a.
Àwọn
ọmọ náà rí wọn fín.
The children held them in contempt.
b.
Ṣolá
rí òòṣà fín. (Ṣọlá kórira òòṣà)
Ṣọlá has contempt for idol.
2.
Rígbà:
to receive, to obtain
a. Ó rí i gbà.
He was able to receive it.
b. Ó rí àánú gbà.
He obtained mercy (Ó rí àánú gbà)
3. Ríhe: to find, to find and pick up what is lost.
a.Ó
rí owó
náà he.
He found and picked up the money that
was lost.
c.
Ó
rí ọlá he.
He found wealth.
4.
Ríjẹ:
well-off, well-to-do, rich
a.
Ó
ríjẹ.
He is rich.
b.
Kọ́lá
ríjẹ.
Kọ́lá is well-off
c.
Bádé
ríjẹ.
Bádé is well-to-do.
5.
Rín,
Rẹ́rìn-ín: to laugh
a.
Bádé
rẹ́rìn-ín
Bádé laughed.
6.
Rìkísí:
conspiracy, plot, intrigue
a.
Wọ́n
ń di rìkísí mọ́ ọn.
They are plotting against him.
b.
Wọ́n
di rìkísí mọ́ ọn.
They conspired against him
c.
Rìkísí
ni ohun tí Bọ́lá ń lé pa
Intrigue is what Bọ́lá is up to.
7.
Rin:
damp, moist, humid
a.
Yàrá
yìí ń rin
This room is damp
b.
Ilẹ̀
ń rin.
The floor is moist
8.
Rìn:
to tickle, to walk, to travel
a.
Ó
rìn lọ sí ilé.
He walked home.
b.
I
tickled him.
Mo rìn ín ní jàkì/Mo rìn ín ní ìgàkín.
c.
Ṣọlá
rìnrìn àjò.
Ṣọlá travelled.
9.
Rin: to grate (cassava), to squeeze
against
a.
Wọ́n
rin ẹ̀gẹ́
They grated cassava.
b. Wọ́n rin ín mọ́ ẹ̀yin ọkọ̀.
They squeezed her against the back of
the car.
10. Rìngbẹ̀rẹ́:
to walk slowly or lazily
a. Ó ń rìn gbẹ̀rẹ́.
He is walking slowly
b. Ó ń rìn gbẹ̀rẹ́.
He
is walking lazily.
11. Ringbindin:
to soak, to be very wet
a. Ó rin gbindin.
It is very wet.
b. Fóòmù náà rin gbindin.
The foam is soaked.
12. Rìn hẹ́bẹ́hẹ́bẹ́: to waddle, to walk like the duck
a.
Ó
ń rìn hẹ́bẹ́hẹ́bé.
He is walking like a duck.
b.
Kóyè
rìn hẹ́béhẹ́bé kọjá omi náà.
Kóyè waddled across the water.
13. Rìnká, Rìn káàkiri: to stroll about, to roam about, to walk about
a.
Wọ́n
ń rìnká.
They are walking about.
b.
Wọ́n
rìn káàkiri.
They roamed about.
c.
Wọ́n
rìn yíká àdúgbò.
They strolled about the street.
14. Rìn kiri: to rove about, to wander
about
a.
Ó
ń rìn kiri.
He is wandering about.
b.
Ó
ń rìn kiri bíi aláìnílé.
He is roving about like a homeless
person.
15. Rìn lẹ́dọ̀: to nauseate
a.
Òórùn
ẹran náà ń rì mí lẹ́dọ̀.
The smell of the meat nauseates me.
16. Rìn lọ, Rìn wò, Rìn yíka: to go round the boundaries of
a.
Ó
rìn yíká oko rẹ̀.
He went round the boundaries of his farm.
17. Rinrin: Very Heavy (qualifying wúwo)
a.
Òkúta
náà wúwo rinrin
The stone is very heavy.
18. Rírà: Purchasable, buying
a. Iṣẹ́ ìwé rírà àti títà ni ó ń ṣe.
He is buying and selling books.
b. Rírà ní owó ńlá ni aṣọ náà jẹ́.
The clothes are purchasable with a high price.
19. Rírà: Putrid, rotten
a. Ẹ̀fọ́ rírà ni ó rà.
She bought rotten vegetables.
b. Òórùn-un rírà ló ní.
It has a putrid smell.
20. Ríìran: to see
a. Mo ríìran.
I saw a revelation.
No comments:
Post a Comment