Nínú ìwé yìí a
rí Baálẹ̀ tí àwọn ará ìlú máa ń pè ní Agbàlọ́wọ́ọméri; nítorí ìwà ọ̀kánjúwà
tí ó maa n wù ni wọ́n se n pe bẹ́ẹ̀, orúkọ rẹ̀ gan-an ni Àgbákànmí ṣùgbọ́n kò
wu ìwà àgbà rárá[1].
Agbàlọ́wóoméri ní òré tí ó ń jé Moríyiná, ó jẹ́ asíndẹ ní ìlú Jòntolo, ó sì
maa n se amín ohunkóhun tí ó bá ń lọ ní ìlú fún Baálẹ̀ Agbàlọ́wọ́ọméri. Ní
ojọ́ kan tí Moríyiná lọ ta fìlà idẹ kan fún Baálẹ̀ ni ó ṣè ṣe òfófó fún Baálẹ̀
pé òun rí Aseeremasika tí ó gbé òkú oníbàárà lo sin sínú igbó ní òru mọ̣́jú. Baálẹ̀
bèèrè pé ṣé ó dá Moríyiná lójú nǹkan tí ó sọ fún òun, Moríyiná ní ìyàwó òun
ni ẹlẹ́rìí. Baálẹ̀ ránṣẹ́ pe Aseeremasika àti ìyàwó rẹ̀ Olásùmíbò láti gbó
tenu won. Kí Aseere àti ìyàwó rẹ̀ tó dé ilé Agbàlọ́wọ́oméri, òyì ojú ti ko
Agbàlọ́wọ́ọméri, tí wọ́n da omi lé e lórí kí ó tó jí, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n ti
Aseere àti ìyàwó rẹ̀ mo ẹ̀wọ̀n di ìgbà tí ara òun yóò fi yá. 
       
Ọjọ́ ìdájọ́ pé, Aseere àti ìyàwó dúró ní wájú Baálẹ̀ láti sọ tẹnu wọ́n
nípa ẹ̀ṣùn tí wọ́n fi kan an. Aṣeere jẹ́ ẹni rere ní ìlú Jòntolo nípa ìwà ọmọlúabi
tí ó ní sí àwọn ará ìlú. Aseere  jẹ́wọ́
pé lóòótọ́ ni òun gbé òku oníbàárà lọ sin sínú igbó ṣùgbọ́n oun kọ́ ni ó pa á,
pé oore ni òun ṣe nígbà tí òun rí i ní ẹ̀gbẹ́ igbó tí òtútú mú un ni òun ràn
án lọ́wọ́, ṣùgbọ́n lẹ́yìn gbogbo aájò òun, ó pàpà kú. Moríyiná àti Kìmí Àdúgbò
tí ó jẹ́ olóyè pàtàkì kan ní ìlú Jòntolo ti ọ̀rọ̀ sẹ́nu Aṣeere pé se ni ó pa
oníbàárà nítorí owó, Aseere jẹ́wọ́ pé àpótí ni oníbàárà òun gbé fún òun. Baálẹ̀
ní kí wọ́n lo gbé àpótí náà ní ilé Aseere; nígbà tí wọ́n máa ṣí àpótí náà,
wọ́n bá àjágbó ẹní àti àkíláya àtùpà elépo nínú rẹ̀. Nítorí pé Agbàlọ́wọ́ọméri
àti àwọn ìjòyè rẹ̀ kó rí nǹkan gbà lọ́wó Aseere, ó pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ọmọlanke
Aṣeere tí ó fi n gbàárù sí àgbàlá òun Baálẹ̀. Aṣeere n be gbogbo wọ́n ṣùgbọ́n
wọ́n kò dá a lóhùn.
          Léyin oṣù kan, ní ilé Baálẹ̀, a ri
tí wọ́n de apá Aseere sẹ́yìn àti ìyàwó ní ẹ̀gbẹ́ kan tí Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè
rẹ̀ n ṣòrò nípa ohun tí wọ́n sọ pé Aṣeere ṣe nípa ọ̀rọ̀ góòlù. Baálẹ̀ fi
èsùn olè kan Aseere pé ibo ni ó ti rí góòlù àti aṣọ tí ìyàwó rẹ̀ Olásùmíbò n
wò àti pé ibo ni ó ti rí góòlù tí ó fún àwọn oníbàárà. Aseeremasika tọrọ àyè
pé kí àwọn obìnrin tí ó wà níbè jade kí òun lé ṣọ ibi tí ó ti rí góòlù, wọ́n
jade, ó ku àwọn ọkunrin níkan síbẹ̀. Aṣeere ní òun gbọ́ tí àwọn kan sọ̀rọ̀
nípa àjágbó ẹní àti àkíláya àtùpà kan pé ẹni tí ó bá rí i gbé pé ẹni náà ti
di olówó, pé ìdí ìrókò kan nínú igbó ni ẹni náà yóò ti lo àwọ́n nǹkan méjeèjì
yii. Aseere ní òun pe òré òun, Àdìgún, làti fi tó o létí nǹkan tí òun gbó
nítorí pé ọdẹ ni Àdìgún; àwọn méjeèjì sí gba inú igbó lọ, nígba tí wọ́n dé
ìdí igi, wọ́n tan àtùpà yii, ilẹ̀kùn kan sí lára igi náà, wọ́n wọnú rẹ̀, wọ́n bá
oríṣirísi ohun mèremère bíi góòlù nínú igi náà. Baálẹ̀ ní kí Aṣeere àti
Àdìgún mú òun dé ìdí igi ìrókò yìí láti rí i pé òtítọ́ ni wọ́n ṣọ fún òun.
            Ní ojọ́ kejì, Agbàlọ́wọ́ọméri ránṣẹ́
pe ọmọ rẹ̀ Àkéjú láti sọ nípa ọ̀rọ̀ góòlù fún ọmọ rẹ̀ pé tí owó wọ́n bá lè
te àsírí náà pé ìrandíran wọ́n kò tòsì mó laélaé. Baálẹ̀ ní ònà láti pa Aseere,
Àdìgún àti Moríyiná ni òun pè e fún kí gbogbo ìsúra náà jé ti òun àti ìdílé
òun. Àkéjù ní òun yóò rán àwọn kan láti pa wọ́n nígbà tí wọ́n bá n ti igbó bò
ní alé, ṣùgbọ́n kí Baálẹ̀ àti Kìmí so màrìwò mó orí fún àmì ìdánimọ̀ sí àwọn
ìyókù nígbà tí wọ́n bá ń ti inú igbó bò. Nígbà tí wọ́n dé inú igbó, wọ́n tan
iná sí àtùpà, ilèkùn igi náà sí. Moríyiná àti Kìmí wo inú rẹ̀ láti kó góòlù,
àpò mewa ni Baálẹ̀ mú dání láti kó góòlù. Aseere àti Àdìgún ti kó ìwònba ti
won, ṣùgbọ́n Baálẹ̀ ní ìgbàtí àpò mewa tí òun kó wá bá tó kún ni àwọn tó máa
lọ, béè iná àtùpà kò jó daadaa mó. Àdìgún so fun Baálẹ̀ pé iná kò jó daadaa
mó. Baálẹ̀ bínú sọ̀rọ̀ sí Àdìgún pèlú ìbínú ó sì tèlé  Kìmí àti Moríyiná bí ó ti n kojá, ó fi ojú
burúkú wo Aseere, ó sì ta Àdìgún nipa kúrò lọ́nà, Àdìgún pògìrá subú lu àtùpà, àwọn
mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wo inú ihò lo léyìn igi ìrókò. Nǹkan kan dún gbàù lésè kan náà,
ilèkùn ihò náà ti tì, àtùpà sì ti fó. Baálẹ̀ àti àwọn yooku rẹ̀ kò lè jade mó.
Ara ta Aseere ṣùgbọ́n kò sí nǹkan tí òun tàbí Àdìgùn lè ṣe sí i, Baálẹ̀ ni ó
fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ara rè. Ìwà ojú kòkòrò àti ìmọ-ti-ara-ẹni ni ó pa Baálẹ̀,
Kìmí àti Moríyiná. Aseere àti Àdìgùn múra láti máa lọ ilé ṣùgbọ́n Àdìgún ní
ara fun òun nípa màrìwò tí Baálẹ̀ àti Kìmí fi sí orí pé kí àwọn náà fi màrìwò
sí orí pé bí ó bá jé àmì oyè ni nítòótọ̣́, àwọn náà kò ní ẹ̀ẹ̀wọ̀ oyè. Nígbà
tí wọ́n dé ònà wọ́n pàdé ode meji, wọ́n ṣe bí ẹni fé ta ofà owó wọn ṣùgbọ́n
wọ́n n wo màrìwò orí wọn. Àwọn ode meji yìí béèrè àwọn yooku wọn, Aseere
àti Àdìgún ní àwọn kò rí àwọn tó kù, Àdìgún bèrè lówó ode keji nǹkan tí wọ́n
n wá kiri nínú igbó, kàkà kí ode náà dáhùn, ohùn arò ọdẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ,
Àdìgún náà fi ohùn arò ode dáhùn padà, ọdẹ keji so ohun tí ó gbé wọ́n wá sí
inu igbó pé ọmọ Baálẹ̀ Àkéjù ni ó rán wọ́n láti pa àwọn kan pé baba òun yóò
wà níbè ṣùgbọ́n yóò so màrìwò mó orí, ṣùgbọ́n àwọn tí kò bá so màrìwò mó orí
ni kí wọ́n ta lọ́fà. Àsírí Baálẹ̀ tún sí Aseere àti Àdìgún lọ́wọ́, wọ́n sì sọ fún
àwọn ọdẹ pé àwọn náà ni wọ́n n dúró dè.
