Saturday, 3 March 2018

Bouba àti Zaza Kojú Àìmọ̀-ọ́nkọ- mọ̀-ọ́n ka


1                    Ọdún tí a kọ ìwé náà – Wọn kò kọ ọ́[1].

2                    Orúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ tó ṣiṣẹ́ lórí ìwé náà – Ẹgbẹ́ fún ìdàgbàsókè Ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ Áfíríkà, Michel Lafon Education, Àjọ Ìgbìmọ̀ Àgbáyé fún Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì àti Ìṣẹ̀ṣe.

3                    Irú ìwé wo ni? – Ó jẹ́ ìwé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún awọn ọmọdé, tí ó ń sọ nípa ìhùwàsí àwọn ọmọdé, ó sì tún wà fún ẹ̀kọ́ fún ọjọ́ iwájú; ó sọ bí a ṣe ń kojú àìmọ̀-ọ́nkọ láti kọ ìwé tàbí ohun kan láti fi mọ̀-ọ́nkà bí a ṣe ń ka nǹkan ní Èdè Yorùbá.

4                    Ẹ̀dá inú ìwé

i.                    Bouba

ii.                 Zaza

iii.               Pọ́ọ̀lù

iv.               Fifi

v.                  Màmá Zaza

5                    Ìtàn inú ìwé náà ní ṣókí

Ìwé yìí dá lé rí ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọdé; bí àwọn ọmọdé ṣé ń hùwà tí a mọ̀ sí ìhùwàsí àwọn ọmọdé. Ó jẹ́ ìwé tó ń kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ fún ọjọ́ iwájú; ìwé yìí dá lórí ọmọ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fifi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, tí ó ń gbé ní abúlé kan. Ó wáá lo ọjọ́ díẹ̀ pẹ̀lú àwọn Zaza àti òbí rẹ̀; ó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá Zaza; ó jẹ́ àkọ́bí nínú ọmọ mèje tí bàbá rẹ̀ bí, òun ló sì ń mójútó àwọn àbúrò rẹ̀. Bouba tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Zaza bèèrè lọ́wọ́ Fifi pé báwo ni ó ṣe rí àyè lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbàtí Fífi sọ wí pé òun kò lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ mọ́. Ìyá Zaza ní kí àwọn ọmọ mú Fifi mọ ìlú ká, kí wọ́n sì ra àwọn nǹkan bọ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n dé ilé, Fifi ra ìwé kan bọ̀ lọ́jà fún àwọn ọmọ ṣùgbọ̀n wọn kò tíì lè ka ìwé náà, Fifi sì nìyí, kò mọ ìwéé kà; ó kàn gbìyànjú láti ka ohun tí ó mọ̀ sí wọn létí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gba ìwé náà láti kà fún àwọn ọmọ náà, wọ́n rí i pé nǹkan mìíràn ni Fifi kọ́kọ́ kà sí wọn létí; èyí bí àwọn ọmọ náà nínú, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé Fifi kò mọ nǹkan-án kà. Pọ́ọ̀lù sọ fún ìyá rẹ̀ pé òun fẹ́ kọ́ Fifi bí wọ́n ṣe ń ka ìwé.

            Ní ọjọ́ kejì, ìyá Zaza sọ fún Fífi kí ó nasẹ̀ lọ sí ìgboro ṣùgbọ́n kí ó má ṣe kọjá ọjọ́ kanrí kí ó tóó padà. Lẹ́yìn tí Fifi lọ tán, ó yí gbogbo ìlú ká, kò mọ ọ̀nà láti padà sí ilé mọ́; gbogbo awọn àmì àti ohun tí wọ́n kọ sí àwọn ọ̀nà kò wúlò fún un. Fifi ní ìwé àfinimọ̀nà àdírẹ́sì sí inú àpò; ó fi han àwọn ènìyàn; arábìnrin kan ló júwe ọ̀nà fún un, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó  júwe ọ̀nà fún un tán, ó bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wí pé ṣé kò mọ ìwéé kà ni, ó sì ní nǹkan burúkú ni tí kò bá mọ ìwéé kà, Fifi sì fi ìtìjú dáhùn ìbéèrè rẹ̀.

            Lẹ́yìn tí Fifi bọ́ sílẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì, ó ní òun ti san ju iye tí ó yẹ kí òun san lórí tíkẹ́ẹ̀tì bọ́ọ̀sì lọ, nítorí kò mọ̀ bí wọ́n ṣe ń kọ nǹkan tàbí kà nǹkan. Lẹ́yìn tí Fifi délé, ó bá Bouba ní orí bẹ́ẹ̀dì tí ara rẹ̀ kò yá; ìyá Zaza ti fi oògùn sí orí tábìlì àti bí ó ṣe máa lò ó, ṣùgbọ́n Fifi kò lè fún Bouba lóògùn, ó sì lọ fara pamọ́. Lẹ́yìn tí ìyá Zaza dé, Fifi bọ́ sí ìta níbi tí ó sá pamọ́ sí, ó sì bú sẹ́kún. Ó ní òun kò lè kọ̀wé tàbí kí òun kàwé, pẹ̀lú ìgbìyànjú Pọ́ọ̀lù láti kọ́ Fifi bí wọ́n ṣe ń kàwé. Èyí ló mú kì Fifi pinnu láti sọ fún àwọn òbí rẹ̀, kí ó sì mú kíláàsì ẹ̀kọ́ àgbà ní ọ̀kúnkúndùn títí di òpin ọdún. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ ni Fifi fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ náà àti fọ́tò kan wí pé òun fẹ́ẹ́ di olùkọ́ láti máa kọ́ àwọn ọmọ.

6                    Ẹ̀kọ́ inú ìwé náà – Ìwé yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ kékeré láti mọ ohun tí ó ń sẹlẹ̀ ní àyíká wọn, ó sì jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ láti gbìyànjú láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ ìwé àti bí wọ́n ṣe ń kà á, àti pé àwọn tó bá ti dàgbà si ni àǹfààní láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ àgbà.

Reference

UNESCO (n.d.), Bouba àti Zaza Kojú Àìmọ̀-ọ́nkọ-mọ̀-ọ́nka. Paris: UNESCO.



[1] Ojelabi Bukola Yetunde ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment