postage:- ‘owó-ìfìwé-ránṣe’ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
The postage for the letter was fifty naira’ (Owó-ìfìwé-ránṣẹ́ lẹ́ta náà jẹ́
àádọ́ta náírà).
postman:- ‘agbalẹ́tà’ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘I gave the postman a handshake’ (Mo bọ ọkùnrin agbalẹ́tà náà lọ́wọ́)
post office:- Ibùdó ìfìwé ránṣẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘She works at Dugbe post office’ (Ibùdó ìfìwé ránṣẹ́ Dùgbẹ̀ ni ó ti ń ṣiṣẹ́)
poster:- ìwé ipolongo (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The rerival poster is out’ (Ìwé ìpolongo ìsọjí náà ti jáde)
postpone:- yẹ̀ sẹ́yìn (di ìgbà
mìíràn) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The election date has been postponed’ (Wọ́n ti yẹ ọjọ́
ìdìbò náà sẹ́yìn di ọjọ́ mìíràn)
pot:- ìkòkò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There
are two pots here’ (Ìkòkò méjì ní ń bẹ níhìn-ín)
potter:- amọ̀kòk`o (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘My father is a potter’ (Amọ̀kòkò ni bàbá mi)
potato:- ọ̀dùnkún’ ànàmọ́, kúkúǹdùkú
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The land is fertile enough to grow potato’ (Ilẹ̀ náà lọ́ràá tó
láti gbin ọ̀dùnkún).
potion:- òògùn olómi (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The young man must have drunk a love potion’ (ọ̀dọ́mọkùnrin yóó ti mu òògùn
ìfẹ́).
poultry:- awọn adiẹ ti à ń sìn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘We keep poultry in our house’ (À ń sin adìẹ ní ilé wa).
pounce:- fò mọ́ lójijì (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He just pounced on me’ (Ó kàn fò mọ́ mi lójijì).
pound1:- pọ́n-un (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The bread costs 20 pounds’ (Ogún pọ́n-un ni búrédì náà).
pound2:-iye ìwọ̀n kan ní Britain
àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn- ó fẹ́rẹ̀ tó ìdajì kilo kan . ‘please give me a pound of gàrí’ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
(Dákun fún mi ní ìwọ̀n pọ́n-ùn gaàrí).
pound3:- gún (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He pounded the yam’ (O gún iyán). –wẹ́ ‘She is pounding beans’ (Ó ń wẹ́
erèé). – rọ́ ‘The yam is well pounded (Ó
gún iyán náà rọ́ dáradára)
pour:- rọ (ọ̀rọ̀-iṣe) ‘They poured
water into the pot’ (Wọ́n rọ omi sínú ìkòkò). –tú ‘We poured water into the
bottle (A tú omi sínú ìgò) –dà ‘He poured water outside (Ó da omi sí ìta) –dà
‘The baby poured out the food-drink (ọmọ náà dà) – rọ̀ ‘The rain poured down
hearily’ (òjò rọ̀ sílẹ̀ gan-an)
poverty:- òṣì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She
could not buy the clothes because of her poverty’ (Kò lè ra aṣọ náà nítorí òṣì
ń ta á).
powder:- ẹ̀tù. (ọ̀rọ̀-orúkọ) Ẹ̀tù
ìbọn ọ̀hún dà?’ (Where is the gun powder?) –osùn ‘Rob your face with the
powder’ (Fi osùn pa ojú rẹ).
power:- agbára (ọ̀rọ̀- orúkọ)
‘Agbára ènìyàn kọ́, agbára Ọlọ́run ni (It is not man’s power, it is God’s)
practical:- ṣíṣe (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘The teacher gave us a practical work’ (Olùkọ náà fún wa ní iṣẹ́ ṣíṣe).
practice:- ìṣe, (ọ̀rọ̀-orúkọ) ìtẹramọ́
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You need more practice before you can join our team. (O nílò
ìtẹramọ́ díẹ̀ sí i kí o tó le wọ ẹgbẹ́ wa).
practice:- ṣe, tẹramọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The more you practise, the more efficient you become (Bí o ṣe tẹramọ́ iṣẹ́
sí, bẹ́ẹ̀ ni o ó ṣe kún ojú òsù wọ̀n tó).
praise:- ìyìn, (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Give
a shout of praise to our God’ (Pa ariwo ìyìn sí Ọlọ́run wa).
praise:- yìn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We need
to praise our governor’ (Ó yẹ kí á yin gómìná wa).
prawn:- edé (ọ̀rọ̀-orúkọ) I like
prawns in vegetable soup’ (Mo fẹ́ràn edé nínú ọbẹ̀ ẹ̀fọ́).
pray:- gbàdúrà (ọ̀rọ̀-ìṣe) We need
to pray hard for Nigeria
(A níláti gbàdúrà gidigidi fún Nììjíríà.
praying mantis:- Kòkòrò tíí tún ń
jẹ kokoro mìíràn (ọ̀rọ̀-orúkọ), kòkòrò-ńlá ‘A praying mantis eats moths’
(Kòkòrò-ńlá a máa jẹ àwọn àfòpiná)
preach:- wàásù (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The
pastor preached on tithe yesterday’ (Olùṣọ́-àgùtàn wàásù lórí ìdámẹ́wàá
lánàá).
precaution:- ìkíyèsára (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘I want to advise you to take some precautions’ (Mo fẹ́ gbà ọ́ níyànju pé kí o
máa ní ìkíyèsára).
precious:- ṣe iyebíye, ní yelórí.
‘My wife is precious to me’ (Ìyàwó mi ṣe iyebíye sí mi).
predict:- sọtẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe),
gbèrò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I predict that Nigeria will win the World Cup’ (Mo
gbèrò pé Nàìjíríà yóò gba Ife-ẹyẹ Àgbáyé).
prediction:- àsọtẹ́lẹ̀, ìgbèrò (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘His prediction come to reality’ (Àsọtẹ́lẹ̀ rẹ wá sí ìmúṣẹ).
preface:- ọ̀rọ̀ ìṣaájú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Prof. Owólabí wrote the book’s preface’ (Ọ̀jọ̀gbọ́n Owólabí ni ó kọ ọ̀rọ̀ ìṣaájú
ìwé náà).
prefect:- Olórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The school prefect is always punctual’ (Olórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà máa ń
tètè dé).
prefer:- yàn, fẹ́ jù abbl (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘We prefer beans to rice’ (À fẹ́ràn ẹ̀wà ju ìrẹsì lọ)
preferable:- dára ju ‘It is
preferable to find out about him before you trust him. (Ó yẹ kí a wádìí rẹ̀ kí
á tó gbẹ́kẹ̀lé e).
prefix:- àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A prefix could be added to a verb to become a noun’ (A lè so àfọ̀mọ́ ìbẹrẹ
mọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe láti di ọ̀rọ̀-orúkọ).
pregnant:- lóyún (ọ̀rọ̀ àpèjùwe) ‘A
woman is pregnant for nine months before a child is born’ (Oṣù mẹ́sàn-an ni
obìnrin fi í lóyún kí ó tó bí ọmọ).
pregnancy:- oyún (ọ̀rọ orúkọ)
‘This is the woman’s second pregnancy’ (Oyún kejì obìnrin náà nìyí).
prejudice:- ẹ̀tanú (ọ̀rọ̀ orúkọ)
‘Prejudice scatters an organisation’ (Ẹ̀tanú ní í tú ẹgbẹ́ ká)
prepare:- múrasílẹ̀, pèsè, ṣe tán
(ọ̀rọ̀-ìṣe) múrasílẹ̀: ‘Every student should prepare for the examination’ (Gbogbo
akẹ́kọ̀ọ́ ló yẹ kí ó mú rásílẹ̀fún ìdánwò). pèsè:- Mother a prepared a
delicacy (Ìyá pèsè oúnjẹ àdídùn kan )
ṣe tán: Are you prepared for the party? (Ṣé o ti ṣe tán fún òde ọ̀hún?)
preparation:- ìmúrasílẹ̀: ‘We need
to make adequate preparation fog the conference’ (A gbọ́dọ̀ ṣẹ̀tò ìmúrasílẹ̀
tó mọ́yánlórí fún àjọ náà).
preposition:- ọ̀rọ̀ atọ́kùn (ọ̀rọ̀
orúkọ) ‘Preposition is one of the parts of speech’(Ọ̀rọ̀ atọ́kùn jẹ́ ọ̀kan
nínú àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀)
prescription:- ìwé ìlànà (ọ̀rọ̀-oríkọ)
‘The prescription of the doctor was perfect’ (Ìwé ìlànà dókítà náà ṣe déédé).
present:- ẹ̀bùn (noun) ‘He gave me a
present on my birthday celebration’ (Ó fún mi ní ẹ̀bùn kan ní ọjọ́ ayẹyẹ ọjọ́-ìbí mi).
present:- tẹ́ pẹpẹ, gbé fún,
‘Present your case before the Lord’ (Tẹ́ pẹpẹ ẹjọ́ rẹ síwájú olúwa)
present:- lọ́wọ́lọ́wọ́, nísinsìnyí
‘At present, he is working at Ifẹ̀ (Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé-Ifẹ̀)
preserve:- pa mọ́, ṣe ìtọ́jú (ọ̀rọ̀
-ìṣe) ‘Drive carefully, preserve your life!).
preserve:- ṣe ìtọ́jú ‘Add salt to
the fish to preserve it’ (Fi iyọ̀ sí ẹja yìí láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀)
preservation:- ìpamọ́, ìtọ́jú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Preservation of forests is government’s duty’ (Ojúṣe ìjọba ni ìtọ́jú
igi-igbó)
president:- ààrẹ alákòóso/olórí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Mr olówóyọ̀ is the president of our club’ (Ọ̀gbẹ́ni Olówóyọ̀ ni ààrẹ ẹgbẹ́
wa)
press:- tẹ̀ (mọ́lẹ̀) ‘Do not press
the cassava flour too much’ (Má ṣe tẹ èlùbọ́ náà mọ́lẹ̀ púpọ̀)
press:- lọ (asọ) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I
must press these shirts before my father arrives’ (Mo gbọ́dọ̀ lọ àwọn ẹ̀wù wọ̀nyí
kí bàbá mi tó dé).
press:- ilé ìtẹ̀wé (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He works at that press’ (Ilé ìtẹ̀wé yẹn ni ó ti ń ṣiṣẹ́).
presume:- Kùgbùù (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Bíọ́lá
presumed him to be a thief’ (Bíọ́lá Kùgbùù pè é ní olè)
pretend:- díbọ́n, pirọrọ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Báyọ̀ pretends to have slept’ (Báyọ̀ ń díbọ́n bí ẹni pé ó ti sùn)
pretty:- lẹ́wà, dára (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The girl is pretty’ (Ọmọbìnrin náà lẹ́wà)
prevent:- dí lọ́wọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Do
not prevent children to serve God’ (Má ṣe dí àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run)
previous:- ti ìṣaájú, ti tẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘The teacher wants to see your previous book’ (Olùkọ́ fẹ́ rí ìwé rẹ
ti tẹ́lẹ̀)
previously:- tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé)
‘We have done it preriously’ (A ti ṣe é tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀)
prey:- Ìjẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘An ant
is a prey to a hen’ (Ìjẹ ni èèra jẹ́ fún àgbébọ̀)
price:- iye (owó) (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘What is the price of a loaf of bread?’ (Èló ni iye ìgé búrédì kan ?)
