Saturday, 10 February 2018

ÌMỌ̀RÀN ÀGBÀ


ÌFÁÁ[1]

Ìwé Ímọ̀ràn Àgbà láti ọwọ́ oǹkọ̀wé Débọ̀ Awẹ́ jẹ́ àkójọpọ̀ ìtàn kéèkèé méje tó jẹ́ ìtàn àwọn ọmọdé láti fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. Ìtúpalẹ̀ àwọn ìtàn náà nìyìí lọ́kọ̀ọ̀kan:

 

ẸNI ṢE OHUN TẸ́NÌKAN KÒ ṢE RÍ

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN

          Agídí pinnu láti lọ dáko nígbó aìwọ tó wà nílùú lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo ènìyàn ti gbà á nímọ̀ràn láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó fẹ́ẹ́ roko, àwọn iwinlẹ̀ ibẹ́ bi í léèrè wí pé kó jẹ́ kí àwọn ràn án lọ́wọ́, Agídí sì fún wọn láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀ fún òun. ebí wọ́n kúkú fẹ́ẹ́ ràn án lọ́wọ́ ni. Báyìí ni àwọn iwin ń ran Agídí lọ́wọ́ ni gbogbo ìgbà tó bá ti fẹ́ẹ́ ṣe nǹkan nínú oko yìí. Lọ́jọ́ tó fẹ́ẹ́ ya àgbàdo tó gbìn ni kòkòrò bá  bà lé e lẹ́yìn ọrùn èyí tó ta á, ariwo rẹ̀ ló jí àwọn iwin ninú igbó aìwọ; wọ́n bi Agidí léèrè ohun tó fẹ́, ó sì ní kòkòrò tó bá lé òun lẹ́yìn ni kí wọ́n bá òun pa. Báyìí ni gbogbo iwin dáwọ́ lu Agidi tó sì gba ibẹ̀ kú pẹ̀lú èróngbà pé àwọn ń pa kòkòro ẹ̀yìn rẹ̀ ni. Inú igbó yìí náà ni òkú rẹ̀ jẹrà sí torí kò sí ẹni tó fẹ́ẹ́ wọ inú igbó aíwọ̀.

 

ỌNÀ ÈDÈ

·        Ìfohunpènìyàn

Sé ọ̀rọ̀ obìnrin máa ń rùn létí irú alágbára bẹ́ẹ̀ ni.

 

·        Àfiwé Tàarà

Àwọn ẹ̀dá wọ̀nyìí ti sán ilẹ̀ lọ bí Èkó bí Ìbàdàn.

 

·        Ìbéèrè Pèsìnjẹ

Bá wo ni n ó ṣe rí irú àgbàdo tó pọ̀ báyìí?

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        ìwà aìgbọ́ràn kò dára gẹ́gẹ́ bí a ṣe ká á pé ìwà aìgbọràn Agídí ló ekú pa á..

·        Kò dára kí á máa dẹ́jàá. Ẹjá dídá pé bóyá nǹkan máa ṣẹlẹ̀ sÁgídí tàbí kò níí ṣẹlẹ̀ ló mú un lọ dáko sínú igbó aìwọ.

 

 

GBADÉ ÀTI RÀÚFÙ

ÌSỌNÍṢÓKÍ  ÌTÀN

Ràúfù máa ń bẹ̀rù Gbadé torí wí pé ó sángun jù ú lọ àti wí pé gbogbo ìgbà tí nǹkan bá jọ dà wọ́n pọ̀ ni Gbadé máa ń nà ań tàbí tí ó máa ń yàn ań jẹ. Irú nǹkan báyìí náà ló ṣẹlẹ̀ láàrin wọn tí kò sì dùn mọ́ Bàbá Ràúfù nínú; torí nàá ó ní wọ́n gbọdọ̀ tún ìjà náà jà. ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀tọ̀ ni Gbadé gbé Ràùfù sánlẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tó di ìgbà ẹ̀kẹta ni Ràúfu tó gbé Gbadè sánlẹ, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ẹ̀kẹrin kí ara Gbadé tó wáá balẹ̀. Láti ìgbà yìí ni Gbadé kò ti yan Ràúfù jẹ mọ́.

 

ỌNÀ ÈDÈ

·        Ìfohunpènìyàn

Ó ṣàlàyé bí iṣu ṣe kú, àti bí ọ̀bẹ ṣe bẹ ẹ́.

Inú bàbá Ràúfù ru fọ̀ọ̀.

 

·        Ìbéèrè Pèsìnjẹ

Kín làǹfàání oúnjẹ tí mo ń fún ọ nígbà náà?

Ìwọ wá ń ṣẹgbẹ́ orí Gbádé ni?

 

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        Ojo ṣíṣe kò dára bí a ṣe rí i nínú ìwà Ràúfù tó jẹ́ pé ìwà ojo rẹ̀ ló jẹ́ kí Gbadé máa yàn án jẹ; ìgbà tí kò bẹ̀rù Gbadé mọ́ ni ó tó gba ara rẹ̀ kalẹ̀.

 

TA LÓ GBỌ́N JÙ?

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN

          Bàbá eléso kan sọ fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ mẹ́ta kan láti ka oǹkà tìtì dè ẹẹwàá láìkà á ní ení-èjì...  Gbogbo wọn ni kò mọ̀ ọ́n àyàfi Ṣọlá nìkan tó fara balẹ̀ ronú sí ìbéèreè náà tó si ìdáhùn ìbéèrè náà báyìí: “agbọ̀n ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ mẹ́rin, kí á fi mọ́ agbọ̀n ọsàn mẹ́fà, àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá...” báyìí ni Ṣọlá gba ìbéèrè náà, gbogbo wọn sì gba pé ọlọgbọ́n ènìyàn ni í ṣe.

 

ỌNÀ ÈDÈ

·        Ìbéèrè Pèsìnjẹ

Èelòó lowó oúnjẹ tí wọ́n fún wọn láti fi jẹun ní ìjáde aago mọ́kànlá?

Bá wo ni oúnjẹ kọ́bọ̀ méjì yóò ṣe rì?

 

·        Ìfohunpènìyàn

Iyè rẹ̀ sọ túkẹ́.

 

ÌLÒ ÈDÈ

·        ÒWE

Bẹ́ ẹ bá láṣọ bí àgbà, ẹ ò le lákísà bí àgbà.

 

 

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        Àfojúdi sẹ́ni tó jù wá lọ kò dára bí ó ṣe hàn nínú ọ̀rọ̀ Bíọlá nígbà tó rò ó pé Bàbá kò mọ ìdáhùn sí ìbéèrè tó bi wọn torí wí pé kò lọ sílé-ẹ̀kọ́.

·         

·        Ó dára láti máa fara balẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i lọ́rọ̀ Ṣọlá tí gbogbo wọn gbà pé ọlọgbọ́n ènìyàn ni pẹ̀lú bó ṣe dáhùn ìbéèrè Bàbá nípa fífarabalẹ̀.

 

ỌMỌ RERE

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN

           Ìṣọ̀lá jẹ́ ọmọ rere tó ran ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ inú ilé èyí tó mú un pẹ́ kó tó dé ilé-ẹ̀kọ́. Lójú ọ̀nà ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló ti pádé arákùnrin onímótò kan tó gbé e dé ilé-ẹ̀kọ́ torí òjò ń rọ̀. Olùkọ́ rẹ̀ náà sì fún un ní ásìá ìwà rere lọ́sẹ̀ náà nígbà tó tún fi owó tí ọkùnrin onímọ́tò náà fún un nítorí bí ìrìnàjò ọjọ́ náà ti rí fún un.

 

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        Ó dára ká máa ran àwọn òbí wa lọ́wọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ ilé bí ó ṣe hàn nìnù ìwà Ìṣọ̀lá.

·        Ìwà ọ̀lẹ kò dára,.

 

 

ÌMỌ̀RÂN ÀGBÀ

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN

Bàbá àwọn ọmọ méjì kan kọ́ wọn ní ọ̀nà téèyàn fi le dolówó láyé nípa kíkúrò nílé fún wọn láti lọ sí ìrìn àjò irọ́ kan torí ọlẹ ni àwọn ọmọ náà. Ó fi oko iṣu rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn pẹ̀lú ìmọ̀ràn pé orù owó kan wà nínú oko iṣu òun àti pé ìgbà tíṣu tòun gbìn bá ti ta dáadáa ni wọ́n tó le rí orù owó náà gbé jáde. Báyìí ni àwọn ọmọ méjì náà bẹ̀rẹ̀ sí i ní tọ́jú oko iṣu bàbá wọn pẹ̀lú ìrètí pé àwọn yóò bá orù owó níbẹ̀ èyí tí wọn kò rí rárá ṣùgbọ́n wọ́n dolówó fún ra wọn nípa títa àwọn iṣu tí wọ́n wà nínú oko náà àti gbíngbín òmíràn padà.

 

ỌNÀ ÈDÈ

Òwe

·        Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́ àti pé ènìyàn kò le mú iṣẹ́ jẹ, kó tún mú ìṣẹ́ jẹ.

 

Ìbéèrè Pèsìnjẹ

·        Ó dáa, ǹjẹ́ kín làwọn ó máa jẹ títí bàbá ó fi dé?

 

Ìfohunpènìyàn

·        Ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ ojú wọn

 

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        Ìwà ọ̀lẹ kò dára torí ìwà ọ̀lẹ àwọn ọmọ yìí ló mú bàbá wọn pinnu ọ̀nà tó gbà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

·        Ó dára ká máa gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí wa lẹ́nu torí ìrírí wọn pọ̀ ju tiwa lọ; àikọ ìmọ̀ràn àwọn ọmọ yìí ló mú wọn dolówó nígbẹ̀yìn.

 

 

DẸ̀DẸ

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN

          Olú, Fẹmi àti àwọn òbí Dẹ̀de máa ń kìlọ̀ fún Dẹ̀dé láti jáwọ́ nínú ìwà olè tó ń wù ṣùgbọ́n kò gbọ́. Ó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ tó lọ́ jí ẹyìn tó wà lẹ́nu pàkúté nínú oko ọkùnrin kan nígbà tí wọ́n ń kọjá lọ síbẹ̀ láti lọ wẹ̀ lódò. Báyìí ni pàkúté mú Dẹ̀dẹ lọ́wọ́ tó sì jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ lọ fẹ́ẹ́ wẹ̀ lódò kò mọ bí wọ́n ṣe le yọ ọ́ lọ́wọ́ rẹ̀; torí náà wọ́n ní láti gbé e dé ilé-ẹ̀kọ́ tòun ti pàkúté lọ́wọ́. Èyí tún jẹ́ kí ìtìjú rẹ̀ pọ̀ sí i torí gbogbo ènìyan ló rí i. Wọ́n fi ìyà jẹ Dẹ̀dé fún ìwà àigbọràn àti ìtìjú tó wù.

 

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        Ìwà olè àti irọ́ pípa kò dára; kò dára bí a ṣe rí bí Dẹ̀dé ṣe kan àbùkù àti ẹ̀tẹ́ bọ̀ níbii ìwà náà.

·        Ìwà aìgbọràn kò dára torí aìgbọ́ràn Dẹ̀de sí àwọn òbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́nu ló kó ìyà jẹ ẹ́.

 

 

 

 

 

ẸNI WOJÚ ÌYÀWÓ

ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN

          Kọ́ládé, Adéfẹ́mi Gbénga àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn yòókù fẹ́ràn láti máa ṣeré ìdárayá lóríṣìríṣi bíi erè sísá tàbí kí wọ́n máa yan bí i ológun tóṣùpá bá ràn. Inú máa ń bí wọn lọ́jọ́ tí òṣùpá kò bá ràn torí wọn kò níí le ṣeré nírú ọjọ́ bẹ́ẹ̀. Irú ọjọ́ báyìí ni àwọn òbí wọn máa ń fẹ́ kí wọn ka ìwé wọn láti máà fi àkókò ṣòfò; nírù ọjọ́ báyìí tí inú bá ti ń bí Gbénga torí ìwé tó ń kà, ìyá rẹ̀ maá ń pa òwé pé “ẹni wojú ìyàwó ló mọ̀ pé ó ń bínú”.

 

ÌLÒ ÈDÈ

 

Òwe

·        Ẹni wojú ìyàwó ló mọ̀ pé ó ń bínú.

 

Ẹ̀KỌ́ TÍ A KỌ́

·        Kò dára kí á máa fi gbogbo àsìkò ṣeré, ká gbájú mọ́ àwọn nǹkan mìíràn tí yóò ṣe wá láǹfàání bíi ìwé kíkà gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ìmọ̀ràn tí Ìyá Gbénga ń gbà á láti máà fi àkókò rẹ̀ ṣòfò.

 

ÌKÁDÌÍ

 Ìwé Ímọ̀ràn Àgbà láti ọwọ́ oǹkọ̀wé Débọ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ oríṣìí ìmọ̀ràn àti ìkìlọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé àwọn ọmọdé ni in nítorí ọ̀nà ìṣàmúlò èdè rẹ èyí tí ko nira rárá, síbẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ jẹ́ èyí tó máa ṣe tọmọdé tàgbá láǹfààní. Ó lo èdè lọ́nà tó gbé iṣẹ́ náà ró dípò kí ó tàbùkù rẹ̀.

Reference

Awẹ́, Débọ̀ (2005), Ìmọ̀ràn Àgbà. Ilesa, Nigeria: Elyon Publishers.



[1] Hassan Khadijat Olayinka ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment