan
Brothers (Nigeria Publishers) Ltd..
No comments:
Post a Comment