Eré
onítàn – eré tí a lè ṣe ní orí ìtàgé – yàtọ̀ púpọ̀ sí àwọn ẹ̀yà lítírẹ́ṣọ̀
mìíràn. Ẹni tí ó bà fẹ́ẹ́ kọ eré gidi gbọ́dọ̀ rántí pé ṣíṣee ṣe lórí-ìtàgé
ni iyì eré-onítàn. Bí eléyìí bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn òfin kan wà tí eré-onítàn kò gbọdọ̀
rú. Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn ni yóò ṣe eré ọ̀hún lórí ìtàgé,
eré-onítàn gbọ́dọ̀ jẹ mọ́ ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn àti àwọn ohun tí ojú ọmọ
ènìyàn le rí. Nítorí náà àwọn ìbéèrè kan wà tí ó yẹ kí á bi ara wa nígbà tí a
bá ka eré-onítàn kan tán: Báwo ni akitiyan ibẹ̀ ti pọ̀ tó? Ǹjẹ́ àwọn
ẹni-ìtàn ibẹ̀ jẹ ènìyàn? Ǹjẹ́ èdè tí wọ́n ń sọ jinná; ǹjẹ́ ó sì bá
akitiyan tí wọ́n ń ṣe mu; ǹjẹ́ ó fún wa ni ìmọ̀ tí yóò jẹ́ kí ìtàn náà yé ni
jinlẹ̀? Irú ẹwà èdè wo ló jẹ́ òǹkọ̀wé náà lógún?
Kí n tóó máa bá ọ̀rọ̀ lọ, ó yẹ kí
n sọ pé ìtàn–àròsọ yàtọ̀ sí ìtàn-àròsọ. Ojú tí a máa fi wo olukúlùkù yàtọ̀
fún ra wọn. Akèrègbè eré ni yóò sọ ibi tí a óò ti fi okùn lámèyitọ́ bọ òun.
Irú ìwádìí tí ó ṣiṣẹ́, tí ó wúlò, lórí eré kan le já sí ìfàkókòṣòfòlóri eré
mìíràn. Nítorí èyí, àwọn ìbéèrè tí ó bá wúlò, tí ó bá jẹ mọ́ eré tí a kà
níkan ni ó yẹ kí á máa lò.
Àwọn
eré-onítàn méjì péré ni ọ̀rọ̀ yóò dá lé lórí nínú ìṣẹ́ yìí: Wọ́n Rò Pé Wèrè Ni (Fálétí), àti Rẹ́rẹ̀ Rún (Òkédìjí).
Kí
á kọ́ mú Wọ́n Rò pé Wèrè Ni.
Ní ṣókí, ìtàn náà lọ báyìí: a
kọ́kọ́ gbọ́ ìròyìn bí Àyọ̀ká ti mọ̀wé tó láti ẹnu àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó wá a
wálé láti bá a pín láti ara ẹ̀bùn owó tí ó gbà lọ́wọ́ olùkọ́. Nílé Àrẹ̀mú (baba
Ayọ̀ká) yìí (1, i) ni a ti gbọ́ nípa ìlérí ìnáwó tí Baba Rámá fẹ́ẹ́ ṣe ni Ọjà
Ọba lọ́tunla. Lẹ́yìn èyí ni a pàdé Olóokọ Ọba àti Bàbá ni òpópó kan (1, ii)
tí wọ́n ń sọ nípa ìnáwó Ọjà Ọba láàrin Baba Rámá, anawo bí ẹ̀lẹ́dà, àti
Yísá òun Àfùlélù. A tún rí díẹ̀ nínú ọgbọ́n Àyọ̀ká tí ó ń ka ewì orí ṣirí
ṣi (I, iii). Níbi tí Baba Rámá (Ládépò) àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Àrẹ̀mú ti ń múra Ọjà
Ọba ni Òjó ti mú ìroyìn búburú ti ọkọ̀ Baba Rámá méjì tí ó forí sọ ara wọn
tí ogójì ènìyàn sì kú wá. Síbẹ̀síbẹ̀, Ládépò lọ sí ọjà lọ táákà owó. Wọ́n
fagagbaga títí (I, iv), wọ́n lu ìlù lálùya.
A tún wáá rí Bàbá, Olọ́kọọba àti
àwọn ọ̀mùti ní ilé ẹlẹ́mu kan (2, i). Wọ́n ń ròyin ìnáwó Ọjà Ọba, wọ́n sì
ń sọ̀rọ̀ lórí ìmọ̀wọ̀n-ara ẹni. Wọ́n ní nínú Omọ́mọ́ṣẹ́ àti Baba Rámá,
ẹnìkan ni yóò pa ara wọn. Níbo ni àwọn ènìyàn ti ń ri owó? Lẹ́yìn èyí, a
tún fi ẹsẹ̀ kan dé ilé Àrẹ̀mú (2, ii) níbi tí òun àti Àṣàbí ti ń sọ nípa
orí burúkú tí ó bá Baba Rámá: Ọkọ̀ mẹ́rin bàjẹ́, ó ta ilé mẹ́rin láti sanwó
mọ́tò Ilé kan tó kù sì tún wò. Àrẹ̀mú pinnu láti ran Ládepò lọ́wọ́. Òjó dúró ti
Baba Rámá nínú ìṣòro rẹ̀ (2, iii). Baba Rámá kábàámọ̀ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Ó fẹ́ẹ́
wọ ẹgbẹ́ awo. Nígbà tí Àrẹ̀mú wáá kí i, ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ̀ ọ́. Àrẹ̀mú lòdì sí
wíwọ̀ ẹgbẹ́ awo, ṣùgbọ́n nígbà tí Àwáwù dé ní tirẹ̀, ó fọwọ́ sí i. Baba Rámá
bá wọn lọ sí igbó ìgbalẹ̀ (2, iv). Wọ́n ní kí ó lọ mú wúnndíá wá kí ó wá gba
owó rẹpẹtẹ. Baba Rámá délé ròyin ohun tí ojú òun rí. Ó ní òun ò ṣe mọ́.
Ìyàwó rẹ̀ ń dá a lọ́kàn le. Níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀, Àyọ̀ká wọlé. Tọkọ, tìyàwó sì ń ronú àtitan
Àyọ̀ká lọ sí igbó ìgbàlẹ̀.
Àwáwù tan Àyọ̀ká lọ sí ẹsẹ̀ ìgbó
kan níbi tí àwọn gbọ́mọgbọ́mọ ti gbé e, tí Ládépò gbà á tí ó sì mú un lọ sí
gbó ìgbàlẹ̀. Wọ́n fún Ládépò lówó, Àyọ̀ká ń fi ewì dárò. Wọ́n di Àyọ̀ká
tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n fẹ́ẹ́ pa á. (3, ii) Baba Rámá ti padà délé pẹ̀lú owó gọbọi
ó sì ròyìn fún Àwáwù pé àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ti pa Àyọ̀ká. Tohun-tẹnu ẹ̀,
Àrẹ̀mú àti gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀ dé, wọ́n ń wá Àyọ̀ká. Ládépò àti ìyàwó rẹ̀ sì
tún ń bá wọ́n wá a (3, iii). Bàbá àti Olookọọba tún wà ní òpópó kan, wọ́n ń
sọ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ gbọ́mọgbọ́mọ. Òjó bá wọ́n níbẹ̀ ó lú à ṣírí ọ̀gá rẹ̀ Ládépò
tí ó wẹgbẹ́, ó sì sọ ti Àyọ̀ká tí ó sọnù. Gbogbo wọ́n túká. Àṣírí ọ̀rọ̀ tú
ní ilé Àrẹ̀mú (3, v) níbi tí gbogbo ènìyàn ti ń dárò. Tíṣà dámọ̀ràn pé ó yẹ
kí àwọn ọlọ́pàá gbọ́. Níbi tí Àrẹ̀mú àti Baba Rámá ti ń jẹun ni Àyọ̀ká ti
sáré wọlé. Wọ́n rò pé Wèrè ni. Ó ròyìn ohun tí ojù òun rí. Ọrọ̀ di ti
ọlọ́pàá.
Wọ́n rojọ́ ní kóòtù Ọmọ́mọṣẹ́ wáá
lulu jẹ́rìí (4, i, ii,iii). Adájọ́ dẹ́kun ìlù fún Ọmọ́mọṣẹ́ fún òṣùpá
mẹ́rìnlélógún. Ó sọ Kékeréawo àti Panńdukú sí ẹ̀wọ̀n ọjọ́ kan; ó dá ẹjọ́
ikú fún Irúnmọlẹ̀; ó sọ àwọn dánàdánà sí ẹ̀wọ̀n gbére. Adájọ ní kí Baba
Rámá ṣe ogún ọdún lẹ́wọ̀n kí Àwáwù sì ṣe ọdún mẹ́wàá
Ọ̀kan nínú àwọn kóko ọ̀rọ̀ tí a le
yẹ̀wò ni ti pé bóyá ìtàn náà dá léríi ohun tí ó le ṣẹlẹ̀ lójú ayé. Tàbí kí a
bèèrè pé ǹjẹ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú Wọ́n Rò Pé Wèrè Ni ní ó lè ṣẹlẹ̀ lójú ayé? A rí i dájú pé ọ̀pọ̀
nínú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú eré-onítàn
yìí ni ó jọ tí ojú ayé gan-an. Ọ̀pọ̀ nínú ìwà àti ìṣesí Àyọ̀ká àti àwọn òbí
rẹ̀ ni kọ̀ ṣàjèjì sí wa. A ti rí irú ọmọ bẹ́ẹ̀ rí. Nígbà gbogbo ni à ń rí
àwọn ìyàwó bíi Àwáwù, aya Ládépò, tí wọ́n ń fi ìmọràn búburú tí ọkọ wọn
sí kòtò. Ènìyàn bíi Bàbá, Olóókọọba, àwọn ajẹ̀gborodàgbà, tí kì í wọ́n nílé
ọtí sì pọ̀ láàrin ìlú. Ẹnu wọn ni a tí máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí gbogbo. Àsì
fi ẹni tí kì í bá jáde ni kòníi ti ri irú onílù bíi Ọmọ́mọṣẹ́ àti àwọn tí
ó ń fi ìwààwára náwó fún wọn. O sì tùn jẹ kí á ránti pé bí òǹkọ̀wé bá fẹ́
tẹ ọ̀rọ̀ kan mọ́ wá létí, yóò fi àsọdùn díẹ̀ sí i, kí ohun tí ó fẹ́ kí á mọ̀
le dúró lọ́kàn wa.
Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ibi kan wà nínú
eré-onítà Wọ́n Rò Pé Wèrè Ni tí ó ya
òǹkàwé lẹ́nu púpọ̀. Gbogbo wa la mọ̀ pé ìtàn àròsọ lásán ni ohun tí à ń kà
yìí, ṣùgbọ́n a gbà á gẹ́gẹ́ bí ìròyìn láti ẹni kan tí a gbẹ̀kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀,
ẹnì kan tí a lè sọ pé kì í purọ́. Bí ó bá wáá bẹ̀rẹ̀ síí sọ àwọn nǹkan tí
kò da wa lójú tó, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sínú, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú ìròyìn tí ó ń
ṣe yóò sì dínkù, a ó sì bẹ̀rẹ̀ sí máa bi ara wa pé ‘Ǹjẹ́ òótọ́ ha ni ọ̀rọ̀ tí
òǹkọ̀wé yìí ń sọ? A kò mà gbọ́ irú eléyìí rí’.
Nígbà tí orí burúkú bá Ládépò (Baba
Rámá), ọ̀nà tí gbogbo rẹ̀ gbà ṣẹlẹ̀ àti bí òun náà ṣe gbà á kò ṣàiya ni
lẹ́nu díẹ̀. Nígbà tí Ládépò gbọ́ tí Òjó sọ pé.
Mọ́tò méjèèjì ló ti rún wómúwómú
(ojú ewé 12)
àti
pé
Àwọn tí wọ́n kú níbẹ̀ ju ogíjì lọ
(ojú ewé 12)
o
yà wá lẹ́nu pé Ládépò lè la ẹnu sọ pé
Ètùtù làwọ́n eléyinì jẹ! (ojú ewé 13)
tí
ó sì takú tí kò lọ sí ibi tí ìjàǹbá náà ti ṣẹlẹ̀, ó kọ̀, ó ní:
… ó tì, ó yá jẹ́ ká lọ sọ́jà’ba. A
kìí tẹra ẹni.
Òǹkàwé
kan kò le tètè gbà pé oníṣòwò kan le fi
òfò rẹ́rìn-ín báyìí kí ó sì maa kánjú lọ sí íbi tí yoo tún ti ná owó.
Bóyá òǹkọ̀wé ṣe àbùmọ́ ìwà fún Ládépò báyìí kí á le rí i bí ìlù Ọmómọṣẹ́
ti jàrábà rẹ̀ tó ni.
Kò sí bí ọ̀rọ̀ ajalù ofò tí óbá Baba
Rámá náà kò ṣe níi jọ òǹkàwé lójú. Ọkọ̀ Ládépò méjì ló forí sọra wọn.
Àwọn méjì tó kù tún bàjẹ́. Ọkọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin bàjẹ́ lẹ́ẹ̀kan náà! (ojú ewé 26).
O tún ta gbogbo ilé rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láti fi sanwó ọkọ̀! O jẹ́ pé ilé kan dúró
fún owó ọkọ̀ ẹyọ kan. Ilé rẹ̀ kan ṣoṣo tó kù sì tún wáá wó! Kí á má purọ́,
irú kòńgẹ́ báyìí kò wọ́pọ̀ lójú ayé. Bóyá a lè sọ pé òǹkọ̀wẹ́ ṣe gbogbo èyí
láti fi hàn wá pé ohun ọrọ̀ ayé kò láyọ̀lè ni.
Ìhùwàsí Àyọ̀ká ní igbó ìgbàlẹ̀ náà
kò ṣàiya ni lẹ́nu. Ẹ̀rù kò bà á; ó láyà láti máa sú Ọmọ-Awo lóhùn (ojú ewé
57) ó sì tún ráyè láti máa ka ewì nígbà tí ikú ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀ (ojú ewé
60). Ọmọdé ha lè láyà tó báyìí? Ṣùgbọ́n bóyá gbogbo eléyìí kàn tún tẹ̀ ẹ́
mọ́ wa léti ni pé àkàndá ọmọ ni Àyọ̀ká. Èyí ó wù ká wí ṣá, kòńgẹ́ ògiri
igbó igbàlẹ̀ tí ó wó tí Àyọ̀ká fi ráyè sá jáde yẹn (ojú ewé 70) jẹ́
àràmọ́ǹdà, ó sì fẹ́ẹ́ lọ́ ìtàn náà pọ̀ mọ ọ̀rọ̀ àyànmó tàbí ti ẹ̀yọ
Ọlọ́run.
Ohun tí ó tún jọ wá lójú díẹ̀ ni
irú ìdájọ́ tí adájọ́ ṣe. Ṣé kò gbọ ìlù rí ni ó fi ní kí Ọmọ́mọṣẹ́ wáá lù ú
ni kóòtù ni? Èwo sì tún wáá ni ti ìlù ẹni ẹlẹ́ni tí ó ṣé fún ọdún méjì? Ó
fi Ládépò tí ó yẹ kí ó pa sílẹ̀, kò pa á, Irúnmọlẹ̀ lóní kí wọ́n pá! Ẹ̀wọ̀n
gbére fún dánàdánà, ogún ọdún péré fún Baba Rámá tí ó fẹ́ẹ́ lo ọmọ. Òfin tí
adájọ náà ń lò kò yé nit ó.
Gbogbo ohun tí a tóka sí wọ̀nyí sá,
kò dí wa lọ́wọ́ láti rí itú tí Fálétí pa nípa lílo ìwà àwọn ẹni-ìtàn láti fi
àṣírí ìbàgbépọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn láwùjọ han ni. Bí a bá wo ẹni ìtàn
mìíràn, a sì dà bí ẹni pé a ti rí i rí lójú ayé.
Tọkọtaya Àrẹ̀mú Àṣàbí fi
ìbágbépọ̀ ẹbi Yorùbá hàn wá nípa bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ àti bí wọ́n
ṣe ń tọ́ ọmọ wọn (ojú ewé 10). Àyọ̀ká fún baba rẹ̀ ní ìmọ̀ràn pé kí ó yé
náwó fún onílù, ṣùgbọ́n Àrẹ̀mú kà á sí ọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu ọmọdé lọ, ó sì
sọ fún un:
Dákẹ́ ẹnu rẹ. Báwa ti
í lọ síbi ijó kí wọ́n ó tó bí ọ nù-un!
Nígbà tí Àyọ̀ká sì tún bèèrè ibi tí
Rámá tí a fi ń pe Ládépò ní Baba Rámá wà, Àrẹ̀mú rò pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò kan
ọmọdé, ó ní:
Máa ṣe
nǹkan tó oń ṣe lọ, ọmọ ńlá!’
Ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀, Àṣàbí, rò pé ó
yẹ kí Àrẹ̀mú ṣe àlàyé fún Àyọ̀kà nítorí pé:
Ọmọ tó bá fẹ́ gbọ́n, a máa ń kọ́
ọ lọ́gbọ́n sí i ni
Èsì
tí Àyọ̀ká fọ̀ nígbà tí ó gbọ́ ìtàn Rámá tán, mú wa fúra, ó sì sín wa ní gbẹ́rẹ́
ìpàkọ́ nípa ohun tí Ládépò le ṣe àti nípa irú ewu tí ó ń rùn lórí Àyòká tí ó
ní:
Àbí wọ́n fi ṣòògùn owó ni? (ojú ewé
10)
Irú
ọ̀rọ̀ tí Àyọ̀ká ń wádìí wọ̀nyí ga jù lójú àwọn òbí rẹ̀ ni baba rẹ̀ fi sọ wí
pé:
Ọgbọ́n pọ̀!
tí ó sì fi àdúrà tì í pé:
Àfi kỌ́lọ́run kó bá ni
ṣọ́ ọ (ojú ewé 11)
láti mọ irú ewu tí ó wà lórí
Àyọ̀ká.
Àṣàbí jẹ́ aya rere tí kì í gbọ́
ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, tí ó sì ń fún ọkọ nímọ̀ràn nígbà tí ó bá wúlò. A rí Àrẹ̀mú
alára gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ òdodo tí ó fi gbogbo ara fẹ́ràn Ládépò. Ṣúgbọ́n ó dà bí
ẹni pé ẹnu lásán ni ó fi ń gba ọ̀rẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn, kò lọ́kàn àti bá a jà
lórí ohun tí a mọ̀ pé kò dára. Nígbà tí Ládépò ní dandan òun ní láti lọ sí
Ọjà Ọba lọ jó lẹ́yìn tí àwọn ọkọ̀ rẹ̀ ti ṣèṣe, kò yẹ kí Àrẹ̀mù tẹ̀lé e
lọ. Bóyá bí Ládépò bá rí i pé ọ̀rẹ́ òun padà lẹ́yìn òun, ìbá le mọ̀ pé ohun tí
òun ń ṣe kò dára. Irú ọkàn ọkùnrin tí Àrẹ̀mú ṣe nígbà tí Àyọ̀ká sọnù fi
hàn bí ẹnì kan tí ó mọ Ọlọ́run tí ó le kó ara rẹ̀ ní ìjánu. Ó ní:
A ó tiṣe? A ó gba kámú ni.
Bí a bá sọ pé a ó máa rò ó, a ó
ṣẹ ‘Lọ́’un
Ó
tún ní:
Ẹ má jẹ́ ká ṣàgbére s’ Ọlọ́run. Ènìyàn ò dàbí Olódùmarè.
Àtawun àtìgbín – ẹrú Ọ̀sanyìn ni.
Ẹ jẹ́ ká fóunjẹ ranu.
‘Ènìyàn bí ìgbín níí hègbín’ ni
ọ̀rọ̀ Baba Rámá àti Àwáwù, ìyàwó rẹ̀. Ládépò jẹ́ aláṣejù, ọ̀bùn tí kò mọ̀ pé
ohun tó pọ̀ a máa tán. Ṣe-ká-rí-mi, ìnáwó ìgbéraga ti wọ ọ́ lẹ́wù tó bẹ́ẹ̀ tí
ó fi jẹ́ pé kò sí ohun tí ó tún náání mọ́. Kódà, ẹ̀mí ènìyàn kò jọ ọ́ lójú.
Láti ìgbà tí mọ́tò rẹ̀ méjì ti ṣèṣe tí ó sì ti sọ pé ètùtù ni àwọn bíi
ogójì tó kú níbẹ̀ jẹ́ ni a ti mọ̀ pé Baba Rámá kì í ṣe ènìyàn gidi. Àléébù rẹ̀
pàtàkì náà ni pé kí orí rẹ̀ máa wú bí alágbe bá ń kì í, àti pé kò fẹ́ kí á sọ
pé ẹnì kan tún wà tí olówó ju òun lọ Bóyá Ládépò ìbá yí padà nígbà tí owó rẹ̀
run tí ojú rẹ̀ sì rí nǹkan ní igbó ìgbàlẹ̀ àmọ́ Èṣù-lẹ́yìn-ìbejì-ìyàwó rẹ̀ kò
jẹ́. Nígbà tí Ládépò ní òun kò wọ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ mọ́, Àwáwù ní dandan àfi bí ó wọ̀
ọ́. Àwáwù mọ àléébù ọkọ rẹ̀, ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ onílù ti ba orí rẹ̀ jẹ́. Nítorí
náà, ọ̀rọ̀ Ọmọ́mọṣẹ́ ni Àwáwú lò láti mú kí Ládépò tún fẹ́ẹ́ wọ ẹgbẹ́.
Àwáwù ní:
Tí
Ọmọ́mọṣẹ́ bá pàdé yín lóde,
Láàrin àwọn
ìjọ yín,
Tó bẹ̀rẹ̀ sí
yín í kì ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá
Tó ń kì yín
ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá
Tẹ́ ẹ wá
tọ́wọ́ bàpò tẹ́ ò rí nǹkan mú jáde-
Inú yín le
dùn sí i? (ojú ewé 48)
A ti mọ̀ pé inú Ládépò kò le dùn sí
i. Ìrànwó tí Àwáwù sì ṣe náà ló jẹ́ kí Ládépò rí Àyọ̀ká mú lọ sí igbó
ìgbàlẹ̀.
Bí Òjó, ọmọ ọ̀dọ̀ Ládépò, ṣe ń
sọ̀rọ̀ jọ ni lójú. Bí kì í bá ṣe dìndìnrìn, a jẹ́ pé ó ti láyà jù. Ṣe bí
ọmọ ọ̀dọ̀ ni? Ó fẹ́ẹ́ ròyìn ìjàǹbá tí ó ṣẹlẹ̀ fún ọ̀gá rẹ̀, ó sì láyà láti
sọ pé:
O… orí ti yín náà ló
burú, ọ̀gá mi! (oju ewé 12)
Bẹ́ẹ̀ náà ni nígbà tí wọn ń wá
Àyọ̀ká tí ó sọnù dé ilé Baba Rámá, Òjó ní òun ri i,’Nínú ẹ̀wù mi yìí ló wà’. Ó
gbọn ẹ̀wù títí ó sì tún sọ̀ pé kò sí níbẹ̀ mọ́. Nígbà tí Tíṣà tún wáá kí
Àrẹ̀mú nípa ti Àyọ̀ká tí ó sọnù, Òjó ní òun ṣe bí Àyọ̀ká ni Tíṣà gbé pọ̀n
ni. Ìwà tí Òjó sì tún wá hù nígbà tí ó ṣòro fún ọ̀gá rẹ̀, kò jẹ́ kí á le pè é
ni òmùgọ̀ táàrà. Ó ní:
Ẹyẹlẹ kì í bónílé
jẹ, kí ó bó nílé mu, kí ó dọjọ́ ikú kó yẹrí (ojú ewé 78)
Ṣùgbọ́n Òjo kan náà yìí ló tún ń
tú àṣírí ọ̀gá rẹ̀ fún Bábá àti Olóókọba tí ó ń sọ pé ọ̀gá òun ti wẹgbẹ́.
Ohun tí a lè sọ pàtó nípa Òjó ni ọ̀gá rẹ̀ Baba Rámá ti sọ, ó ní:
Aṣiwèrè
ni! Ọgbọ́n rẹ̀ máa ń darí lọ dári bọ̀ bíi kànnàkànnà ni .. (ojú ewé 62)
Bàbá àti olokọọba dúró bíi aláwàdà
láti dá wa lára yá, kí ìtàn tí à ń kà má ba à korò jù. Ṣùgbọ́n nígbà tí Bàbá
àti Olokọọba bá ń sọ̀rọ̀, bí a ti ń rẹ́rìn-ín ni a sì ń rí ọgbọ́n kọ́.
Ẹnu wọn ni a ti ń gbọ́ oríṣiríṣi ohun àṣírí tí ó ń lọ láàrin ìlú.
