Mo ní ẹ ronú, ọmọ
Yoòbá, ẹ tóó káya jọ
Òrìṣà jẹ́ n
péjì obìin ò dénú
Ojú ni gbogbo wa
fi ń fẹ́raa wa
Ẹní láya púpọ̀
sọ̀bàlẹ̀ ọkàn nù
Ara ìyá èyí ò
yá, ara baba tọ̀hún ò le 5
Àmódi ń ṣẹ̀gbọ́n-ọn
tibí, ọ́ fẹ́ bíńtín sí araa tìyín
Sókè, sódò lọkọ
ó máa lọ bí ìlẹ̀kẹ̀ ìdí
Lámọrín ò rọ́mọ
bí, tẹ̀mẹ̀dò ò rósùu rẹ̀ mọ́
Gbogbo ẹ̀,
gbògbò ẹ̀, lórí ọkọ ni
O ti ṣe fún tèmi lẹ́bà tó o gbéyán fún
ti ẹ 10
Bá n namọ-ọ̀n
mi nùun, òféérefé ọ̀rọ̀ ni
Ọkọ yìí ò bá ro
ọ̀rọ̀ yí ire o tóó ṣe é
Ayé ti yí padà,
ayé ti di gbẹ̀dẹ̀mùkẹ̀
Gbogbo ohun à á
fi ẹni pupọ ṣe ló ti ẹńjìn-nì
Àṣejù lojú
méjì, n ò mọbi tá a gbójú kan dé tí ò ríran. 15
No comments:
Post a Comment