Ó ṣe náà ṣùgbọ́n
kè è pẹ́ jìnàjìnà
Ni gbogbo àwọn
dúdú fibí ṣèpàdé
Láti gbáṣà
ìbílẹ̀ ga
Owó tó ná wa kúò
ńdíẹ̀
Ṣùgbọ́n a kò ṣàìyọ
doromọ́ kan pàtó 5
Ìgbéga àṣà
èèyàn dúdú
Táwọn funfun ti
pò mọ́lẹ̀
Oníjó ń jó,
aláyò ń yọ̀
Ṣùgbọ́n níjọ́ míìn
bírú èyí bá tún ń bọ̀
Ẹ jẹ́ á ro tàwọn
mẹ̀kúnnù 10
Ká fi pípè náà ṣe
ti wọn
Kí wọn bá wa dá
sí i.
Kọ́rọ̀ ó lè gún
Ẹnìkan è é jẹ
Kí fífẹ̀ di tile 15
Yíyẹ níí yẹ ni
Tá a bá rìn tá a
pọ̀
Ṣùgbọ́n ẹ
gbàgbé ni
Péjó nìkan kọ́
làṣàa wa
Ẹ ẹ̀ bọ̀sanyìn,
kẹ́ ẹ bọṣàngó 20
Kẹ́ ẹ pògún
onírè, kẹ́ ẹ pọbàtálá
Kí gbogbo ayé
fojú róhun ti wa
Àléébù lèyí, ẹ
dákun ẹ wò ó wò
Í í déwájúú dẹjọ́
Í í déyìn-ín
dasọ̀ 25
Aìímọ̀-ọ́nrìn
kórí má jì
Ṣùgbọ́n tó bá
mì
N ṣe là á gbé e
é gún
No comments:
Post a Comment