Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀
Yorùbá àti lámèétọ́ ló ti ṣiṣẹ́ lórí obìnrin tàbí ewì obìnrin ní ilẹ̀ Yorùbá.
Iṣẹ́ oríṣìíríṣìí ló wà nílẹ̀ nípa bí àwọn obìnrin ṣe ń ṣe àgbékalẹ̀ wọn àti ipa tí wọ́n ń kó nínú lítíreṣọ̀ àwùjọ lápapọ̀[1].
Ilésanmí ti ṣíṣẹ́ púpọ̀
nípa ọ̀rọ̀ obìnrin tàbí àwọn ewì tí ò jẹ mọ́ obìnrin ní ilẹ̀ Yorùbá (1989,
1991a, 1991b, 1992). Ilésanmí (1989:82-88) ṣiṣẹ́ lórí ipa tí àwọn obìnrin ń
kó láwùjọ Yorùbá láyé àtijọ́ bó ti hàn nínú lítíréṣọ̀ alohùn. Ó jẹ́ kí á mọ
ipa pàtàkì tí àwọn obìnrin ń kó nínú lítíréṣọ̀ àtẹnudẹ́nu àti nínú ìtànkalẹ̀
lítíréṣọ̀ àti ipò tí Yorùbá fi obìnrin sí. Ó ṣàlàyé pé àwọn obìnrin ni
agbátẹrù púpọ̀ ewì ilẹ̀ Yorùbá. Ó sọ pé wọ́n ní àwo tó dàbí ẹni pé o lágbára
ju ti àwọn ọkùnrin lọ. Àwọn lò ni awo ẹlẹ́ẹ̀rìndínlógún, àwọn ló ni awo
ẹlẹyẹ, àwọn ló lẹ́gbẹ òwe, àwọn ló ni ìsàré àti orin Ọ̀ṣun, àwọn ni
agbátẹrù ọ̀pọ̀lọpọ̀ òòṣà tó jẹ mọ́ omi. Àwọn obìnrin ló máa ń gbẹ́ṣìn
ìbílẹ̀ lárugẹ; oríṣìíríṣìí sì ni ijó wọn ní ìgbà àjọ̀dún òòṣà tí wọ́n jẹ́
agbátẹrù rẹ̀.
Nínú iṣẹ́,4r Ilésanmí
(1989:82), ó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ipa tí obìnrin ń kó nínú lítíréṣọ̀
alohùn Yorùbá, ó ní:
Àwọn obìnrin ni agbátẹrù
ọ̀pọ̀ ewì àtẹnudẹ́nu ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní awo tó dàbí ẹni lágbára ju awo
àwọn ọkùnrin lọ… Orin ni, ìṣàré ni, títí kan ìṣọ̀rọ̀-kéwì, ẹnu wọn ni
akọ àparò òṣèré tó jẹ́ ọkùnrin fi gorí ebè, alóyinlétè obìnrin pọ̀ ju
tọkùnrin lọ… Àwọn obìnrin ló máa ń gbẹsìn ìbílẹ̀ lárugẹ.
Sheba (1999:61) náà ṣe
àgbéyẹ̀wò àkójọpọ̀ ewì Adébọ̀wálé (1998) Ìgbà Lónigbàá Kà. Nínú
àgbéyẹ̀wò yìí ló ti ṣe àkíyèsí pé oríṣìíríṣìí kókó-ọ̀rọ̀ ni àwọn ewì náà
mẹ́nu bà. Odidi mẹ́wàá nínú ewì mọ́kànlélọ́gbọ̀n tó wà nínú ewì náà ló jẹ mọ́
obìnrin. Àpẹẹrẹ ewì náà ni ‘ohun ẹlẹgẹ́’ ni àṣẹ tí ó ń rọ àwọn obìnrin
láti gba àṣẹ ọkùnrin tàbí ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ tifẹ́. Àránsí (2003)
sọ pé Ewì “Wọ́n N Wò Yín’, ‘Só Dáa Bẹ́ẹ̀?’, ‘Atẹ́ẹ́rẹ́ Lóge’” ń rọ
takọtabo kí wọn bìlà fún ìwà ìbàjẹ́. Nígbà tí ewì ‘Abiyamọ Ìwòyí’ bu
ẹnu àtẹ́ lu ìwà àwọn obìnrin ìwóyí nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tọ́jú ọmọ. ‘Ọpẹ́
fọba Ńlá’ tako èrò àwùjọ bàba ló-nilẹ̀. Ewì yìí jẹ́ kí á mọ̀ pé abo
lágbára ju akọ lọ. Ní pàtàkì, bí a bá wo ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ìkúnlẹ̀.
Sheba (1999) nínú àtúplẹ̀
ìwé ewì àpilẹ̀kọ Yorùbá yìí, gbà pé àwọn ewì tí obìnrin yìí kọ ṣètọ́fábo ní
ibi tí ò yẹ, wọ́n sì ṣègbèfábo níbi tó tọ́. Bákan náà ló gbà pé àkójọpọ̀ ewì
Adébọ̀wálé yìí gbé àwòrán obìnrin sáyé púpọ̀. Ó fi obìnrin hàn gẹ́gẹ́ bí
àwòkọ́ṣe rere. Ibi tí ó ti yẹ́ kó bá wọn wí, kò ṣàlàìbá wọn wí.
Sheu (2001), nínú Àgbéyẹ̀wò
Àkójọpọ̀ àwọn Ewì, gbà pé àwọn
obìnrin jẹ́ onídájọ́ òdodo nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ obìnrin ẹlẹgbẹ́ wọn.
Sheu (2001:55-67) tún ṣe àgbéyẹ̀wò ìwé ewì àpilẹ̀kọ Ìgbà Lonígbàá Kà
náà. Nínú àtúpalẹ̀ rẹ̀ yìí, ó gbà pé ojúlówó aṣẹ̀tọ́fábo paraku ni Adébọ̀wálé
jẹ́. Nítorí ó pàte obìnrin rere àti àwọn obìnrin tí wọn ń hùwà tí kò bójú mu.
Àránsí (2005), nínú Ìtúpalẹ̀
kókó ọ̀rọ̀ ewì Yorùbá tí díẹ̀ nínú àwọn ònkọ̀wé-bìnrin kọ sòrọ̀ nípa ewì
Adébọ̣̀wálé, Adéjùmọ̀, Thompson àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó gbìyànjú láti wo
iṣẹ́ wọn. Ó ní àwọn obìnrin akéwì ti ṣe iṣẹ́ púpọ̀ bíi iṣẹ́ lórí ọmọ,
ìṣèlú, ìgbéyàwó, ikú, obìnrin àti ìlera. Àrańsí (2005) jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn
obìnrin akéwì gbà pé ọmọ ni iyọ̀ ayé. Ó fi kún un pé wọ́n gbàdùrá pé ọmọ ni
yóò gbẹ̀yìn wa. Nínú iṣẹ́ yìí, a rí i pé àwọn obìnrin akéwì yìí tún jẹ́ kí à
mọ ọ̀nà tí àwọn agbófinró ń gbà fìyà jẹ àwọn ará ìlú fún ọ̀rọ̀ tí wọn kò
mọwọ́ mẹsẹ̀ tí ọ̀daràn mìíràn dá. Nínú iṣẹ́ rẹ̀, ó gbà pé àwọn obìnrin ń kó
ipa pàtàkì nínú ewì àti lítírésọ̀ Yorùbá àti pé kókó ọ̀rọ̀ ewì wọ́n dára, ó dẹ̀
níí ṣe pẹ̀lú àwùjọ. Nítorí àwùjọ ló bí lítírésọ̀; inú àwùjọ ni lítírésọ̀ ti
hù jade; eṣo àwùjọ ni.
Kọ́láwọlé (1997:74) náà
tọ́ka sí i pé:
A
Plethora of female genres exist among the Yorùbá. These include, Obitun songs,
Olòri songs, Arẹmọ songs, Ago-Ọka, gẹ̀lẹ̀dẹ́, Olele and Alámọ̀ songs.
(Ọ̣gọ̀ọ̀rọ̀ ohùn ẹnu tó
jẹ́ pé obìnrin ló ń pè wọ́n pọ̀ nínú àwùjọ Yorùbá. Lára wọn ni orin Obitun,
orin Olorì, orin Arẹmọ, Agọ-ọka, Gẹ̀lẹ̀dẹ́, Olele àti orin Alámọ̀)
Èyí fi hàn pé ipa tí obìnrin
ń kó nínú ohùn ẹnu Yorùbá kò kéré rárá. Ohùn tí àwọn obìnrin máa ń pè jẹ́
ọ̀nà láti fi èrò ọkàn wọn hàn nípa ojú àmúwáyé nínú àwùjọ wọn. Ó sọ pé
“oral genres are strop weapons of self-assertion”; èyí túmọ̀ sí pé, lítírésọ̀
alohùn jẹ́ irinṣẹ́ láti tí ṣe àfihàn èrò inú ẹni. Kọ́láwọlé (1997:74) tẹ̀
síwájú láti sọ pé:
These
oral genres are manifestations of collective woman’s voices, dynamic group
consciousness and a tool of eliciting positive influence on the society.
(Àwọn ohùn ẹnu wọ̀nyí jẹ́
àfihàn èrò àgbájọpọ̀ àwọn obìnrin àti irinsẹ́ láti mú àyípadà tó dára bá
àwùjọ.)
Ayọ̀adé
(2004) siṣẹ́ lórí ìtúpalẹ̀ orin ìbejì ní agbègbè Ọ̀ṣun; ó ṣe ìpín-sí-sọ̀rí
àwọn orin Ìbejì, òrin Ẹbọ Ìwúre, orin to fi ìbejì hàn gẹ́gẹ́ bí òrìṣà àti
orin tó fi agbára àwọn ìbeji hàn.
Ajíbádé
(2002) sọ pé ìyá Ọ̀ṣun tó jẹ́ obìnrin máa ń ní ojúbọ̣ Ọ̀ṣun láti lè mọ
ohun tí Ọ̀ṣun ń fẹ́ fún àwọn aráàlú. Ìyá Ọ̀ṣun ló mọ ẹbọ tó yẹ láti rú
nígbà tí àjálù ibi tàbí àjàkálẹ̀ àrùn bá ń dàámú ìlú; ó mọ irúfẹ́ ẹbọ tó yẹ
láti rú fún àwọn obìnrin tó ń wọ́mọ, àwọn tí àbíkú ọmọ ń dá láàmú àti àwọn
tí ọmọ wọn bá ń sọ̀kùnrùn. Ìyá Ọ̀ṣun jẹ́ ẹni tó jinlẹ̀ nípa oríkì àti orin
Ọ̀ṣun.
ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ
Abímbọ́lá, W. (1968), Ìjìnlẹ̀
Ohun Ẹnu Ifá. Apá Kìíní. Glasgow
Collins.
Abímbọ́lá, W. (1976), Ifá
An Esposition of Ifá Literary Corpus. Ibadan :
Oxford University Press.
Adébọ̀wálé, O. (1999),
“Ìfojú Tíọ́rì Ìṣègbèfábo wo Ipò Obìnrin nínú Ètò Ìgbéyàwó: Àyẹ̀wò Ìtàn Àròsọ
Yorùbá”. Nínú T.M. Ilésanmí (ol.) Yorùbá: A Journal of the Yorùbá Studies
Associations of Nigeria .
Department of African Languages and Literatures, O.A.U., Ile-Ife.
Adébọ̀wálé, O. (1999), Ọgbọn
Ònǹkọ̀wé Alátinúdá. Lagos :
Captstone Publications.
Adéjùmọ̀, G.A. (2002), Rò ó o Re. Ebute Meta, Lagos : The Capstone
Publications.
Adéoyè, C.L. (1979). Àṣà
àti Ìṣe Yorùbá. New York :
University Press.
Adéyínká T.A. (2004), Àwọn
Obìnrin Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀dá Ìtàn Nínú Ìwé Sunday Ẹ̀sọ́ Olúbọ́rọ̀dé, Department
of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo
University , Ile-Ife.
Ajíbádé, G.O. (1999),
“Yorùbá Women Government their Men A Socio-religious Approach to Feminism”,
nínú Ife
Social Science Review. Obafemi
Awolowo University ,
Ile-Ife, 194-201.
Ajíbádé, G.O. (2002),
“Àgbéyẹ̀wò Ọ̀ṣun Òṣogbo nínú Iṣẹ́ Ọnà Ajẹméwì àti Ajẹmáwòrán”. Ph.D
Thesis, Department of African Languages and Literatures, Obáfẹ́mi Awólọ́ẉọ̀
University, Ilé-Ifẹ̀.
Akínjógbìn, A. (ed.) (1969),
Ewì Ìwòyí, Glassgow: Collins & Sons. Co. Ltd.
Àránsí, A.O. (2005),
“Ìtúpalẹ̀ Kókó Ọ̀rọ̀ Ewì Yorùbá tí Díẹ̀ nínú Àwọn Ònǹkọ̀wé-bìnrin kọ”. M.A. Thesis, Department of African Languages
and Literatures, Obafemi
Awolowo University ,
Ile-Ife.
Ayọ̀adé, A.S. (2004),
“Ìtúpalẹ̀ Orin Ìbejì ní Agbègbè Ọ̀ṣun”, Department of African Languages and
Literatures, Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.
Bámgbóṣé, Ayọ̀ (1970),
“Word Play in Yoruba Poetry”, WAL, Vol. 36, No 2.
Dáramọ́lá and Jéjé (1967), Àṣà
àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ibadan :
Onibon-Oje Press.
Ilésanmí, T.M. (1974),
“Olele: Ọ̀kan nínú Ewì Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà” B.A. Long Essay, Department of African
Languages and Literatures, Obafemi
Awolowo University ,
Ile-Ife.
Ilésanmí, T.M. (1988),
“Hearthstones as Cultural Study of Songs in Ijesaland”, Ph.D Thesis, University of Ibadan ,
Ibadan .
Ilésanmí, T.M. (1990),
“Àkóyawọ́ Lítíréṣọ̀ Yorùbá”, Mimeograph.
Ilésanmí, T.M. (1999), Yorùbá: A Journal of the
Yorùbá Studies Associations of Nigeria . Department of African
Languages and Literatures, O.A.U., Ile-Ife.
Kọ́láwọlé, M.E.M. (1997), Womanism
and African Conciousness, ERITREA :
African World Press, Inc.
Kọ́láwọlé, M.E.M. (1998), Gender
Perceptions and Develoment in Africa, ERITREA : African
World Press, Inc.
Ògúnbọ̀wálé, P. (1966) Àṣà
Ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: Oxford
University Press.
Ọláidé, S.J. “Ìpójú Èrò
Ìṣègbèfábo Ṣàtúpalẹ̀ Iṣẹ́ Àwọn Àṣàyàn Ònǹkọ̀wé-bìnrin Yorùbá”, Ph.D Thesis, Obafemi Awolowo
University , Ile-Ife.
Ọlátúnjí, O.O. (1984), Features
of Yorùbá Oral Poetry. Ibadan :
University Press Limited.
Olúdáre Ọlájubù (1976), Ìwé
Àsà Ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: University Press Ltd.
Ọmọlọlá Adéronkẹ́ A.
(1998), “Àgbéyẹ̀wò Orin Ọdún Àrigíyà ní Ìkàrẹ́-Àkókó”. Department of African
Languages and Literatures, Obafemi
Awolowo University ,
Ile-Ife.
Òjó, J.R.O. (1990), The
Position of Women in Yorùbá Traditional Society. Department of African
Languages and Literatures, Obafemi
Awolowo University ,
Ile-Ife.
Ọ̀pẹ̀fèyítìmí, A. (1999),
“Myths and Women of Power in Yorùbá Orature” nínú Gender Perceptions and
Development in Africa . Mary E. Modupe
Kolawole (ol.), ERITREA: African World Press, Inc.
Ọ̀pẹ̀fèyítìmí, A. (1997), Tíọ́rì
àti Ìsọwọ́lò-èdè. Osogbo: Tanimehin-Ola Press.
Ọ̀pẹ̀fèyítìmí, A. (1995),
“Womb to Tomb: Yorùbá Woman Power Over Life and Death”, nínú Ife Annals of
the Institute of Cultural Studies. A Publication of the Institution of Cultural
Studies. Obafemi Awolowo University ,
Ile-Ife. Pp. 55-67.
No comments:
Post a Comment