Friday, 2 February 2018

Láti kò tó sí Kòtò

ORÚKỌ ÌWÉ:                     LÁTI KÒ TÓ SÍ KÒTÒ[1]
ÒǸKỌ̀WÉ:                           LÁSÚNKÀNMÍ TẸ̀LÀ
ÒǸTẸ̀WÉ:                            EVANS BROTHERS (NIGERIA PUBLISHERS)
LIMITED, IBADAN, NIGERIA.
ÀGBÉJÁDE KÌN-ÍN-NÍ:  2009

Ìsọníṣókí Ìwé Láti kò tó sí Kòtò
            Ìwé eré-oníṣe Láti kò tó sí Kòtò tí a ti ọwọ́ Lásúnkànmí Tẹ̀là jẹ́ ìwé tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ nípa lílo Ọlọ́ládé tí ó jẹ́ olúborí ẹ̀dá ìtàn. Àkọ́lé ìwé yìí gan-an jẹ́ atọ́nà tàbí atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé yìí.
            Yorùbá bọ̀, wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn baba ìwà. Èyí kò sí nínú ọ̀rọ̀ àti ìgbésí ayé Ọlọ́ládé tí ó jẹ́ olúborí ẹ̀dá ìtàn ìwé eré oníṣe Láti kò tó sí kòtò. Òun gangan ni ajere àkọ́lé ọ̀hún sì mọ̀ lórí. Òǹkọ̀wé fẹ́ ká mọ̀ wí pé gbogbo ẹni bá ń sáré lé kò tó, kò tó tí ò lè jẹ, tí ò le mu; àgbà tó bá wẹ̀wù àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ti oúnjẹ àárọ̀ dọ̀sán kó tó le jẹ ẹ́; tó sáré owó títí, tí ò nísinmi; tó sáré tó ǹ le kò tó kiri, àfàìmọ̀ kó má se pé kò tó náà ni yóò lé tí yóò fi wọ kòtò bíi ti Ọlọ́ládé nínú ìwé Láti kò tó sí kòtò.
            Ọlọ́ládé rọ́jú tan ó ń wá àìrójú kiri. Ọlọ́ládé ní ìyàwó àtàtà. Ọláníkẹ̀ẹ́ dára lóbìnrin. Inú kan ló fi ń bá ọkọ rẹ̀, Ọlọ́ládé, lò. Wọ́n bímọ; àwọn ọmọ wọn sì ṣe àṣeyọrí. Wọ́n yàn; wọ́n yanjú ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò tẹ́ Ọlọ́ládé lọ́rùn tó. Bó ṣe ń ṣòwò epo rọ̀bì, ló ń ṣòwò fàyàwọ́. Ọláníkẹ̀ẹ́ kilọ fún un títí pé ìwọ̀ntún wọ̀nsì ni nǹkan dùn mọ. Gbogbo ìgbìyànjú Ọláníkẹ̀ẹ́ láti yí ọkọ rẹ̀ lọ́kàn padà nípa iṣẹ́ àṣejù lò já sí pàbó.
            Yorùbá ní àṣejù ni baba àṣetẹ́. Iṣẹ́ àṣekúdórógbó ni Ọlọ́ládé ṣe títí tó fi kan ìyọnu. Òyì ojú lò kọ́kọ́ gbé Ọlọ́ládé nínú ọ́fíìsì rẹ̀ ní Ọlọ́ládé Ventures. Èyí ló mú kí wọ́n fún un ní ìsinmi. Pẹ̀lú ìsinmi yìí, Ọlọ́ládé kò lè ṣàìmá ṣiṣẹ́. Èyí tó burú ju ti Ọlọ́ládé fi ṣe àgémọ ní gbóórò ni iṣẹ́ tí Ọlọ́ládé tún ń lọ ṣe lásìkò ìsinmi rẹ̀ ní Ámẹ́ríkà. Ọlọ́ládé dọ́gbọ́n ra ẹ̀rọ fóònù tí ó lè ṣe iṣẹ́ lápútọọ̀pù tí Ọláníkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀, gbé pamọ́ kí ọkọ rẹ̀ báa lè sinmi, ṣùgbọ̀n Ọlọ́ládé lo ọgbọ́n láti ra ẹ̀rọ fóònù tí ó sì fi ń ṣiṣẹ́ lóru tí ìyàwó rẹ̀ bá ti sùn tán.
            Ibi ìjíròrò Ọlọ́ládé pẹ̀lú àwọn Òyìnbó nípa okòwò tuntun tí wọ́n fẹ́ẹ́ sì ní Kánádà ni gbẹgẹdẹ ti gbina. Níbi ìpàdé pẹ̀lú àwọn Òyìnbó ni Ọlọ́ládé ti yí lulẹ̀ lórí àga. Eré ni, àwàdà ni, Ọlọ́ládé ṣe bẹ́ẹ̀, ó kú. Ọlọ́ládé sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di kò-ní-baba; ó sọ Ọlánìkẹ́ ìyàwó rẹ̀ di opó nítorí ìwà ojúkòkòrò. Ìwádìí fi hàn pé àìnísinmi tó ló fa ikú Ọlọ́ládé. Ọ̀kan rẹ̀ ló dédé kọṣẹ́. Ọ̀kẹ́rẹ́ gun ìrókò, ojú ọdẹ dá wàyí.
            Ká ṣiṣẹ́ ká máà sinmi; ká ṣòwò, kó jèrè lọ́pọ̀; kérè wọni lójú, kó wọ ni lẹ́wù; ká sáré òní, ká má le sinmi; ká sàníyàn títí láìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn bín-ín-tín; ká sáré, sáré, torí owó; ká sáré, kò-ì-tó, kò-ì-tó; ká máa sáré kó le pọ̀ si aré àṣálàágùn, láìbojú wẹ̀yìn mọ́ làléébù kan pàtàkì tó jẹ́ ti Ọlọ́ládé. Kìí ṣàgbèrè, bẹ́ẹ̀ ni kìí mọtí para ṣùgbọ́n kíni kan tó ba àjàò rẹ̀ jẹ́ náa ni àìsinmi. Mo le gòkè, mo lè sọ̀, ara ní í fàbọ̀ sí.
Ìṣọwọ́lò-Èdè
            Ìlànà eré-oníṣe náà ni Lásúnkanmi Tẹ̀là gbà kọ ìwé Láti Kò Tó sí Kòtò. Òǹkọ̀wé ṣàmúlò àwọn èdè tó dùn. Ọnà-èdè inú ìwé yìí mú kí ẹwà ède inú ìwé yìí wuyì. Àkọtọ òde òní ni òǹkọ̀wé fi kọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí ó de ìwé eré-oníṣẹ́ yàtọ̀ sí ti àwọn ẹ̀yà lítíréṣọ̀ yòókù.
            Òwe gẹ́gẹ́ bí irúfẹ́ ìlò-èdè kan jẹ́ olúborí ìlò-èdè tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò. Àwọn ìpèdè ìsítí tó ń kìlọ̀ ìwà ní òǹkọ̀wé ṣàmúlò pẹ̀lú.

Òwe
Pg 19 – Bù fún mi kí ń bù fún ọ lòwe kọ̀ǹkọ̀ lódò
Pg 22 – Ọ̀rọ̀ kò le pọ̀ lápọ̀jù ká fọ̀bẹ bù ú
Pg 23 – A kìí mọ ọ́n gún mọ̀ ọ́n tẹ̀ kíyán ewùrà máà ní kókó
Pg 25 – Òkè ibi ni kò jẹ́ kí a rí ọ̀hún òwe ta ò gbọdọ̀ pa nílé àna.
Pg 28 -   Ìgbà ara là á búra, ẹnìkan kìí bú Ṣàngó lẹ́ẹ̀rùn
Pg 31 – A ń kì í, à ń sà á, a sọ pe abiṣuu-ta-lóko gbọọrọ-gbọọ, abágbado-ó-yọmọ bọ̀ọ̀ku-bọ̀ọ̀kù láàlà, ìwọ tún ń bini pọ́dẹ ló kú tàbágbẹ̀?
Pg 33 – Ọmọ tó bá fẹ́ẹ́ dàgbà kìí gbọpẹ lọ́wọ́ àgbà. Ọmọdé kìí láṣọ bí àgbà kó lákìísà bí àgbà.
Pg 39 – Ẹni tí yóò jẹyin inú àpáta kò gbọdọ̀ wẹnu àáké
Pg 45 – Olè kìí jàgbà kó mọ́ ṣe é lójú fìrí
Pg 16 – Kí ni kí ń sọ pe mo rí lọ́bẹ̀ tí mo fi wa irú sọ́wọ́

Àfiwé : Àfiwé Tààrà
Pg 16 – Ọ̀gá ń ṣiṣẹ́ aago
Pg 112 – “… ta a ṣe mọ́ra pàpàkókó àwọn èwe ìwòyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ oge ṣíṣe …”
Pg 113 – “…n ó ti láya bíi ti kìnnìún, n ò sì ti gbọ́n ejò, pẹ̀tú sinmi bíi tàdàbà

Àwítúnwí: Àwítúnwí alákùdé
Mo ,
Mo sọ, sọ
Fífi Tíọ́rì Ìbáragbépọ̀ wo Ìwé “Láti kò tó sí Kòtò
            Ìgbàgbọ́ àwọn onímọ̀ tíọ́rì ìbáragbépọ̀ ni pé èso àwùjọ ni lítíréṣọ̀. Fún ìdí èyí, gbogbo ohun tí òǹkọ̀wé alátinúdá bá kọ tàbí tí ó ṣẹ̀dá ni a gbọ́dọ̀ kọ́ tàbí kí á rí gẹ́gẹ́ bí èso àwùjọ. Àwùjọ ló jẹ́ ìpìlẹ̀ fún lítíréṣọ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ máa ń ṣàlàyé lítíréṣọ̀.
            Nínú ìwé Láti kò tó sí kòtò, ìgbé ayé Ọlọ́ládé ṣàfihàn wàhálà tí àwọn olówó àwùjọ máa ń ni. Bẹ́ẹ̀ sì ni òǹkọ̀wé lo Ọlọ́ládé láti jẹ́ kí òǹkàwé mọ̀ wí pé ìsàlẹ̀ ọrọ̀ lẹ́gbìn-in. Lótìítọ́ ni Ọlọ́ládé ní ilé-iṣẹ́ ńlá ṣùgbọ́n ó tún ń ṣe òwò epo rọ̀bì, òwò fàyàwọ́ (wọ́n tilẹ̀ tún ń ta ọkọ̀ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n sì tún ń jí i gbà padà lọ́wọ́ wọn). Gbogbo ìwà yìí ló lòdì sòfin tí wọ́n sì wà láwùjọ wa lónìí.
            Lákúnlé jẹ́ ọ̀gá àwọn ọmọ ogun orí-omi tí ó ń sìnlú tọkàn-tọkàn. Bẹ́ẹ̀ sì ni a rí Fọlọ́runṣọ́ tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ nínú iṣẹ́ ològun ilẹ̀ wa. Òǹkọ̀wé ṣàfihàn àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n yẹ kan jẹ́ aláàbò ìlú ṣùgbọ́n tí ìwà olè, ọ̀kánjúà ti wọ̀ lẹ́wù. Gbogbo ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí ni òǹkọ̀wé ń pe àkíyèsí àwọn òǹkàwé sí nítorí gbogbo àwọn ìwà ìbàjẹ́ yìí ni wọ́n ṣodo sínú àwùjọ wa lónìí.
            Ìwà ìpanilẹ́kún jayé Arígbabùú náà burú jà. Bí wọ́n bá ta ọkọ̀ fún ẹnìkan, àwọn ni wọn lọ ń já a gba padà lọ́wọ́ àwọn tó rà á tí wọ́n a sì tun tà á. Àwọn ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí ni òǹkọ̀wé ń ṣàfihàn. Pabanbarì rẹ̀ ni ìwà àṣejù; wọ́n ní àṣejù ni baba àṣetẹ́; ìwọ̀n ni gbogbo nǹkan dùn mọ, ìsinmi sì lára ń fẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà. Wàhálà inú ọlá ti àwọn ẹ̀dá kan fi gbà pé ọlá níyọnu ni òǹkọ̀wé lo Ọlọ́ládé àti ìdílé rẹ̀ láti ṣàfihàn àwọn wàhálà bẹ́ẹ̀. Lítíréṣọ̀ ń bẹ ìgbésí ayé àwọ ẹ̀dá wò ni.
Reference
Tẹla, Lasunkanmi (2009), Láti Kò Tó sí Kòtò. Ibadan, Nigeria: Evans Brothers (Nigeria Publishers) Limited.



[1] Adesanya, Olalekan Ige ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment