Tuesday, 24 November 2015

BÀBÁ JỌ̀Ọ́


Á à à! Ayé ẹ ṣèyí tán
Tiyín lẹ ṣe, ẹ ò ṣe tỌlọ́run Ọba
Èyí ò mà dáa, ẹ ẹ̀ sì rò ó ṣe
O torí  o lówó, o ń rẹ́nìkejì jẹ
O torí o lọ́lá, o ń tẹnìkejì mọ́lẹ̀ 5
Bàbá jọ̀ó, èyí ò dáa; o ò sì rẹ̀ ńlẹ̀
Ṣé torí ọmọ ò wá ọ wálé
Lo ṣe pé kò ṣe dáadáa
Nnú ìdánwò tó kọjá
Ọlọ́run mà ń bẹ, adákẹ́dájọ́                   10
O ní bỌ́lọ́run ó máàfáà, kì í sojú ọmọ-ọn kéwú
Pé kílẹ̀ tóó pòsìkà, ohun rere á ti bàjẹ́
Ó dáa náà, kò burú
O ti gbàgbé pỌ́lọ́run àtijọ́ níí pẹ́ mú-ùnyàn
Bààlúù ni tòní ń gùn                          15
Bàbá jọ̀ọ́, má jọ́mọ ọ̀ún  ṣẹ̀wọn láìṣẹ̀
Bó o ṣe jù ú lọ lỌlọ́run ṣe jù ọ́ lo,̣ kò ṣe ọ́ níkà
Erin ń gbégbó, èlírí náà ń fibẹ̀ ṣebùgbé
Ẹ ṣe wáá ní kọ́mọdé má mì mọ́ ńlẹ̀ yí
Bàbá jọ̀ọ́, ẹ rò ó wò, èyí ò sunwọ̀n    20
Káṣàá fò, káwòdì fò
Kẹyẹ gbogbo fò láìfapá kanra ni
Bí ò sí tìjà


No comments:

Post a Comment