Ní ayé àtijọ́, àwọn ọmọdé máa ń fi ẹyin sísè
tàbí aùsá sísè ta ayò. Ẹni kan yóò di ẹyin tàbí aùsá tirẹ mọ́ ọwọ́ ṣùgbọ́n
yóò jẹ́ kí orí rẹ̀ yọ sí ìta díẹ̀. Ẹni kejì yóò fi orí ẹyin tàbí aùsá tirẹ gbá
èyí tí èkèjì rẹ̀ dì mọ́ ọwọ́. Ọ̀kàn nínú ẹyìn tàbí aùsá yìí ni yóò fọ. Ní
ìbẹ̀rẹ̀ ayò yìí ni wọn yóò ti sọ bóyá jọjẹ ni wọ́n ń ta tàbí gbàtán. Tí ó
bá jẹ́ jọjẹ ni, àti ẹni tí ẹyin tàbí àùsá rẹ̀ bá fọ́ àti èyí tí kò fọ́ ni
wọn yóò jò pín ẹyin tàbí aùsá tí ó bá fọ́ yìí jẹ. Tí ó bá jẹ́ gbàtán, ẹni tí ó fọ́ ẹyin tàbí
aùsá ẹni kejì nìkan ni yóò dá ẹyin ẹnì kejì rẹ̀ tí ó fọ́ jẹ tàbí kí ó tà á.
Ẹyin tí ó fọ́ báyìí tàbí ẹyin tí a sè tí ó fọ́ ni a máa ń pè ní súkúńdíyán.
Owó tí wọ́n máa ń ta ẹyin tí ó fọ́ yìí, ìyẹn súkúńdíyán kìí tó owó tí wọ́n ń
ta èyí tí kò fọ́. Ọ̀pòlọpọ̀ ìgbà ni gbàtán máa ń dá ìjà sílẹ̀ nítorí pé ara
máa ń kan ẹni tí ẹyìn tàbí àùsá rẹ̀ bá fọ́ tí kò sì rí jẹ nínú rẹ̀. Jọjẹ
kìí sábàá dá ìjà sílẹ̀.
Tí a bá fi eléyìí wé òṣèlú
ilè Nàìjíríà, a ó rí i pé gbàtán ni. Eléyìí ni ó jẹ́ kí o máa ń dá ìjà sílẹ̀.
Jọjẹ ni ó yẹ kí a máa fi òṣèlú wa ṣe. A ó rí i pé nínú jọjẹ, eni tí ó
borí, yóò gba ẹyin tirẹ yóò sì tún gbà ìlàjì nínú ẹyin ẹni kèji síbẹ̀ ìjà
kò níí sí. Gbàtán nìkan ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
No comments:
Post a Comment