OJÚ RÍ[1]
Kọ́lá
Òní ni òǹkọ̀wé ìwé ìtàn àròsọ Ojú Rí; ọlọ́rọ̀ geere ni ìtàn yìí; ìtàn gígùn sì ni pẹ̀lú.
Kọ́lá Òní jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Gbọ̀gán ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Arárọ̀mí ní ìlú Gbọ̀gán àti ti Pọ́ọ̀lù Mímọ́ ní Owódé- Ẹgbádò ní ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ girama ní Gbọ̀gán ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Yunifásitì Ifẹ̀ àti ti Ekó.
Òǹkọ̀wé tó mọ èdè lò ni Kọ́lá Òní; èdè rẹ̀ gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gbàwo bọ̀;
èdè rẹ̀ sì tún yanrantí, ó fi gbọ̀ọ̀rọ̀
jẹkà; àpẹẹrẹ èyí wà nínú àlàyé iṣẹ́ yìí.
ÌSỌNÍSÓKÍ
Ògúngbèmí
ni olórí ẹ̀dá-ìtàn
ìwé ìtàn àròsọ Ojú Rí; ìwé yìí ń sọ nìpa orísìí ìdojúkọ ẹ̀dá kí àseyọrí tó dé.
Yorùbá bọ̀ wọń ní, kọ́rọ̀ tó dayọ̀, ojú a máa rí. Ògùngbèmí jẹ́ ọkọ Rúùtù àtí
baba ọmọ mẹ́jọ;
Ògúnlabí ni akọ́bí rẹ̀, sùgbọ́n Ògúnlabí ti ní ìdílé tirẹ, ó fẹ́ Bọ́sẹ̀, wọ́n
sì ti bí ọmọ kan tí í ṣe Délé; ìnagijẹ tí wọ́n fún un ni Kọ́ńkọ́ọ́dù.
Bùkátà
tó pọ̀ níwájú Ògúngbèmí ló mu ún máá wá owó kiri, lẹ́yìn tí ó ti kúrò ní ibi iṣẹ́
sójà tó ń ṣe. Ọ̀rẹ́ rẹ̀,
Ògún Àjọbọ,
ló ń dúró dè nínú ilé ìtura Máradán ní ìlú Ìbàdàn, tí ó ń ro ọ̀rọ̀ ilé ayé rẹ̀,
àti orísìí nǹkan tí ojú rẹ̀ ti rí sẹ́yín. Ó dúró títítí kò rí ọ̀rẹ́ rẹ, ó wá
pinnu láti rìn síwájú díẹ̀ bóyá ọ̀rẹ́ rẹ̀ á dé kí òun náà tóó dé. Bí ó ṣe padà dé, èrò púpọ̀ ló bá níwájú ilé ìtura; nígbà tí òun náà yóò fi rápálá wọ ààrin àwọn èèrò,
kàyééfì nlá ló jẹ́ fún un torí òkù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló bá nílẹ̀; lóòótọ́ ni ọ̀rọ Yorùbá tó sọ pé, ènìyàn ò sunwọ̀n láàyè,
ọjọ́ a bá kú là á dère.
Èèmọ̀
bá tún lékan sí I; ó ku ibi tí Ògùngbèmí yóò gbé é gbà; ibi tí ó fojú sí, ọ̀nà ò gba ibẹ̀ mọ́.
Nígbà tí yóò fi délé, ebi ti fẹ́ẹ́ lu àwọn ọmọ pa; àti ìyàwo àtí ọmọ ni wọ́n gùn lọ́rùn bìi àgùnfọn. Ìyà ti
pá orí wọn dáadáa. Ògúngbèmí bá bọ́ síta láti wá iṣẹ́ kan ṣe kí ìyà leè dópin
nínú ilé wọn.
Lẹ́yìn
tí ó rìn síwájú sẹ́yìn, ó rí iṣẹ́ sí ilé ìtẹ̀wé àwọn Òyìnbó; ìdí ẹ̀rọ tó ń gé ìwé ni wọ́n fi í sí; ọjọ́ kan òjò, ó borí ẹgbẹ̀rún ọ̀dá; ará ti ń tu tẹrú tọmọ nílé Ogúngbemí kí láálàà ó tún
tóó lù ú. Ṣé orí burúkú kì í jẹ́ kí àgùntàn hu ìwo; èèyàn tì kò bà sì lórí àṣeyọrí, bó mu omi lásán, yóó há
á léyín, torí ó dorí akáyín ni àkàrà deegun.
Lẹ́yìn osù diẹ̀ ní Ògúngbèmí sọ ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ nu nibi tí
ó tí ń ṣe iṣẹ́ ọba. Ni iṣẹ́ bá parí nínú ilé itẹ̀wé àwọn Òyìnbó.
Ní
ilé ìwòsàn ní Ògúngbèmí ti rí Iná ń jó ògiri ò sá, tí ó wá ṣe àbẹ̀wo sí i, tí
ó sì ṣe ìlérí àti ràn an lọ́wọ́. Osólè tútù ni ó ní kí Ògúngbèmí ṣe, ṣùgbọ́n ó
kọ̀ jalẹ́ láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, àmọ́ aṣọ ó bá ọmọ́ye mọ́, ọmọ́yẹ ti rin
ìhòhò wọ ọ̀jà, iwajú ò ṣéé lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣeé padà sí torí Agbọ́tikúyọ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà, kò gbà fún Ògúngbemí làtí padà sẹ́yìn.
Lẹ́yìn
ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ erò lórí àwọn nǹkan tí Agbótikúyọ̀ sọ fún un, ó pinnu latí mú ọrẹ́
rẹ, Bákàrè, lọ, torí ó gbọdọ mú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kán wá tí wọn ó si lo
aásìkí rẹ́ fún un tí ọ̀rẹ̀ rẹ̀ yóò sì ya wèrè lèyín tí wọ́n bá ti lò ó tán. Àmọ́
ọ̀rọ̀ yíwọ́ mọ Ògúngbèmí lọ́wọ́; òún gan-an ni ó ya wèrè tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì lówó bíí sẹ̀kẹ̀rẹ̀.
Ògúnlabí, ọmọ rẹ̀, ó kúkú rí ti baba rẹ̀ rò rárá; kódà tipátipá ni ó fi wáá bẹ̀ ẹ́ wò nígbà tó wà ní ilé iwòsàn. Ìpátá gidi ni; jìbìtì ni ó ń lu àwọn ènìyàn kiri; kò ní isẹ́ kankan tí ó ń ṣe; nígbà tí kò rí iṣẹ́ ṣe mó ní ilù Ìbàdàn tí ó wà ní ó kó lọ sí Èkó; ó lọ sí ọ̀dọ ọrẹ́ rẹ, Kabiru tí àwọn méjéèjì sì jọ ń ṣe ọṣẹ́ kiri ìlù Ekó.
Bosẹ, ìyàwó rẹ̀, kó kúkú bìkítà torí irú ìróǹborùn ni àwon méjééjì; àfi ọmọ wọn Dele ti òun ya ọmọ gidi.
Rúùtù
jẹ́ ìyàwó rere lọ́ọ́dẹ̀ ọkọ; obìnrin tí a fi ń tọrọ obìnrin ni; ó dúró tí ọkọ rẹ; ko fi í sílẹ̀ rárá; òun náa kí í kúkú ṣe imẹ́lẹ́ ènìyàn; ó kàn jẹ́ pé nǹkan kí í rí bí a ti fẹ́ kó rí nígbà
mìíràn ni. Ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ri í pé ọkọ rẹ̀ rí iwosàn; bí ó ṣe ń sá sókè ló ń sá sódò. Ó lọ sí ọ̀dọ ọmọ rẹ̀ lÉkòó; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀tẹ́ ló bá bọ̀ níbẹ̀. Ó kìlọ̀ títí fún ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́
bí abiamọ rere;
onígbàgbọ́ kúkú ní Rúùtù jẹ́; ó mú ẹ̀sin Kìrìsìtẹ́ẹ̀nì ní ọ̀kúnkúndun ó sì ń gbìyànjú àgbára rẹ̀ látí ri í
pé ìdílé rẹ̀ mọ Ọlọ́run.
Délé, ọmọ
Ògúnlabí, wáá rí àǹfààni àti lọ si ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásiti Ifẹ̀. Wọ́n gba á gẹ́gẹ́ bíí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin; ọmọ ti ó já fáfá ni Délé; kò jọ bàbá rẹ̀ tó sá kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrà ni Délé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dán wò ní
ilé-ẹ̀kọ́; níbẹ̀ náà nì ó ti rí ìyàwó rẹ̀, Kemi. Lẹ́yìn tí Délé parí ní ilé-ẹ̀kọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní wá iṣẹ́ ó sì ṣe àbápàdé oríṣìí ìdojúkọ nibẹ̀
kí ó tó wá di ògbóǹtarìgì lọ́yà.
Nìgbà
tí ọ̀rọ̀ Ògúngbèmí kò ní ìyanjú, tí ọmọ rẹ̀, Ògúnlabí tún gbìyànjú àti pà á ṣùgbọ́n tí
Ọlọ́run kò pe tiẹ̀ ní ikú, Rúùtù àti Bákàre wáá gbè e lọ sí ọ̀dọ bàbá Fádípẹ̀, ẹ̀ni tí ó jẹ́ babaláwo tí
ó sì mọ ewé àti egbò. Níbẹ̀ ní Ògúngbemí ti rí iwòsaǹ léyìn ọjọ́ mẹ́tà tí wọ́n
ti ń ṣaájò rẹ̀.
Fádípẹ̀
wáá sọ fún Bákarè pé owó rẹ̀ kò níí wá mọ́ tààrà bí i ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé
e, torí onítọ̀ún kò kúkú mọ ohun tí Ògúngbèmí ṣe ti ilé fi jó. Ọ̀rọ̀ sí kúkú rí
bí bàbá yíí ṣe sọ ó; òye ọ̀rọ̀ náà wáá yé Bákare; ó
sì ń sa ipá rẹ̀ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìsoro náà.
Ọjọ́
gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ni tolóun; ọwọ́ pálábá Ògúnlabí wá ṣégi; ọwọ́ àwọn àgbófinró bà á lẹ̀yìn tí ó ti fi olè kún ọ̀lẹ. Wọ́n mú un lọ
sí ilé ẹjọ́; ọmọ rẹ̀ ni ó sì dúró gégé bí agbófinró fún un, láti ara ẹjọ́ yìí sì nì
Délé fi di ògbóǹtarìgì lọ́yà, tí ó sì di olókìkí pẹ̀lú. Àmọ́ ikú ni Ògúnlabí
fi pàpà ṣe ìfà jẹ ní tirẹ̀ lẹ́yin gbogbo ìgbìyànju ọmọ rẹ.
Lẹyín èyí ní gbogbgo nnkan wá bẹ̀rẹ̀ sí níí dùn fún Ògúngbèmí àti ìdilé rẹ̀; Dele kọ́ ilé ńlánlá fun wọ́n; ó kọ́ sọ́ọ́bù fún Rúùtu tí yóò ti
máa ràn aṣọ gègè bíi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ó sì kọ “Musílíátù di
telọ́” sí i lára; ibi iṣẹ́ yìí sì ní òun àti ọkọ rẹ̀ ti ṣe alábápàdé ara wọn.
Délé sì tún ra mọ́tọ̀ nlánlá méjì fún Ògúngbèmi; gẹ́gẹ́ bíi iṣẹ́ ọwọ́ tiẹ̀ náà, ó sì kọ “Ògúngbèmi Ọlọ́run
ò ṣebi” sí ara àwọn mọ́tò náà.
Orísìírísìí
akitiyan ni Bákárè sà láti rí i pé nǹkan padà bọ́ sípò fún un ṣùgbọ́n pàbó ló
já sí; ó wá pinnu láti gba ọ̀dọ Ògúngbèmí lọ kí ó ba à leè gba
òun àti ìdílé rẹ̀ sọ́dọ̀ kí ìyà wọn lè dópin, ìgbà ìpọ́njú la kúkú n mọ̀rẹ́,
Ògúngbèmí kò rò ó léèméjì tó fi ní kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtí ìdílé rẹ̀ máa kó bọ̀ wá sílé.
Ìtàn
yìí wáá fi hàn wá pé ọ̀rọ̀ tí yóò bá ṣakàn, bíi ẹja níí kọ́kọ́ rí; béwúro ó bá sì ṣadùn, a kọ́kọ́ rí bíi iwọ.
IRÚFẸ́ ASỌ̀TÀN
Asọ̀tàn
afarasin ni irúfẹ́ asọ̀tàn tí a ní. Èyí ni asọ̀tàn tí kò sí nínú ìtàn ṣùgbọ̀ń
ó mọ gbogbo ohun tí ó ń lọ nínú ìtàn pátápátá. Arí-hín-rí-ọ̀hún ní ó jẹ́; òun ni ó sì ṣe òfófó ìtàn náa fùn àwọn òǹkàwé. Òye àti
ìmọ̀ kíkún tí ó ní nípa ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn yìí ló fún un ní àǹfààní àtí lè ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
àlàyé nípa ìtàn náà. Ó mọ̀ nípa ẹ̀dá ìtàn kọ̀ọ̀kan àti àwọn ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan
wọn lè ṣe ó sì júwèé wọn fínnífínní. Àpẹẹrẹ èyí wà ní ojú ìwé
kìn-ín-ní sí ìkejì níbi tí ò ti ń júwèé Ògúngbèmí. Ojú-ìwé
45 ni ó ti jùwèé Ògúnlabí.
Ìtàn gígùn
Àwọn
àbùdá tí ó fi ìtàn yìí hàn gẹ́gẹ́ bíi ìtàn gígùn ni:
Ìlò orin
A rí àpẹẹrẹ
èyí ní:
Ojú ìwé kẹrin:
Àgbẹ̀ tí kò gbin kòkó
Bo bá dàgbá tán, ọmọ rẹ̀ á ṣépè lé e
Arékende
Aayé, aarékende.
o.i
11
Atiro mẹ́sẹ̀ ò le,
ọ̀ná jìn.
Wọ́n ní n má ja lóde
ọ̀ná jìn.
A
tún rí àwọn àpẹẹrẹ mìíran ni àwọn ojú ìwé wọ̀nyìí, o.i 42, o.i 67, o.i 49, o.i 99, o.i 16, o.i 17, o.i 117.
Ìlò oríkì.
A
rí àpẹẹrẹ èyì ni ojú ìwe kẹtàdínlógún nígbà tí Rúútù ń ki ọkọ rẹ̀ ní mẹ́sàn-an mẹ́wàá.
Ìlò Àlá
Àpẹẹrẹ
èyí wà ní ojú ìwé kẹrìndínlógún; èyí ni àlá tí Ògúngbèmi la nípa ìjàǹbá tí ó ṣẹlẹ̀ sí i ṣùgbọ́n kò ka àlá náà kún rárá. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ ẹ̀bẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ pé kí ó má lọ sí ibi iṣé ní ọjọ́
náà
ó papa lọ.
Ìtàn nínú ìtàn
Èyí
náà jẹ́ àbùdá kan pàtàkì tí ó máa ń mú ẹ̀mí ìtàn gùn. A rí àpẹẹrẹ èyi lọ́pọ́lọpọ́
nínú ìwé yìí.
Ni ojú ìwé ogójì, a rí itàn inú alọ́ tí ó ń sọ
nípa Ìjàpá àti Ojolá tí wọ́n jọ ń se ọ̀rẹ́.
Àpẹẹrẹ
mìíràn tún wà ní òjú iwé karùnlélọ́gọ́run nibi ti wọn ti ń sọ nípa ọkunrin ọdẹ
tó sọnù nínú igbó.
O.i 118,
èyí ni ìtàn tí ààfáà n sọ nígbà tó ń se wáàsi ní ìta
gbangba, èyí tí Bákárè fi etí gbọ́ tí ó sì mú kí ó ronú
pìwàdá nípá ìwà ibi tí ó ní lọ́kan.
Ìbojúwẹ̀yìn
Ó ní í ṣe pẹ̀lú
mímú iṣẹ̀lẹl àtijọ́ wá sí ìrántí ní asiko tí à ń bá ìtàn mìíràn lọ.
Apẹẹre:
o.i 3
Ni àsìkò yìí ni Ògúngbèmí ránti ìgbà tí ó ǹ ṣe iṣẹ́ sójà àti bí ó ṣe fi iṣẹ́
nàà silẹ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí níí wa ọkọ.
o.i 33
Ó ń sọ nípa ìgbésí ayé Bakèrè
làtí ìgbà tí ó ti jẹ́ ọmọdé àti orísìí ìdojúkọ tì ó rí nígbà tí ó dàgbà titi di
àsìkò tí ó wà yìí.
o.i 46
Òǹkọ̀we ń sọ nípa ìtàn Rúùtù, ìdílé rẹ̀ àti bí ó ṣe pàdé ọkọ rẹ ni ìdí iṣé
télọ̀ tí ó ń kọ́ nígbà náà.
o.i 85 Ó n sọ nípà ìgbà tí Dèlé fi wà ní Yunifásiti Ifẹ ò sì ń
rántí ọjọ́ tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀, Babatúnde lọọ pitú ní gbọ̀gàn Oduduwa.
Yàtọ̀
sí àwọn àbùdá yìí, ìṣẹ̀lẹ̀ ínú ìtàn yìí gan-an fi hàn pé ìtàn gígún ni torí àkókò tí ó gbà wáyé kò
kéré rárá. Ó ju ọ̀rọ̀ ọdún maarún-un sí mẹ́fà lọ.
ÌLÒ ÈDÈ
Kọ́lá
Òní jẹ́ gbédègbẹ́yọ̀, tí ó mọ́ èdè lò dáadáa ó sì ṣàmúlo àwọn ọnà èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀; lárà àwọn ọnà èdè náà ni:
Àfiwé tààra
o.i 1...ó
kàn gbé orúko lórí lásań bìi háràhárà.
...ó gbajúmọ̀ ni bíi ìsáná ẹlẹ́ẹ́tà.
....ó
pupa bíí òòlẹ̀ àwẹ̀.
o.i 6...ara òun yá gágá bii ara a-kẹ̀kọ-sàsọ.
o.i 13 ..òun gan-an ń rin sìn-in bíi gúgúrú ìdí
Èsù.
o.i 45..ọkọ bi ẹmọ́, aya bi àfè.
o.i 19
..ó ń sọ kìjìkìjí bi ẹja tí wọ́n mú sórí ilẹ̀.
o.i 106
Ìyá mi gan-an tó sálọ bi òkò rọ́bà, tó sán lọ bi ẹyẹ-oko
yìí..
àti bẹ́ẹ̀
bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìbéérè pèsìjẹ
o.i 4
..kí ni òun ó fi máa bọ́ wọn? Ọ̀nà wo ni òun ó gbà máa san
owó ilé-ìwé wọn?
o.i 24
..o ti ṣe mọ̀ pénìkan ò le lówó lọ́wọ́.?
o.i 119
..Abi ki oun kúkú lọ ọ̀dọ̀ Ogúngbèmi lékòó ná ni? Kí òun
bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kòun wá máa gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ tayatọmọ?
Ìfohunpènìyàn
o.i 199
owó tó ni bóun ò
bá sí nílé, kẹ́nikẹ́ni ó má dámọ̀ràn kímọ́ràn lẹ́yìn òun.
Níbí, wọn ń sọ̀rọ̀
nípa owó bíi pé ènìyàn ni; wọ́n gbé àbùdá ènìyàn wọ owó.
Ìlò Àkànlò Èdè
o.i 42
..fi orí já igbó já ijù
o.i 113
..gbobgo bí ó ṣe ń yí bàbá Fádípẹ̀ sébè ní bàbà Fádípẹ̀
ǹ yìi sí poro
o.i 10
..ká fi sẹ́nu ká dákẹ́
Àsọrégèé
o.i 15
..bí ènìyàn gun ẹsin nínú rẹ̀ kò le è kọ ẹsẹ̀.
Ìlò òwe
Òǹkọ̀wé fẹ́ràn
làti máa lo àsínpọ̀ òwe, á ri àpẹẹrẹ èyí nínú iṣẹ́ yìí.
o.i 2
...ò dá ní ọmọ se de ẹ̀gbẹ́, ẹ̀gbẹ́ kì í ṣe ilé ọmọ. Bí
kò bá sí ikú ajọkú, bawo ni ọ̀kẹ́rẹ́ ṣe le gbétan lé ìgalà? Òjò tó rọ̀ lójẹ́ ká
kó ẹyẹlé pọ̀ mádiẹ.
o.i 6
..ajá tí yòò sọnù kì í gbọ́ fèrè ọlọ́dẹ.
o.i 7
.. .ọ̀ràn tí ń se
Lémibajẹ́ kò ṣe ọmọ rẹ̀, Lémibàjẹ́ ń sunkun owó, ọmọ rẹ̀ ń sunkun ọkọ. Konko
jabele
o.i 26
..ojú ẹ̀ fọ́, etí ẹ̀ di, agbọ̀n ìsàlẹ̀ tún ya dé ìpàkó, ó
ní kí ẹlẹ́mìí ó má sàà tí gbà á; bí ẹlẹ́mìí kò bá tètè gbà á, iwọ̀ gan ò gbọdọ̀
jù sí i?
o.i 27
..ojú lásan ti tó mọ ọbẹ̀ tí yóò dùn; ẹ̀yìn ẹsẹ la ti í mọ
ọmọ tí yóò sẹ̀ẹ̀míì.
o.i 49
..ọ̀rọ̀ gbénú ẹni rà bi ìtì ọ̀gẹ̀dè. Òun ò gbọdọ̀ sórí
olórí kí àwòdì ó wá gbé tòun lọ. Bí iná bá ń joni tó ń jó ọmọ ẹni, tara ẹni
là á kọ́ gbọ̀n.
o.i 53
..Bókèété bá dàgbà tán, ọmú ọmọ rẹ̀ ní í mu. Ẹni tó bá ṣe
síbi pẹpẹ yẹ kó jẹ níbi pẹpẹ...
o.i 81
..díẹ̀ ni tÌdòwú lára ìbejì, ẹ̀kẹta ọmọ ní í ṣe.
o.i 102
... kébù ó rà, ká fojú kègbodò, kẹ́yin ó fọ́, ká fojú
kòròmodìẹ tó ńi r’ogbo. Òótọ́ ọ̀rọ̀ bí ìsọkúsọ ní í rí. Bí tẹnìkan ò bá bàjẹ́,
tẹlòmìíràn kì í dára. Tibi tire la dálé ayé, ohun tó kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ
sẹ́lòmíràn.
o.i 22
.. oníkókó
tó dọwọ́ bojú, ibẹ̀ ni ó ba á, onígbẹ̀gbẹ̀ tó dọwọ́ bọrùn, ibẹ̀ ni ó bá a.
o.i
3 …iṣẹ́
to sẹ́ ọmọ logún ọdún, ìyà tó jẹ ọmọ lọ́gbọ̀n oṣù, bí kò ba pa ọmọ, yóò dẹ̀yìn
lẹ́yìn ọmọ ni...
o.i 12 ...ikún ń jọ̀gẹ̀dẹ̀, ikún ń rẹ̀dií finkin, ikún ò mọ̀
pé ohun tó dùn ní í pani, òpìpi yé mọ níwọ̀n.
Àkíyèsí
mìíran nípa òǹkọ̀wé ni pé ó ṣe àfihàn ẹ̀sìn nínú iṣẹ́ rẹ̀; a rí àpẹẹrẹ èyí ní ojú-ìwé kọkàndínlógún sí ogún àti ojú-ìwé kẹrìndínlógún.
Òǹkọ̀wé tún ṣàmúlò
ọfọ̀, a rí ẹ̀rí èyí ní ojú ìwé kejìdínlógún.
Nínú
ìtẹ̀síwájú ìtàn, a ṣàkíyèsí pé ẹni tó mọ̀ nípa àṣà Yorùbá ni ònkọ̀wé jẹ́.
Yorùbá fẹ́ràn àlejò ṣiṣe púpọ̀, èyí ló sì mú kí ìdílé bàbá Fádípẹ̀ gba Rúùtù
àti Bákare láyè nínú ilé wọn nígbà tí wọ́n lọ fún ìwòsàn.
Kókó ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí.
Iṣé lòògùn
ìṣé.
Iṣẹ́
ní í kúkú sọ ẹni di ènìyàn ńlá; lẹ́yìn orísìí wàhálà tí Ògúngbèmí ti dojú kọ, kò kúkú
sinmi à ń wáṣé; ó sa gbobgo ipá rẹ̀ latí ri í pé ó rí iṣẹ́, ṣùgbọ́n lẹ̀yín tí ó rí iṣẹ́, èèmọ̀ ló kò níbẹ̀.
Obìnrin rere
Rúùtù jẹ́ aya rere lọ́ọ́dẹ̀ ọkọ; ó dúró ti ọkọ rẹ̀ nígbà ìṣòrò kò fí í silẹ̀ rárá, ó sì
tún máa ń ki ọmọ rẹ̀ nilọ̀ latí pa ìwà burúkú tì. Ó mú ẹ̀sìn ní ọ̀kúnkùn dùn; kò sí da ilẹ̀ ọkọ rẹ̀. Irú àwọn obìnrin báyìí sọ̀wọ́n ní
àwùjọ wa lóde òní.
Lílu jìbìtì
Èyí
jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ̀ ìwòyí; ìwà jìbìtì ni wọn ń wù kiri, wọn kò sí wá iṣẹ́ gidi ṣẹ; tí ó bá tún yá, wọn á fi olè kún ọ̀lẹ wọn. A rí àpẹẹrẹ
èyí lára Ógúnlàbí àti Kàbírù.
Ọjọ́ kan ni tole, ọjọ́ kan ni tolóhun
Lẹ́yìn
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti Ògúnlabi fi ojú àwọn ènìyàn rí, ọ̀wọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ẹ́, ó
sì kú ikú àìtọ́jọ́.
Reference
Oni, Kọla (2001), Ojú Rí. Abeokuta, Nigeria: Topdam Educational Publishers Nigeria
Limited.
No comments:
Post a Comment