Òǹkọ̀wé[1]: Orúkọ òǹkọ̀wé ni Adébísí Adésígbìn.
Adébísí Adésígbìn jẹ́ ọmọ bíbí
ìlú Ìfẹ́tẹ́dó ní Ìpínlẹ̀ Ọsun. Lẹ́yìn tí ó jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ Mọ́dá
(Modern School), ó tẹ̀ síwájú láti gba ìwé-ẹ̀rí tì Onípò kẹta àti
Onípò kejì (Teacher's Grade III and Grade II). Ó tún gba ìwé-ẹ̀rí N.C.E
ní Adéyẹmi College of Education Ondó; B.A. Education (Yorùbá) ní
Yunifásítì Ifẹ̀ àti òyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ M.A. (Yorùbá Literature) ni Ọbáfẹ́mi
Awólọ́wọ̀ University, Ilé-ifẹ̀.
ÌSỌNÍṢÓKÍ
Ìwé
eré-onítàn Ọ̀rẹ́ kó Gbẹlẹ̀ta jẹ́
ìtàn tí ó dá lórí àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Àkàngbé,
Àlàmú àti Bùrẹ́mọ. Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta wọ̀nyí jẹ ọ̀rẹ́ tí wọ́n dìjọ
jìyà níbi tí wọn ti ń roko àgbàro, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àṣedòru, tí wọ́n
ń ṣe iṣẹ́ bó o jí, o jí mí. Ọ̀kan nínú wọn gbèrò pé kí àwọn pa oko
àgbàro tì, kí àwọn tu owó àwọn jọ, kí àwọn sì kó lọ sí ìlú
mìíràn láti lọ máa ṣòwó. Wọ́n gbà sí i lẹ́nu, wón sì fẹnu kò pé
kí àwọn tóó lọ, ó tọ́ kí àwọn lọ sí ilé aláwo láti lọ ṣe yẹ̀ńwò
lórí bóyá àjò àwọn yóó dára. Wọn lọ sí ilé babaláwo, babaláwo
dífá, ó sì jẹ kí ó yé wọ́n pé àjò wọn yóó dára, ṣùgbọ́n ẹnikàn
ni yóó kọ́kọ́ rọ́wọ́ mú nínú àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta, wọ́n sì gbọdọ̀ rúbọ̀
nítorí ìlara tí ó le tibẹ̀ yọjú. Wọn pawo lékèé, wọn pèsu lékè, wọn
tún wọ̀rùn yànyàn bí ẹni pé wọn kò níí kú mọ́ láyé, wọn ketí ọ̀gbọin
sẹ́bọ. Wọn gbà pé ohun tí babaláwo ó jẹ ló ń wà, wọ́n sì fẹnu kò pé
àwọn kò níí rú ẹbọ. Nígbà tí wọ́n dé ìdálẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ owó, wọn
sì ń rí ṣe, ṣùgbọ́n ọwọ́ ọ̀kan nínú wọn tí ó ń jẹ́ Àkàngbé tètè
lawó ṣáájú tí àwọn méjì yòókù, ó sì máa ń fún wọn lówó tí
owó bá ṣáfẹ́rẹ́ lọ́wọ́ wọn. Nígbà tí ara Àlàmù àti Bùrẹ́mọ̀ kò gbà
á mọ́ pé ọ̀rẹ́ àwọn lówó ju àwọn lọ, wón bẹ jàǹdùkú lọ́wẹ̀, wọ́n sì
pààyàn sí Àkàngbé lọ́rùn, wọn tún parọ́ mọ́ ọn nílé Ọba pé òun
lapààyàn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, orí kó Àkàngbé yọ nítorí aájò
tí àwọn ìyàwó rẹ̀ ṣe, ó sì bọ lọ́wọ́ ikú òjijì. Bákan náà ni Ọba
sì dájọ́ kí wọn pa àwọn ọ̀rẹ́ méjì yòókù tí wọ́n dojú ẹjọ rú ni
okùn tí wọ́n dẹ fún àparò bá mú agílíntí.
ÌLÒ-ÈDÈ
Onírúurú
ìlò-èdè ni òǹkọ̀wé ṣàmúlò nínú ìwé eré-onítàn Ọ̀rẹ́ kó Gbẹlẹ̀ta. Èyí sì ni àwọn ọnà
tí òǹkọ̀wé gbé àwọn èdè inú ìwé náà gbà. Lára àwọn ìlò-èdè
tí ó jẹ yọ ni orin, òwe, àkànlò-èdè, Ẹṣẹ-Ifá, ọ̀rọ̀ inú bíbélì, ọ̀rọ̀
inú kùránì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Orin
Àpẹẹrẹ
àwọn ibi tí orin tí jẹ yọ nínú ìwé náà ní :
Iṣẹ́ alákọ̀wé ṣe débi a ń ṣàgbàro
Ọ̀rọ̀ mìíràn dé mo rí tíṣà tí ń ṣàgbàro
Iṣẹ́ alákọ̀wé ṣe débi a ń gbàgbàkọ
Ọ̀rọ̀ mìíràn dé mo rí tíṣà lọ́rùn ọ̀pẹ
(Ojú-Ìwé
1)
Ẹ mọ́ sìká láyé
Torí à ń rọ̀run
Ẹ mọ́ sìkà láyé
Torí à ń rọ̀run
Bí ẹ bá dé ‘bodè
Ẹ ó rojọ́
(Ojú-Ìwe
8)
Bí mo bá ń lọ sóde
Mà sọ fọ́kọ wúyẹ́wúyẹ́
Bí mo bá ń lọ sóde
Mà sọ fọ́kọ létò létò
Orí ó fún mi lọ́kọ
Kò mà ní gbọkọ ọ̀hún o
(Ojú-Ìwé
127)
Kristian má tí ì wá ìsimi
Gbọ́ bí Ańgẹ́lì rẹ ti ń wí
Ní ààrin ọ̀tá l’o wà
Maa ṣọọ́ra
Oogun ọ̀run-apadi
T’a ko rí ń ko’ra wọn jọ
Wọ́n ń sọ ìjàfára rẹ
Máa ṣọ́ọra
Máa ṣọra bí ẹni pé
Níbẹ̀ ni ìṣẹ́gun rẹ̀ wà
Gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́
Máa ṣọ́ọra
(Ojú-Ìwé
107)
Òwe
Onírúurú ọ̀nà ni òwe ti jẹ yọ
nínú ìwé Ọ̀rẹ́ kó Gbẹlẹ̀ta. Àpẹẹrẹ
ni:
·
Bí òwe ba jòwe ẹni tí a kò bá le
dáhùn, ẹ̀rù ìjà ló ń ba olúwarẹ̀ (Ojú-Ìwé 1-2)
·
Àsọtì ọ̀rọ̀ ní í jẹ́ ọ̀rọ̀ àná ńkọ́?
(Ojú-Ìwé 29)
·
Òmùgọ̀ ènìyàn ní í wí pé tẹ̀dá
tán, bí ẹ̀mí bá wà, ìrètí ń bẹ (Ojú-Ìwé 2)
·
Béèyàn kò bá dé oko baba ẹlòmí-ìn
rí, yóó máa wí kiri pé kò sí oko tí ó to oko bàbá oun. (Ojú-Ìwé
138)
·
Ẹni da éérú ni éérú ń tọ
(Ojú-Ìwé 147)
Ọfọ̀
Ǹjẹ́ mo dewé onísìnkìnrínmini
Àfàimọ-ni-kó-ni-mọ́ra lónìí o
Kí tọmọdé tàgbà máa fẹ́ tèmi o
Itún ló ní kí wọn máa tún mi ṣe
Àbèrè ló ní kí wọn máa bèèrè mi
Tèwe tàgbà ní í fẹ́ràn iyọ̀
Ọmọ kékeré kì í bínú omi
(Ojú-Ìwé
131-132)
Ẹṣẹ-ifá
Àpẹẹrẹ Ẹṣẹ-Ifá tí ó jẹ yọ nínú
ìwé náà ni:
Ọ̀rẹ́ ò gbẹlẹ̀ta
Elèjì l’ọ̀rẹ́ gbà
A díá fún sẹ̀kẹ̀rẹ̀
Ọmọ Aráriwo-mú-sajé
Níjọ́ tí ń fomi ojú ṣè
‘rahùn ajé
Wọ́n ní ẹbọ ni ó rú
Ìgbà ó rúbọ tán
Ajé gbogbo wáá yalé tọ̀ ọ́
Ajé gbogbo wáá rí kúdikúdikúdikúdi
Sánkokágbó Awo Ajífọwọ́bajé
Sòwòjèrè awo Ẹ̀ta
Ẹran balẹ̀
Ojú ń yọ́lọ́dẹ
Ajé níí bojú ọ̀rẹ́-ẹ́ jẹ́
Ìlara àlàjù
Baba elénìní ènìyàn
Ìlara àlàjù
Baba ikú gbígbóná fẹlifẹli
A díá fún ọ̀gẹ̀dè
Tí ń fi ‘lara tọrọ ọmọ lọ́wọ́ Ọ̀rúnmìlà
Ifá ni kó rúbọ ìlara
Nítorí ọ̀gẹ̀dẹ̀ ó gbọ́mọ jó
Ṣùgbọ́n kọ́mọ ó mọ́ bàa s’ikú pọ̀gẹ̀dẹ̀
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ kọ̀, kò rúbọ
Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀
B’ọ́gẹ̀dẹ̀ bá ti yọmọ tán
Ọmọ aráyé á bẹ sógán
Á wáá di ọ̀-bàrà-ọ̀-wàrà-hẹẹ
(Ojú-Ìwé
11-12)
Èjì ogbè awo Alára
Fífẹ́ là á fẹ́’ gún
Gígẹ̀ lá a gẹ̀rìṣà
Oṣó ilé, àjẹ́ ilé
Ẹ wá fẹ́ tèmi lónìí o
Bẹ́wìrì bá pẹnu pọ̀, a fẹ́ná
Ojú kì í pọ́n orí kó má nírun
Ojú kì í pọ́n ààrò kó má rẹru
Ojú kì í pọ́n ààtan kó má gbọrẹ
(Ojú-Ìwé
131-132)
Ọ̀rọ̀ inú Bíbélí
Èyí jẹ yọ bí ó ti hàn ní ìṣàlẹ̀
yìí:
Kristian ma ti’wa’simi
(Ojú-Ìwé 107)
Ọ̀rọ̀ inú Kùránì
Mo mọ ‘Álíámúdù’, ‘Íná Àtọ́ẹ́ná’
Yààsin
Tàbátíàdál
Líílááfí qùáràísh
Líílaàfíí hím
Rìhi láta, sítáì wàsá èfi
fálíyá ‘bùdú ú ... àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
(Ojú-Ìwé
34)
ÌLÒ ÀṢÀ
Àṣà Yẹ̀míwò
Àṣà
yìí jẹ yọ bí àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta yìí ṣe lọ́ sí ọ̀dọ̀ Fabíyìí láti mọ́
bí àjò àwọn yóó ṣe rí. Bákan náà, àwọn ìyàwó Àkàngbé náà lo
ìlànà yẹ̀míwò lọ́dọ̀ Fáworọ́mọ láti le mọ́ ohun tí ó fa àkóbá fún ọkọ
wọn. Lọ́nà kẹta, ìlànà yẹ̀míwò tún wáyé nígbà tí àwọn Ọba àti
ìjòyè ìlú bí Ifá léèrè láti mọ́ ohun tí ó fa àjàkálẹ̀ àrùn wọ
ìlú wọn.
Àṣà Ìbúra àti Ìmùlẹ̀
Èyí
jẹ yọ gẹ́gẹ́ bí àwọn olújẹ̀rìí ṣe ń fi ògún búra ṣáájú kí wọ́n tó
rojọ̀ lórí ohun tí ojú wọn rí. Àṣà ìbúra àti ilẹ̀ mímu yìí tún jẹ
yọ níbi ti Àlàmú àti Bùrẹ́mọ̀ ti mulẹ̀ pẹ̀lú àwọn jànàdùkú tí wọ́n
gbé iṣẹ́ ìpànìyàn fún.
Àṣà Ìfinijoyè
Èyí hàn gẹ́gẹ́ bí Ọ̀ba ìlú
Òkè-Odò ṣe ṣèlérí pé òun yóó fi oyè dá Àkàngbé lọ́lá nítorí
ìwà òdòdò rẹ̀.
Àṣà Ìran-ara-ẹni-lọ́wọ́
Èyí
hàn ni bí ó ti jẹ pé Àkàngbé ń fi owó ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́
nígbà tí wọ́n bá lọ bá a pé kò sí owó lọ́wọ́ àwọn.
Àṣà Ìkóbìnrìnjọ
Èyí hàn bí Ọba ìlú Òkè-odò ṣe
ní ìyàwó tí ó le ni mẹ́wàá. Bákan náà, Àkàngbé ni ìyàwó
méjì.
Àṣà Ìbánidárò
Ó hàn bí àwọn ènìyàn ìlú
Òkè-odò ṣe bá Olóyè Asípa darò nígbà tí wọn jí Bọ́lá ọmọ rẹ̀ gbé
pa.
Àṣà Ìbọ̀rìṣà
Èyí wáyé ni bí ó ti jẹ́ pé wọn
ń bọ Ògún, wọ́n sì ń bọ Ọbalúayé ni ìlú Òkè-Odò. O tilẹ̀ tún hàn
pé wọn ń ṣàmúlò àṣà ìfènìyànrùbọ.
Ẹ̀KỌ́ INU ÌWÉ NÁÀ
·
Ọ̀rẹ́ kò gba ẹlẹ̀ta. Èyí ni pé
méjì ní ọ̀rẹ́ dùn mọ
·
Kò yẹ́ kí ènìyàn máa gbọ́kàn lé
ènìyàn
·
Ẹni bá ṣebi á kórè ibi
·
Òlóòótọ́ kì í kú sípò ìkà
·
Ó tọ́ láti ṣe ìwádìí tó jìnlẹ̀ ṣáájú
ẹjọ́ dídá
·
Alátìlẹ́yìn àti adúrótini ni
obìnrin.
Ìwé Ìtọ́kasí
Adésígbìn, B.
(2008), Ọ̀rẹ́ Kò Gbẹlẹ̀ta. Ìbàdàn: AYUS Publications.
No comments:
Post a Comment