Top[1]
(n/OR) ibi gaga: ibi tí ó ga jù lọ. The woman is standing at the top of the
table (Obìnrin náà dúró sí orí tábìlì) (ii) orí pẹpẹ : orí nǹkan tí a ń kó nǹkan
lé. Can you clean the top (upper) surface of the table (Ǹjẹ́ o lè nu orí tábìlì
náà bí?) (iii) olórí: Ẹni tí ipò rẹ̀ ga jù lọ láàrin ènìyàn tí wọ́n jọ wà tàbí
ẹni tí ó máa ń darí àwọn ará ibi iṣẹ́ rẹ̀. The woman is a top official in
the organization. Ọ̀gá kan ni obinrin náà ní ibi iṣẹ́ rẹ̀. (iii) Aṣọ tí wọ́n
máa ń wọ̀ sí òkè ara. The dress I worn on top is torn (Aṣọ tí mo wọ̀ sí òkè
ti ya). (iv) ìdérí nǹkan. Where is the top of this bottle? (Ìdérí ìgì yìí dà?).
(v) Excellent (Tí ó dára gan-an) ‘How was your party?’ ‘Top, mate’. (‘Bawo ni
àṣeyẹ rẹ?’ ‘Ó ga jù, ọ̀rẹ́’.(vi) Dára jù lọ. Among his friends, she is the
top. (Láàrin àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, òun ló dára jù lọ’. (vii) Ní àfikún. Look, here’s
30 naira, I’ll buy you lunch on top. (Wò ó, ọ̀gbọ̀n naira nì yí, màá tún ra
oúnjẹ fún ọ kún ún.) (viii) Láti mú nǹkan láti ìbẹ̀rẹ̀ ní pàtàkì fíìmù tàbí
orin. Okay, everybody, let’s take it from the top. (Ó yá gbogbo yín, ẹ jẹ́ kí
a mú un láti ìbẹ̀rẹ̀).
v/IṢ: (i)
Láti dára jù lọ/sàn jù lọ. The band topped the chart for five years. (Àwọn
eléré náà ni ó wà ní òkè fún ọdún márùn-ún). (ii) bu nǹkan lé lórí Top my cup
of tea (Fi nǹkan lé orí tíì inú kọ́ọ̀bù mi). (iii) Cut the top of the
vegetables. (Orí. Gé orí àwọn ẹ̀fọ́ yẹn)
Total
(adj/AJ) (i) àpapọ̀ iye nǹkan: The total number of the people is 30 (Ọgbọ̀n ni
iye àwọn ènìyàn náà). (ii) biribiri. The room was in total darkness (Yàrá náà
wà ní òkùnkùn biribiri).
Town
(n.OR) ìlú: Ibi kan tí ọ̀pòlọ̀pọ̀ ilé, ilé ìtàjà, abbl. wa. Àwọn ènìyàn ń gbé
ibẹ̀. Ó tóbi ju abúlé lọ. The nearest town is ten miles away. (Ibùsọ̀ mẹ́wàá ni ìlú tó súnmọ́ ibi jù wà).
Train
(n/OR) Ọkò-ojú-irin: Ọ̀kọ̀ tí ó máa ń rìn ní orí irin. I like travelling by
train. (Ó máa ń wù mí kí n máa wọ ọkò-ojú-irin lọ sí ibi tí mob á fẹ́ lo).
(ii) Títò kọjá ní orí ìlà kan. The way cows are walking on a train looks
beautiful. (Bí àwọn mààlúù náà ṣe ń tò rìn kọjá wùùyàn). (iii) Tí wọ́n ń tẹ̀lé
ara wọn. The train of recent events are sad. (Awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń tẹ̀lé ara
wọn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí burú). (iv) Ohun tí ó máa ń fa oríṣiríṣi nǹkan
dání. Unemployment brings a great difficulties in its train. (Àiìríṣe máa ń mú
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòrò dání).
(v/IṢ)
kọ́: They train dogs to sniff out drugs. (Wọ́n kọ́ ajá bí wọ́n ṣe ń fi imú
fínlẹ̀ wá oògùn olóró jade).
Tram
(n/OR) ọkọ̀-ojú-irin kékeré: He crossed the tram route (Ó rìn kọjá ibi tí ọkọ̀-ojú-irin
kékeré máa ń gbà).
Travel
(v/IṢ) rin ìrì-àjò. The car is very fast when it comes to travelling. (Tí ó bá
di ti pé kí a rin ìrìnàjò, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé yìí máa ń sáré). (ii) rìn dáadáa.
This car can really travel (Ọkò ayọ́kẹ́lẹ́ yìí lè rin ìrìnàjò dáadáa. (iii)
rìn ìrìnàjò láìdibàjẹ́. Some foods do not travel well (Àwọn oúnjẹ kan kìí ṣe
kí wọ́n máà díbàjẹ́ tí a bá gbé wọn rin ìrìnàjò).
Tree
(n/OR) Igi. A banana tree. Igi ọ̀gẹ̀dẹ̀.
Trouble (v/IṢ)
wàhálà, ṣòro, dààmú: Don’t trouble me (Má wàhálà mi)
(n/OR)
Ìsòro, wàhálà: He is introuble (Ó wà núnú ìṣòro).
True
(n/OR) Òótọ́: Is it true that she is leaving? (Ṣé òótọ́ nip é ó ń lọ).
(adj/AJ)
(i) gan-gan: He reveals his true character (Ó fi ìwà rẹ̀ gan-gan hàn). (ii)
Only true birds fly (Ẹyẹ gidi nìkan ló máa ń fò).
No comments:
Post a Comment