Sunday, 15 April 2018

Igbá Oró


ÌSỌNÍṢÓKÍ

Ìwé eré oníṣe, Igbá Oró[1], Kinjọ̀ Bọ́lọ́rundúró kọ, dálé ìlú Ifẹ̀-Oòyè tí Adéyẹmí jẹ́ Ọba ìlú náà. Ìlú Ifẹ̀-Oòyè kọjú ogun sí Ìlú Ìlọfà àti ìlú Tìkàlójú nítorí pé wọ́n dìtẹ̀ ọlọ́tẹ̀ sí ọba Adéyẹmí ti Ìlú Ifẹ̀-Oòyè tí Ọládìtàn sì wá jábọ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú Ogun pé ìlú Ifẹ̀-Oòyè borí ogun nípasẹ̀ Fágadé àti Bánúsọ. Inú Ọba Adeyemi dùn láti gbọ́ ìròyìn ayọ̀ yìí. Ní alẹ́ ọjọ́ yìí, ààrá ń sán, òjò ń rọ̀ gan-an, àwọn àjẹ́ mẹ́ta ń ṣe ìpàdé - Ẹyẹ́yẹmi, Ẹyẹdò àti Ẹyẹ́wándé ń sọ ohun tí àwọn ṣe. Fágadé àti Bánúsọ ń lọ lọ́nà ni àwọn àjẹ́ mẹ́ta yọ sí wọn. Àwọn àjẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pè wọ́n ní Kábíyèsí. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún Fágadé àti Bánúsọ nítorí pé  Ọba Adéyẹmí sì wà láyé, kò tíì kú. Àwọn àjẹ́ mẹ́ta yìí ní Ọba lọ́la ni Fágadé, pé àwọn ọmọ Bánúsọ yóò jẹ ọba ìlú Ifẹ̀-Oòyè náà. Orí ọ̀rọ̀ yìí ni Fágadé àti Bánúsọ wà nígbà tí Addédèjì àti Ọládìtàn dé pé Ọba Adéyẹmi ń pe Fágadé ni ààfin. Ọ̀rọ̀ náà ya Fágadé àti Bánúsọ lẹ́nu, bóyá ọ̀rọ̀ tí àwọn àjẹ́ mẹ́ta yìí sọ fẹ́ wá sí ìmúṣẹ. Ọba Adéyẹmi fi oyè ńlá dá Fágadé lọ́lá; ó di olóyè Olufi àti olóyè Olúonà. Ìyàlẹ́nu ni gbogbo èyí jẹ́ fún Fágadé inú rẹ̀ sì dùn gidi. Fágadé fi ìwé kékeré kan sílẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀, Àdùkẹ̀, láti sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un; ibi tí Àdùkẹ́ ti ń ka ìwé yìí ni ìráńṣẹ́ Ọba Adéyẹmi ti wọlé láti jíṣẹ́ fún Àdùkẹ́ pé Ọba Adéyẹmí ń bọ̀ láti wá bá wọn lálejò. Lẹ́yìn tí Àdùkẹ́ rí i pé Ọba ń bọ̀ wá bá wọn lálejo ni ara rẹ̀ kò  ti balẹ̀ mọ́; èrò oríṣìíríṣìí ló ń wá sí i lọ́kàn. Ọba Adéyẹmi wá sílé Fágadé ní ìlú Fìdítì pẹ̀lú àwọn ìjòyè àti ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn oúnjẹ́ alẹ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbádùn tí Fágadé fi tọ́jú àwọn àlejò, oníkálukú wọ inú yàrá lọ. Fágadé wà lórí ìrònú nígbà tí Àdùkẹ́ wọlé tì í pé àsìkò tí ó yẹ kó gba gbogbo ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ Ọba Adéyẹmí ló ṣí sílẹ̀ fún un, pé Fágadé yẹ kí ó dádé, kí ó jọba ìlú Ifẹ̀-Oòyè nítorí àwọn ìyàa mi wà lẹ́yìn rẹ. Àdùkẹ́ ní kí Fágadé jẹ kí wọ́n pa ọba Adéyẹmi kí ó baà lè jọba ìlú Ifẹ-Oòyè. Àdùkẹ́ ní kò sí ẹni tí yóò mọ̀ pé àwọn ni ó pa Ọba.

            Bánúsọ àti Fárínu wọlé dé pẹ̀lú àtùpà lọ́wọ́; wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ wọlé sùn lẹ́yìn tí gbogbo àwọn yòókù ti wọlé sùn. Ara ń fu Banúsọ, ẹ̀rù ń bà á, ọkàn rẹ̀ kò sì balẹ̀. Bí wọ́n ti ń wọlé ni Fágadé pàdé wọn lọ́nà, ó ya Fágadé lẹ́nu pé Bánúsọ kò tíì sùn; àwọn méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ bí inú ọba Adéyẹmí ṣe dùn láti wá sílé Fágadé; lẹ́yìn èyí Fágadé wọlé lọ. Bánúsọ náà wọlé lọ sùn. Fágadé rí i pé gbogbo ènìyàn ti wọlé lọ sùn ó sì lọ ṣe èrò ibi tí ó ní lọ́kàn sí Ọba Adéyẹmí. Lẹ́yìn tí Fágadé ti pa ọba Adéyẹmi tán, Àdùkẹ́ ń gbọ̀n bí ewé ojú omi, ara àwọn méjèèjì ń gbọ̀n pàápàá ìgbà tí ẹyẹ òwìwí fọhùn arò.

Lẹ́yìn gbogbo èyí tí ilẹ̀ mọ́ tán, asọ́bodè gbọ́ tí ẹnìkan ń kan ìlẹ̀kùn, ẹni náà sì ń kan ìlẹ̀kùn léraléra. Fágadé dìde láti lọ sí ìlẹ̀kùn. Adéjọbí àti ládẹ̀jọ kí Fágadé wọ́n sí bèèrè Ọba Adéyẹmí pé òun ni wọ́n fẹ́ wá jí pé ilẹ̀ ti mọ̀. Adéjọbí wo yàrá tí Ọba Adéyẹmí sùn sí; igbe oró ni Adéjọbí fi bọnu láti inú yàrá. Fágadé àti Ọládèjì wọnú yàrá ti Adéjọbí; àwọn méjèèjì kígbe oró. Igbe oró yìí ni Àdùkẹ́ gbọ́ tí ó sì wọlé. Àdùkẹ́ kígbé oró, ó ń gbá ara rẹ̀ mọ́lẹ̀; gbogbo wọ́n ń kígbe oró, wọ́n ń sunkún. Máyọ̀wá àti Súnkànmí sọ̀rọ̀ sétí ara wọn pé kí àwọn méjèèji tètè máa sá lọ nìtorí pé ikú ń rùn lórí àwọn méjèèjì nìtorí pé àwọn ènìyàn rò pé àwọn ni ó pa ọba Adéyẹmi; gbogbo ènìyàn péjọ sílé Fágadé.

            Lẹ́yìn ikú ọba Adéyẹmí, Fágadé bọ́ sórí oyè; wọ́n fi i jẹ ọba ìlú Ifẹ̀-Oòyè; inu rẹ̀ dùn nítorí pé ohun tí ó ń fẹ́ ti tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Lẹ́yìn èyí, ọba Fágadé ránsẹ́ sí Bánúsọ pé kí ó wá sí ààfin òun. Kò jẹ́ kí ó mọ èrò tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ sí i. Ó gbé ẹsin fún Bánúsọ nítorí pé Bánúsọ fẹ́ràn ẹsin. Ọba Fágadé ní ayẹyẹ tí ó fẹ́ ṣe ṣùgbọ́n Bánúsọ ṣèlérí pé òun yóò padà wá. Nígbà tí Bánúsọ lọ tán, Fágadé sọ fún Àdùkẹ́ pé ọkàn òun kò balẹ̀ sí Bánúsọ àti ọmọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá wà láyé pé òwú ni wọ́n, wọn ò ṣe é fẹ̀yìn tì. Ọba Fágadé ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn wọ̀ǹpárì láti pa Bánúsọ àti ọmọ rẹ̀. Wọ́n rí Bánúsọ pa ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ sá lọ. Ní ibi ayẹyẹ tí Fágadé ń ṣe lọ́wọ́, àwọn ìjòyè rí i pé Bánúsọ kò sí níbẹ̀; ọ̀rọ̀ náà ká Ọládìtàn àti Ọládèjì lára púpọ. Níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ Bánúsọ ni ẹbọra Bánúsọ wọlé ó sì jókòó sórí ìjókòó Fágade. Ara Fágadé n gbọ̀n nígbà tí ó rí ẹbọra Bánúsọ, ó sì sọ oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ lẹ́nú. Ẹ̀rù bá gbogbo àwọn ìjòyè. Àdùkẹ́ fi ọgbọ́n sọ fún àwọn ìjòyè pé bí ó ṣe máa ń ṣe akọni èèyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni. Ọba Fágadé ń sọ oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu sí àwọn ìjòyé nípa ẹbọra tí ó ń ranjú mọ́ òun. Àdùkẹ́ dá ọgbọ́n pé bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà mìíràn nìyí ṣùgbọ́n ọjọ́ ayẹyẹ tí ó jẹ́ ni ó jẹ́ kí ó dun òun nítorí pé ó ti ba ayẹyẹ náà jẹ́. Àdùkẹ́ ní kí àwọn ìjòyè máa lọ ile wọn. Fágadé bèèrè lọ́wọ́ Àdùkẹ́ ìdí tí Adéjọbí kò fi wá síbi ayẹyẹ tó ṣe. Àdùkẹ́ bèèrè bóyá ó ráńṣẹ́ pe Adéjọbí, ọba Fágadé ní òun pè é. Bákan náà ni Fágadé ro bí yóò ṣe lọ bá àwọn àjẹ́ láti bèèrè bí ọ̀rọ̀ náà yóò ṣe rí. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Ọba Fágadé ṣe ayẹyẹy ni àwọn ẹlẹyẹ ṣe ìpàdé láti bayé Fágadé jẹ́; wọ́n ṣe ìpàdé láti padà lẹ́yìn Fágade, kí wọ́n sì tì í sẹ́nu ikú.

            Ní àdúgbò kan ní ìlú Ifẹ̀-Oòyè, Ọládìtàn wọlé pẹ̀lú ìjòyè kan, wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ ìwà ìkà tí Ọba Fágadé ń hù láàrin ìlú; bí ó ṣe pa ọba Adéyẹmi àti Bánúsọ, tí ó parọ́ mọ́  àwọn ọmọ Ọba Adéyẹmí, Súnkànmí àti Máyọ̀wá pé àwọn ni ó pa bàbá wọn. Irọ́ kan yìí náà ni ó pa mọ́ Fárínú ọmọ Bánúsọ àti bí ó ṣe fi ìbínú pa àwọn ẹ̀sọ́; gbogbo ìwá wọ̀nyìí kò tẹ́ àwọn ìjòyè lọ́rùn. Ìdí nìyìí tí Adéjọbí kò fi wá síbi ayẹyẹ tí Ọba Fágadé ṣe. Ọba Fágadé tọ àwọn ẹlẹyẹ lọ kí wọ́n fún un kún agbára. Àwọn ní àwọn wà lẹ́yìn rẹ̀, pé ẹni tí obìnrin bí kò le káwọ́ rẹ̀. Ní ilé Adéjọbí, ìyàwó àti ọmọ Adéjọbí, Olúrọ́pò, wà nínú ilé pẹ̀lú Adédèjì, tí ó sì wá sọ fún Oyíndà, Ìyàwó Adéjọbí, pé Adéjọbi ti sá lọ ní ìlú. Ẹ̀rù ba Oyíndà láti gbọ́ èyí; ìdí tí ọkọ rẹ̀ fi máa sá lọ kúrò nílé láìronú òun àti ọmọ kò yé e. Adédèjì pàrọwà sí Oyíndà ó sì ní Ọlọ́run ni gbogbo ọ̀rọ̀ náà yé. Bí ìyá àti ọmọ ṣe ń sọ̀rọ̀ bí wọn yóò ṣe máa jẹun ni ìránṣẹ́ ọba Fágadé wọlé tí ó sì bèèrè Adéjọbí; Oyíndà fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí Wọ̀ǹpárì ìdí tí ó fi ń bèèrè ọkọ rẹ̀. Wọ̀ńpárì ní ọ̀dàlẹ̀ ni Adéjọbí. Ìbínú yìí ni Olúrọ́pò fi sọ̀rọ̀ sí Wọ̀npárì nìtorí pé ó pe Adéjọbí ní ọ̀dàlẹ̀. Wọ̀ǹpárì fi ọ̀bẹ gún Olúrọ́pò àti ìyá rẹ̀, Oyíndà.

            Ní ìlú Ìgbẹ́tì tí Máyọ̀wá àti Adèjọbí sá lọ ní yàrá kan ni ààfin ọba Ògídíolú, àwọn méjèèjì jọ ń sọ̀rọ̀ bí ìlú ṣe bàjẹ́, tí Fágadé ti sọ orí ìlú kọdò tí ohun gbogbo kò lọ déédéé mọ́ fún àwọn ènìyàn nílùú. Máyọ̀wá bèèrè ìdí tí Adéjọbí fi sá kúrò ní ìlú láìmú ìyàwó àti ọmọ dání. Ẹ̀rù ló ń ba Adéjọbí kí wọ́n má pa òun nítorí pé òun ló ṣẹ Ọba Fágadé kìí ṣe ìyàwó òun àti ọmọ òun. Máyọ̀wá àti Adéjọbí sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmúyẹ tí ó yẹ kí wọ́n bá lára adarí. Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Àkínrefọ̀n wọlé; àwọn mẹ̀tẹ̀ẹ̀ta kí ara wọn. Akínrefọ̀n sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìlú fún Máyọ̀wá àti Adéjọbí ṣùgbọ́n bí Adéjọbí ṣe bèèrè ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ Akínrefọ̀n ni ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n; kò lè sọ̀rọ̀. Akínjọbí ní kó sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí fún òun. Akínrefọ̀n ní Ọba Fágadé ti pa ìyàwó àti ọmọ rẹ̀. Inú Akínjọbí bàjẹ́; ara rẹ̀ ń gbọ̀n; kò mọ ohun tí yóò ṣe. Omi ẹkún ń dá lójú rẹ̀ nígbà tí Máyọ̀wá àti Akínrefọ̀n ń bẹ̀ ẹ́. Ní ààfin Ọba Fágadé, ara Àdùkẹ́ kò yá; ó ti ní ààrùn ọpọlọ; àwọn oníṣègùn Òyìnbó gbìyànjú láti jẹ́ kí ara rẹ̀ yá ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo wàhálà wọn

            Ní ààfin ọba ìlú Ìgbẹ́tì, a rí Akínyẹmí, Akínrefọ̀n, Adédèjì àti Ọládèjì pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun ìlú kan tí ó wà lẹ̀bàá ìlú Ifẹ̀-Òòyè; àwọn ọmọ ogun ìlú Ìgbẹ́tì kò gbẹ́yìn rárá, wọ́n ń ṣe ìpàdé bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Ọba Fágadé. Máyọ̀wá, ọ̀gágun Ògèdèǹgbé, àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú Adéjọbí àti àwọn Ológun ṣe ń yan lákọlákọ wọ ìlú Ifẹ̀-Oòyè; ọ̀kan lára ìránṣẹ́ ọba Fágadé rí àwọn ológun; ó sá padà lọ́ sí ààfin láti fi tó Fágadé létí; ara Fágadé ń gbọ̀n; ẹ̀rù ń bà á ṣùgbọ́n òun náà múra ogun. Lẹ́yìn gbogbo ọfọ̀ tí Adéjọbí àti Fágadé sí ara wọn, Adéjọbí ṣẹ́gun Fágadé; Fágadé ṣubú lulẹ̀ ó sì kú; inú àwọn ará ìlú Ifẹ̀-Oòyè dùn wọ́n sì fi Màyọ̀wá jẹ ọba ìlú Ifẹ̀-Oòyè.

 

 

 

 

 

ÀWỌN ỌNÀ ÈDÈ NÍNÚ IGBÁ ORÓ

ÒWE

-           Ọmọ tí ẹkùn bí, ẹkùn ni ó jọ

-           Àgbàlagbà tó bá ń sáré nínú ẹ̀gún, bí kò bá lé nǹkan, a jẹ́ pé nǹkan ń lé e

Nínú ìran kejì (pg 5, 6)

-           Bálẹ́ yóò ti ri, ẹ bòwúrọ̀ léèrè              (pg 18)

-           Ibi tí ó bá wu ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ ni í darí ìgbẹ́ sí

-           Bíná bá kú, a feérú bojú, bógẹ̀dẹ̀ bá kú a fọmọ rẹ̀ rópọ̀

Nínú ìran kẹrin (pg 22, 23, 24)

-           Ẹni bá fẹ́ jẹun gbọingbọin, dandan ni kó tìlẹ̀kùn gbọingbọin

-           Ẹni tó fẹ́ joyin inú àpáta kò gbọdọ̀ wẹnu àáké

-           Ẹni tí ó sì mọ́bọ, dandan ni kó ṣe bí ọ̀bọ

-           Ṣé ilé làpótí jókòó sí dèdìí                               (pg 27, 31)

-           Ewúrẹ́ wọlé kò kágò, àgùtán wọlé kò kágò, ni wọ́n bá mú wọn so  (pg 34)

-           Ẹni tọ́wọ́ rẹ̀ ò tíì tẹ kuku idà, kò gbọdọ̀ bèèrè ikú tó pa baba rẹ̀

-           Awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bọnú, kò kúkú jẹ a rí ikùn aṣebi

-           Ogun àwítẹ́lẹ̀ kìí parọ tó bá gbọ́n

-           Bójú bá yẹjú, kóhùn má yẹhùn

Nínú idán kẹta (pg 72, 73)

-           Àjẹ̀ ké lánàá, ọmọ kú lónìí                              (pg 77)

-           Bí ìgbín bá fà, ìkarahun a tẹ̀lé e

-           Bóníṣègùn bá rojọ́ dandan ni kó jàre ẹni to fiwọ pa

-           A ti fòjé bolóòṣà lọ́wọ́, baba ẹni tí ó bọ́ ọ ló kù

(pg 83, 85)

-           Adìẹ ìrànà kìí ṣẹran àjẹgbé

-           Kò sí ẹni tó wọdò tán tó tún ń kígbe òtútù

(pg 110, 111)

-           Ẹni rọ́ba fin, dandan ni kó ríjà ọba                 (pg 118)

-           Àgùtàn tó bá bájá rìn, dandan ni kó jẹ ìgbẹ́

-           Ìfura lòògùn àgbà

-           Ọ̀run ń ya bọ̀ kìí ṣọ́rọ́ ẹnìkan

-           Ọ̀rọ̀ ò lè tóbi títí ká fọ̀bẹ bù ú

Nínú idán kẹrin           (pg 139, 141)

ÀFIWÉ TÀÀRÀ

-           Ọ̀rọ̀ ọ̀hún sú dudu bí aró

-           Gbogbo rẹ̀ wá dàbíi òkè Gọ́lígọ́tà

-           Bẹ́ẹ̀ ni yóò máa hùwà bí ẹlẹ́gùn Sàngó

-           Yóò rù hangogo bí ajá tí ebi ń pa

-           Tí wọ́n dàbí àkísà orí ọ̀rọ̀

-           Àwa là ń layé já bí ẹni lami

-           Àwa tá ń ròkun erémi bí ẹni roko

-           Irungbọn rẹ̀ bíi jọjọ àgbò

-           Alẹ́nu má fọhùn bí agbo ògiri

-           Wọ́n ti rá bí isó

-           Ọba tó lọ́kàn tútù bí àdàbà

-           Akọ akọ bí tògìdán

-           Wọ́n ń hanrun bí ìgbà ààrà ń sán

-           Tí mo ń gbọ̀n rìrì bí ẹ̀rọ alùpùpù

-           Kó mọ́ sáká bí ọwọ́ aláìlẹ́jẹ̀ lọ́run

-           Bí a gbó gbó gbó bí olú ogbó

-           Orí adé ti sán lọ bí ẹyẹ

-           Ìbínú ru bòmí bí ọṣẹ

-           Gbogbo wọn ló sì ń wò kòò bí màálù rọ́bẹ̀

-           Níbi tẹ́jẹ̀ ọba ti pọ́n lóló bí epo

-           Tó rẹ̀ dòdò bí osùn

-           Tó ń tu pùtù bí omi inú àpáta

-           Wọ́n ń wò kòò bí orí ẹran

-           Ọ̀run tó sú dúdú bí aró

-           Ó láyà bí i kìnìún

-           Bó o gbọ́n bí Ifá

-           Bó o mọ̀ràn bí ọ̀pẹ̀lẹ̀

-           Tó o wá gbé ìrònú wọ̀ bí agbọ́n

-           To sì ń gbọ̀n rìrì bí alùpùpù gòkè odò

-           Mo kúkú rí i tí ó ń gborí pẹ́pẹ́ bi aláǹgbá

-           Ẹ̀mí amùjẹ́ bí ẹni mumi

-           Tó burú bí ejò olóró

-           Kó o lóró nínú bí i tẹsin

-           Ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà lèsù ń hùwà bí ti màlékà

-           Kára ó tu ọba bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ etídò

-           Gbogbo wọn ni ń kùn hùnnùhùnnù bí òkú tí ò fọmọ sáyé

-           Kóníkálukú ó múra gírí bí akọni

-           Ayé ti ń jó ó tán bí iná àbẹ́là

ÀWÍTÚNWÍ

-           Ẹ wò sùn sùn sùn

-           Àní bẹ́ẹ bá mọ̀ràn mọ̀ràn

-           Kààsà kààsà ń bọ̀ lẹ́yìn

Kààsà kààsà rè é

-           Tójú dá wáú

Tójú wá kan gbinrin gbinrin

-           Ìbà yẹ mí, yẹ

Ìbà sì sàn sàn sàn

-           Ká jìjọ jó jó jó

Ká jìjọ yọ̀ yọ̀ yọ̀

-           Ọkùnrin bìrìmù bìrìmù

-           Tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù làwọn ọmọ ogun ń rìn

-           Tó dágbà dàgbà

-           Igbe wọn ń bọ̀, wọ́n ń bọ̀

ÌFOHUNPÈNÌYÀN

-           Agogo ti ró gban-un

-           Agogo ọ̀ràn

-           Agogo ti ránṣẹ́ pe Ọba Adéyẹmi       

 

Bolorunduro, Kinyo (2008), Igbá Oró: A Creative Translation of Shakespeare’s Machbeth to Yorùbá Language. Ilesa, Nigeria: Fobol Publications Nig. Ltd.



[1] Ogunruku Gbemisola Tolulope ló kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment