Friday, 2 February 2018

IBI AYÉ BÁ MI DÉ

ORÚKỌ ÌWÉ:                     IBI AYÉ BÁ MI DÉ[1]
ÒǸKỌ̀WÉ:                           ADÉFÚNKẸ́ FÁMOJÚRỌ̀
ÒǸTẸ̀WÉ:                            EXTENSION PUBLICATIONS LIMITED
IBI ÌTẸ̀WÉ:                         IBADAN
ÀGBÉJÁDE ÀKỌ́KỌ́:       2010

Ìsọníṣókí Ìwé “Ibi Ayé Bá Mí Dé”
            Ìwé “Ibi Ayé Bá Mí Dé” tí a ti ọwọ́ Adéfúnkẹ́ Fámojúrọ̀ kọ jẹ́ ìwé eré-oníṣe tí ó ń ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ pàápàá jù lọ lórí ọ̀rọ̀ ọmọbìnrin, ọ̀rọ̀ lọ́kọ-láya àti ọ̀rọ̀ ọmọ. Ipa òbí àti ti alágbàtọ́ lórí ọmọ jẹ yọ púpọ̀ nínú ìwé yìí.
            Ọlájùmọ̀kẹ́ ni olúborí ẹ̀dá-ìtàn inú ìwé yìí. Ikú kò dájọ́, kò dóṣù tó fi mú ìyá Ọláníkẹ̀ẹ́ lọ ọ̀run àrèmabọ̀. Ikú Ìyábọ̀dé tí í ṣe ìyá Ọlájùmọ̀kẹ́ ló sọ ọ́ di ọmọ òrukàn òjijì. Ikú ìyá Ọlájùmọ̀kẹ́ ló sọ ọ́ di èrò Kàdúná lọ́dọ̀ àbúrò ìyá rẹ̀ tó ń jẹ́ Gbèmí. Ọtí àti ẹja tútù ni Gbèmí ń tà ní Kàdúná. Àwọn kan tilẹ̀ máa ń pè é ní Màmá Kòsóṣì.
            Ọ̀dọ̀ Gbèmí ni Ọláníkẹ́ ti parí ìwé mẹ́wàá, ṣùgbọ́n lásìkò tí ìdánwò àṣekágbá ti girama rẹ̀ súnmọ́, Ọláníkẹ́ ṣalábàápàdé ọmọkùnrin àgùnbánirọ̀ kan tí ó ǹ jẹ́ Túndé. Túndé fi ipá bá Ọláníkẹ́ lájọṣepọ̀. Kàkà kí Ọláníkẹ́ sọ fún ìyá rẹ̀, Bọ́láńlé, ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló lọ ṣàlàyé fún. Pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ta, Ọláníkẹ́ padà lóyún. Gbèmí rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìtìjú ńlá ṣùgbọ́n Yorùbá bọ̀, wọ́n ní ọmọ ẹni kìí burú ká lé e fẹ́kùn pa jẹ. Bí a bá sì fọwọ́ ọ̀tún bá ọmọ wí, a ó fi tòsì fà á mọ́ra. Èyí ló mú kí Gbèmí dárí jì Ọlájùmọ̀kẹ́. Ṣebí Gbèmí kò kúkú bímọ. Èyí tún jẹ́ kó mọ rírì ọmọ.
            Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ọlájùmọ̀kẹ́ ṣe ìdánwò àṣekágbá, ó sì yege. Lákòókò yìí, Ọlájùmọ̀kẹ́ ti bímọ. Inú rẹ̀ kò dùn sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó sọ ọ́ di abiyamọ òjijì. Tundé tí ó dá wàhálà sílẹ̀ ti sìnlú tán, ó sì ti padà sí ìlú rẹ̀ ní Ìsẹ́yìn, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ tí ó fi ipá bá Ọlájùmọ̀kẹ́ lájọṣepọ̀ ni Ọlájùmọ̀kẹ́ ti ṣépè fún un pé àwọn òbí rẹ̀ kò níí jèrè rẹ̀. Wọ́n ní ọmọdé búròókò, ó bojú wẹ̀yìn, ó ṣebí òòjọ́ lólúwéré ń pani. Èpè Ọlájùmọ̀kẹ́ kò ṣàìṣẹ. Ikú mú Túndé lọ. Àwọn òbí rẹ̀ kò jèrè rẹ̀. Ọlámilékan Ayọ̀dèjì ni wọ́n sọ ọmọ Ọláníkẹ́.
            Ọláníkẹ́ tún ṣe ìdánwò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó yege, ó sì di akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì ti ìlú Èkó. Ṣáájú àkókò yìí, ìrònú Ọláníkẹ́ bí yóò ṣe lọ ilé-ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ọmọ lọ́wọ́ ló jẹ́ ìṣòro fún un. Iṣẹ́ Gbèmí náà kò fi àyè gbà á láti tọ́mọdé. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Ọmọ́tọ́lá, ọ̀rẹ́ Gbèmí, wọ́n pinnu láti gbé ọmọ Ọláníkẹ́ lọ sí ilé àwọn ọmọ aláìníyàá tí Ọláníkẹ́ náà sì mọ̀ si. Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, oṣù ń gorí oṣù. Ọláníkẹ́ ti pàdé ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọ̀rẹ́ Ọláníkẹ́. Kọ́láwọlé, ẹ̀gbọ́n Wùnmí, ni òun àti Ọláníkẹ́ fẹ́ra lẹ́yìn tí Ọláníkẹ́ kàwé tán.
            Òkè òkun ni Kọ́láwọlé ń gbé. Kò pẹ́ tí ó fi mú Ọláníkẹ́ lọ sí òkè òkun pẹ̀lú. Wọ́n bímọ obìnrin kan tó ń jẹ́ Túnráyọ̀. Ṣàdédé ni ìjà ń ṣẹlẹ̀ láàrin Kọ́láwọlé àti ìyàwó rẹ̀, Ọláníkẹ́. Gbèmí àti Ọmọ́tọ́lá, onímọ̀ràn ọ̀rọ̀, ki Ọláníkẹ́ láyà pé kí ó máa gbà fún ọkọ rẹ̀. Ìgbà tó yá ni Ọláníkẹ́ àti Kọ́láwọlé pínyà. Ọláníkẹ́ mú Túnráyọ̀ mọ́ra ṣùgbọn ọ̀dọ̀ Kọ́láwọlé ni Túnráyọ̀ padà gbé dàgbà, nítorí wọ́n fi i ránṣẹ́ sí Nàìjíríà sọ́dọ̀ àwọn òbí Kọ́láwọlé. Ìjá dé, orin dòwe láàrin Kọ́láwọlé àti Ọláníkẹ́.
            Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Ọlálékan tí Ọláníkẹ́ kọ́kọ́ bí fún Túndé ti dàgbà. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé àwọn ọmọ aláìníyàá tí Gbèmí àti Mọ́lọlá gbé e lọ ló gbà á tọ́. Tí wọ́n sì fún un ní orúkọ mìíràn. Túnjí lorúkọ tuntun tí wọ́n fún un. Túnjí pàdé Túnráyọ̀ nílé-ẹ̀kọ́ gíga láìmọ̀ pé ọmọ ìyá làwọn méjèèjì. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ wọn, wọ́n mú ọjọ́ ìgbéyàwó; ọjọ́ burúkú-èṣù-gbomimu ni ọjọ́ yìí. Ọjọ́ ẹ̀yẹ tí ó di ọjọ́ ìbànújẹ́ gidi ni. Ọláníkẹ́ jẹ́ kí àwọn ọmọ méjèejì mọ̀ wí pé òun lò ń bí wọn. Báyìí ni Ọláníkẹ́ ṣe ba ọjọ́ ẹ̀yẹ àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́.
Ìṣọwọ́lò-Èdè
            Èdè tó dùn ni Adéfúnkẹ́ Fámojúrọ̀ fi kọ ìwé Ibi ayé bá mi dé. Ó kọ ìwé yìí ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó de eré-oníṣe yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀yà lítíréṣọ̀ Yorùbá tó kù. Ìlò-èdè ní ìlànà oríkì ni ó jẹ́ olúborí ìlò èdè òǹkọ̀wé. Òǹkọ̀wé tún lo èdè òwe àti orin. Ète àti ìlànà ìsọ̀rọ̀dòótọ́ (anachrony) tí àwọn òǹkọ̀wé alátinúdá máa ń ṣàmúlò ni Adéfúnkẹ́ Fámujúrọ̀ náà ṣàmúlò nípa dídárúkọ àwọn ibùdó àti agbègbè inú àwùjọ bí Èkó, Ìsẹ́yìn, Kàdúná, Àbújá, Abẹ́òkúta àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Oríkì
Pg 1 -        Ọlájùmọ̀kẹ́ mi, Àríkẹ́ Adé (ọmọ òpó kọrọbítí kọrọbítí, òpó kọrọbìtì kọrọbìtì, òpómúléró mọja àlekàn, ìwàlẹ̀ òpó, ọmọ a bí rin)…
Pg 30 -      Hà, hà, hà, Ọlátúndé mi, Ẹ̀ṣọ́ Ìkòyí ọmọ agbànyùn, ọmọ aṣígun pápá mọdẹ, àrọ̀nì matẹ̀ ògùn…
Pg 74 -      Ọkọ mi, olówó orí mi, Ìrèmọ̀jé ará ìlágbẹ̀dẹ, ọmọ awórin-tún-rin-rọ
Pg 113 -    Ẹ, ẹ, ọkọ mi, Ìrèmògún ọmọ Awusẹ. Ìrèmògún ará ìlágbẹ̀dẹ, ọmọ awórin-tún-rin-rọ.
Pg 116 -    Ọmọ òpó kọrọbítí kọrọbítí, òpó kọrọbìtì kọrọbìtì. Ìwàlẹ̀ òpó, ọmọ atobi rìn

Òwe
Pg 184 -    Alágẹmọ ti bímọ, àìmọ̀ọ́jó kù sọ́wọ́ ọmọ rẹ̀
Pg 48 -      Aláboyún moṣù, kò mọjọ́

Fífi Ojú Ìmọ̀ Ṣoṣiọ́lọ́jì wo Ìwé Ibi Ayé Bá Mi Dé
            Ṣoṣiọ́lọ́jì jẹ́ ìmọ̀ tó nííṣe pẹ̀lú ìbágbépọ̀ àwọn ènìyàn àwùjọ kan. Lítíréṣọ̀ sì jẹ́ èso àwùjọ. Àwùjọ ló ń bí lítíréṣọ̀. Àwọn òǹkọ̀wé alátinúdá máa ń wo ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ pọ̀ mọ́ ìrírí wọn nínú àwùjọ láti gbé iṣẹ́ lítíréṣọ̀ kan jáde. Èyí ló fà á tí ó fi jẹ́ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ òǹkọ̀wé la máa ń bá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
            Ìwé Ibi ayé bá mi dé ṣe àfihàn díẹ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ wọ̀nyí: Ìgbé ayé Ọlájùmọ̀kẹ́ tí ó jẹ́ olúborí ẹ̀dá ìtàn ṣàfihàn ìdojúkọ àti àwọn ìpèníjà tí ọmọ òrukàn máa ń ní. Ikù àwọn òbí rẹ̀ ṣokùnfà gbígbé ọ̀dọ̀ àbúrò ìyá rẹ̀, tí àmójútó rẹ̀ sì kù díẹ̀ káàtó. Ìmọ̀ràn Gbèmí, àbúrò ìyá rẹ̀, yìí náà lò lé e kúrò nílé ọkọ rẹ̀ Kọ́láwọlé. Ìwà burúkú tí Túndé náà hù ṣàfihàn àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn àgùnbánirọ̀ máa ń hù nílùú tí wọ́n bá ti lọ sin orílẹ̀-èdè wọn. Túndé fi ipá bá Ọláníkẹ́ lájọṣepọ̀, èyí sì da ìrìnàjò ayé Ọláníkẹ́ rú. Nígbẹ̀yìn, Túndé papa ṣánkú mọ́ àwọn òbí rẹ̀ lójú nítorí èpè tí Ọláníkẹ́ gbé e ṣẹ́. Irú ìwà ìbàjẹ́ tí Túndé wù yìí wọ́pọ̀ nínú àwùjọ tí òǹkọ̀wé sì fẹ́ kí àwùjọ ṣe àtúnṣe sí.
            Òǹkọ̀wé tún lo Kẹ́mi láti ṣàfihàn bí àwọn ọ̀dọ́binrin ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ṣe yan òwò ìrégbè àti ìranù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́. Gbogbo èyí sì ni a ń rí nínú àwùjọ wa lónìí. Ìwà ìbàjẹ́ ńlá tí Gbèmí àti Ọmọ́tọ́lá, ọ̀rẹ́ rẹ̀, hù nípa gbígbé ọmọ Ọláníkẹ́ lọ sílé àwọn ọmọ aláìníyàá kò dára tó. Ọláníkẹ́ pàápàá gbà kí wọ́n gbé ọmọ bíbí inú rẹ̀ lọ sí ilé àwọn ọmọ aláìníyàá láìkú rẹ̀. Gbogbo irú àwọn ìwà ìbàjẹ́ yìí ni ó wọ́pọ̀ láwùjọ wa lónìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìròyìn ló ń gbé bí àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó gboyún ọ̀sán gangan ṣe lọ ń ju ọmọ dànù láìbìkítà ọjọ́ ọ̀la. Ọjọ́ ọ̀la tí Ọláníkẹ́ dé, àwọn ọmọ rẹ̀ méjèejì fẹ́ẹ́ ṣe ìgbéyàwó láìmọ̀ pé ọmọ ìyá kan náà làwọn méjèèjì.
            Òǹkọ̀wé ń kìlọ̀ ìwà fún gbogbo òǹkàwè. Òǹkọ̀wé sì tún ń ta àwùjọ lólobó nípa onírúurú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ tí ó ń ṣàfihàn nínú iṣẹ́ àtinúdá rẹ̀. Ẹ̀kọ́ ńlá ni òǹkọ̀wé fi ìwé Ibi ayé bá mi dé kọ́ gbogbo ẹ̀dá lákọlábo.
Reference
Famojurọ, Adefunke (2010), Ibi Ayé Bá Mi Dé. Ibadan, Nigeria: Extension Publications Limited



[1] Adesanyan Olalekan Ige ni ó kọ ìwé yìí.

No comments:

Post a Comment