Thursday, 8 February 2018

Tíṣa Oko


Tíṣà kan wà

Olélé

Láyé yìí o

Ẹ wá wo tísà

Tíṣà oko ni

Kìí kọmọ níwèé

Láyé yìí o

Bí wọ́n ṣe ń sebẹ̀

Ló ń kọ́mọ

Ó wá dijọ́ kan

Ọmọ kan sọ bàbá rẹ̀

Ó ní, ‘Bàbá mi

Àbẹ́ ẹ̀ gbọ́, mo ti lóyún’

Baba wá bi í léèrè wí pé

‘Ta ló loyún inú rẹ o?

Ta ló loyún yẹn?

Ko ṣe were, kò ṣe kíá’

Ọmọ dáhùn wí pé

‘Ṣé ẹ rí tísà yí o

Ìyẹn tíṣà wa

Òun ló fún mi lóyún’

Baba bá relée tíṣà, ó ní

‘N gbọ́ tíṣà yìí

Ìwọ tíṣà oko

Ṣè’wọ ló fọ́mọ́ mi lóyún?’

Tíṣà dáhùn, ó ní

‘Rárá, rárá o

Rárá o,  èmi kọ ò

Èmi kọ́ ni mo fọ́mọ rẹ lóyún’

Ọmọ dáhùn, ó ní

‘Rántí ijọ́ ẹ̀sìkọ́sàn o o ò

Ijọ́ ẹ̀sìkọ́sàn, tí mo sùn nílé yín’

Tíṣà dáhùn, ó ní,

‘Àfiyẹn o o ò

Àfìyẹn o

Àfìyẹn nìkan o

Ni mo mọ̀ tó dámi lójú’

Ọmọ tún dáhùn, ó ní,

‘Rántí ijọ́ àìsùn ìkórè o ò

Ijó àìsùn ìkórè

Tí mo sùn nílé yín’

Tíṣà tún dáhùn, ó ní,

‘À tún fìyẹn o

À tún fìyẹn

Ni mo mọ̀ tó dámi lójú’

Gbogbo aráyé wá dá tísà lóhùn

Wọ́n ní,

‘Ẹ̀ẹ̀kán o, la mọ̀ tí ń doyún

Ẹ̀ẹ̀kan o la mọ̀ tí ń doyun

Ẹ̀ẹ̀kan soso o la mọ̀ tí ń doyún’.

No comments:

Post a Comment