Friday, 27 January 2017

Reply



reply:- ìdáhùn/èsì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The boss wants a reply in two weeks’ (Ọ̀gá gẹ́ gba èsì láàrin ọ̀sẹ̀ méjì)

reply:- dá lóhùn/dáhùn/fèsì (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He has not replied my letter’ (Kò tí ì dáhùn lẹ́tà mi)

report:- ìròyìn/ìyìn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He wrote a report on Audu’s school work’ (Ó kọ ìr`oyìn kan lórí iṣẹ Audu ní ilé-ìwé)

report:- ròyìn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We reported the robbery to the police’ (A ròyìn olè-jíjà náà fún àwọn ọlọ́pàá)

report:- fisùn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We shall report you to the principal’ (A ó fi o sun ọ̀gá ilé-ìwé)

reporter:- oníròyin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The reporter lives in our compound’ (Oníròyìn náà ń gbé ní agboole wa)

reporter:- olùfisùn/afinisùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The devil is our Wicked reporter’ (Olufisin búburú wa ni Èṣù)

represent:- dúró nípò ẹlòmíràn/ṣe ojú fún ni (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Mr Adébáyọ̀ represented Nigeria at the World court’ (Ọ̀gbẹ́ni Adébáyọ̀ ṣe ojú fún Nàìjíríà ní ilé-ẹjọ́ àgbáyé)

represent:- fihàn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘In this picture, Jesus is represented talking to his friends’ (Nínú àwòrán yìí, a fi Jesu hàn níbi tí ó ti ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀)

representative:- aṣojú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Oyo state sent only two representatives to the competition’ (Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rán aṣojú méjì sí ibi ìdíje náà)

reproach:- ẹ̀gàn/ẹ̀sín/ẹ̀tẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He has brought a reproach to their family’ (Ó ti mú ẹ̀gàn bá ẹbí wọn)

reproach:- kẹ́gàn/bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lù/gàn/ṣáátá (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Do not reproach yourself, it was not your fault’ (Má bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ara rẹ, kìí kúkú ṣe ẹjọ́ rẹ)

reproduce:- bímọ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Cats often reproduce twice a year’ (Olóńgbò máa ń bímọ lẹ́ẹ̀méjì lọ́dún kan)

reproduce:- ṣẹ̀dá (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I reproduced the drawing I had seen’ (Mo ṣẹ̀dá àwòrán tí mo rí)

reproduction:- ìbísí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Insects help in the production of flowers’ (Àwọn kòkòrò ń ṣèrànwọ́ ní ìbísí àwọn òdòdó)

reproduction:- ìṣẹ̀dá/àtúnmújáde (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The reproduction of the drawings was not good enough’ (Ìṣẹ̀dá àwòrán náà kò dára tó).

reptile:- afàyàfà/ẹranko tí ń fi àyà fà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Snakes, crocodiles and lizards are all reptiles’ (Afàyàfà ni èjò, ọ̀ni àti aláǹgbá)

republic:- ìlú tí kò ní ọba ṣùgbọ́n tí wọ́n ní ààrẹ’ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘How many countries are republic in Africa?’ (Orílẹ̀-èdè mélòó ni wọn kìí tií jẹ ọba ṣùgbọ́n tí wọn ń jẹ ààrẹ nílẹ̀ Aáfíríkà?)

reputation:- òkìkí/orúkọ rere (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Wọlé Ṣóyínká has a good reputation in the united states of America’ (Wọlé Ṣóyìnká ní òkìkí rere ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà)

request:- ìbéèrè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I have a request to make can I have some of your mangoes?’ (Mo ní ìbéèrè kan- ṣé o lè fún mi ní díẹ̀ nínú máńgòrò rẹ?)

request:- ẹ̀bẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a letter of request for textbooks on your table’ (Ìwé ẹ̀bẹ̀ fún àwọn ìwé-kíkà ń be lórí tábìlì rẹ)

request:- bẹ̀/bẹ̀bẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìsẹ) ‘I request that you keep quiet in this hospital’ (Mo bẹ̀ yín kí ẹ má pariwo nínú ilé-ìwòsàn)

request:- bèèrè (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Go and request for your results immediately’ (Lọ bèèrè ìwé-èsì ìdánwò rẹ ní kíákíá)

require:- nílọ̀/fẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I require two children to help me’ (Mo nílò ọmọ méjì láti ràn mí lọ́wọ́)

requirement:- ohun tí a fẹ́/ohun tí a nílò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The requirements for admission into that university are too high’ (Ohun tí wọn ń fẹ́ fún ìgbaniwọlé sí Yunifásítì yẹn ti ga jù)

rescue:- ìkóyọ/ ìgbàlà/ìgbàsílẹ̀/ẹ̀yọ nínú ewu (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We went to the rescue of the teacher’ (A lọ ṣiṣẹ́ ìgbàlà olùkọ́ náà)

rescue:- gbà sílẹ̀/yọ nínú ewu/gbà là (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We rescued the boy who fell into the river’ (A kó ọmọkùnrin náà tí ó já sínú odò yọ nínú ewu)

research:- ṣe ìwádìí/wádìí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘They are researching into the cause of the accident’ (Wọn ń wádìí ohun tó le fa ìjàmbá náà)

research:- ìwádìí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘What have their researches shown?’ (Kín ni àwọn ìwádìí wọn fihàn?_

resemble:- jọ/dà bí/ (Ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She resembles her mother when she smiles’ (Ọmọbìnrin náà jọ ìyá rẹ̀ nígbà tí ó bá ń rẹ́rìn-ín)

resemblance:- ìjọra/àfijọ/jíjọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is no resemblance between Bíọ́lá and Bólú’ (Kò sí àfijọ kankan láàrin Bíọ́lá àti Bólú)

resent:- fi ìbínú hàn/bínú sí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Some people resent everyone who is richer than they are’ (Àwọn ènìyàn kan máa ń bínú sí ẹnikẹni tí ó bá lówó jù wọ́n lọ)

resentment:- ìbínú/ìrunú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Báyọ̀ńlé has the job that you wanted do you feel resentment against him?’ (Báyọ̀ńlé ti gba iṣẹ́ tí ò ń wá ṣe o ní ìrunnú sí i ni?)

reserve:- fi pamọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I have reserved a room for you at the hotel’ (Mo ti fi yàrá kan pamọ́ fún ọ ní ilé-ìtura náà).

reserve:- ìpamọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘They kept 10 bags of beans in reserve’ (Wọ́n fi àpò ẹ̀wà mẹ́wàá sí ìpamọ́)

reservoir:- ìbi ìpamọ́ omi tàbí nǹkan mìíràn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This reservoir gives water to the whole city’ (Ibi ìpamọ́ omi yìí ni ó ń fún gbogbo ìlú ní omi)

residence:- ibùgbé/ilé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Most of the students live in the halls of residence’ (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló ń gbé ní gbọ̀ngàn ibùgbe)

resident:- olùgbé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There were confrontations between the residents and the police’ (Ìporógan wà láàrin àwọn olùgbé náà àti àwọn ọlọ́pàá)

residential:- ti ibùgbé (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘ Write your residential address here’ (Kọ àdírẹ́sì ti ibùgbé rẹ̀ síhìn-ín)

resign:- fi sílẹ̀/ṣíwọ́ iṣẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Mr Ọlọ́pàádé has resigned his appointment with the University’ (Ọ̀gbẹ́ni Ọlọ́pàádé ti kọ̀wé fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní Yunifásítì).

resign:- gbà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I resigned myself to a long wait’ (Mo gbà láti dúró pẹ́ títí)

resignation:_ ìfisílẹ̀/ìjọ̀lọ́wọ́ ‘I sent in my resignation last week’ (Mo fi ìwé ìfiṣẹ́sílẹ̀ mi ránṣẹ́ lọ́sẹ̀ tó kọjá)

resist:- ta kò/kọjú ìjà sí/tàpá sí/ta láyà/òdì sí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The students resisted a more to increase the school fess’ (Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ta ko ìgbésẹ̀ láti fi owó kún owó-ilé-ìwé náà)

resistance:- ìlòdìsí/ìtàpásí/àtakò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Persistent resistance to change has almost ruined that company’ (Ìlòdìsí ìyípadà ní gbogbo ìgbà ti fẹ́rẹ̀ run ilé-iṣẹ́ yẹn)

resolve:- wá ójútùú sí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Attempts are being made to resolve the problem of insecurity in schools’ (Igbìyànjú ti ń lọ láti wá ojútùú sí ìṣòrò àìsí-ààbò ní àwọn ilé-ìwé)

resolve:- pinnu (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The government has resolved to name the culprits’ ‘Ìjọba ti pinnu láti dárúkọ àwọn ọ̀bàyèjẹ́ náà’

resort:- láti parí/yọrí sí ṣíṣe nǹkan kan (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘When Bísí would not obey the teacher, he resorted to slapping her’ (Nígbà tí Bísí kò gbọ́ràn sí olùkọ́ náà lẹ́nu, Ó kúkú parí rèsí gbígbá a létí)

resort:- ibìkan tó dára láti lo ìsinmi (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Kakànfò Inn is a nice place for a resort’ (Ibi tó dára kan ni kakaǹfò láti lo ìsinmi)

resort:- ohun ti  a ṣe ní ìgbẹ̀yìn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘In the last resort, I can ask my friend for some money’ (Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo rẹ̀ mo le bèèrè owó díẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ mi)

resources:- ohun tó ń ran ènìyàn lọ́wọ́/ohun àlùmọ̀ọ́nì/ìgbékẹ̀lé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘One of our natural resources is petreleum’ (Ọ̀kan nínú àwọn ohun àlùmọ̀ọ́nì wa ni epo rọ̀bì)

resourceful:- tì ìgbẹ́kẹ̀lé/ti ohun tó ń ran ni lọ́wọ́/ti ohun tó kún fún èròjà (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Wálé is a resourceful person in this matter’ (Ẹnikan tó kún fún èròjà ni Wálé nídìí ọ̀rọ̀ yìí)

respect:- ọ̀wọ̀/ìyìn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We have respect for those who work for other people’ (A ní ọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ fún àwọn èèyàn mìíràn)

respectable:- yẹ fún ìyìn/yẹ fún ọlá/tí a kà sí (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘I live in a respectable area’ (Mò ń gbé ni agbègbè tó yẹ fún ọlá)

respectful:- kún fún ọ̀wọ̀/tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘We were brought up to be respectful of authority’ (A tọ́ wa dàgbà láti kún fún ọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ)

respect:- bọ̀wọ̀ fún/buyìn fún/bu ọlá fún/ júbà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We respect our teachers in my school’ (A máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn olùkọ́ wa ní ilé-ìwé mi)

respond:- dáhùn/fèsì (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She never responded my letter’ (Kò fèsì fún lẹ́tà mi rí)

response:- ìdáhùn (ọ̀rọ̀-òrúkọ) èsì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I have had no respons to my letter asking for help’ (N kò tíì rí èsì sí lẹ́tà mi ti mo fi ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́)

responsible:- tí ó ṣe é fọkàn tán/ti ó sẹ é gbẹ́kẹ̀lẹ́ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Mrs Arótiba is a responsible woman’ (Obìnrin tí ó ṣe é fọkàn tán ni aya Arótiba)

responsible:- ní láti dáhùn fún (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Are you the one responsible for the accident?’ (Ṣé ìwọ ni o níláti dáhùn fún ìjàmbá náà?)

responsibility:- ìgbẹ́kẹ̀lé/ìfọkàntán/ẹrù/iṣẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The police have the resoponsibility to ensure that the rules are enforced’ (Iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá ni láti rí i pé òfin di pípamọ́)

rest:- ìsinmi/oorun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You need to have some rest’ (O nílò ìsinmi díẹ̀)

rest:- ìyókù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I only took two mangoes. I don’t know about the rest’ (Máńgòrò méjì ni mo mú. N kò mọ̀ nípa àwọn ìyókù).

Rest:- sinmi/sùn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I rested for an hour before I wnt out’ (Mo sinmi fún wákàtí kan kí n tó jáde)

rest:- gbé lé (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I rested my elbow on the table’ (Mo gbé ìgùnwọ́ mi lé orí tábìlì)

restaurant:- ibi àrójẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We stopped at a restaurant to eat’ (A dúró jẹun ní ibi àrójẹ kan)

restore:- mú bọ̀ sípò (ọ̀rọ̀-ìṣe)/dá padà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The most recent operation restored his sight’ (Iṣẹ́-abẹ àìpẹ́ yìí ló mú ìran rẹ̀ bọ̀ sípò) ‘Having used the books, he stored them to the library’ (Nígbà tí ó lo àwọn ìwé náà tán, ó dá wọn padà sí yàrá-ìkàwé)

restrain:- dá lẹ́kun/dá dúró/ká lọ́wọ́ kò/dí ní ọ̀nà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The prisoner had to be restrained by the police’ (Àwọn ọlọ́pàá níláti ká ẹlẹ́wọ̀n náà lọ́wọ́ kò)

restrict:- pààlà fún/há mọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The classes are small as we are restricted by the size of the classrooms’ (Àwọn kíláàsì náà kéré nítorí pé fífẹ̀ àwọn yàrá kíláàsì náà há wa mọ́)

result:- ìyọrísí/òpin/èso/èsì (ọ̀rọ̀-orúkọ)’ I hit him and as a result he fell down’ (Mo kàn án lẹ́sẹ̀ẹ́, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé ó ṣubú)

result:- yọrí sí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘When a student does not read. Failure results’ (Bí akẹ́kọ̀ọ́ kò bá kàwé, ìjákulẹ̀ ní í yọrí sí )

resume:- tún bẹ̀rẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We shall resume our work after lunch’ (A ó tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wa lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán)

retail:- aláyọtà (ọ̀rọ̀ àpjèjúwe) ‘My mother is a retail trader’ (Oníṣòwò aláyọtà ni ìyá mi)

retail:- ta nǹkan wẹ́wẹ́/sú tà/lé tà/yọ tà (ọ̀rọ̀-ìse) ‘The company manufactures and retails its products’ (Ilé-ìṣẹ́ náà ń ṣẹ̀dá ọjá wọ́n sì tún ń yọ ọjà wọn tà)

retain:- dá dúró ‘The university retains few of its graduates’ (Yunifásítì náà máa ń dá péréte nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́-jáde wọn dúró fún iṣẹ́)

retire:- pẹ̀yìndà/lọ sinmi/ṣíwọ́ iṣẹ́ ‘She was forced to retire early from teaching because of her ill health’ (Ó fi tipátipá ṣíwọ́ iṣẹ́ olùkọ́ nítorí àìlera rẹ̀).

retirement:- ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ọba (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘My father is 55. He is approaching retirement. (Bàbá mi ti pé ọmọ ọdún márùn-únlé láàádọ́ta. Ó ti ń súnmọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ọba)

retreat:- pẹ̀yìndà/padà sẹ́yìn(ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We retreated back down the mountain’ (A pẹ̀yìndà lọ sí ìsàlẹ̀ níbi òkè).

retreat:- ìfàṣẹ́yìn/ìpẹ̀yìndà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Your retreat at this time is not good’ (Ìpẹ̀yìndà rẹ ní àkókò yìí kò dára)

return:- padà/mú padà (ọ̀rọ̀-ìsẹ) ‘Don’t forget to return my book’ (Má gbàgbé láti dá ìwé mi padà)

return:- ìpadàbọ̀/àbọ̀/àbọ̀dé ‘On my return, I saw the door was opened’ (Ní ìpadàbọ̀ mi, mo rí i pé ìlẹ̀kùn ṣí sílẹ̀)

reveal:- Ṣípayé/fihàn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Details of the murder was revealed by the local newspaper’ (Ìwé ìròyìn ìbílẹ̀ ni ó ṣípayá ìròyin kíkún nípa ìpànìyàn náà)

revenge:- gbẹ̀san/ya oró/jẹ níyà padà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She revenged her father’s death’ (Ó gbẹ̀san ikú bàbá rẹ̀)

revenge:- ìránró/ìgbẹ̀san (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She is seeking revenge of her husband’s death’  (Ó ń wọ́nà ìránro ikú ọkọ rẹ̀)

reverence:- ìbọ̀wọ̀/ìbẹ̀rù/ọlá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The crowd knelt in reverence and worsjip’ (Àwọn èrò kúnlẹ̀ ní ìbọ̀wọ̀ àti ìjúbà)

reverend:- ẹni-ọ̀wọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Let us welcome the Reverend into our midst’ (Ẹ jẹ́ kí á kí Ẹni-ọ̀wọ̀ káàbọ̀ sí ààrin wa)

reverse:- ìpààrọ̀/ìdàkejì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You think I gave Bímbọ́ the fruit, but the reverse is true’  (O rò pé mo fún Bímbọ́ ni èso náà ṣùgbọ́n ìdàkejì ni òtítọ́)

reverse:- yí padà/pààrọ̀/fi ti iwájú sẹ́yìn/ fi ti òkè sí ìsàlẹ̀ ‘Please reverse the position of that book’ (Dákun yí ipò tí o fi ìwé náà sí padà)

reverse:- darí padà sẹ́yìn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The driver reversed the car quickly’ (Awakọ náà darí ọkọ̀ padà sẹ́yìn ní kíákíá).

review:- ìyẹ̀wò (ìwé) (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He gave me his latest novel for review’ (Ó fún mi ní ìwè ìtàn-àròsọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ fún ìyẹ̀wò).

review:- yẹ̀ wò/tún wò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He said I should review his novel’ (Ó ní kí n yẹ ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀ wò)

revise:- wò fún àtúnṣe/tún yẹ̀wò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I will have to revise my opinion about Bọ́lá’ (N ó níláti tún èrò mi yẹ̀wò nípa Bọ́lá)

revise:- ṣe àtúnyẹ̀wò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I have been revising all week’ (Gbogbo ọ̀sẹ̀ yìí ni mo ti fi ń ṣe àtúnyẹ̀wò)

revision:- àtúnyẹ̀wò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There will be a revision for those who missed the lecture in the first place’ (Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yóó wà fún àtúnyẹ̀wò nítorí àwọn tí wọn kò sí lábẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìgbà àkọ́kọ́)

revive:- mú sọjí/mú yè/tún gbé dìde/jí dìde (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We shall revive the football club next year’ (A ó tún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà gbé dìde ní ọdún tó ń bọ̀)

revolt:- ṣọ̀tẹ̀/kọ ìsìn ọba (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The people revolted against the military dictatiorship’ (Àwọn èèyàn ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba ológun apàṣẹwàá))

revolt:- dá àìsàn sí lára (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The Smell of the bad fish revolted me’ (Òórùn ẹja burúkú náà dá àìsàn sí mi lára)

revolt:- ọ̀tẹ̀/ìṣọ̀tẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The army officers led a revolt against the king’ (Àwọn ọ̀gágun ló darí ìṣọ̀tẹ̀ sí ọba ìlú)

revolve:- yí ká (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The Earth revolved round the sun’ (Ayé ń yípo ká òòrùn)

revolution:- ìyíká (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The revolution of the earth takes a year’ (Ìyíká ayé máa ń gba ọdún kan)

revolution:- ìṣọ̀tẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The youths of this country will rise in revolution against the government one day’ (Àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè yìí yóò dìde ìṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba yìí lọ́jọ́ kan)

reward:- èrè/ẹ̀bùn/ẹ̀san (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a reward on ground for anyone who finds the lost money’ (Ẹ̀bùn ń bẹ nílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá rí owó tí ó sọnù náà)

reward:- ta ní ọrẹ/fi ẹ̀bùn fún/san ẹ̀san fún (ọ̀rọ̀-iṣe) ‘The police said they would reward anyone who finds the stolen car’ (Àwọn ọlọ́pàá sọ pé àwọn yóò fi ẹ̀bùn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọkọ̀ tí wọ́n jí náà)

rhinoceros:- àgbáǹréré/ẹranko bí ìmàdò ńlá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rhinoceros lives in Africa’ (Àgbáǹréré máa ń gbé ní Aáfíríkà)

rhyme:- àwọ ọ̀rọ̀ tí ó dún bákan náà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The following words are examples rhymes of in Yorùbá’ bọ́, kọ́, pọ́ and fọ́. (Àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń dún bákan náà ní èdè Yorùbá ni –bọ́, kọ́, pọ́ àti fọ́)

rhyme:- dún bákan náà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘‘Là’ rhymes with ‘kà’’ (‘Là’ dun bákan náà pẹ̀lú ‘ka’)

rhythm:- ibádọ́gba ìró ìlù nínú tìlùtìfọn tàbí dídún ẹ̀rọ̀ kan. ‘They danced to the rhythm of the drms’ (Wọ́n jó sí ìbádọ́gba ìlù orin náà)

rib:- egungun ihà/ẹfọ́nhà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He broke one of his ribs in the accident’ (Ó kán ọ̀kan nínú àwọn egungun ìhà rẹ̀ níbi ìjàmbá náà)

ribbon:- ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́/aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ tí a fi ń gbá nǹkan yíká (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She tied her hair with ribbon’  (ó fi ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ di irun rẹ̀).

rice:- ìrẹsì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We eat rice everyday in our house’ (A máa ń jẹ ìrẹsì lójoojúmọ́ ní ilé wa)

rich:- ní ọrọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘I have never met a rich man before’ (Èmi kò tíì pàdé ẹni tó ní ọrọ̀ kankan rí).

rich:- ọlọ́ràá (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The rich land by the river gives two crops a year’ (Ilẹ̀ ọlọ́ràá tó wà lẹ́bàá odò náà máa ń so èso lẹ́ẹ̀méjì lọ́dún kan)

riches:- ọrọ̀/owó lọ́pọ̀lọpọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She gave away all her riches’ (Ó fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ tọrọ)

richly:- lọ́pọ̀lọpọ̀/púpọ̀/jìngbìnnì/gan-an (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘He richly deserves all the praise he receives’ (Gbogbo oríyìn tí wọ́n gbé fún un tọ́ sí i púpọ̀)

rickets:- ààrùn arọmọléegun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rickets kill sọ many children in Afirca’ (Ààrùn arọmọléegun máa ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé ní Aáfíríkà).

rid:- gbà kúrò/bọ́ lọ́wọ́/lé lọ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I’m getting  rid of this car next week’ (N ó bọ́ lọ́wọ́ ọkọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀)

riddle:- eré ọpọlọ/àlọ́ àpamọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A riddle helps one to think fast’ (Eré ọpọlọ máa ń ran ènìyàn lọ́wọ́ láti le ronú kíákíá).

ride:- gùn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He wants to ride a bicycle’ (Ó fẹ́ gun kẹ̀kẹ́)

ridge:- òkè òrùlé/òté ilé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘From the ridge, we could see the whole town below us’ (Láti orí òkè òrùlé, a lè rí gbogbo ìlú ní ìsàlẹ̀ wa).

ridiculous:- rírẹ́rìn-ín/pípani/ẹ́rìn-ín/aláwàdà/oníyẹ̀yẹ́ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Crying over a cake is a ridiculous way to behave’ (Ìṣe aláwàdà kan ni láti máa sunkún nítorí àkàrà òyìnbó).

rifle:- irúfẹ́ ìbọn kan (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The sigh of a rifle scares me’ (Fífí ojú kan ìbọn máa ń dẹ́rù bà mí)

rift:- àlàfo/ìjà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a rift between Bímpé and Táyọ̀’ (Ìjà ń bẹ láàrin Bímpé àti Táyọ̀) There was a rift in the clouds and the sun shone through’ (Àlàfo ń bẹ ní àwọ̀sánmọ̀ níbi tí òòrùn ti là)

rig:- so pọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The men rigged their boat before they started out to fish’ (Àwọn ọkùnrin náà so ọkọ̀-omi wọn pọ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí i pẹ́ja)

right:- tọ́/yẹ/dára (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘It is right that everyone goes to school’ (Ó yẹ kí gbogbo ènìyàn lọ sí ilé-ìwé)

right:- ọ̀tún (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Show me your right hand’ (Fi ọwọ́ ọ̀tun rẹ hàn mí).

right:- ohun tó yẹ/ohun tó dára/ohun tí ó tọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You should know the right from the wrong’ (Ó yẹ kí o mọ ohun tí ó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́)

right:- ẹ̀tọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We must all fight for our rights’ (Gbogbo wa ni a gbọ́dọ̀ jà fún ẹ̀tọ́ wa)

right:- ìdàkejì òsì/òtún (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘If you walk down this road, you will see a school on the left and a bank on the right’ (Bí o bá rìn sí ìsàlẹ̀ ọ̀nà yìí, o ó rí ilé-ìwé kan ní òsì àti ilé-ìfowópamọ́ ní ọ̀tún)

right:- dáradára (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘I did my work right’ (Mo ṣe iṣẹ́ mi dáradára)

right:- sàn-án-sàn-án (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘That’s our house, right in front of you’ (Ilé wa nìyẹn, ní iwájú rẹ sàn-án-sàn-án)

rigid:- le/ṣòro láti tẹ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘An iron bar is rigid when it is cold, but not when it is very hot’ (Ọ̀pá irin le tí ó bá tutù, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ bí ó bá gbóná)

rim:- etí/bèbè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There was a pattern of green flowers round the rim of her plate’ (Bátànì òdòdó aláwọ̀ ewéko ń bẹ yíká etí abọ́ rẹ̀)

rid:- èèpo (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Do oranges have green rind?’ (Ṣé ọsàn máa ń ní èèpo aláwọ̀ ewéko?)

ring:- òrùka (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She wore a gold ring’ (Ó wọ òrùka wúrà)

ring:- lù bí agogo/ró bí agogo (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The bell rang’ (Agogo ró)

ring:- pè lórí agogo (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I rang Báyọ̀ to see if he could come to school’ (Mo pe Báyọ̀ lórí agogo láti wò ó bóyá yóò le wá sí ilé-ìwé)

rinse:- fi omi ṣàn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I rinsed the clothes and hung them up to dry’ (Mo ṣan aṣọ náà, mo sì fi wọ́n kọ́ láti gbẹ)

riot:- ìrúkèrúdò/ariwo ìjà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There was a riot down the road’ (Ìrúkèrúdò kan ṣẹlẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀nà)

riot:- jà nínú ìrúkèrúdò/fa ìrúkèrúdò/fa rògbòdiyàn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The people rioted when they found there was no rice’ (Àwọn ènìyan fa ìrúkèrúdò nígbà tí wọ́n rí i pé kò sí ìrẹsì)

rip:- là/yà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘When Mayọwa was climbing over the wall’ he ripped his trousers on a nail’ (Nígbà tí Máyọ̀wá ń gun ògiri, ó fi sòkòtò rẹ ya lórí ẹ̀só)

rip:- ibi yíya (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Máyọ̀wa has a rip in his trousers’ (Mayọwa ni ibi yíya níbi sòkòtò rẹ̀)

ripe:- pọ́n/dẹ̀/gbó (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘These oranges are not ripe yet’ (Àwọn ọsàn wọ̀nyí kò tíì pọ́n)

ripen:- dàgbà tán/mú pọ́n/mú dẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The mangoes were ripening slowly in the sún’ (Àwọn máńgòrò náà ti ń pọ́n díẹ̀díẹ̀ nínú òòrùn).

ripped:- ìgbì omi kéékèèké/ìbìlù afẹ́fẹ́/ ìgbì kékeré ‘There were ripples on the sea as the wind grew stronger’ (Ìgbì afẹ́fẹ́ kékeré wà lórí òkun bí atẹ́gùn ṣe ń le sí i)

ripple:- gbì/bìlù (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The water rippled as the bird swam’ (Omi náà gbì bí ẹyẹ náà ṣe wẹ̀)

rise:- dìde/gòkè/jíǹde (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I do not rise early’ (Èmi kìí tètè jí dìde) ‘The price of kerosene has risen’ (Owó epo-èèbó ti gòkè) ‘Rise up and let’s go’ (Dide nílẹ̀ kí o jẹ́ ká lọ)

rise:- là (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Sun rises in the East and sets in the West’ (Òòrùn ń là ní Ìlà-Oorùn ó sì ń wọ̀n ní Ìwọ̀-oòrùn)

rise:- èlé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There has been a rise in the price of cassava’ (Èlé ti ń wà lórí owó gbágùúdá)

risk:- ewu (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He took a risk when he crossed the road’ (Ó la ewu kọjá nígbà tí o fo ọ̀nà náà)

risk:- ìdágbá/ìdáwọ́lé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘If you leave your bag here, it is at your own risk’ (Bí o bá gbé àpò rẹ síhìn-ín, ìdágbá ara rẹ ni)

risk:- fi wewu/dágbá (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He risked his life when he climbed the mountain to save the child’ (Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pọ́n òkè náà gùn láti gba ọmọ náà là)

ritual:- ìsìn/ìlànà ìsìn/ètò/ètò ìsìn ‘Most religions have some rituals which are importan’ (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sìn ló ní àwọn ètò kan tó se pàtàkì)

rival:- orogun/aláfarawé/abánidíje (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She and I are rivals for the first position’ (Abánidíje ni òun àti èmi fún ipò kìíní)

river:- odò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The longest river in Africa is the Nile’ (Odò ti ó gùn jù ní Aáfíríkà ni Nile)

riverbed:- ilẹ̀ odò/ìsàlẹ̀ odò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Do not swim into the riverbed’ (Ẹ má wẹ̀ dé ìsàlẹ̀ odò o)

road:- ọ̀nà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a good road from this town to the next one’ (Ọ̀nà gidi wà láti ìlú yìí dé ìlú mìíràn)

roam:- rìn káàkiri/pàráàro (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We roamed around the city looking at all the big buildings’ (A rìn káàkiri ìlú náà a sì ń wo gbogbo àwọn ilé  ńlá-ńlá)

roar:- igbe/ohùn bíbú/híhó ọ̀kun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The lion gave a loud roar’ (Kìnnì-ún náà ké igbe)

roar:- bú ramúramù/kẹ́/hó/kérora (ọ̀rọ̀-ịse) ‘Get out of my way, the man roared’ ‘Kúrò lọ́nà fún mí, ọkùnrin náà bú ramúramù.

roast:- sun/yan/dín gbẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘They roasted a pig for the feast’ (Wọ́n yan ẹlẹ́dẹ̀ kan fún àsè náà)

rob:- jà ní olè/jalẹ̀/jí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘That man robbed me of N5000 last month’ (Ọkùnrin yẹn jà mí ní olè ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà ni oṣù tó lọ)

robber:- ọlọ́ṣà/olè/dánàdánà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A person who robs is a robber’ (Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jalẹ̀, olè ni)

robbery:- olè jíjà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Cases of bank robbery are rampant nowaday’s (Ìṣẹ̀lẹ̀ olè jíjà ní ilé-ìfowópamọ́ ti wọ́pọ̀ jù láyé òde-òrú)

robe:- ẹ̀wù/aṣọ ìgúnwà/agbádá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The chief wore a robe for the ceremony’ (Olóyè náà wọ agbádá fún ayẹyẹ náà)

robot:- ẹ̀rọ aṣèṣe-ènìyàn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘These cars are built by robots’ (Àwọn ẹ̀ro aṣèṣe-ènìyàn ló ṣe àwọn ọkọ̀ wọ̀nyí)

rock:- mi síwá-sẹ́yin/tì síwá-sẹ́yìn/mì (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The boat rocked from side to side in the wave’ (Ọkọ̀ omi náà mì síwá-sẹ́yìn lọ́tùn-ún àti lósì nínú ìjì náà).

rock:- àpáta/òkúta ńlá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There are many different types of rock, and many different colours’ (Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpáta ló wà pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọ pẹ̀lú).

rock and roll:- orin àti ìlù kólekóle (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Many people like rock and roll music’ (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló fẹ́ràn orin kólekóle)

rocket:- rọ́kẹ́ẹ̀tì/ẹ̀rọ tí a tì sáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú ohun-ìjà olóró tàbí nǹkan mìíràn tí ó maa ń gbé lọ sí òfurufú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The rocket was launched in 1980’ (Wọ́n ti rọ́kẹ́ètì náà sí òfurufú ní ọdún 1980)

rod:- ọ̀pá/pàṣán/ẹgba (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Don’t spare the rod for your child’ (E má ṣe yọ ọwọ́ ẹgba kúrò lọ́rọ̀ ọmọ yín)

rode:- gun (ẹsin) (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá sẹ́yìn) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He rode on a horse’ (Ó gun ẹṣin)

rodent:- ọ̀fọ́n-ọ̀n/èkúté (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘It is dangerous to live with rodents’ (Ó léwu láti máa bá ọ̀fọ́n-ọ̀n gbélé)

rogue:- alárèékérekè/ènìyàn búburú ‘Mr Adékúnlé is a rogue’ (Alárèékéreke ni ọ̀gbẹ́ni Adékúnlé)

role:- ipa kíkó nínú eré/ipa (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Wale played the role of a chief in the drama’ (Wálé kó ipa olóyè kan nínú eré-oníṣe náà).

roll:- yí ká (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The ball rolled under the table’ (Bọ́ọ̀lù yí ní abẹ́ tábìlì)

roll:- ká (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Roll up the picture so that it does not get dameged’ (Ká àwòrán náà sókè kí ó má baà bàjé)

roll:- ìká (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘the trader has many rolls of cloth in his shop’ (Oníṣòwò náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìká aṣọ nínú ìsọ̀ rẹ̀)

roman catholic:- Ìjọ Àgùdà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Roman Catholic priests do not marry’ (Awọn páàdì ìjọ Àgùdà kìí gbéyàwó)

romance:- eré ìfẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘It is a story of the romance between a king and a servant girl’ (Ìtàn eré ìfẹ́ ni láàrin ọba kan àti ẹrúbìnrin kan)

romance:- ara-yíyá-gágá/ìwúrí/adùn (ọ̀rọ̀-orúkọ), ‘She thought there was romance in journeys’ (Ó rò pé adùn kankan wà nínú ìrìn-àjò)

romance:- àrọ̀/ìtàn lásán/àhesọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Don’t just tell me a romance. I want to know what actually happened’ (Má kàn rọ́ ìtàn lásán kan fún mi o. Mo fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an)

romantic:- eléré ìfẹ́/tì adùn ìfẹ́ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘When they were alone in the garden, he became very romantic’ (Nígbà tí wọ́n dá wà nínú ọgbà, ó wá di eléré ìfẹ́ gidi)

rondavel:- ilé àbẹ́tẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Some people can’t live in a rondavel’ (Àwọn ènìyàn kan kò lè gbé nínú ilé àbẹ́tẹ̀)

roof:- òrùlé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a cat on our roof’ (Ajá kan ń bẹ lórí òrùlé wa)

roofing:- ohun-èlò tí a fib o ilé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I do not like this roofing’ (N kò fẹ́ ohun tí wọ́n fib o ilé yìí)

room:- yàrá/ipò/ààyè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Our house has four rooms’ (Ilé wa ni yàrá mẹ́rin) ‘We are eight here. There is no room for anyone else’ (Àwọn mẹ́jọ ni a wà níbí. Kò sí ààyè fún ẹnìkankan mọ́)

root:- gbòǹgbò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We eat some roots such as yams and cassava’ (A máa ń jẹ àwọn gbòǹgbò kan bí iṣu àti ẹ̀gé)

root:- ìpilẹ̀sẹ̀/okùnfà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘What is the root of your trouble between you and Bíọ́lá?’ (Kín ni okùnfà wàhálà tó wà láàrin ìwọ àti Bíọ́lá?)

rope:- okùn/ikàn/ọsán ‘We tied the dog to the tree with a rope’ (A fi okùn so ajá náà mọ́ igi)

rose:- dìde/gòkè/jíǹde/là (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ sẹ́yìn) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I rose up early today’ (Mo tètè jí lónìí)

rose:- irú ìtànná kan (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There are many types of roses’ (oríṣiríṣi ìtànná olóòórùn dídùn ló wa)

rot:- bàjẹ́/rà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The wood is rotting because it has been wet for a long time’ (Igi náà ti ń rà nítorí pé wọ́n ti da omi sí i fún ọjọ́ pípẹ́)

rotten:- díbàjẹ́/rà (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The fish is rotten; nobody should eat it’ (Ẹja náà ti díbàjẹ́; ẹnìkankan kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́)

rotate:- yí bíi kẹ̀kẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The Earth rotates round the sun’ (Ayé ń yí bíi kẹ̀kẹ̀ ká òòrùn).

rotation:- yíyí bíi kẹ̀kẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Does the rotation of the Earth take one year?’ (Ṣé yíyí bíi kẹ̀kẹ̀ Ayé máa ń gba ọdún kan ni?)

rough:- pálapàla/yángiyàngi/págun-pàgun/ṣàìdán/ṣàìjọ̀lọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘We have rough roads in Nigeria’ (Ọ̀nà págun-pàgun ni a ní lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà)

rough:- líle (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘This boy is very rough’ (Ọmọkùnrin yìí le púpọ̀)

roughly:- lákọlákọ (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) They play football too roughly’ (Wọ́ ń gbá bọ́ọ̀loù lákọlákọ).

roughly:- nǹkan bíi… (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘I spent roughly N 10,000 yesterday’ (Mo ná nǹkan bí ẹgbẹ́rún mẹ́wàá náírà lánàá)

round:- yíká/roboto/sù/rìbìtì/bìrìkìtì round –bìrìkìtì (Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘The children stood round the man who was telling the story’ (Àwọn ọmọdé dúró bìrìkìtì yí ọkùnrin tó ń sọ ìtàn náà ká)

round:- roboto (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘A ring is always round’ (Ọ̀rùka sáábá máa ń rí roboto ni)

roundabout:- ìbùdótó yí roboto (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There are many roundabouts in Ìbàdàn (Ibàdó tó yíká roboto pọ̀ ní Ìbàdàn)

rounders:- eré tọ̀pá-tibọ́ọ̀lù alásàáyípo (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The game of rounders is popular in America’ (Eré tọ̀pá-tibọ́ọ̀lù alásàáyípo gbajúmọ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà)

roundworm:- ejò-inú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Roundworms make animals to grow thin’ (Ejò-inú máa ń mú ẹranko gbẹ)

route:- ipa ọ̀nà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We came by a longer route than usual’ (Ipa ọ̀nà tí a gbà lónìí pẹ́ wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ)

routine:- ipa ti ọ̀nà iṣẹ́ ojoojúmọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I have my morning routine’ (Mo ní àwọn ipa-ọ̀nà ìṣe ojoojúmọ mi)

row:- ìlà/ọ̀wọ́/ẹsẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We sat in a row to watch the match’ (A jókòó ní ọ̀wọ́ láti wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà)

row:- ariwò/ijà (ọ̀rọ̀-orúkọ) asọ/ìkùnsínú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Iwo of them are having a row about money’ (Àwọn méjéèjì ní ìkùnsínú nípa owó)

row:- wà/tu ọkọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)’We rowed the boat down the river’ (A tu ọkọ̀ omi náà sí ìsàlẹ̀ odò)

royal:- ti ọba/bí ọba (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Ọlábísí is from a royal family’ (Ọ́lábísí wá láti ẹbí, ti ọba)

royalty:- ipò ọba/ìwà ọba/oyè ọba (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We were treated like royalty’ (Wọ́n ṣe wá bí ọba)

rub:- gbo/fira/fi pa/kùn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She rubbed her shoe with a cloth’ (Ó fi aṣọ pa bàta rẹ̀)

rubber:- rọ́bà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rubber comes from trees’ (Lára igi ni a ti ń rí rọ́bà)

rubberband:- okùn rọ́bà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We use rubberband to fasten things’ (A máa ń lo okùn rọ́bà láti di nǹkan)

rubbish:- ohun aláìníláárí/pàǹtí/ìsọkúsọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘What’s all this rubbish on your neck?’ (Kín ni gbogbo pàǹtí tí o sọ mọ́ orùn yìí?)

rubbish:- ìsọkúsọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He said he would win the race, but that’s rubbish’ (Ó ní òun yóò borí eré-ìje náà ṣùgbọ́n ìsọkúsọ gbáà nì yẹn)

rubbish:- aláìníláárí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Put this empty tin in the rubbish basket’ (Ju agolo òfìfo yìí sínú apẹ̀rẹ̀ aláìníláárí yẹn)

ruby:- òkúta pupa tí a fi ń ṣiṣẹ́ ọnà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rubies cost a lot of maney’ (Àwọn òkúta pupa fún iṣẹ́ ọnà máa ń wọ́n)

rudder:- ìtukọ̀/ìtọkọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A rudder controls a ship’ (Ìtukọ̀ níí darí ọkọ̀ ojú-omi)

rude:- òpè/aláìm`ọwàáhù/láìlóye (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Bíọ́lá is very rude to their grand-mother’ (Bíọ́lá ń hùwà aláìlóye sí ìyà-àgbà wọn)

ruffle:- dà rú (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The wind ruffled the water’ (Afẹ́fẹ́ náà da omi náà rú)

rug:- aṣọ ìbùsùn/aṣọ àtẹ̀gùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He has a red rug in his room’ (Ó ní aṣọ ìbùsùn pupa ní yàrá rẹ̀)

rugged:- pálapàla, láìtẹ́jú/ṣákiṣàki (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Most of our roads are not rugged anyone’ (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀nà wa ni kò rí pálapàla mọ́)

ruin:- bàjẹ́/pa run (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘My new shoe got ruined in the mud’ (Bàtà mi tuntun bàjẹ́ nínú ẹrọ̀fọ̀)

ruin:- ìparun/bíbàjẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Years of war have left the area in ruins’ (Àìmọye ọdún tí wọ́n fi jà ogun ti sọ sọ agbègbè náà di ìparun)

rule:- jọba/ṣe àkóso (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Whe rules this country?’ (Ta ni ó ń ṣe àkóso orílẹ̀-èdè yìí?)

rule:- fa ìlà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He ruled a straight line under his name’ (ó fa ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ sí abẹ́ orúkọ rẹ̀)

ruler:- alákòóso/olùdarí/ọba (ọ̀rọ̀-orúkọ ‘The ruler of the country has ordered the release of prisoners’ (Alákòóso orílẹ̀-èdè náà ti pàṣẹ ìtúsílẹ̀ fún gbogbo àwọn ẹlẹ́wọn)

ruler:- ohun tí a fi ń fa ìlà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I lost my ruler yesterday’ (Mo sọ nǹkan ìfàlà mi nù lánàá)

rule:- òfin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The school rules must be obeyed’ (A gbọ́dọ̀ pa ofin ilé-ìwé mọ́)

rum:- otí ìrèké/ọtí ṣago/ọtí àbùrọ/ọtí òyìnbó (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He took a cup of rum’ (Ó mu ife ọtí àbùrọ kan)

rumble:- ariwo (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A rumble of laughter was heard from that room’ (A gbọ́ ariwo ẹ̀rin láti inú yàrá yẹn)

rumour:- àgbósọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rumour has it that our principal has left for another school’ (Àgbọ́sọ tí a gbọ́ ni pé ọ̀gá ilé-ìwé wa ti lọ sí ilé-ìwé mìíràn).

run:- sáré/sá ‘He ran across the road’ (ó sáré fo ọ̀nà)

run:- ṣiṣẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The machine is not running correctly’ (Ẹ̀rọ náà kò ṣiṣẹ́ dáradára).

run:- eré sísá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We went for a run in the hills’ (A lọ fún eré sísá lórí òkè)

run:- ìrìnàjò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There are no stops on the mombasa run’ (kò sí ààyè ìdúró ní ìrìnàjò Mombasa)

rung:- lu agogo (Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The bell was rung at 2pm yesterday’ (Wọ́n lu agogo ní agogo méjì lá nàá)

rangu:- àpólà igi tí ó tóbi ní idi kan ju èkejì lọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Rungu was used as a weapon in East Africa’ (Ohun ìjà ni àpólà igi tó lówúra lẹ́gbẹ̀ẹ́kan ní Ìlà-oòrùn Aáfíríkà).

rural:- ti igbó/ti oko/ti ìgbẹ́ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Crops are grown in rural areas, and often brough into the town to be sold’ (Ní agbàgbè igbó ni a ti ń gbin nǹkan-ọ̀gbìn, a sì máa ń ṣáábà gbé e wá sí ìgboro fún títà)

rush:- ewéko odò/koríko odò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We use rush to make baskets’ (A máa ń lo koríko odò láti hun agbọ̀n)

rush:- sáré síwájú/rọ́ lù (ọ̀rọ̀-ìṣe) já lù /dà gìrìgìrì/ sáré gìrìgìrì (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘People rushed to buy shares in the company’ (Àwọn ènìyàn dà gìdìgìrì lọ ra ìpín-ìdókòwò ní ilé-iṣẹ́ náà)

rush:- ìkánjú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is no rush anylnger’ (kò sí ìkánjú kankan mọ́)

rust:- ìdógùn-ún/ìdípàrà/ìpárà irin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The old car had a rust on it’ (Ọkọ̀ àtijọ́ náà ní ìdípárà lára).

rusty:- dídógùn-ún (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘I can’t work on this dusty iron’ (Èmi kò lè ṣiṣẹ́ lórí irin dídógùn-ún yìí o)

rust:- dógùn-ún/dipárà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Don’t leave your metal tools outside in the rain, they will rust’ (Ẹ má fi àwọn irin-iṣẹ́ onírin yín sí ìta nínú, òjò o, wọn yóò dógùn-ún)

rustle:- ìró múmì ewéko/ìró afẹ́fẹ́ nínú koríko (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We heard a rustle of a small animal passing through) (A gbọ́ ìró mímì ewéko pé ẹranko kékeré kan kọjá).

rustle:- mì sọ́tùn-ún sósì (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The leaves rustled in the wind’ (Àwọn ewéko mi sọ́tùn-ún sósì nínú afẹ́fẹ́)

rut-àmì kẹ̀kẹ́ nínú ẹrẹ̀/àmì táyà ọkọ̀ nínú ẹrẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘After the rain. We saw ruts in all the roads’ (Nígbà tí òjò rọ̀ dá, a rí àwọn àmì táyà ọkọ̀ ní gbogbo ọ̀nà).

Ss

sack:- àpò ńláà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He carried the rice in a sack’ (ó gbé ìrẹsì náà sínú àpò ńlá)

sack :- yọ kúrò lẹ́nú iṣẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) dá dúró (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He was sacked last week’ (Wọ́n yọ ọ́ kúrò lẹnu iṣẹ́ lọ́sẹ̀ tó lọ).

sacred:- mímọ́/yíyàsọ́tọ̀/lọ́wọ̀/jẹ́ ọ̀wọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘In the Hindu religion, cows are sacred and must not be killed’ (Nínú ẹ̀sìn Hindu ohun mímọ́ ni àwọn màálù bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pa wọ́n).

sacrifice:- ẹbọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘They offered a goast as a sacrifice to the rain god’ (Wọ́n fi ewúrẹ́ kan rú ẹbọ sí òrìṣà òjò)

sacrifice:- ìfìsílẹ̀/ìyọ̀ǹda (ọ̀rọ̀-orúko) ‘Her parents made many sacrifices so that she could study abroad’ (Àwọn òbí rẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyọ̀ǹda kí ó le kàwé ní òkè-òkun).

sacrifice:-rúbọ /ṣẹbọ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘They sacrificed a goat to the rain god’ (Wọ́n rúbọ ewúrẹ́ kan sí òrìṣà òjò)

sacrifice:- fi sílẹ̀/yọ̀ǹda/jọ̀wọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He sacrificed his life to save the young child from the burning house’ (Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ sílẹ láti gba ọmọdé jòjòló náà là nínú ilé tó ń jóná)

sad:- banújẹ́/fajúro (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘I am very sad to hear that you lost your father’ (Mo banújẹ́ gidigidi láti gbọ́ pé baba rẹ ti kú)

sadden:- ba inú jẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) /fa ojú ro (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Why are you so sad?’ (Kín ni ó dé tí o fi fa ojú ro béẹ̀))

sadly:- pẹ̀lú ìbànújẹ́/tìbànújẹ́-tìbànújẹ́ (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘After eight years, the couple departed sadly’ (Lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ, àwọn tọkọ-taya náà pínyà pẹ̀lú ìbànújẹ́)

saddle:- ibi ìjókòó ẹni tó ń gun ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ)/gaarì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I want to repair my bicycle’s saddle’ (Mo fẹ́ tún ibi ìjókòó kẹ̀kẹ́ mi ṣe)

safari:- ìrìnàjò pípẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We are going on safari next week’ (A ó rin ìrìnàjò pípẹ́ kan ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀)

safari:- ìrìnàjò ìdẹ̀gbẹ́ ẹranko (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘During our safari, we saw a lot of elephants but only one lion’ (Nínú ìrìnàjò ìdẹ̀gbẹ́ wa, a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ erin ṣùgbọ́n kìnnì-ún kan péré ni a rí).

safe:- láìléwu /lálàáfíà (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘It is good to be safe at home on a night like this’ (Ó dára láti wà láìléwu nínú ilé ní irú alẹ́ báyìí)

safety:- ibi àìléwu/ààbò/ibi ààbò (ọ̀rọ̀ orúko) ‘He was asked to stay indoor for his own safaty’ (Wọn ní kí ó dúró nínú ilé fún ààbò ara rẹ̀).

safe:- ìpamọ́/àpótí ìpamọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I can’t find the key to the safe’ (N kò rí kọ́kọ́rọ́ àpótí ìpamọ́ o)

sag:- yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)/yin jẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The bed sags in the middle and it us becoming uncomfortable’ (Ibùsùn náà ti ń yin jẹ láàrin kò sì rọgbọ́ mọ́ láti fi sùn)

said:- sọ/pé/wí/ní (ọ̀rọ̀-ìṣe) (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá) ‘He said I should go there’ (Ó ní kí n lọ síbẹ̀).

sail:- tagbokùn/ṣikọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe)/tukọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She sailed the boat’ (Ó ṣíkọ̀ ọkọ̀-omi)

sail:- ìgbokùn ọkọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The boat had red sails’ (Ìgbokùn ọkọ̀ pupa ni ọkọ̀ omi náà ní ).

sailor:- atukọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Is this the sailor?’ (Ṣe atukọ̀ náà nìyí?)

saint:- ẹni mímọ́/ènìyàn mímọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Peter and Mary are names of saints in the Christian church’ ‘Pétérù àti Màríà jẹ́ orúkọ àwọn ènìyàn mímọ́ nínú ìjọ onígbàgbọ́’

sake:- ìtorí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I stopped smoking for the sake of my health’ (Mo fi kòkò tábà mímu sílẹ̀ ní ìtorí ìlera ara mi)

salad:- awo oúnjẹ tẹ̀fọ́-tèso tutu (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Some people do not eat salad’ (Àwọn èèyàn kan kì í jẹ oúnjẹ tẹ̀fọ́-tèso tutu).

salamander:- ẹranko kékeré bí aláǹgbá kan abaraákúnná tó ń gbé orí ilẹ̀ àti inú omi (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Have you ever seen a salamander?’ (Ǹjẹ́ o ti rí ẹranko bí aláǹgbá kékeré kan báyìí agbórí-ilẹ̀-gbórí-omi rí?)

salary:- owó ọ̀yá/owó iṣẹ́/owó oṣù (ọ̀rọ̀ orúkọ) ‘The teachers are asking for an increase in salary’ (Àwọn olùkọ́ ń bèèrè ẹ̀kúnwó sí owó-oṣù wọn)

sale:- ọjà títà/títà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a table for sale that I would like to buy’ (Tábìlì kan wà fún títà tí n ó fẹ́ láti rà)

salesman:- ọlọ́jà/olùtajà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I have told the saleman to show me the clothes’ (Mo ti sọ fún ọlọ́jà náà láti fi àwọn aṣọ náà hàn mí).

salmon:- ẹja odò tutu ńlá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Salmons swim up rivers to lay their eggs’ (Àwọn ẹja odò tutu ńlá máa ń wẹ̀ dókè odò láti yé ẹyin wọn)

salt:- iyọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘If you cook meat without salt; it does not taste so good’ (Bí o bá se ẹran láìní iyọ̀, kò lè dùn dáradára)

salty:- tíiyọ̀ já/oníyọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘This soup is too salty. I can’t take it’ (Iyọ̀ ti já ọbẹ̀ yìí. N kò le jẹ ẹ́)

salute:- kí/bẹ́rí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The soldier saluted his officer when he met him’ (Ọmọ-ogun náà bẹ́rí fún ọ̀gágun rẹ̀ nígbà tí ó pàdé rẹ̀)

salute:- ìkíni ológun/ìbẹ́rí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The soldiers stood in front of the flag and gave their salute’ (Àwọn ọmọ-ogun dúró níwájú àsìá, wọ́n sì ṣe ìkíni ológun wọn)

salvation:- ìgbàlà kúrò nínú ewu (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Let us pray for the salvation of the world’ (Ẹ jẹ́ kí á gbàdúrà fún ìgbàlà gbogbo ayé)

same:- ọ̀kan náà/kan náà (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘We eat the same food for breakfast every day’ (Oúnjẹ kan náà ni a máa ń jẹ ní àárọ̀ ní ojoojúmọ́)

sample:- àpẹẹrẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I’d like to see a sample of your work’ (N ó fẹ́ láti rí àpẹẹrẹ iṣẹ́ rẹ).

sample:-ṣàyẹ̀wò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I have sampled three sorts of mangoes’ (Mo ti ṣàyẹ̀wò irúfẹ́ máńgòrò mẹ́ta)

sand:- iyànrìn (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘The children were playing in the sand’ (Àwọn ọmọdé ń ṣeré lórí iyanrìn)

sandbank:- bèbè etí odì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Go and  stand at the sandbank’ (Lọ dúró níbi bèbè etí odò)

sandpaper:- bébà olójú-wúruwùru tí a fi ń dán ojú nǹkan (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You can use a sandpaper to smoothen its surface’ (O lè lo bébà olójú-wúruwùru láti dán ojú rẹ̀)

sandpit:- orí-iyanrìn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Children like to play on sandpit’ (Àwọn ọmọdé fẹ́ràn láti máa ṣeré lórí iyanrìn)

sandstone:- yangí (ọ̀rọ̀-oríkọ)

sandy:- kìkì iyanrìn (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ní iyanrin (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘This area is sandy’ (Kìkì iyanrin ni àdúgbò yìí)

sandal:- sálúbàtà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Bayọ has a yellow sandal’ (Báyọ̀ ní sálúbàtà aláwò-òfèéfèé kan)

sandwich:- búrẹ́dì aláwẹ́ tí a fi nǹkan mìíràn bọ̀ láàrin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Daniel ate an egg sandwich’ (Dáníẹ́lì jẹ búrẹ́dì aláwẹ́ tí a fi ẹyìn bọ̀ láàrin).

sane:- olórí-pípé/ọlọ́pọlọ-pípé/tí ó ní ọpọlọ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe ‘I don’t think a sane person would drive as he did’ (Èmi kò rò pé ọlọ́pọlọ-pípé ẹ̀dá kankan le wa ọkọ̀ bí ó ṣe wà á yẹn) (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)

sang:- kọrin (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He sang well today’ (O kọrin dáradára lónìí)

sanitary:- ní ìmọ́tótó/ti ìmọ́tótó/afọhun-mọ́tótó (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The little rooms all crowded together were not very sanitary’ (Àwọn yàrá kéékèèké tí ó fún pọ̀ wọ̀nyẹn kò ní ìmọ́tótó)

sank:- rì/mù/wọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ ti pẹ́) ‘The boat sank into the sea’ (Ọkọ̀-omi náà rì sínú omi).

sap:- oje igi (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This sap is from that mango tree’ (A rí oje-igi yìí láti ara igi mangoro yẹn)

sap:- òpònú ènìyàn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Wale is easily deceived becaused he is a sap’ (Wàlè kò ṣòro í tànjẹ nítorí òpònú ènìyàn ni)

sap:- fún gbẹ/fún mu (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The ho sun sapped our energy’ (òòrùn gbígbóná náà fún okun wa gbẹ)

sapele:- igi gíga tó wọ́pọ̀ ní Ìwọ̀ oòrùn Aáfíríkà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Sapele has red-brown wood with lines and patterns’ (Igi-gíga ìwọ̀ oòrùn Aáfíríkà yìí máa ń pọ́n pẹ̀lú àwọn ìlà àti bátànì)

sardine:- irúfẹ́ ẹja kékeré (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Sardines could be preserved in tins’ (A lè fi àwọn ẹja kéékèèké wọ̀nyẹn pamọ́ sínú agolo fún ọjọ́ pípẹ́ láìbàjẹ́).

sash:- ọ̀já/láwànì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Amina wore a red sash round her white dress’ (Àmíná wé ọ̀já pupa lórí aṣọ rẹ̀ funfun)

sat:- jókòó (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I sat by that tree in the morning’ (Mo jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi yẹn láàárọ̀)

satellite:- ẹ̀rọ oníná òfurufú tó ń ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ káàkiri ayé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The interriew came live by satellite’ (Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà wáyé lójú-ẹsẹ̀ nípa ẹ̀rọ òfurufú asọ̀ròyìn-àgbáyé)

satin:- aṣọ dídán gbinrin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Ladies like satin’  (Àwọn ọlọ́mọge máa ń fẹ́ràn aṣọ dídán gbinringbinrin)

satisfy:- tẹ́ lọ́rùn (ọ̀rọ̀-ìṣe) yó (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘That meal satisfied me’ (Oúnjẹ yẹn yó mi) ‘This work will not satisfy our teacher’ (Iṣẹ́ yìí kò ní í tẹ́ olùkọ́ wa lọ́rùn)

satisfaction:- ìtẹ́lọ́rùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘After the meal, he sat back with a smile of satisfaction on his face’ (Nígbà tó jẹun tán, ó jókòó pẹ̀lú ẹ̀rín ìtẹ́lọ́r`un lójú rẹ̀)

satisfactory:- dára/nítẹ̀ẹ́lọ́rùn/tí ó tẹ́nilọ́rùn (ọ̀rọ̀ àpèjúwe). ‘This work is satisfactory’ (Iṣẹ́ yìí tẹ́nilọ́rùn)

saturate:- kún, rin/rẹ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Saturate this clothes in soapy water’ (Rẹ aṣọ yìí sínú omi ọṣẹ) ‘Before I walked five minutes in the rain, I was saturated’ (Kí n tó rin ìrìn ìṣẹ́jú márùn-ún nínú òjò, aṣọ mi ti rin)

saturation:- ẹ̀kún (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘Has the well reached saturation?’ (Ṣẹ́ kanga náà ti dé ẹ̀kún ni?)

saturday:- Ọjọ́ tí ó kẹ́yìn nínú ọ̀sẹ̀/ọjọ́ ìsinmí àwọn Júù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We don’t go to school on Saturdays’ (A kì í lọ sí ilé-iwe ní gbogbo ọjọ́ tí ó kẹ́yìn nínú ọ̀sẹ̀)

sauce:- ọbẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The meat was cooked in a sauce of coconut  juice and peper’ (Wọ́n se ẹran náà nínú ọnẹ̀ olómi àgbọn àti ata).

saucepan:- ìkòkò/ìsaasùn/páànù ìsebẹ̀ 9ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Do not bring a dirty saucepan here’ (Má gbé ìkòkò tó dọ̀tí wá síbí o).

saucer:- àwo tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ife (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He has broken the saucer’ (Ó ti fọ́ àwo ìtẹ́ẹ̀-ife).

Sausage:- àdàlú ẹran gígún pẹ̀lú epò àti búrẹ́dì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Bíọ́lá has received two tins of sausage’ (Bíọ́lá ti gba agolo àdàlú ẹran gígún tepotibúrẹ́dì méjì).

sausage tree:- igi ilẹ̀ gbígbóná tó ń so èso lára ẹ̀ka (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I have never seen a sansage tree’ (N kò rí igi ilẹ̀ gbígbóná elésolẹ́ka rí)

savage :- ẹhànnà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The mad dog became savege’ (Ajá dìgbòlugi náà di ẹhànnà)

save:- :- fi pamọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘If you save money now, you will be able to buy a car later’ (Bí o bá fi owó pamọ́ nísinsìnyí, o ó le ra ọkọ̀ tó bá yá).

Save:- gbàlà (ọ̀rọ̀-ìṣè) ‘I save the dog from burning to death’ (Mo gba ajá náà là kúrò nínú jíjóná kú)

save:- ṣẹ́ kù/dá sí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We should save oil because of scarcity’ (Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ epo kù nítorí ọ̀wọ́n-gógó)

savings:- àpamọ́/ìpamọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘How much do you have in your savings?’ (Èlo ni o ní ní ìpamọ́ rẹ?)

saviour:- olùgbàlà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Jesus Christ is the saviour of the world’ (Jesu Kristi ni olùgbàlà aráyé).

saw:- rí (ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá) (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I saw him yesternight’ (Mo rí i ní alẹ́ àná)

saw:- ayùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘They used a saw to cut the big tree’ (Wọ́n fi ayùn gé igi ńlá náà)

saw:- rẹ́ igi/yùn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘They have sawn up the tree that fell down’ (Wọ́n ti rẹ́ igi tó wó lulẹ̀ náà).

sawmill:- ilé ìgégi (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a sawmill behing our house’ (Ilé ìgégi kan ń bẹ lẹ́yìn ilé wa)

say:- wí/sọ/ní (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘What are you saying? (Kín ni ò ń wí?)

saying:- wíwí/sísọ/ọ̀rọ̀ sísọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Accidents will happen’, as the saying goes’ (Ìjàmbá yóò wáyé’, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ sísọ ṣe lọ).

scab:- èèpo /èépá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a scab on your wound’ (Èépá ń bẹ lójú egbò rẹ)

scaffolding:- àkàsọ/àtẹ̀gùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This scaffolding is very high’ (Àkàsọ̀ yìí ga púpọ̀)

scald:- (ọ̀rọ̀-ìṣe) bu omi gbígbóná jó ‘Be careful not to scald yourself with the steam’ (Ṣọ́ra kí o má bu ooru gbígboná jó ara rẹ lé).

scale:- (ọ̀rọ̀-orúkọ) àmì ìwọ̀n  ‘The machine has a scale from 1 to 10’ (Ẹ̀rọ̀ náà ní àmì ìwọn láti oíkan sí ẹ̀wá.

scale:- ìpẹ́pẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Fish have scales’ (Àwọn ẹja máa ń ní ìpẹ́pé)

scales:- òṣùwọ̀n (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Put the bag of rice on the scales and see how mush it weights’ (Gbé àpò ìrẹsì náà sí orí òṣùwọn kí o lè mọ iye tí ó wọ̀n)

scalp:- awọ àti irun orí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I can see your scalp from here’ (Mò ń rí awọn àti irun orí rẹ láti ibi yìí)

scamper:- sáré kánmọ́kánmọ́/gbé ẹsẹ̀ kánmọ́-kánmọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The monkeys scamped away from us’ (Àwọn ọbọ náà sáré kánmọ́kánmọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa)

scan:- wò fínnífínní/wádìí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The soldiers scanned the country near the forest’ ( Àwọn ọmọ-ogun náà wo orílẹ̀-èdè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ igó náà fínnífínní).

scandal:- ohun ikọ̀sẹ̀/ẹ̀gàn/àbùkù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There was no hint of scandal during his reign’ (kò sí àyọ́wí ìwà àbùkù kankan lásìkò ìsàkóso rẹ̀).

scar:- àpá ojú egbò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Máyọ̀wá has a scar on his leg’ (Máyọ̀wá ní àpá kan ní ẹsẹ̀ rẹ̀)

scar:- /gba àpá/ gbé àpá/ ya (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The glass scarred his face in the accident’ (Díńgí náà ya á lójú níbi ìjàmbá náà).

scarification:- ìkọlà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I quickly knew his tribe by the scarification on his face’ (Mo tètè mọ ẹ̀yà rẹ nípa ìkọlà tó wà lójú rẹ̀).

scarce:- ṣọ̀wọ́n/ṣàìpọ̀/ṣàìwọ́pọ̀/wọ́n (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Lions have become very scarce in this part of African’  (Àwọn kìnnì-ún ṣàìwọ́pọ̀ ní apá ilẹ̀ Aáfíríkà yìí).

scarcely;- fẹ́rẹ̀/ṣàṣà/agbára kaka (ọ̀rọ̀ àpónlẹ́). ‘Since I left school, I have scarcely ever seen the teachers again’ (Láti ìgb`a tí mo ti fi ilé-ìwé sílẹ̀, mo fẹ́rẹ̀ má rí àwọn olùkọ́ náà mọ́)

scarcity:- ọ̀wọ́n (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is scarcity of kerosene in Ibadàn’ (Ọ̀wọ́n epo-òyìnbó wà ní Ìbàdàn)

scare:- dẹ́rùbà (ọ̀rọ̀-ìṣe) /bà ní ẹ̀rù (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I was scared of the big dog’ (Ajá ńlá náà dẹ́rùb bà mí).

scarecrow:- aṣọ́komásùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘That scarecrow looks exactly like a man (Aṣọ́komásùn yẹn jọ ènìyàn gan-an)

scare:- ẹ̀rù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I had a bad scare – I thought the bus was going to crash’ (Ẹ̀rù burúkú kan bà mí – Mo ti rò pé ọkọ̀ bọ̀gìnnì náà ń lọ foríṣánpọ́n ni)

scarf:- ìborùn/(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She put a scarf round his neck’ (Ó fi ìborùn wé ọrùn rẹ̀)

scarlet:- àwọ̀ òdòdó (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There were scarlet drops of blood on his shirt’ (Ìro ẹ̀jẹ̀ tó ní àwọ̀ òdòdó wà lára èwù rẹ̀).

scatter:- túká/fọ́nká (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Do not scatter the dirts on the floor’ (Ẹ má fọ́n àwọn ìdọ̀tí ká ilẹ̀ o)

scene:- ibi ìṣẹ̀lẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Let us go to the scene of the accident’ (Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibi-ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá náà).

scene:- ìran (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She witnessed some very interesting scenes’ (Ó ṣẹlẹ́rìí àwọn ìran kan tó dùnmọ́ni).

scene:-ìran eré-oníṣe (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The play has two acts and four scenes’ (Eré náà ní idán méjì àti ìran mẹ́rin)

scenery:- ìwò ilẹ̀/ìrí ilẹ̀ yíká (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The scenery of the mountains is very beautiful’ (Ìrí ilẹ̀ yíká àwọn òkè náà rẹwà púpọ̀)

scent:- òórùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The scent of the flowers filled the room’ (Òórùn òdòdó náà gba gbogbo yàrá)

schedule:- ìlànàètó (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The next thing on our schedule is to visit our friends’ (Ohun tí ó kàn lórí ìlànà ètò wa ni láti bẹ àwọn ọ̀rẹ́ wa wò)

scheme:- /ìlànà/ìmọ̀/èrò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He has a scheme to get some money’ (Ó ní ìlànà kan láti rí owó díẹ̀)

scheme:- gbèrò (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘These men were scheming against the king’ (Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń gbèrò láti lé ọba kúrò láàfin)

scholar:- akẹ́kọ̀ọ́/ọlọ́gbọ́n/ọ̀mọ̀wé (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He is the most distinguished scholar in English language’ (Òun ni ọ̀mọ̀wé tí ó ta yọ jù nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì).

scholar:-ajèrè-ẹ̀kó-ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Bíọ́lá is the only Nigerian scholar studying in America’ (Bíọ́lá nìkan ni ajèrè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ Nàìjíríà tí ó ń kàwé ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà)

scholarship:- àǹfààní láti kọ́wèé ọ̀fẹ́/ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘She won a scholarship to study Medicine at the Ọbáfẹ́mi Awólówò University’ (Ó jèrè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣègùn Òyìnbó ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀)

school:- ilé-ìwé/ilé-ẹ̀kọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This is my school’ (Ilé-ìwé mi nìyí)

science:- ìmọ̀/ọgbọ́n/òye/ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Modern science is advance’ (Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òde-òní ti gbìnàyá)

scientific:- ti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ /ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘We are carrying out a scientific research’ (À ń ṣe àgbéjáde ìwádìí ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀)

scientist:- onímọ̀ ìjìnlẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We have one scientist in our family’ (O nímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ni a ní nínú ẹbí wa).

scissors:- alùmọ́gàjí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Please give me a pair of scissors there’ (Dákun fun mi ní alùmọ́gàjí kan níbẹ̀yẹn).

scold:- bá wí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Mother scolded her for breaking the plates’ (Ìyá bá a wí fún àwo tí ó fọ́)

scoop:- awọ̀ (ọ̀rọ̀ -orúkọ) ‘She took rice from the bag with a scoop’ (Ó fi awọ̀ kó ìrẹsì jáde nínú àpò)

scoop:- wọ̀ jáde (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He quickly scooped the clothes from the chair’ (Ó wọ́n àwọn aṣọ náà jáde kíákíá kúrò lórí àga).

scorch:- jó fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I scorched the shirt when I was pressing it’ (Mo jó ẹ̀wù náà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ nígbà tí mò ń lọ̀ ọ́).

score:- ìṣirò/àròpọ̀ àbáyọrí, (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘What’s the score now?’ (Kín ni àròpọ̀ àbáyọrí nísinsìnyí?)

score:- ní àkọsílẹ̀ ayọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) /gba ayò wọlé ‘Martins scored two goals in the march’ (Ẹ̀ẹ̀mejì ni Martins gbá ayò wọlé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà).

scorn:- kẹ́gà/pẹ̀gàn/fi sẹlẹ́yà/fi ṣẹ̀sín (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He scorns the younger boys’ (Ó máa ń fi àwọn ọmọkùnrin kéékééké ṣẹlẹ́yà).

scorn:- ẹ̀gàn/àbùkù (ọ̀rọ̀-orúkọ) /àìbọ̀wọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He showed his scorn for my question by saying he would not answer it’ (Ó fi àìbọ̀wọ̀ rẹ̀ hàn sí mi pé òun kò ní í dáhùn ìbéèrè mi)

scorpion:- àkeekèé/òjògán (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Don’t play with a scorpin’ (Má fi àkeekèé ṣeré o)

scout:- amí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I know you are a scout here’ (Mo mọ̀ pé amí ni ọ́ níhìn-ín)

scout:- ọmọ ẹgbẹ́ aṣamí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Wálé is a scout  ‘he’s a member of the scouts’ (Amí ni Wálé –ọmọ ẹgbẹ́ àwọn Amí ni).

Scowl:- ṣóòkùn ojú sí/fa jú ro mọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Don’t scowl at me’ (Má fajúro mọ́ mi o).

scowl:- ìfajúro (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He looked up at me with a scowl’ (Ó gbójú sókè wò mí pẹ̀lú ìfajúro)

scramble:- pọ́n/gùn pẹ̀lú ọwọ́ àti ojúgun (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The children were scrambling up the mountain’ (Àwọn ọmọdé náà pọ́n òkè pẹ̀lú ọwọ́ àti ojúgun).

scrap:- ìwé àjákọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I wrote his name on a scrap’ (MO kọ orúkọ rẹ̀ sí orí ìwé àjákọ́ kan)

scrapbook:- ìwé tí a lè lẹ nǹkan mọ́/ìwé tí à ń lẹ nǹkan papọ̀ sí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He keeps his pictures in a scrapbook’ (Ó máa ń fi àwọn àwòrán rẹ̀ pa mọ́ sí inú ìwé tí à ń lẹ nǹkan papọ̀ si)

scrape:- ha/hán (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He scraped his car against that wall’ (ó fi ọkọ̀ rẹ̀ ha ogiri yẹn)

scratch:- ya léèkánná/họ/yún (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Could you help me scratch my back?’ (Ṣé o lè bá mi họ ẹ̀yìn mi?)

scratch:- apá híhọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Don’t worry; it’s only a scratch’ (Má ṣe ìyọnu; àpá híhọ kan náà ni).

scream:- kígbe/ké/han gooro (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I screamed with fear when the robber jumped on me’ (Mo han goor fún ẹ̀rù nígbà tí ọlọ́ṣà náà bẹ́ lé mi lórí).

scream:- igbe (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I heard a scream from that house’ (Mo gbọ́ igbe kan láti inú ìlé yẹn)

screech:- dún bí òwìwí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The car tyres screeched on the road’ (Táyà ọkọ̀ náà dún bí òwìwí lórí ọ̀nà)

screech:- dídún bí òwìwí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I heard the screech of the bird as it flew away’ (Mo gbọ́ dídún bí òwìwí ẹyẹ náà bí ó ṣe ń fò lọ).

screem:- ìbòjú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘How big is your television screen?’ (Báwo ni ìbòjú amóhùnmáwòrán rẹ ṣe tóbi tó?)

screw:- ìdè (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He hung his picture on the wall with two screws’ (Ó ti àwòrán rẹ̀ kọ́ ògiri pẹ̀lú ìdè méjì)

screw:- dè (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He screwed the picture onto the wall’ (Ó de àwòrán náà mọ́ ògiri)

scribble:- kọ ìkọkúkọ/kọ wúiruwùru (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘You have scribbled all over my book’ (O ti kọ ìkọkúkọ sí gbogbo ìwé mi)

scripture:- Bíbélì Mimọ/Ìwé Mímọ́/Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ‘The scripture says, ‘Help your neighbour’ (Ìwé Mímọ sọ pé, ‘Ran ọmọnìkejì rẹ lọ́wọ́).

scrub:- fọ̀/gbo (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The woman scrubbed her face with a piece of cloth’ (Obìnrin na gbo ojú rẹ̀ pẹ̀lú ìrépè aṣọ).

scrub:- aṣálẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ). ‘A farmer cannot grow crops in the scrub’ (Àgbẹ̀ kò lè rí irúgbìn kankan gbìn ní ilẹ̀ aṣálẹ̀).

Sculptor:- afínnà/eni tí ó ń gbẹ́ ère òkúta/oníṣọ̀nà òkúta (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I met the sculptor yesterday’ (Mo pàdá oníṣọ̀nà òkúta náà lánàá)

sculpture:- ọnà fífín/ère fífín (ọ̀rọ̀-orúkọ)/iṣẹ́ ọnà ère (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We bought a sculpture of a cow and two trees’ (A ra ère fífín màálù kan àti igi méjì)

sea:- òkun/omi-iyọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We live by the sea’ (À ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ òkun)

seabed:- ìsàlẹ̀-òkun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Do not swim to the seabed’ (Má wẹ̀ dé isàlẹ̀-òkun).

sealevel:- orí òkun/èkún òkún (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The sea-level rises during the raining season’ (Ẹ̀kún òkun a máa ga sí i lásìkò òjò).

Seaman:- atukọ̀ òkun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘My father is a seaman at Warri’ (Atukọ̀-òkun ni bàbá mi ní Warri’

Seaport:- èbúté òkun/ìgúnlẹ ọkọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Lagos and PortHarcourt are both seaports’ (Èbúte òkun ni Lagos àti Port Harcourt)

seashell:- ìkarahun ẹja tó ń gbé nínú òkun (ọ̀rọ̀-orúkọ) /ikarahun ẹ̀dá okun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I love the sight of a seashell’ (Ìkarahun ẹ̀dá òkùn wù mí láti wò)

seaside:- ẹ̀bá òkun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We shall visit the seaside during the holiday’ (A ó ṣe àbẹ̀wò sí ẹ̀bá òkun nígbà ìsinmi).

seal:- Ẹranko òkun tó ń jẹ ẹja tó sì ń gbé agbègbè òkun (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘A seal lives in the sea coasts’ (Ẹranko-ọ̀kun máa ń gbé ní agbègbè okun)

seal:- fi èdìdí dí (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘This tin is sealed so that air cannot get in’ (Wọ́n ti fèdìdí dí agolo yìí kí afẹ́fẹ́ ma baà wọlé)

seam:- ojúràn-án (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The seams of the shirt are not neat’ (Àwọn ojúràn-án ẹ̀wù náà kò dán)

search:- wá kiri (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I searched everywhere for my book but could not find it’ (Mo wá ìwé mi káàkiri ṣùgbọ́n n kò rí i).

search:- ìwákiri/wíwá-kiri/ìwádìí/àwárí (ọ̀rọ-orúkọ) ‘After a thorough search, the police found the missing boy’ (Lẹ́yìn wíwá-kiri tí ó dunlẹ̀, àwọn ọlọ́pàá rí ọmọdẹ́kùnrin tí ó sọnù)

season:- ọ̀tẹ̀/ àkókò kan ní ọdún/ìda-yìí/sáà/àsikò/ìgbà/ìwòyí (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Mangoes are in season new’ (Àsìkò máńgòrò nìyí o)

seasonal:- ti àkókò/ti ìgbà /ti ọ̀tẹ̀/ti sáà (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘There are seasonal changes in the weather’ (Àwọn ìyípadà ti àkókò máa ń wà ní ojú ọjọ́)

seat:- ìjókòó/àga (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Wálé can’t find any seat’ (Wálé kò rí ìjókòó kankan)

second:- ìṣẹ́jú (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Wait a second! (Dúró fún ìṣẹ́jú kan!).

second:- èkejì/ẹ̀ẹ̀kejì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Bíọ́lá came first in the class, I came second’ (Bíọ́lá ṣe ìpò-kìíní nínú kíláàsì, mo ṣe èkejì)

secret:- ohun ìkọ̀kọ̀/àṣírí/bòńkẹ́lẹ́/abẹ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) níkọ̀kọ̀/lábẹ́lẹ̀/láṣìírí (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘He has a secret that no one knows’ (Ó ní àṣírí kan tí ẹnìkẹ́ni kò mọ̀) ‘The woman wrote me a secret letter’ (Obìnrin náà kọ lẹ́tà ìkọ̀kọ̀ kan sí mi)

secretary:- akọ̀we (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Tell the secretary to type the letter immediately’ (Sọ fún akọ̀wé kí ó tẹ lẹ́tà náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀).

section:- ababla/apá kan/ọ̀wọ́/ìpín (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Try and read the concluding section of the book’ (Gbìyànjú kí o ka abala tí ó gbẹ̀yìn nínú ìwé náà)

secure:- láìléwu/làìfòyà/láìbẹ̀rù (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘I know I’m secure with two dogs’ (Mo mọ̀ pé mo wà láìléwu pẹ̀lú ajá méjì)

security:- ààbò (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The government looks after the security of the country’ (Ìjọba ń ṣiṣẹ́ ààbò orílẹ̀-èdè).

see:- rí/reran (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘If you look for me, you will see me’ (Bí o bá wá mi, o ó rí mi)

see:- ní òye (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I don’t see what you mean’ (N kò ni òye ohun tí o ní lọ́kàn)

seed:- irúgbìn/irú ọmọ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I planted some vegetable seeds last month’ (Mo gbin irúgbìn ẹ̀fọ́ díẹ̀ lóṣù tó kọjá).

seedling:- èèhù (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The farmer requests for some seedlings’ (Àgbẹ̀ náà bèèrè fún àwọn èèhù díẹ̀).

seek:- wá kiri/bèèrè (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Drivers are advised to seek alternative routes’ (Wọ́n gba àwọ awakọ̀ níyànjú láti wá ọ̀nà mìíràn gbà).

seem:- bí ẹni pé/ṣe àfihàn/dàbí/jọ pé (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The man seems to be ill’ (Ó jọ pé ara ọkùnrin náà kò dá)

seep:- jò dànù (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The bottle is broken and the water seeped away’ (kòròǹdodo ti fọ́, omi sì ti jò dànù)

seesaw:- pákó alágbede méjì (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The children are playing at the seesaw’ (Àwọn ọmọdé ń ṣeré níbi pákó alágbede méjì)

seize:- fi agbára gbà/gbá mú/mú ní ipá (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He seized the girl by the arm’ (Ó gbá ọmọbìnrin náà lápá mú)

seldom:- lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan/dígbà (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) ‘They seldom watch television these days’ (Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa ń wo amóhùnmáwòrán lẹ́nu ọjọ́-mẹ́ta yìí)

select:- ṣàyàn (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I was selected for the school team’ (Wọ́n yàn mí fún ẹgbẹ́ aṣojú ilé-ìwé).

selection:- àṣàyàn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Take one of the selection of books’ (Mú ọ̀kàn nínú àwọn àṣàyàn ìwé wọ̀nyí)

self:- tìkara-ẹni/ara ẹni (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He can’t look after himself’ (Kò lè tọ́jú ara rẹ̀).

selfish:- tí ó mọ ti ara rẹ̀ nìkan (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘Don’t be selfish’  (Má mọ ti ara rẹ nìkan).

selfishness:- ìwà ìmọ-ti-ara-ẹni-nìkan (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘No one likes her because of her selfishness’ (Kò sí ẹni tó fẹ́ràn rẹ̀ nítorí ìwà ìmọ-tì-ara-ẹni-nìkan rẹ̀).

sell:- tà (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She sold it to me for N100’ (Ó tà á fún mi ní ọgọ́rùn-ún náírà)

seller:- olùtà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The seller has gone to pray. Come back later’ (Olùtà ti lọ gbàdúrà. Padà wá bí ó bá ṣe díẹ̀ síi)

semicircle:- ìdàjì òbìrìkítí/ìlàjì àwòrán roboto (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We sat in a semicircle round the fire’ (A jókòó ní ìdàjì òbìrìkìtí yí iná ká)

semicircular:- oníajì obìrìkítí (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘The moon is semicircular’  (Òòrùn wà ní onídajì òbìrìkìtí)

semicolon:-àdàmọ̀dì kólọ́ọ̀nu (ọ̀rọ̀-orúkọ) Put a semicolon here’ (Fi àdàmọ̀dì kólọ́ọ̀nù síbí)

seminary:- ibi ìkọ́ni àlùfáà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘I was at the seminary two years ago’ (Mo wà ní ilé-ìkọ́ni àlùfáà ní ọdún méjì sẹ́yìn).

senate:-àjọ ìgbìmọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ)/ilẹ́ ìgbìmọ̀ aṣọfin ‘Does the senate make lawa?’ (Se àjọ ìgbìmọ̀ máa ń sọ̀fin ni?).

senator:- ọmọ àjọ ìgbìmọ̀/ọmọnilé-ìgbìmọ̀ aṣofin (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Tinubu was once a senator in Nigeria’ (Ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣofin ni Tinúbu nígbà kan).

send:- rán lọ/rán níṣẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘I have sent Bólú to the market’  (Mo ti rán Bólú ní ọjà) .

senior:- ẹ̀gbọ́n/àgbà/aṣaájú (ọ̀rọ̀     ‘He is my senior’ (Aṣaájú mi ni)  ‘This is Mr Adémọ́lá senior’ (Ọ̀gbẹ́ni Adémọ́lá àgbà nìyí)

sense:- òye/ìmọ̀/ọgbọ́n/èrò (ọ̀rọ̀ orúkọ) ‘He has a good sense of smell’ (O ní òye òórùn gidi)

sensation:- ìmọ̀/àìbalẹ̀-ọkàn  (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You caused a sensation when you didn’t wake up on time’ (O dá àìbalẹ̀-ọkàn sílẹ̀ nígbà tí o kò tètè jí)

sensible:- lóye/gbọ́n/ní ìmọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘If you are sensible, you will study for another year’ (Bí o bá gbọ́n, o ó kàwé fún ọdún mìíràn)

sensitive:- ní ìfura/tètè mọ̀ lára/ìyàra ní ìmọ̀ (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘She is sensitive to what people say of her’ (Ó ní ìfura ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa rẹ)

sense:- mọ̀ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘The dog could sense that I was afraid of it’ (Ajá náà mọ̀ pé ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí)

sensitive plant:- patanmọ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘You can’t find a sensitive plant here’ (O kò le rí patanmọ́ níbí)

sentence:- gbólóhùn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Can you write a meaningful sentence?’ (Ṣé o lè kọ gbólóhùn tí ó ní ìtumọ̀ kan?).

sentence:- dá léjọ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘He was sentenced to one year imprisonment’ (Wọ́n dá a lẹ́jọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún kan)

sentry:- aṣọ́de/adènà (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘There is a sentry out there’ (Aṣọ́de kan ń bẹ níta níbẹyẹn)

separate:- ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ (ọ̀rọ̀-àpèjúwe) ‘They have gone to separate places’ (Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ibi tí wọ́n lọ)

separate:- pín níyà/yà sọ́tọ̀/yà nípa (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘She separated the rice from the bean’ (Ó ya ìrẹsì nípa kúrò lára ẹ̀wà) ‘Don’t separate me from my parents’ (Má pín mi níyà pẹ̀lú àwọn òbí mi)

september:- oṣùkẹsàn-án ọdún/ọ̀wẹ́wẹ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘My birthday comes up in Septermber’ (Ọjọ́-ìbí mi yóò wáyé ní oṣù ọ̀wẹ́wẹ)

septic:- jẹrà (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘An untreated cut may go septic’ (Egbò tí a kò tọ́jú le jẹrà).

sequence:- ìtọ̀lẹ́yìn/ìtò (ọ̀rọ̀-orúkọ)/ṣísẹntẹ̀lé(ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘He described the sequence of events that led to the robbery’ (ó sàpèjúwe àwọn ìṣíṣe iṣẹ̀lẹ̀ tó fa olè jíjà náà)

sergeant:- oyè ológun/oyè kan nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá ‘A sergeant can command other soldiers’ (Ọmọ-ogun olóyè sájẹ́ǹtì le darí àwọn ọmọ ogun yòókù).

serial:- àtẹ̀léra (ọ̀rọ̀-oríkọ) /eré oníṣe onípele (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘This is the second part of the serial’ (Apá kejì eré onípele náà nìyí).

series:- ìtẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ/ọ̀wá (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The recent series of events is worlthy of note’ (Àwọn ọ̀wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àsìkò yìí ń fẹ́ àkíyèsí)

serious:- wúwo /ṣe pàtàkì /tóbi/ní ìrònú (ọ̀rọ̀ àpèjúwe) ‘There is a serious matter to discurs’ (Ọrọ̀ pàtàkì kan wà tí a ó jọ sọ)

seriously:- pẹ̀lú ìrònú/pẹ̀lú ọ̀wọ̀/tọkàntọkàn, gidi gan-an ‘They are seriously rich’ (Wọ́n ní owó gidi gan-an) ‘Please do that job seriously’ (Jọ̀wọ́ ṣe iṣẹ́ yẹn tọkàntọkàn).

sermon:- ìwàásù/ọ̀rọ̀ ìyànjú/ìkìlọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘When the sermon is over, we shall sign’ (Nígbà tí ìwàásù bá pari, a ó kọrin)

serve:- ṣe iṣẹ́ fún/sìn/ṣe ìránṣẹ́ (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘We promise to serve our country’ (A ṣe ìlérí pé a ó sin orílẹ̀-èdè wa) ‘The girl in that house is serving the old man’ (Ọmọbìnrin tí ó wà nínú ilé yẹn ń ṣe ìránṣẹ́ fún bàbá arúgbó náà)

serve:- gbé oúnjẹ fún (ọ̀rọ̀-ìṣe) ‘Have you served my visitiors?’ (Ǹjẹ́ ẹ ti gbé oúnjẹ fún àwọn àlejò mi?)

servant:- ìránṣẹ́/ọmọ-ọ̀dọ̀ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘Their servant cooks and cleans the house’ (Ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn máa ń dáná ó sì máa ń tọ́jú ilé)

service:- ìsìn/iṣẹ́ (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘We need the services of a doctor’ (A nílò iṣẹ́ dókítà kan).

service:- iṣẹ́ ìsìn (ọ̀rọ̀-orúkọ) ‘The food was good but their service was very slow’ (Oúnjẹ náà dára ṣùgbọ́n iṣẹ́-ìsìn wọn kò jáfáfá).

No comments:

Post a Comment