Bóyè Babalọlá ni ó kọ ìwé yìí ní ọdún 1956. Nínú ìwé yìí, ọ̀nà tí a ń gbà
sun ìjálá ni òǹkọ̀wé mẹ́nu bà. Ọ̀nà náà jọ bí ìgbà
tí a bá ń ké ewì; ìlà sẹ́ki sẹ́ki ni
ó máa ń gbà wáyé, nítorí náà ni a ṣe lè rí àwọn ọ̀nà-èdè àti àwọn nǹkan
mìíràn tí a lè fi ṣe ìtúpalẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú. Lára wọn ni:
1. Àwítúnwí
2. Ìfohunpènìyàn
3. Àfiwé tààrà
4. Ìfọ̀rọ̀dárà
5. Ìbéèrèpèsìjẹ
6. Àsọrégèé
Àwítúnwí
Àwítúnwí ni a tún ń pè ní àtẹnumọ́. Àwítúnwí ni ó ń pilẹ̀ dídọ́gba àti ìfohùngbohùn. Kò ní ṣe àjèjì sí wa láti rí àwítúnwí nínú ìwé yìí; àwọn àwítúnwí náà ni;
a. Ẹiyẹ tí kò ṣènìà rẹ̀
laró........ pg 8
Àlùkò gbajúmọ̀ láàrin ẹiyẹ ........ pg 9
Ẹiyẹ tí kò s’eníà t’ó k’aṣọ rẹ̀
l’ósùn ........ pg 9
Ẹtu gbajúmọ̀ láàrin ẹiiyẹ ........ pg 9
Ẹiyẹ ti kò S’enìà t’ó d’aṣọ rẹ̀
pádìrẹ ...... pg 9
Àwítúnwí
ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ ni àwọn àwítúnwí òkè yìí. Àpẹẹrẹ mìíràn ni:
b. ........ Ó fẹ́rẹ̀ẹ́
tó na o, kò ì tó .......... pg13
Ikun mú arúgbó, kò ì tó .......... pg 13
Jọ̀jọ̀ l’ọrùn ajẹ̀wà, kò ì tó .......... pg 13
Ikú lẹ̀kẹ́ òkété, kò ì tó .......... pg 13
Ó fẹ́’rẹ̀ tó nà o, kò ì tó .......... pg 13
c. Nwọn p’Olúfọ́n dé’bẹ; kò ì tó ........ pg 14
Erinlẹ̀ dé’bẹ̀, kò lé gé e .......... pg 14
Òrìṣà ògìyàn dé’bẹ̀, kò lè gé e .......... pg 14
Nwọ́n p’Ọ̀ṣun dé’bẹ̀; kò le gé e ........ pg 14
Nwọ́n p’Ọya dé’bẹ̀; kò le gé e .......... pg 14
d. ........... Ilẹ̀ ní tirẹ̀ nà ....... pg 16
Bí tẹ̀tẹ̀ ẹ̀gún bá yọ’wọ́ ògún gbàràgbàrà ........ pg 16
Ilẹ̀ ní fi tirẹ̀ nà ....... pg 16
Ìfohunpènìyàn
Èyí ni pé kí a máa nípa àwọn ẹ̀dá kìí ṣe ènìyàn yálà ó jẹ́ ẹlẹ́mìí tàbí tí
kì í ṣe ẹlẹmìí. Àpẹẹrẹ wọn nínú ìwé ni:
..... Ìwọ̀sí
oko ẹ̀gàn kò níwọ̀n ....... pg 8
Ẹiyẹ tí
kò ṣ’ènìà t’ó p’aṣọ rẹ̀ láró ...... pg 8
Àlùkò gbajúmọ̀
láàrin ẹiyẹ ....... pg 8
Ẹtu
gbajúmọ̀ láàrin ẹiyẹ ........ pg
8
...... Ijó tí
‘gbado n t’Olúfẹ̀ bọ ....... pg 10
Ni ‘gbàdo bá d’ará ‘kirè, ọmọ Ewú
ojele ...... pg 11
Erin wá
pe kújọ̀wú; ó pe kújọ̀wú ....... pg 15
Ó ní kí
kújọ̀wú ó pasà lẹ́hìn òn erin ....... pg 15
Àfiwé Tààrà
...... Ògbónátapótapó
bí alágbẹ̀dẹ ọ̀run ....... pg 8
...... L’a múso
bí ẹran ...... pg 9
...... Mo dé wẹ̀rẹ̀
bí eji alẹ́ ..... pg 12
...... Mo dé gbẹ̀rẹ̀
bí eji ìyálẹ̀ta ..... pg 12
...... Nítorí
àkọrin – láìlélégbè bí òkú ọ̀run ni ...... pg 12
...... Ó ní kí
ng má pẹ́ l’óko bí ẹrù ...... pg 13
Kí ng má
tètè wá’le’ bí ọmọ òkú ọ̀lẹ ...... pg 13
Ìfọ̀rọ̀dárà
...... Àwọn
àgbà kan, àgbà kàn ...... pg 9
...... Ó ní “Ẹ
wá eku méjì, olùgbéré” ...... pg 10
...... Ẹ wá ẹja
méjì, Olùgbàlà ....... pg 10
...... Abúnlẹ́,
ọmọ olódòkanòtéréré ...... pg 11
...... Ọmọ
Olódòkanòtàràrà ...... pg 11
...... T’ó sàn
wèrèkè, ...... pg 11
...... T´ó sàn
wérèke ...... pg 11
...... Mo gb’ọfọ̀
l’ọ́wọ́ rokoroko ...... pg 12
...... Mo
gb’àgbàlá l’ọ́wọ́ nájànájà ...... pg 12
...... Nwọ́n wí
títí ...... pg 16
...... Nwọ́n fọ̀
fọ̀ fọ̀ ...... pg 16
...... Kújọ̀ú ò
gbọ́ ...... pg 16
...... Kújọ̀ú ò
gbà ...... pg 16
Ìbéèrè-pèsìjẹ
...... Aṣọ kí
l’ó mú bo’ra? ...... pg 10
...... Ó ní “Ẹnyin
l´ólómi ní’lù nyín bí? ...... pg 10
...... Ó tún ní
“Ẹnyin l’ólómi ní’lu nyín bí? ...... pg 10
...... A ní
“Tàbí nyẹ̀gẹ̀ lù ú?” ...... pg 13
...... “Tàbí ng
sọ ọ jẹ?
Àsọrégèé
...... K’ó tó
dé, igi ti d’agogo dẹ rebete ...... pg 14
...... Igi d´ọ̀gbàrà
ọmọ okùn mẹ́rìndínlógún ...... pg 14
IWE-ÌTỌ́KASÍ
Babalọlá, Bóyè (1956) Ijálá Àtẹnudẹ́nu. Ibadan: Ministry of Education.
General Publications Section, Western Region
No comments:
Post a Comment