Sunday, 15 April 2018

ỌMỌ́YẸ


ÌTÀN NÍ ṢÓKÍ[1]
Bàba Kọ́la kú ní àsìkò ìgbà tí Kọ́lá rí ore-ọ̀fẹ́ ètó ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ láti lọ sí ìlú Òyìnbó. Ọ̀kan lára ohun tí yóò mú gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ní ore-ọ̀fẹ́ yìí  kún ojú òsùwọ̀n ni pé wọ́n gbọdọ̀ ní ìyàwó ti ara wọn. Kọ́lá àti ìyá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí ṣètò lórí bí wọn yóò ṣe wá ìyàwó gidi kan fún un. Wọ́n ṣe àṣeyọrí nípa rírí ọmọbìnrin dáradára kan ní àdúgbò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mojèrè. Ọ̀rọ̀ Kọ́lá àti Mojèrè wọ̀ dáadáa; wọ́n nífẹ́ ara wọn púpọ̀, wọ́n sì ń múra àti lọ sí ìlú Òyìnbó. Ó kù díẹ̀ kí àsìkò tó fún ìrìnàjò wọn ni àwọn elétò ẹ̀kọ́-ẹ̀fẹ́ náà sọ pé wọn ò fẹ́ kí àwon ọkùnrin wọn ó mú obìnrin kankan dáni mọ́. Kọ́lá ní láti dá lọ sí ìlú Òyìnbó fún ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó gbé Mojèrè ní ìyàwó tán. Ó ń kọ lẹ́tà sí Mojèrè ní ẹ̀ẹ̀kọ̀kan títí tí ó fi padà wá sílé. Wọ́n tí bá Kọ́lá wá iṣẹ́ sí Èkó kó tóó de, nítorí náà, òun àti Mojèrè ní láti kó lọ sí Èkó ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé Èkó tán, Kọ́lá bẹ̀rẹ̀ síí jayé kiri; kò tọ́jú Mojèrè mọ́. Ó ń gbé ọlọ́mọge mìíràn kiri. Ìyẹn gba gbogbo owó ọwọ́ rẹ̀ tán. Ó ti pẹ́ tí Kọ́lá ti ń yí ìwé owó ni bánkì tó ti ń ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀rẹyìn, àsírí rẹ̀ tú, wọ́n sì gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Mojèrè tí padà sí abúlé sáájú àsìkò náà nítori pé ojú rẹ̀ ti rí tó. Ìya rẹ̀ ti dá a ní okòwò ajé rẹ̀ sì ti ń bugbá jẹ. Kọ́lá padà sí abúlé láti lọ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Mojèrè àti ìyá rẹ̀ ṣùgbọ́n ìyá Mojèrè kọ̀ láti fi ọmọ rẹ̀ lé Kọ́lá lọ́wọ́. Ó ní kí Kọ́lá máa mú ọmọ tí Mojèrè bí fún un lọ. Ìyá Kọ́lá náà ti kú kí ó tó dé nígbà tó kọ̀ tí kọ́lá kò tọ́jú rẹ̀. Kọ́lá ti ìka àbámọ̀ bọ ẹnu. Aṣọ ò bá ọmọ́yẹ mọ́, ọmọ́yẹ ti rìn ìhòhò wọ ọjà.
 
ÀWỌN ÀBÙDÁ ERÉ-ONÍṢE
Eré-oníṣe jẹ́ irúfẹ́ ẹ̀yà lítírésọ̀ kan. A máa ń tètè mọ àwọn akópa. Ó jẹ jáde láti inú àwọn ọdún ìbílẹ̀ wa. A máa ń ní àyè láti tú pẹrẹ́pẹrẹ̀ nǹkan àwùjọ nínú eré-oníṣe. Àwọn àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá máa ń jẹyọ nínú eré-oníṣe . Àwọn àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá náà máa ń jẹyọ nínú rẹ̀.
 
ÌLÀNÀ SỌ-KÍ-N-SỌ: Èyí kìí ṣe ohun tí a wátì nínú ìwé yìí. Òǹkọ̀wé ṣe àmùlò ìlànà yìí dáradára
 
Ẹ̀DÁ ÌTÀN: Àwọn ẹ̀dá ìtàn inú ìwé yìí kò fara sin rárá. Àwọn ni:


SÁDÍKÙ
ṢUBÚỌLÁ
KỌ́LÁ
BÀBÁ ÌJẸ̀BÚ
MOJÈRÈ
BÀBÁ MOJÈRÈ
ÌYÁ GBÀYÍLỌLÁ
GBÀYÍLỌLÁ
KÚDÍ
ÀJÍKẸ́
Ọ̀GÁ KỌ́LÁ
ADÁJỌ́
ỌLỌ́PÀÁ
TÍSÀ
BÀBÁ DAYỌ̀
ÌYÁ DAYỌ̀
DAYỌ̀


 

 

ÀKÒRÍ: Àkòrí wà fún ìwé yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ ṣe àwísí kan sí àkòrí náà. ‘Ọmọ́yẹ’ kìí ṣe àkòrí tí ó bá ìtàn yí mu jù. Ìdí ni pé kókó ọ̀rọ̀ tí yóò kọ́kọ́ wá síwa lọ̀kàn tí a bá gbọ́ àkòrí yí ni pé ‘Ọmọ yẹ ẹni’. Ṣùgbọ́n ìdàkejì kókó ọ̀rọ̀ yìí ni a bá nínú ìtàn náà. Lóòótọ́, a padà ṣe àkíyèsí pé nínú òwe yìí ní àkòrí ti jáde: ‘Aṣọ ò bá ọmọ́yẹ mọ́, ọmọ́yẹ ti rìn ìhòhò wọ ọjà’.

 

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN: Àhunpọ̀ ìtàn yìí kò dán mọ́rán tó. Àkíyèsí ni pé òǹkọ̀wé yìí gbìyànjú láti máa rọ́ ìtàn nínú àkámọ́ sáájú idán tàbí ìran kan, èyí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.

 

IBÙDÓ ÌṢẸ̀LẸ̀: Àkíyèsí ni pé ìtàn yí kò ní ibùdó ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó. Àlèébù ńlá ni èyí jẹ́ fún iṣẹ́ òǹkọ̀wè yìí.

Reference

Adewuyi, Lasun (2002), Ọmọyẹ. Oṣogbo, Nigeria: Newdeal Publishers.



[1] Akintujoye Ayomidotun D. ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment