Tuesday, 24 November 2015

BÀÁMI Ń ROKO ỌDẸ


 Bàámi ń roko ọdẹ lálẹ́ òní
Àpò tó kún fọ́fọ́ nìyáà mí dì  fún àgbàdo sísun òun ẹ̀sun iṣu
Pẹ̀lú ata, epo àtohun èròǹjà yòókù
Fún ìrìnàjò àdánìkànrìn-in  rẹ̀ yìí
Nínú igbó dúdú                       5
Igbó òruru

Bàámi ń roko ọdẹ lálẹ́ òní
Páá báyìí nìyáà mi múra
Tó lọ oríibùsùn-un rẹ̀ lọọ fìhà lé
Tó ń fòyà, tó ń gbàdúrà                   10
Tó ń ṣàìsùn àìròtẹ́lẹ̀
Torí ọkọ tó ń rebi
Àṣóòótọ́ ni wọ́n ń sọ
Pé ọkọ́ tóbi jọjọ lọ́wọ́ aya
N ò tètè mọ̀                           15

Bàámi ń roko ọdẹ lálẹ́ òní
Ọ̀pọ̀ ìgbà lagbára tó ń sà
Máa ń já sí òtúbáńtẹ́
Òjò á pa á, ìṣẹ́ á ṣẹ́ ẹ
Àwọn ìrì òjò bíi bọ́mbù                      20
Wọn a wẹ̀ ẹ́ kanlẹ̀ wẹ̀ẹ̀ẹ̀
Òtútù á dé, a sì máa gbọ̀n
A máa gbọ̀n rìrì bíi tojú omi
Ìdààmú ìpayínkeke ọ̀tọ̀
Eyín á lura bí irin                     25
Ní òun nìkan dáyá
Nínú igbó òruru

Bàámi ń roko ọdẹ lálẹ́ òní
Àwọn ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn sì ti kẹ́nu jọ
Láìsági lógbẹ́, láìtàgùrọ̀ lọ́fà              30
Wọ́n ń retí ẹran ọ̀fẹ́
Ọ̀fẹ́ ní í ro
Àbí ẹ̀yin ò mọ̀ pé
Ọta ìbọn kan tí ẹ gbọ́
Tó ró kììì lálẹ́ àná                     35
Ó lè jẹ́bọn tó yìn
Nígbà tó gbéná ọdẹẹ  rẹ̀
Tó tàn án yààà
Sí ojú tí ó rí tó ń dán
Láìmọ̀ pé ojúu kòtónkan ni             40
Fẹ̀pà ṣe pósí eku èlírí.


No comments:

Post a Comment