Tuesday, 24 November 2015

ARÉDÈ


Níjọ́  mo relé arédè
Ọkàn mí gbọgbẹ́
Ọkàn mí gbàròkàn
Èṣù èwo ló mú irú èyí délẹ̀ wa
Tí ń faya ṣolú ọkọ ?                5
Tíbi a pè lórí dibi à ń fi tẹlẹ̀
Àwon Òyìnbó tó làṣà yí tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ́ẹ́rí
Wọn ò ṣe tó tiwa, èyí gbàrà ọ̀tọ̀
Kí ọkọ mórógùn wá, àbí kinla!
Kí ó fọgbá, kó fọ àwo, kó fọ̀kòkò baba ìsáàsùn                                 10
Àbákú laṣọ awo, à bó a ti wí?
Ọkọ kan, aya kan! Nílẹ̀ yí náà?
Tá a bá fẹ́ẹ́ gbágbo ijó, ta ni yóò bá wa jó o?
Tá a bá fẹ́ẹ́ ṣèpàdé àkòdì, ta ni yóò bá wa yẹ̀díẹ̀ wò?
Ta ni yóò bá wa káta?                       15
Ẹ̀gúsí ń kọ́ tó so dọ̀ọ̀mì sébè?
Gbogbo àwọn ṣọkọyọ̀kọ̀tọ̀ tí ń bàjẹ́ láàlà ń kọ́?
Ta ni yóò bá wa fẹ́ wọn?
A tún ní o ṣiṣẹ́, o fajú ro
Pé n mówóo yẹti wá, owó aṣọ àtowóo bàtà ẹsẹ̀                                 20
Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti sanwó orí, tí mo san tilé, tí mo san tọ̀nà
Ṣémi lò tún ń larúkọ mọ́ lórí, ìyáa lágbájá?
O ti kí mi láàárọ̀ yí ná à bá a jà tì?
Wọ́n ní bí mo bá kú bí mo bá lọ, ìwọ lo logún-ùn mi, ìyẹn ṣèèwọ̀
Tẹbí tará là wá mọ̀ tíí  píngún nílẹ̀ẹ tàwa                                  25
Ǹjẹ́ àsìkò náà tó tí n ó pariwo tí n ó sọ̀rọ̀ kàn
Arédè yí ò wù mí n ò so yìgì
Bí mo fáya sí Pọtá, ma fẹ́ sí Ará, ma fẹ́ sí Kútíwenjí
Irú èyí ló lè tètè fa ìsọ̀kan ilẹ̀ẹ wa pọ̀ láìròtì
Kárìn ká pọ̀ bí ìlú là á rí                               30
Àrìnpọ̀ ló wù mí, n ò fáya kàn ń tèmi


No comments:

Post a Comment