Sunday, 15 April 2018

Ìwé Èdè Yorùbá: Apá Kinní


ÀRÀ DÍDÁ
            Olúṣèyí Ìgbẹ́kọ̀yí àti Oyèbádé Òkìkíọlá jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́[1]. Ilé-ẹ̀kọ́ kan náà ni àwọn méjèèjì jọ wà; bọ́dà ni wọ́n ń ṣe ni kọ́lẹ́ẹ̀jì Orítamárùn. Bádé ni ẹbí kan sí ìlú Orítamárún tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n baba rẹ̀, Alàgbà Ògúngbèmí. Ní ọjọ́ sátidé kan ni Bádé àti ṣèyí lọ sí ilé Ògúgbèmí láti lọ kí i. Bí Bádé àti èyí ṣe dé ilé alàgbà Ògúngbèmí, ọmọbìnrin kan ló sí ilẹ̀kùn fún wọn. Bádé bèèrè bàbá àti ìyá Ògúngbèmí, ọmọbìnrin náà ní baba ń rẹjú lọ́wọ́ nígbà tí ìyá wà ní pálọ̀.
            Ìyá Ògúngbèmí ṣe oúnjẹ ọ̀sán fún Bádé àti ọ̀rẹ́ rẹ̀, èyí; lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán yìí, Bádé àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ èyí lọ sí ẹ̀yìnkùlé, wọ́n rí basíkúlù Alàgbà Ògúngbèmí, èyí ta lé básíkùlù náà láìgbàṣẹ, ó sì bẹ̀rẹ̀ síígùn ún ṣeré kiri nínú ọgbà. Bádé ní kí ó kó ọwọ́ rẹ̀ kan sókè, kí ó ma fi ọwọ́ kankan mú básíkùlù náà dání. Ní ibi tí Bádé àti Ṣèyí ti ń ṣeré yìí lọ́wọ́ ni alàgbà Ògúngbèmí jáde láti wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, kò jágbe mọ́ Ṣèyí rárá, ṣùgbọ́n bí Ṣèyí ṣe rí i ni ó gbé básíkùlù náà sílẹ̀. Alàgbà pe Ṣèyí bí ó ti gbé básíkùlù náà tì tán, ó ní ìwà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Bádé hù nísìsìyí jẹ́ kí òun rántí ìtàn eégún kan àti ọlọ́kọ̀ rẹ̀. Nínú ìtàn yìí, Alàgbà Ògúngbèmí sọ bí lọ́kọ̀ eégún yìí ṣe máa ń sọ àwọn oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ ìṣírí fún un lemọ́lemọ́ tí òun náà yóò máa ta òkìtì. A ní
                                    Bí o bá dá lápá, n ó bá ọ tò ó
                                    Bí o bá dá lẹ́sẹ̀, n ó bá ọ tò ó
                                    Bí o bá dá lọ́rùn, n ó délé sọ fún aya rẹ;
                                    Ma ní iṣẹ́ ajé la jọ wá ṣe.
            Lẹ́yìn tí Ògúngbèmí pa ìtàn yìí tán fún àwọn méjèèjì, ó ní gbogbo bí àwọn méjèèjì ṣe ń ṣe yìí le fa ìfarapa fún àwọn méjèèjì. Ó ní tí apá tàbí ẹsẹ̀ ọ̀kan lára wọn bá lọ dá tí kò ní àtúnṣe ń kọ́?

                       

Àwọn ohun tí a lè tọ́ka sí:
Òwe:               Bí ìlù bá ń dún àdúnjù, yóò fàya ni
                        Ṣe bí o ti mọ, ẹlẹ́wà Ṣàpọ́n
                        Ká mọ̀ ọ́n wé kò dàbíi kó yẹ ẹni

Ọ̀rọ̀ Àyálò
            Básíkùlù
            Sátidé
            Pálọ̀
            Bọ̀dá
            Yunifásitì                    -           University
            Pangiliti
            Gómìnà                       -           Governor
            Poosọ́fíìsì                    -           Post-office

