Friday, 19 August 2016

Àtúpalẹ̀ Ìhun Àwọn Àṣìpa Òwe Láwúwo nínú Rẹ́ré Run


 

 Akíntúndé Akínyẹmí[1], [2]

1.      Ìfáárà

          Ní àwùjọ Yorùbá, iṣẹ́ lámèyítọ́ nípa òwe kò ṣe bẹ́ẹ̀ fẹṣẹ̀ rinlẹ̀ tó àkójọpọ̀ òwe[3]. Ṣíbẹ̀ a rí iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan bíi ti Bámgbóṣe (1968), Ọlátúnjí (1984) àti Àlàbá (1986). Ohun tó sì fa àìfẹsẹrinlẹ̀ iṣẹ́ lámèyítọ́ òwe kò ju wí pé a kò ka òwe kún ohun ken bàbàrà tó yẹ láti tú palẹ̀ níbi tí àwọn ohùn ẹnu ti kúnlẹ̀ láwùjọ.2 Ṣùgbọ́n bí a bá wo ẹwà inú àtinúdá òwe àti ẹ̀kọ́ tàbí iṣẹ tí òwe ń jẹ́ láwùjọ Yorùbá, a kò ní jayò pa láti sọ pé ẹ̀ka lífíréṣọ̀ tó yẹ láti sàtúpalẹ̀ ni.

 

          Ohun tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí gan-an ni àtúpalẹ̀ irúfẹ́ àrà kan lára àràbarà òwe tí Òkédìjí máa ń pa sínú àwọn ìwé àtiníúdá rẹ̀ gbogbo. Enu òwe ti Láwúwo pa nínú ìwé Rẹ́rẹ́ Rún lẹ́yìn tí orí rẹ̀ dàrú nìkan ni mo fẹ́ gbé yẹ̀wò. Èrògbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣe àtúpalẹ̀ ìhun òwe náà lọ́nà tí òye ẹ̀wà iṣẹ́ tí òǹkọ̀wé lò wọ́n fún fi lè yọ. Àpilẹ̀kọ yìí fẹ́ kí á tún èrò wa pa pé àsìpa òwe lásán kọ́ ni àwọn òwe Láwúwo náà.

 

2.      Ìlò Òwe Nínú Ìwé Òkédìjí

          Bí a bá ka gbogbo ìwé àtinúdá Òkédìjí[4], kíákíá la ó ṣàkíyèsí pé ó fẹ́ràn òwe lílò ju ọna èdè mìíràn lọ. Nígbà tí Òkédìjí ń fi ìfẹ́ rẹ̀ sí òwe hàn nínú ‘ìdúpẹ́’sí ìwé Àgbàlagbà Akàn, ó sọ pé:

 

         

 

Láti ìgbà tí ìwé mi àkọ́kọ́ ti jáde ni àwọn ọ̀rẹ́ mi gbogbo ti ńkọ mi ni òwe oríṣiríṣi; láìmọ̀ pé àwọm ńkọ́ mi. Bí nwọ́n ti mba mi sọ̀rọ̀, ni mo ńfetisí òwe tí nwọ́n npa. Ẹni tó bá ri òwe tirẹ̀ kà nínú ìwé yìí, kí ó gbà pé mo fi ìwé ọpẹ́ yi dúpẹ́ lọ́wọ́ òun.

 

Bákan náà tún ni Òkédìjí sọ nínú ‘Ìdí Abájọ’ìwé Rẹ́rẹ́ Rún wí pé “òwe ni mo fi eré-onítàn yìí pa; òwe náà sì jẹ́ ògédé ẹnà fífọ̀”. Irú ẹ̀rí yìí fis hàn pé ìlò òwe ló jẹ Òkédìjí lógún jù lọ nínú ọnà èdè tó ń mú lò láti fi kọ ìwé rẹ̀. Èyí kò sọ pé òǹkọ̀wé náà kì í lọ àwọn ọ̀nà èdè mìíràn rárá.

 

          Bí Òkédìjí bá lo òwe nínú àwọn ìwé àpilẹ̀ko àtinúdá rè, ó máa ń dá oríṣiríṣi àra sí I bó ṣe ń lò wọ́n. Àrà tó ń dá náà náà ni kì í jẹ́ kí ìlò tó ń lo òwe ní àlòjù àti àlòtúnlò ó sú òǹkàwé rẹ̀. Dípò tí ìbá fi sú òǹkàwé, àkàgbádùn ni àwọn ìwé Òkédìjí máa ń jẹ́. Àrà tí Òkédìjí ń fi òwe dá kò pin síbìkan. Bó bá kọ̀wé tuntun kan lónìí, àrà tuntun mìíràn yóò wà nínú bí yóò ṣe pòwe. Òkédìjí a máa yí òwe padà ní ìparí, a máa sọ òwe di gbólóhùn ìbéèrè, a máa sàlàyé òwe, a máa se àtòpọ̀ òwe, a tilẹ̀ máa ṣẹ̀dá òwe. Ìṣọ̀lá (1976, 1978, 1981) ti sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nípa ìlò òwe nínú íwé Òkédíjí.

 

          Ọ̀rọ̀ tí Ìṣọ̀lá (1981:408) sọ nípa àràǹbara àwòrán tí Òkédìjí ń fi òwe yà nínú àwọn ìwé àtinúdá rẹ̀ jẹ́rìí sí èyí:

 

Òkédìjí knows the importance of proverbs in Yorùbá rhetorics and he uses proverbs over so often without boring the reader. He pleasantly surprises the reader by introducing twists to proverbs; he turns normal proverbs; he modifies proverbs; Òkédìjí loves proverbs.

 

Irú àrà báyìí, tí Òkédìjí ń fi òwé dá, kò gbẹ́yìn nínú Ìwé Rẹ́rẹ́ Rún náà. Ọ̀kan nínú irú àrà bẹ́ẹ̀, tí í ṣe ìṣèdá òwe kan, lára òwe méjì, ni a ṣiṣé lé lórí nínú àpilẹ̀kọ̀ yìí.

