Tuesday, 24 November 2015

Ẹ FINÚ TÁN AYA




Bá a bá ráya wa pẹ̀lọ́kùnrin
Ṣe là á pajú dà dárayá
Tá à á kọtí ọ̀gbọn-in sírúu wọn
Kó má fajàngbọ̀n lọ́wọ́
Kó má fa họ́wù lẹ́sẹ̀                          5
Kó ṣe bẹ́ẹ̀ tú yìgì tá a so                         
Ó yẹ á finú tán aya ẹni
Gbogbo ibi tó bá bọ́ sí náà kí ń ti ń ṣebi
Nígbà tí è é ṣajá tí è é ṣẹlẹ́dẹ̀
Ọkùnrin tó o rí pẹ̀lú ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan            10
Lè máa bá a sọ̀rọ̀ àtàtà                      
Ọ̀rọ̀ tí tẹ́yin méjèèjì ó fi dáa
Tí ó fi yẹ yín kalẹ́, tẹ́ ẹ̀ ní í ṣe é tì
Ayé àtijọ́ ni wọ́n ti ń sọ pé
Tópẹ́ bá fi máa dọpẹ́lọpẹ́ ìyàwó ẹni, ohunkóhun míìn tá a bá rí ni ká ṣe 15
Ìyẹn ò sí mọ́ ìyẹ́n ti lọ                         
Tọkọ taya ló ń fọwọ́ọ́ kún un tó fi ń dórí 
O ṣe wáá rọ́kùnrin pẹ̀láyaà rẹ
Tó ò ń fajúro, o sì wáá dì bí ẹni ọ̀fọ̀ ṣẹ̀
Pé                                                               20
Bàtá tó ń ké láké jù
Ń ṣe ló fẹ́ẹ́ bẹ́                          
Aya tó gúnyán fún wọn
Rokà fún wa
Ń ṣe ní ó lọ                                                 25
Bí ẹni pé kè é ṣẹnìkan ló fún ọ fẹ́,
Ẹwúrẹ́ tilẹ̀ ni tàbádìyẹ?                     
Tó o fi ní ò gbọdọ̀ yọ́ tẹ́rẹ́
Kò gbọdọ̀ jáde, kò gbọdọ̀ bọ́ ẹ́ẹ́kùnlé
Má-su-má-tọ̀; òfin agbẹ̀sìn sódì                            30
Ọ̀rọ̀ yìí kò kúkú yé ọ délẹ̀ ni
Ikùn àgbà níí mì, ẹ̀nu ẹ̀ è é mì          
Ó mú mi rántí ọmọ ọ̣̀dọ̀ ọ̀rẹ́ẹ̀ mi kan
Tó ti ń mu sìgá ọjọ́ ti pẹ́
Ó ti ń mu katabá ọ̀ná jìn                                      35
Ṣùgbọ́n kò jẹ́ kọ́gàá ẹ̀ ó mọ̀ ńlé
Ó wáá dijọ́ kan wàyíò              
Ọmọ ń já sìgá bọ̀ fòò, ó ń fèéfín ságbárí
Kò mọ̀ pọ́gàá òun ń bọ̀ nísàlẹ̀ ibìkan
Pẹ̀kí tójú ṣe mẹ́rin tountọ̀gá ló sọ sìgá nù sínú igbó                 40
Sìgá figbó ṣelé, tibí ń bẹ lẹ́nu
“Àwé ibo lo ti ń bò? Ibo lo ń lọ?”    
“Ìsàlẹ̀ Ọjà ni mo ti ń bọ̀, tí mo ní kí n gba Mọ́kọ́la yọ sílé”
Èéfín ń  sọ kùù bíi Ṣàngó gbìjà
Erukutu gba gbogbo orí bíi tọkọ Ọya                  45
Bó ó ṣọkọ ìyàwó tí mò ń sọ lẹ́ẹ̀kan
Á á faraya, á á pariwo                       
Àsìkò téèéfí gbalẹ̀ bíi tọba Kòso
Ẹ̀fọn tó bà lé ọ̀gá lẹ́sẹ̀ lọ̀gá ń fọgbọ́n-ọ́n lé
Térukutu fi lọ lórí ọmọ iṣẹ́ rẹ̀                      50
Ọ̀gá ò ṣe bí ẹní rí nǹkan
Kò tilẹ̀  yán ọ̀rọ̀ wò ńgbà ó délé                             
Ń ṣe ló ṣojú fúrú tó fọ̀rọ̀ ṣe mọ̀-ọ́nnú
Àwé, ire ó wà nínú ibí pọ̀ tó ò bá mọ̀
Sìgá yìí ló ṣàmumọ fọ́mọ iṣẹ́ arútúú jayé             55
Ó fọ̀wọ̀ fọ́gàá, ó pa sìgá tì láéláé.
N ni mo ṣe ni                            
Bá a bá ráyaa wa pẹ̀lọ́kùnrin
Ká pajú dà ká dára yá
Bó ṣohun ibi ló ń ṣe                                             60
Kó lè fì yẹn ṣàṣemọ̀


No comments:

Post a Comment