FÁÀRÍ ÀṢESÓDÌ
            Ìtàn yìí sọ nípa àwọn ọkọ àti ìyàwó tí wọ́n gba ọkùnrin kan sí iṣẹ́ lọ́dọ̀ wọn. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àyànsíkùn. Àyànsíkùn kò kà ju àbọ̀ ìwé nínú ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nítorí náà èdè Gẹ̀ẹ́sì tí ó máa ń sọ kì í ṣe ojúlówó ṣùgbọ́n ó mọ Yorùbá dáadáa. Àwọn ọkọ àti ìyàwó máa ń fún Àyànsíkùn ní ìsinmi ní gbogbo ọjọ́ ọ̀sẹ̀ nítorí pé onígbàgbọ́ ni Àyànṣíkùn. Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ọkọ àti ìyàwó yìí nítorí pé ní gbogbo ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ yìí ní agogo mẹ́jọ ni Àyánṣíkùn yóò wọ pijámọ̀ tí ó ba ti di ìrọ̀lẹ́; àwọn ọkọ àti ìyàwó ń wo Àyánṣíkùn pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà tí ó ń hù. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ yìí, àwọn ọ̀rẹ́ Àyànṣíkùn yóò wàá kí wọn yóò yí orin tàbí ọ̀rọ̀ fatafata láti inú àpótí rẹdifíúṣọ̀n àti àwọn ariwo ọ̀rọ̀ sísọ àti ẹ̀rín ke-ke-ke òun àti àwọn àlejò rẹ̀.
            Ní ọjọ́ kan, ọ̀gá rẹ̀ ọkùnrin pè é láti bá Àyánsíkùn sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe máa ń wọ aṣọ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì; ọ̀gá rẹ̀ ní ilẹ̀ olóoru ní ilẹ̀ wa; ó ní àwọn aṣọ náà dára lójú ṣùgbọ́n àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tí ooru mú gan-an ni wọ́n wà, pé kí ó máa wọ àwọn aṣọ tírọ́sà oníwúlì, kóòtù oníwúlì, ṣẹ́ẹ̀tì àti táì ṣùgbọ́n kí ó máa wọ àwọn aṣọ ilẹ̀ Yorùbá bí kafitaani, agbádá, abbl. Ọ̀gá rẹ̀ sí kìlọ̀ pé kí ó yéé fi ariwo dí àwọn ará ilé lọ́wọ́.

Àwọn ohun tí a lé rí tọ́ka sí:
Òwe:               Bí ojú bá ń ṣe ipin, ojú la fi í hàn.
                        Ibi tí ó bá wu ẹfúùfù lẹ̀lẹ̀ ni í darí ìgbẹ́ sí
                        Àgbá òfìfo ni í pariwo jù
Tiwa n tiwa, ọmọ tí erin bá bí erin ní í jọ. Ṣé bi ọmọdé bá gé igi nínú igbó, àgbà ló mọ ibi tí yóò wó sí.
Pátápátá là á fọ́jú, kùnàkùnà là á dẹ́tẹ̀, ojú àfọ́ọ̀fọ́tán, ìjà níí dálẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Àyálọ̀
            Sọ́ọ́sì               -           Church
            Nòfẹ́mbà         -           November
            Tírọ́sà oníwúlù            -Trouser wool
            Kóòtù oníwúlù            -Wool coat
            Tai                   -           Tie
            Tábìlì               -           Table
            Sẹ́ẹ̀tì                -           Shirt
            Gíráàsì             -           Grass
            Básíkùlù          -           Bicycle
            Pijámà             -           Pyjamas
            Rédíò              -           Radio

IRỌ́  PÍPA KÒ PÉ
            Irọ́ jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ sí gbogbo ènìyàn; kò sí ẹni tí kì í parọ́ ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ irọ́ tí yóò kóni yọ nínú ewu èyí ni wọ́n ń pè ní irọ́ funfun. Nígbà mìíràn; ìyá lè parọ́ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé òun fẹ́ lọ sí ọjà ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ìrìnàjò ni ó ń lọ, nítorí pé kí àwọn ọmọ má baà sunkún pàápàá tí ó bá jẹ́ àwọn ọmọ tí ó sì kéré púpọ̀ tí wọn kò tí ì dàgbà ni wọ́n máa ń pa irú irọ́ yìí fún.
            Bákan náà, ó sọ̀rọ̀ nípa ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ tí kò bá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ tí ó da iṣẹ́ ẹnìkejì rẹ̀ kọ, tí olùkọ́ bèèrè bóyá òun ló ṣe iṣẹ́ rẹ̀ tí ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ yìí bá ní òun fúnra òun ló ṣe iṣẹ́ náà èyí kì í ṣe irọ́ funfun, irọ́ dúdú tó burú ni. Nínú àwọn ìtàn ìdárayá àti ìdẹ́rínpan,i àwọn oríṣìíríṣìí irọ́ ni wọ́n máa ń pa sínú àwọn ìtàn yìí láti dá àwọn ènìyàn lára yá.
            Nínú àwọn ìwé ìròyìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ irọ́ ni wọ́n máa ń pa sínú àwọn ìwé ìròyìn.
Bákan náà ni láàrin àwọn ọ̀rẹ́ nípa ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n lọ.

Àwọn ohun tí a lè rí tọ́ka sí
Òwe:               Purọ́ kì í níyì, ẹ̀tẹ́ ni í kángun rẹ̀.
                        Bí abẹ́rẹ́ bí abẹ́rẹ́ là á ṣèké, ijọ́ tó bá tọ́kọ́ rọ ni í pani

FI ỌWỌ́ ARA RẸ ṢE ARA RẸ
            Ọkùnrin kan lọ sọ ìtàn kan nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ara rẹ̀. Èrè tí ó wà nínú ọtí mímu kì í bímọ ire. Ìyá jẹ àwọn ọkùnrin yìí kí wọ́n tó le tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn. Lẹ́yìn tí àwọn méjèèjì ti ṣe ìdánwò fún skọ́lásíp tí àwọn Òyìnbó fún àwọn ènìyàn láti lọ ka ìwé ní òkè òkun, àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì ń retí kí orúkọ wọn jáde nínú ìwé ìròyìn tàbí nínú rédíò.
            Kò pẹ́ rárá, àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì yìí rí orúkọ wọn lára àwọn ènìyàn tí ó ní àǹfààní láti lọ sí ìlú Òyìnbó. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ méjì tí ó ń ṣiṣẹ́ ni ọgbà Rélùwé ní ìlú Sáríà jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti ṣàjọyọ̀ orí ire tí ó dé bá a ṣùgbọ́n àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ibi tí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn ni ọkùnrin yìí dìde láti lọ tọ̀; ṣé ọkùnrin yìí ti mu ọtí yó kò sì mọ ibi tí ó ń lọ títí tí ó fi fi fèrèsé ṣe ìlẹ̀kùn tí ó fi jábọ́ láti ojú fèrèsé; báyìí ni ọ̀gá rẹ̀ tí ó jẹ́ Òyìnbó fi jáde ni alẹ́ yìí láti wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀; ó rí ọkùnrin yìí, inú bí Òyìnbó yìí ó sì ní òun kò rò pé ó máa jẹ́ ènìyàn gidi tí ó bá dé ìlú Òyìnbó nítorí pé kò mọ̀ pé ọ̀gá yìí ló fi orúkọ rẹ̀ sí ara àwọn tí ó ń lọ sí ìlú Òyìnbó. Báyìí ni àǹfààní ṣe bọ́ lọ́wọ́ ọkùnrin yìí.
Àwọn ohun tí a lè rí tọ́ka sí:
Òwe:               Ọwọ́ ara ẹni la fi í tún ìwà ara ẹni ṣe
                        Bí babaláwo bá téni nífa, à sì tún ara ẹni tẹ̀
                        Ààbọ̀ ọ̀rọ̀ làá sọ fún ọmọlúàbí, bó bá dé inú rẹ̀ a di odidi

Ọ̀rọ̀ Àyálò
            Skọlasip           -           scholarship
            Mọ́ńdè             -           Monday
            Rélùwé            -           Railway
            Sátidé              -           Saturday
            Íngíláńdì          -           England
            Gíráàsì             -           Grass
ÌTÀN KAN NÍPA BÍ ỌDÚN EGÚNGÚN ṢE BẸ̀RẸ̀
            Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Ọ̀jẹ́kúnlé àti Ògúnṣíji. Ògúnṣíji jẹ́ ọmọ bàbá olówó ṣùgbọ́n ó gbójú lé ogún bàbá rẹ̀, kò múra sí iṣẹ́ ṣíṣe rárá. Nínú àwọn ọmọ tí bàbá náà bí, Ògúnṣíji jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó ya ọ̀lẹ. Lẹ́yìn ikú baba náà, Ògúnsíji ti ń ronú bí gbogbo ogún ṣe máa jẹ́ tirẹ̀. Ògúnṣíji lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀, Ọ̀jẹ́kúnlé, láti sọ ohun tí ó ní lọ́kàn kí gbogbo ọrọ̀ bàbá rẹ̀ le jẹ́ tirẹ̀. Ògúnṣíji ti mú aṣọ bàbá rẹ̀ kan tí ó máa ń wọ̀ nígbà ayé rẹ̀, agbádá ẹtù kan. Ògúnṣíji sọ fún Ọ̀jẹ́kúnlé pé yóò ṣe bí òkú, yóò wá sí ilé wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pín ogún, yóò máa ṣe bíi bàbá wọn tí ó kú. Báyìí ni Ọ̀jẹ́kúnlé sì gbà láti ṣe bí òkú.
Ní ọjọ́ tí wọn yóò pín ogún ni Ọ̀jẹ́kúnlé yọ sí gbogbo àwọn ará ilé, ẹ̀rù ba gbogbo ènìyàn ṣùgbọ́n Ògúnṣíji ṣe àyà gbàǹgbà, ó lọ dọ̀bálẹ̀ fún òkú náà, wọ́n sì gbé ìjókòó fún òkú náà, ó sì ní kí wọ́n kó ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ owó, gbogbo aṣọ rẹ̀ tí ó dára jù, kí wọ́n kó o fún Ògúnṣíji, kí àwọn ọmọ yòókù pín àwọn owó tí ó ní. Lẹ́yìn gbogbo èyí, Ògúnṣíji fẹ́ yan Ọ̀jẹ́kúnlé jẹ ṣùgbọ́n Ọ̀jẹ́kúnlé fi hàn án pé ó gbọ́n ju Ògúnṣíji lọ. Gbogbo ohun tí kò dára nínú Ogún tí wọ́n kó ni Ọ̀jẹ́kúnlé fún Ògúnṣíji.
Àwọn ohun tí a lè rí tọ́ka sí:
Òwe:               Agídí mọ̀lọ̀jà, awo I-Ifẹ̀, àwọn ní i gbawo ní gbọ̀nwọ́
                        Ẹni tó ju òkúta luni ló ní ká sọ ìdàrọ́ lù òun

Ọ̀GBẸ́NI AṢỌ̀TÚNṢÒSÌLÁÌNÍTÌJÚ 
            Ọ̀gbẹ́ni Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú ni ìtàn yìí dálé. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ kí á mọ̀ pé ọ̀rẹ́ ìgbà ilé-ẹ̀kọ́ ni àwọn méjèèjì tí ó sì lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú, ní ìlú Bóòkélé. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ọ̀rẹ́ Ọ̀gbẹ́ni Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú tí ó wá dé e lálejò láti rí ibi tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń gbé pẹ̀lú bí ìlú Bóòkélé ṣe ní àwọn ibi tí ó dára tí ènìyàn le gbé ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀ Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú ń gbé nínú àwọn abúlé inú ìlú Bóòkélé; àwọn ilé àbẹ̀rẹ̀wọ̀ ni ilé náà, kò sí ohun tí ó wuni nínú ilé náà. Ọ̀rẹ́ Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú kò mọ ìdí tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi lè máa gbé irú ilé báyìí pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọ. Àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ nítorí pé ìdí iṣẹ́ olùkọ́ ni ọ̀gbẹ́ni  Aṣọ̀túnṣòsíláìnítìjú ti fẹ̀yìn tì. Ìlú Bóòkélé jẹ́ ìlú tí ó ní ilé iṣẹ́ ńláńlá àti ilé-ẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn ńlá tí àwọn ènìyàn máa ń wá láti gba ìtọ́jú. Ọ̀gbẹ́ni Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú jẹ́ àgbẹ̀ tí ó ní ilẹ̀ oko tí ó pọ̀, tí ó sì gba àwọn òṣìṣẹ́ sínú oko tí wọ́n bá a ṣiṣẹ́. Gbogbo ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń jẹ, inú oko rẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ ti ń wá; ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kí ó tẹ̀lé òun lọ sí oko kí ó rí bí ó ṣe tó. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ọ̀rẹ́ Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú ti lọ, ní ọjọ́ òsè, ó bèèrè lọ́wọ́ Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú ilé ìjọsìn tí ó ń lọ. Ọ̀rẹ rẹ̀ lọ sí ilé ìjọsìn kan ní ọjọ́ yìí, ó pàdé ọkùnrin alábójútó àwọn ilé ẹ̀kọ́ ní agbègbè náà. Ọkùnrin yìí ló tí àṣírí Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé kòṣeku-kòṣẹyẹ ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣe. Ọkùnrin yìí ló jẹ́ kí ó mọ̀ pé Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú ni olú àwòrò tí wọ́n sì ń san owó fún un. Ọ̀rẹ́ Aṣọ̀túnṣòsìláìnítìjú rí i pé nítorí owó ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe ń gbé ní abúlé Bóòkélé.

Àwọn ohun tí a rí tọ́ka sí :
Òwe:               Ẹni tí ó bá fẹ́ joyin inú àpáta, kò gbọdọ̀ wo ẹnu àáké
                        Láálá tó ròkè, ilẹ̀ ló ń bọ̀
Ẹni tí yóò bá jẹ́ ọ̀ṣákálá, yóò jẹ́ òṣákálá, ẹni tí yóò bá jẹ́ òṣokolo yóò jẹ́ òṣokolo, ọ̀ṣàkà òṣoko kò yẹ ọmọ ènìyàn
Àbàtà ta kété bí ẹni pé kò bódò tan
Ohun tí àgbàlagbà fi ń jẹ ẹ̀kọ, abẹ́ ewé ló wà

Ìlò Ọnà èdè – Àwítúnwí
            Ràbàtà ràbàtà, wògìràn wògìràn

BÚRẸ́DÌ ÀJẸPỌ́NNULÁ
            Àyọlò yìí sọ nípa ọkùnrin tí ń ta búrẹ́dì ní Ògùnpa, ní ìlú Ìbàdàn. Bí ọkùnrin yìí ṣe máa ń polówó búrẹ́dì rẹ̀ máa ń pani lẹ́ẹ̀rín, pẹ̀lú orin tí ó máa ń kọ. Gbogbo àwọn tí ònínú ọkọ̀ ti mọ ọkùnrin náà dáadáa ṣùgbọ́n obìnrin kan kò mọ ìtumọ̀ ohun tí ọkùnrin náà ń sọ. Àwọn ènìyàn inú ọkọ̀ sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí ọkùnrin náà ń sọ, ỌLỌ́MỌ-MEJI BREAD. Kò pẹ́ rárá, bọ́ọ̀sì wọn gbéra ìrìn-àjò lọ sí Èkó; nínú ọkọ̀ yìí ni obìnrin kan ti gbé ohun tí ó fẹ́ jẹ jáde nínú àpò ọwọ́ rẹ̀. Sánwiìsì ni oúnjẹ náà. Obìnrin yìí fi sáńwiìsì náà lọ ọkùnrin tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nínú ọkọ̀, ọkùnrin náà kò kọ́kọ́ gba oúnjẹ náà lọ́wọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n obìnrin náà fi dandan sí i. Ọkùnrin náà sì bèrè orúkọ ohun tí obìnrin náà fún un jẹ. “sáńwiìsì ni àwọn Òyìnbó ń pè é”, obìnrin náà fèsì bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin àti obìnrin yìí sọ̀rọ̀ lóríṣìíríṣṣìí nínú ọkọ̀ pàápàá lórí oríṣìíríṣìí oúnjẹ tí àwọn ènìyàn máa ń jẹ.

Àwọn ohun tí a lè rí tọ́ka sí :
Òwe:               Ó kéré ní sọ ẹni di ahun
                        Dídùn ló dùn la bá ọ̀rẹ́ jẹ̀fọ́

Ọ̀rọ̀ Àyálò nínú ìwé náà
            Bọ́ọ̀sì               -           Bus
            Sanwíìsì           -           Sandwich
            Búrẹ́dì             -           Bread

Ẹ̀RỌ AMÁDITIGBỌ́RÀN
            Ìtàn yìí sọ nípa ọ̀gbẹ́ni Adéyẹmọ. Adéyẹmọ jẹ́ adití tí ó sì máa ń lo ẹ̀rọ amáditígbọ́ràn. Ọ̀gbẹ́ni Ògúnrántí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ sí àpèjẹ fàájì Gómìnà Èkó nínú ọgbà rẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì yìí wọ àsọ tó dára. Ojú agbo yìí ni wọ́n ti rí Ọ̀gbẹ́ni Adéyẹmọ, àwọn méjèèjì sì lọ kí Adéyẹmọ. Nígbà tí wọ́n ń kí Adéyẹmọ, ohun ọ̀tọ̀ ni ó fi ń fún àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì yìí lésì à fi ìgbà tí ọ̀kan lára wọn kígbe sọ̀rọ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Adéyẹmọ tó mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì ń kí òun ni. Lẹ́yìn tí àwọn méjèèjì kí Ọ̀gbẹ́ni Adéyẹmọ tán, wọ́n padà sí àyè wọn.

Àwọn ohun tì a lè rí tọ́ka sí:
Òwe:               Ọwọ́ ara ẹni la fi ń tún nǹkan ara ẹni ṣe
                        Gèlè kò dùn bíi ká mọ̀ ọ́ wé, ká mọ̀ ọ́ wé
Ọ̀rọ̀ Àyálò
            Kílààsì             -           Class
            Sẹ́meèsì           -           CMS   
            Kọ́lẹ̀ẹ̀jì             -           College
            Rẹktángù         -           Rectangle
            Góróbà                        -           Guava
            Tòmátì             -           Tomatoes
            Sùkúù              -           School
            Yunifásítì        -           University
            Rẹ́ẹ̀ǹtì              -           Rent
            Báànkì             -           Bank

NÍ IBI IṢẸ́ ALÁGBẸ̀DẸ
            Ọ̀jẹ́bọ̀dé Òkìkíọlá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì kínní ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan ní ìlú Èkó nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Akínyọ̀ádé Ọláníyan jẹ́ olùkọ́ ní ile-ẹ̀kọ́ náà. Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ẹ̀kọ́ Yorùbá ni olùkọ́ bèèrè oríṣìíríṣìí oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, Ọ̀gbẹ́ni Akínyọ̀ádé bẹ̀èrè lọ́wọ́ Òkìkíọlá bí wọ́n ṣe máa ń rí iṣu, pé ṣé wọ́n máa ń ká iṣu ni tàbí inú ilẹ̀ ni wọ́n ti máa ń rí i?. Òkìkíọlá kò rí iṣu rí nítorí náà kò lè dáhùn ìbéèrè náà. Ọ̀gbẹ́ni Akínyọ̀ádé lọ gba àyè lọ́wọ́ àwọn òbí Òkìkíọlá kí òun lè mú Òkìkíọlá wá sí ìlú rẹ̀ ní Ìpetumodù láti rí oríṣìíríṣìí ohun tí wọ́n ń ṣe ní ìlú rẹ̀. Àwọn òbí Òkìkíọlá fi ọwọ́ sí i láti fi ọmọ wọn sílẹ̀ kí ó tẹ̀lé Ọ̀gbẹ́ni Akínyọ̀ádé ní àsìkò ọlidé rẹ̀. Bayìí ni Òkìkíọlá àti olùkọ́ rẹ̀, Akínyọ̀ádé, ṣe lọ sí ìlú Ìpetu. Alàgbẹ̀dẹ kan wà ní iwájú ilé àwọn ọ̀gbẹ́ni Akínyọ̀ádé. Òun àti Òkìkíọlá lọ sí ọ̀dọ̀ alágbẹ̀dẹ. Òkìkíọlá bèèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ alagbẹ̀dẹ, tí alágbẹ̀dẹ náà ṣe àwọn àlàyé fún Òkìkíọlá, ó sì kọ bí wọ́n ṣe máa ń kí àwọn alàgbẹ̀dẹ.

Àwọn ohun tí a lè rí tọ́ka sí:
Òwe:               Ọmọ tí ò dé oko bàbá ẹlòmíì rí ni í wí pé oko bàbá òun ló tóbi jù
                        Ojú mẹ́wàá      ò jojú ẹni
                        Bí ọmọdé bá dúpẹ́ oore àná, yóò rí òmíràn gbà
                        Ohun tó bá wuni ni í pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni, onígba ẹrú kú, aṣọ rẹ̀ kù kan ṣoṣo
                        Àlejò kì í mọlé ju onílé lọ
                        Bí iná bá kú, á fi eérú bojú, bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú, á fi ọmọ rẹ̀ rọ́pò
                        Òwúrọ̀ lọjọ́
Ọ̀rọ̀ Àyálò
            Sùkúrù             -           School
            Gíráàsì             -           Grass
            Sẹ́èfù               -           Safe
            Ọ́gọ́stì             -           August
            Ọlidé               -           Holiday
            Kọfí                 -           Coffee
            Tísà                  -           Teacher
            Kísìnnì             -           Kitchen
            Táwẹ̀lì             -           Towel


NÍ IBI IṢẸ́ ÀWỌN AMỌ̀KÒKÒ 
Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Ọláníyàn àti Òkìkíọlá ti parí ohun tí wọ́n fẹ́ lọ́dọ̀ alágbẹ̀dẹ, ní ìgbà tí ó di alẹ́, kí wọ́n tó sùn, Ọláníyan ti bi Òkìkíọlá léèrè ibi tí ó fẹ́ lọ wóran ní ọjọ́ kejì, Ókíkí ní pé ibi iṣẹ́ àwọn amọ̀kòkò. Ọ̀gbẹ́ni Ọláníyan mú Òkìkíọlá lọ sí ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ kan láti rí amọ̀kòkò. Inú ìyá yìí dùn láti rí Ọláníyan. Òkìkíọlá kí Màmá náà; wọ́n sọ ohun tí ó gbé wọn wá. Ìyá náà fi gbogbo irin iṣẹ́ han Òkìkíọlá. Irú amọ̀ tí wọ́n máà ń lò láti mọ ìkòkò àti oríṣìíríṣìí ohun-èlò inú ilé.
            Òkìkíọlá bèèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ ìyá náà ó sì fún un ní ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Àwọn obìnrin mìíràn náà wà ní ẹbu tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ amọ̀kòkò. Iṣẹ́ oríṣìíríṣìí ni wọ́n ń fi amọ̀ ṣe. Ọwọ́ àwọn obìnrin yìí yàtọ̀ sí ara wọn. Gbogbo wọn ló sì ní aṣọ iṣẹ́ tí wọ́n máa ń wọ̀ láti ṣiṣẹ́.



Àwọn ohun tí a lè rí tọ́ka sí:
Òwe:               Bí ọmọdé bá mọ ọwọ́ wẹ̀, yóò bá àgbà jẹun.
                        Ó kéré níí sọ ẹni di ahun
                        Oníkálukú a-bi-tiẹ̀-lára
                        Àlejò bí òkété là á fi èkùrọ́ lọ̀
Reference
Babalola, Adeboye (1962), Ìwé Èdè Yorùbá: Apá Kinní. Lagos, Nigeria: Longman Nigeria Limited.


[1] Ogunruku Gbemisola Tolulope ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment