Iwé yìí jáde ní ọdún 2003[1]. Ìwé yìí dá lé orí Rẹ̀mí, tí ó jẹ́ Olú-ẹ̀dá ìtàn. Mosúnmọ́lá, ìyá Rẹ̀mí, fẹ́ Ọlárìn-inre, ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀, fún ìgbà pípẹ́; láti ìgbà tí Mosúnmọ́lá
ti bí ọmọ kan yìí ni kò ti gbọ́ pá bẹ́ẹ̀
ni kò gbọ́ po mọ́. Rẹ̀mí wá di ojú
kan ẹ̀pà ojú kan erèé fún àwọn tọkọtaya; fún ìdí èyí ni Mosúnmọ́lá ṣe ń kẹ́ Olúrẹ̀mì ní ojú àti
nímú; kì í jẹ́ kí bàbá rẹ̀
gan-an kó fi ọwọ́ kàn án; ariwo ni wọ́n pa mọ́
Mosúnmọ́lá tí ó fi jẹ́ kí ọmọ náà lọ sí ilé-ẹ̀kọ́; kì í jẹ́ kí tísà kó fi ọwọ́ kan Rẹ̀mí. Pẹ̀lú gbogbo ìwà
yìí ni Rẹ̀mí ṣe di ọmọ àkẹ́bàjẹ́.
Ìgbà tí Rẹ̀mí di ọmọge ni
ó gbé igbá ìranù; ó mú òwò ṣìná lójú
páálí. Kì í ṣe pé òbí rẹ̀ kò ní owó láti tọ́ Rẹ̀mí, àmọ́ ojú
kòkòrò rẹ̀ ni ó fa èyí. Ó ṣe sìná dé ibi tí ó ti rí oyún he; kò sì mọ ẹni tí ó ni oyún náà; àwọn ọkùnrin méjì ni ó sọ pé wọ́n ni oyún náà. Èyí fa kí
ọ̀kan nínú wọn ṣe ikú pa Mosúnmọ́lá tí wọ́n sì ta ìbọn mọ́ Àjíkẹ́, ọ̀rẹ́ rẹ̀, lẹ́sẹ̀. Rẹ̀mí kó àrùn kògbóògùn ó sì ti ibẹ̀ dágbére fún
ayé.
Ìtàn ọlọ́rọ̀-geere ni ìwé
yìí jẹ́. Ọ̀nà èdè ibẹ̀ kò pò.
Ọ̀nà-èdè
Àwọn ọ̀nà-èdè tí ó wà nínú ìwé yìí ni:
1. Àsọdùn / àsọrégèé
2. Àfiwé tààrà
3. Òwe
4. Orin
5. Àwítúnwí
6. Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
1. Àsọdùn / Àsọrégèé
...... ọ̀nà náà fẹ̀ tó èyí tí mọ́tò máa ń gbà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn
...... pg 1
...... Ikun imú rẹ̀ ọ̀tún fẹ́rẹ̀ bọ́ sí ti òsì ...... pg 2
...... Ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ ...... pg 6
2. Àfiwé tààrà
...... Kí òun náà
máa ṣe bí alákọ̀wé ...... pg 2
...... Oko bàbá rẹ̀
ló sì lọ bí ọlá Ọlọ́run yìí ...... pg 3
...... Wọ́n sì fẹ́ràn
bàbá Mosún bí ẹ̀mí ...... pg 5
...... Nṣe ni
bàbá náà sì ń pààrọ̀ aṣọ bí ọ̀gà ...... pg 8
...... Ìyàtọ̀
tó kúná bí etí ...... pg 9
3. Òwe
Òwe jẹ́ àkópọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí
àsàyàn àwọn ọ̀rọ̀ tí ó gba àròjinlẹ̀. Nítorí pé àwọn baba ńlá wa jẹ́ aláròjinlẹ̀ àti alákíyèsí
àwùjọ wọn ni wọ́n ṣe máa ń pa òwe. Ó jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ tí wọ́n ń lò ní ọ̀nà
àrà. Òwe inú ìwé yìí ni:
§ Wọ́n ní báa bá dàgbà tán, ó yẹ kí ayé ogun í jà ...... pg
5
§ Ṣé ọmọ ọba kì í sì í nìkan ràjò ....... pg 11
§ Òrò ni àna, ẹnìkan kì í fi í ṣeré ...... pg 16
§ Kàkà kí eku má jẹ sèsé yóò fi sàwàdànù ......pg 46
§ Wọ́n ní a kì í kẹ́ ọmọ kan kí ó di méjì ...... pg 22
§ Obìnrin jàjà nà mi ni wọ́n fi í na apọ́n pa ...... pg 22
§ Ọlọ́mọ kan kúrò ní kò bí ọ̀kan rí ...... pg 23
4. Orin
Orin jẹ́ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ní bí a ṣe ń gbé e kalẹ̀; ó ní pátànì tirẹ̀ àti ìlànà pẹ̀lú. Àpẹẹrẹ nínú ìwé yìí ni:
a.
Ọmọ olóore nìyí o
Ẹ ò fẹ́ràn
àtẹ̀ẹ̀bà yẹ́ ẹ sí o
Ọmọ Olóore
nìyí o
Ẹ ò fẹ́ràn
àtẹ̀ẹ̀ba yẹ ẹ sí o ...... pg 12
b.
Ìbálé dowó o,
Mosúnmọ́la,
tọ́jú abẹ́ rẹ o
Má fìbálé
gba kóòkì
Ìbálé dowo o
Mosúnmọ́lá,
tọ́jú abẹ́ rẹ o ...... pg 17
c.
Ilé ọkọ ṣòro
Ta ni kò mọ
pé ilé ìyá dùn-ún gbé
Ilé ọkọ ṣòro
Bóo gúnyán lẹ́bẹ́,
wọn a ló ní kókó
Ilé ọkọ ṣòro
...... pg 19
d.
Alámọ tó mọríì mi
Ló sọ mi di ìyá
Rántí
Alámọ̀ tó mọríì
mi
Ló sọ mí di
ìyá Rántí ...... pg 23
Àwítúnwí
...... Ọmọ olóore nìyí o
Ẹ ò fẹ́ràn àtẹ̀ẹ̀bà yẹ́ ẹ sí o
Ọmọ olóore nìyí o
Ẹ ò fẹ́ràn àtẹ̀ẹ̀bà yẹ́ ẹ sí o
...... pg 12
Àwítúnwí
odidi gbólóhùn ni àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí
...... Ìbálé dowó o,
Mosúmọ́lá tọ́jú abẹ́ rẹ o
Má fìbálé gba kóòkì
Ìbálé dowó o ...... pg 17
Mosúnmọ́lá, tọ́jú abẹ́ rẹ o
Àwítúnwí odidi gbólóhùn ni èyí
jẹ́ pẹ̀lú
...... Ilé ọkọ ṣòro
Bó o gúnyán lẹ́bẹ́, wọn a ló
ní kókó
Ilé ọkọ ṣòro
Bó o rokà lẹ́bẹ́, wọ́n a ló rọ̀
púpọ̀
Ilé ọkọ ṣòro
Àwítúnwí ẹlẹ́yọ
ọ̀rọ̀ ni àpẹẹrẹ òkè yìí jẹ́.
...... Alámọ̀ tó mọríì mi
Lo sọ mí di ìyá Rántí
Alámọ̀ tó mọríì mi
Ló sọ mí di ìyá Rántí ......
pg 23
Àwítúnwí
odidi gbólóhùn ni èyí jẹ́
Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
...... Ó gba òfo ju kùpọ́ọ̀nù lọ ...... pg
25
IWÉ-ÌTỌ́KASÍ
Ọ̀pádọ̀tun, Ọlatunji (2003): Ikú Ọmọ. Ikẹja, Lagos: Longman Nigeria Plc.
No comments:
Post a Comment