Ajẹ̀gborodàgbà ni wọ́n, bí a kò bá pàdé wọn ní òpópó kan, à sì tún fi ilé
ọti. A kò mọ ibi tí wọ́n ń gbé gan-an. Gbogbo kókó ọ̀rọ̀ tí eré yìí dá lé
lórí ni àwọn aláwàdà ọ̀rọ̀ wọ̀nyí rí ọ̀rọ̀ sọ sí. Nípa ọ̀rẹ́ ṣíṣe, Bàbá ní
‘Kò sọ́rẹ̀ẹ́ mọ́ lóde òní sẹ́’ (oju ewé viii). Olóókoọba náà sì kín in lẹ́yìn
pé: ‘Ajé ní í bojú ọ̀rẹ́ jẹ́’ (ojú ewé 25). Àwọn ni wọ́n ṣàlàyé fún wa nípa
bí àwọn ènìyàn ṣe ń fi iṣẹ́ kékeré bojú tí wọ́n sì ń ṣe fàyàwọ́ lábẹ́lẹ̀.
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni a ti mọ̀ pé Àyọ̀ká
kì í ṣe ọmọ lásán, orí rẹ̀ pé, ó mọ̀wé, ó sì gbọ́n. Ó mọ̀wé dé ibi pé wọ́n
mú un fún ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́; ó sì gbọ́n tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí baba rẹ̀ alára fi sọ pé:
Ọgbọ́n
pọ̀! Afi kí Ọlọ́run kó bá ni sọ́ ọ.
Láti
kékéré ni ó ti ń hùwà àgbà. Nígbà tí ó gbọ́ pé baba rè ń tẹ̀lé Ládépò lọ sí
Ọja Ọba, ó gbà á nímọ̀ràn pé kò yẹ kí á máa kó owó ti a làágùn kí á tóó ri
fún onílù, ó sì fi òwe kan parí rẹ̀:
Nítorí ọjọ́
ọ̀wọ́n la á ṣe é yọ̀ mọ níwọ̀n nígbà ọ̀rọ̀. (ọjú ewé 18)
Ọmọ tí ó láàánú lójú ni. Nígbà tí
ó gbọ́ ìròyìn ọkọ̀ tó ṣèṣe, òun nìkan ni ó rántí ronú nípa àwọn tí ó kú.
Óní ‘Àwọn tí wọ́n kú ńkọ́?’ (ojú ewé 14). Àánú tí ó ní yìí náà ni kò fi
kọṣẹ́ fún Àwàwù ọ̀rẹ́ ìyá rẹ̀ tí kò bímọ. Ó sì sọ fún Àwáwù níwájú adájọ́
pé:
Bí o bá sì
bẹ̀ mi níṣẹ́ tí mo kọ̀ fún o lè bà ọ́ lọ́kàn jẹ́. (ojú ewé 75)
Ojú àánú yìí ni ó fẹ́rẹ̀ kó bá a
tán. Irú ìgboyà tí Àyọ̀ká ní nígbà tí wọ́n fẹ́ẹ́ pa á kò ní ṣàìyà wa lẹ́nu. Bí
wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ni óń dá wọn lóhùn, tí ó sì sọ pé òun gbẹ́kẹ́lé Ọlọ́run
òun. Èyí tí ó tilẹ̀ ya ni lẹ́nu jù lọ ni pé ó tún ráyè fi ewì ki baba rẹ̀ tí ó
sì ń sọ pé:
Igi tá à bá
fẹ̀hìntì
Baba mi,
Àrẹ̀mú, ló ti mẹ́gùn-ún j’ẹ̀dẹ́.
Ènìyàn tá à
bá finú hàn ló jáláròkiri ẹni (ojú ewé 60)
Ṣààṣà ni ọmọ tí ó le láyà irú
rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí pé Àyọ̀ká jẹ́ olóye ọmọ tẹ́lẹ̀ ni kò jẹ kí ó jọ wá
lójú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ifẹ́ tí a sì tí ní sí Àyọ̀ká ní ó jẹ́ kí irú ọ̀nà àrà tí
Ọlọ́run gba yọ ọ́ yẹn dùn mọ́ wa.
Ìwé eré-onítàn Wọ́n Rò Pé Wèrè Ni mú wa ronú púpọ̀ nípa ìbaṣepọ̀ àwa ọmọ ènìyàn
nílé ayé. A rí ẹ̀kọ́ kọ́ nípa ọ̀rẹ́ ṣíṣe, a sì rí kọ́ nípa bí ìwà àwọn
ẹlòmíràn ṣe ń ran ìṣesí tiwa lọ́wọ́. Ohun tí oníkálukú ń náání yàtọ̀ síra
wọn.
Ọ̀rẹ́ Ládépò àti Arẹ̀mú wọ̀ nigbà tí
ó ń dán fún àwọn méjèèjì, tí òdá owó kò dá ẹnì kan kan. Àrẹ̀mú tí kò là
rẹpẹtẹ ní ìtẹ́lọ́rùn, kọ̀ sì sọ pé
ẹni tó lówó ṣe náwó rẹ̀ bó bá ṣe fẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí Ládépò sọ ṣe
pàtàkì níbi tí a dé yìí, pé
Ohun tójú kò
bá rí rí
Tí ojú bá rí
i, kì í ṣèèmọ̀ ojú
Ohun tójú bá
ti ń rí, tójú ò rí mọ́, òun lèèmọ̀ (ojú ewé 75)
Èyí ni pé nígbà tí ọ̀rọ̀ burúkú bá
ṣẹlẹ̀ ni a tóó lè mọ bí ìwà ẹnì kan ti dára tó. Ìdààmú dé bá Ládépò, ó ṣì
ṣe. Ládépò kò ní ẹ̀mí tí ó fi le gba kámú irú àyípadà bẹ́ẹ̀. Àjọ̀jẹ kò wáá
dùn mọ́ nítorí pé Baba Rámá kò ní mọ́.
Síbẹ̀sibẹ̀, bí a bá dẹ́bi fún baba
Rámá tán, ó yẹ kí a rántí pé ajíbè pọ́nlá ni àwọn ènìyàn yòókù tí ó yí i ká
náà, àwọn náà ṣe díẹ̀ lólè. Ìwà àwọn tí ó wà ní àwùjọ Ládépò ràn án lọ́wọ́
nínú ibi tí ó ṣe. Lọ́nà kìínní, bí ó bá jẹ́ pé Àrẹ̀mú ti ń bá a jà gidi lórí
inákúnàá ni, bóyá, Ládépò ìbá ti ronú pìwàdà, ìbá ti máa ṣọ́ owó ná, àyípadà
yìí kì bá sì tí ni ín lára tó bẹ́ẹ̀. Bí a bá sì tún wo ipa tí Àwáwù, ìyàwó
Ládèpò kó nípa àṣìṣe yìí, a ó rí i pé Èṣù-lẹ́yìn-ìbejì ni. A kò gbọ́ ìgbà
kan rí ti Àwáwù kìlọ̀ fún ọkọ rẹ̀ pé kí ó rọra náwó. Nígbà tí Ládépò sì lọ
sí igbó ìgbàlẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, ó pinnu pé òun kò tún bá wọn débẹ̀ mọ́ (ojú ewé
45). Ṣùgbọ́n Àwáwù fi tipátipá mú un padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ìmùlẹ̀.
Àwàwú ló ṣe ètò bí ọwọ́ gbọ́mọgbọ́mọ se tẹ Àyọ̀ká. Àwọn gbọ́mọgbọ́mọ
àti àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ pàápàá kò níí ṣàìpin nínú ẹ̀bi Baba Rámá. Bí kò bá sí
tiwọn ni, ètò náà kì bá ti ṣeé ṣe.
Ẹ̀bi gbogbo àwọn ará ìlú papàá pọ̀
nínú àìle gba kámú Ládépò. Wọ́n ti gbé Ládépò gun ẹṣin aáyán Gbogbo ènìyàn ló
ń lọ wòran ìnáwó rẹ̀ lọ́jà Ọba. Bí ó bá sì ń kọjá lọ, tọmọdé tàgbà,
‘pàápàá àwọn òbinrin, wọn a tún máa gbẹ́nu sókè: Baba Rámá! Baba Rámá!
Gbọngbọ́n-gbọ́ngbọn!! Ó jọun pé wọn ò níṣé tí wọn ó ṣe?’ (ojú ewé 35).
Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ń mú Ládépò ronú
tí wọ́n jẹ́ kí ó máa rántí ìgbà tí ó ti dára fún un tẹ́lẹ̀.
Lóòótọ́, adájọ́ dá Ọmọmọṣẹ́
lẹ́bi, ṣùgbọ́n bí a bá rò ó dáradára, a kò rí ẹ̀bi dá fún onílù. Àwúre alágbe
ò le mú ẹlẹ́wù kan. Ẹni tí ó bá lówó ló le ná an fálágbe. Ẹni tí orí rẹ̀ bá
wú ju iṣẹ́ apá rẹ̀ lọ ni ó fẹ́ẹ́ tẹ́. Iṣẹ́ alágbe ni alágbe ń ṣe. Wọn kì
í fi tipátipá mú ènìyàn.
Ètò ìtàn inú ere-onítàn Wọ́n Rò Pé Wèrè Ní yìí jẹ́ èyí tí ó jìnlẹ̀
púpọ̀. Gbogbo rẹ̀ dá lé bí àléébù ìwà àṣejù ẹnì kan ṣe tì í dé ibi tí ó ti
ṣe àìdára tí ó sì wáá tẹ́. Bí ìwà ìbàjẹ́ bá hànde tán, ẹni tí ó hù ú.
A di olórí
oníbajẹ̀
Tí í wọ mà
ǹtín-ìn funfun. (ojú ewé 8)
Kí eré tóó bẹ̀rẹ̀ ni Fálétí ti ṣòfófó ohun tí ó fẹ́ẹ́ ṣe
fún wa; pé ọ̀rẹ́ kò sí mọ́ ọ̀dàlẹ̀ ló kù. Bí eré ti bẹ̀rẹ̀ ni òǹkọ̀wé ti tan
iná sí ọpọlọ pípé àti ìwà rere Àyọ̀ká, tí ó sì ti jẹ́ kí ìfẹ́ wa darí sọ́dọ̀
rẹ̀. Óńkàwé á máa retí ìgbà tí Àyọ̀ká yóò kàwé parí tí yóò sì di ọmọ tí ó ń
ṣe orílẹ̀-èdè lore. Baba rẹ̀ ń fẹ́ ko kọ̣́ṣẹ́ amòfin. Fálétí ṣe gbogbo
eléyìí láti mú ki ẹ̀sẹ̀ Ládépò wúwo gan-an ni. Bí ó bá jẹ́ dìndìnrìn ọmọ kan
ni ó gbé, kò níí mú wa lára tó bẹ́ẹ̀.
Lẹ́yìn tí òǹkọ̀wé ti sọ Àyọ̀ká di
ààyò òǹkàwé tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbin èso àléébù ìwà Ládépò, ìwà tí yóò fíi
dáràn: O ń lọ táákà owó ní Ọjà Ọba. Fálétí tún jẹ́ ká rí i pé ìwà ìbàjẹ́
yìí ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi pé kò mójú tó iṣẹ́ ara rẹ̀ mọ́, kò bìkítà fún ọkọ̀
rẹ̀ méjì tó jáàmù. Èyí ni ó jẹ́ kí a gbà pé kò sí ohun ibi kan tí ó lè fi
Ládépò lọ́wọ́ láti ṣe, a sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ládépò tó
lówó ni a bá pàdé nínú ìtàn ní ìbẹ̀rẹ̀. Níwọn ìgbà tí ó bá sì ń rí owó ná,
àdánwò tí ó le kan kò le sí fún un. Èyí ni ó mú Fálétí gbé àdánwò tí ó nira lé
Baba Rámá láyà. Owó tán lọ́wọ́ oníwà, ó dòṣónú. Ẹni tí ọ̀ràn kò bá ni ó ń pe
ara rẹ̀ ní ọkùnrin. Ẹ̀rù tí ń ba Ládépò láti wọ ẹgbẹ́ ìmùlẹ fi hàn pé
iṣẹ́ tààrà ni ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kò fi ẹ̀rú bọ̀ ọ́. Bóyá Ládépò ìbá sì gba kámú,
àmọ́ ọ̀kánjúwà obìnrin ti Fálétí fún un kò fi í lọ́rùn sílẹ̀. Ótì í dáràn tán,
ni ẹsẹ̀ òkú tí wọ́n sin bá yọ sílẹ̀.
Ara àwọn ẹ̀kọ tí Fálétí fẹ́ẹ́ kọ́
wa nínú ìtàn yìí ni pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ lérè àti pé Ọlọ́run ń bẹ lẹ́yìn aṣòdodo.
Ọ̀dàlẹ̀ jìyà ìtìjú, ikú àti ẹ̀wọ̀n. Ọlọ́run tí sì ń bẹ lẹ́yìn àyọ̀ká àti
àwọn ẹbí rẹ̀ ni ó rọ̀jò tí ó ya ògiri tí ọmọ fi ríbi sá lọ.
Bí a bá wá yẹ èdè tí Fálétí lò nínú
eré-onítàn yìí wò, ó yẹ kí á kan sáárá sí i. Lóòótọ́, bí a bá ní kí a máa
tanná wá oríṣiríṣi àwọn adùn-èdè tí ó
wà nínú Wọ́n Ró Pé Wèrè Ni, ilẹ̀ yóò
kún. Kò sí ìwé àròsọ kan tí a kò le rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ oríṣi ọnà-èdè,
ṣùgbọ́n ohun tí ó wúlò gan-an ni pé kí á gbìyànjú kí á wá àwọn ọgbọ́n
asọ̀tàn, àwọn ọnà èdè tí ó jẹ òǹkọ̀wé lógún jú lọ. A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé
akéwì ni Fálétí, gedegbe sì ni ẹ̀bùn yìí hàn nínú Wọ́n Ró Pé Wèrè Ni. A ó ṣàkíyèsí pé nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ká òǹkọ̀wé
yìí lára, nígbà tí ó bá ní nǹkan pàtàkì láti sọ ni ó máa ń lo ewì. Ṣé a mọ̀
pé dídùn létí ewì a máa dùn ún rántí ju ọ̀rọ̀ wuuru lọ. Ibi tí a kọ́kọ́ ti gbádùn ewì ni Idán kìínní, Ìran
kejì, níbi tí Bàbá ti ń bá Olóókọ-ọba tàkurọ̀-sọ. Ọ̀rọ̀ ewì àdáyébá ni Fálétí
lò níbí. Bí ó ti ń pa wá lẹ́rìn-ín ni ó ń fún wa ní ìmọ nípa ipò tí àwọn
ènìyàn fi Ládépò sí ní ààrin àwùjọ. Olóókọ-ọbá ní:
Samuẹli ò sí ní Mọ́sálá
ṣí
Olóókọ-ọba ò sí ní
Ṣóọ̀ṣì
Ká tó rágba ó dinú igbó,
Ìtàkùn bí kerékerè
dẹ̀hìn ọ̀dàn
Kò sí rú kán-ún láàrin
òkúta,
Bẹ́ẹ̀ ni kò sírú iyọ̀
lérùpẹ̀ (ojú ewé 6)
Ó wáá fi ye Bàbá pé:
Baba Rámá ló fẹ́ ṣe
bẹbẹ
…
A náwó bí ẹlẹ́dà.
Ìbéèrè tí Bàbá bèèrè pé ‘Àbí ẹlẹ́dà náà ti ‘ẹ̀ ni?’ ló fa ewì
tó jíire tí Olóókọ-ọba fi sọ fún wa pé ọ̀nà èrú àwọn ènìyàn ń gbà lówó:
Olówó wo lólóòlótọ́ lóde
òní?
…
Bẹ́ẹ̀ ni tìmùtìmù sí
kẹ́gbin dà s’ínú. (ojú ewé 6)
Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà ti Àyọ̀kà ń rán
àkọ̀sórí tí ó kọ́. Ewì ni Fálétí lò níbí láti ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo ènìyàn àti
lá ti ta wá lólobó ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ níwájú nínú ìtàn yìí, ó ní:
Má ṣe bá olè kẹ́gbẹ́.
nítorí pé ẹni tí ó bá ń jalẹ̀, yóó
wẹ̀wọ̀n:
A di olórí oníbàjẹ́
Tí í wọ mà ǹtín-ìn
funfun… (ojú ewé 8)
Ẹnu àwọn onílù ni a tún ti gbọ́
ewì tí ó jíire nítorí pé wọ́n mọ̀ pé bí ewì bá dùn, a máa mú orí yá. Bí orí
ẹni bá sì wú, àtináwó kì í ṣòro. Ọmọ́mọṣẹ́ ki Ládépò títí:
Ò dé kílé ó kún, ò kún
ẹ̀dẹ̀ tẹrùtẹrù
…
Abìrìn gbẹ̀rẹ̀ bí ẹni
ẹ̀gbẹ́ ń dùn
Ègbẹ́ kò dùn ún, ẹgbẹ́
rẹ̀ ni kò fẹ́ í kí
…
Ọkùnrin kọ́rọ́bọ́tọ́ bí
ọká o!
Àfàìmọ̀ laṣọ rẹ kò ní
í bá wa lọ … (ojú ewé 16)
Baba Rámá kò mọ ìgbà tí ó bọ́ ẹ̀wù ọrùn rẹ̀ fún onílù. Agbára ewì
nìyẹn.
Gbogbo ibi tí ó fa ọ̀rọ̀ ironú
jinlẹ̀ ni Fálétí tí lo ewì. Nígbà tí ọ̀rọ̀ Ládépò dàrú tí ó wá ń kẹ́dùn, ewì
ló lò. Ìgbà tí ó ń pinnu àtiwọ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, ewì náà ló fi fún wa ní ohun tí ó rò débẹ̀ (ojú ewé 36). Ní
igbó ìgbàlẹ̀ ewì ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ ni wọ́n ń sọ. Kódà,
nígbà tí Àyọ̀ká gan-an rí ikú báyìí, ewì ni ó fi dárò tí ó dágbére fún ayé (ojú
ewé 59). Nígbà tí ọ̀rọ̀ tún dé ilé ẹjọ́, àtọ̀daràn, àtadájọ́ ló ń lo ewì
nítorí pé ọ̀rọ̀ tí ó múni lọ́kàn ni wọ́n ń sọ.
Bí a kò bá le máa to àwọn
àkànlò-èdè àti òwè inú eré yìí lẹ́sẹẹsẹ, ó yẹ kí á le mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ ẹ̀rín
àti àwàdà tí Fálétí fi já àlùbọ́sà sí èdè tí ó lò. Gbogbo ibi tí a bá ti pàdé
Bàbá, Olóókọ-ọba àti àwọn ọ̀mùtí, àrínlamilójú ni ẹ̀rín. (Wo ojú ewé vii, 6,
21, 22, 23, 24, abbl.). Ọ̀rọ̀ ẹnu Òjó
náà sì tún má ń pa ni lẹ́rìn-ín ní ọ̀pọ́lọ́pọ̀ ìgbà.
Rẹ́rẹ́
Rún: Bírà tí Òkédìjí fi èdè dá
Ìtàn
eléyìí dá lérí akitiyan àwọn òṣìṣẹ́ láti mú kí ayé dẹrùn díẹ̀ sí i fún ara
wọn àti àìbìkítà fún ìrọ̀rùn àwọn òṣìṣẹ́, láti ọ̀dọ̀ àwọn ibi iṣẹ́. Nínú
ìtàn yìí, ìyà ń jẹ àwọn òṣìṣẹ́, wọ́n sí fi ìyà tí ó ń jẹ wọ́n yìí àti
ìpinnu wọn láti gbọ́nyà nù hàn nínú orin àjùmọ̀kọ wọn: “Èrò tí ń r’Òjéje”
tí ó kún fún ìtumọ̀. Ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́, Làwáwo, wà látìmọ́. Níbẹ̀ náà ni a ti
rí Ìdòwú tí ó ń gbèjà àwọn ọ̀gá tí ó sì tako àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Mopé, akọ̀wé,
jẹ́ kí á mọ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ ọọ́fíìsì náà wà lẹ́yìn ẹgbẹ́ níbi tí Láwúwo ń
ṣe ọ̀gá.
Ìwà ìkùnsínú àti ìfọwọ́hẹṣẹ́ yìí
bí Onímògún àti àwọn ìjoyè rẹ̀ nínúi. Wón sọ̀rọ̀ Láwúwo pé ọwọ́ líle ló ràn
án. Onímògún rí owó ra àga olówó iyèbíye, ṣùgbọ́n kòrówó san owóoṣù òṣìṣẹ́
oṣù tó kọjá, ó sì tún fẹ́ kí a máa mù òṣìṣẹ́ fún àìsan owó-orí. Arẹ̀ṣà,
ọkan nínú àwọn ìjòyè ìlú, fẹ́ẹ́ lo Ìdòwú láti dáwó láti fi ran ọ̀gá wọ́n,
Láwúwo, tó wà látìmọ̀, lọ́wọ́. Wọ́n dá owó tí ó lé ní àpò mẹ́rin naira. Láwúwo
kúrò látimọ́, ó bá wọn níbi wọ́n ti ń dawó. Ó bínú púpọ̀. O sọ̀rọ̀ lórí
ìrẹ́jẹ àti àìdọ́gba àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ múra àtijìyà. Kò fẹ́ ìrànwọ́ owó, kò fẹ́
lọ́yà. Wúràọ́lá, ìyá-ẹgbẹ́, bẹ̀ ẹ́ tì.
Síbẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ kó àpò mẹ́rin
náírà fún Morẹ́nikẹ́, ìyàwó Láwúwo, kí ó bá wọn fún un. Láwúwo pinnu láti dá
owó padà. Ó sọ ìtàn ìdílé rẹ̀ pé ìyà ni baba àti ìyà òunjẹ kú. A gbọ́ nípa
òògùn tí Morẹ́nikẹ́ ń lò fún ẹ̀fọ́rí.
Àwọn ìjòyè fẹ́ẹ́ fi ọgbọ́n mú kí
Láwúwo ṣe tiwọn nípa fifi owó àti ìdẹ̀ra bọ̀ ọ́ nínú. Láwúwo kọ̀ nítorí pé
àǹfààní na kò kárí àwọn òṣìṣẹ́. Wọ́n ya oríṣiríṣi fọ́tò Láwúwo níbi ìpàdé
rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Wọ́n dẹ Ìdòwú láti kó bá Láwúwo kí òun sì di ọ̀gá
iṣẹ́.
Ìdòwù dẹ àwọn oníjìbìtì láti
dọ́gbọ́n gba owó lọ́wọ́ Mọrẹ́nikẹ́. Wọ́n gba àpò márùn-ún àti ogún náírà náà.
Mọrẹ́nikẹ́ gbé májèlé jẹ, ó kú nítorí pé ó mọ̀ pé òun ti ṣẹ Láwúwo.
Olúgbọ́n wáá jíṣẹ́ onímògún fún
àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi iṣẹ́ wọn. A yan Ìdòwú (ọ̀dàlẹ̀) ní olórí. Orí Láwúwo ti
dàrú, ó ń sọ kántankàntan. Nígbà tí Onímògún yọ sí àwọn òṣì ṣẹ́, wọn kò dọ̀bálẹ̀
kí i, wọ́n ń bínú, wọ́n ń kùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó dá Adéníyì dúró lẹ́nu
iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ́, eegun ẹ̀yin wọn ṣẹ́. A yọ́ naira mẹ́jọ mẹ́jọ nínú owó
wọn, owó orí wọn lé naira méjì méjì, àkókò iṣẹ́ wọn sì gun sí i. Wọ́n kò le
sọ̀rọ̀ mọ́, Ìdòwú sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣiṣẹ́. Àfi Mopélọ́lá, obìnrin
akọ̀wé, nìkan ni ó sọ̀rọ̀ burúkú sí àwọn ọ̀gá iṣẹ́, ó sì fi iṣẹ́ sílẹ̀.
Àwọn yòókù ọ̀bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú orin ‘Èrò tí ń r’Òjéje’.
Bí a bá wo àwọn ẹni-ìtàn inú ìwé
yìí, a ó rì i pé kò sí èyí tí ó ń dá ìwà hù fún ara rẹ̀, àjọṣe ni gbogbo
ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Láwúwo ni olórí àwọn òṣìṣẹ́. Kò jà fún ara rẹ̀. Wọ́n tì í
mọ́lé, kò bínú, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ dáwó fún un, ó kọ̀ ọ́; ó ní:
…ẹ tún
fẹ́ẹ́ máa ró òsun dà sínú ibú?
Wúràọ́lá bẹ̀ ẹ́ kí ó rọra máa ṣe
Dẹjú o
rímu, Láwúwo (ojú ewé 32).
Ṣùgbọ́n Láwúwo ní ‘kí odò máa gbé
àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi lọ, ki n dijú?” (ojú ewé 33). Ò kọ ọ̀rọ̀ àbẹ̀tẹ́lẹ̀
àwọn ìjòyè nítorí kò mọ ti ara rẹ̀ nìkan.
Síbẹ̀ a rí i pé Láwúwo ni àwọn ìwà
kan tí ó yà á sọ́tọ̀ láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Ó dà bí ẹni pé ìrìn ni àwọn yòó
kùn rìn níbi tí òun ti ń sáré. Àwọn fẹ́ẹ́ dáwọ́ lọ́yà òun kò fẹ́. Nígbà tí ó
ya wèrè, kò sí ẹni tó ó láyà láti máa bá ìjà na lọ. A ha le sọ pé agídí rẹ̀
ló ba nǹkan jẹ́ fún òun àti gbogbo àwọn òṣìṣẹ́? Bóyá bí ó bá dẹjú, ìbá
rímú? A kòrí i bá wí, nítorí a mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni gbogbo ohun tí àwọn ìjòyè
ṣe ìlérí fún un. Àbí a tún le sọ pé àyànmọ̀ Láwúwó ni ó tì í dé ibi tí ó dé
yìí pé orí burúkú rẹ̀ ni ó fi kó bá àwọn òṣìṣẹ́? Bí a bá gbọ́ ìtàn ìdílé rẹ̀
tí ó sọ (ojú ewé 39), a tún le sọ́ pé àjọbí ni ìyà tó jẹ yìí: ògiri ni ó wó
pa baba rẹ̀, níbi tó ti ń mọ́lé onílé; ìyà rẹ̀ sì ya wèrè níbi tó ti ń tọ́jú
ọmọ mọ́kànlá, òun nìkan! Ó ní:
‘Iwọ wo orógùn tí ń
rokà, ọkà mélòó ni orógùn ń jẹ? ...
Ìṣẹ̀dálẹ̀ ilé wa ni,
k’á máa ṣiṣẹ́ oníṣẹ́…’
Bí a bá wáá rò ó jinlẹ̀ ṣá, a ó rí
i pé Láwúwo dúró fún ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá tí wọn ń fi ìgbésí ayé wọn sin
ọmọ ènìyàn. Ìdílé yẹn dúró fún gbogbo àwọn ènìyàn ní oríṣiríṣI orílẹ̀-èdè
tí wọ́n ti ń jà fún ìrọ̀run àwọn mẹ̀kúnnù, tí àwọn gan-an kì í sì í jọrọ̀
kankan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, iṣẹ́ wọn kì í yọ, nítorí pé kò sí ìsowọ́pọ
ṣùgbọ́n orúkọ wọn kì í parẹ́.
Ọ̀rọ̀ àìsí ìsowọ́pọ̀ yìí ló dífá fún
irú Ìdòwú tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú òṣìṣẹ́ ṣùgbọ́n tí ọ̀kánjúwà rẹ̀ kò jẹ́ kí ó le
ronú ire àjùmọ̀ní àfi ọ̀rọ̀ ànìkànjọpọ́n ti ara rẹ̀. Pé òun ń gbádùn, tí
àwọn yòókù sì ń jìyà, kò dà á lọ́kàn rú rárá. Bí irú àwọn bí i Ìdòwú bá ti
le wà láàrin àwọn òṣìṣẹ́, àtijagun mólú yóó ṣòro. Ìdòwú kàn dúrò fún ohun
èlò tí a kàn le fowó rà láti ṣiṣẹ́ ibi.
Àwọn ìjòyè rí Ìdòwú lò láti yẹjú
Láwúwo tí ó jẹ́ abẹnugan àwọn òṣìṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Láwúwo ṣe dúró fún àwọn
òṣìṣẹ́ tí ìyà ń jẹ, tí ó sì ń jà fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni Onímògún dúró fún
àwọn arẹ́nijẹ agbaniṣíṣẹ́ tí wọ́n rò pé mẹ̀kúnnù kan kò láṣẹ́ àti gbó wọn
lẹ́nu. Ó ní:
Ìlá a máa ga ju olóko 1ọ? (ojú ewé
15)
… ilá t’ó bá ga ju olóko lọ…ṣógà!
Àwọn
òṣìṣẹ́ ni ilá, àwọn ìjòyè ni olóko. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà tí ó gbọ́
pé àwọn òṣìṣẹ́ ń fẹ́ ipò nínú ìgbìmọ̀ ìlú? Ó ní:
Wọ́n ń fẹ́ẹ́ ní …
a-ṣo-jú…!!! (ojú ewé 16)
Irú àyípadà bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì sí i. Ó bi
Balógun tí ó fẹ́ẹ́ máa gbe àwọn òṣìṣé: ‘Balógun, ìwọ náà kúkú ṣe iṣẹ́
ìjọba rí. Ǹjẹ́ o kọ́lé rárá títí o fi fẹ̀yìn ti lẹ́nu iṣẹ́?’ Tí Onímogún ni p
é ẹni tí ó bá ti wà nípò ọlá, òkè ni yóò máa wà láéláé. Ó gbà pé ọwọ́ líle
ló ran àwọn òṣìṣẹ́: ‘ẹni tó bá fojú di Ọba, àwówó á wóo ni’ (17). Agbára
ipò tí wọ́nní, owó tí wọ́nrí lò, ìṣẹ́ ti ó ń ṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti ọ̀dàlẹ̀
ààrin wọn ni ó mú iṣẹ́ àwọn ìjòyè rọrùn.
Bí a ti rí ọ̀dàlẹ̀ (Ìdòwú) láàrin
ọ̀sìṣẹ́ bẹ́ẹ̀ la sì rí ènìyàn rere
láàrin àwọn ìjòyè. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti hàn pé Balógun fẹ́ràn àwọn òṣìṣẹ́ ó
sì ń fẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ gbogbo ohun tí wọn ń fẹ́. Nígbà tí Onímògún ń
bínú, Balógún rọ̀ ọ́ pé:
Bí
yànmùyánmú bá bà lé ọmọ ẹni lórí a kò gbọdọ̀ yọ kùmọ̀ pa á (ojú ewé 15).
Sùúrù ni Balógún ń fẹ́ kí wọn fi
mú ọ̀rọ̀ náà, ó sì ń sọ fún àwọn ìjòyè yòókù nígbà tí Onímògún jáde tán pé:
‘Ọ̀rọ̀ tí à bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mú ni Onímògún ń fẹ́ẹ́ fà lákọ yi’ (ojú ewé
18). A sì fura pé ‘Ìjòyè ńlá kan láàrin ìlú yi’ tí ó fún àwọn òṣìṣẹ́ ní
ọgọ́rùnún náírà nígbà tí wọn ń dáwó níláti jẹ́ Balógun. Ohun tí kò jẹ́ kí
ọ̀rọ̀ Balógun tà láàrin àwọn ìjòyè ni pé òun nìkan ni. Àwọn ìjòyè yòókù kò
ronú bíi tirẹ̀.
Ohun tí ó jẹ́ kí ìjà àwọn òṣìṣẹ́
kùnà náà ni pé lóòọ́tọ gbogbo wọn ló wà lẹ́yìn Láwúwo, kò sí èyí tí ó láyà
láti le fara da ìyà bí i tirẹ̀. Mopélọlá nìkan ni ó láyà láti fi iṣẹ́ sílẹ̀
bóyá nítorí pé ó mọ̀ pé òun yóò tètè rí iṣẹ́ níbòmíràn ni nígbà tí ó jẹ́ pé
àwọn atẹ̀wé wọ́n. Síbẹ̀síbẹ̀, irú ọ̀rọ̀ tí ó dúró sọ sí wọn fi hàn pé òun ni
ó tún súnmọ́ Láwúwo nínú ìgboyà. Ó sì dà bí ẹni pé Òkédìjí fi ọ̀rọ̀ Mopélọ́lá
yìí ṣe ìkìlọ̀ ìkẹyìn fún àwọn aṣebi láti dá wa lọ́kàn le díẹ̀ ni.
Lóòọ́tọ̀ ìtàn inú Rẹ́rẹ́ Rún dún, ó sì mú wa lọ́kàn púpọ̀,
ṣùgbọ́n ibi tí iyí eré náà wà ni nibi èdè aláràbarà tí òǹkọ̀wé lò. Ó yẹ kí á
rán ara wa létí pé bí a bá ń sọ̀rọ̀ lítíréṣọ̀, ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni
irú èdè tí òǹkọwé fi kọ ọ́. Ọ̀rọ̀ ṣákálá, ìròyìn lásán, àtòpọ̀ ohun àṣà
tàbí ti òṣèlú kọ́ ni lítíréṣọ̀. Mímọ èdè lò ni a fi ń dá àwọn ojúlówó
òǹkọ̀wé mọ̀. Bí a bá dé ibi èdè lìlò, a kò le fi àlùkùráánì wé áábíídíí, ká má
fi Ṣàngó wé ìbọn, làbẹ làbẹ ò dà pọ̀ mọ́ kóríko odò yòó kù Rẹ́rẹ́
Rún yege púpọ̀. Ó wa nínú àwọn tí a lè fi sí ipò kìínní. Bí a bá sọ pé
èdè dùn, oríṣiríṣi nǹkan ni a le ní lọ́kàn: Ó le jẹ́ pé èdè náà yọ̀ létí; tí
ó kú mùúù, tí ó sì ládùn bí ẹni tó fi làákàyè kéwì. Ósì le jẹ́ pé àwọn
ìjìnlẹ̀ èdè, àkànlò ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwàdà ni. Ó sì le jẹ́ pé òǹkọ̀wé náà mọ
ikú tó pa òwe lílò. Nínú gbogbo eléyìí, ó ní èyí tí ó máa ń jẹ òǹkọ̀wé kan
lógún. Òkédìjí mọ̀ púpọ̀ nípa ìlò òwe. Ṣààṣà ni ojú ewé tí a óò ṣí tí a kò níí
rí àwọn òwe àtàtà. À fẹ́rẹ̀ lè sọ pé bí a bá to àwọn òwe ibẹ̀ nìkan jọ,
ìtàn náà le yé ni.
Oríṣi ọ̀nà màrùn-ún ni Òkédìjí ń
gbà lo òwe: a máa lo òwe lásán – irú èyí tí gbogbo wa mọ̀; a máa dárà sí òwe; a
máa kan àkànpọ̀ òwe; a máa tú òwe palẹ̀, ó sì ní àwọn òwe Láwúwo.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, Òkédìjí á lo
òwe tí gbogbo wa mọ̀ tí ó sì bá ọ̀rọ̀ tí á ń sọ lọ́wọ́ mú. Ọ̀nà mìíràn tí
Òkédìjí fi ń lo òwe ni kí ó máa tú u palẹ̀, kí ó kì í délé, kí ó pa á délẹ̀
kodoro níbi tí a kì í sábà pa á dé rí: Nígbà tí Onímògún ń bínú sí àwọn òṣìṣẹ́,
ó ní:
Kín tilẹ̀ wáá ni à ǹfàànì orógbóo-jàre?
A bó o kòléèpo, a pa á kolawẹ́, a gé e jẹ ó korò. Èyí igi rẹ̀ tún rèé, kò ṣeé
dáná yá, ewé rẹ̀ ò ṣeé pọ́nkọ. (Ojú ewé 15).
Ó
ki òwe ẹyọ kan yìí délé kí a le mọ bi ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ̀ ti kéré
tólójúrẹ̀. Nígbà tí Láwúwó sì ń kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ nípa wàhálà tó wà
níwájú wọn, ó ki ẹyọ òwe kan dé gógó:
Tàkúté ló mú àà! Ọ̀ sínú oko yìí,
ààlọ̀ ń sunkún, olóko ńyọ̀, ó ń rẹ́rìín, olóko ò mọ̀ pé bí ààlọ̀ ti ńlọ
araa rẹ̀ l’ó nlọ olóko! Nitorí pé ààlọ̀ kò gbọdò kú sínú oko ẹni. Àgbẹ̀ tí
ààlọ̀ bá kú sínú oko rẹ̀ kò le rù ú là; kò sí bó ṣe le gbé ọdún náà já k’ótóó
jáde láiyé. Àìrọ̀lẹ̀ ni yíò jẹ́ Ọlọ́run nípè (ojú ewé 26).
Kíkí
òwe délẹ̀ báyìí dà bí àtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ láti jẹ́ kí àwọn tí à ń bá sọ̀rọ̀ mọ
bí ohun tí à ń sọ ṣe ṣe pàtàkì tó. Níbi yìí, Láwúwo ń sọ pé àwọn òṣìṣẹ
náà gbọ́dọ̀ múra gírí kí wọn kó ara wọn ní ìjánu bí wọ́n ti ń fi apá kan bá
àwọn ọ̀gá jà.
Àwọn tí a pè ni òwe Láwúwo ni
òǹkọ̀wé fún ra rẹ̀ ti tòjọ sí ojú ewé 99. Àwọn ní à ṣìpa òwe tí Láwúwo ń
pa nígbà tí orí rẹ̀ dàrú. Òkédìjí kàn fihàn níhìn-ín pé bí orí bá ti dàrú, èdè
kò le já gaara mọ́.
Yàtọ̀ sí gbogbo àrà tí òǹkọ̀wé fi
òwe dá yìí, a tún ṣàkíyèsí pé Òkédìjí ní etí inú tí ó fi ń ṣàkíyèsí àwọn
àléébù tí àwọn àjòjì ní nígbà tí wọ́n bá fẹ́ẹ́ sọ Yorùbá. Nígbà tí Matíù
Sapẹlẹ bá sọ̀rọ̀, a rí i pé kò le pe (1), (n) ni ó ń lò dípò
‘Emi náà ni onórí
naginagi tabiii gbégìnódò. ‘(Ojú ewé 23).
Yàtọ̀ sí (1) tí kò le pè, ó tún ń
ṣi àwọ ohun orí ọ̀rọ̀. Òkédìjí mọ ènìyàn sísín jẹ púpọ̀.
Irú èyí náà ló tún ṣẹlẹ̀ nígbà tí
Aláwodé ń sín Haúsá jẹ nígbà tí wọ́n
lọ lu Mọrẹ́nikẹ́ ní jìbìtì. Nínú ọ̀rọ̀ Aláwodé, Òkédìjí fi hàn pé Haúsá máa
ń fi (p) pe (kw); óń fi (ọ) pe (o) àti (ni) pe (ne). Bí
àpẹẹrẹ
Amá èyí,
baba yárubá báńsá nè Burúku kwatakwata
nè, abbl. (ojú ewé 60)
A kò gbọdọ̀ parí ọ̀rọ̀ èdè inú Rẹ́rẹ́ Run láìsọ nípa orin ‘Èrò tí ń r’Òjéje’. A mọ̀ pé
Òkédìjí yá orin yìí lò láti inu àlọ́ àpagbè ni; ṣùgbọ́n ó ní ìdí tí ó fi yá a.
Àlọ́ yìí sọ nípa ọmọ tí ìyá fi ẹyin sílẹ̀ fún, ṣùgbọ́n tí orogún ìyá rẹ̀
kò jẹ́ kí ó rí i jẹ, tí ó sì fún un ní wùrà tó kan bóbó dípò. Orin yìí wáá dà
bí òwe nípa irú ipò tí àwọn òṣìṣẹ́ wa láyé. A le sọ pé Ọlọ́run tí ó dúró
fún ìyá ọmọ - ti fi ohun dáradára sílẹ̀ fún wa láyé. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀gá
ìṣẹ́ - àwọn orogún – kò jẹ kí ó tẹ àwọn mẹ̀kúnnù lọ́wọ́.
Orin yìí ni ó jẹ́ àmùrè fún àwọn
òṣì ṣẹ́, tí óń rán wọn léti ìyà tí wọn ń jẹ́ àti ìjàkadì wọn láti ja
àjàbọ́. Irú orin yìí tí Òkédìjí yá lò wúlò púpọ̀ nítorí pé a ti mọ ìtumọ̀ àlọ́ yìí tẹ́lẹ̀,
èyí sì ràn wá lọ́wọ́ láti tètè rí irú ìyà tí ó ń jẹ àwọn òṣìṣẹ́. Yóò wúlò
púpọ̀ bí ẹnì kan bá le wo gbogbo ibi tí orín náà ti wáyé nínú eré yìí, kí ó sì
ro ìtumọ̀ tí a le fún un ní ibi kọ̀ọ̀kan.
[1]
This work was published as Iṣọla, Akinwumi (2007), ‘Wọ́n Rò Pé Wèrè Ni àti Rẹ́rẹ́
Rún: Eré-Onítàn Yorùbá’, in Ìṣẹ̀ǹbáyé
àti Ìlò Èdè Yorùbá: Book Series No 30, edited by O.O. Oyelaran and L.O. Adewole,
pp. 167-186.Cape Town: The Centre for Advanced Studies 0f African Society.
[2]
Gbogbo ìtọ́ka
ojú-ìwé jẹ́ bí ó ti
wà nínú Adebayo Faleti (1969), Nwọn
Rò Pé Wèrè Ni (Àtúnṣe
Kejì). Ibadan: Oxford University Press; Oladejo Okediji (1973), Rẹ́rẹ́
Rún. Ibadan: Onibonoje Press and Book Industies Nig. Ltd.
No comments:
Post a Comment