Bí
mo ṣe dákẹ́ ìyẹn ni àyà mí tún lù kìkì. Mo ní, kí ni wọ́n tilẹ̀ wáá rí tí ó
fi jẹ́ pé èmi ni wọ́n wáá pè pé ki ń wáá sọ̀rọ̀ nípa oríkì? Mo ní àbí nítorí pé
wọ́n gbọ́ pé mo bí ọmọ kan nídun-ùnta ni wọ́n ṣe rò pé èmi náà ti dàgbà ọ̀
jẹ̀. Àwọn àgbà bí Adébòyè Babalọlá (1966, 1967), lẹ́yìn àwọn òpìtàn bíi
àlùfáà Samuel Johnson (1921), ṣáà ti tẹnu mọ́ ọn pé àwọn àgbàlagbà ní í ki
ọmọdé. Èmi ò sì tí ì tó ẹni tí í máa ki ènìyàn; ẹni kan náà tí mo sì lè kì
kò í tí ì gbédè tán-an re, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í sábà sunkún àsunùndabọ̀ tí a fi lè
wí pé mo ti lè máa gbé e jó, bí Babalọlá (1966,25) ti tún ní àwọn àgbà máa ń
ṣe, tí wọn ó ki irù ọmọ bẹ́ẹ̀ ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá, torí rẹ̀ yóò wú
(láìgbédè), ti yóó sì fẹnu mọ́nu. Kí wáá ní wọ́n rí o?
Mo
tún ọ̀rọ̀ náà rò, mo ní, àbí wọ́n tún hugbọ́ pé bóyá mo ti bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe
àkójọpọ̀ oríkì, irú èyí tí ẹnì kan kò sí tíì ṣe rí ni? Nítorí pé, bí kò bá
ṣe bẹ́ẹ̀, kò yẹ kí wọ́n ó tún pe ẹnì kankan, kí á tóó wáá pé èmi, láti tún
wáá ṣàròyé lórí ohun tí gbogbo ọmọ káàárọ̀-oò-jí-i-re mọ̀ bí ẹni mowó. Bí a
bá wo sààsùun rẹ̀, a ó ṣàkíyèsí pé ó fẹ́rẹ̀ má sí ohun kan tí ẹnì kan le tún pé
òun lá àlá ri nípa oríkì lẹ́yìn gbogbo nǹkan tí àwọn aṣíwájú wa gbogbo ti
sọ, tí wọ́n sì ti kọ sílẹ̀ fún wa kà lórí ọ̀rọ̀ yìí kan náà. Àwọn bíi Àlùfáà
Samuel Johnson (1921( tí a dárúkọ tán nísìnyìí), Adébóyé Babalọlá (1956,
1963, 1966, 1967, 1974, etc.) àwọn Alayé bíi Tìmì Adétóyèṣe Láoyè tó wàjà
(1963), B.L. Láṣebìkan (1958), P.O. Ògúnbọ̀wálé (1962), Bákàrè Gbàdàmọ́sí
(1961), C.L. Adéoyè (1969), àti àwọn aláròóò bí Ulli Beier (1959) àti Pierre
Fatumbi Verger (1967), kí á tóó wáá kan àwọn akéwejẹ̀ bíi Wándé Abímbọ́lá
(1968), Bọ́láńlé Awẹ́ (1974), Olúdáre Ọlájubù (1972), Ọlátúndé Ọlátúnjí
(1968 ; àti èyí tí ń bọ̀ lọ́nà), Adébáyọ̀ Ọláyọmi (1968) Láwuyì Ògúnníran
(1972), òun Túnjí Vidal (1969) tó fi orìn
ṣòwò ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni, ogunlọ́gọ̀ náà ló ti fi ohùn sílẹ̀ lórí oríkì yìí náà tí a
kò sì tíì mẹ́nu bà. Kí wáá ni ohun àrà tí ẹnìkan le tún pé òun gbé dé nípa
rẹ̀?
Níwọ̀n
ìgbà tí ó sì jẹ́ pé èmi náà kò tíì máa fi taratara ṣe àkójọpọ̀ oríkì, nítorí
gbédègbẹ́yọ̀ lèmi, ọ̀nà-ọ̀fun ènìyàn lèmi í sì í máa wò bi wọn bá ti ń sọ̀rọ̀
kí n lè mọ bí wọ́n ṣe í ṣẹnu wí i, èmi yóò kàn tẹ̀ ẹ́ básubàsu ni, bí àṣà
kan òkè ọ̀hùn, ni n ó bá dákẹ́, ni a ó wá jọ máa tàkurọ̀ sọ, tí èmi náà yóò
fi rí ẹ̀kọ́ kọ́ nípa oríkì láti ọ̀dọ̀ gbogbo ẹ̀yin bọ̀rọ̀kìní akéwèé tí ẹ wà
níjokòó.
OHUN TI ORIKI JẸ́
Bí
ó bá yẹ̀ ní Babalọlá (1966, 24; 1967, 11f) àti àlùfáà Johnson (p.87), ṣààṣàa
ni ìwé tí ó wà ńlè lórí oríkì lónìí tí kò ní í sọ pé oríyìn ẹni ni oríkì wà
fún. Bí a bá sì wá kíyè sí ọ̀rọ̀ náà náà dáadáa a ó gbà bí Johnson (1921) ti wí
pé:
When the orúkọ (name) the oríkì and the orílè (totem) are
given, the individual becomes distinctive, the family is known, and he can at
any time be traced. … The man is universally known by his orúkọ (name)
familiarly by his oríkì (attributive) (p. 87).
Níwọ̀n
ìgbà tí àkàwé kì í pa ẹni lára, a lè sọ pé bí nọ́ńbà ti jẹ́ sí àwọn ará
Amẹ́ríkà, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ, oríkì, àti orílẹ̀ jẹ́ sí àwọn Yorùbá. Ní ilẹ̀ Amẹríkà,
tí o bá ti mọ nọ́ńbà ètò èèsè ìfẹ̀yìntì (social security number) ènìyàn, tí o
sì mọ nṇ́ńbà láńsẹ́ẹ̀sì àti ti tẹlifóònù rẹ̀, ó ti mọ̀ ọ́n tán. Bẹ́ẹ̀ ni ti
orúkọ, oríki, àti orílẹ̀ jẹ́ láàrin àwa Yorùbá.
Bí
àpẹrẹ ohun tí Johnson ń wí: Ọlásopé kún ilé ayé, ṣùgbọ́n Ọlásopé Àkànbí kò
wọ́ pọ̀. Bí Ọlásòpé Àkànbí sì pé méjì mẹ́ta, Ọlásopé Àkànbí Ògún kò lè pé
méjì. Bí a bá tilẹ̀ tún wáá pè é lápètán, tí a ní ‘Ọlásopé, Àkànbí Ògún, ọmọ
Batẹ̀ tí í joyè’, ó ṣòro kí á tóó rí ẹyẹ méjì tí í jẹ́ adìẹ lábẹ́run ayé
yìí ni èyí. Bí a bá tò ó bí Johnson (1921) ti tò ó, Ọlásopé ni orúkọ, Àkànbí
ni oríkì, Ògún (ọmọ Batẹ̀ tí í jóye) ni orílẹ̀ ti èmi
Ọmọ Àrẹ̀ó Ògún
Ọmọ ‘Mọsùnọ́lá
Abínúwáyé
Agbóróọdẹmújẹ́
Igbá dá kọ̀ kọ̀ máà ya
Mọba kùkùté ga lóde
Kò ga nínú
Ọba bẹ́ẹ̀kẹ́ bí odi ẹlẹ́mọ
Ẹni mi kùkùté ara rẹ̀ ló mì
Abániwíjọ́ ara wọn ni wọ́n ń ṣe
Ọ̀wọ́ Ilàrí baba Àpésìn
Ọ̀wọ́ tọ́kọ̀sìn baba Oyèéfàbi
Má ya,
Igbá dá kọ̀ kọ́ ya.
Ṣùgbọ́n
kí n tóó mẹ́nu ba ìyàtọ̀ tí mo rí láàrin orúkọ oríkì, àti orílẹ̀, tàbí ohun tí
ó pa wọ́n pọ̀, mo fẹ́ẹ́ ṣọ̀yájú díẹ̀, kí n sọ ìdí tí a fi lè wí pé bíi a ṣe
í pe ni tún ṣe pàtàkì lọ́nà kan láàrin àwa Yorùbá ju bí nọ́ńbà ṣe jẹ́ láàrin
Àmẹ́ríkà lọ, bí ó tile jẹ́ wí pé nọ́ńbà ti di Ọlọ́run wọn nílẹ̀ ibẹ̀.
Yorùbá
gbàgbọ́ pé gbogbo ohun tí Olódùmarè dá pátá porongodo ni ó ní agbára: àti ohun
abẹ̀mi ni o, àti ohun tí kò ní ẹ̀mi ni, tí ó fi kan igi oko, afẹ́fẹ́, òkúta,
erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ pàápàá tí à ń sọ lẹ́nu; gbogbo rẹ̀ ni Olódùmarè fún ní
agbára ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, tí ti ọ̀kan kò sí jọ ti èkejì.
Yorùbá
sì tún wáá gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn àti gbogbo nǹkan ni ó ní kinní kan tí a lè
pè ní ‘ọrun ẹni’. Èyí já sí bíi àṣíri ẹ̀dá nǹkan kọ̀ọ̀kan tí Olódùmarè dá
sí ilé ayé. Lóòótọ̀, a gbàgbọ́ pé Ọ̀rúnmìlà-Baru, àgbọnnìrègún, Akèrè-fi-nú-ṣọgbọ́n,
òun nìkan náà ni ẹlẹ̀rìí ìpín. Òun nìkan ni ó mọ àṣiri ẹ̀dá gbogbo ohun tí
Olódùmarè dá sínú ayé. Síbẹ̀ Olódùmarè fi gbogbo nǹkan yòókù pátá jíǹkí ọmọ
ènìyàn ni.
Gbogbo
agbára tí Ẹlẹ́dàá fún ohun kọ̀ọ̀kan pátá ni ó sì wà ní àrọ́wọ́tó ọmọ ènìyàn láti
lè lò wọ́n fún àǹfààní ara wa. Aká wáá ṣe, a níláti mọ àṣírí ẹ̀da tàbí
ọ̀run ohun kan, tàbí ẹlòmíràn náà, tí a bá fẹ́ẹ́ lo agbára tí ẹlẹ́dàá fún un
láti ṣe ara ẹni ní àǹfààní.
Ifá
ni àwọn baba wa á tọ̀ lọ fún irú àṣírí bẹ́yẹn; òun náà ni ó sì dà bí ẹni
pé ó fi lé wọn lọ́wọ́ pé a níláti pe nǹkan ní àpè-kan-ọ̀run-rẹ̀ kí ó tóó lè
yọ̀ǹda agbára rẹ̀ fún ni. Oríkì yìí náà wáá jẹ́ kọ́kọ́rọ́ ọ̀run ẹni.
Ìdí
nìyí tí oríkì fi ṣe pàtàkì láàrín àwa Yorùbá. Níwọ̀n ìgbá tí ó sì jẹ́ pé ara
ọ̀run ẹní ni ibi tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí ohun ẹ̀dá yòówù kí ó lè jẹ́ ti ṣẹ̀,
àti gbogbo ìwò, ìṣe, tí ó fi kan àkójọpọ̀ ohun tí a lè pè ní ìwà rẹ̀, kò tọ́
kí á pe oríkì ní oríyìn. Ṣé gbogbo wa náà ni a ṣá gbà pé kì í ṣe gbogbo
nǹkan tí ó wà lábẹ́run ayé yìí ni a lè wí pé ìwò, ìṣe, àti ìwà rẹ̀ wuyì, tàbí
tí ó lè wú ni lórí kò sì dí ìgbà tí ènìyàn bá lókìkí, kí ó tóó ní oríkì. Bẹ́ẹ̀
ni gbogbo nǹkan pátá ni ó ní oríkì.
Bí
ọdẹ́ bá fẹ́ẹ́ lọ sí ìgbẹ́ àrèpa, bí ò bá pe ìbọn ní bíí ti í jẹ́, ó gbàgbọ́
pé ìbọn kò ní í ṣàìjẹ́ òun bí ó ti wù kí ó ṣòro tó. Oníṣègùn gbàgbọ́ pó bí
àrùn náà ti wù kí ó burú tó, bí a pè é bí í ti í jẹ́, yóò gbọ́ ògùngùn. Bí a bá
pe ewé bí í ti í jẹ́, kò ní í sunko, ohun yòówù kí a fẹ́ fi ṣe.
A
tìlẹ̀ lè sọ pé ìgbà ti onílù bá ki ni, tí orí ẹni wú, ìgbà náà ni ewu ń wu ni
jù láyé yìí; nítorí pé kò sí ohun tí wọ́n lè pé kí a ṣe ní àsìkò yẹn tí yóò
fi ni lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ohun tí ẹni pe ni fẹ́ẹ́ ṣe sí ni, tàbí tí ó
fẹ́ẹ́ fi ni ṣe, tí ọwọ́ rẹ̀ kò níí ká.
Yorùbá
sì tún wá gbàgbọ́ pé gbogbo ibi tí ènìyàn tábí nǹkan yòówù kí ó jẹ́ kò sí,
ẹlẹ́dàá rẹ̀ wà níbẹ̀. Orí ni àdàpé ẹlẹ́dàá fún ọmọ ènìyàn. Níwọ̀n ìgbà tí ó
sì jẹ́ pé bí etí ènìyàn di, tí ẹlẹ́dàá rẹ̀ kò di, kò di ìgbà tí nǹkan tí a bá
fẹ́ẹ́ mú lò bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹni kí á tó lè pe agbárí rẹ̀ mú lò.
ORIṢII ORIKI
Ki
wáá ní ìyàtọ̀ láàrin orúkọ, oríkì àti orílẹ̀?
A lè pé orúkọ ni àmì ọ̀rọ̀ tí gbogbo ayé mọ̀ mọ́ ni, tí ó jẹ́ pè bí
wọ́n bá pè a ó jẹ̀ẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n bí ìyàtọ̀ kan dan-in-dan-in tilẹ̀ wà láàrin
oríkì àti orílẹ̀, a ó fi ara mọ́ àlàyé Adébóyè Babalọlá (1967), pé oríṣì
oríkì kan ni orílẹ̀.
Ó ní:
Orílẹ̀ ènìyàn, láàrin àwọn Yorùbá, ni àpapọ̀ àwọn baba-ńlá
àti àwọn ìyá-ńlá tí ó ti wà ní ìbẹ̀rẹ̀-pẹ̀pẹ̀ ìtàn ìdílé olúwarẹ́. Oríkì
orílẹ̀ sì jẹ́ oríkì jáǹtìrẹrẹ tó júwe ìwà, ìṣe àti àrà àwọn baba-ńlá àti
ìyá-ńlá tí à ń sọ̀rọ̀ bá wọ̀nyí yóò lọ sẹ́hìn dé ayé àtijọ́ gan-an kété lẹ́hìn
tí Ọ̀rànyán tẹ Ọ̀yọ́ Ilé dó,…(p12)
Lójú
tèmi, oríṣi oríkì mẹ́ta ni ó wà. Èkíní ni èyí tí a lè pè ní oríkì àdájẹ́ tàbí
oríkì àbísọ. Èyí nìkan ni Johnson pè ní oríkì. Àpẹẹrẹ irú èyí ni Àkànbí, ti
mo ti mẹ́nu bà lókè lẹ́ẹ̀kan, àti Àṣàkún, Àbẹ̀ní, Àrẹ̀ó, bí ẹ ti lè rí ì nínú
ìwé Johnson tí mo ti pe àkíyèsí yín sí, àti ti Adéoyè (1969) tí ó tẹ̀lé Johnson
pẹ́pẹ́, àti tí Ọláyọmí (1968) náà. Ti ọkùnrin wà, tí obìnrin náà sì wà bí
àwọn ìwé wọ̀nyí ti ṣe àlàyé. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin ní í jẹ́ Àṣàkún tàbí
Àbẹ̀ní; ọkùnrin nìkan ni a sì í kì ní Àkànbí, tàbí Àrẹ̀ó.
Oríṣi
oríkì kejì ni a lè spè ní àlàjẹ́[3]. Èyí ni àdàpè orúkọ tí a fún ẹni tí ó jẹ́
orúkọ kan rí, tí a wáá ń fi pe gbogbo ẹni tí ó bá tún ń jẹ́ orúkọ yẹn lẹ́yìn
rẹ̀. Ó lè jẹ́ ìtorí ìwà ẹni àkọ́kọ́, tàbí bí ó ṣe rí, tàbí nítorí iṣẹ́ rẹ̀ ni
wọ́n ṣe fún ẹni náà ní àdàpè yẹn. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo ẹni tí í bá á jẹ́
Àjàyí ni à ń dà pè ní Ògídí Olú, tí àpèjá rẹ̀ sì jẹ́:
Ògídí Olú,
Oníkànga àjípọn,
Ò bomi òsùùrù wẹdà.
Ẹni Àjàyí gbàgbà,
Tí kò le gbà tán,
Ikú ní í gbalúwa rẹ.
Àjàyí, alose nígbàgede
Bámìkọ́lé, abọdán í kẹfun.
Ògídí Olú, Dára-módù.
Bẹ́ẹ̀ sì ni
gbogbo ẹni tí í báá jẹ́ Adéagbo ní à ń kì ní
Adéagbo
Òtéńjù
Alátọ̀sí májòóbògbẹ
Àdéagbo
Abàtọ̀sí í yàtọ̀[4]
Bí
ẹ ó ṣe rí i nínú ìwé Adéoyè (1969) àti ti Gbàdàmọ́s (1961), kò dájù pé orúkọ
Yorùbá tí kò ní àlàjẹ́ wọ́ pọ́.
Ò
dà bí ẹni pé bíi orúkọ ẹ̀fẹ̀ tàbí ìnagijẹ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàjẹ́ sábà í
bẹ̀rẹ̀. Ó sì ní ohun tí ẹni tí a fún lórúkọ bẹ́ẹ̀ yẹn ṣe kí á tóó panu pọ̀
pè é bẹ́ẹ̀, bíi ti Adéagbo. Inagijẹ ni bíi àdàpè tí ó ń tọ́ka ìṣe, ìwà tàbí
ìwò bí mériìírí tí a mọ̀ mọ ẹni. Irú nǹkan báyìí lè jẹ́ ohun àbùkù bíi ti
Adéagbo, tàbí ohun ẹwù bíi àdàpè tí àwọn obìnrin-ilé máa ń fún àwọn ọmọdé
tí wọ́n bá nílé tí wọn ko sì gbọdọ la orúkọ mọ́ lórí. Àpẹẹrẹ:
(a) (i) ayílukọ - ọmọbìnrin
tó lómira
(ii) awélẹ́gbẹ̀ẹ́ - ọmọbìnrin tó
ga tí kò lára, tó sì lẹ́wà.
(iii) tòbíàrán -
ọmọbìnrin tí aṣọ yẹ.
(b) (i) ajókòó-tàgbà-máà-jupè-rán-níṣẹ́
(ii) àtàrí-ò-jóòrùn-ó-ràn.
Oríkì
orílẹ̀ ni oríṣi kẹta. Mo sì ti tọ́ka sí èyí lẹ́ẹ̀kan bí Babalọlá (1967) ti
ṣe àlàyé rẹ̀. Ẹ wo orílẹ̀ ìran Ajíbógundé yìí wò:
Oríkì Ìran Ajíbógundé
Èmi ò lè ṣe kí n má pè ó o.
Ó wá jọ ilé àwọn baba mi.
Ó jọ’lé Ògúnjùmọ̀ní
Alósọòópọ̀bọ
5 O jọ’lé
Afẹ́bíọyẹ́ o, Ọ̀jẹ̀dìran.
Ó jọ’lé Àtàndá onídà í-muẹ̀jẹ̀ẹran
Àtàndá abidà í-jẹ̀jẹ̀ ènìyàn
Idígegele kó oògùn sí ọkọ
Ẹbẹ̀lókù.
Ọ̀rẹ́ mi ń bẹ ní’hà ibikan.
Làgbàyí ọmọ Abóròkòlówólọ́wọ́
10 Tí n bá ń lọ
ilé òrẹ́ mi, Kújẹmré.
Ọmọ Ẹlẹ́jọ́awúju.
Ọkùnrin tààrà kanlẹ̀ n’Sàlẹ̀ Ọ̀wọ̀n
Lóseé, mo sédò n ò pẹja.
Òsé, mo sédò n ò pakòrò.
15 Òsé wọn i-sé
dò iwájí ‘mọ Kújẹmrá.
Lòsé la sé gbogbo odò léhìn
Òsé Làgbàyí mo sé gbogbo odò láàrin, baba wá ń roko
lágbadagbúdú omi.
Ọmọ
arùgbó kan sè ọbẹ̀ lọ́jẹ̀ẹ́ ilé, ojú eérú ló kú sí.
Bí ó bá kú
n ó fọbẹ̀ náà jẹ,
Agbóńgbé
orí kere.
20. Ọkùnrin
tààrà kanlẹ̀ n’Sàlẹ̀ Ọ̀wọ̀n.
Ọmọ
wíwọ́n ẹdùn l’Ọ́jẹ̀ẹ́ Ilè,
‘Mọ
oní-pọn-ran-gan-dan
‘Mọ
oní-pọn-ran-gan-dan
‘Un là í-fi
dági ní ẹ̀kun èso
25. Ọmọ ọ̀wọ́n
ẹdùn
‘Mo
oní-pọnrangandan
‘Un là fi
í-sàràbá nígọ̀ kalẹ̀
Ọmọ awàràbàyànyàn
bíi-kó-d’-irókò
Àgbẹ́òléwú
máa gbọ́rọ̀ ẹnu mi
30. Aworobii-kó-d’emi
Ọmọ Ọ̀wọ́ọ̀rọ̀-wọ́
wọ́gi nífun dà sígbó
Ẹ̀kùlé Àrè
là ígbé lu ‘gbá à jẹ́, ọmọ
Ajíbógundé
ará Ọ̀jọwọ̀n
Má lu ‘gbá
à jẹ́ lọ lóde baba èmi
Agbóńgbó orí kere, ọkùnrin tààrà kanlẹ̣̀ l’Sàlẹ̀ Ọ̀wọ̀n.
35. Níjọ́ tí baba
èmi, Làgbàyí, ń toko ọnà í bọ̀
Apá ilé wa ń sá kíjokíjo, ìrókò wọn a gbọ̀n jìnnìjìnnì
Wọn la à
mẹni Làgbàyi, ó fẹdùn ké
Taa n’baba
wa ó fẹdùn pa
Ọ̀-fọbaǹdù-kàn-igi-gbọ̀ngbọ̀n
40. Ọba-ǹdù
n’yóó jẹlé ìrókò wó túútúú; Kújẹrńrá, ẹ kú
Tí n bá ń lo ilé àwọn baba èmi, Afìjàlọ̀bí Ọlọ́jọwọ̀n
Ọlọ́jọwọ̀n, baba wa, ni í-tọrọ ọpá aláyé ṣe bíi ọmọ
Okoye
Ọmọ mẹ́ta
n’baba wọ́n bí
Òsé
lẹ̀gbọ́n, Okoye làbúrò
45. Ajíbógundé
lọmọkẹ́hìn wọn lé-ńje-lé-ńje
Òsé ń gbẹ́
ònà níjù.
Okoye ń bá
eégún re ilé
Ará
àgbóṣòkun
Kújẹmrá Ọmọ ẹlẹ́jọ́awúju, ọkùnrin tààrà kanlẹ̀ n’sàlẹ̀
Ọ̀wọ̀n
50 Wọn ní baba
wa kégi ń’gbó
Ọlọ́jọwọ̀n,
wọ́n ní igi wó pa baba lóko
Ẹ má dá
wọn lóhùn, ẹ jàre, jowolo ẹnu ni wọ́n ń jẹ
Kàngẹ́ ni n
ó gbó, ara Ọ̀jọwọ̀n
N ò gbọdọ̀
gbẹ̀nà-ǹgbẹnà tán.
55. Ẹni agbẹ́nà
a rỌ̀yọ́ láyé Ọba Abíọ́dún
O torí baba
olúkálùkù
Wọ́n ń
gbẹ́nà rỌ̀yọ́ láyé Ọba Abíọ́dún
Ọlọ́jọwọ̀n
wọn a gbẹ́ tiwọn ní kiribiti ní kiribiti.
Ó torí baba
àwọn olúkálùkù
60. Wọn a gbẹ́nà
a rỌ̀yọ́ láyé Ọba Abíọ́dún
Ọlọ́jọwọ̀n
wọn a gbẹ́ tiwọn lógiidọbọ ní kiribiti
Ó torí baba
èmi Làgbàyí ará Ọ̀jọwọ̀n
Baba mi ń
gbẹ́nà í rỌ̀yọ́ láyé Ọba Abíódún.
Ọgọ́jọ̣
òpó n’ baba Ajíbógundé gbẹ̣́
65. Ó ní wọn ó
sọgọ́rin rẹ́ layaba
Àádọ́rin
rẹ̀ òsì-ẹ̀fà
Ẹ̀wá yòókù
ló ní ó máa gbálẹ̀
Ṣàngó ní
ọrọọrún
Òpó ò
fọhùn rí láyé Ọba Abíọ́dún
Níjọ́ òpó
fọhùn lójú èmi nilé ségi láàfin Ọ̀yọ́
70 Ẹlẹ́rú ń
jogún ẹrú
Oníwọ̀fà ń jogún àwọn ìwẹ̀fà
Aláṣọ ń
jogún aṣọ
Òpó wá
róṣọ, òpó gbàjá
Kinní yìí
wá róṣọ; òpó kànǹdududu níwájú Ọba
75 Ò káwọ́ lérí,
ó ń sunkún
Ó lóun ò
rénìyàn tí yóó jogún ìran baba òun
Abímbéṣú ló
jogún ìran Òpó
Abídorí Ọm’Ẹlẹ́mi tó ró’gba igi ní
aṣọ
Ẹ̀gà ta
pẹ̀ẹ̀rẹ̀ joko ẹnìkan nàmù
80 Ọmọ ìyá lájá
òun ọ̀bọ, Làgbàyí ará Òjọwọ̀n
Kújẹ́nlówólọ́wọ́, ará Ọ̀jọwọ̀n, ọmọ Adépọ́nrin fun Ọba,
ọkùnrin tààrà kanlẹ̀ ni ‘Sàlẹ̀ Ọ̀wọ̀n
Bí n bá ń
lọ ilé àwọn baba èmi
Òsé ń gbẹ́
níjù
Okoye ń bá
eégún re ilé
85 Bí
ẹ bí sín eégún jẹ nílẹ̀ yìí, ṣebẹ́nìkan ò le mú yín?
Baba yín ló
lẹni tí ń bẹ ń’nú eégun
Ọlọ́jọwọ̀n,
baba wa, ló lẹni tí ń bẹ ń’nú aṣọ.
Ọkùnrin
tààrà kanlẹ̀ n’Sàlẹ̀ Ọ̀wọ̀n
Àgbẹ́-ò-léwú
máa gbọ́rọ̀ ẹnu èmi tí bá ń yẹka
90. Bẹ̀rẹ̀ sí mi
níhàhín ná o
Bóyá ma
réwú Ọlọ́jọwọ̀n lórí rẹ.
Ajíbógundé ‘m’ Adépẹ́mirin-fún-Ọba, Làgbàyí ará Ọ̀jọwọ̀n.
Mo tún kí
ọ níhà ibẹ̀nu, mo dárale.
Gbogbo
ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ ọkùnrin ní ìdílé Ajábógundé ni à ń kì báyìí. Orílẹ̀ ilé
baba ẹni ni tẹni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ki ni mọ́ ilé ìyá ẹni náà, pàápàá
tí ìyá ẹni bá ní ọ̀run tí ó jọjú.
Orílẹ̀
Ajíbógundé yìí ń sọ fún ni pé àwọn ìran yìí a máà ṣọdẹ, wọn a sì máa gbé
egúngún. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ agbẹ́gilówó, iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, agbẹ́gilére ni iṣẹ́
àṣelà wọn. Àwọn ni wọ́n sì mọ igi tó dára fún oríṣi iṣẹ́ ọnà.
Àwọn
ìran Ajíbógundé náà ṣígbọnlẹ̀ lénìyàn, wọn a sì máa wuyì. Láyé Aláàfin
Abíọ́dùn, àwọn ni ọlọ́nà ọba tí ó jẹ́ pé bí wọ́n bá gbẹ́gi tán, a dà bí ẹni
pé kí á sọ̀rọ̀ sí i kí ó lahùn. Olódùmarè tún fi ẹ̀mí gígùn jíǹkí ìran
Ajíbógundé.
Kò
yé àwa Yorùbá bí ènìyàn ṣeé wà láyé tí kìí lọ́run, tí kì í lóríkì. Ìdí nìyí tí
Olóògbé Ládòkè Akíntọ́lá, Ààrẹ Yorùbá, fi í máa sọ pé
Ẹ gbọ́ tí wọn ni Òòṣa debè
Òòṣà di poro
Bí òòṣà ti wọn yẹn
Bá bínú tán, báwo
Ni ẹ ṣe mọ̀ tí ẹ ó
fi kì í tí yóò fi jẹ́?
Yorùbá gbàgbọ́ pé bí ẹni kọ̀ọ̀kan
tí ní oríkì orílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ẹranko, gbogbo ewéko, gbogbo ohun rírí,
ohun àìrí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n ní oríkì wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.Kò sì sí ọ̀run ọ̀kan
kan nínú wọn tí a kò lè rí nínú odù Ifá. Ẹ ò gbọ́ bí wọ́n ti i ki túùkú,
ẹlẹ́dẹ̀ igbó:
Odódó ẹlẹ́dẹ̀ ẹgàn
Ẹran abi kangara lẹ́nu
Ẹranko tí a kò fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ rẹ̀
Tí ó sì ń gbà àna lọ́wọ́ ẹni Ẹranko tí torí abo
Tí ó ṣe inú rẹ̀ lápèrè
tí a sì í kí ẹnu ní:
Àlímọ́tù akèǹgbè
Lánínhún inú ahá
Àárọ̀ ní í fi í wọ̀lú
Bó ba di ọjọ́ alẹ́, gọngọ a máa sọ
Ìyàwó oníkọ́bọ̀ méjì tí í lé
Ológóje ọ̀kẹ́ lugbó
Ohun tẹ́sin mu mu mu tó gbàgbé ìwo
Ohun tádìẹ mu mu mu, tó gbàgbé ìtọ̀
Ohun táwó mu mu mu, tó fi ké ráhùn wọnú igbó lọ[5]
Ìnagijẹ
lásán ni àwọn oríkì méjèèjì yìí nítorí pé ó dájú pé ìjìnlẹ̀ ẹ̀dá túùkú wà nínú
Ifá, bẹ́ẹ̀ sì ni ti ẹmu. Ẹ ò gbọ́ tí Ifá pe ọtí ní amíwàgùn ẹni, ọtí yòówù
kí ó jẹ́?
Nítorí
náà, oríkì àwọn nǹkan kọ̀ọ̀kan ni àkójọpọ̀ ohun tí Yorùbá mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀
pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀, ohun tí a ń fi í ṣe, ìwà àti ìṣe rẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀
lọ. Ní ààrin àwa Yorùbá, àwọn ọdẹ sì ni ìmọ̀ yìí ṣodo sí lọ́dọ̀. Nítorí
ìrírí wọn gẹ́gẹ́ bíi àgbẹ̀, bíi ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Yorùbá, àti ìpò wọn bí ọdẹ tí
wọn jẹ́, kò sí ẹranko, ewéko, tàbí ohun kan mìíràn tí wọn ò mọ ọ̀run rẹ̀. O
tilẹ̀ dà bí ẹni pé bí wọ́n ti lè yá ọlọ́san-ìn ní wọ́n lè yá adẹ́bọ, tí wọ́n
sì lè yá àdáàrù bí ó bá kan tí ọ̀run gbogbo nǹkan. Inú ẹṣẹ Ifá ni Yorùbá
ṣe gbogbo àwọn ìmọ̀ wọ̀nyí lọ́jọ̀ sí.
ORÍKÍ NÌLẸ̀ ÌBÒMÌRÀN
Yorùbá
bọ̀, wọ́n ní, ‘ẹni bá rìn jìnà yóò fi odó ìbílẹ̀ jẹun’ (Bí èyí bá jọ òwe, kí
ó jẹ́ ti ẹ̀yin àgbà.) Kò yẹ kí ó ya ni lẹ́nu púpọ̀ bí a bá gbọ́ pé ọ̀rọ̀ bíi
oríkì tí a ti ń yẹ̀wò lónìí wà ní ilẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ilẹ̀ Yorùbá.
Àpẹẹrẹ
àwọn ilẹ̀ tí mo sì mú láti tọ́ka sí fún yín kì í ṣe ni ilẹ̀ Náìjíríà; nítorí
pé bí ó bá jẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà ni, àwọn kan lè máa ronú pé bóyá ọwọ́ àwa Yorùbá
ni àwọn ẹ̀yà yẹn ti yá oríkì. Morris (1964) àti Coupez òun Kamanji (1970) ti
fi hàn wá pé ohun tí a lè sọ pé ko ya oríkì wà láàrin àwọn Bahima ti Ankole
ni Uganda (Morris), bẹ́ẹ̀ sì ni ó wà fún àwọn ilé ọlá láàrin àwọn Tutsi ní
Rwanda (Coupez & Kamanji). Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìsí ìyàtọ̀ díẹ̀ láàrin oríkì
Yorùbá àti tí ilẹ̀ tí a dárúkọ wọ̀nyí. Bí àpẹẹrẹ, láàrin àwọn Bahima tí ó
jẹ́ pé ẹran (màalúù) ni àwọn í sìn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn, tí wọn ò sí
lóko, tí wọn ò lódò mìíràn, orísì oríkì méjì ni wọ́n ní. Bí wọn ò bá ki ara
wọn, wọn a sì máa ki mààlúù wọn ní àkìsunkún. Ní ti àwọn Tutsi ti Rwanda,
àwọn náà ní ìran ẹ̀ṣọ́, wọ́n lọ́ba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn ẹran tún fi ìdí
múlẹ̀ láàrin àwọn náà. Coupez àti èkejì rẹ̀ fi yé ni pé oríkì ọlá ló ṣe
pàtàkì jù láàrin wọn bíi oríkì orílẹ̀ láàrin àwa Yorùbá. Bí àpẹẹrẹ, èyí ni
ìbẹ̀rẹ̀ oríkì balógun Ọba Omugabe Mutambuka, Tajungye, nígbà tí ó lọ kó ìlú
Buhweju ní ọdún 1865. Tajungye ló kí ara rẹ̀, kò sì ṣàìjọ oríkì àwọn
akínkanjú bí Ibíkúnlé, Ìbàdàn,
Ruhimbwá ndemera
nti ómu ihangá na Rutaahira
Ruhambisa-ábiri
nkatoorwa ómutánda
Rukaré guunyihá
haraingwa na Rwihira ngabo
Ruzingizá
naitangirá Bihanga na Bitembe
Kaanyabareega
nkeekwata na Bukwakwa
Bantura yaakwata ékyéshongoro
ngu tubingye.
Oruhindá nkagikubuuza
nti órubango na Rwamujonjo
Abanyóro baatiina ómukaituranó
gwa Kahenda
Enkóko za Karembe
zantanga Kujùga
Rukiná
mbakumbizá Nyamizi na Rutasikwa[6].
Bi wọn ba
ní ká kì í ni Yorùbá, oríkì rẹ̀ yóò jọ báyìí:
Emi lArólógun fìjàgboyè àjòjì
Ẹ̀ṣí lọ́tùn-ún lósì faṣọ àlà gunwà
Arógunyọ̀, Arógundédé da jìnnìjìnnì
bakọ ẹ̀ṣọ́
Mo ba Bitembe tú wọn ka
5. Níbi wọn gbé ń dáná irọ́
Ẹni
jàkùnmà ń yọ̀rù ti Bihanga tọ̀ lẹyìn
Ègbè
Bwakwakwa lọtẹ̀ Kaanyibareega
Téwì
Bàǹtúrà ń ti ń sọ wọ́n dòjòjò.
Kò
síìmi, kò sí ẹ̀ṣí à jànà
10. Rwamunjonjo kò kÒrùhìndà
Èrùjẹ̀jẹ̀,
àmódi Banyoro niju Behenda
Kùtùfẹ̀lì
àkùkọ Karembe
Kùkùtè
kò mira jingin
Mọ̀nọ́mọ̀nọ́
sòkèdilẹ̀ logun Nyamisi
Nínú
ẹ̀dà oríkì yìí ní èdè Yorùbá, ọ̀rọ̀-orúkọ ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí a fa ìlà sí
nídìí, túmọ̀ sí.
Bí
a bá fi oríkì wọn ní orílẹ̀-èdè wọ̀nyí wé ti Yorùbá, ò fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé bákan náà
ni ọmọ ń ṣorí ni; pàápàá bí a bá wo ètò ohun tí wọn sọ nínú oríkì àti bí
wọ́n ṣe ń wí i. Bí àwọn òǹkọ̀wé tí a mẹ́nu bà ti wí, oríṣiríṣi orúkọ ẹni
à ń kì ni wọ́n ń fi í bẹ̀rẹ̀ ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. Bó ṣe, wọn a mẹ́nu ba
orìṣìí nǹkan ńláńlá ti òun àti àwọn
ìran rẹ̀ ti gbe ṣe; wọn a sì tún ki àwọn ìrandíran ẹni bẹ́ẹ̀ lọ sààkun. Bí
ẹ bá tilẹ̀ wo ti àwọn Bahíma, bí wọ́n ṣeé ki mààlúù wọn gan-an nìyẹn. tí
yóò gùn wọn bíi Ṣàngó, tí yóò sì máa pa wọ́n bí ọtí.
IWULO ORÌKÌ
Bí
mo bá dákẹ́ lẹ́nu lórí ohun tí mo ti sọ fún yín síwájù yìí, ó dá mi lójú pé
ẹ̀yin náà kò ní í ṣaláìle tọ́ka sí oríṣi ọ̀nà tí oríkì fi wúlò fún àwa tí
ẹ̀kọ́ àti ìlọsíwájú èdè àti àṣà Yorùbá jẹ lógún. Lórí èyí, àti lóríi gbogbo
ohun tí ó kù tí n ó bàá yín sọ, ààbọ̀ ọ̀rọ̀ ni n ó ṣe é, tí à ń sọ fún
ọmọlúwàbí. Ẹ ó sì rí díẹ̀ nínú àkíyèsí tí n ó mẹ́nu bà nínú àwọn ìwé bíi
mélòó kan tí mo dárúkọ sí ìsàlẹ̀ fún àǹfààní yín. Ṣùgbọ́n ohun kan pàtàkì tí
mo nírètí pé ẹ ó dì mù ni pé omi-ń-bẹ-lámù ni ọ̀rọ̀ ìwádìí lórí oríkì; a kò
sì tíì lálàá ibi tí a ti lè sọ pé a mọ̀ tó nípa rẹ̀.
Àwọn
òpìtàn bíi Bọ́láńlé Awẹ́ (1974) fi ìka tọ́ ọ pé bákan náà kọ́ ni àwọn oríṣi
oríki ti a kà sókè yìí wúlò fún àwọn òpìtàn ilẹ̀ Yorùbá. Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́
pé orílẹ̀ tí a lè pín gbogbo Yorùbá sí fẹ́rẹ̀ má ju mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lọ́, lẹ́yìn
gbogbo ogun, ọ̀tẹ̀ àti tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun tí ó ti da ilẹ̀ Yorúbá rú, tí ó sì fa kí
àwọn ènìyàn máa ṣí láti ibi kan dé sí ibòmíràn láti nǹkan bíi ẹ̀gbẹ̀rún
ọdún sẹ́yìn, oríkì orílẹ̀ jẹ́ atọ́nà pàtàkì tí a lè tẹ̀lé láti mọ ibi tí
irú-wá-ògìrì-wá tí à ń kò nínú àwọn ìlú àti ìletò Yorùbá ti ṣẹ̀. A mọ̀ pé kì
báà ṣe òkun erémi, Ikọ́ ni Ikọ́ í jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì í ki àwọn Ògún, Erin,
Ọ̀gọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, a kì í kì wọ́n yàtọ̀.
Ṣùgbọ́n
gẹ́gẹ́ bí Bọ́láńlé Awẹ́ (`974) ti pe àkíyèsí wa sí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó
wúlò fún òpìtàn ni orílẹ̀ máa ń fi ojú fò dá. Idí èyí ni a fi lè sọ pé oríkì
orílẹ̀ wúlò fún ìtàn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n oríkì àlàjẹ́ ni ó le fún wúlò fún
ìtàn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n oríkì àlàjẹ́ ni ó lè fún wan í ìmọ̀ tí ó kún jù nípa
ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń dìtàn. Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé kò sí sáà ti ìlú kì í lọ́ba,
níjòyè, lákíkanjú, tí ó sì jẹ́ pé àlàjẹ́ wọn bíi ti Ibíkúnlé Ibàdàn,
Ògèdèǹgbé Iléṣà, Kùrunmí Ijàyè, Fábùnmi Èkìtì, àti Ẹfúnṣetán Aníwúrà,
Iyálóde Ibàdàn, àlàjẹ́ wọn níí sọ ohun ti wọ́n gbé ṣe láyé tiwọn, àti ipò
tí àwọn ìlú tò wọ́n sí, ohun tí ìlú rò nípa ìwà wọn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àlàjẹ́
àwọn alákòóso kò ní í ṣàìwúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún aáyan ìtàn ìlú kọ̀ọ̀kan.
Kì
í ṣe àwọn òpìtàn nìkan ni oríkì wúlò fún; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo oríkí ni ó
wúlò fún òpìtàn. Bí a bá bèèrè pé kí tilẹ̀ ni ẹ̀ka ẹ̀kọ́ bíi bótánì àti
sùọ́lójì jẹ mọ́ ọ̀n, àti iṣẹ́ àwọn awòràwọ̀ (àsọ́nọ́mi), oníkùsà (jìọ́lójì),
àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ kò ní í ṣàìṣe àkíyèsí pé ṣààṣàa ni irú ìmọ̀ tí wọn
ń lé kiri tí kò ti wà nínú oríkì tí Yorùbá ní fún àwọn irú nǹkan kọ̀ọ̀kan tí
ó jẹ wọ́n lógún. Bí ẹ bá fẹ́ẹ́ mọ̀ nípa ewéko, mẹfọ́lọ́jì wọn, ohun tí a lè
lò wọ́n fún, irú ilẹ̀ tí ó gbọ̀ wọ́n, àsìkò tí a lè rí wọn àti irú àrùn tí í
ṣe wọ́n, ọdẹ àti ọlọ́san-ìn ló yẹ ki á tọ̀ lọ. Iwé béńbé kan tí Pierre
Fátúmbí Verger kọ tí ó pè ní àwọn ewé osanyìn jẹ́ bí ìtọ́wò irè tí a lè kó bí
a bá gbìyànjú lọ́nà ibẹ̀ yẹn. Àwọn ìṣègùn wa òde òní ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́
láti kọ́ nípa orísi àrùn tí í máa bá wa jà, tí kò sí láàrin àwọn òyìnbó, tí
àwọn òyìnbó kò kápá, ṣùgbọ́n tí a mọ oríkì wọn. Ẹ ò rí i pé omi ń bẹ lámù
lóòótọ?
ORIKI ÀTI ÈDÈ YORÙBÁ
Bí
ẹ bá tún fi ojú inú wò ó, ẹ ó sì tún
ṣe àkíyèsí pé èdè Yorùbá yìí gan-an ni oríkì wúlò fún, pàápàá jù lọ àlàjẹ́,
orílẹ̀ àti oríkì àwọn oríṣíríṣi nǹkan tí àtìrandíran Yorùbá ti lò, tí wọ́n
sì ti bá pàdé.
Bó
ṣe wọn a ní èdè oríkì le, ó kún fún ọ̀rọ̀ tí ó ti kú, tí ẹni kan kò lò mọ́.
Ṣùgbọ́n àkíyèsí tí èmi alára ṣe nípa èrò àwọn ènìyàn wa lórí ọ̀rọ̀ inú oríkì
Yorùbá bá èyí tí Morris ṣe nípa èrò àwọn ọ̀mọ̀wé Bahima lórí oríkì tiwọn náà
mu.
Ó
ṣàkíyèsí pé:
An educated Muhima is usually unable to understand a large
part of an ekyevuge[7].
This is partly because he is unable to fathom the imagery which the composer
has used and partly because the actual vocabulary used is unkown to him. He is
inclined, therefore, to say that the language of the ebyevuge[8]
is archaic. This is, however, not the case. .. A very large proportion of the
vocabulary used in the ebyeyogo will
not be found in existing dictionaries and would be unkown to a Mwiru[9]
and to very many Bahima. …In fact, the language of the ebyevuge, so far from
being archaic, is full, as is all spoken Runnyankore, of recent borrowings from
Bugania and elsewhere. (26-27).
Èyí túmọ̀ sí:
Ṣàṣà ni ọ̀mọ̀wé Muhima tí kò jẹ́ pé ìwọ̀nba ekyevuge kan ni ó lè yé e. Ara ohun tí í
sì í fa èyí ni pé (ẹni bẹ́ẹ̀) kò le fi ojú-inú rí àwòrán tí akéwì fi sọ̀rọ̀ ya
kalẹ̀, bẹ́ẹ́ sì ni ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọn lò ni kò gbọ́ rí. Òun lò fà á tí irú
ẹni bẹ́ẹ̀ fi í kúkú gbà pé èdè àtijọ́ ni èdè ebyevugo. Ọ̀rọ̀ kò sì wáá rí bá yìí.
….Ọ̀pọ̀ salalu ọ̀rọ̀-èdè tí a lè bá bá pàdé nínú eboyevugo ní kò sí nínú àtúmọ̀-èdè
kankan, tí Mwiru kan kò mọ̀, tí Bahima tó mọ̀ wọ́n náà kò sì jù wóńwẹ́…Ibi
ọ̀rọ̀ wà gan-an ni pé èdè inú ebyevugo kì
í ṣe èdè àtijọ́ kankan: kàkà bẹ́ẹ̀, ó kún fún ọ̀rọ̀ àsáwọ̀ láti èdè Buganda
àti èdè ilẹ̀ mìíràn bíi gbogbo èdè Bunnyankore yòókù (yàtọ̀ sí ti inú ebyevugo.
o.o.o)
Kí
ẹ lè mọ̀ pé bí ó ti rí fún àwọn ọ̀mọ̀wé Bahima, ni ó rí fún ọ̀pọ̀ nínú àwa
Yorùbá lónìí, ẹ wo orílẹ̀ ìran Ajíbógundé tí a yẹ̀wò lẹ́ẹ̀kan. Mélòó nínú wa
ni o mọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí a ṣe lò wọ́n nínú orílè yìí?
(a) àgbẹ́
ẹdùn
ewú
ọbaǹdù
òsì-ẹ̀fà
ọrọọrún
(b) ̣ẹmi
apá
igọ̀
ìkòrò
(c) awúju
Ọ̀pòlọpọ̀
láàrin wa sì ni oríṣiríṣi gbólóhùn inú oríkì yóò pa lákọṣẹ, gbólóhùn bíi:
Ọmọ
wíwọ́n ẹdùn l’ọ́jẹ́ Ilé
_____
un
là ífi dá ‘gi ní ẹ̀ku eso.
Bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣòro yìí kì í (kààn)
ṣe ti Yorùbá àdúgbò, irú èyí tí ó lè jẹ́ kí Yorùbá Ijẹ̀ṣà ó ṣòro fún ará
Ẹ̀gbádò. Èyí ń sọ fún wa pé àwọn atúmọ̀-èdè Yorùbá tí ó wà nílẹ̀ kò ì tí ì
kún tó. Oríkì sì jẹ́ ibì kan tí a ti lè wakùsà ọ̀rọ̀ tí àìmọ àṣà Yorùbá dunra
máa ń jẹ́ kí á pàdánù. Lẹ́ẹ̀kan sí i, omi ń bẹ lámù lọ́nà ibí yìí náà. Ohun ti
ó wáá ń kọ èmi lóminú ni pé àwọn àgbà tí wọ́n mọ ìtàn, tí wọ́n mọ oríkì,
wọn kò ní í ju sáyé. Bí a bá ṣàfira ẹ̀pa lè máà bóró mọ́ fún èdè wa.
Kò
sí ẹni tí ó lè dá a lábàá pé kí a máa sín gbólóhùn oríkì jẹ bí a bá ń sọ̀rọ̀.
Ṣùgbọ́n àǹfààní wà nínú kí a mọ ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ìsọ̀rọ̀-wuuru àti ti
oríkì. Ọ̀rọ̀ sì pọ̀ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òní kìí ṣe ọjọ́ aré, n
ó mẹ́nu ba díẹ̀ lára itú tí àwọn asunrárà, asùnjàálá, ẹni tí ó ń sín ìgbálá,
ẹni tí ó ń mù olele, awo tí ń ki Ifá, ẹni tí ń pògèdè, àásán, tàbí àyájọ́,
ìṣègùn àti ẹni ti ó ń ki oríkì ṣánpọ́nná, itú tí gbogbo wọn máa ń fi èdè pa
bí wọ́n bá kan oríkì.
Ọlátúndé
Ọlátúnjí (1969) ti fi ìka tọ́ ọ pé orúkọ àpèlé àpèlé máa ń pọ̀ nínú oríkì ju
inú àròfọ̀ ẹnu Yorùbá mìíràn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ohun kan tí mo kàan fẹ́ẹ́ tọ́ka sí
fún àǹfààní àwọn onímọ̀ lìǹgúísíìkì ààrin wa ni àpẹẹrẹ onírúurù ìlànà
mọfọ́lọ́jì, pàápàá ju lọ ti ìṣèdá ọ̀rọ̀ tí a lè bá pàdé nínú oríkì. Irú
àkíyèsí báyìí ni ó lè kó wa ní ìjánu lórí irú òfin tí àwa onígìrámà fẹ́ẹ̀ máa
fi lélẹ̀ nípa bí àwọn elédè ṣe ń sọ ọ́. Bi àpẹẹrẹ, gbogbo wa ni a mọ̀ pé
ara àpólà ìṣe (tí àwọn onígẹ̀ẹsì ń pè ní verb
phrase) ni Yorùbá ti í ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ jù. Orikì ló kín wa lẹ́yìn pé kò
tọ́ kí a sọ pé ara ọ̀rọ̀-ìṣe goloto nìkan ni. Nínú orílẹ̀ Ajíbógundé, ẹ ó rí
àwọn àpẹrẹ wọ̀nyìí
alọ́sòópọ̀bọ
afẹ́bíọyẹ́
abóròókòlọ́wọ́lọ́wọ́
awàràbàyànyàn
adépọ́nirin
fún ọba
ọ̀fọbaǹdù-kan-ìgi-gbọ̀ngbọ̀n
Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn tí ènìyàn lè
bá pàdé nínú oríkì ni
òtIbàdànbáwọnjódùndúnrÌlọrin
àìtètèlóbìnrin
(kò pé a lówólọ́wọ́)
àkúkúùjoyè
Ẹ
ó ṣàkíyèsí pé kò si ọ̀rọ̀ bí àkúkú-,
òfì-, òti-, alá-, àti àìtètè- pàápàá
náà, bó bá yẹ̀ níbi a ti mọ ìparí àpólà-ìṣe tí tètè bẹ̀rẹ̀. Àìtètèkọbiara sí àkíyèsí yìí ló sì tún jẹ́ kí ọ̀rọ̀
ohun tí ó yẹ kí á pè ní ọ̀rọ̀- ìṣe ní èdè Yorùbá tún lọ́jú pẹ̀ díẹ̀.
Èyí
nìkan kọ́. Nínú iṣẹ́ kan tí ọ̀rẹ̀ mi, Samuel A. Ẹkúndáyọ̀, ṣe láìpẹ́ yìí
lórí ibi tí ó yẹ kí á to àtọwọ́dá orúkọ sí nínú gírámà Yorùbá, ó ní bí ó
tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi àfòmọ́ (affixes) ni Yorùbá ní tí í fi í ṣẹ̀dá
ọ̀rọ̀-orúkọ láti ara àpólá-ìṣe, sibẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo, iyẹn àì, ni ó wúlò jù.
Bí mo ti ní àǹfààní láti pe àkíyèsí rẹ̀ sí i. ẹ ó rí i pé, bí ó bá yẹ oríkì
wò ni, kì bá tí sọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn àfòmọ́ yòókú ni oríkì tilẹ̀ tún jẹ́ ó dà
bí pé wọ́n wúlò ju àì lọ. Àpẹẹrẹ: oní, à-, ò-, ì-, àti-, bí wọ́n ṣe wà nínú àwọn àyọlò òkè wọ̀nyí,
àti nínú àwọn gbólóhùn oríkì yìí (Babalọlá, 1967):
(1) Òkínìkàndánkànsí, baba ‘Rántí
alẹ́nuníwọ̀n-tòkèlè
(Oríkì
Ìran Ẹlẹ́rìn, 249)
(2) Ẹ
ọ̀ rí i? Ipàǹgunja
Ni
Yánbímlólú bẹ́ lórí.
Ìkòǹkogunlójú
ló bẹ́rí àwọn baba mi lọ
(Oríkì
Ìran Olúkòyí, 76 – 78).
A tilẹ̀ lè sọ pé àlòòdabọ̀
àtọwọ́dá orúkọ tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àfòmọ̀ bí à-, a-, ò-, o-, è-, àti-, oní-, nìkan ni ó ya oríkì sọ́tọ̀ sí orin
tàbí àròfọ̀ Yorùbá yòókù, pàápàá tí a bá tùn fi àwọn àtọwọ́dá orúkọ bẹ́ẹ̀
kún ọ̀rọ̀ ìbátan gbogbo lóríṣiríṣI tí Ọlátúnjí (1969) ti tọ́ka sí. Èyí kò sì
lè máà rí bẹ́ẹ̀. Bí mo ti sọ ṣíwájú, ìṣe, ìrísí, ìwà ẹni ni oríkì jẹ mọ́.
Àwọn àfòmọ́ wọ̀nyí ni ó dà bí ìka tí ó tọ́, ti a fi í remú nípa ṣíṣẹ̀dá
àwọn ọ̀rọ̀ (yàtọ̀ sí gbólóhùn) tí ó lè fi àwọn nǹkan tí oríkì jẹ mọ́ wọ̀nyí
hàn. (cf. Akin Iṣola Odu, 13, 1976)
Bi
a bá tún wo irú gbólóhùn tí a máa sábá kò nínú Oríkì, a ó tún ṣàkíyèsí pé
ìlànà síátáàsì tí wọ́n tẹ̀lé máa ń yàtọ̀ sí ti ọ̀rọ̀ wuuru. Ẹ wo àwọn àpẹẹrẹ
wọ̀nyí láti inú orílẹ̀ Ajíbógundé
(1) Idígegele kó òògùn sí ọkọ Ẹbẹ̀lókú
(2) Tí n bá ń lọ ilé ọ̀rẹ́ mi, Kújẹ́nrá
(3) Ọkùnrin tààrà kanlẹ̀ ń ‘sàlẹ́ Ọ̀wọ̀n
(4) Kàngẹ́ ni n ó gbó, ará Ọ̀jọwọ̀n
(5) Ọmọ wíwọ́n ẹdùn lỌ́jẹ̀ ilé
‘Mọ
oní-pọn-ran-gan-dan
‘Mọ
oní-pọn-ran-gan-dan
‘Un
là íri í-s’àràbà nígọ̀ kalẹ̀.
Ohun tí ẹ ó kọ́ ṣàkíyèsí ni wí pé
gbólóhùn oríkì kì í sábà ni àmì àsìkò ìṣẹ̀lẹ̀, tàbí ti ìpò tí ìsẹ̀lẹ̀ yẹn wà
(aspect): bó bẹ̀rẹ̀ ní o; bó ní òpin ni o, tàbí kò ní. Èyí máa ń jẹ́ kí ohun ti
oríkì ní í wí dà bí ohun ayérayé, bí òtítọ́ tí kì í yí padà.
Bí e. bá wo gbólóhùn (1) àti (3) òkè yìí, ẹ ó
kìíyè sí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni a fò. Gbólóhùn (2) jẹ́ abala kan nínú àkànpọ̀
gbólóhùn tí Yorùbá fi í sọ ìdí abájọ. Ọ̀kọrin yìí kò sì mẹ́nu ba abala kejì
rárá. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ohun tí ó ń sọ ni pé ‘bi ó bá jẹ́ pé Kújémrú ọ̀rẹ̀ mi
ni n ó ki, báyìí ni n ó máa wí…’
Wàyí
o, bí ẹ bá wáá wo àpẹẹrẹ (5), oríṣiríṣi nǹkan ní ń ṣẹ̀lẹ̀ níbẹ̀. Bí a ó
bàá sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ wuuru, a ó sọ báyìí pé,
ni Ọ̀jẹ́ Ilé, níbi tí Iran rẹ gbé ṣẹ̀ ẹdùn olówó-iyebíye
ni àwọn ìran rẹ fi sọ igọ̀ kùrò lára igi ní pọnrangandan, bí ó tile jẹ́
àràbà
Àpòlá ‘wíwọ́n ẹdùn’ gbé ọ̀rọ̀-ẹ̀yán
ṣaájú orí ọ̀rọ̀ tí ó ń yán; bẹ́ẹ̀ ni orí ọ̀rọ̀ ní í ṣaájú ní Yorùbá. Ọ̀kọrin
náà wá sọ gbólóhùn àkọ́kọ́ di àpólà ti kò ní ọ̀rọ̀-ìṣe. Irú àwọn àdìítú
gírámà báyìí ní ó mú Babalọlá (1967) sọ pé
Àwọn oríkì orílẹ̀ náà kún fún ààbọ-ọ̀rọ̀ ọ̀rọ̀ tí à ń sọ
fún ọmọlúwàbí tàbí ọ̀mòràn, tí sì í dé inú rẹ̀ tí í dodidi. Ẹni tó bá ń ka
ìwé oríkì yìí gbọ́dọ̀ lo gbogbo làákàyè rẹ̀ láti fi ronú ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀
oríṣiríṣi tó kún inú rẹ̀ dé ẹnu. Olúwarẹ̀ gbọ́dọ̀ múra láti fi ọgbọ̀n àti
sùúrù fọ́ àwọn ọ̀rọ̀ gígùn mìíràn sí wẹ́wẹ́ láti mọ ìtumọ̀ ibẹ̀ (p. 13).
Lónìí,
a mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà tayọ ti ọ̀rọ̀ gígùn. Kí ọ̀rọ̀ Yorùbá má baà di ti ejò tí ó
wọ inú àgé, àgbá di ọwọ́ wá. Kí a ti ibi pẹlẹbẹ mú ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ; a lè ti
ibi oríkì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìjìnlẹ̀.
Abọ̀
mi rè é o.
Atóka Ìwé
Abímbóla,
Wande (1968): Ìjìnlè Ohùn Enu Ifá (Collins,
Glasgow).
Adeoye,
C.L (1969): Orúko Yorùbá (Printed by
the Caxton Press, Ìbàdàn).
Awe,
Bolanle (1974): ‘Praise Poems as Historical Data: The Example of Yorùbá Oríkì’ Africa Vol. XLIV, No. 4, pp. 331-349.
Ayorinde,
J.A. (1973): ‘Orikì’, in Sources of
Yoruba History, edited by S.O. Biobaku (Clarendon Press, Oxford).
Babalola,
Adeboye (1966): The Content and Form of
Yorùbá Ìjálá (Clarendon Press, Oxford).
Babalola,
Adeboye (1967): Àwon oríkì Orílè (Collins,
Glasgow).
Biobaku,
S.O. (1973): Sources of Yorùbá History (Clarendon
Press, Oxford).
Coupez, A.
et Th. Kamanji (1970); Littérature de Cour au Rwanda (Clarendon
Press, Oxford).
Ekundayo,
S. Ayotunde: “An Alternative to Lexical Insertion for Yorùbá Complex Noun”, Studies in African Linguistics Supplement
1, 3:233-260.
Gbadamosi,
Bakare (1961): Oríkì (Mbari
Publications, Ìbàdàn).
Ìsòlá,
Akínwùmí (1973): Sàngó Pípè: One of the
of Yorùbá-Poetry (Unpublished M.A. Thesis, University of Lagos).
Ìsòlá,
Akínwùmí (1976): ‘The Artistic Aspects of Sàngó-Pípè’ Odù, A Journal of West African Studies, No. 13.
Johnson,
Samuel (Rev.) (1921): The History of the
Yorubas (reprinted 1969, C.S.S. Bookshops, Lagos).
Laoye,
Adetoyese (1963): Oríkì àti Orílẹ̀ (Mbari
Mbayo Publications, Òsogbo).
Lasebikan,
D.L. (1958): Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Yorùbá,
Àkójo Kìínní (Longmans, London).
Morris,
Henry F. (1964): The Heroic Recitations
of the Bahima of Ankole (Clarendon Press, Oxford).
Ogunbowale,
P.O. (1962): Àwon Irúnmọlè Ilẹ̀ Yorùbá (Evans
Brothers Ltd., London).
Ogunniran,
Lawuyi (1972): Eégún Aláré (Macmillan,
Ìbàdàn).
Oyelaran,
Olasope O. (Forthcoming) ‘On Rhythm in Yorùbá Poetry’ in Papers on Yoruba Oral Tradition (University of Ibadan Press, Ìbàdàn).
Olajubu,
Oludare (1972): Akójopò Èwì Egúngún (Longman,
Ìbàdàn).
Olatunji,
Olatunde (1969): ‘Classification of Yorùbá Oral Poetry’, Week-end Seminar on
Yorùbá Language and Literature (December 13-16th, 1969), Institute of African
Studies, University of Ifẹ̀.
Olatunji,
Olatunde (Forthcoming) Features of Yorùbá
Poetry (U.P.L., Ìbàdàn).
Olayomi,
Adebayo (1968): Ìtumọ̀ Orúkọ àti Oríkì
Yorùbá (African University Press, Lagos).
Verger,
Pierre Fatunbi (1967): Àwọn Ewé Ọ̀sanyìn
(Institute of African Studies, University of Ibadan).
Vidal,
Tunji (1969): ‘Oríkì in Traditional Yorùbá Music’. African Arts/Arts ‘Afrique, Vol, III, No. 1, 56-59.
[1]
This paper was published as O.O. Oyelaran, O.O. (2007), Oríkì’, in Ìṣẹ̀ǹbáyé àti
Ìlò Ède Yorùbá, edited by O.O. Oyelaran and L.O. Adewole. Iléṣà, Nigeria: Elyon
Publishers.
[2] Ibi ìdánilẹkọ̀ọ́ àwọn The Yorùbá Studies Society,
University of Ibadan, Ibdan ni mo ti kọ́ ka ìwé yìí ni ọjọ́ 30, oṣù Janúarì,
1976. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wa, àwọn egbé yìí, tí wọ́n gbà mi láyè láti
tẹ̀ ẹ́ jáde nínú àkójọpọ̀ Ìṣèmbáyé àti
èdè Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí a sì ti ṣe àlàyé saájú, ọmọ le ní ogún tàbí ọgbọ̀n
orúkọ bí ọmọlẹ́bi àti ọ̀rẹ́ bá ṣe pọ̀ sí lorúkọ ọmo. ṣeé pọ̀ sụ̀gbọ́n gbogbo
àwọn orúkọ yòówù tí a bá sọ ọmọ lẹ́hìn orúkọ àbísọ, àmútọ̀runwá tàbí
orúkọ àbíkú, àlàjẹ́ ni irú àwon orúkọ báyìí já sí. Orúkọ àlàjẹ́ lè jẹ́ orúkọ
Ògún, Ọ̀ṣun, Ọya, Ṣàngó tàbí ti Onílù, ọlọ́dẹ tàbí ti gbẹ́nàgbẹ́nà. Yorùbá
kì í sáàbà tẹ orúkọ àlàjẹ́ mọ ọmọ lára, àwọn àgbà agbo ilé ni sìí sáá bà
mọ ìlò irú àwon orúkọ báyìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì máa gbàgbé àwọn
orúkọ àlàjẹ́ tí a sọ wọ́n.
Ṣùgbọ́n
yíǹkì fẹ́rẹ̀ má tí ì gbe lẹ́nu pẹ̀ẹ́ni rẹ̀ tí ó tún fi sọ ní ojú ìwé 49 pé
Orúkọ àlàjẹ́ tàbí àdàpè kì í se orúkọ tí òbí ọṃ sọ ọmọ
rẹ̀ lọ́jọ́ ìkómojáde. Láti inú orúkọ tí a bá sọ ọmọ ni àlàjẹ́ tàbí àdàpé rẹ̀
ti í jáde. Bí a bá sọ ọmọ ní Ògèdèǹgbé, Gbógungbórò ni àdàpè rẹ̀… Ọmọ a
máa ní àlàjẹ́ nítorí pé ẹni tí ó ti kọ́kọ́ jẹ́ orúkọ yẹn rí jásí akínkanjú,
tàbí olówó tàbí olókìkí tàbí onínú-rere, tàbí afínjú àbí olùfọkànsìn tàbí
alááyan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. Àlàjẹ́ a sì máa hàn ju ̣gidi lọ; nígbà mìíràn ẹlomíràn
kò tilẹ̀ ní mọ̀ pé àlàjẹ́ ni òun lò bí orúkọ.
Bí
Adéoyé se kọ Yorùbá sílè gan-an ni mo kọ àyọlò ̣wọ̀nyí. Ẹ ó sàkiyèsí pé ọ̀rọ̀
ẹnu méjì báyìí sòro díẹ̀. Ó dà bí ẹni pé àpèlé ni Adéoyè fẹ́é ̣pe ti ojú ìwé
48, nítorí àpèlé ni ̣àkọlé ẹsẹ tí a ti mú àyọlò àkókó. Tí ojú ìwé 49, ni
àwa fara mọ́.
I Who Am
Praised thus held out in battle among foreigners along with The Overthrower;
I Who
Ravish Spear In Each Hand Stood out
resplendent in my cotton cloth;
I Who
Encircle the Foe, with Bitembe, Brought back the beasts
from Bihanga;
With
Bwakwakwa, I fought at Kaanybareega, Where Bantura started
a song that we might overcome them.
Thus with my spear, I and Rwamujonjo conquered Oruhinda;
The
Banyoro were afraid on the battle-field of Kahanda;
The cocks
of Kurembe had already crowed;
I Who Am
Nimble with The One Whom None Can Dislodge felled them at Nyamizi.
[8] Èyí ni ọ̀pọ̀
ekyeyugo. -ky- ni àmì ẹyọ kan, -by-
sì dúró fún ọ̀pọ̀ fún ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ yìí ní èdè àwon Bahima.
[9] Àwon
èyà kan tí wọn ń sọ èdè àwon Bahima, ṣùgbón ìran tí wọn kò ní irú oríkì
àwon Bahima nítorí pé iṣé àgbè nìkan ni Nwiru (Bairu, ‘òpò Nwiru’) mọ̀.
No comments:
Post a Comment