Sunday, 28 August 2016

ÀBÙDÁ ÈDÉ ÀTI Ẹ̀KA ÈDÈ YORÙBÁ


 
Túndé Olówóòkéré

1.      Ìfáárà[1]

          Yàtọ̀ sí Hockett (1963:16) tí ó gbíyànjú láti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí a lè pè ní àbùdá èdè, gbogbo àwọn onímọ̀ yòókù títí kan Bloomfield (1933:3), Crystal (1974:239), Barber (1964:9) in wọ́n ṣàpèjúwe tàbí ni wọ́n sọ ohun tí a ń fi èdè ṣe. Fún àpẹẹrẹ, lójú Bloomfield (1933:3) àti Barber (1964:9), èdè ni ó ya ènìyàn kúrò lára ẹranko.

 

          Ó fẹ́rẹ́ jẹ́ pé èrò àwọn onímọ̀ lápapọ̀ nípa pé ènìyàn níkan, lára gbogbo ẹ̀dá , ni ó ní èdè. Ju gbogbo nǹkan yòókù lọ, èdè ni ó ya ènìyàn sọ́tọ̀ tí ó sì jẹ́ kí àṣeyọrí àwọn ẹ̀dá alààyè ṣeé ṣe láwùjọ.

 

          Lóòótọ́ ni pé àwọn ẹranko ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí wọn lè gbà fi èrò inú wọn han ara wọn yálà nípa kíkígbe, jíju ìrù àti bẹ́ẹ̀ bẹ̣́ẹ̀ lọ. Àwọn ẹyẹ mìíràn a tilẹ̀ máa kìlọ̀ fúnra wọn bí ewu bá ń bọ̀. Àwọn ẹranko mìíràn ní bí wọn ti ṣe ń pera wọn bi wọn bá fẹ́ ṣeré-ifẹ́. Akítì ń kígbe lóríṣìíríṣìí ọ̀nà láti jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ mọ̀ pé ewu, ẹ̀rù àti ìdùnnu ń bọ̀.

          Alákàn ní tó ogóji ọ̀kàn-ò-jọ̀kan ífi-ẹ̀rò-inú wọn han ara wọn nípa ọ̀nà tí wọn bá gba dúrọ́ tàbí ọ̀nà tí wọn gba yí ara wọn padà. Ohun yòówù tí ìdúró tàbí ìyírapadà lè dúró fún kì í yí padà. Ọ̀nà ibárasọ̀rọ̀ oyin tilẹ̀ tún díjú ju ti alákàn. Bí oyin bá ṣẹṣẹ rí ibi tí oúnjẹ wà, ìjó ni yóò fi sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ìjó tí oyin ń jó lẹ̀ jẹ́ àjóyípọ, ajóṣekọdọrọ, ìdí jíjù tàbí ijó ọ̀nà-àrà lọ́nà tí àwọn ẹlẹgbé rẹ̀ yọ́ọ̀ fi mọ̀ bí ibi tí oúnjẹ náà wà ti jìnà tó. Gbogbo ọ̀nà íbàra-ẹni-sọ̀rọ̀ wọ̀nyí yàtọ̀ sí èdè ènìyàn. Ìgbe ẹranko kò dá ṣáká nípá pé kò ní ìhun tó ṣeé fọ sí wẹ́wẹ́. Ìṣòro wà láti gé ariwo tí wọn ń pa sí wẹ́wẹ́ bí a ti ṣe ń gé fáwẹ̀lì àti kọ́ńsónáǹtì. Ìṣòro wà láti pààlà sí ààrin ọ̀rọ̀ kan àti òmìíràn irú èyí tí a lè ṣe fún èdè ènìyàn. Ìdí nìyí tí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ àti ìtumọ̀ oríṣìí ariwo tí àwọn ẹrankọ lè pa mo níba.

 

Kí nì èdè?

          Ariwo tí o ń ti ẹnu ènìyàn jáde láti bá awùjọ ajọlèdè sọ̀rọ̀ ni èdè. Ariwo tí a ń tọ́ka sí yìí ní ètò. Ènìyàn níkan ni ariwo wọn létò tí wọn sì ń kọ́ àtọmọdọ́mọ wọn.

          Èdè sísọ jẹ mọ́ író ajẹmóhùn. A ti sọ pé ẹnu ni a fi ń sọ èdè. Láti inú ẹ̀dọ̀fóró ni èémí tí a gé kékèké tí í di ìró tí èdè kọ̀ọ̀kan ń lò ti í wá. Ẹ̀yà-ara tí a fi ń gé èémí sí kékèké láti pe ìró ni a mọ̀ sí afipè. Kálukú ẹ̀yà-ara wọ̀nyí ni wọ́n ní ojúṣe tiwọn. Aáyan láti ṣàpèjúwe oríṣìíṣìí ìró tí a ń gbọ́, pàápàá, àwọn ìró tí a pè nípa sísé afẹ́fẹ́ àti èyí tí a pì láìṣé e ni ó fa ìyàtọ̀ ìró fáwẹ̀lì àti ìró kọ́ńsónáǹtì.

         

          Kí ọ̀rọ̀ wa lórí àbùdá èdè tó le tà, a tún tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ àwọn ẹranko mọ níba. Lọ́na mìíràn, ẹ̀wẹ̀ àṣà èdè kíkọ sílẹ̀ kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ohun tí a ń tọ́ka sí bi àbùdá èdè nítorí ẹgbàágbèje èdè ni wọ́n wà láyé tí wọn kò ní àkọsílẹ̀.

         

          Èdè tí a ń sọ jẹ́ àṣà àwùjọ tí ó wà láti ayébáyé. Àṣà kíkọ èdè sílẹ̀ kò tíì pẹ́ kò sì tíì tàn dé gbogbo àwùjọ ajọlèdè. Ohun mìíràn tí a tun fẹ́ sọ nípa èdè ni pé ọ̀rọ̀ tí a bá sọ jáde lẹ́nu í pòórá ni ṣùgbọ́n èdè tí a bá kọ sílẹ̀ wà títí láé. Fún ìdí èyí, bí a bá ń sọ̀rọ̀ èdè, sísọ ni ó ti bẹ̀rẹ̀, àtọwọ́dá ni èdè kíkọ, o sí ní oríṣìí ọ̀nà tí kálukú gbà ń kọ èdè rẹ̀ sílẹ̀ torí ìwọ̀fún ni ítẹ́lọ́rùn. Bákan náà ẹ̀wẹ̀ ni pípòórá tí èdè tí a sọ jáde lẹ́nu í pòórá jẹ́ okùnfà tí èdè fi i ní oríṣi ẹ̀ka. Fún ìdí èyí, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a lè gbà wò èdè sísọ àti èdè kíko sílè. Ọ̀nà kíkọ èdè sílẹ̀ yàtọ́ sí ara wọn, fún ìdí èyí yóò jẹ́, ìṣòro púpọ̀ láti sọ pé àbùdá èdè sísọ̀ àti àbùdá èdè kíkọ sílẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan. Nínú èdè mìíràn, ẹnu ìwọ̀nba ìró tí wọn bá pè jáde lẹ́nu ni wọn ń kọ sílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ pè àwọn mìíràn máa ń dín ìró tí wọn ń sọ kù tàbí kí wọn fi kún ìró tí wọn pè jáde lẹ́un nínú èdè tí wọn kọ sílẹ̀.

 

2.      Àbùdá Èdè

2.1.   Àbùdá Àìlópin-Ọ̀rọ̀

          Àbùdá àìlópin ọ̀rọ̀ ni pé kí ọ̀rọ̀ èdè má ní òpin tàbí ààlà. Èyí ni pé kí a má lè ka iye ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú èdè kan. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, ìlànà gbọ́dọ̀ wà fún ṣíṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ mìíràn wọnú èdè. A lè ṣe èyí nípa lílo àfòmó mọ́ ọ̀rọ̀ ní ìbèrè, ààrin tàbí ní ìparí. Bákan náà ni a lè ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ mìíràn gédégédé yala lára èdè tí ó yí èdè wa ká tàbí àṣà tuntun tí ó wọ èdè tí a ń sọ. Èdè tí kò bá fi  àyè gba ọ̀rọ̀ tuntun yóò lópin; dandan ni kí a sì lè ka iye ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú èdè bẹ́ẹ̀.

 

2.2    Àbùdá Iyínípò-padà

          Èdè jẹ́ irin-iṣẹ́ tó fún àwujọ ajọlèdè ní àǹfààní láti fi èrò inú wọn hàn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti kọja, ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti èyí tí a lérò pé yóò wáyé lọ́jọ́ íwájú. Èdè tí kò bá ní ọ̀rọ̀ fún ìyínípòpadá kò níí lè sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan-ò-jọkan ìṣẹ̀lẹ̀. Àbùdá ìyínípòpadà ni ó jẹ́ kí a lè fi èdè sọ ìtàn-àròsọ, ìdábàá àti láti fi kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀.

 

2.3    Àbùdá Ìbèjì

          Méjì-méjì ni ayé. Èdè jé kí a lè yí ohun tí a sọ padà. Bóyá èyí ló jẹ kí Yorùbá fi sọ pé ayé tó ní Adégún náà ni ó tún sọ pé Adéògún. Èyí fi hàn pé ojú méjì ni èdè ní, bí a ti ṣe lè sọ pé nǹkan ń bẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni a tún lè sọ pé nǹkan kò sí. A lè sọ pé:

 

                   funfun        dúdú

                   tobi            kéré

                   sùn            

                   orí              ìdí

                   gbọ́n           gọ̀

                   ọkùnrin      obìnrin

                                lọ

                   dìde            jókòó

                   ṣiṣẹ́             siré

                   dùn             korò

 

Irú àkíyèsí yìí ló fà á tí Hockett (1963:16) fi sọ pé:

 

A language deprived of duality would be extremely cumbersome since each plereme would have to differ holistically from each other.

 

2.4.   Àdáṣeláítẹ̀lẹ́-ìlànà

           Orúkọ tí a fún ohun kan kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ohun náà; ìwọ̀fún ni ìtẹ́lọ́rùn. Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé àwọn ajọlèdè kan ń fún àwọn ohun tó yí wọn ká lórúkọ bí ó ti wù wọ́n. Kò sí ìdí tí a fi ń pe ohun kan ní orúkọ tí a fún un nítorí kò sí àsopọ̀ kankan láàrin orúkọ kan àti ohun tí a fún ní orúkọ náà. Ẹ jẹ́ kí a wo ẹranko tí Yorùbá ń pè ní “ajá” ẹranko kan náà ni Gẹ̀ẹ́sì ń pè ní “dog”. Kò sí ohun tí ó so ẹranko yìí àti orúkọ tí àwùjọ ajọlèdè kọ̀ọ̀kan fún un pọ̀.

 

2.5.   Àbùdá Ìdáṣáká

          Àwùjọ ajọlèdè ní ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí ẹni tí ó bá gbọ́ èdè wọn kò fi níí ní ìyọnu láti mọ ohun tí wọn ń sọ. Èdè gbọ́dọ̀ yanjú láìsí pé ó jẹ́ pọ́nna. Ọ̀nà fífi ìlù bá ni sọ̀rọ̀ lè yọrí sí pọ́nna. Ẹ jẹ́ kí a wo oríṣi itumọ̀ tí àwọn tó ń gbọ́ “èdè ìlù” lórí Rédíò Kwara fun ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ yìí:

 

                             Dán dàn dán dan dán dán

                             dán dan dàn dàn dàn dàn

 

1.      Fádèyí Olóró, àfi ṣùkẹ̀ ṣùkẹ̀ ‘

2.      Wọ́n rìn bí ọlọ́lá, àfi tẹ̀kì tẹ̀kì

3.      Ó dùn mọ́ mi nínú, àfi yùngbà yùngbà

4.      Kí là ń ronú fún, àwa àgbẹ̀ àgbẹ̀

5.      Ó kàwé ni lásán, kò mọ̀ dòò dòò

6.      Ó sì gbá mi létí, àfi gbòsà gbòsà

7.      Ó fò jáde nílé, àfi fòrò fòrò

8.      Mágàjí Olówó, ìwọ làgbà làgbà

9.      Wọ́n sì dé mi lade, àfi pìrà pìrà

10.    Ó sì mọ́ mi lójú àfi mọ̀ìn mọ̀ìn

 

          Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Àjàyí (1989) sẹ, ohun tí a fi ìlù sọ lè ní ju ìtumọ kan lọ àyàfi bí a bá mọ ohun tó ń ṣelẹ̀ nígbà tí onílù lù ìlù. Ẹni tí ó fi ìlù sọ̀rọ̀ níkan ni ó lè sọ pàtó ohun tí òun ní lọ́kàn. Kò sí ẹni tí a lè sọ pẹ́ kò tọ̀nà nínú gbogbo àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọn fún “èdè ìlù” ní ìtumọ̀. Èdè ènìyàn kò lè ní irú pọ́nna yìí.

 

          Èdè jẹ́ àjọní àwùjọ ajọlèdè lọ́nà tó fi jẹ́ pé gbogbo èròjà tí èdè bẹ́ẹ̀ bá ní ni gbogbo olùsọ èdè bẹ́ẹ̀ yóò ní ní ìkáwó wọn lọ́nà tí ó fi jẹ́ pé ohun tí wọn bá ń sọ yóò fi yé wọn. A lè pe àròjà tí a ń wí yìí ní àjẹbí tí ó wà nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ṣíṣe pàsípàarọ èròjà yìí nípa sísòrò ń jẹ́ kí a lè fi èrò inú wa hàn.

 

2.6    Gbígbọ́ ohun tí a ń sọ

          Èdè ní àbùdẹ́ pé bí ènìyàn bá ti ń sọ̀rọ̀ kí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ náà fúnrarẹ̀ máa gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Ìgbà tó bá ń gbọ́ ohun tí ó ń sọ jáde ni ó tó le mọ̀ pé iṣẹ́ tí òun fẹ́ rán sí elòmìíràn ni òun ń rán kí òun tó lè retí èsí tí ó yẹ.

         

          Èdè ní mímọ̀n-ọ́nlò. Ó ní irú ọ̀rọ̀ tí a ń sọ ní oríṣìíríṣìí ìgbà. Èdè lẹ̀ dé ibi pé ní àkókò ayọ̀, ó ní bí a ti ṣe ń sọ̀rọ̀, ní akókò ìbànújẹ́, ó ní irú ọ̀rọ̀ tí a ń sọ. Bí a bá fẹ́ sọ ohun tí a mọ̀ fún ènìyàn, ọ̀nà tí a ó gbà sọ ọ́ yàtọ́ sí bí a ó ti ṣe bẹ̀bẹ̀ tàbí bí a bá fẹ́ pàrọwà fún ènìyàn. Èdè jẹ ohun-èlò tí ó ní ẹ̀dà tí a ń lò ní àwùjọ awo àti tọ̀gbẹ̀rì.

 

2.7.   Àbùdá Pípòórá

          Etí ni a fi ń gbọ́ ohun tí a bá fi ẹnu sọ. Ọ̀rọ̀ tí a bá sọ kì í ṣe ìdíwọ́ fún ọ̀rọ̀ mìíràn. Inú ọ̀pọ̀lọ ẹni tí o ń sọ̀rọ̀ àti  ẹni tí ń gbọ́ ọ ni èdè n kóra jọ sí.

 

3.      Ẹ̀ka Èdè

          Àwùjọ ajọlèdè ni ó ní ọ̀nà tí wọn lè gbà fi bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí wọn yóò sì gbọ́ ara wọn ní àgbọ́yé. Èdè àwùjọ ajolèdè kàn lè ni àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ láti ibi kan sí òmíràn. Ìgbà tí irú ìyàtọ̀ díèdíẹ̀ wọ̀nyí bá wáyé láàrìn àwùjọ ajọlèdè ni a máa ń sọ pé ẹ̀ka-èdè kan náà ni àwọn ènìyàn náà ń sọ. Òye pàsípààrọ̀ a máa wà láàrin ẹ̀ka-èdè. A lè ki ẹ̀ka-èdè bí apá kan tàbí ara èdè àwùjọ ajọlèdè tí wọn ní orírun kan náà ṣùgbọ́n tí ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà láàrin ẹ̀ka-èdè kan sí èkeji. Ìyàtọ̀ yìí lè wáyé lọ́nà síntáàsi, ọ̀rọ̀-onítumọ̀-àdámọ́ tàbí ní ìlànà fọmọlọjí. Ẹ jẹ́ kí a fi àpẹẹrẹ èdè Yorùbá ṣàlàyé ohun tí a ń sọ. Olorí ẹ̀ka-èdè Yorùbá yóò sọ báyìí:

 

Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá (ỌẸ) Kò ní dára fún ẹni tó sọ́ bẹ́ẹ̀

Ọ̀yọ́                                         Kàa dáa fẹni to sọ́ baun

Oǹdó:                                      Eè ní sàn ko onẹ o fọ̀ bẹ́nẹ̀n

Ìjẹ̀bú:                                      Eè ní dáa rẹni é sọ wà

Ẹ̀gbádò:                                  Kò ní dáa fẹ́ni yọ sọ bẹ́ẹ̀

Ìgbómìnà:                               Kè ní dáa kẹni yọ sọ báun

Èkìtì:                                                Ẹ́a sunọ̀n kọni ko wí bẹ́ẹ̀

Òkè Àgbè (Àkókó):              Kà ga san yẹn oí nì ẹ ro

 

          Àtàjòjì ni ọ, àtonílé ni wọ́n ka ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wọ̀nyí sí èdè tí ó lè dé dúró. Àwọn àjòjì ní tiwọn rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yàtọ̀ tí ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan ń mú lò.

 

ỌẸ[2]                      Ọ̀yọ́                    Oǹdó          Ìgbóm[3]       Àkókó       Èkìtí

dára                      dáa             sàn              dáa             sàn           sunọ̀n

Kò ní                   Kàa             Éè ní          Kè ní          Ka ga          Ẹ́a

fún ẹni                 fẹ́ni             kò onẹ̀        kẹni            Yẹn oí         kọni

 

Àwọn olùsọ ẹ̀ka-èdè kọ̀ọ́kan fẹ́ rí tiwọn bí èdè tí ó lè dá dúró fúnra rè yàtọ̀ sí pé kí a pè é ní àfikún tàbí àsomọ́ èdè mìíràn. Àwọn olùsọ ẹ̀ka-èdè kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fẹ́ kí wọn sọ pé èdè wọn ni aṣorírun tàbí pé ọ̀dọ̀ ẹlẹ́dàá ni èdè wón ti wá. Àwọn olùsọ ẹ̀ka-èdè kọ̀ọ̀kan wọ̀nyí ni wọn ka èdè wọn sí ṣùgbọ́n olorí ẹ̀ka-èdè níkan ní ó ní àkọọ́lẹ̀ tó péye nínú gbogbo ẹ̀ka-èdè Yorùbá.

 

          Bí ẹ̀ka-èdè kọ̀ọ̀kan wọ̀nyí ti ń ṣaáyan láti rí ara wọn bí èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo wọn ń tọ́ka sí Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orírun wọn. Ìtàn àtẹnudẹ́nu sọ pé Òtù Ifẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá kọ́kọ́ dá àwọn ènìyàn sí tí àwọn ènìyàn sì ń tàn ká títí dé Edo Bini ní ìpínlẹ̀ Bendel, Sabẹ àti Kétu ní Republic of Benin. Ìtàn sọ pé ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọ-ọmọ ni Ọlọ́fin bí. Lára àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ọba Ado Bini, Ọ̀ràn-ányàn Ọba Ọ̀yọ́, Òràngúnàga Ilé-Ìlá, Oníkétu, Onípópó àti Ọba Sábẹ̀ẹ́. Lára ọmọ-ọmọ Ọlọ́fin ni Èwi Ọba Adó, Alárá, Ájerò àti àwọn Ọba káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. Ìtàn àtẹnudẹ́nu tọ́ka sí Ọlọ́fin bí ẹni tí ó dàgbà tí ó sì gbó. A gbọ́ pé ìgbà tí kò ríran mọ́ ni Ọwá Àjàká, ọkan lára àwọn ọmọ rẹ̀, ní òun yóò wá èròjà tí ó lè ṣe ìwòsàn fún bàbá òun lọ sí òkun. Ìgbà tí ó lọ tí wọn retí rẹ̀ títí tí wọn kò gbúròó rẹ̀ ni Ọlọ́fin pín àwọn dúkìá rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù kí wọn lọ tẹ ìlú tiwọn dó kí wọn sì máa jọba lórí wọn. Ìtàn mìíràn ní ìgbà tí Ifẹ̀ kún àkúnya fún ọ̀pọ̀ èrò ní àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́nká tí kálukú sì ń dá Ìjọba rẹ̀ ṣe. Ọ̀kan-ò-kọ̀kan ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n wá orisun wọn dé Ifẹ̀. Ọ̀ràn-ányàn lọ tẹ Ọ̀yọ́ dó tí àwọn Ẹ̀gbá gbà pé Ọ̀yọ́ ni àwọn ti wá. Àwọn Ìjẹ̀bú ti Òwu wá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọba olókìkí ní ilẹ̀ Yorùbá ní ó jẹ́ pé idà àṣẹ láti jẹ ọba tuntun gbọ́dọ̀ ti Ifẹ̀ wá. Bákan náà ni wọ́n ka Ifẹ̀ sí orí ti enìkan kò gbọdọ fi tẹlẹ̀.

         

          Ní àkókò ogun tí Mọdakẹ́kẹ́ lé àwọn ará Ifẹ̀ sígbó, Ògúnmọ́lá Balógun Ìbàdàn rán àwọn aṣojú láti ṣètò àlàáfíà láàrin Ifẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́. Johnson (1921:232) ní Ògúnmọ́lá sọ báyìí:

                  

It would never do to let the cradle of the race – Yorùbá race remain perpetually in desolation and the ancestral gods not worshipped.

 

Lójú Ògúnmọ́lá, Balógun Ìbàdàn, ó rí i pé kò níí bójú mu kí orírun ìran Yorùbá di ahoro láìsin àwọn òrìṣà babańlá wa. Bí a bá fi ojú ìtan wò ó, a lè sọ pé orírun kan náà ni àwọn Yorùbá ní.

 

          Ìbéèrè tí a lè bí ara wa ni pé kí ló wá fà á ti ẹ̀ka-èdè Yorùbá fi pọ̀ rẹpẹtẹ bí a ti ṣe rí i yìí? Ìdáhùn ni pé àyípadà a máa bá èdè ní oríṣìí ọ̀nà láti ibi kàn dé òmíràn. Èdè tí kì í bá ti í ṣe ènìyàn péréte ló ń sọ ọ́, dandan ni kí ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà láàrin olùsọ̀ rẹ̀, pàápàá, nígbà tí wọn kì í bá ti í gbé ojú kan náà. Ìgbà tí  kò bá ti sí pé àwùjọ ajọlèdè kan ní àṣepọ̀ nípa pé kí a ti ibi kan lọ sí èkejì, àyípadà lè dé bá èdè lóróṣi ọ̀nà. Fún ìdí èyí, oríṣí ọ̀nà ni èdè lè gbà yí padà yálà lọnà fonọ́lọji tàbí síntáàsì. Ìyàtọ̀ tilẹ̀ lè dé bá èdè dẹ́ ibi pé kí àwọn ajolèdè tó ní orírun kan náà máà gbọ ẹ̀kà-èdè ara wọn. Ẹ jẹ kí a fi ẹ̀ka-èdè Àkókó ti Òkè Agbè ṣe àpẹẹrẹ. Ìyàtọ̀ wà láàrin ẹ̀ka-èdè méjèèjì yìí dé ibi pé a fẹ́rẹ̀ lè sọ pé ẹ̀ka-èdè Òkè-Agbè kì í ṣe Yorùbá  nítorí ó ṣòro fún àwọn ẹ̀ka Yorùbá mìíràn láti gbọ́ èdè Òkè-Àgbè. Bí ọ̀rọ̀ onítumọ̀ àdámọ̀ ṣe yàtọ̀ ni ìlànà fonọ́lọ́jì wọn yàtọ̀ sí ti olórí ẹ̀kà-èdè Yorùbá.

 

          Bí a bá rántí pé láti ìgbà tí àwọn Yorùbá ti fọ́nká tí kálukú sì ń dá ètò ìjọba rẹ ṣe, kò sí àṣepọ̀ kankan bí alárà láàrin àwọn ọmọ Ọlọ́fin. Iṣẹ́ àgbẹ̀ tí kálukú ń ṣe kò fún wọn láǹfàní láti máa ti ibì kan lọ sí ibòmíràn, pàápàá jù lọ, ni ọ̀nà jínjìn réré tí kò sì sí ohun-èlò ìrìn-àjó. Kò sí àṣepọ̀ ti ó wà láàrin àwọn Yorùbá tí ó wà ní Ṣakí tàbí Iṣẹ́yin àti àwọn Yorùbá tí wọn wà ní Ìlàjẹ-ẹsẹ̀-odò. Igbó ńlá pọ̀ ní Ìkàrẹ́, Àkókó, Èkìtì, Ìléṣa àti Ifẹ̀ nígbà tí àwọn ìlú Yorùbá Ọ̀yọ́, Ṣakí, Iṣẹ́yìn wà ní ilẹ̀ pápá. Kò sí àpèjọ kankan tí ó lè fa kí ẹ̀yà Yorùbá wọ̀nyí ní àṣepọ̀ láti rí i pé kò sí ìyàtọ̀ nínú èdè wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè pààlà pé ibi tí ẹ̀ka-èdè kan pin sí nìyí, síbẹ̀, ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ tí ó wà láti ìlú kan sí òmíràn ni ó para pọ̀ di ńlá dé ibi pé àwọn ẹ̀ka-èdè tó bá jìnnà síra wọn tí kò sí àṣepọ̀ láàrin wọn lè máà gbọ́ ẹ̀ka-èdè mìíràn ti wọn sì jọ ní orírun kan náà.

 

          Àwọn Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, ẹní a bá sùn tì ni a ń jarunpá lù. Àwọn alámùúlégbè àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá máa ń ní àṣepọ̀ ju àwọn Yorùbá tí wọn jìnnà réré sí ara wọn. Ọ̀rọ̀ onítumọ̀ àdání inú èdè àwọn alámùúlégbè tí àṣepọ̀ ba wà láàrin wọn a máa wọnú ara. Kódà, ìṣorogbígbó èdè alámùúlégbè kì í pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nítorí àṣepọ̀ òwò máa ń wà láàrin wọn. Àwọn Yorùbá Ìmẹ̀kọ máa ń bá àwọn Ègùn ti Republic of Benin ṣe òwò pọ̀. Bakan náa ni àwọn Àkókó máa ń ní àṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn Ìṣẹ̀kírì àti àwọn Ẹ̀do Bini tí wọn jẹ́ alámùúlégbè wọn. Ọ̀rọ̀ wọn a máa wọnú ara bẹ́ẹ̀ ni kì í sí ìṣòro fún wọn láti gbọ́ èdè ara wọn. Ohun tí ó wá ṣe pàtàkì nípa èdè àti ẹ̀ka-èdè rẹ̀ ni pé gbogbo ìran Yorùbá ni wọ́n gbọ olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá bí wọn bá sọ ọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwùjọ ajọlèdè Yorùbá kọ́ ni wọ́n lè sọ olorí ẹ̀ka-èdè tí wọn kò sì bìkítà láti kọ́ ọ. Olórí ẹ̀ka-èdè ni wọ́n fi ń kọ́mọ ní ilé-ẹ̀kọ́, òun ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ ní àpèjọ tí ó ba pa oríṣìíríṣìí ẹ̀yà Yorùbá papọ. Olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni wọ́n fi ń ka ìròyìn, òun ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ nílé aṣòfin. Olórí ẹ̀ka-èdè ni wọ́n fi ń kọ̀wẹ́, ni wọ́n fi ń kọ gírámà, lítíréṣọ̀, atúmọ̀-èdè, wọ́n sì ń lò ó fún kíkọ́ àjòjì. Bí ipò olorí ẹ̀ka-èdè ti ṣe pàtàkì tó yìí, àwọn ẹ̀ka-èdè yòókù ní ipa tiwọn tí wọn ń kó. Ẹ̀ka-èdè kọ̀ọ̀kan ni wọn ń lò ní àdúgbò kọ̀ọ̀kan láti bá ara wọn sọ̀rọ̀, láti kí ara wọn, láti bọ òrìṣà wọn, láti sọ̀tàn àti láti kọrin

