Obìin mẹ́ìndínlógún
N ní ń bẹ́
lọ́ọ̀dẹ̀ẹ Ṣàngó
Ńbi ká sánpá
Ńbi ká yan
Lọyá fi gbọkọ lọ́wọ́ọ gbogbo wọn 5
Ńbii ká sọ̀rọ̀,
ká fa kòmóòkun yọ
N la ṣe ń perúu
yín lákéwì àtàtà
Fohùn òkè ta ko
tìsàlẹ̀ nìkan
Kọ́ là ń pè léwì
Yàtọ̀ sáfiwé
ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti tààrà 10
Òwe tún ń bẹ
rẹrẹrẹ
Wọn a sọ̀rọ̀ tó
gbayì létè
Wọn a fi wíwúni
lórí lé e
Èyún-ùn nìkan
kọ́, kò sẹ́ni tí ò mọ̀yún-ùn
Àní níbii ká
máṣà ìṣẹ̀ǹbáyé lò mọ́ tòde òní 15
Kí gbogbo rẹ̀
wá kú dùn-ún-ùn bí ojú tó ti kékeré fọ́
N la ṣe ń peruu
wọn ní baba
Nítorí bójú
bá ti kékeré fọ́
Ṣe níí kú
mọ̀ràn-ìn mọran-in
Ẹni tó mọ̀Bàdàn
tán tó tún mọ Láyípo pẹ̀lú ẹ̀ 20
Tó gbégùn tó
gbọ́ wọ́yọ̀wọ́yọ̀
Iwájú lọ̀pá
ẹ̀bìtì ó kúkú máá ré sí
A kò ní í ṣàìmáa
rí yín bá
Igba ọdún,
ọdún kan
No comments:
Post a Comment