prick:- ẹ̀gún (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There
is a prick on the floor’ (Ẹ̀gún ń bẹ ní ilẹ̀)
prick:- gún (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The niddle
pricked her hand’ (Abẹ́rẹ́ náà gún un lọ́wọ́)
prickle:- Èso ẹlẹ́gùn-ún (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘These prickles are fruits from that tree’ (Àwọn èso ẹlẹ́gún-ún yìí ni èso
igi yẹn)
prickly heat:- ooru gbígbóná (ọ̀rọ̀-orúkọ)
ara sísú ‘I’m feeling the prickly heat’ (Mo ní ìmọ̀lára ooru-gbígbóná náà)
pride:- ìgbéraga (ọ̀rọ̀-orúkọ
‘Pride goes before destruction’ (Ìgbéraga ní í ṣaájú ìparun)
pride:- ògo (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Ṣóyínká
is a pride of this country’ (Ògo orílẹ̀-èdè yìí ni Ṣóyínká)
priest:- àlùfáà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I
love catholic priest’s (Mo fẹ́ràn àwọn àlùfáà ìjọ àgùdà)
primary:- alàkọ̀óbẹ̀rẹ̀ (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘This is the primary school I attende’ (Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí mo
lọ nìyí)
primary:- pàtàkì, olórí (ọ̀rọ̀-orúkọ,
ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘This is a primary issue’ (Ọ̀rọ̀ pàtàkì ni èyí) (Olórí ọ̀rọ̀ ni
èyí).
prime minister:- olórí àwọn
mínísítà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Joseph was once a prime minister in Egypt ’ (Olórí àwọn mínísítà ni Jósẹ́fù ní ìgbà kan rí ní Íjíbítì).
primitive:- ti ìbẹ̀rẹ̀, ti ìgbà
àtijọ́ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The gongs were a primitive means of communication in
those days’ (Agogo jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ti àtijọ́ láyé ọjọ́-un)
prince:- ọmọ ọba (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A prince deserves the honour of a king’ (Ọ̀wọ̀ ọba yẹ ọmọ ọba)
princess:- ọmọbìnrin ọba ‘Kings
do not always give their princes to just any man to marry’ (Àwọn ọba kì í
sáábá fi ọmọbìnrin ọba fún ọkùnrin kan
lásán láti fẹ́ bí aya)
principal:- Olórí, ní pàtàkì (ọ̀rọ̀-orúkọ,
ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Wisdom is the principal thing’ (Ọgbọ́n ni ó ṣe pàtàkì jù)
principal:- ọ̀gá ilé-ìwé girama ‘Mr
Badmus is the principal of the college’ (Ọ̀gbẹ́ni Badmus ni ọ̀gá ilé-ìwé girama
náà)
principle:- òfin; ìlànà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘What are principles guiding the fhoice of a career?’ (Àwọn ìlànà wo ló rọ̀ mọ́
yíyan iṣẹ́ ǹ ṣe?)
print:- tẹ̀wé (ọ̀rọ̀ ìṣe) ‘Go and
print the question papers’ (Ẹ lọ tẹ̀wé àwọn ìbéèrè náà)
print:- ohun tí a tẹ̀ (ọ̀rọ̀ -orúkọ)
‘The book was in large print’ (Lẹ́tà gàdàgbà – gàdàgbà ni a fi tẹ ìwé náà).
prision:- ẹ̀wọ̀n, túbú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Mandela was in prison for 27 years’ (Ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni Mandela lò ní ẹ̀wọ̀n)
prisoner:- ẹlẹ́wọ̀n ‘The prisoners
deserve their rights’ (Ẹ̀tọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tọ́ sí wọn)
private:- ìkọ̀kọ̀, abẹ́lẹ̀, ìdákọ́ńkọ́
(ọ̀rọ̀ àpẹ̀júwe, ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We should have a private dialogue’ (Ó yẹ kí á
sọ̀rọ̀ abẹ́lẹ̀ kan )
‘I will collect the money in private’ (N ó gba owó náà ní ìkọ̀kọ̀)
private:- ọmọ ológun tí kò ní okùn
kankan (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He joined the army as a
private’ (Ó darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí kò ní okùn kankan ).
privilege:- àǹfààní (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Mr Adéolú has the privilege of being the chairman of the occasion’ (Ọ̀gbẹ́ni
Adéolú ni àǹfààní láti jẹ́ alága ayẹyẹ náà).
prize:- èrè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I won a
prize for the best student in English’ (Mo gba èrè fún akẹ́kọ̀ọ́ tó pegedé jù
nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì).
probable:- àfàìmọ̀ ‘It is probable
that I shall be working in Abuja next year’
(Àfàìmọ̀ kí n má máa ṣiṣẹ́ ní Abuja
ní ọdún tó ń bọ̀)
probably:- bóyá (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘The
director will probably come, so don’t go far’ (Bóyá ọ̀gá le wá o, má rìn jìnnà)
problem:- ọ̀ràn, ìṣòro (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘This is a societal problem’ (Ìṣòro àwùjọ kan lèyí)
procedure:- ìgbésẹ̀, ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘when you have been robbed, the right procedure is to go the
police’ (Nígbà tí olè bá jà ọ́, ìgbésẹ̀ tí ó tọ́ ni láti tọ àwọn ọlọ́pàá lọ)
proceed:- tẹ̀síwájú (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Let us proceed to the next step’ (Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú sí ìpele tó kàn).
process:- ọ̀nà, ìlànà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Let me see the processes involved in writing a book’ (Jẹ́ kí n rí àwọn ọ̀nà
tí ó rọ̀ mọ́ ìwé kíkọ)
procession:- ọ̀wọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘There is a procession of dancers on the road’ (Ọ̀wọ̀ àwọn oníjó ń bẹ lọ́nà)
produce:- ṣe (mú) jáde, so, bí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
produce:-mú jáde ‘Go and produce the paper you hid in the morning’ (Lọ mú ìwé
tí o fi pamọ́ láàárọ̀ jáde) produce – so ‘Every tree produces fruits after its
kind’ (Gbogbo igi ní í so èso irú ara rẹ̀) produce – bí ‘The cat produced six
kittens’ (Olóńgìnní náà bí ọmọ mẹ́fà)
producer:- olùpèsè, aṣẹ̀dá , (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The producers of that tooth paste have left Nigeria ’ (Àwọn tó ń ṣẹ̀dá ọṣẹ-ìfọyín
yẹn ti kúrò ní Nàìjíríà) production:- ìpèsè, ìṣẹ̀dá ‘The workers have stopped
the production’ (Àwọn òṣìṣẹ́ ti dáwọ́ ìṣẹ̀dá dúró)
profession:- iṣẹ́ǹṣe, iṣẹ́
‘Teaching is a noble profession’ (Iṣẹ́ olùkọ́ níyì)
profession:- ìjẹ́wọ́ ‘The boy’s
profession in the court revealed the truth’ (Ìjẹ̀wọ́ ọmọkùnrin náà nílé fi
òtítọ́ hàn).
professional:- akọ́kṣẹ́mọṣẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Give the job to the professional’s (Gbé iṣẹ́ náà fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ)
professor:- ọ̀jọ̀gbọ́n (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘We have only one professor in my family’ (Ọ̀jọ̀gbọ́ kan péré ni a ní nínú ẹbí mì)
proficient:- yíyẹ, títọ́, pípé (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘Wálé is a proficient barber’ (Onígbàjámọ̀ tó pé ni Wálé) proficient –
dáńtọ́ ‘Mrs Arówólò is proficient in all the three Nigerian language’ (Aya
Arówólò dáńtọ́ nínú gbogbo èdè Nàìjíríà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta)
profit:- èrè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We made
a profit of a hundred naira’ (A jẹ èrè ọgọ́rùn-ún kan náírà)
profitable:- pé (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ní
èrè (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Selling mangoes is profitable’ (Ó pé láti máa ta máńgòrò)
programme:- ètò (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘May
I see the programme of events?’ (Ǹjẹ́ mo le rí bí ètò yóò ṣe lọ?)
programme:- ṣètò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘That
is how I have programmed it’ (Bí mo ṣe ṣètò rẹ̀ gan-an nìyẹn)
progress:- ìtẹ̀síwájú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He has made a lot of progress in the last two month’ (Ó ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀síwájú
ní bí oṣù méjì sẹ́yìn)
progress:- tẹ̀síwájú, lọ síwájú (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘You may progress to the next class) (O lè tẹ̀síwájú sí kíláàsì tó kàn)
project:- èrò, ìgbèrò (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘She has a project to complete next year’ (Ó n ṣiṣẹ́ lórí ìgbèrò kan tí yóò parí lọ́dún
tó ń bọ̀)
project:- gbé yọ, gbé jáde ‘Please
project your work before everybody’ (Dákun gbé iṣẹ́ rẹ yọ síwájú gbogbo
ènìyàn)
projection:- àgbẹ́yọ (ọ̀rọ̀-orúkọ),
ìgbèrò ‘Our projection about the contract did not work out’ (Àgbéyọ/Ìgbèrò wa
nípa iṣẹ́ àgbàṣe náà kò ṣiṣẹ́)
prominent:- Hàndeketekete, lókìkí (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘His wife is a prominent doctor’ (Dókítà olókìkí ni ìyàwó rẹ̀) ‘The
location of the school is very prominent’ (Ibi tí ilé-ìwé náà wà hànde
ketekete)
promise:- ìlérí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We
have a promise to keep’ (A ní ìlérí kan
tí a gbọ́dọ̀ pa mọ́)
promise:- ṣe ìlérí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Did you promise them anything?’ (Ǹjẹ́ o ṣe ìlérí ohunkóhun fún wọn?)
promote:- gbé ga, gbé lékè, sún
síwájú (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The Secretary has just been promoted’ (Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé
akọ̀wé náà ga ni)
promotion:- ìgbéga, ìgbélékè (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Let us work hard because it is promotion time’ (Ẹ jẹ́ kí á múra sí iṣẹ́
nítorí àkókò ìgbéga nìyí)
prompt:- kánkán, ní déédé (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘Than you for your prompt answer to my quest (O mà ṣeun fún ìdáhùn
kánkán tí o fún ìbéèrè mi) ‘The meeting is scheduled for 2pm prompt (Déédé
agogo méjì ọ̀sán ni wọ́n fi ìpàdé ọ̀hún sí)
prong:- ẹ̀gún (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘I
dislike running on prongs’ (Mo kórìíra eré sísá lórí ẹ̀gún)
pronoun:- ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ (ọ̀rọ̀
-orúkọ) ‘A pronoun replaces a noun’ (Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ máa ń rọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ)
pronounce:- pè, sọ̀rọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Please try and pronounce the word’ (Gbìyànjú kí o pe ọ̀rọ̀ náà jáde)
pronunciation:- ìsọ̀rọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘You need to improve on your pronunciation’ (O nílò láti múra sí i lórí ìsọ̀rọ̀
rẹ)
proof:- àmì, ẹrí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I
disagree with you because you don’t have a proof’ (N kò gbà fún a nítorí o kò
ní ẹ̀rí kankan )
prop:- ìtìlẹyìn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Make a wood for the wall’s prop’ (Ṣe igi kan fún ìtìlẹyìn ògiri náà)
prop:- tì, fara hẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I
propped my bicycle against the tree’ (Mo fi kẹ̀ẹ̀kẹ́ mi ti igi náà)
propeller:- àjẹ-ọkọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A propeller makes an aeroplane move’ (Àjẹ-ọkọ̀ ní í mú ọkọ̀-òfurufú fò)
proper:- yẹ, tọ́, dára (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘It is not proper to eat on the road’ (Kò tọ́ láti máa jẹun rìn lọ́nà)
properly:- ní yíyẹ, ní títọ́,
dáradára (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘Wash that cloth properly’ (Fọ aṣọ yẹn dáradára)
prophet:- wòlíì, alásọtẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘There is a prophet in Israel ’
(Wòlí`I kan ń
bẹ ní Isreli)
prophecy:- àsọtẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He reminded me of the prophecy’ (Ó rán mi létí àsọtẹ́lẹ̀ náà)
prophesy:- sọ tẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘I will prophesy unto you and you shall live’ (N ó sọ tẹ́lẹ̀ sí ọ, ìwọ yóó
sì yè)
proportion:- ipò/iye/òsùwọn
onírúurú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The proportion of girls to boys is equal in our
school’ (Ọgbọọgba ni iye àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ní ilé-ìwé wa)
propose:- dámọ̀ràn, dábàá (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Propose a thing and the committee shall consider it’ (Iwọ́ dámọ̀ràn ohun kan , àwọn ìgbìmọ̀ yóó
sì gbé e yẹ̀wò)
proposal:- àbá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘His
proposal is widely accepted’ (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló gba àbá rẹ̀ wọlé)
prospective:- àfọkànsí lọ́jọ́ iwájú
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘My prospective customer wants us to meet today’ (Oníbàárà mi
ti mò ń fọkàn sí fẹ́ kí á pàdé lónìí)
prosper:- ṣe rere (ọ̀rọ̀-ìṣe), ṣe
àṣeyọrí, ṣe àṣeyege ‘We can prosper if we work hard’ (A lè ṣe rere bí a bá
múra síṣẹ́)
prosperity:- àṣeyege, àṣeyọrí,
àlùyọ ‘This weather can help the prosperity of the farmers’ (Ojú-ọjọ́ yìí yóò
ran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe aṣeyege)
prosperous:- ọlọ́rọ̀ (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘The prosperous man hates the poor beggar’ (Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náa
kórìíra òtòṣì oníbáárà náà)
protect:- dààbò-bò (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Mothers protect their children’ (Àwọn ìyá a máa dààbò bo àwọn ọmọ wọn)
protection:- ìdáàbò-bò (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘She has no protection from the sun’ (Kò ní ìdáàbò-bò kankan lọ́wọ́ òòrùn)
protective:- aṣààbò, alààbò (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘The warrior has lost his protective weapon’ (Jagunjagun náà ti sọ
ohun-ìjà aṣààbò rẹ̀ nù)
protein:- èròjà aṣaralóore (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Protein is found in meat, fish and milk’ (À ń rí èròjà aṣaralóore nínú ẹran,
ẹja àti wàrà).
Protest:- ta kò, kọ̀, yarí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The children protested when they were punished unfairly’ (Àwọn ọmọdé náà
yarí nígbà tí wọ́n fi ìyà jẹ wọn láìyẹ)
protest:- ìkìlọ̀, ìtakò, ìkéde (ọ̀rọ̀
-orúkọ) ‘A protest is going on against child abuse’ (Ìkéde ń lọ lọ́wọ́ láti
ta ko àṣìlò ọmọdé)
protestant:- ìjọ tó lòdì sí ìjọ
àgùdà ‘England is a
protestant country’ (Orílẹ̀-èdè England
kò fi ààyè gba ìjọ àgùdà)
protractor:- ohun-èlò ti a fi ń wọn
igun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A protractor is most useful in measuring angles’ (Ohun-èlò
ìwọngun wúlò jù bí a bá fẹ́ wọn igun)
proud:- fi ṣògo (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘He
is always proud of his daughter’ (Ó ṣáábà máa ń fi ọmọbìnrin rẹ̀ ṣògo)
prove:- fìdí múlẹ̀, (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I
was born in USA
but I have no paper to prove it’ (Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí ṣùgbọ́n n kò ní
ìwé tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀).
proverb:- òwe (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Proverbs are always pregnant of meanings’ (Àwọn òwe máa ń lóyún `itumọ̀)
provide:- pèsè (ọ̀rọ̀ -ìṣe) ‘When
shall I provide for my home?’ (Nígbà wo ni n ó pèsè fún ilé mi?)
provision:- ìpèsè (ọ̀rò-orúkọ) ‘The
provision of books for this school is small’ (Ìpèsè ìwé fún ilé-ìwé yìí kéré jọjọ)
province:- ìgbèríko (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Chine is divided into several provinces’ (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbèríko ni orílẹ̀-èdè China
pín sí)
provincial:- ti agbègbè ìlú, ti
ìgbèríko (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘The provincial government has constructed a building
in the provincial capital’ (Ìjọba ti ìgbèríko ti kọ́ ilé kan sí olú-ìlú ìgbèríko rẹ̀).
public:- ti gbogbo ènìyàn (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘This is a public park’ (Ibùdókọ̀ ti gbogbo ènìyàn nìyí)
public:- àwọn ènìyàn, (ọ̀rọ̀ -
orúkọ) gbogboogbò ‘The public should have a say in a democratic government’
(Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ lẹ́nu ọ̀rọ̀ nínú ìjọba tiwán-tiwa)
publish:- tẹ ìwé fún títà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Our English teacher has published two books’ (Olùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì wa ti kọ ìwé
méjì síta fún títà).
puff:- mí hẹlẹhẹlẹ, mí túpetúpe
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I was puffing after running so fast’ (Mò ń mú túpetúpe nígbà tí
mo sáré gan-an)
puff:- afẹ́fẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A
puff of wind blew off the papers’ (Afẹ́fẹ́ kékeré kan ló fẹ́ àwọn bébà náà dànù)
puff adder:- èjò kúkurú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The puff adder gets bigger when it is angry’ (Èjò kúkurú kan máa ń tóbi sí i bí inú rẹ̀ bá ń ru)
pull:- fà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘pull that
door to yourself’ (Fa ìlẹ̀kùn yẹn mọ́ra)
pulley:- ẹ̀rọ ìgbé-nǹkan (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A pulley is used to lift heavy things’ (A máa ń lo ẹ̀rọ ìgbé-nǹkan láti gbé
ohun tó bá wúwo).
pullover:- àwọ̀lé (ọ̀rọ̀ - orúkọ)
‘Put on your pullover because of the cold’ (Wọ àwọ̀lé rẹ nítorí otútù)
pulp:- èèpo fẹ́lẹ́fẹ́lé (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘We can eat the pulp of a mango’ (Èèpo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ara máńgòrò ni a lè jẹ)
pulpit:- àga ìwàásù (ọ̀rọ̀ - orúkọ)
‘The pastor preaches from the pulpit’ (Olùṣọ́-àgùtàn máa ń wàásù láti orí àga
ìwàásù).
pulse:- ìlùkìkì ọkàn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘His pulse runs very fast when he has malaria’ (Ìlùkìkì ọkàn rẹ̀ a máa sáré
nígbà tí àìsàn ibà bá kì í mọ́lẹ̀)
pump:- ẹ̀rọ ìfami (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The pump is faulty’ (Ẹ̀rọ ìfami náà ti bàjẹ́)
pump:- fa omi (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Pump
some water when there is power supply’ (Bí iná bá dé, ẹ fa omi díẹ̀)
pumpkin:- elégédé (ọ̀rọ̀ - orúkọ)
‘Some people do not eat pumpkin’ (Àwọn èèyàn kan kì í jẹ elégédé)
punch:- lu ihò, kàn ní ẹ̀ṣẹ́ (ọ̀rọ̀
-ìṣe) punch: lu ihò ‘Who punched this pot like this?’ (Ta ni ó lu ihò sí ara
ìkòkò yìí báyìí?)
punch: kàn ní ẹ̀ṣẹ́ ‘Bíọ́lá punched
the thief on the nose’ (Bíọ́lá kan olè náà ní ẹ̀ṣẹ́ ní imú) punch:- ẹ̀ṣẹ́, ẹ̀rọ
ìlu-ihò (ọ̀rọ̀-orúkọ) punch: ẹ̀ṣẹ́ ‘Mike Tyson won with just two punches’
(Mike Tyson jáwé olúborí pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́ méjì péré) Punch: ẹ̀rọ ìlu-ihò ‘The
punch has been carried from its place’ (Wọ́n ti gbé ẹ̀rọ ìlu-ihò kúrò ní ààyè
rẹ̀)
punctual:- ṣe ní àkókò, ṣe gẹ́gẹ́
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Let us be punctual for the meeting’ (Ẹ jẹ́ kí á dé ní àkókò
fún ìpàdé náà).
punctually:- lákòókò gan-an (ọ̀rọ̀
àpọ́nlé) ‘The car arrived punctually at 3pm’ (Ọkọ̀ náà dé ní agogo mẹ́ta
gan-an)
punctuate:- fi àmì sí ìwé kíkà (ọ̀rọ̀
- ìṣe) ‘Remember to punctuate your essay correctly’ (Rántí láti fi àmì ìwé
kíkà sí àròkọ rẹ bí ó se yẹ)
punctuation:- ìfàmìsí (ọ̀rọ̀ - orúkọ)
‘The punctuation was well done’ (Ìfàmìsí àròkọ náà mú nádóko)
puncture:- ihò kékeré (ọ̀rọ̀ - orúkọ)
‘We were late because our car’s tyre had a puncture’ (ó pé wa díẹ̀ nítorí pé
táyà mọ́tò wa lu ihò kékeré)
puncture:- lu ihò (ọ̀rọ̀ - ìṣe) ‘Do
not puncture your brother’s skin with that needle’ (Má fi abẹ́rẹ́ yẹn lu ihò
sí ara àbúrò rẹ) .
punish:- jẹ níyà (ọ̀rọ̀-ìṣe), fi
ìyà jẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The children were punished for stealing sweets’ (Wọ́n jẹ
àwọn ọmọdé náà níyà fún jíjí súùtì).
punishment:- ìjìyà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He deserved the punishemt’ (Ìjìyà náà tọ́ sí i)
pupa:- ìpele ìdàgbà dé híhu ìyẹ́ kòkòrò (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The insect has reached the pupa stage’ (Kòkòrò náà ti dàgbà dé ìpele ìhùyẹ́).
pupil:- ọmọ ilé-ìwé, akẹ́kọ̀ọ́ (ọ̀rọ̀
-orúkọ) ‘The pupils are on their way to school’ (Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń lọ sí
ilé-ìwé)
pupil:- abala dúdú nínú ojú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘In the bright light, your pupils get smaller’ (Bí iná bá mọ́lẹ̀ yòò, abala
dúdú nínú ojú rẹ yóò kéré sí i).
puppet:- ère ènìyàn tàbí ẹranko
kékeré ‘The carver just carried a puppet of our teacher’ (Agbẹ́gilére náà ṣẹ̀ṣẹ̀
gbẹ́ ère kékeré kan
tí í se ti olùkọ wa).
puppy:- ọmọ ajá (ọ̀rọ̀ - orúkọ)
‘My mummy hates puppies’ (Ìyá mi kórìíra àwọn ọmọ ajá)
pure:- mọ́, dá ṣáká, funfun ní ìwà
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Is spring water pure?’ (Ṣe omi ṣẹ́lẹ̀rù mọ́?)
pure:- funfun ní ìwà, mímọ́ ‘Let
everyone live a pure life’ (Ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù gbé ìgbé-ayé mímọ́)
purify:- wẹ̀ mọ́, sọ di mímọ́ (ọ̀rọ̀
- ìṣe) ‘We purify oil to use it in cooking’ (A máa ń sọ epo di mímọ́ láti fi
se ọbẹ̀).
purple:- àwọ̀ aládàpọ̀ pupa àti
búlùù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The hills looked purple in the distance’ (Àwọn òkè dà bí
aláwọ̀ àdàpọ̀ pupa àti búlùù lọ́ọ̀ọ́kán).
purpose:-ète, èrò, ìlèpa (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘For what purpose did you buy the box?’ (Ète wo lo ní lọ́kàn tí o fi ra àpótí
náà?)
purpose:- ìlépa ‘My purpose in life
is to be a lawyer’ (Ìlépa mi láyé ni láti di agbẹjọ́rò)
purr:- kùn bí olóńgìnní (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Bíọ́lá purrs when bí olóńgbò nígbà tí ó bá ń kó etí rẹ̀).
pursue:- lépa, sáré lé (ọ̀rọ̀ -ìṣe)
‘The policemen pursued him to the river’ (Àwọn ọlọ́pàá lépa rẹ̀ dé odò).
pus:- ọyún (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘It is
painful having a pus in a sore’ (O máa ń dùn èèyan bí ọyún bá ń bẹ nínú
egbò).
push:- tì, bì, rọ́, taari (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Push the door when you are going out’ (Ti ìlẹ̀kùn náà síwájú bí o bá ń jáde)
‘The policeman pushed the thief into their van’ (Ọlọ́pàá laari olè náà wọ inú
ọkọ̀ wọn).
put:- fi sí (ọ̀rọ̀ - ìṣe) ‘Put this
cup on the table’ (Fi ife
yìí sí orí tábìlì)
puzzle:- ìsújú, ìrújú, ìṣòro (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Adédibú’s death was a puzzle to the governor’ (Ìsújú ni ikú Adédibú jẹ́ fún
gómìnà)
puzzle:- rú lójú, sú lójú (ọ̀rọ̀ -
ìṣe) ‘The new machine puzzled me until Bayọ explained how it worked. (Ẹ̀rọ
tuntun náà rú mi lójú àfí ìgbà tí Báyọ̀ tó ṣàlàyé bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́)
pylon:- òpó iná (ọ̀rọ̀ -orúkọ)
‘Childern should avoid playing near a pylon’ (Awọn ọmọdé kò gbọ́dọ̀ máà ṣeré
lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó iná)
pyramid:- òkúta ti a mọ bìrìkìtì
onígun mẹ́rin nísàlẹ̀ ẹlẹ́nu sóńsó lókè (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘Pyramids are found
mostly in Egypt ’
(Ilẹ̀ Egypt ni a ti lè rí àwọn okúta bìrìkìtì tí a mọ ga ẹlẹ́nu sóńsó lókè
jù)
python:- òjòlá (ọ̀rọ̀ -orúkọ)
‘Evern in films, a python scares me’ (Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú fíìmù ni, òjòlá a
máa bà mí lẹ́rù)
Qq
quack:- ké bíi pẹ́pẹ́yẹ (ọ̀rọ̀ -ìṣe)
‘Stop quacking like a duck’ (Yé ké bíi pẹ́pẹ́yẹ)
quadrangle:- onígun mẹ́rin (ọ̀rọ̀
-orúkọ) ‘Our house surrounds a quadrangle with a glass in the middle’ (Ilé wa
yípo ilé onígun-mẹ́rin kan
pẹ̀lú díńgí láàrin rẹ̀)
quaint:- àjèjì (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The
boy has a quaint idea about how you should behave’ (Òye bí o ṣe le hùwà ṣàjèjì
sí ọmọkùnrin náà)
quake:- gbọ̀n, wárìrì, mì (ọ̀rọ̀ -ìṣe)
‘He was quaking with fear’ (Ó ń wárìrì fún ẹ̀rù)
qualify:- mú yẹ, pegedé ‘His
training qualifies him to work abroad’ (Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ mú un yẹ láti ṣiṣẹ́
lókè òkun).
qualification:- ìmúyẹ, ẹ̀rí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He has the qualification to chair the committee’ (Ó ní àmúyẹ láti jẹ alága
ìgbìmọ̀ náà)
quality:- ìrí, dídára-tó (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘What quality of cloth do you want?’ (Irúfẹ́ ìrí aṣọ wo ni o fẹ́?)
quantity:- ìwọ̀n, iye, títóbi (ọ̀rọ̀
- orúkọ) ‘She ate a small quantity of rice’ (Ìwọ̀n ìrẹsì díẹ̀ ni ọmọbìnrin
náà jẹ)
quarantine:- yíyàsọ́tọ̀ àwọn
aláàrùn kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn láti má ṣe àkóbá àwọn tó kù (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Máyọ̀wá ṣì wà ní àhámọ́ àwọn aláàrùn lọ́sẹ̀ yìí).
quarrel:- ìjà, asọ̀, aáwọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘There is a quarrel between the couple’ (Aáwọ̀ ń bẹ láàrin àwọn tọ́kọtaya
náà).
quarrel:- jà, sọ̀ ‘Those children
are always quarreling over little things’ (Àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn máa ń jà
lórí nǹkan kéékèèké).
quarrelsome:-oníjà (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘Yétúndé is a quarrelsome girl’ (Oníjà ni Yétúndé)
quarry:- ihò níbi ti a ti ń fọ́
òkúta (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘shall we leave for the quarry’ (Ṣe a lè máa lọ sí ibi
ihò ti a ti ń fọ́ òkúta báyìí).
quart:- ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘There are four quarts in a gallon’ (Ìlàrin mẹ́rin ló wà nínú gálọ́ọ̀nù kan ).
quarter:- ìlàrin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We
only got a quarter of the palm oil’ (Ìlàrin péré ni ó kàn wá nínú epo pupa náà)
quarter: pín sí mẹ́rin (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He quartered the organge among the rour of them’ (Ó pín ọsàn náà sí mẹ́rin
láàrin àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìn )
quarters:- ilégbèé àwọn òṣìṣẹ́ tó
wà ní agbègbè ibi-iṣẹ́ wọn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The Yorùbá teacher lives in the
school gquarter’ (Olùkọ́ Yorùbá ń gbé nú ilégbèé tí ilé-ìwé kọ́)
quartz:- Òkúta íle dídán
gbinrin-gbinrin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Gold is sometimes found in quartz’ (A máa ń rí
wúrà nínú òkúta líle tó ń dán gbinrìn-gbinrin nígbà mìíràn)
quay:- èbúté ọkọ̀ ojú-omi, ibi
ìgúnlẹ̀-sí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We will always find fishermen at the quay’ (A máa ń
rí àwọn pẹ̀japẹja ni èbúté ọkọ̀ ojú-omi ní gbogbo ìgbà)
queen:- ọbabìnrin, ayaba (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Daurama was the queen of Daura in Hausa history’ (Daurama ni ọbabìnrin Daura
nínú ìtàn orírun àwọn Hausa)
queer:- ṣòdí, yàtọ̀ ‘Everywhere is
silent something queer must have happened’ (Ibi gbogbo ló dákẹ́ rọ́rọ́ yìí. Ìṣẹ̀lẹ̀
òdì kan ti ṣẹlẹ̀)
quench:- paná, pa kú, parun (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘I need two cups of water to quench my thirst’ (Mò ń fẹ́ ife omi méjì láti paná òǹgbẹ mi).
query:- ìbéèrè, ìwádìí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘We all had a query each last month’ (Gbogbo wa ni a gba ìwé ìbéèrè lóṣù tó kọjá)
query:- bèèrè, wádìí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Your don’t quenry your boos’ (O kò gbọdọ̀ máa wádìí ọ̀gá rẹ/A kìí wádìí ọ̀gá
ẹni)
question:- ìbéèrè (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The interviewer asked me twelve questions’ (Ìbéèrè méjìlá ni àwọn afọ̀ròwánilẹ́nu-wò
bèèrè lọ́wọ́ mi)
question:- bèèrè (ọ̀rọ̀-ìṣe) (We
questioned how he got such a huge among of money). (A bèèrè bí ó ṣe ní irú owó
tùùlùtuulu yẹn lọ́wọ́)
question mark:- àmì ìbéèrè (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘You must put a question mark after a question’ (O gbọ́dọ̀ fi àmì ìbéèrè sí
gbólóhùn ìbéèrè tí o bá kọ)
queue:- ìlà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This is
a long queue, I can’t wait’ (Ìlà yìí ti gùn jù, n kò lè dúró)
queue:- tò sórí ìlà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I
will not attend to you if you do not gueue up’ (N kò ní í dá yín lóhùn bí ẹ kò
bá tò )
quick:- yára, tètè, (ọ̀rọ̀-àpèjúwe)
‘Do it quickly’ We had a quick meal today’ (A tètè jẹun lónìí)
quick:- jáfáfá (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘Maria is quick at her work’ (Maria jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀)
quicksand:- iyanrìn rírọ̀ /iyanrìn
dídẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Quicksand is very dangerous. Someone can be pulled into
it’ (Iyanrìn rírọ̀ léwu. Ènìyàn le rì sínú rẹ̀ )
quiet:- dákẹ́, pẹ̀lẹ́, dákẹ́ (ọ̀rọ̀-àpèjúwe)
‘Báyọ̀ńlé has a quiet voice’ (Báyọ̀nlé ní ohùn pẹ̀lẹ́)
quill:- ìyẹ́ apá ẹyẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Some 200 years ago, most pens were made from quills’ (Ní nǹkan bí ìgba ọdún
sẹ́yìn, ìyẹ́ apá ẹyẹ ni a fi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ kálàmù)
quilt:- aṣọ ìborí àketè (ọ̀rọ̀
orúkọ) ‘I need a quilt to spread on my bde’ (Mo nílò aṣọ ìborí àketè kan láti tẹ́ sórí ìbùsùn
mi)
quinine:- egbòogi ibà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A quinine is good as an anti-malaria dring’ (Egbòogi-ibà dára láti gbógun ti
ààrùn ibà)
quilt:- fi sílẹ̀, kọ̀ sílẹ̀, lọ
kúrò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He quit school at the age of ten and started working on his
father’s farm’ (ó fi ilé-ìwé sílẹ̀ ní ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́
nínú oko bàbá rè
quite:- pátápátá (ọ̀ọ̀ àpọ́nlé) ‘I
quite agree with you’ (Mo gbà fún ọ pátápátá)
quiver:- àpò ọ fà (ọ̀rọ̀ orúkọ)
‘Every hunter should have a quiver each (Ó yẹ kí gbogbo ọdẹ ní àpò ọfà kọ̀ọ̀kan)
quiz:- eré ọpọlọ níbi ti a ti ń
dáhùn ìbéèrè láti borí ẹnìkejì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We came first at the quiz
competition’ (A ṣe ipò-kìíní níbi ìdíje eré ọpọlọ)
quote:- tún ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn wí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘I want to quote pastor Adébóyè sọ )
quote:- sọ iye owó ọjà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Has the manager quoted the price of the consignments?’ (Ǹjẹ́ ọ̀gá-àgbà ti sọ
iye owó tí àwọn ọjà náà jẹ́?’)
Rr
rabbit:- ehoro onírun (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Rabbits live in holes under the ground’ (Àwọn ehoro onírun máa ń gbé nínú
ihò lábẹ́ ilẹ̀)
rabies:- àìsàn ti ń ṣe ènìyàn ti
ajá bù jẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rabies is a serious illness, so beware of dogs’
(Àìsàn búburú ní í ṣe ẹni tí ajá bá bù jẹ̀, nítorí náà ẹ ṣọra fún àwọn
ajá)
race:- ìran. Irú, ìdílé, eré ìje (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘I belong to the African race’ (Ìran Afíríkà ni mí)
race: eré ìje ‘Ṣadé came last in
the 100m race’ (Ṣadé ló ru póò nínú eré ìje ọlọ́gọ́rùn-ún mẹ́tà)
race:- sáré ‘Bọ̀dé raced against
Báyọ̀ in the race’(Bọ̀dé bá Báyọ̀ sáré nínú eré-ìje náà).
rack:- orí ìkọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘His
mother stores fried meat in a rack’ (Ìyá rẹ̀ máa ń fi ẹran dídín pamọ́ sí orí
ìkọ́)
racket:- ọ̀pá tí a fi ń gbá bọ́ọ̀lù
lórí pápá (Ọ̀rọ̀-orúkọ), rákẹ́ẹ̀tì ‘I can’t give out my racket, go and buy
your’s (N kò lè fi ọ̀pá ìgbábọ́ọ̀lù tèmi sílẹ̀, lọ ra tìrẹ)
radar:- ohùn-èlò tí a fi ń mọ ibi
ti bàálù ń fò lọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Radar makes use of radio waves’ (Ohun-èlò ti
a fi ń mọ ibi tí bàálù ń fò lọ ń ṣe àmúlò ìgbì rédíò)
radiate:- tàn, ràn bí òòrùn (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘She radiates joy on her face’ (Ayọ̀ ń tàn ní ojú rẹ̀)
radio:- rédíò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A
Hausa man may lack everything, but not a radio’ (Gbogbo nǹkan ni Hausa le má
ní, bíi ti rédíò kọ́).
radius:- ìlà tí a fà láti àárin
òbìrìkítí lọ kan igun kan (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Have you drawn a circle?
Then draw a radius’ (Ṣé o ti ya obìrìkítí kan ? Lẹ́yìn náà fa ìlà kan
láti ààrin rẹ̀ lọ kan igun kan )
raffia palm:- imọ̀ ọ̀pẹ raffia (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘They used raffia palms to make baskets in those days’ (Láyé ọjọ́-un wọ́n máa ń
lo imọ̀ ọ̀pẹ raffia láti fi ṣe apẹ̀rẹ̀).
raft:- àdìlù igi tí ó léfòó lójú omi
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Can you see a raft on the river?’ (Ǹjẹ́ o rí àdìlù igi kan lójú odò)
rafter:- ẹkẹ́ ilé, ìtì igi ilé (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The building’s rafters are getting weak (Ẹkẹ́ ilé náà kò lágbára mọ́)
rag:- àkísà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She
cleaned the floor with a rag’ (Àkísà ni ó fi fọ ilẹ̀ náà)
rage:- ìbínú, ìrunú (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘My mother was in a rage when I came home last nigh’ (`Ibínú ru lójú ìyá mi
nígbà tí mo dé lálẹ́ àná).
Rage:- bínú fùfù, bínú gan-an (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He rages when he is hungry’ (Ó máa ń bínú fùfù bí ebi bá ń pa á).
Raid:- ìgbógunti, sùnmọ̀mí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The soldiers made a raid into that country’ (Àwọn ọmọ ogun gbé sùnmọ̀mí wọ
orílẹ̀-ẹ̀dè yẹn).
raid:- gbógunti, rọ́ lù, gbógun sí
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The soldiers are ready to raid the city’ (Àwọn ọmọ ogun ti
gbaradì láti gbógun ti ìlú náà).
rail:- Ọgbà irin tí ọkọ̀ ilẹ̀ ń
rìn (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘Trains move on two rails’ (Àwọn ọkọ̀ ilẹ̀ máa ń rìn
lórí ọgbà irín méjì)
railway:- ojú-ọ̀nà ọkọ̀ ilẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Do not play on the railways. It is dangerous’ (Má ṣeré lójú ọ̀nà ọkọ̀ ilẹ̀.
Ó léwu)
rain:- rọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘It rains
everyday in July’ (Òjò ń rọ̀ ní ojoojúmọ́ nínú oṣù Agẹmọ)
rain:- òjò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Children
should not be allowed to play in the rain’ (A kò gbọdọ̀ gba àwọn ọmọdé
láàyè láti ṣeré nínú òjò).
raise:- gbé sókè, gbé lékè, gbé dúró
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘When I say ‘stop’, you raise your pen’ (Bí mo bá ti sọ pé kí ẹ
dúró, ẹ ó na kálàmù yín sókè).
raise:- mú jáde fún èrò (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Mr Ọláolú raised a point for discussion’ (Ọ̀gbẹ́ni Ọláolú mú ọ̀rọ̀ kan jáde fún ìjíròrò)
raisin:- èso àjàrà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The raisin is sweet. I enjoyed it’ (Èso àjàrà náà dùn. Mo gbádùn rẹ̀)
rake:- ohun-èlò tí a fi ń kó nǹkan
jọ, irin ìhọlẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You will need a rake on the farm today’ (Ẹ ó
nílò irin ìhọlẹ̀ nínú oko lónìí)
rake:- kó jọ̀, họlẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He raked the stones up and put them in a heap’ (Ó kó òkúta jọ ó sì fi wọn
sórí ebè)
ram:- àgbò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Faithful
muslims slaughter rams on Ramadan festival’ (Àwọn mùsùlùmí òdodo ló máa ń pa
àgbò lọ́jọ́ ọdún Iléyá).
ramadan:- oṣù ààwẹ̀ mùsùlùmí (ọ̀rọ̀
orúkọ) ‘Ramadan fast is always 29 days or 30 days’ (Oṣù ààwẹ̀ mùsùlùmú máa ń
ṣáábà jẹ́ ọjọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀njọ́).
ramp:- gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí a kọ́ forí sọ
ibi àmúgùn kan (ọ̀rọ̀-orúkọ ‘Walk carefully
because of the ramp down there’ (Rọra rìn o nítorí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó forí sọ
igun òkè kan
nisàlẹ̀ níbẹ̀ yẹn)
rampant:- wọ́pọ̀ gan-an ‘Malaria was
rampant in the villages last year’ (Ààrùn ibà wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn abúlé lọ́dún
tó kọjá).
ran:- sáré (ọ̀rọ̀-ìṣe- ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún
ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn) ‘The children ran to meet their mother’ (Àwọn ọmọ sáré lọ
pàdé ìyá wọn)
ranch:- oko màálù ńlá (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘My father has a ranch at Ìbàdàn’ (Bàbá mi ní oko màálù ńlá kan ní Ìbàdàn)
random:- láìròtẹ́lẹ̀, láìmọ̀-ọ́n-mọ̀-ṣe,
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The soldier fired the enemies at random’ (Ọmọ-ogun náà yin
àwọn ọ̀tá níbọn láìròtẹ́lẹ̀,
rang:- lu agogo (ọ̀rọ̀-ìṣe-ìṣẹ̀lẹ̀
tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn)
range:- àlààfo láàrin nǹkan méjì (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The range between our school and there is about 20meters’ (Àlààfo tí ó wà
láàrin ilé-ìwé wa àti tiwọn tó bíi ogún mítà)
range:- (àkójọpọ̀) àwọn òkè (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A range of hills is between us and the sea’ (Àwọn òkè kan ló la àwa àti òkun láàrin).
ranger:- aṣọ́gbó (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘His brother is a professional ranger’ (Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ aṣọ́gbó ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀)
rank:- ẹgbẹ́; ọgbà, ipò, oyè (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A general is an army officer with a high rank’ (Ipò gíga ni ipò ọ̀gágun àgbà
láàrin àwọn ọmọ ogun)
rank:- tò lẹ́sẹẹsẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The teacher ranked the students work’ (Olùkọ́ to iṣẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́sẹẹsẹ)
ransack:- wá kiri, tú yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The robbers ransacked the whole building’ (Àwọn adigunjalè náà
tú gbogbo ilé náà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́)
ransack:- wá kiri ‘They ransacked
the kitchen for a large bowl’ (Wọ́n wá abọ́ ńlá kiri ilé-ìdáná).
ransom:- ìràpadà, owó ìdásílẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Who will be the ransom to salvage this country?’ (Ta ni yóò ha ṣe ìràpadà
láti kó orílè-èdè yìí yọ?).
ransom:- owó ìdásílẹ̀:- ‘The rich man paid a ransom of N1 million to
get his son back from the kidnappers’ (Ọkùnrin olówó náà san owó ìdáílẹ̀ mílíọ̀nù
kan náírà li
gba ọmọkùnrin rẹ̀ padà lọ́wọ́ àwọn gbọ́mọ-gbọ́mọ)
rapid:- yára, kánkán (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘The most rapid way of getting to the city is by bus’ (Ọ̀nà tó yára jù láti wọ
ààrin ìlú ni nípasẹ̀ ọkọ̀ bọ̀gìnnì).
rapidly:- ní kánkán/kánmọ́kánmọ́ (ọ̀rọ̀
àpọ́nlé) ‘He talked so rapidly that I could not understand him’ (Ó sọ̀rọ̀ kánmọkánmọ́
dé ibi pé ohun tó sọ kò tilẹ̀ yé mi)
rare:-kò wọ́pọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘That red bird is very rare in this country’ (Irú ẹyẹ pupa yẹn kò wọ́pọ̀ ní
orílẹ̀-èdè yìí).
rascal:- ọmọ ìta/ìpátá/èèyàn lásán
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘It is only a rascal that sleeps in a garage’ (Ọmọ ìta náà ní
í sun ibùdókọ̀)
rash:- láìfarabalẹ̀/oníwàdùwàdù/oníwàra
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe). ‘It was rash of him to let his son of twelve years drive his
car’ (Ó ti ṣe wàdùwàdù jù fún un láti jẹ́ ké ọmọkùnrin ọfún méjìlá rẹ̀ máa
wa mọ́tò rẹ̀).
rash:- ara sísú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘With
some illnesses, you get a rash on the face’ (Bí àwọn àìsàn kan bá ṣe èèyàn, ara sísú le gba ojú èèyàn)
rat:- èkúté/ọ̀fọ́n-ọ̀n ‘If care is
not taken, rats could eat up a bag of rice!? (Bí èèyàn kò bá kíyèsára, ọ̀fọ́n-ọ̀n
le jẹ àpò ìrẹsì kan
tán!’
rat:- alárìnká (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Bisi
is a rat. She likes visiting places’ (Alárìnká ni Bísí. Ó fẹ́ràn àbẹ̀wò
káàkiri).
rate:- iye lòsùwọ̀n ‘At what rate do
they sell their eggs?’ (Kín ni iye owó ti wọ́n fi ń ta ẹyin wọn?)
rate:- bí nǹkan ṣe ń lọ sí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘She learns at a quick rate’ (Ó ń tètè mọ nǹkan)
rather:- kúkú/ṣá ‘This shirt is
rather tight’ (Èwù yìí fún mi ṣá) ‘He rather wrote the letter’ (Ó kúkú kọ lẹ́tà
náà) ‘I ‘m still rather hungry-may I have some more to eat?’ (Ebi kúkú tún ń
pa mi – ṣe mo le rí díẹ̀ jẹ sí i?)
ration:- òdiwọ̀ nǹkan kan sí òmíràn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘There is a high ration of teachers to pupils in their school’ (Àwọn olùkọ́ pọ̀
ju àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ ní ilé-ìwé wọn)
ration:- ìwọ̀n ohun ti a le gbà tàbí
fún ènìyàn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Each child has a ration of one egg a day’ (Ẹyin kan ni ọmọ kọ̀ọ̀kan le gbà ní ọjọ́ kan )
ration:- dín ohun tí a lè gbà tàbí
fún ni kù (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We were rationed to a plate of rice each a week’ (Wọ́n
dín óunjẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan kù sí abọ́ ìrẹsì kan lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan)
rattle:- mì pẹ̀lú ariwo (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘She rattled some coins in the box’ (Ó mi owó woroworo pẹ̀lú ariwo nínú àpótí).
rattle:- ohun ìṣeré ọmọdé aláriwo
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Give the rattle to the crying baby’ (Fún ọmọ tó ń sunkún ní
ohun ìṣeré ọmọdé náà)
rave:- sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The angry woman raved at her children’ (Obìnrin náà sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè
tìbínú-tìbínú sí àwọn ọmọ rẹ̀).
raven:- ẹyẹ ìwò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We
have ravens in Africa ’ (Ẹyẹ ìwò ń bẹ ní
Aáfíríkà)
ravine:- àlàfo jíjìn díẹ̀ láàrin ilẹ̀
gíga àti òkè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I love the sight of a ravine’ (Ó wù mí láti máa wo
àlàfo jíjìn láàrin òkè àti ilẹ̀ gíga)
raw:- tutu/àìsè (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘Animals eat raw meat’ (Àwọn ẹranko máa ń jẹ ẹran tutu)
ray:- ìtànsán/ìmọ́lẹ̀ ‘The ray of
the sun brought light into the room’ (Ìtànsán òòrùn ló mú òye wọ inú yàrá)
razor:- abẹ ìfárí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘It is good to use razor to clear your beard’ (Ó dára kí a o lo abẹ ìfárí láti fú irungbọ̀n rẹ).
reach:- dé/bá/fi kàn (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Stop reading when you reach page 26’ (Dáwọ́ kíkà dúró bí o bá ti dé ojú-ìwé kẹrìndínlọ́gbọ̀n).
reach:- àrọ́wọ́tó (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The orange is just out of my reach’ (Ọsàn náà kò sí ní àrọ́wọ́tó mi)
react:- hùwà sí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ìṣẹ̀lẹ̀
kan . ‘The
villagers reacted angrily to the news’ (Àwọn ará abúlé ba ara jẹ́ sí ìròyìn
náà)
reaction:- ìhùwàsí/ìṣesé (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘What was your mother’s reaction when you informed her of your promoting?’(Kín
ni ìhùwàsí iye rẹ nígbà tí o sọ fún un nípa ìgbéga rẹ?).
read:- kàwé/kà (ọrọ̀-ìṣe) ‘He read
the story to his son’ (O ka ìtàn náà fún ọmọ rẹ̀)
ready:- múra/ṣe tán/yá (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘I am not ready to go out yet’ (N kò tíì ṣe tán láti jáde)
readily:- lọ́wọ́lọ́wọ́/lọ́gán (ọ̀rọ̀
àpọ́nlé) ‘All ingredients are readily available (Gbogbo èròjà ló ti wà nílẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́)
real:- tòótọ́/dájú/lódodo/ojúlówó (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘This is a real watch’ (Ojúlówó agogo nìyí o).
reality:- òtítọ́, òdodo (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘In reality, only six people attended the party’ (Ní òdodo, ènìyàn mẹ́fà péré
ní wọ́n wá sí ibi àpèjẹ náà).
realize:- mọ̀ (pẹ́)/mọ̀ ní ọ̀ràn (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘When I head the noise on the roof, I realized that it was raining’ (Nígbà ti
mo gbọ́ ariwo lórí òrùlé, mo wá mọ̀ pé òjò ló ń rọ̀)
realize:- fi pa (bí owó) (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘How much did we realize from the business?’ (Èló ni a pá níbi òwò náà?’)
reap:- kórè/ká (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Whatsoever you sow, that you will reap’ (Ohun tí o bá gbìn in ìwọ yóò ká)
rear:- ẹ̀yìn (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘He
enjoys sitting at the rear seats’ (Ó kúndùn kí ó máa jókòó sí àwọn àga ẹ̀yìn)
rear:- sìn (ẹranko) (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘That farmer rears sheep’ (Àgbẹ̀ yẹn ń sin àgùtàn)
rearrange:- tún tò lẹ́sẹẹsẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Please try and rearrange the chairs’ (Dákun gbìyànjú kí o tun àwọn àga náà tò
lẹ́sẹẹsẹ)
reason:- ìdí/èrèdí/ìtorí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The reason she was ill was that she had eaten bad fish’ (Ìdí ti ara rẹ̀ kò fi
yá ni nítorí ẹja ti ó ti bàjẹ́ tí ó jẹ)
reason:- sọ àsọyé fún (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Come and let’s reason together’ (Ẹ wa kí á jọ sọ àsọyẹ́ pọ̀)
reassure:- tún mú dá lójú (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He reassured his parents that he would not stay out late’ (ó tún mú un dá àwọn
òbí rẹ̀ lójú pé òun kò ní í pẹ́ lóde)
rebel:- ọlọ̀tẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The
rebel leader has run away’ (Adarí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ti sá lọ)
rebel:- ṣọ̀tẹ̀ sí (ọ̀rọ̀-ìṣe).
‘The labour union rebelled against the Federal Government’ (Àjọ àwọn òṣìṣẹ́
ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Àpapọ̀)
rebuild:- tún kọ́/tún mọ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘It is the government’s duty to rebuild dilapidated schools’ (Ojúṣe ìjọba ni
láti tún àwọn ilé-ìwé tó ti di àlàpà kọ́).
rebuke:- bá wí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Rebuke
your child when he does wrong’ (Bá ọmọ rẹ wí bí ó bá ṣe ohun tí kò dára).
rebuke:- ìbáwí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The
student got a rebuke from the principle’ (Akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìbáwí láti ọwọ́ ọ̀gá
ilé-ìwé)
receive:- gbà/rí gbà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Did you receive any letters today?’ (Ǹjẹ́ o rí àwọn lẹ́tà kankan gbà lónìí?)
receipt:- ìwé ìjẹ́rìí gbígba nǹkan
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I collected a receipt for the payment I made’ (Mo gba ìwé ìjẹ́rìí
pé mo san owó fún owó ti mo san).
reception:- ìpàdé àgbájọ láti gba
ènìyàn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The reception follows immediately after the service’
(Igbàlejò yóò wáyé ní kété tí ìsìn bá ti parí).
recent:- àìpẹ́ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe),
ìsinsìnyí (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Recent events show that the world is coming to an
end’ (Ìṣẹ̀lẹ̀ ìsinsìnyí fihàn pé ayé ń lọ sópin)
recently:- ní kòpẹ́kòpẹ́/ní
ìsinsìnyí/ní àìpẹ́ (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘I have been to Ghana
recently’ (Ní kòpẹ́kòpẹ́ yìí ni mo lọ sí Ghana )
receptacle:- ohun tó le gba nǹkàn
sínú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A cup is a receptacle for water’ (Ife lè gba omi sínú rẹ̀)
recipe:- àpèjúwe (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The
recipe says we should allow the water to boil for 5 minutes’ (Àpèjúwe sọ pé kí
á kí á se omi náà lórí iná fún ìṣẹ́jú márùn-ún).
recite:- ka àkọ́sórí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Come and recite the poem for us’ (Wá ka àkọ́sórí ewì náà fún wa)
reckless:- láìbìkítà/àìwòye,
àìlánìíyàn (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘He showed a reckless disregard for his own safety’
(Ó fi ìwà àìbìkítà rẹ̀ hàn sí ààbò ara rẹ̀)
recklessly:- ní àìbìkítà/pẹ̀lú
àìwòye (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘He admitted driving recklessly’ (Ó gbà pé òun wa ọkọ̀
pẹ̀lú àìwòye)
reckon:- ṣírò/kà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She
reckoned up the money we owed her’ (Ó ṣírò owó ti a jẹ ẹ́)
reckoning:- ìṣírò/ìkaye (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘By my reckoning, he is about 37 years old’ (Pẹ̀lú ìṣírò mi, yóò tit ó bí ọmọ
ọdún mẹ́tàdínlógójì).
recognize:- mọ̀/jẹ́wó, rántí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘I recognized olú although I hadn’t seen him for 10years. (Mo dá olú mọ̀ bí ó
tilẹ̀ jẹ́ pé n kò tí ì rí i fún bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn) jẹ́wọ́ - ‘Everyone
recognizes that Wálé is the most brilliant student in the class’ (Gbogbo ènìyàn
ló jẹ́wọ́ pé Wálé ni ó mọ ìwé jù nínú kíláàsì náà) rántí:- ‘He just recognized
that he had left the money at home’ (Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rántí pé òun ti gbàgbé owó
sílé)
recognition:- ìdánimọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He should no sign of recognition when he was me’ (Kò fi àmì ìránti kankan hàn nígbà tí ó rí
mi)
recommend:- yìn/sọ̀rọ̀ ẹnìkan ní rẹrẹ
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He was recommend for the job’ (Wọ́n ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere láti
gba iṣẹ́ náà)
recommendation:- ìyìn/ìsọ̀rọ̀ ẹni
ní rere (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I wrote a letter of recommendation about him to my
boss’ (Mo kọ̀wé ìyìn rẹ̀ fún ọ̀gá mi)
reconcile:- ṣe ìlàjà/bá làjà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He has recently been reconciled’ (Àìpẹ́ yìí ni ó bá ìyàwó rẹ̀ làjà)
reconciliation:- ìlàjà/ìbálàjà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘There was a reconciliation between the brothers after their quarrel’ (Àwọn
arákùnrin náà ti ṣe ìlàja láàrin ara wọn lẹ́yìn ìjà wọn).
record:- kọ sínú ìwé ìrántí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘You should keep a record of your expenses’ (Ó yẹ kí o kọ bí o ṣe náwó sílẹ̀
fún ìrántí).
record:- gba ohun sílẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The pastor’s message was recorded’ (Wọ́n gba ohùn ìwàásù olùṣọ́-àgùtàn náà
sílẹ̀)
record:- àkọsílẹ̀/ìwé ìránti (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The doctor keeps a records of all illnesses treated’ (Dókítà náà ní ìwé àkọsílẹ̀
fún gbogbo àìsàn ti wọ́n wò)
recover:- gbà padà/tún rí gbà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The police helped me recover all the items from the thieves’ (Àwọn ọlọ́pàá
bá mi gba gbogbo ẹrù mi padà lọ́wọ́ àwọn olè)
recover:- sàn nínú ààrùn tàbí àìsàn
(ọ̀rọ̀-ìse) ‘He is still recovering from the operation pains’ (Ó ṣì ń sàn
nínú ìrora iṣẹ́-abẹ náà ni)
recreation:- ìdárayé lẹ́yìn iṣẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘His recreations include football and swimming’ (Àwọn eré ìdárayá rẹ̀ lẹ́yìn
iṣẹ́ ni bọ́ọ̀lù-gbígbá àti ìwẹ̀-wíwẹ̀).
recruit:- àṣẹ̀ṣẹ̀kọ́ṣẹ́/àṣẹ̀ṣẹ̀gbaṣẹ́
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The new army recruits wer learning about guns’ (Àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀gbaṣẹ́
ọmọ ológun ń kọ́ nípa bí a ṣe ń yin ìbọn)
recruit:- gbà sínú ẹgbẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Two policemen were recruited from our village’ (Àwọn méjì ni wọ́n gbà sínú iṣẹ́
ọlọ́pàá nínú abúlé wa)
rectangle:- nǹkan pẹrẹsẹ tó ní
ìhà mẹ́rin àti igun mẹ́rin ọgbọọgba (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Most books are
rectangles’ (ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ló ní ìhà mẹ́rin àti igun mẹ́rin ọgbọọgba)
red:- pupa (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘He likes
red shirts’ (Ó fẹ́ràn èwù pupa)
red:- pọ́n (ọ̀rọ̀ apèjúwe) ‘Her eyes
were red from crying’ (Ojú rẹ̀ pọ́n fún ẹkún)
reduce:- dín kù/bù kù (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The number of employes was reduced from 40 to 25’ (Wọ́n dín iye àwọn òṣìṣẹ́
kù láti ogójì sí márùn-úndínlọ́gbọ̀n)
reed:- ìye/ọ̀pá ìye/ìfefe (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The edge of the stream is full of reeds’ (Ìye kún ẹ̀gbẹ́ odò náà)
reef:- òkúta nísàlẹ̀ òkun (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘I have never seen a reef’ (N kò rí òkúta ìsàlẹ̀ òkun rí)
reef knot:- kókó kan tí a fi ń so okùn méjì pọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘You will need a knot to tie up the money’ (O ó nílò láti so owó náà mọ́kókó
léèmejì dan-in-dan-in)
reel:- igi ti a ká òwú wé/kẹ̀kẹ́ òwú
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Go and bring the reel of woo’ (Lọ mu kẹ̀kẹ́ òwú náà wá)
refer:- tọ́ka sí, fi lọ̀, mẹ́nu kàn
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Refer his case to another doctor’ (fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ dókítà
mìíràn) tọ́ka sí – I’m referring to the lecture we received last week’ (Mò ń
tóka sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti a gbà lọ́sẹ̀ tó kọjá) mẹ́nu kàn – ‘Her mother never
referred to her again’ (Ìyá rẹ̀ kò tilẹ̀ mẹ́nu kan ọrọ rẹ̀ mọ́)
referee:- alákòóso/onídàájọ́ eré
ìdárayá kan
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The referce was partial’ (Alákòóso eré náà ṣe òjóró)
refine:- ṣẹ́/jọ̀/yọ èèrí kúrò (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Sugar is refined before we eat it’ (A máa ń ṣẹ́ ṣúgà kí á to le jẹ ẹ́)
refinery:- ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣẹ́
tàbí jọ nǹkan (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘My father works in an oil refinery’ (Bàbá mi ń ṣiṣẹ́
ní ilé-iṣẹ́ ìfọpo’
reflect:- tan ìmọ̀lẹ̀ sí, ronú jinlẹ̀
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ṣàfihàn ‘A mirror reflects a picture of you when you look at it’
(Dííígí yóò ṣe àfihàn rẹ bí o bá wò ó) tan ìmọ́lẹ̀ sí – ‘The sunlight
reflects in the room’(Òòrun ń tan ìmọ́lẹ̀ sí inú yàrá) ronú jinlẹ̀ - ‘He
reflected before answering my question’ (Ó ronú jinlẹ̀ kí ó tó dáhùn ìbéèrè mi)
reform:- tún ṣe/sọ di ẹni rere (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘She is very rude. She needs to reform her behaviour’ (Ó bàjẹ́ gan-an. Ó yẹ kí
ó tún ìwà rẹ̀ ṣe).
refrain:- fà sẹ́yìn/dá ara dúró (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He refrained from being rude to me’ (Ó fàsẹ́yìn kúrò nídìí bíbàjẹ́ (àìbọ̀wọ̀
fún sí mí).
refresh:- tù lára ‘A cool drink
refreshed me after working all day’ (Ohun mímu tutu tù mú lára lẹ́yìn tí mo ti
ṣiṣẹ́ látàárọ̀)
refreshement:- ohun jíjẹ àti mímu
(ọ̀rọ̀-orúkọ ‘We bought refreshment at the bus stop’ (A ra ohun jíjẹ àti mímu
ní ibùdókò).
refrigerate:- sọ di tutu láìbàjẹ́
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The meat is refrigerated so that it will stay fresh until it is
sold’ (Wọ́n sọ ẹran náà di tutu kí ó má baà bàjẹ́ títí wọ́n yóò fi tà á)
refrigerator:- ẹ̀rọ amú-nǹkan-tutù
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We have a refrigerator in our kitchers’ (A ní ẹ̀rọ amú-nǹkan-tutù
ní ilé ìdáná wa)
refuge:- ààbò/ibi ìsádi/ibi ìsásí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘God is our refuge’ (Ọlọ́run ni ààbò wa)
refugee:- ẹni tí ó sá lọ sí ilẹ̀
mìíràn fún ààbò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Why become a refugee in another country?’ (Kín
ló dé tí o di ẹni tó ń sá lọ orílẹ̀-èdè mìíràn fún ààbò?)
refuse:- kọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘my mother
refused to let me go out’ (Ìyá mi kọ̀ láti jẹ́ kí n jáde)
refuse:- ohun ẹ̀gbin/èérí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Please pack the refuse away from here’ (Jọ̀wọ́ kó ohun ẹ̀gbin yìí kúrò níbí).
refusal:- kíkọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘My
refusal to let my daughter go out makes her angry’ (Kíkọ̀ ti mo kọ̀ láti jẹ́ kí
ọmọbìnrin mi jáde ń bí i nínú)
regain:- rí gbà padà/jèrè padà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Abíọ́dún has regained his first postion in the class’ (Abíọ́dún tí rí ipò
kìíní rẹ̀ gbà padà nínú kíláàsì).
regal:- ti ọba/bí ọba (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘The prince was dressed in his regal attires’ (Wọ́n wọ aṣọ bíi ti ọba
fún ọmọ ọba/Ọmọ ọba wọ aṣọ rẹ̀ ti ó dàbí ti Ọba)
rgard:- kíyèsí/bu ìyìn fún/kà sí/fi
pè (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We regard him as our cleverest student’ (A kà á sí gẹ́gẹ́ bí
akẹ́kọ̀ọ́ wa tí ó jáfáfá jù lọ)
regard:- ìbọ̀wọ̀fún/ìbuyìnfún/àkíyèsí
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Báyọ̀ has no regard for anybody’ (Báyọ̀ kò ní àkíyèsí fún ẹnikẹ́ni)
regarding:- nípa ti (ọ̀rọ̀ atọ́kùn)
‘A letter was received regarding his appointment’ (A gba lẹ́tà kan nípa ti àtiríṣẹ́ rẹ̀)
regardless:-
láìfipè/láìfiyèsí/láàbuyìnfún/láikàsí (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘Táyọ̀ says what he
thinks regardless of other people’s feelings’ (Táyọ̀ kàn máa ń sọ ohun tó bá
rò ni láìfiyèsí bí ó ṣẹ rí lára àwọn yòókù)
regime:- àkókò ìjọba/ìgbà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘We hope that things will change under the new regime’ (A ní ìrèti pé nǹkan
yóò yí-padà lábẹ́ àkókò ìjọba tuntun yìí).
regiment:- ẹgbẹ́ ogun kan (ọ̀rọ̀-orúkọ)
n’there are 2,000 men in the regiment’ (Ẹgbẹ̀rún méjì ọkùnrin ló wà nínú ẹgbẹ́
ọmọ ogun náà).
region:- ẹkùn ìlú/agbègbè (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘This is a cotton-growing region’ (Agbègbe tí òwú ti ń hù nìyí).
regional:- ti agbègbè/ti ẹkùn ìlú
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The regional government has commenced work on the road’ (Ìjọba
ti agbègbè yìí ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀nà náà)
register:- ìwé ìránti/ìwé ti à ń kọ
orúkọ sí fún ìrántí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This is my class register’ (Ìwé ti à ń kọ
orúkọ sí ní kíláàsì mi nìyí).
register:- kọ orúkọ sílẹ̀ ṣe àkọsílẹ̀
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Have you registered your name?’ (Ṣé o ti kọ orúkọ rẹ sílẹ̀?’)
register- ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The machine registered how fast we were moring’ (Ẹ̀rọ náà ṣe àkọsílẹ̀ bí a
ṣe ń sáre´tó)
regret:- kábàámọ̀/jẹ̀ka/fi ẹ̀dùn
ránti (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I regret speding so much money on a car’ (Mo kábàámọ̀ pé mo
ná owó tó tó báyẹn lórí ọkọ̀ kan ).
regret:- ìbànújẹ́/àbámọ̀/ìránti pẹ̀lú
ẹ̀dùn/ẹ̀dùn ọkàn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘It is with regret that I tell you I cannot
accept the job you offered me (Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ni mo fi ń sọ fún ọ pé n kò
lè gba iṣẹ́ ti o fún mi)
regular:- déédé (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
‘Patients eat regular meals in the hospital’ (Àwọn aláìsàn máa ń jẹun déédé
ní ilé-ìwòsàn).
regularity:- ìṣedéédé (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The clock ticked with great regularity’ (Agogo náà ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìṣedéédé
tó ga)
regularly:- lóòrèkóòrè (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé)
‘Please take your drugs regularly’ (Dákun máa lo òògùn rẹ lóòrèkóòrè)
regulation:- òfin/ìlànà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘It is the school’s regulation that no student goes out of the school compound’
(Òfin ilé-ìwé yìí nip é akẹ́kọ̀ọ́ kankan
kò gbọdọ̀ jáde kúrò nínú àyíká ilé-ìwé yìí)
rehearse:- tún kà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He
rehearsed his speech last night’ (Ó tún àpilẹ̀kọ rẹ̀ kà lálẹ́ àná)
rehearsal:- ìdánrawò sílẹ̀/kíkà sílẹ̀
‘We had just six days of rehearsal’ (Ọjọ́ mẹ́fà péré ni a fi ṣe
ìdánraàwo-sílẹ̀)
reign:- jọba (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Did
Abacha reign for eitht years in Nigeria ?’
(Ǹjẹ́ Abacha jọba ní orílẹ̀-èdè Nàìjiríà fún ọdún mẹ́jọ?’)
reign:- ìjọba (ọ̀rọ̀- orúkọ) ‘His
reign pleased everyone’ (Ìjọba rẹ̀ tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn)
rein:- Okùn ìjánu ẹṣin (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A horse’s rein must be too long’ (Okùn ìjánu ẹṣin kò gbọdọ̀ gùn jù)
reincarnation:- àkúdàáyà (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Yorùbá believe in reincarnation’ (Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ nínú àkúdàáyà)
reinforce:- fi agbára kún/fi okun
kún/fi ogun kún ogun (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Success in this examination will reinforce
his interest in academics’ ‘Aṣeyọrí nínú ìdánwò yìí yóò fi agbára kún ìfẹ́ tí
ó ní sí ìwé-kíkà’
reject:- kọ̀ sílẹ̀/ṣá tì (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘We rejected his idea for a music school’ (A kọ àbá rẹ̀ pé kí á dá ilé-ìwé
orin sílẹ̀).
rejoice:- yọ̀/ṣe inú dídún sí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The Wilsons rejoiced when their son came back from abroad’ (Tọkọtaya Wilson
yọ̀ nígbà ti ọmọ wọn dé láti òkè òkun)
relate:- bá tan/bá mu (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘This play relates to reincarnation belief’ (Eré yìí bá ìgbàgbọ́ nínú àkúdàáyà
mu)
relate:- sọ ròyìn/wí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Have you related your experience at Abuja
to your family?’ (Ṣé o ti ròyìn ìrírí rẹ ní Abuja fún ẹbí rẹ?)
relationship:- ìbátan/ìbáṣepọ̀
‘What’s your relationship to that girl?’ (Kín ni ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú ọmọbìnrin
yẹn?)
relative:- ẹbí/ará/ìbátan/ìyekan (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Some of my relatives live in Ìbàdàn’ (Àwọn ará mi kan ń gbé ní Ìbàdàn)
relax:- sinmi/dẹwọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘After a week of hardwork, she relaxed at home’ (Lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára ọ̀sẹ̀ kan , ó sinmi nínú ilé)
relaxation:- ìsinmi/ìdẹwọ́/ìdẹ̀ra
‘I will have few days of relaxation next month’ (N ó gba ọjọ́ ìsinmi díẹ̀ ní
oṣù tó ń bọ̀)
relay:- gbá ìròyìn kan kí o sì sọ fún ẹlòmíràn ‘He told me
your story and I relayed it to my mother’ (Ó sọ ìtàn rẹ fún mi, mo sì gbà á
sọ fún ìyá mi)
relay race:- eré ìje (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘A relay race is always very interesting’ (Eré ìje máa ń dùn ni ṣáá)
release:- dá sílẹ̀/tú sílẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Four prisoners were released last year’ (Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rin ni wọ́n dá
sílẹ̀ ní ọdún tó kọjá).
release:- ìdásílẹ̀/ìtúsílẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ
‘After their release, the prisonerws came home’
(Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ wọn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà wá sílé)
relevant:- tí ó tọ́/tí ó yẹ (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘Do you have a relevant experience on this job?’ (Ǹjẹ́ o ní ìrírí ti
ó yẹ lórí iṣẹ́ yìí?)
relic:- ohun ìrántí (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘Do not remove that book. It is a relic of the deceased professor’ (Máṣe mú
ìwé yẹn kúrò. Ohun ìrántí ni fún ọ̀jọ̀gbọ́n ti ó kú)
relieve:- ràn lọ́wọ́/dẹ̀ lára (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The medicine relieved his headache’ (Òògùn náà dẹ̀ ẹ́ lára kúrò nínú ẹ̀fọ́rí
rẹ̀)
relief:- ìrànlọ́wọ́/ìdẹ̀ra (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘I felt great relief when I heard I had passed the examination’ (Ìdẹ̀ra ńlá dé
bá mi nígbà ti mo gbọ́ pé mo ti yege níbi ìdánwò náà)
religion:- ẹ̀sìn/ìsìn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
religious:- olùfọkànsìn/ti ẹ̀sìn (ọ̀rọ̀
àpèjúwe ‘He is a religious person’ (Ọlùfọkànsìn ẹ̀dá ni’
relunctant:- ṣe tìkọ̀/tìkọ̀tìkọ̀/lọ́ra
(àpèjúwe) ‘The child was relunctant to leave his mother’ (Ó ṣe ọmọ náà tìkọ̀
láti fi ìyá rẹ̀ sílẹ̀)
rely:- sinmi lé/gbẹ́kẹ̀lẹ́ (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘You can rely on me to help you’ (O lè gbẹ́kẹ̀ lé mi láti ràn ó lọ́wọ́)
reliable:- ṣe é sinmi lé/ṣe é gbẹ́kẹ̀lé
(ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Wálé kì í ṣe ẹni tó ṣe é sinmi lé)
remain:- kù, dúró (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘It
remains N20 with me’ (Ó ku ogún náírà pẹ̀lú mi)
remain:- dúró ‘I am going to school
but my brother will remain at home’ (Èmi ń lọ sí ilé-ìwé ṣùgbọ́n àbúrò mi
yóò dúró nílé)
remainder:- ìyókù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I
will handover the remainder to you’ (N ó yọ̀ǹda ìyókù fún ọ)
remains:- òkú ènìyàn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘We sas Adedibu’s remains before it was buried’ (A rí òkú Adédibú kí wọ́n tó
sin ín)
remark:- ìfiyèsí/ìsọ̀rọ̀sí/ọ̀rọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘He made a remark about the woman who received the award’ (ó sọ ìfìyèsí kan ní pa obìnrin tí ó
gba àmì ẹ̀yẹ náà)
remark:- fiyèsí/sọ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He
remarked that we should love ourselves’ (Ó sọ pé kí á fẹ́ràn ara wa)
remarkable:- ìyanu/lókìkí (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘Some remarkable successes occurred during his reign’ (Àwọn àṣeyọrí
olókìkí kan ṣẹlẹ̀
ní àkókò ìjọba rẹ̀)
remedy:- òògùn/àtúnsẹ/ọ̀nà àbáyọ
(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Let’s think of a remedy to this problm’ (Ẹ jẹ́ kí á ronú ọ̀nà
àbáyọ sí ìṣòro yìí)
remedial:- alátùn-únṣe (ọ̀rọ̀
àpèjúwe) ‘The boy was doing remedial exercises for his weak legs’ (Ọmọkùnrin
náà ń ṣe àwọn eré-ìdárayé alátùn-únṣe fún ẹsẹ̀ rẹ̀ tí kò le)
remember:- rántí (ọ̀rọ̀-ìṣe) /níran
(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I always remember his birthday’ (Mo sáábà máa ń rántí ọjọ́-ìbí
rẹ̀)
remind:- rán ní etí.ṣí ní etí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘That man reminds me of my former teacher’ (Ọkunrin yẹn rán mi létí olùkọ́ mi
nígbà kan )
remnant:- ìyókù/ìrépè aṣọ/ìpẹ́pẹ́rẹ́/(ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘I made a shirt from a remnant of that cloth’ (Mo rán ẹ̀wù kan pẹ̀lú ìrépe-aṣo yẹn)
remote:- jìnnà (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The
have a remote farm at Èkìtì’ (Wọ́n ní oko tó jìnnà kan ní Èkìtì)
remotely:- páàpáà/jìnnà tefétefé (ọ̀rọ̀
àpọ́nlé) ‘He is not remotely like me’ (Kò jọ mí páàpáa).
Remove:- mú kúrò/ṣí nídìí/ṣí nípò
padà (ọ̀rọ̀-ìṣe ‘Will you remove your books from my table? (Dákun mú ìwé rẹ
kúrò ní orí tábìlì mi)
removal:- ìṣípòpada (ọ̀rọ̀-orúkọ)
/ìmúkúrò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The company does removals of workers into the other
branches’ (Ilé-iṣẹ́ náà máa ń ṣe ìṣípòpadà àwọn òṣìṣẹ́ lọ sí àwọn ẹ̀ka
mìíràn)
renew:- sọ di ọ̀tun/túnṣe/túnjí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘He renewed his car licence’ (Ó sọ ìwé-ọkọ̀ rẹ di ọ̀tun)
renew:- bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘The players renewed their promise to play hard’ (Àwọn agbábọ́ọ̀lù náà sọ
ìlérí wọn di ọ̀tun láti gbá bọ́ọ̀lù tọkàntọkàn).
Renewal:- ìsọdọ̀tun/ìtúnṣe (ọ̀rọ̀-orúkọ
‘Let us start the renewal processes now’ (Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ àwọn ìgbé sẹ̀ ìsọdọ̀tun
nísinsìnyí)
rent:- owó ilé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He
pays N4,000 a week rent’ (Ó ń san owó ilé ẹgbẹ́rún mẹ́rin náírà lọ́sẹ̀).
rent:- yá ilé gbé (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He
rents an office in the city’ (Ó ń yá ọọ́fíìsì lò nínú ìlú)
rent:- fà ya (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He rent
his cloth when he heard the sad news’ (Ó fa aṣọ rẹ̀ ya nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn
ìbànújẹ́ náà).
repair:- tún ṣe/tún fi sí ipò ‘Have
you repaired the bicycle yet?’ (Ṣé o ti tún kẹ̀kẹ́ náà ṣe síbẹ̀?)
repair:- ìtúnṣe/àtúnṣe (ọ̀rọ̀
-orúkọ) ‘I haven’t got enough money to pay for the repairs of my bicycle’ (N
kò tí ì ní owó tí ó tó láti sanwó àtúnṣe kẹ̀kẹ́ mi)
repay:- san padà/rà dí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘I will repay you tomorrow’ (N ó san owó náà padà fún ọ lọ́la)
repeat:- tún sọ/tún wí (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘Could you repeat what you said?’ (Ǹjẹ́ o lè tún ohun tí o wí sọ?)
repeat:- tún ṣe (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I
hope you do not repeat your behaviour today’ (Mo lérò pé o kò ní í tún ìwà rẹ
hù lónìí)
repetition:- ìtúnṣe (ọ̀r`ọ-orúkọ)
/àtúnwí/àtúnsọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Make no repetition of your sentences’ (Má ṣe
àtúnwí gbólóhùn rẹ)
repel:- lé padà sẹ́yìn (ọ̀rọ̀-orúkọ)
‘The soldiers repelled the people who were attacking them’ (Àwọn ọmọ ogun
náà lé àwọn tó ń takò wọn padà sẹ́yìn)
repent:- ronúpìwàdà (ọ̀rọ̀-ìṣe)/káàánú
nítòótọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I was angry with him but later I repented and forgave
him’ (Inú bí mi sí i ṣùgbọ́ nígbà tí ó yá mo ronúpìwàdà, mo sì dáríjìn ín)
replace:- mú padà sípò/dá padà (ọ̀rọ̀-ìṣe)
‘When you have finished using the axe, please replace it’ (Bí o bá ti lo àáké
náà tán, jọ̀wọ́ dá a padà)
replace:- fi dípò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I
shall replace this chair with a new one’ (N ó fi àga tuntun dípò àga yìí)
No comments:
Post a Comment