Saturday, 3 February 2018

The Choice of An Ori


THE CHOICE OF AN ORÍ[1]

 

ÌSỌNÍSÓKÍ

 

“Èmi ìbá mọ ibi olórí gbé yanrí, ǹbá lọ yan tèmi. Ibí kan náà la gbé yanrí, kádàrá ni ò papọ̀. Orí ti Tàyé yàn yàtọ̀ sí ti Kẹhìndé. Ìtaǹ inú iwé yìí ń sọ nípa orí; ó sọ nípa àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta kan, Afùwàpẹ́, Orílèémèrè àti Orísèékú. Òde ọ̀run ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ń gbé tí wọ́n sì máa ń jẹ ìgbádùn ara wọn; wọn á máa ṣe oríṣíí eré kiri ní Ọ̀run.

Ọmọ Ifá Ọbariṣa ni  Afùwàpẹ́, ọmọ Ògún ni Oríséèkù, tí Oríléméèrè sì jẹ́ ọmọ Ìja. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bá pinnu àti lọ sí ayé; wọ́n wáá tọ àwọn àgbààgbà ọ̀run lọ láti gbà wọn ní ìmọ̀ràn lórí bí wọn ó ṣe gbé é gbà. Lẹ́yin tí wọ́n gba ìmọ̀ràn tán pé kí wọn má wo ọ̀tún tàbí òsì, kí wọ́n ní àfojúsùn àti pé kí wọ́n má ṣe yà lọ sí ibikíbi yàtọ̀ sí ilé A-fabẹ́rẹ́-gúnyán àti ilé Àjàlá alámọ̀ àti orísìí àwọn nǹkan mìíràn tí wọn yóò bá pàdé lọ́nà, àwọn àgbà yìí tú sọ orísìí ìdojùkọ tí wọn yòó bá pàdé ní ayé àti ọ̀nà tí wọn yòó fi ṣẹ́gun wọn.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bá ọ̀nà wọn pọ̀n láti lọ sí òde ayé; ní ojú ọ̀nà wọn; orísìí ìdójúkọ ní wọn bà pàdé; bí òòrùn ṣe pa wọn ní àpadojúdélẹ̀ àtí orísìí nǹkan mìíràn. Nígbà tí wọn borí gbogbo àwọn wọ̀nyí, wọ́n dé ilé A-fabẹ́rẹ́-gúnyán, ìyàlẹnu bá wọn nítorí ohun tí ọkùnrin yìí ń ṣe; ó ń fabẹ́rẹ́ gún iyán,wọ́n wáá sọ fun un pé kí ó júwèé ilé Àjàlá alámọ̀ fún wọn ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí sọ fún wọn pé kí wọ́n ní sùúrù kí òun fi abẹ́rẹ́ gúnyán tán; àmọ́ inú bí Orísèékù, ó ní àwọn ń kánjú àti pé àwọn kò le è dúró rárá,; ṣùgbọn, ọlọgbọ́n ènìyàn ni Àfùwàpe, ó gbọ́n ju àwọn tó kù lọ; ó wá sọ fún ọkùnrin yìí pé àwọn yóò dúro ti yóó fi ṣetán. Títí ilẹ̀ ọjọ́ náà fi ṣú, ọkùnrin yìí kò gún iyán tán, ígbà tí ó wáá di ọjọ́ kejì, ó ti parí ohun tí ó ń ṣe, ó wá jùwèé ọ̀nà náà fún wọn.

Bí wọn ṣe ń lọ lọ́nọ̀ ni Orísèékù gbọ́ ohùn ariwo ìjà ó sì ti tètè mọ̀ pé bàbá òun ni ó ń ja; ó gbérà kí ó lọ ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ rán an létí ìmọ̀ràn àwọn àgbà pé wọn ko gbọdọ̀ yà si ibòmìíràn yàtọ̀ sí àwọn ibi tí wọn sọ fùn wọn. Èyí mú ki Orísèékù dúró, kò sì lọ mọ́. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé ọ̀nà ilé Àjàlá, Afùwàpé pinnu láti loọ ri bàbá rẹ̀, ó ní òun ń gbọ́ ohùn bàbá òun, pé òun sì fẹ́ lọ bá wọn; inú bi Orísèékù fun ohun tí ó gbọ́ ṣùgbọn Afùwàpẹ́ kò rí i rò rárá, ó sì kọrí sí ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀. Orísèékù àti Orílèméèrè wá ń lọ láìdúró dè é. Ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n pàdé abàmì ẹ̀dá kan tí ìrísí rẹ̀ sì ṣeni ni kàyéfì. Wọ́n bèèrè ojú ọ̀nà tí ó yà sí ilé Ajàlá lọ́wọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé kí wọn jẹ́ kí òun se ọbẹ̀ tí òun ń sè tán, bí Orísèékù tún ṣe gbọ́ èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí níí sọ àwọn ọ̀rọ̀ àlùfàńsá sí i. Ó sì da ọbẹ̀ tí ọkùnrìn náà ń sè nù pẹ̀lú ìbínú. Ọkùnrin yìí sì fi ìbìnú lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.

Nígbà tí Afùwàpé dé ọ̀dọ bàbá rẹ̀, ó bẹ bàbá rẹ̀ kí  ó má bínú sì í torí ìwà àfojúdi tí ó wù sí í, bàbá rẹ̀ dárí jì i, ó sì sọ àwọn ohun tí yóò nílò fún ìrìn àjò rẹ̀.

Ní ojú ọ̀nà àwọn Orísèèkú àti Orílèméèrè, wọ́n pàde arọ kan tí ó jùwèé ọ̀nà fún wọn ṣùgbọn ó gba owó lọ́wọ́ wọn kí ó tó sọ ibẹ̀ fún wọn.

Nígbà tí Afùwàpé dé ọ̀dọ ẹ̀dá abàmì tí ó ń se ọbẹ̀ yìí, ó ní sùúrù tí ó fi se ọ̀bẹ̀ tán, ó sì tún fún un ni iyọ̀ tí ó fi sì ọbẹ̀ rẹ̀ dípò eérú tí ó fẹ́ẹ́ lò. Inú ọkùnrin yìí dùn ó sì sàlàyé ọ̀nà náà fún un, ó sì tún salayé fún un nípa àwọn ohun ti yòó bá pàdé ní ilé Àjàlà àti irú ènìyàn tí Àjàlá jẹ́ pé onígbèsè ni.

Àwon méjì tó kù, Orìsèèkú àti Orílèémèrè dè ilé Ajala, ṣugbọn ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ ní wọ́n bá, èyí tí ṣe Lìjàdú, tí ó mú wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Fágúwà tíwọ́n sì lọ yan orí tó wù wọ́n, lẹ́yin tí wọ́n san ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó fún wọn. Sùgbọn oríkórí ni wọ́n yàn torí bí wọ́n ṣe ń kó sí páńpẹ́ Èṣù tí ó ṣe orí náà jákujàku, tí ó sì sọ wọ́n di ẹni tí ko see rí ni àwùjọ.

Afùwàpé ní tirẹ̀ yan orí rere torí Ajala fúnraarẹ̀ ní ó mú un lọ sí ibi ti ó ti yan orí léyin tí Afùwàpe ti bá a san gbèsè tán. Àjàlá sì sọ orísìí nǹkan fún un nípa ohun tí yóò bá pàdé ní ilé ayé. Bí Afùwàpé ṣe dé ilé ayé ní àwọn ènìyàn ń gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀; gbobgo ìlú tí ó dé ni wọn ti ń yẹ́ ẹ sí, tí wọ́n sì ń dá a lọ́lá. Ṣùgbọ́n ìlú Ọ̀yọ́ ni àfojúsùn rẹ̀, nìgbà tí ó sì dé Ọ̀yọ́, wọ́n dá a lọ́lá, wọ́n sì sọ fún un pé àwọn ti ń retí rẹ̀ ti pẹ̀. Ni Afùwàpẹ́ bá di ẹni ọlá àti ẹni ẹ̀yẹ ní ilú Ọ̀yọ́.

Nígbà tí àwọn Orísẹ́èkù àti Orílèméèrè dé ilé ayé, wọ́n kò gbà wọ́n rárá; wọ́n ń lé wọn dànù ní gbogbo ìlú tí wọ́n dé. ṣùgbọn wọ́n tẹ́wó gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀ ní ilù Ọ̀yọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kò gbà wọ́n. Oríléméèrè bẹ̀rẹ̀ sí níí ṣiṣẹ́ nígbà tí Orísèékù ń tọrọ jẹ kiri titi ó fi dàgbà darugbó tí ó sì gba ibẹ̀ kú. Àmọ́, Oríléméèrè ní tirẹ̀ ó wá ọ̀gbọ́n dá si ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ tí ó si ń jẹ tí ó ń mu láti ara iṣẹ́ tí ò ń ṣẹ leyin tì babalawo ti sàlayé fún un pé kí ó tẹra mọ́ iṣẹ́ pé nǹkan yóò dẹ̀ ẹ́ lọ́rùn. Nígbà tí òun náa dàgbà tí ó darúgbó, ó kú ṣùgbọ́n ókú ẹ̀yẹ ní ó jẹ́ fún un ní ìwọ̀nba bí o tí mọ.

Báyìí ni orí ṣe san Afùwàpé ní ilé ayé tí ó sì di ẹni tí gbogbo arayé ń yẹ́ sí ni gbogbo ìlú. Nígbà tí ó sì kú, ẹ̀mí rẹ̀ lọ sí ọ̀run latí lọ sinmi ní ilé. Ṣùgbọn, ẹmi Orisèékù ń rìn káàkiri ayé tí ó si ń da àwọn ènìyàn láàmú.

 

ỌNÀ ÈDÈ

Èyí ni àwọn ọnà èdè tí òǹkọ̀wé sàmúlò nínú iṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì mú kí iṣẹ́ rẹ̀ dùn-ún kà, tí ó sì tún fún iṣẹ́ rẹ̀ ní iyì. Lára àwọn ọnà èdè tí òǹkọ̀wé sàmúlò ni:

Ìfohunpènìyàn

Èyí ni gbígbé àbùdá ènìyàn wọ nǹkan aláìlẹ́mìí tabí ẹranko mìíràn.

“soon the newborn rays of a beautiful new sun bathed the faces of our friends...”o.i 25

Níbí òǹkọ̀wé gbé àbùdá ènìyàn wọ òòrùn láti lè jẹ́ kí ẹwà wọ iṣẹ́ yìí.

“the sun kept climbing to his zenith and flung rays of fire at the skulls of our friends, who were now sweating heavily .”o.i 26

Ènìyàn tàbí ẹranko ni ó máa ń gun nǹkan, ṣùgbọ́n níbí, òòrùn ni ó ń gun nǹkan. Ohun ti ó ń gbìyànjú àti sọ níbí ni pé òòrùn ń pa àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta yìí.

“The sun, nearly at the end of his journey and ready to retire painted the sky in the diverse colours…” o.i 27

Òǹkọ̀wé sì ń sọ nípa òòrùn níbí, ó ń sọ nípa bí òòrùn ṣe fẹ́ẹ́ wọ̀.

“..it must be said that lady moon, who often takes long trips through the universe, does not show herself as regularly as the sun…” o.i 27

Àpẹẹrẹ kan náa ni èyí, àbùdá ènìyàn ni wọ́n gbé wọ òsùpá.

“..smile came to his thin lips..”o.i 60

ọ̀nà tí òǹkọ̀wé fi ṣe àgbékalẹ́ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìfohunpènìyàn.

Death delivering them from their torments would have

             been sweet to them now. But iku, Death, is a capricious being

who worries very little about men’s desire or wishes.

        She comes to ask for them when they are least expecting it,

                                     and blithely ignores them when with all their heart they wish her                         

                                     coming. O.i 124

òǹkọ̀wé ń sọ̀rọ̀ nípá ikú nibi bíi pé ènìyàn ni tí ó lè wá ní ìgbà tó bá wù ú láti mu ẹnikẹ́ni lọ.

“…a repulsive smile floating on his angular face.”

 

Àfiwé tààrà

Éyí ni fífi nǹkan méjì tí ó ní àbùdá kan náa wé ara wọn. A sì rí àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí.

“..there where the roads cross and become as bald as a vulture’s head….”O.i 32

Nìbí a fi ojú ọ̀nà wé orí igúnnugún.

“....he closed his eyes and breathed deeply, as if drunk on his own words...” o.i 34

Òǹkọ̀wé fí bi ọkùnrin náa ṣe di ojú wé ti ẹni tí ó ti mu otí yó.

“....the elf remained for a good while in this ecstatic attitude, as if under a spell...”o.i 55
a fi ẹ̀dá
lọ́run náà wé ẹni tó wà ni abẹ́ èèdì, torí ìwà tí ó ń wù ní àsìkò nàà fara jọ tí ẹni tó wà lábẹ́ èèdì.

“...I don’t want to haggle like a vulgar shopkeeper.” o.i 71

“....who greedily seized the wallet with his bony hooked fingers like a raptor grasping a long-desired prey.”O.i 71

“…he glimpsed someone throwing himself about like a demon in front of the door…” o.i 74

O fi ẹni tí ó rí wé èṣù ojú ọ̀nà.

“....he didn’t like this man at all, this dark, tubby little man with his swollen cheeks like those of a trumpeter...”o.i 75

Òǹkọ̀wé fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọkùnrin náà wé ti ẹni tó ń fun fèrè.

“…they looked like fans perched on his tiny head.”O.i 121

Àsọrégèé

            ....Eṣhu, who throws a stone yesterday to kill a bird today

            Eshu, who when squatting reaches the roof and who when

standing isn’t tall enough to reach the top of the hearth.

Eshu, who can sleep for three years, can sit on the skin of an ant,

and can make a stone bleed when he treads it. Eshu, the wrath

of the gods and the terror of men.” o.i 115

òǹkọ̀wé ń ki Eṣu, òrìṣa kan ní ilẹ̀ Yorùbá, èyí ni ó sì fá á kí ó ḿaa ṣe èyí ní ọ̀nà àpọ́npo.

Àkíyèsí ni pé òǹkọ̀wé tún àmùló àkànlò èdè níní iṣẹ́ rẹ̀. A rí àpẹẹrẹ èyí ní;

“...that was the straw that broke the camel’s back” o.i 41

Èyí ni pé, ohun tí ó mú kí ẹni nàà fárígá..

“... i’ve got other fish to fry” o.i 48

Èyí túmọ̀ sí pé ẹni náà ni àwọn nǹkan mìíràn láti ṣe.

 

Irúfẹ́ asọ̀tàn

Asọ̀tàn afarasin ni irúfẹ́ asọ̀tàn tí a ní. Èyí ni asọ̀tàn tí kò sí nínú ìtàn ṣùgbọ̀ń ó mọ gbogbo ohun tí ó ń lọ nínú ìtàn pátápátá. Arí-hín-rí-ọ̀hún ní ó jẹ́, òun ni ó sì ṣe òfófó ìtàn náa fùn àwọn òǹkàwé. Òye àti ìmọ̀ kíkún tí ó ní nípa ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn yìí ló fún un ní àǹfààní àtí lè ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìtàn. Ó mọ̀ nípa ẹ̀dá ìtàn kọ̀ọ̀kan àti àwọn ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn le ṣe. Ó sì júwèé wọn fínnífínní.

 

Kókó ọ̀rọ̀ inù ìwé yìí

Kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ìtàn yìí dálé ni ọ̀rọ̀ nípa Ọrí, pé ohunkohun tí ẹ̀dá bá jẹ́ láyé lọ́wọ́ orí ni ó wà. ẹni tí ilé ayé sàn fún, orí rẹ̀ ni ó fà á, ẹni tí ilé ayé ko rọgbọ fún, orí rẹ̀ náà ní ó fà á. Orí ni à bá sì máa bọ kí á fí orìṣà sílẹ̀ torí ijọ̀ ti orì ǹ gba ni níbo ni òrìṣà wà; orí ni ẹjá fi ǹ la ibú já orí ni a fi ń mu ẹran nì àwo kí orí wa ó gbé wa débi ire.

Yorùbá sì ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ nínú orí torí wọ́n gbà pé ènìyàn gbọdọ bèèrè lọ́wọ́ orí kí ó tó ṣe ohunkohun láyé; ìṣe pàtàki orí yìí ní ó fa oríṣiríṣi ìpèdè nípa orí.

Reference

Camara, Louis (2001), The Choice of an Ori, translated from the French by Prof. Jean-Pierre Météreau. Saint-Louis, Senegal: Xamal.



[1] Abiola Temitope Ruth ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment