Sunday, 20 May 2018

ÀJÀ LÓ LẸRÙ


ÌTÀN NÍ ṢÓKÍ[1]

            Ìwé ìtàn àròsọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni ìwé Àjà ló lẹrù. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, a gbọ́ pé Lápàdé rí ẹnìkan nínú igbó nígbà tí ó ń ti oko rẹ̀ bọ̀.

            Ó fura pé owó ni ẹni náà rì mọ́lẹ̀, ó sì hú owó náà jáde. Lẹ́yìn èyí ni Aúdù, ọ̀gá ọlọ́pàá, dé tí ó sì fi ọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ọkọ̀ kan sáré kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn méjèèjì. Kò pẹ́, kò jìnnà, Lápàdé rí i pé ọkọ̀ náà subú nítòsí ọ̀dọ̀ òun. Awakọ̀ náà sì fi ara pa yaánnayànna. Lápàdé di awakọ̀ yìí lókùn, ó sì gbé e pamọ́ sínú igbó.

            Nígbà tí Lápàdé dé ilé, ó rán Tafa kí ó lọ gbé  awakọ̀ náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Táíwò lọ sí ilé Jàm̀pàkò. Sàlámì Kéḿbérú wá sí ilé Lápàdé láti wá jalè. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyà, ó jẹ́wọ́ pé àìlówó àti àìsísẹ́ lọ́wọ́ ni ó jẹ́ kí òun jalè. Wọ́n lọ sí ilé lọ sí ilé Jàm̀pàkò, wọ́n fi ìyà jẹ Tìámíyù, wọ́n lù ú bí ẹni lu bàrà, wọ́n yọ ẹyin rẹ̀, wọ́n sì tún gba owó lọ́wọ́ rẹ̀. Ibẹ̀ ni wọ́n ti gbọ́ pé wọ́n gbé Tọ́láni, Àbúrò Angelina, wọ́n sì ti gbé e lọ sí Ìkèrèkú ní Abẹ́òkúta. Lápàdé àti Tàfá gbà láti ran Angelina lọ́wọ́ (ó wọ Lápàdé lójú nítorí ẹwà rẹ̀ ni ó jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu nípa wíwá àwọn ọ̀daràn yìí lọ sí Abẹ́òkúta nì ìkèrèkú).

            Nígbà tí wọ́n débẹ̀ (Ìkèrèkú), wọ́n rí àwọn igbó tí àwọn arúfin wọ̀nyí gbìn, wọ́n bá Sélí àti ìyá arúgbó tó ń bá wọn ta ẹrù olè. Sélí ṣe òfófó fún Lápàdé irú iṣẹ́ àti ìwà wọn ní abà Abẹ́òkúta náà níbi ti wọ́n ti ń gbin igbó sí. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ni awọn ọ̀daràn wọ̀nyìí dé, ìyá àgbà ròyìn àwọn àlejò fún wọ́n. Sélí mú Lápàdé àti Tàfá lọ sí oko tí wọ́n gbin igbó sí. Ibi tí wọ́n ti ń tú igbó náà dànù ni wọ́n bá wọn. Wọ́n fi ìjà pẹẹ́ta ṣùgbọ́n Lápàdé àti Tàfá bá wọn jà títí àwọn ọlọ́pàá fi dé. Lápàdé àti Tàfá sá lọ ṣùgbọ́n ọwọ tẹ àwọn arúfin wọ̀nyí.

 

 

KÓKÓ ÀTI ÀKỌLÉ ÌWÉ YÌÍ

            Ọládẹ̀jọ Okédìjí fẹ́ ká mọ̀ pé kí á fi ọwọ́ wẹ ọwọ́ ni ọwọ́ fií mọ́. Nítorí Yorùbá bọ̀, wọ́n ní “Àgbájọ ọwọ́ la fi í sọ̀yà, àjèjé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dórí”

            Àkọ́lé ìwé yìí fi hàn pé àwọn ọlọ́pàá kò le ṣe nǹkan kan nípa ìwádìí àwọn arúfin ṣùgbọ́n Lápàdé tí ó jẹ́ Olú ẹ̀dá ìtàn ló lè ṣe é nítorí pé àwọn ni “Àjà” àwọn Audu (Ọgá ọlọ́pàá) ni “pẹpẹ”.

            Ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé yìí jọ ti ojú ayé (ìbáyemú-Realism) nítorí ní àwọùjọ àwa Yorùbá, kò sí ibi tí àwọn arúfin kò sí (aláìníṣẹ́, olè, amugbó, atagbó, agbingbó àti gbọ́mọgbọ́mọ). Àwọn ènìyàn bíi Lápàdé àti Tàfá sì wà pẹ̀lú, wọn mọ àwọn tí ọwọ́ wọn kò mọ́ láàrin ìlú àti ibi tí wọ́n fi ṣe ibùgbé. Ó sì hàn gbangba pé ipá àwọn ọlọ́pàá kò ká wọn, èyí tí ó sì ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ wa títí dòní olónìí.

            Bákan náà ni a rí bí ìròyìn àti ìwé ìròyìn ti í tako ara wọn láwùjọ wa lónìí. Ọ̀tọ̀ ni ìròyìn tí wọ́n yóò sọ lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì tàbí ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán, ọ̀tọ̀ ni èyí tí a ó rí kà nínú ìwé ìròyìn.

 

ÀWỌN Ẹ̀DÁ ÌTÀN

Òkédìjí fún wọn ní orúkọ àti oríkì láti fi wọ́n hàn bí wọ́n ṣe rí.

i.          LÁPÀDÉ: Òun ni olú ẹ̀dá ìtàn. Ó dàbí ẹni pé àkọsílẹ̀ (kádàrá) ló mú kí ó ṣàṣeyọrí. Lápàdé jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti ọlọ́pọlọ pípé ènìyàn; ó ní àkíyèsí àti àfiyè sí. Ó ti ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá rí kí ó tó padà sí iṣẹ́ àgbẹ̀. O mọ àwọn ènìyàn dáadáa, àwọn ènìyàn rẹ̀ náà sì mọ̀ ọ́n nítorí pé àárín wọn ni ó ń gbé. Ikú bàbá rẹ̀ ló sọ ọ́ di èrò ìgbélé àti àgbẹ̀.

            Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń fi ìṣòrò wọn han Lápàdé lọ́pọ̀ ìgbà láti lè bá wọn yanjú rẹ̀. Èyí jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro tó dojú kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àìríṣẹ́ ṣe, olè jíjà, igbó mímu, igbó títà, jàǹdùkú, àti gbọ́mọgbọ́mọ.. Lápàdé ní ọmọ ìránṣẹ́, èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tàfá. Tàfá jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Lápàdé. Bígbìn-ín bá fà, ìkarahun a tẹ̀lé e ni òun àti Tàfá.

ii.         TÀFÁ – Láti ìpìlẹ̀ ni òun ti gbọ́n féfé bi eku ẹdá tí ó sì níka níku bí ọ̀bọ. Tàfá ní olùrànlọ́wọ́ Lápàdé; ó ní oríkì ìnagijẹ̀ (wọ́n ń pè é ní ìgìrìpá ọmọ Láwálé); ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó máa ń ki ara rẹ̀ báyìí “Èmi Àjàó, Aro ọmọ Láwálé, èmi ajámọláyà bí ààrà àkọ́rọ̀ ojo. Èmi ayàjin-mọ-gìrìgìrìgìrì”[2] abbl. Olè níí mẹsẹ̀ olèé tọ̀ lórí àpáta, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ iná là á rán sí iná. Ìdí nìyìí tí Lápàdé fi yan Tàfá gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Arúfin ni tẹ́lẹ̀, alágbára máá mérò baba ọ̀lẹ àti ìpáǹle ni, ó sì ti ṣẹ̀wọ̀n ju ọ̀bọ lọ. Ó mọ àwọn òdaràn wọ̀nyí, ó sì mọ ibùgbé wọn. Gbogbo ìwọ̀nyìí jẹ́ kí iṣẹ́ Làpàdé rọrùn.

iii.        AÚDÙ KÀRÍMÙ - Ọ̀gá ọlọ́pàá ni. Ó kàn joyè àwòdì ni ṣùgbọ́n kò le gbádìyẹ. Yorùbá ní ẹlẹ́rù ni í kọ́kọ́ kófẹ, olórí ni kìí jẹ́ kó bàjẹ́ ṣùgbọ́n Aúdù Kàrímù fẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ làpálàpá ni ó ń pa. Ẹ̀dá tí kò já fáfá tó ni, kò mọ iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní agbára láti káwọ́ àwọn ọ̀daràn. Àkókò rẹ̀ ni ọlọ́ṣà àti àwọn ọ̀daràn pọ̀ sí i ní ìlú Ìbàdàn.

iv.        SÀLÁMÌ KÉḾBẸRU – Jàgùdà páálí ni, ojúlówó ọlọ́ṣà hàn-ún hàn-ún tí ẹ̀mí ènìyàn kò tó abẹ́rẹ́ lójú rẹ̀ níí ṣe. Ó láyà ó sì ní ọgbọ́n àrékérekè, ọgbọ́n yìí ló fi sákúró lẹ́wọ̀n láìjálẹ́kùn. Sálàmi Kéḿbérú yìí, kò sí ìlú tí kò gbérí, kò sí èdè tí kò le sọ bíi elédè gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn ni (ojú ewé 49). Àìgbọ́-tìyá àti baba ló lé e nílé tó sì sọ ọ́ dèrò ìta. Kìí jalè lọ́sàn-án, ṣùgbọ́n kò sí ilé tí kò le wọ̀ lóru.

v.         GBẸ́KÚTA - Òkèdìjí lo orúkọ yìí láti fi hàn pé lóòótọ́, orúkọ a máa roni ni ọ̀pọ̀ ìgbà ṣùgbọ́n nígbà mìíràn orúkọ tí a ń jẹ́ máa ń mú kí ènìyàn si ìwà hù. Gbékútà (baba mugbómugbó), ó ń gbin igbó, o ń mu igbó, ó sì ń ta igbó. Ní ojú ewé (146) a rí i pé ó ní oko igbó síí “Ìkèrèkú”. Inú oko igbó ti wọ́n ń tu ni Lápàdé àti Tàfá ìbá pa á síí bí kìí á ṣe ti Kọ́lá àti Táíwò ti wọ́n ń sáré bọ pẹ̀lú ìbọn àti àdá lọ́wọ́.

vi.        TÌÁMÍYÙ ARÍSÉMỌ́ṢE – Ó jẹ́ asíwájú àwọn òdaràn. Òun ni baba ìsàlẹ̀ àwọn ọ̀daràn. Arúfin pátápátá gbáà ni. Ó ní aṣojú ní ìlú kọ̀ọ̀kan tí wọ́n  ń bá a ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì ń jábọ̀ fún un, olóògùn hánrán-ún àti alágbára máà lérò ni.

Àṣeyọrí Lápàdé

            Lápàdé ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà láti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ ní ìlú ìbàdàn àti agbègbè rẹ̀.

            Ìforítì àti àfojúsùn tí Lápàdé ni ó jẹ́ kó le ṣẹ́gun àwọn arúfin wọ̀nyí dáadáa. Iṣẹ́ àti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ ni ó sọ ọ́ di olówó àti ẹni iyì láwùjọ.

            Lápàdé sì lo owó tí ó rí gbé Lásìkò tí ó tọ pinpin àwọn arúfin wọ̀nyìí dáadáa.

            Lápàdé lo owó náà láti san owó tí bàbá Selí jẹ Táíwò. Eléyìí ló sì sọ Selì di òmìnira ara rẹ̀. Ìyókù owó ọ̀hún ló ń lò fún àwọn aláìní ó sì tun lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó yìí lórí ìwádìí àwọn arúfin káàkiri.

            Wàyí ò, ipa tí ẹ̀dá ìtàn bá kó nínú ìtàn àròsọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ dé òpin ìtàn náà ló máa ń fa kí a ka àwọn kan sí olú ẹ̀dá ìtàn, kí á sì mọ àwọn kan sí ẹ̀dá ìtàn àfarahẹ. Bí a bá yọwọ́ àwọn ẹ̀dá ìtàn afarahẹ kúrò nínú ìtàn, a kò sì lè ka ìtàn náà kí ó fún wa ní ìtumọ̀ kíkún.

ÀWỌN ÀṢÀ YORÙBÁ TÓ SÚYỌ NÍNÚ ÌTÀN NÁÀ

i.                    Ìlò Orúkọ ìlú Yorùbá: Òkédìjí lo àwọn orúkọ ìlú pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ìwé yìí. bí àpẹẹrẹ, A rí ìlú Ìbàdàn tí n ṣe ibùgbé Lápàdé, a sì rí Abeokuta níbi tí àwọn arúfin gbin igbó sí.

ii.                  Iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣíṣe: Iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ àjogúnbá láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wa: A rí èyí gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ Lápàdé, olú ẹ̀dá ìtàn ìwé yìí (pg 1)

iii.                Ìkíni “Àgò onílé yìí o” (pg 70)

iv.                Òwe pípa: Òwé pípa jẹ́ àṣà àti àbùdá tí ó ti di bárakú láwùjọ àwa Yorùbá. Akọ́lé ìwé yìí jẹ́ òwe.Òǹkọ̀wé kìí délẹ̀ báyìí: “Àjà ló lẹrù, irọ́ ni pẹpẹ ń pa” (pg 154)

v.                  Oúnjẹ Yorùbá jíjẹ: Èyí hàn nínú oúnjẹ Lápàdé. Bí kò jẹ iyán yóò jẹ ọkà nítorí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “iyán loúnjẹ, ọkà loogùn, àìrí rárá lafií jẹ̀kọ, kẹ́nu mágbófòo ni ti gúgúrú”.

vi.                Kíki Oríkì: ọ̀pọ̀ ìgbà tí Tàfá bá fẹ́ mú kí orí rẹ̀ wú láti ṣe nǹkan, yóò ki ara rẹ̀ báyìí “èmi ìgìrìpá, Àjàó aro ọmọ Láwọlé, èmi ajọ́mọláyà bíi àrá àkọ́rọ̀ òjò”.......abbl (pg 134, 80) abbl.

vii.              Ìwà Ọmọlúàbí àti Ìwà olùfẹ́ àlejò ṣíṣe: Sẹli gúnyán fún Lápàdé àti Tàfá, ó sì gbé ẹmu ògidì fún wọn. Seli wu ìwà ọmọlúàbí sí Lápàdé. Ìwà ọmọlúàbí ló sì mú kí Seli gbòmìnira kúrò lọ́dọ̀ àwọn amúnisìn. (pg 107)

ÈDÈ TÍ ÒǸKỌ̀WÉ FI SÍ ẸNU ÀWỌN Ẹ̀DÁ ÌTÀN

            Ojúlówó èdè Yorùbá tí ó kún fún onírúurú ọnà ìsọwọlo-èdè (use of language) ni òǹkọ̀wé fi sí àwọn ẹ̀dá ìtàn. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà-ìsọwọ́lo èdè náà nìyìí:

i.                    Àfiwé Tààrà: Èyí ni kí á fi nǹkan méjì wé ara wọn, kí a sì dárúkọ nǹkan méjèèjì kí a wá fi “bíi” so wọ́n pọ̀.

Àpẹẹrẹ díẹ̀ nìyìí:

i. Ó ń jó wèrè nílẹ̀ bíi òkú ejò tì òòrùn ń ta sí lára (pg 90)

ii. Ojú náà wú tomutomu bíi ti òkú ọjọ́ mẹ́rin (pg 90)

iii. Tàfá ń lù ú bíi bàrà (pg 90)

iv. Délé sì ti sunkún bíi ẹni ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ (pg 124)

v.  Wọ́n ń ti bíi igbá (pg 125)

vii. Òun nìkan ṣoṣo ń jà bíi ènìyàn mẹ́fà (147)

ii.                  Àsọrégèé: Èyí ni kí á ròyìn nǹkan ju bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ lọ:

i.    Ọbẹ̀ náà dùn ju oyin lọ (pg 108)

ii.   Àpapọ̀ gíga rẹ̀ níláti tó pẹ̀tẹ́ẹ́sì mẹ́jọ (pg 142)

iii.  Oko igbó tuntun tí wọ́n gbìn fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó ìlú Ìbàdàn (pg 153)

iii.                Àkànlò èdè: Èyí ni ìpèdè tí a máa ń  lò nígbà tí Yorùbá kò bá fẹ́ sọ̀rọ̀ sákálá ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ tàbí fun ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀.

i.    Fimú fínlẹ̀                    (o.i 7)

ii.   Jaburata                       (o.i 29)

iii.  Jàgùdù                         (o.i 12)

iv. Mu wá lómi                  (i.o 14)

v.   Ìyekan                         (i.o 67)

vi.  Kàmọ̀mọ̀                     (i.o 81)

vii. Kùkùlọjọ̀                     (i.o 114)

viii. Forí ọká họmú            (i.o 157)

iv.                Gbólóhùn Dídọ́gba: Èyí ni kí àwọn gbólóhùn bíi méjì tàbí mẹ́ta dọ́gba ní ìhun tàbi ìtumọ̀.

i.                    Ayé àgbẹ̀ bíi ayé ajẹ ajẹrọ̀run        (o.i 108)

Iṣẹ́ àgbẹ̀ bíi iṣẹ́ àṣe àṣerọ̀run

ii.                  Àparò ó fò, aṣọ rẹ̀ ẹ́ tan.

v.                  Òwe: Èyí pọ̀ nínú ìtàn àròsọ náà bí ewé rúmọ̀, wọ́n sì jẹ́ kí èdè Yorùbá inú ìtàn náà jinlẹ̀ dáadáa.

Bí a bá kíyè sí Ọládẹ̀jọ Òkédìjí, a ó rí i wí pé kí á tú òwe palẹ̀, kí á ki òwé ní àkìdélẹ̀ ní ọ̀nà àrà jẹ́ pàtàkì ẹwà-èdè tí ó ń lò.

i.                    Má foko mi dá ọ̀nà, ọjọ́ kan làá ṣòfin rẹ̀, olúwéré yóò ṣe ọkàn gírí ni, tí yóò pinnu, pé òun ó gba oko tòun kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń fi í ṣe ọ̀nà, olóko kò gbọdọ̀ bẹ̀rù kí ó máa leè fọhùn kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ di ọ̀nà yẹ́lẹyẹ̀lẹ (pg 62)

ii.                  Aṣọ̀ràn ìbàjẹ́ ṣebí òun là ń wí, aṣeburúkú kú ara fúnfun (pg 7)

iii.                Bí owe bá jọ òwe ẹni, bí a kò le dáhùn, èrù ìjà ló ń bà á. (pg 9)

iv.                Àìsúnmọ́ ẹni, àìmọ̀ṣe ẹni, ènìyàn kìí gbókèèrè níyì.  (pg 10)

v.                  Kàkà kí ó sàn lára ìyá àjẹ́, ó tún ń fi ọmọ rẹ̀ bí obìnrin, ẹyẹ wá ń yí lu ẹyẹ.  (pg 31)

vi.                Àgbà tó bá rí ejò tí kò sá, ara ikú ló ń yá a.  (pg 59)

vii.              Bí eégún ń lé ọ,a rọjú nítorí bó ṣe ń rẹ ará ayé ni í rẹ ará ọ̀run.  (pg 81)

viii.            Ọ̀pọ̀lọ́ ní inú òun kò dára, ta ni yóò ri ẹ̀yìn rẹ̀ tí kò níí mọ̀ bí inú rẹ̀ ti rí.  (pg 106)

ix.                A ní ká jẹ èkuru kó tán, ẹ tún ń gbọn ọwọ́ rẹ̀ sínú àwo. (pg 130)

x.                  Ká lọ́ṣọ mọ́dìí, ká lọdìí máṣọ, kídìí ṣá ti má gbófo ni

xi.                Àjà ló lẹrù, irọ́ ni pẹpẹ ń pa.  (pg 154)

xii.              Ọjọ́ gbogbo ni tolè o ṣùgbọ́n ọjọ́ kan á máa jẹ́ tolóhun. (pg 160)

 

ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ

Ọládẹ̀jọ O (1969), Àjà ló lẹrù. Ìbàdan: Caxton Press West Africa Ltd. 



[1] Anjorin Sola Saamuel ló kọ bébà yìí.
[2] Àrà ọ̣̀ ni eléyìí nínú àwọn òṇ̀wé Yorùbá nítorí Okediji ṇ́ kí á fi oríkì dá ènìyàn mọ̀ nínú ìwé rẹ̀ láìfi ọ̣̀ wuuru ṣe àpèjúwe ẹni náà.

No comments:

Post a Comment