 

          Láìpẹ́, Aróhunmọ́láṣe (1984) náà sọ̀rọ̀ nípa ìlò òwe nínú ìwẹ́ Rẹ́rẹ́ Rún. Nínú iṣẹ́ náà, Arọ́hunmọ́laṣe ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn òwe tí Láwúwo pa kí orí rè ó tó dàrú àti àwọn tó pa lẹ́yìn tí ọrí rẹ̀ dàrú tán. Ojú tí Aróhunmọ́láṣe (1984):3-9) fi wo àwọn òwe tí Láwúwo pa dáadáa kí orí rè ó tó dàrú ni pé:

 

Wọ́n fi ipa tí Láwúwo kó bi aṣáájú àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń jà fún ẹ̀tó wọn hàn. Nígbà tí Láwúwo ti jẹ́ abẹnugan fún àwọn òṣìṣẹ́ tí èrò rẹ̀ bí aṣáájú kò tíì ṣákìí, gbogbo àwọn òwe rẹ̀ ni ó fi í hàn bí aṣáájú tí ó kúnjú ìwọ̀n.

 

Bákan náà ni Aróhunmọ́làṣe (1984:5-6), nínú iṣẹ́ kan náà, sọ pé:

                  

féé tà fáráyé hàn-kedare … Bí a bá wo àwọn òwe Láwúwò wọ̀nyí, tí a sì túmọ́ wọn léréfèé, a ó gbà pé àsìpá ni àwọn òwe wọ̀nyí, ṣùgbọ́n àyèwò yóò fi yé wa pé wọ́n ní ìtumọ̀ tí ó péye gẹ́gẹ́ bí ìsọ́wọ́ lo èdè Òkédìjí láti lè mú èrò tí ó fẹ́ tà fáráyé jáde.

 

Àkíyèsí mi nípa iṣẹ́ Ìṣọ̀lá àti ti Aróhunmọ́làṣe ni pé ìlò òwe nínú ìwé Òkédìjí lásán ló jẹ wọ́n lógún. Kò dàbí ẹni pé wọ́n wọ́n kobi ara sí ohun tó fún òǹkọ̀wé láyè láti ṣe àtúnṣe sí òwe Láwúwo wọ̀nyí tí òǹkọ̀wé náà sì ṣe lè lo òwe tó túnse láti gbé èrò ọkan rẹ̀ síta. Ní pàtàkì, bí a bá ṣàkíyèsí pé bí òǹkọ̀wé ba pa òwe náà bí a ṣe mọ̀ ọ́n sí gan-an, ọ̀tọ̀ ni èrò tí yóò gbé jáde. Èyí ló jẹ́ kí iṣé yìí ó rò pé bí a bá fojú ìhun wo àwọn àsìpa òwe Láwúwo, a ó mọ ohun tó fún Òkédìjí láyè láti ṣe àtúnṣe sí òwe Yorùbá lọ́nà tó fi gbé èrò ọkàn òǹkọ̀wé síta. Àtúpalẹ̀ àwọn òwe Láwúwo náà lọ́nà tí a fi lè rína rí ọgbọ́n tí òǹkọ̀wẹ́ mú lò àti ẹ́wà tí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ mú bá ìlò òwe nínú ìwé Rẹ́rẹ́ Rún ni iṣẹ́ kàn báyìí.

                         

3.      Ìhun Òwe Láwúwo Nínú Rẹ́rẹ́ Rún

          Àbá tí Milner (1960) dá nípa ìhun òwe ni mo mú lò láti se àtúpàlẹ̀ àti àlàyé ìhun àwọn òwe Láwúwo nínú íwé Rẹ́rẹ́ Rún, Bí a bá fojú èrò Milner wo ìhun òwe, a lè rí awé méjì nínú òwe kan. Ìyẹn ni pé òwe lè ní ‘orí ‘kí ó sì ní ‘ẹsẹ̀’[5]. Awẹ́ òwe kọ̀ọ̀kan ló lè dá ìtumọ̀ ní nínú òwe tí a bá ti lò ó; èyí ló jẹ́ kí Milner ó sọ pé ó yẹ kí mọ irú àmì tí a ó fún òwe kọ̀ọ̀kan - awẹ́ ẹja (-) tàbí akàn (+). Kí á tóó mọ irú àmì tí a ó fún awẹ́ kọ̀ọ̀kan, ó yẹ kí á mọ ìtumọ̀ awẹ́ náà. Bí awẹ́ òwe náà bá fanimọ́ra, tó múnu ẹni dùn, tí kò kọni lóminú, a lè fún un ní àmì akàn (+).  Ṣùgbọ́n bí awẹ́ òwe bá kọni lóminú, tí kò fanimọ́ra, tí kò múnú ẹni dùn, a ó fún irú awẹ́ òwe bẹ́ẹ̀ ní àmì ẹja (-).

 

          Bí a bá wá fi ojú awé méjì tí òwe Yorùbá máa ń ní yìí wo ìhun òwe tí Láwúwo pa lẹ́yìn tí orí rẹ̀ dàrú tán, àwọn àkíyèsí kan wà tí a ṣe. Ní àkọ́kọ́, a ṣàkíyèsí pé òwe méjì méjì ni Òkédìjí yọ́ papọ̀, tó sì ṣẹ̀dá òwe kan ṣoṣo lára wọn. Fún àpẹẹrẹ, nínú òwe wọ̀nyìí;

 

(1)     Òjò ló kó ẹyẹlé pọ̀ mọ́ adìẹ àti

(2)     Ejò kì í jẹ àgbàdo

         

ni Òkédìjí ti sẹ̀dá òwe:

 

(3)     Òjò ló ko ẹyẹlé pọ̀ mọ́ àgbàdo.

 

Bákàn náà ni Òkédìjí ṣẹ̀dá òwe:

 

(4)     Ọmọ tí yóò jẹ́ Àṣàmú, òkèèrè la ti í wò ó

 

látínu òwe méjì yìí:

 

(5)     Ọmọ tí yíò jẹ́ Àṣàmú, kékeré níí ti í máa ṣe ẹnu ṣámúṣámú.

 

(6)     Igi ganganran má gún mi lójú, òkèèrè la ti í sọ ọ́.

 

          Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé a lè sọ pàtó pé àkíyèsí kìíní tí a se nípa ìhun òwe Láwúwo ni pé òwe méjì-méjì ni Òkédìjí ń yọ́ pàpọ̀ di ẹyọ kan lásìkò tí orí Láwúwo dàrú. Àrà ló sì fi dá; iṣẹ́ ló fẹ́ kó jẹ́ fún àwọn òǹkàwé. Òwe kan tó ṣe bí ẹni yàtọ̀ ni èyí tí Láwúwo kọ́kọ́ pa gbàrà tí orí rẹ̀ dàrú tó sọ pé:

 

(7)     Ìwò táà ń wọ àparò, aṣọ rẹ pọ́n koko, ṣùgbọ́n Àlùkò kò pa aṣọ èṣin dà.

 

Nínú àlàyé Òkédìjí, nígbà tó ṣàtòjọ àwọn òwe tó wà lọ́kàn Láwúwo lásìkò tó ń pa òwe náà, Òkédìjí sọ pé òwe mẹ́rin ni Láwúwo papọ̀ di ẹyọ kan. Àwọn òwe náà ni:

 

(8)     Ìwò tí à ń wo àparò, bíi ká fi dálá, orí ẹiyẹ ni kò pẹyẹ.

(9)     Pípọ́n laṣọ àparòó pọ́n koko.

(10)  Àgùtàn ò pa aṣọ èṣín dà.

(11)  Agbe ló laró, Àlùkò ló losùn.

 

          Lójú tèmi, ohun tó jẹ́ òwe nínú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kò ju gbólóhùn kẹjọ lọ. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ Yorùbá lásán ni (9) si (11), wọn kì í ṣe òwe. Bí a bá sì wo òwe tuntun tí Òkédìjí ṣẹ̀dá, ìyọ́pọ̀ òwe kẹjọ àti àwọn ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ Yorùbá náà ni.

 

          Àkíyèsí kejì tí a ṣe nípa ìhun òwe Láwúwo ni pé ó ti ní irúfẹ́ bátàni kan pàtó ti Òkédìjí máa ń tẹ̀ lé láti yọ́ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan. Ìlànà náà ni orí òwe pẹ̀lú nǹkan kan tí kì í ṣe ẹsẹ̀ òwe náà gan-an. Ìlànà márùún ni a rí tí Òkédìjí lò nígbà tó ńyọ́ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan nínú ìwé Rẹ́rẹ́ Rún.

 

A.      Orí Òwe’A + ‘ẹsẹ̀’ B = Òwe Tuntun

          Ìlànà yìí ni Òkédìjí mú lò jù. Nínú òwe mẹ́wàá tí Láwúwo pà lẹ́yìn ìgbà tí orí rẹ̀ dàrú tan, mẹ́fà ló tẹ̀ lé ìlànà yìí. (Àwọn náà ni òwe 1, 2, 3, 4, 5, 9, àti 10). Bí Òkédìjí ṣe ń fi ìlànà yìí dárà ni pé yóò mú ‘ẹsẹ̀ òwe’ kan yóò so ó mọ́ ‘orí òwe’ mìíràn láti ṣẹ̀dá òwe tuntun.

 

(12)     ‘Orí Òwe’ A:    Ojú kìí ti egungun nínú aṣọ.

(13)      ‘Esẹ̀ Òwe’ B:   Ohun tíí tan léégún ọdún, ọmọ alágbáà á kọrísóko.

(14)      ‘Òwe Tuntun:           Ojú kì í ti egungun, kí ọmọ alágbaà má kọrísoko.

(15)      ‘Orí Òwe’ A:   Àgbàlagbà kì í rí erin tán kó padà di ẹ̀lírí.

(16)      ‘Esẹ̀ Òwe B:    àgbàlagbà kì í jọ́ láńgbáláńgbá.

(17)      Òwe Tuntun:   Àgbàlagbà kì í rí erin tán kó máa jó láńgbáláńgbá.

 

B.      ‘Orí Òwe’ A + ẹyọ ọ̀rọ̀ mélòó kan nínú ẹ́sẹ̀ òwe’ B = Òwe Tuntun

          Ìlànà kejì tí Òkédìjí gbà yọ́ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan ni ki ó ṣe àṣàyàn ọ̀rọ̀ mélòó kan nínú ‘ẹsẹ̀ òwe’ kan, kí ó sì so ó mọ́ ‘orí òwe’mìíràn láti ṣẹ̀dá òwe tuntun. Àpẹẹrẹ kan ṣoṣo ni a rí tí Láwúwo pa:

 

(18)  ‘Òri Òwe’A:       Bí eégún ẹni bá jóorẹ, orí a máa yáni.

(19)    Ẹyọ Ọ̀rọ̀ ‘Ẹsẹ̀ Òwe’ B: Bí ọmọ ẹni bá dára, ká sọ, kì í se pé a ó fi ṣaya.

(20)   Òwe Tuntun: Bí eégún ẹni bá jóore, ká wí, kì í ṣe pé ànìn, anìn.

 

D.      Ori Òwe’A + ẹyọ ọ̀rọ̀ mélòó nínú ‘orí òwe’ B = Òwe Tuntun

          Ìlànà kẹta kò jìnnà sí ìkejì. Ìyàtọ̀ ibẹ̀ kọ̀ ju pé ẹyọ ọ̀rọ̀ mélòó kan ni Òkédìjí ń mú nínú ‘orí òwe’ kan tó ń kàn mọ́ ‘orí òwe’mìíràn láti ṣèdá òwe tuntun. Irúfẹ́ òwe kan ṣoṣo náà ni a rí lábẹ́ ìsọ̀rí yìí.

 

(21)   ‘Orí Òwe’A:       Ẹni tí ó bá fórí tì í títí dè òpin, òun náà la ó gbàlà.

(22)    Ẹyọ ọ̀rọ̀ ‘orí Òwe’B: Àgbéré  tí óní òun ni àforítì.

(23)   Òwe Tuntun: Ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, àfàìmọ̀ ni kọ̀ fi níí di aláàárù.

 

Ẹyọ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì tí Òkédìjí ń mú nínú ‘orí’ tàbí ‘ẹsẹ̀ òwe’ kan láti kàn mọ́ ‘orí òwé, mìíràn láti ṣẹ̀dá òwe tuntun, kì í jẹ́ kí òwe tuntun náà ní ìtúmọ̀ àfi bí ó bá fi ọ̀rọ̀ tara rẹ̀ bíi mélòó kan kún un. Èyí ló jẹ́ kí a rí anìn anìn nínú àpẹẹrẹ ìlànà B, tí a sì rí àfàìmọ̀ ni kò fi níí di  nínú àpẹẹrẹ ìlànà D; bẹ́ẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà kò sí nínú òwe A àti B tí a fi ṣẹ̀dá òwe tuntun.

 

E       Orí Òwe’ A + ‘Orí Òwe’ B = Òwe Tuntun

          Ìlànà kẹrin tí Òkédìjí lò láti yọ́ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan ni àkànpọ̀ ‘orí òwe’ méjì. Nínú ìlànà yìí, gbogbo awẹ́ ‘orí òwe’méjèèjì ni Òkédìjí máa ń kàn pọ̀:

 

(24)  ‘Orí Òwe: A:       Òkú ń sunkún òkú, akáṣọlérí ń

                                      sunkún ara wọn.

(25)  ‘Orí Òwe’B:        Akásọlérí mọ ibi òun ń rè;  yíó máa dàárọ̀ o.

(26)  Òwe Tuntun:      Òkú ń sunkún òkú; akáṣọlérí ko mọ ibi òun

                                      ń rè.

 

Ẹ.      ‘Orí Òwe’ A + ‘Torí-tẹsẹ̀  Òwe’B= Òwe Tuntn

          Nínú ìlànà tí Òkédìjí ń gbà yọ́ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan ni a ti tún rí kíkan odidi òwe kan ní ‘torí-tẹsẹ̀’ mọ́ ‘orí òwé’ mìíràn láti ṣèdá òwe tuntun. Àpẹẹrẹ èyí náà kò ju ẹyọ kan lọ.

 

(27)  ‘Orí Òwe’ A:      Àgbà tó ní òun kò fẹ́ẹ́ fẹsẹ̀ kan ẹrẹ̀,

                                      tojú-timú ní í fi yí i.

(28)  ‘Torí-tẹsẹ̀ Òwe’: Ohun tó bá òjú, ó bá imú.

(29)  Òwe Tuntun:      Àgbà tó ní òun kò níí fẹsẹ̀ kan ẹrẹ̀, ohun tó

                                      bá ojú kò ṣe níí bá imú?

 

Àkíyèsí kẹta tí mo ṣe ni pé gbogbo ìgbà tí Òkédìjí bá ń yọ́ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan báyìí, ohun méjì ló máa ń jẹ́ àtọ́nà fún un. Àkọ́kọ́ ni iṣẹ́ tó fẹ́ fi òwe tuntun náà jẹ́. Ìkejì ní ìtumọ̀ tó fẹ́ kí òwe náà ó ní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe tí Láwúwo pa lẹ́yìn tí orí rẹ̀ dàrú ló ń fi ìhónú rẹ̀ hàn sí ètò ìsèlú àwùjọ rẹ̀. Èyí ló sì fà á tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ‘ẹsẹ̀ òwe’ tí Láwúwo pa náà ló gba àmì ẹja láti fi ìhónú Láwúwo hàn.

 

Gbogbo wa la mọ̀ pé ọ̀nà tí à ń gbà fi ìhónú ẹni hàn kì í tí kìí fanimọ́ra ni mẹ́wẹ̀ẹ̀wá gbà.

 

(30)  ‘Orí1, = Ìwò táà ń wo àparọ, aṣọ rẹ̀ pọ́n

koko                                                 = (-)

(31)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Orí ẹyẹ ni ò pẹyẹ                             = (+)

(32)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Ṣùgbọ́n Àlùkò kò paṣọ èsí dà        = (-)

(33)  ‘Orí1, =       Òjò ló kó ẹyẹlé                                = (-)

(34)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Pò mọ́ adìẹ                                       = (-)

(35)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Pọ̀ mọ́ àgbàdo                                 = (-)

(36)  ‘Orí1, =       Ojú kì í ti eégún                              = (+)

(37)  ‘Ẹsẹ̀1,  =     Nínú aṣọ                                          = (+)

(38)  ‘Ẹsẹ̀2,  =     Kí ọmọalágbà má kọrí soko           = (-)

(39)  ‘Orí1,  =      Bí eégún ẹni bá joore                      = (+)

(40)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Orí a máa yáni                                 = (+)

(41)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Ká wí kì í ṣe anìn, ànìn                            = (-)

(42)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Ẹni tí a bá fi orí rẹ̀ fọ́ àgbọn           = (-)

(43)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Kì í dúró jẹ nínú rẹ̀                         = (-)

(44)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Ọ̀tàlénírinwó èrìgì ni yó forí mule

                             láìyọ                                                 = (-)

(45)  ‘Orí1,  =     Ọ̀kúrń sunkún òkú                         = (-)

(46)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Akáṣọlérí ń sunkún ara wọn          = (-)

(47)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Akáṣọlérí kò mọni òun ń rè           = (-)

(48)  ‘Orí1, =      Àgbà tó ní òun kò níí fesẹ̀ kan ẹrẹ̀ = (+)

(49)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Tojú timú níí fi í yí i                       = (-)

(50)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Ohun tó bá ojú kò ṣe níí bá imú    = (-)

(51)  ‘Ọrí1, =      Ẹni tí ó bá fọrí tì í títí dé òpin        = (-)

(52)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Òun náà ni a ó gbà là                      = (-)

(53)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Àfàìmọ̀ ni kò fi níí di aláàárù        = (-)

(54)  ‘Orí1, =      Ọmo tí yóò jẹ́ Àṣamú                     = (+)

(55)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Kékeré níí ti í máa ṣe ẹnu

sámúsámú                                        = (+)

(56)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Òkèèrè la ti í wò ó                           = (-)

(57)  ‘Orí1, =      Àgbàlagbà kì í rí arin tán                = (+)

(58)  ‘Ẹsẹ̀1, =      Kó padà di ẹ̀líírí                              = (-)

(59)  ‘Ẹsẹ̀2, =      Kó máa jó láńgbáláńgbá                 = (-)

 

                   Àkìyèsí tí a se nípa àmì ẹja-n-bákàn tí awẹ́ òwe Láwúwo ń gbà ni pé gbogbo ‘ẹsẹ̀ òwe’ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó pa nígbà tí orí rẹ̀ dàrú ló gba àmì ẹja (-). Márùún lára ‘ẹsẹ̀ òwe’ náà ló jẹ́ pé wọ́n gba àmì ẹja tẹ́lẹ̀. Márùún tó kù sì gba àmì akàn tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí Òkédìjí ṣẹ̀dá òwe tuntun, ó rí i pé àmì ẹja ni ‘ẹsẹ̀ òwe’ náà ni. Kàkà tí awẹ́ òwe bẹ́ẹ̀ kò bá fi níí gba àmì ẹja, òǹkọ̀wé yóò lo àmì ìyísódì bíi kì í tàbí láti yí òwe bẹ́ẹ̀ po sí ohun tí à ń retí. Wo ̣ẹsẹ̀2 òwe 32, 41, 47, 50 àti 53. Àmì ẹja ti ẹ́sẹ̀ òwe’ Láwúwo mẹ́wẹ̀ẹ̀á ní kò ṣèèṣì. Òkédìjí lò wọ́n láti fi ìhonú Láwúwo hàn sí ètò ìṣèlú àti ti ọrọ̀-ajé àwùjọ rẹ̀ ni. A mọ̀ pé ọkàn Láwúwo kò papọ̀ mọ́; àìbàlẹ̀ ọkàn tó dàpọ̀ mọ́ ìhónú tó ní sí ètò ìṣèlú wọn ló jẹ́ kí ‘ẹsẹ̀ òwe’ náà ó gba àmì ẹja tíí ṣe àmì tí kò fanimọ́ra. Ó ṣe èyí nítorí ohun tó fẹ̀ lò wọ́n fún. Bí òwe náà bá gba àmì akàn, kó níí bá ìṣẹ̀lẹ̀ inú  íwè mu. Àmì ẹja ni ó fi àìbalẹ̀ ọkàn tàbí ìkọminú hàn. Ipo tí Láwúwo sì wà náà nìyí.

         

          Kí a tó ṣàlàyé iṣẹ́ tí Òkédìjí ń fi àwọn òwe Láwúwo ṣe, ó yẹ kí a sọ ohun tó ran Òkédìjí lọ́wọ́ láti yọ òwe méjì pọ̀ di ẹyọ kan ní ìhun òwe tó jẹ́ ‘torí-tẹsẹ̀’ àti ìlò tí à ń lo òwẹ láwùjọ Yorùbá. Bí olùsọ bá sọ apá kan òwe tíí sábàá jẹ́ ‘orí òwe’, olùgbọ́ ló máa ń sábàá parí rẹ̀ nípa sísọ ‘ẹsẹ̀ òwe’ náà tí í ṣe abála kejì. Bí a bá ń sọ̀rọ̀, ‘orí òwe’ la máa ń sọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé olùgbọ́ yóò fi ‘ẹsẹ̀’ kún un. Èyí ni Yorùbá ṣe ń pòwe pé “ààbọ̀ ọ̀rọ̀ là ń sọ fọ́mọlúwàbí, bó bá dénú rẹ̀, yóò di odidi.” Nítorí pé ó rọrùn láti lo apá kan nínú òwe láìlo apá kejì ló ń fà á tí a ṣe ń gbàgbé apá kejì òwe tàbí kí olóye lórí kan ó wá nǹkan tuntun mìíràn fi dípò apá kejì. Irú èyí ló ń bí òwe bíi “màlúù tí kò nírù, ó ń bẹ ní Sábó” tàbí “igi ganganran máà gún mi lójú, mo yẹ̀ ẹ́” tàbí “àgbà tó jìn sí kòtò, ojú rẹ̀ ló fọ́.” Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí, ọ̀pọ̀ òwe ni apá kan rẹ̀ máa ń sọnù pátápátá, ṣùgbọ́n ẹ̀hun rẹ̀ yóò fi hàn pé ó ku apá kan tí a kò mọ̀.

         

          Èyí fi hàn pé gbogbo òwe kọ́ ló ń pẹ́ láyé, ọ̀pọ̀ òwe ló ń kú, ọ̀pọ̀ ló sì ń wáyé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣẹ̀dá. Irú wọn ni òwe Òkédìjí wọ̀nyí. Báyòówù kí òwe ó pẹ́, tàbí kí ó tètè wáyé tó, wíwáyé òwe kì í yapa sí bátànì tí a mọ̀ ní ‘torí-tẹsẹ̀’. Bí òwe bá fẹ́ẹ́ kú náà, ọ̀kan nínú ‘torí-tẹsẹ̀’ òwe níí kọ́kọ́ kú. Bí ‘orí’ bá kú, a ó máa lo ‘ẹsẹ̀’ lọ, bí ‘ẹsẹ̀’ bá kú, a ó máa lo ‘orí’lọ. Èyí fi hàn pé òwe máa ń jòwèrè kú, ó sì máa ń jòwèrè wáyé ni.

         

4.      Iṣẹ́ Tí Òkédìjí Fẹ́ Fi Àrà Òwe Yíyọ́pọ̀ Yíí Jé

          Iṣọ̀lá (1976:22) sọ nigbà kan pé iṣẹ́ tí Òkédìjí fi àwọn àsìpà òwe Láwúwo ṣe ni pé ó kàn fẹ́ẹ́ fi wọn dárà ni. Bí àpẹẹrẹ, ń ṣe ni a fi ohùn dárà nínú

(61) Òkú ń sunkún òkú,  akáṣọlérí kò mọ ibi òun ń rè”. (Rẹ́rẹ́ Rún, o.i. 83).

          Ìlò àwọn òwe wọ̀nyí kọjá ìfọ̀rọ̀dàra nìkan. Wọ́n tún ń gbé èrò ọkàn òǹkọ̀wé síta. Fún àpẹẹrẹ, òwe tó sọ pé ojú kì í ti eégún kí ọmọ alágbàáà má kọríṣókó ń sọ fún wa pé ojú ti ti Láwúwo gbẹ̀yìn nínú ìjà òmìnìra tó ń jà fún àwọn òṣìṣẹ́. Àfi kó wábi sá lọ forí pamọ́ sí. Bákan náà ni ‘Òkú ń sunkún òkú, akásọlérí kò mọ ibi òun ń rè’ lè máa túmọ̀ sí pé kò sí ẹni tó mọ ibi tí ọ̀rọ̀ ń lọ nínú àwọn òṣìṣẹ́ tó fẹ́ẹ́ máa ṣe aáyàn ìsìnkú Morẹ́nikẹ́. Nítorí náà, bí a bá sọ pé Òkédìjí fi àwọn òwe náà dára, ohun tí à ń sọ ni pé ìfọ̀rọ̀dárà ibẹ̀ ló kọ́kọ́ hàn sí òǹkàwé ni. Àwọn òwe Láwúwo yòókù kò sì ní irú ẹwà bẹ́ẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn wá pé Òkédìjí lo àwọn àṣìpa òwe Láwúwo wọ̀nyí láti fi jẹ́ iṣẹ́ kan ni. Iṣẹ́ náà sì ni ìlò èdè lọ́nà tó rẹwà; nípa ìfọ̀rọ̀dárà tó ṣe. Bí kìí bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kò yẹ kí ìjọra inú òwẹ Láwúwo àti ọ̀rọ̀ tó gbọ́ kó tóó pa òwe rẹ̀ ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ìjọra yìí lè pe àkíyèsí òǹkàwé sí àrà tí òǹkọ̀wé ń dá, kó sì panilẹ́rìn-ín, kí èrò inú ìwé ó lè yé wa.

 

6.      Òwe Láwúwo Tí Òkédìjí Fi Gbé Èrò-Ọkàn Rẹ̀ Síta

          Nínú ọ̀rọ̀ tí Òkédìjí sọ lábẹ́ ìdí abájọ ìwé Rẹ́rẹ́ Rún, ó sàlàyé pé ìyà tí ó ń jẹ àwọn òṣìṣẹ́ káàkiri àgbáyé ló ń kọ òun lóminú tó mú òun kọ ìwé náà. Òkédìjí tilẹ̀ ṣe àtòjọ ohun tí ojú àwọn òṣìṣẹ́ ń rí lẹ́nu iṣẹ́ káàkiri àgbáyé:

 

Láwúwo, Ìdòwú, Mopélọ́lá, àti àwọn òṣìṣẹ́ yòókú kì í se ẹnà fífọ̀ rárá. Òṣìṣẹ́ ni àwọn. Orí iṣẹ́ laago ó kú sí, epo òyìnbó kì í sùn, ewé ojú omi kì í ní ìsinmi. Àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí ni ewé ojú omi, àwọn ni epo òyìnbó, àwọn sì tún ni aago. Iṣẹ́ la rí a ò rówó, iṣẹ́ bùáyà, ṣùgbọ́n kò sí àkójọ …wọ́n á ṣiṣẹ́ kẹ́tẹ́kétẹ́, wọn á gba owó yímíyímí, wọn ń ṣiṣẹ́ ènìyàn mẹ́fà, wọ́n á gbówó ẹnìkan ṣoṣo, tàbí ààbọ̀. Wọ́n a ṣiṣé wúrà, wọn á gbowó ògúlùtu. Àwọn ní ajá tí  í pẹran tí ọdẹ é gba ẹran lẹ́nu wọn. Ojú ni wọ́n fi rí i, ètè wọn kì í bà á. Àwọn ni abẹ́lẹ́jayángbẹ, àwọn ni orógùn ọkà.

                                                         (Rẹ́rẹ́ Rún, o.i.1-2).

 

Irú ìyà tó ń jẹ àwọn òsìṣẹ́ nìyí káàkiri àgbáyé, inú Òkédìjí kọ̀ sì dùn sí i. Àwọn òṣìṣẹ́ kò rówó ná, wọn kò rówo fi rasọ láti wọ̀. Ẹ gbọ́ ohun tí Láwúwo sọ nipa ipò tí àwọn òṣìṣẹ́ wà:

 

Ẹwù ù mi tí ẹ rí pé ó ya léjìkà, kì í se pé ó dùnmọ́ mí nínú; ṣùgbọ́n, amúkùún, ẹrùu rẹ wọ́, ó ní òkè lẹ̀ ń wò, ẹ ò wolẹ̀! Irú ipò tí gbogbo òṣìṣẹ́ wà ló ràn mí, kò sẹ́ni kankan tó rówó raṣọ gidi sára nínú wọn.

                                         (Rẹ́rẹ́ Rún, o.i. 45-46).

 

Ipò àìríná, àìrílò, àìrásọwọ̀ tí àwọn ọ̀sìṣẹ́ wà yìí, ló mú Láwúwo pa òwe tó pa nígbà tí orí rẹ̀ dàrú pé:

 

(62)  Ṣé ìwò tá à ń wàparò, aṣọọ rẹ̀ pọ́n koko, ṣùgbọ́n àlùkò ò paṣọ èsí dà, pírí lolongo ó jí.

 

Àwọn òṣìṣẹ́ ni àparò tí aṣọ wọ́n pọn koko, àwọn ni àlùkò tí kò paṣọ èsí dà. Àwọn ló ń sùn sínú ìyà tó ń jí sínú ìyà láràárọ̀. A ó rí i pé òwe Láwúwo yìí bá èrò ọkàn Òkédìjí mu nípa ìpò tí àwọn òṣìṣẹ́ wà. Irú àkíyèsí yìí ni a rí tí a ṣe sọ pé àwọn òwe Láwúwo náà kọjá àṣìpa òwe lásán. Bó bá jẹ ạ̀ṣìpa, kò yẹ kó bá èrò ọkan òǹkọ̀wé mu.

 

          Èrò ọkàn oǹkọ̀wé mìíràn tí àwọn òwe Láwúwo tún kín lẹ́yìn ni ọ̀nà tí àwọn òṣìṣẹ́ lè gbà kọ ìyà àti irú ẹni tó lè jẹ́ àṣíwájú òṣìṣẹ́. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfọ̀rọ̀wáni lẹ́nuwò tí àwọn olùwádìí ti ṣe pẹ̀lú Òkédìjí ló ti máa ń sọ pé òun gbé Láwúwo kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alágídí kan. Ẹni tí kì í gbọ́, tí kì í gbà. Èyí ló fà á tí Láwúwo kò fi kọbi ara sí gbogbo ìmọ̀ràn tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Wúràọlá, fún un nípa àṣejù rẹ̀ tó ń ṣe:

 

Láwúwo, pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ la fi ń rìn nínú ìdàgbẹ́ tí a kì í fi í fara gbọgbẹ́. Àgbà tó ní òun kò fẹ́ẹ́ fẹsẹ̀ kan ẹrẹ̀, tojú tẹnu níí fi í yí ẹrẹ̀.. Má fàáké kọ́rí o, má ṣàsejù … Dẹjú o rímú, ọmọ aráiyé ò fẹ́ni fọ́rọ̀, àfórí ẹni. Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dọwọ́ rẹ. Àti pé kí o dín fitafitaa rẹ kù nínú ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ títí ìjòngbọ̀n ilẹ̀ yí ó fi kásẹ̀ nílẹ̀.  Fulenge fulenge rẹ yíò kan máa bí àwọn ìjòyè nínú sí i ni… wo ìgbín, bí ọ̀ràn bá dé, ìgbín a kó wọnú ìkarahun; ẹhìn ọ̀ràn ni ìgbín yíò tóó tún ràn… To o … Láwúwo! Tún ọ̀rọ̀ yí rò wò o. Rò ó dáadáa o. Èrò lọbẹẹ̀ gbẹ̀gìrì.

                                                (Rẹ́rẹ́ Rún, o.i. 32-35)

 

Ẹ̀yìn igbá ni Wúràọlá ń yín àgbàdo sí fún Láwúwo. Láwúwo kò mú ọ̀kan lò nínú gbogbo ìmọ̀ràn Wúràọlá.

 

          A wá rí Láwúwo bí alágídí tí ó sì lo agídí náà lọ́nà tó fi tẹ́ gbẹ̀yìn. Èyí ló mú Òkédìjí pa òwe tó lè kọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ irú ẹni tó yẹ kó jẹ́ olórí wọn:

 

(63)  Ṣé bí eégún ẹni bá joore.

          Ká wí, kì í ṣe pé … anìn anìn…

 

Láwúwo ni eégún tí kò jóore, tí atọ́kun rẹ̀ tíí ṣe Wúràọlá àti àwọn òṣìṣẹ́ kò sì mọ ohun tí wọ́n lé sọ mọ́ lẹ́yìn tí agídí rẹ̀ ti kó bá a. Ẹ̀kọ́ tí Òkédìjí fẹ́ ká kọ́ nínú òwe yìí ni pé bí àwọn òṣìṣẹ́ kò bá fẹ́ kábàámọ̀ ìjà òmìnira wọn, wọ́n gbọdọ̀ mọ irú ẹni tí wọn yóò fi se olórí.

 

          Àṣejù tí Láwúwo lò náà ló jé kí ìyà ó jẹ ẹ́ dé ibi pé ó di tirẹ̀ nìkan. Èyí ló sì mú un pa òwe tó pa pé:

 

(64)  Eni tí a bá fi orí rẹ̀fọ́ àgbọn:

          Ọ̀tàlénírinwó èrìgì ni yíò forímulẹ̀ láìyọ.

 

          Láwúwo gan-an rí ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí aláṣejù hàn, lẹ́yìn tí orí rẹ̀ dàrú, kò sì fẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ tó kù ó ṣe àṣìṣe tí òun ṣe mọ́. Èyí ló jẹ́ kí ó pa òwe tó lè fún wọn ní ìmọ̀ràn yìí nígbà tí Onímògún bí i (Láwúwo) bóyá ó ní ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá àwọn òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ lẹ́yìn tí orí rẹ̀ dàrú tán. Ọ̀rọ̀ tí Láwúwo sọ ni pé:

 

(65)  Kábíyèsí, àgbà tó ní òun kò fẹ́ẹ́ fẹsẹ̀ kan ẹrè, ohun tó bá ojú, kò se nìí bá imú.

 

Ẹ̀kọ́ tí Òkédìjí fẹ́ kọ́ àwọn òǹkàwé rè ni pé bí ẹ̀dá bá ń kọ ìwọ̀sí, bí kò bá fi èrò àti ọgbọ́n kọ̀ ọ́, ìyà tí yòó jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ju èyí tó ń kọ gan-an lọ. Èyí lò ṣe sọ pé àgbà tí kò fẹ́ fi ẹsẹ̀ kan ẹrẹ̀, bí kò bá sọ́ra, òun tó bá ojú yóò bá imú.

 

          Èrò yìí kan náà ló hùn nínú òwe tí Láwúwo pa fún àwọn òṣìṣé lẹ́yìn ìgbà tí àwọn aláṣẹ ìlú ti fi kún owó orí wọn, àti àṣìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ yóó máa lò lẹ́nu isẹ́. Onímògún lò sọ pé kẹ́ni ti gbogbo ìpinnu ìlú bá tẹ́ lọ́run ó dìde dúró, kí wọn lè mọ̀ wọ́n. A gbọ́ pé gbogbo àwọn òṣìsẹ̀ bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lọ. Láwúwo wá pa òwe láti fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìmọ̀ràn pé:

 

(66)  Ẹni tó bá forí tì í títí dé òpin, àfàìmọ́ ni kò fi níí di aláàárù.

 

Èrò ọkàn òǹkọ̀wé tó hàn níbí yìí ni pé Òkédìjí kò gbà pé ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ fa wàhálà dé yìí, ó tún yẹ kí wọn máa dá kún un. Ẹni tó bá ní òun yóó forí ti ijàjàgbara tí àwọn ń jà, àfàìmọ̀ ni kò fi níí di aláàárù bíi Láwúwo.

         

          Òkèdìjí tún ní ìmọ̀ràn fún àwọn agbaniṣiṣẹ́. Ò fẹ́ kí àwọn agbaniṣísẹ́ ó máa rántí pé èniyàn bíi tàwọn ni àwọn òṣìṣẹ náà. Ó ń kìlọ̀ fún àwọn agbániṣíṣẹ́ pé bí wọ́n bá ń bínú, kí wọn ó rọra hùwà. Nítorí pé Onímògún ń bínú sí àwọn òṣìṣẹ́, ó lé Mopélọ́lá, atẹ̀wé tó ṣẹ́ dáadáa. Àìronú jinlẹ̀ Onímògún nípa ìwà Mopélọ́lá ni Òkédìjí ṣe pòwe pé:

 

(67)  Ọmọ tí yíò jẹ́ Àṣàmú, òkèèrè la ti í wò ó.

 

Ìyẹn ni pé Onímògùn kò fiyè sílẹ̀ wo ìwà Mopélọ́lá kí ó tó gbé ìgbésẹ̀ tó gbé nípa rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí akọ̀wé àgbà fẹnu ko Onímògún létí pé atẹ̀wé wọ́n àti pé nígbà tí gbogbo òṣìṣẹ́ daṣẹ́ silẹ̀ lọ́jọ́sí nípa owó oṣù wọn, Mopélólá nìkan ni kò dara pọ̀ mọ́ wọn ni Onímògún tóo yí ìpinnu rẹ̀ padà pé kí Mopélọ́lá máa báṣẹ́ rẹ̀ lọ. A ó rí i pé ìwà elérò kúkúrú nìyí. Ọ̀rọ̀ wá dọ̀rọ̀ àtẹ̀yinkọ́gbọ́n, akétí ajá. Ìwà tí kò bójú mu tí onímògún hù yìí ni Òkédìjí se pòwe pé:

 

(68)  Àgbàlagbà kì í rí erin tàn, kó máa jọ́ láńgbáláńgbá.

 

          Ohun tí gbogbo àlàyé wònyí fi hàn wá ni pé Òkédìjí mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àtúnṣe sí àwọn òwe Láwúwo náà ni. Iṣẹ́ tó sì fẹ́ lò wọ́n fún ló mú un ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí ló sì jẹ́ kí àwọn òwe náà ó bá èrò ọkàn òǹkọ̀wé mu régí. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí á mọ̀ pé ìyípadà tí Òkédìjí ṣe sí bí a ṣe mọ ìlò àwọn òwe náà láwùjọ Yorùbá tẹ́lẹ̀ kò sọ ìtumọ̀ wọn nu. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Mukarovsky (1964:18) sọ nípa èdè lítíréṣọ̀ pé àwọn onímọ̀ lítíréṣọ̀ máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dá èdè lítíréṣọ̀ rú sí èdè ojoojúmọ́ ni; àti pé ẹwà ni èyí ń mú bá lítírésọ̀ bẹ́ẹ̀:

 

Poetic language is not a brand of the standard. This is not to deny a close connection between the two which consists infact that for poetry, the standard language is the background against which it is reflected….

 

 

 

Àṣàyàn Ìwé Ìtọkasí

Abrahams, R. D & Badcock, B. A (1977), ‘The Literary Use of Proverbs, nínú Journal of American Folklore 90, 358:414-429.

Àlàbá, O. (1986), ‘Àgbéyèwò Òwe Ìwòyí’, nínú LÁÀŃGBÀSÀ  3:51-66.

Aróhunmọ́làṣe (1984), ‘Ìtúpalẹ̀ Àwọn Òwe Láwúwo nínú Rẹ́rẹ́ Rún (Òkẹ́dìjí)’, Department of African Languages and Literatures, University of Ifẹ Seminar Paper.

Bámgbóṣé, A. (1968), ‘The Form of Yorùba Proverbs’, nínú ODÙ 2, 4:74-86.

Ìṣọ̀lá A. (1976), ‘Eré Onítàn Fálétí: Wọ́n Rò Pé Wèrè Ni Òkédìjí: Rẹ́rẹ́ Rún’, nínú Yorùbá Studies Association Workshop for 6th Form Teachers, University of Lagos.

Iṣọla, A. (1978), “The Writers Arts in Modern Yorùbá Novels.”, Unpublished Ph. D. Thesis, University of Ìbàdàn.

Iṣọla, A. (1981), ‘Modern Yorùbá Drama’, nínú Drama and Theatre in Nigeria: A Critical Source Book, edited by Y. Ogunbiyi. Lagos: Nigeria Magazine, o.i. 399-410.

Milner, G. (1969), ‘What is a Proverb’, nínú New Society 332:61-83.

Michael, D. L. (1984), ‘Analogic Ambiguity: A Paradox of Proverb Usage’, nínú J. A. F., 97, 383:423-441.

Mukarovsky, J. (1964), ‘Standard Language and Poetic Language’, nínú Prague School Reader On Aesthetics Literary Structure and Style, edited by Paul Garvin, George Town University Press, o.i. 17-30.

Òkédìjí, O. (1973), Rẹ́rẹ́ Rún. Ìbàdàn: Oníbọn-òjé Publishers.

Ọlátúnjí, O. (1984), Features of Yorùbá Oral Poetry. Ìbàdàn: U.P.L.

 



[1] Àwọn òwe Láwúwo tí a gbé yẹ̀wò nínú àpilẹ̀kọ yìí ni àwọn òwe tí Láwúwo pa lásìkò tí orí rẹ̀ dárù tán. Mẹ́wàá ní wọ́n; àwọn sì ni òǹkọ̀wé kò jọ sí ìparí ìwé Rẹ́rẹ́ Rún (o.i. 99-100).
[2] This paper was published as Akinyemi, Akintunde (1990), ‘Àtúpalẹ̀ Ìhun Àwọn Àṣìpa Òwe Láwúwo nínú Rẹ́ré Run’ Seminar Series 2, edited by T.M. Ilesanmi, L.O. Adewole and B.A. Oyetade, Ile_Ife, Nigeria: Department of African Languages and Literatures.
 
[3] Lárá àwọn iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni
                I.O. Dálànọ̀ (1966), Òwe Lẹsin Ọ̀rọ̀. Ìbàdàn. O.U.P.
                J.O. Ajíbọ́lá (1947), Òwe Yorùbá, Ìbàdàn: U.P.L.
                S.O. Badà (1970), Àwọn Òwẹ Yorùbá àti Ìsẹ̀dálẹ̀ Wọn.    
Ìbàdàn.
                K. Akínlàdé (1982), Òwe àti Ìtumọ̀. Ìbàdàn: Abiprint Pub.
 
[4] Gbogbo ìwé Òkédìjí náà jẹ́ mẹ́fà. Àwọn ni:
                O. Òkédìjí (1969), Àjà Ló Lẹrù. Ìbàdàn: Macmillan.
                O. Òkédìjí (1971), Àgbàlagbà Akàn. Ìbàdàn: Longman.
                O. Òkédìjí (1973), Rẹ́rẹ́ Rún. Ìbàdàn: Oníbọ́-òjé.
                O. Òkédìjí (1972), Ọ̀gá Ni Bùkọ́lá. Lagos: Macmillan
                O. Òkédìjí (1981), Atótó Arere. Ìbàdàn: University Press
                O. Òkédìjí (1987), Ṣàngó.  Ìbàdàn: Oníbọn-òjé.
 
[5] Ohun tí Milner pè ní ‘head of proverb’, ‘tail of proverb’ni mo pè ni ‘Orí òwe’ àti ‘ẹsẹ̀ òwe’nínú àpilèkọ yìí.

No comments:

Post a Comment