Bọ́mọdé dìde tó
fẹ́ẹ́ kéwú
Wọn a ló kéré
Bẹ́sọ́ wẹ́rẹ́ ń
fèdè ìmàrò fọ̀ tó ń gbàdúrà àtàtà
Wọn a ní ó gbẹ́nu
sọ́hùn-ún
Bí rèwerèwe
lórin tó fẹ́ẹ́ kọ fún wa 5
Wọ́n a ní ta ni
ń jẹun, tájá ń jùrù?
Ẹ ẹ̀ sì gbèwe
náà láyè
Ayé yìí ì í màá
ṣe tẹnìkan
Ọmọdé tó fẹ́ẹ́
kéwì, ó mọhun ó ní ńnú
Ọmọ pínnísín
tó fẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ àtàtà 10
Ó mọhun ó dì
síkùn
Ibi ó ti yanrí
ìwọ lè mọ́ yàn ńbẹ̀
Ó ṣeé ṣe kó ti kọ́gbọ́n wá látoyún inú
Ó ti lè mọ́gbọ́n
tọ̀run bọ̀ láìròtì
Àbẹ́yin ò fìtàn
Àjàntálá ṣẹ̀kọ́ 15
Tó sòrò ńjọ́ tá
a bí i
Torí náà tẹ́ ẹ
bá rọ́mọdé
Tó ń gbìdánwò
Tó ń tiraka
Ń ṣe ni ẹ ràn
án lọ́wọ́ 20
Ó níhun-unre tó
fẹ́ẹ́ sọ ni
No comments:
Post a Comment