Sunday, 15 April 2018

ÀWỌN ÀKÙKỌ MÉJÌ


ÌSONÍṢÓKÍ[1]

Ìtàn àwọn àkùkọ méjì ní ìletò Sálúkà: Adìẹ olópìpì àti adìẹ arẹwà. Adìẹ olópìpì yìí kò ní ìyẹ́ tí ó jọni lójú, bí ó sì ti wù kí ó gbìyànjú tó, kò lè kọ jákè lá-lá bí ẹnìkejì rẹ̀. Adìẹ arẹwà yìí lẹ́wà gidigidi, ó ga títí dé orí, a máa kọ lá-lá, a sì máa fi ìgbà gbogbo tún ìyẹ́ aláràbarà rẹ̀ tò, àwọn ará ìlú fẹ́ràn rẹ̀ jọjọ. Ìfẹ́ tí àwọn ará ìlú ní sí adìẹ arẹwà yí kò dùn mọ́ adìẹ olópìpì nínú, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí ronú sí ohun tí òun le ṣe láti lé adìẹ arẹwà yìí dànù tàbí kí ó mú kí àwọn ènìyàn kóríra rẹ̀. Ó mọ̀ pé òun ní ọgbọ́n inú, ó sì ṣe tán láti fi ṣe ìkà fún arẹwà adìẹ. Ó wá ọ̀nà tí ó fi mú kí adìẹ yìí kọ lọ́gànjọ́ òru, tí ó sì jí àwọn ará ìlú sílẹ̀. Inú àwọn ará ìlú kò dùn sí èyí rárá; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí kóríra rẹ̀ débi pe wọ́n wá ọ̀nà tí wọ́n fi tà á sí ìlú kejì. Inú adìẹ olópìpì dùn pé òun ti lé èkejì òun lọ, ó ti wá ku òun nìkan ní ìlú báyìí. Adìẹ olópìpì yìí kọ títí lòwúrọ̀ ọjọ́ kejì láti jí àwọn ará ìlú ṣùgbọ́n kò sí eni tó gbọ́ ohùn rẹ̀ rárá. Nígbà tí ó rí i pé kò sí ẹni tó jáde títí tí oòrùn fi ràn, ó yára tètè bá ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó di ìlú òdìkejì. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí ó dé ìlú kejì, ó tún bá ara rẹ̀ lórí òrùlé pẹ̀lú adìẹ ńla arẹwà aláràbarà.  Ǹjẹ́ adìẹ tó dìtẹ̀ rẹ̀ lọ́jọ́sí kọ́ yìí ni?

ÀṢÀ ÌKÍNI

Ọ̀rọ̀ lórí àṣà ìkíni nílẹ̀ Yorùba jẹyọ nínú ìwé yìí. Àkíyèsí ni pé, tí àwọn ènìyàn bá ti jí ní òwúrọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n máa ń kí ara wọn.

OWÚ JÍJẸ

Bí ó ṣe wà láàrin àwọn ọmọ ènìyàn náà ló wà láàrin àwọn ẹranko. ṣènìyàn-ṣẹranko, sẹranko-ṣènìyàn. Àwọn adìẹ nàá ń dìtẹ̀ ara wọn. Èyí han kedere nínú ìwà tí adìẹ olópìpì hù sí adìẹ arẹwà nínú ìtàn yìí. A tún le tọ́ka sí àwọn àbùdá ènìyàn tí a gbé wọ àwọn eranko wọ̀nyí nínú ìwé yìí.

KÁDÀRÁ

Ó yẹ kí àwa ọmọnìyàn fi èyi ṣe àríkọ́gbọ́n. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó wà ní àyíká wa ni Adẹ́dàá fi síbẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìdàgbàsókè wa. Àkíyèsí ni pé láìsí adìẹ arẹwà tí ó wà ní àyíká adìẹ olópípì yìí, adìẹ olópìpì kò le wúlò. Ẹwà ìgbáyégbádùn ni kí á máa ran ara wa lọ́wọ́. Kálùkù ló ní ìwúlò tirẹ̀. Ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa láti rí i pé bí adìẹ olópìpì ti gbìyànjú tó láti lé adìẹ arẹwà náà kúrò, níṣe ló tún bá ara rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìlú kejì

ÌBÁGBÉPỌ̀

Ohun ìdùnú ni ó ń jẹ́ fún àwọn ará ìletò Sálúkà láti máa jí lówùúrọ̀, wọ́n máa ń bá ara wọn jíròrò. Tí ó bá di pé wọ́n fẹ́ ṣe ìpinu kan, wọ́n jọ máa ń fikùnlukùn ni. Gbogbo wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ adìẹ arẹwà tó dá oorun mọ́ wọn lójú lọ́jọ́sí. Wọń sì gbé e tà.

ẸWÀ

Ẹwà jẹ́ nǹkan tó máa ń mú kí àwọn ènìyàn tó wà nì agbègbè fẹ́ràn ẹni. Kò sí ẹni tó rí nǹkan tó rẹwà tí kò níí fẹ́ ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀.

Reference

West African Book Publishers Ltd (1977), Awon Akuko Meji. Lagos, Nigeria: West African Publishers Ltd.



[1] Akintujoye Ayomidotun D. ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment