Monday, 30 April 2018

Tíọ́rì Ìṣègbèfábo/Ìṣẹ̀tọ́fábo


Tí a bá fẹ́ yan tíọ́rì fún ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ kan, ó pọn dandan láti yan èyí tí yóò lè fi òye ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan hàn wá nípa ohun tí a fẹ́ yẹ̀wò[1]. Tíọ́rì jẹ́ gẹ́gẹ́ bí òfin tàbì ìlànà tí ó jẹ́ atọ́nà fún lámèétọ́ nígbà yòówù tó bá ń yẹ iṣẹ́ kan wò. Tíọ́rì wà láti ran lámèétọ́ lọ́wọ́ lẹ́nu àgbéyẹ̀wò iṣẹ́tó ń ṣe. Òhun ló dúró bí ìjánu fún lámèétọ́ bẹ́ẹ̀ láti lè ṣe ìdájọ́ òdodo nípa iṣẹ́ tó ń yẹ̀wò gan-an, kí ó lè ṣe gbẹ́nugbẹ́nu tó péye.

Tíọ́rì lítíréṣọ̀ tí àwọn lámèétọ́ oníṣẹ́-ọnà ajẹmọ́-lítíréṣọ̀ máa ń lò fún ṣíṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ pọ̀ lóríṣìíríṣìí. Ṣùgbọ́n irú iṣẹ́ tàbí àtúpalẹ̀ tí lámèétọ́ bá ń ṣe ló máa ń ṣọ irú tíọ́rì lítíréṣọ̀ tí yóò yàn láàyò. Nínú iṣẹ́ yìí, tíọ́rì ìṣègbèfábo àti tíọ́rì ìṣètọ́fábo ni a fẹ́ yẹ wò.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tíọ́rì ni àwọn onímọ̀ ti gbé kalẹ̀ láti ṣe àtúpalẹ̀ lítíréṣò. Irúfẹ́ iṣẹ́ tí lámèétọ́ bá dá wọ́ lé lo máa sọ irúfẹ́ tíọ́rì àmúlò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tíọ́rì ìmọ̀ ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ náà lè fún wa ní àyọrísí kan, ṣùgbọ́n  tí a bá fi tíọ́rì ìṣègbèfábo/ìṣẹ̀tọ́fábo wò iṣẹ́, òun náà so mọ́ ìbágbépọ̀ àwùjọ. Nítorí inú àwùjọ ni àwọn obìnrin wà.

Àárín àwọn Òyìnbó (Amẹ́ríkà) ni tíọ́rì yìí ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n dá ẹgbẹ́ àwọn obìnrin sílẹ̀ ní àsárín sẹ́ńtúri ọ̀ọ́rúndúnkejìdínlógún (1800) sẹ́yìn. Nígbà tí ìdàgbàsókè gbogbo nǹkan àti òmìnira jẹ gbogbo ènìyàn lógún. Àsìkò yìí ni àwọn obìnrin kọ́kọ́ ní àǹfààní láti kó ara wọn jọ àti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ló ti ṣe àsàrò ọ̀kan-ò-jọ̀kan nípa bí tíọ́rì ìṣègbèfábo ti bẹ̀rẹ̀, àwọn bíi Marfu (1983), Nancy (1989:167), Ramazanoglu (1989:1), Zamani (1994), Khomeini (1994), Sheba (1996), Kọ́láwọlé (1997), àti Carl Henric àti Kamergrauzis (2003:17-23).

Ní ọdún 1920, a rí àwọn àkàndá-bìnrin méjì kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà, Emona Willard àti Frances Wright, ṣe ẹ̀kọ́ fún àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Èrò wọn nígbà náà sì ni pé àwùjọ ń rẹ́ àwọn obìnrin jẹ ju bí ó ti yẹ lọ. Wright tilẹ̀ sọ ní gbangba pé:

Until women assume the place in society which good sense and good feeling alike assign to them, human improvement must advance but feebly.

                                                            (Flexner, 1959:27)

 

(Títí di ìgbà tí obìnrin bá wà ní àyè tí ó yẹ ní àwùjọ, ìdàgbàsókè ẹ̀dá kò lè gòkè dàbí alárà kan.)

 

Ní ọdún 1833 ni kọ́lẹ̀jì kan ní ìlú OBerlin ṣínà fún takọtabo láti kẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ obìnrin kò ju bí ó ṣe lè ṣe ìtọ́jú ilé àti aya rere lọ́dẹ̀ ọkọ. Ẹgbẹ́ ẹ̀tọ́ obìnrin “Women’s Right Movement”, bẹ̀rẹ̀ gan-an ní 1833. Àsìkò yìí ni àwọn obìnrin àti ọkùnrin jà fún pípa òwò erú rẹ́, àwọn obìnrin bíi Sarah Grimke jẹ́ ara ẹni àkọ́kọ́ tó ṣiṣẹ́ lórí èyí. Àwọn obìnrin yìí wá rí i pé ìjà yìí kì í ṣe láti pa òwò ẹrú rẹ́ nìkan ṣùgbọ́n ó lọ́wọ́ ìjà òmìnira àwọn obìnrin nínú. Sarah Grimke sọ nípa ìjẹgàba àwọn ọkùnrin ní 1837 pé:

All history attests that man has subjugated woman to his will, used her as a means to promote his selfish desire… but never has he desired to elevate her to that rank she was created to fell…

 

All I ask our brethren is that they will take their feet from off our necks and permit us to stand upright on that ground which God designed us to occupy.

                                                            (Grimke, 1837:10)

 

(Gbogbo ìtàn ni ó jẹ́rìí sí i pé ọkùnrin ti tẹrí obìnrin ba sì ìfẹ́ tirẹ̀, ó lò ó bí ohun èlò láti tẹ́ ara rẹ̀ nìkan lọ́rùn… ṣùgbọ́n kì í gbèrò láti gbé e ga dé ipò tí a dá a láti dé…

 

…Gbogbo ohun tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wa ni pé kí wọn gbẹ́sẹ̀ kúrò lọ́rùn wa, kí wọ́n jẹ́ kí àwoa náà dúró gangan lórí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti pèṣè fún wa láti gbé.)

 

Nǹkan tí Sarah ń sọ ni pé dípò kí ìwàpọ̀ tọkọtaya fún ẹnìkejì wọn láyè láti fa obìnrin sókè, ṣe ni àwọn ọkùnrin sọ obìnrin di àpótí ìtìṣẹ̀ débí pé wọ́n sọ àmì ìdánimọ̀ wọn nù. Nítorí èyí wọ́n pe àwùjọ níjà láti fún obìnrin lẹ́tọ̀ọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́dàá ṣe dá wọn.

Ìjàgbara fún òmìnira yìí tẹ̀ síwájú di ọdún 1840 tí àpérò àgbáyé kan wáyé lórí òwò ẹrú “World Anti-slavery Convention” ní ìlú London. Lucretia Mott àti Elizabeth Stanton wà lára àwọn aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wá sí ìpàdé yìí. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wọn nígbà tí wọn ò jẹ́ kí obìnrin kankan sọ̀rọ̀ tàbí kí ó bá wọn jókòó láàárín àjọ náà. Kódà, àwọn ọkùnrin tí ó lòdì sí àìdọ́gba tí ó wà láàárín àwùjọ tún lọ́wọ́ nínú èrò yìí. Èyí wá ta wọ́n lólobó pé wọn ò lè jà fún òmìnira àwọn adúláwọ̀ tí a kó lẹ́rú láìjẹ́ pé àwọn obìnrin lápapọ̀ bọ́ lóko ẹrú pẹ̀lú.

Nítorí náà Mott àti Stanton pe ìpàdé lórí ẹ̀tọ́ obìnrin ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kejì, ọdún 1848 lẹ́yìn tí wọ́n padà délé. Nínú ìpàdé wọn yìí ni wọ́n ti gbé àwọn ìpinnu kan jáde nípa ojú tí àwọn ọkùnrin fi ń  wo obìnrin láwùjọ. Wọ́n fi han aráyé pé àwọn lòdì sí àìdọ́gba tí ó wà láàárin takọtabo tí ó sì fa obìnrin sẹ́yìn yálà nínú ìgbéyàwó ni nínú àìfún obìnrin ní iṣẹ gidi ṣe ni tàbí àìdọ́gba fún obìnrin àti ọkùnrin láwùjọ. Ní ilé ìjọ́sìn gan-an, abẹ́ ọkùnrin ni obìnrin wà.

Lẹ́yìn ogun abẹ́lé ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní ọdún 1861, òwò ẹrú wá sí òpin. Ṣùgbọ́n ohun mìíràn tún wáyé. Àwọn aláṣẹ ya akọ àti abo ṣọ́tọ̀ nínú ìwé òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ìgbà àkọ́kọ́. Èyí jí àwọn obìnrin gírí sí ojúṣe wọn láti ja ìjàgbara, wọ́n sì bèrẹ̀ sí níí bèèrè ẹ̀tọ́ wọn láti ní àǹfàní láti dìbò. Wọ́n polongo akitiyan yìí, wọ́n sì ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ káàkiri. Stanton gbàgbọ́ pé ẹ̀sìn jẹ́ ìdíwọ́ pàtàkì fún àwọn láti ja ìjà yìí yọrí nítorí náà ó gbógun ti èyí. Ó kó àwọn ènìyàn bíi mẹ́tàdínlógún kan jọ tí wọn sì kọ Bíbélì Obìnrin (Women’s Bible). Nínú èyi ni wọ́n tí sọ̀rọ̀ nípa ipa obìnrin nínú Bíbélì; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn rí akitiyan yìí sí ìlòdì sí ẹ̀mí mímọ́.

Ní ìparí, akitiyan àwọn obìnrin yìí yọrí sí ayọ̀ nígbà tí ìjọba fún àwọn obìnrin láyè àti ní agbára ìbò dídì. Àgbára yìí jẹ́ kí obìnrin àti ọ̀pọ̀ ènìyàn rò pé takọtabo ti dọ́gba láwùjọ. Èrò yìí mú kí wọ́n fà sẹ́yìn nínú ojúṣe wọn. Ṣùgbọ́n ní bí ọdún 1960 ni àwọn obìnrin tó tún ta jí sí ojúṣe wọn láti jà fún àwọn ẹ̀tọ́ tó kù.

Bí a bá wo akitiyan àwọn Òyìnbó yìí pẹ̀lú ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, pàápàá, ní ilẹ̀ Nàìjíríà, a kíyè sí i pé ó yàtọ̀ gidi. Ṣáájú àwọn Òyìnbó àti ìjọba ológun tàbí olóṣèlú ní àwọn obìnrin Nìàjíríà tí ń lọ́wọ́ sí ètò òṣèlú. Àpẹẹrẹ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ni Ẹfúnṣetán Aníwúrà ìlú Ìbàdàn, Queen Amina Zazzau àti Queen Kambassa ní Bonny. Lẹ́yìn òmìnira, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú dìde, a ní Hájìyá Gambo Sawaba. Ẹgbẹ́ obìnrin sì ń dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan.

Ibi tí àwọn obìnrin ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ń jà kiri fún ìjẹgàba ọkùnrin lórí obìnrin ni wọ́n ti dé Nàìjíríà, èyí tí ó fi hàn pé àṣà yàtọ̀ ṣíra wọn. Lójú àwọn obìnrin adúláwọ̀ lápapọ̀, ìṣẹ̀tọ́fábo ló jẹ wọ́n lógún nítorí náà, obìnrin adúláwọ̀ kì í ṣe ẹni àtẹ̀mẹ́rẹ̀. Wọ́n ní oríṣìíríṣìí ipa pàtàkì tí wọ́n ń kó nínú àwùjọ bí a ṣe ṣàlàyé síwájú.

Tí a bá fi ojú ìjàjàgbára àwọn Òyìnbó Amẹ́ríkà wo àṣà, ìṣe àti  ìgbàgbọ́ àwọn adúláwọ̀ abala tíọ́rì pé kí obìnrin wà lọ́tọ̀, kí ọkùnrin náà wà lọ́tọ̀ kò bá àṣà wa mu, nítorí obìnrin adúláwọ̀ kááramáásìkí gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹbí. Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ ẹbí ṣe pàtàkì sí wọn àti pé ìgbàgbọ́ wọn  ni pé ó di dandan kí àwọn jẹ́ ìyá ìyàwó àti abiyamọ. Wọ́n máa ń sọ pé ẹni wáyé tí kò bímọ kò wáyé ire.

Nítorí èyí, a kò mú tíọ́rì yìí lò ní adúláwọ̀ nítorí ewu máa wà, kí ìdílé aláyọ̀ máa bàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ama Ata Aido tó hàn nínú Kọ́láwọlé (1997:1) pé:

Feminism! The destroyer of homes. Imported from America to ruin nice African homes.

 

(Ìṣègbèfábo! Èyí tí ń ba ẹbí jẹ́, a yá a láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti ba ìdílé dáradára ilẹ̀ adúláwọ̀ jẹ́.)

 

Èrò onímọ̀ yìí tọ̀nà nítorí àwùjọ àdúláwọ̀, pàápàá, ti Yorùbá kò fàyè sílẹ̀ láti ta ohun tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí nù lára wọn. Àkíyèsí wá fi hàn pé ojú tí obìnrin Òyìnbó fi ń wo ayé yàtọ̀ sí ti obìnrin ilẹ̀ adúláwọ̀. Pàtàkì nǹkan tí wọ́n ń lépa ni láti mú ìpín ìbádọ́gba ọkùnrin àti obìnrin wà nínú àwùjọ wọn. Àwọn obìnrin adúláwọ̀ kò fi gbogbo ara gba èrò wọn yìí nítorí wọn ò rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó wà lábẹ́ ìdè ọkùnrin kankan tàbí nínú oko ẹrú. Ìdí abájọ tí wọ́n fi ṣe àgbékalẹ̀ tíọ́rì ìṣẹ̀tọ́fábo (Womanism) èyí tí àwọn onímọ̀ ń lò láti fi ṣe ìgbọ̀n-yẹ́bẹ́ yẹ́bẹ́ àwọn ìṣòro tí obìnrin dojú kọ àti akitiyan àwọn obìnrin láti lè jára gbà lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí ó ti ń jẹ gàba lé wọn lórí láti ọjọ́ pípẹ́.

Ohun tí ‘womanism’, tó túmọ̀ sí ìṣẹ̀tọ́fábo, ń gbìyànjú láti ṣe ni kí wọ́n ta obìnrin jí láti gbé ọwọ́ wọn sókè àti láti fi yé àwùjọ pé kò tọ̀nà láti fi ojú ẹ̀gàn wo irúfẹ́ ẹ̀dá kan ní àwùjọ nítorí àbùdá wọn. Nǹkan tó ṣe pàtàkì fún tíọ́rì yìí ni wíwo ojúṣe obìnrin nínú àwùjọ àti láti sí àwùjọ níyè nípa ọ̀rọ̀ tí ó rọ̀ mọ́ ẹbí.

Ògúnyẹmí (1988:65) ṣe àfikún pé:

Womanism is black-centered, it is accommodationist, it believes in the freedom and independence of woman like feminism, unlike the radical feminism, it wants meaningful union between black women and black men and black children, and will see to it that men begin to change from their sexist stand.

 

(Ìṣẹ̀tọ́fábo jẹ mọ́ adúláwọ̀, ó fi àyè gba ìkónimọ́ra, ó gbàgbọ́ nínú obìnrin àti àìsínígbèkùn abo gẹ́gẹ́ bíi tíọ́rì ìṣègbèfábo, ó yàtọ̀ sí àwọn alákatakítí ìṣègbèfábo, ó fẹ́ kí àjọṣepọ̀ tó nítumọ̀ wà láàrin obìnrin adúláwọ̀ àti ọkùnrin adúláwọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ tí wọ́n bí, àti pé yóò gbé ìgbésẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn ọkùnrin yí èrò wọn nípa abo padà.)

 

            Lóòótọ́ ni ìhà tí àwọn obìnrin adúláwọ̀ kọ sí ìdílé lágbára ṣùgbọ́n ìrẹ́jẹ akọ ni wọn máa ń takò. Èyí kò sí sọ pé kí wọn má gba akọ láyè gẹ́gẹ́ bí orí fún wọn ní àwọn ibi tí wọ́n lérò pé ó tọ́ (Kọ́láwọlé, 1997:22).

            Kọ́láwọlé (1997:196) tilẹ̀ gbà pé:

Womanism does not deny the natural biological God-given traits and characteristics, but rejects the manipulation of such traits to hold women down.

 

(Ìṣẹ̀tọ́fábo kò tako bí ẹlẹ́dàá ṣe ṣẹ̀dá wọn, ní ìrísí àti àbùdá ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n takò ni bí àwọn ọkùnrin ṣe ń lo àǹfààní àwọn àbùdá wọ̀nyí láti fà wọ́n sẹ́yìn).

 

            Ohun tí ó jẹ́ ìlépa àwọn tíọ́rì méjéèjì yìí ni láti mú obìnrin kúrò ní ipò ẹrú àti láti máà fi àyè sílẹ̀ fún àwọn obìnrin láti jẹ́ àpínmógún tàbí ẹni àtẹ̀mẹ́rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ló sì ń fẹ́ kí a máa wo obìnrin gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹ̀dá kejì nítorí bí a ṣe bí ẹrú la bí ọmọ kò sí fàyè sílẹ̀ pé obìnrin kéré sí ọkùnrin, pé kí á fún àwọn obìnrin láyè láti lo ẹ̀bùn tí adẹ́dàá fún wọn, ìgbélarugẹ àwọn iṣẹ́ rere obìnrin àti ìwúlò wọn láwùjọ.

ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ

Abímbọ́lá, W. (1968), Ìjìnlẹ̀ Ohun Ẹnu Ifá. Apá Kìíní. Glasgow Collins.

Abímbọ́lá, W. (1976), Ifá An Esposition of Ifá Literary Corpus. Ibadan: Oxford University Press.

Adébọ̀wálé, O. (1999), “Ìfojú Tíọ́rì Ìṣègbèfábo wo Ipò Obìnrin nínú Ètò Ìgbéyàwó: Àyẹ̀wò Ìtàn Àròsọ Yorùbá”. Nínú T.M. Ilésanmí (ol.) Yorùbá: A Journal of the Yorùbá Studies Associations of Nigeria. Department of African Languages and Literatures, O.A.U., Ile-Ife.

Adébọ̀wálé, O. (1999), Ọgbọn Ònǹkọ̀wé Alátinúdá. Lagos: Captstone Publications.

Adéjùmọ̀, G.A.  (2002), Rò ó o Re. Ebute Meta, Lagos: The Capstone Publications.

Adéoyè, C.L. (1979). Àṣà àti Ìṣe Yorùbá. New York: University Press.

Adéyínká T.A. (2004), Àwọn Obìnrin Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀dá Ìtàn Nínú Ìwé Sunday Ẹ̀sọ́ Olúbọ́rọ̀dé, Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.

Ajíbádé, G.O. (1999), “Yorùbá Women Government their Men A Socio-religious Approach to Feminism”, nínú Ife Social Science Review. Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, 194-201.

Ajíbádé, G.O. (2002), “Àgbéyẹ̀wò Ọ̀ṣun Òṣogbo nínú Iṣẹ́ Ọnà Ajẹméwì àti Ajẹmáwòrán”. Ph.D Thesis, Department of African Languages and Literatures, Obáfẹ́mi Awólọ́ẉọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.

Akínjógbìn, A. (ed.) (1969), Ewì Ìwòyí, Glassgow: Collins & Sons. Co. Ltd.

Àránsí, A.O. (2005), “Ìtúpalẹ̀ Kókó Ọ̀rọ̀ Ewì Yorùbá tí Díẹ̀ nínú Àwọn Ònǹkọ̀wé-bìnrin kọ”.  M.A. Thesis, Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.

Ayọ̀adé, A.S. (2004), “Ìtúpalẹ̀ Orin Ìbejì ní Agbègbè Ọ̀ṣun”, Department of African Languages and Literatures, Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.

Bámgbóṣé, Ayọ̀ (1970), “Word Play in Yoruba Poetry”, WAL, Vol. 36, No 2.

Dáramọ́lá and Jéjé (1967), Àṣà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ibadan: Onibon-Oje Press.

Ilésanmí, T.M. (1974), “Olele: Ọ̀kan nínú Ewì Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà” B.A. Long Essay, Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.

Ilésanmí, T.M. (1988), “Hearthstones as Cultural Study of Songs in Ijesaland”, Ph.D Thesis, University of Ibadan, Ibadan.

Ilésanmí, T.M. (1990), “Àkóyawọ́ Lítíréṣọ̀ Yorùbá”, Mimeograph.

Ilésanmí, T.M. (1999), Yorùbá: A Journal of the Yorùbá Studies Associations of Nigeria. Department of African Languages and Literatures, O.A.U., Ile-Ife.

Kọ́láwọlé, M.E.M. (1997), Womanism and African Conciousness, ERITREA: African World Press, Inc.

Kọ́láwọlé, M.E.M. (1998), Gender Perceptions and Develoment in Africa, ERITREA: African World Press, Inc.

Ògúnbọ̀wálé, P. (1966) Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: Oxford University Press.

Ọláidé, S.J. “Ìpójú Èrò Ìṣègbèfábo Ṣàtúpalẹ̀ Iṣẹ́ Àwọn Àṣàyàn Ònǹkọ̀wé-bìnrin Yorùbá”, Ph.D  Thesis, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.

Ọlátúnjí, O.O. (1984), Features of Yorùbá Oral Poetry. Ibadan: University Press Limited.

Olúdáre Ọlájubù (1976), Ìwé Àsà Ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: University Press Ltd.

Ọmọlọlá Adéronkẹ́ A. (1998), “Àgbéyẹ̀wò Orin Ọdún Àrigíyà ní Ìkàrẹ́-Àkókó”. Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.

Òjó, J.R.O. (1990), The Position of Women in Yorùbá Traditional Society. Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.

Ọ̀pẹ̀fèyítìmí, A. (1999), “Myths and Women of Power in Yorùbá Orature” nínú Gender Perceptions and Development in Africa. Mary E. Modupe Kolawole (ol.), ERITREA: African World Press, Inc.

Ọ̀pẹ̀fèyítìmí, A. (1997), Tíọ́rì àti Ìsọwọ́lò-èdè. Osogbo: Tanimehin-Ola Press.

Ọ̀pẹ̀fèyítìmí, A. (1995), “Womb to Tomb: Yorùbá Woman Power Over Life and Death”, nínú Ife Annals of the Institute of Cultural Studies. A Publication of the Institution of Cultural Studies. Obafemi Awolowo University, Ile-Ife. Pp. 55-67.

Sheba, J.O. (1999), “Àwọn Ònǹkọ̀wé-bìnrin Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí Aṣègbèfábo” nínú T.M. Ilésanmí (ol.) Yorùbá: A Journal of the Yoruba Studies Association of Nigeria.



[1] Kadiri Tawakalitu Bukola ló kọ b’ebà yìí.

No comments:

Post a Comment