 

4       Ìgúnlè

          A ti gbìyànjú láti fi hàn pé ọ̀nà ibánisọ̀rọ̀ pọ̀ sùgbọ́n ènìyàn níkan ni ó ní èdè. Èdè dá sáká lọ́nà tí ohun tí a fẹ́ kí ẹlòmíràn mọ̀ kò fí ní jẹ́ pọ́nna. Ọ̀rọ̀ inú-èdè kò láàlà bákan náà ni èdè ni àbùdá ìgbààyè nípa pé a lè fi ọ̀rọ̀ kan rọ́pọ̀ òmíràn. Èdè ṣeé yí pada lọ́nà tí a kò fi níí fi ọ̀rọ̀ ẹnu ṣe àkóbá fún ara ẹni. Bí a bá ti sọ̀rọ̀ ni ohun tí a sọ yóò ti bá afẹfẹ́ lọ ṣùgbọ́n inú ọpọlọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ àti olùgbọ́ ni pàṣípààrọ̀ ohun tí a sọ wà. Ẹnu ni a fi ń sọ èdè etí ni a fi í gbọ́ ọ.

 

Ìwé Ìtọ́kasí

 

Adetugbọ, A. (1982),      “Towards a Yorùbá Dialectology”, in Yorùbá Language and Literature, edited A., Afọlayan, pp. 207-224. Ìbàdàn: U.I.P. and U.P.L.

Ajayi, Badẹ  (1989),        “Yorùbá Drum Language: A Problem of Interpretation”, Paper Read at the Seminar Series Organized by the Institute of Cultural Studies, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ilẹ́-Ifẹ̀, 16th March, 1989.

Akínkugbe, O.A. (1978), “A Comparative Phonology of Yorùbá Dialects, Ìsekiri and Ìgala.”, Unpublished Ph. D. Thesis, University of Ibadan.

Barber, C.L.    (1964), The Story of Language. 5th Edition. London: Pan Books.

Bloomfield, L. (1933),          Language. London: Allen and Unwin.

Crystal, D.      (1974), Linguistics. Aylesbury: Hezell Walson and Viney.

Fromkin, V. and Rodman, R. (1978), An Introduction to Language. U.S.A.: Holt, Rinehart and Winston.

Hockett, C.F.   (1963),          The Problem of Universals in Language’, in Universals in Language, edited by Joseph Greenberg. Cambridge, Mass.: The M.I.T. Press.

Oyelaran, O. (1978),   “Tense/Aspect in Ọ̀wọ́rọ̀, A Yorùbá Dialect”, Paper Presented at the 13th W.A. L.C., Fourah Bay College, University of Sierra-Leone, Freetown 3rd–7th April, 1978.

Johnson, S. (1921),     The History of the Yorùbás. London: Lowe & Brydone Printers.



[1] This paper was published as Olowookere, Tunde (1989), ‘Àbùdá Èdè àti Ẹ̀ka-èdè Yorùbá’, Seminar Series 2, edited by T.M. Ilesanmi, L.O. Adewole and B.A. Oyetade, pp.176-192. Ile-Ife, Nigeria: Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University.
[2] Olórí ẹ̀ka-èdè ni a kọ báyìí.
[3] Ìgbómìnà ni a kọ báyìí.

No comments:

Post a Comment