            Aseere àti Àdìgún padà dé ìlú,
ìròyìn ti tàn lọ pé Baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ kan ti kú pé Aseeremasika ni
wọ́n tèlé lo sí inú igbó kan lóru tí àwọn ọdẹ kan sì ta Baálẹ̀, Kìmí àti
Moríyiná lófà, wọ́n sí kú. Aseere àti òré rẹ̀ nìkan ni ó yè. Gbogbo ara ìlú fi
ìbínú wọ́n hàn pé wọ́n fé rí Àrẹ̀mọ Baálẹ̀, kí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu
Aseeremasika. Nígbà tí Àrèmọ máa sọ̀rọ̀ ó ní Aseere pa ènìyàn kan ni baba òun
ní kí ó mú òun dé ibi tí ó sín ẹni náà sí. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún Aseere irú
irọ́ tí Àrèmọ pa moó ọn. Aseere sì sọ̀rọ̀ pé ọ̀rọ̀ kò rí bí Àrẹ̀mọ ṣe só,
pé Àrẹ̀mọ mó nípa ìrìnàjò lọ sí inú igbó, pé gbogbo aṣọ, owó àti góòlù tí
òun rí kó nínú igbó ni Àrẹ̀mọ ti wá kó nílé òun mójú. Àwọn ara ìlú bèèrè lówó
Àrẹ̀mọ ṣùgbọ́n kò rí nǹkan sọ, gbogbo ẹrù yi ni wọ́n bá nílé Àrẹ̀mọ. Àwọn
ara ìlú pinu pé àwọn kò lè fi Àrẹ̀mọ Àkéjù ṣe Baálẹ̀ ìlú, pé Aseeremasika ni
àwọn fé kí ó je Baálẹ̀ ìlú wọ́n nítorí oníwà rere ni Aseere jẹ́ láàrín ìlú.
 ÀWỌN
ÌLÒ ÈDÈ TÍ ONKỌ̀WÉ LÒ NÍNÚ ÌWÉ ERÉ ONÍṢE AGBÀLỌ́WỌ́ỌMÉRI
BAÁLẸ̀ JÒNTOLO.
ÌREMỌDẸ
Èyí
wáyé laarin Àdìgún àti àwọn ọkùnrin ọdẹ méjèèjì tí wọ́n n fi ohùn arò ode
bára wọ́n sọ̀rọ̀.
                                   Ọdẹ kì í
kako, ọdẹ kì í ka kàkò
                                   Ọdẹ kì í
se ẹnu fóró fóró fóró
Sọ ohun ikùn
sílè bi òdìdè nínú oko
                                    Mo ti perin
nínú igbó o
                                    Mo ti pẹfọ̀n  ní àbàtà
                                    Mo ti pa túrùkú ẹlẹ́dẹ̀ ẹgàn
                                    Ẹranko tó
tó ẹranko
                                    Emi kò wá
mọ kálé sòsòrò sí igbó
                                    De ọmọ
elọ̀míràn bí ẹranko nínú ugbó.
                                    Bí ewúrẹ́
bá rí olóore a sáré wá o
                                    Bí ajá
gòlòtò rí ẹni n bá je kí á yio ju ìrù
                                     Bí àgùtàn
pòpó rí ẹlẹ́ẹ̀rí yio rìn mó ọ
                                     Àjobó òròkí olóúnjẹ kò yá á lù pa
Ẹ seun, a fé máa lo.
                                     ẹni se rere kó máa sé lọ
                                     ẹni se ìkà kó má fi sílẹ̀
                                     Oore ló
pé, ìkà kò pé e jòwó jàre ẹlẹ́gbẹ́ wa.
ORIN
 Èyí wáyé nígbà tí àwọn
ará ìlú Jòntolo fi Aseere jẹ ọba.
                                   Se rere o,
se rere ! oore ló pé ìkà kò pé, se rere, se rere,
                                   Ìkà yio pa
oníkà o, ire á bi ẹni rere,
                                   Ohun tí a bá
gbìn nínú ayé o,
Yio so, yio so, ọmọ
yin yio je níbẹ̀.
ÒWE
A
ri àwọn òwe ti òǹkọ̀wé lò nínú ìwé Agbàlọ́wọ́méri
Baálẹ̀ Jòntolo
                Ìran Kinní
                                      Ewú
logbó, ìrùgbọ̀n làgbà, mamu ni ti àfojúdi
                                       Bí a bá
n pa èèpo osè ara ní í fi í san
                                       Etí ọba
nílé, etí ọba lóko
                 Ìran Kejì
                                       Ìtélèdí ẹni kì í rí ni tì
                                      Ọ̀rọ̀ kì
í pò kí á fi ọ̀be bù ú
               Ìran Kẹrin
                                        A kì í
kó imí tán ki ìkan tun máa rùn nílè
                                      Lé akátá
jìnnà kí á tó ó padà bá adìe
                                      Bí iná kò
bá tàn láṣọ ẹ̀jẹ̀ kì í tán ní èékán
Ìran
Kẹfa
                                   Ibi ènì ni a
máa pa ìyá alákàrà sí
                                   A fi oró ya
oró kì í jé kí oró tán
  A kì í gbé àwòrán gàgà kí a má fi owó rẹ̀ te nǹkan
ÌWÉ ÌTÓKASÍ
Odunjo
J.F (1958), Agbàlọ́wọ́ọméri Baálẹ̀ Jòntolo.
Longman Nigeria Limited.
No comments:
Post a Comment