Mo kólá, mo
kálùbọ́sà, mo kó rodo
Mo táwọ́ sáparò;
ò dunbẹ̀ dunmi
Ẹni tá ò fẹ́mọ
lọ́wọ́ ẹ̀ tí ń gbàna lọ́wọ́ ẹni
Mo nawọ́ sí étu
onítan-án pe ogún ẹrú
Oníkìísẹ̀ẹ́ pe ọgbọ̀n
ìwọ̀fà; tíi fi gbogbo araá pe aláàrú tan tan tan 5
Mo ṣe bí gbogbo
wọn ó jẹ́mi ísè lọ́bẹ̀
Ṣùgbọ́n ibi mo
fojú sí, ọ̀rọ̀ ò gbabẹ̀
Irú à bá fi
jíyìn ọbẹ̀, ekú gbé e lò
Ògìrì ọbẹ̀ tún
nihún ti fọ̀n rè
Ǹ̀jẹ́ kí n rèé
wáyọ̀ bóyá yóò ṣeni níre 10
Mo dúró, owọ́ọ̀
mi ò to
Mo bẹ̀rẹ̀, owóò
mi ò kàn
Mo wáá fọ̀rọ̀
kan lọ̀ yín, emi ní ń ṣe?
Bọ́rọ̀ bá ṣe bí
èyí díjú, àgbà là á pè
Mo wáá sáré
títí, mo re Kóńgò 15
Pé wọn ó bá n
pe Lùmúńbà eni ire
N ni wọ́n sọ
fún mi pÉjìẹ́ ti mú un lọ
Èjìẹ́ kẹ̀? Emi n
wọ́n ní ó ṣe?
Kí la ó ti ṣèyí
sí o, Èdùmàrè?
Wọ́n ní kò kúkúu
mọ́tò, kò kúkú omi 20
Wọ́n níkú ọta
ló kú, lọ́wọ́ aṣekúpani
Ẹ̀rú bà mí, àyá
fò mí, ọkàn mí gbò jìgì
Mo ṣọkàn ọkùnrin,
mo forí lÉtópíà
Pé n lọ rèé rí
Sàlásì ní fẹ̀rẹ̀fẹ̀rẹ̀
Wọ́n ló tún ti ṣe
tán filẹ̀ bora bí aṣọ 25
Ọmọ awo kò fọ̀
sẹ́nìkan té e lọ
Té e lọ àjò
àrèmabọ̀
Mo níkú tó pa ọ́,
àwé, ikú òún ò ṣèèyàn
Ikú ọ̀ún ò ṣé-e-re
Mo múra pàá ó
dilẹ̀ Àgànyìn 30
Pé n lọọ fojú
kan Kúrúmọ
“N gbọ́ Kúrúmọ
ń bẹ ńlé àbó ròde?
Wọ́n dákẹ́, wọn
ò dáhùn, wọn tiiri bí omi
Mo lémi lódé, ẹ
yára dá mi lóhùn lóhùn kan
Wọ́n níkú ti ṣebi,
ikú ti ṣèkà 35
Ikú ti mẹ́ni ire
lọ tèfètèfè
Omí bọ́ lójúù mi
pòrò pòrò bí ọmọ-ékeé
Torómi ojú la fi
ń rántí ẹni ńlá
Ìké pàtàkì la fi
ń rántí ẹnì ó wùùyàn
Omijé ni n ó máa
fi rántíi Kúrúmọ 40
Ǹjẹ́ tá a bá
ròkun, tá a bá rọ̀sà, ilé là á fàbọ̀ sí
Mo ní n wáá
fàgbo ilé rẹmọ n ké sí Múrí
Múrí ọmọ
arógunjó, ọmọ arógunyọ̀
Ẹni tó síntọ́
sààràrà lásán
Té e pẹgbẹ̀rún
èèyàn nílẹ̀ Kóńgò níjọ́sí 45
Mo mọ́nà pọ̀n, ó
dÈkó pé n fojú kọmọ-ọn Lámọín
Mo débẹ̀ ni mò ń
gbọ́ gbàù gbàù
Emi ó ti ri, emi
ó ṣe?
Ogun Àdùbí nì yí
àbí ti Kírìjì?
Ìbọ́n rọlẹ̀ ni
mo wọlé, nǹkan ti ṣe 50
Gbogbo ọgbọ́n
tá a ní ti lọ́ mọ́ wa lówọ́ lÁáfíríkà
Aáfíríkà o mà kú
ọ̀fọ̀ o
O kú ọ̀fọ̀ àwọn
ọmọ-ọ̀n rẹ
Tí gbogbo wón
kú, tí gbogbo wọ́n lọ
Ká tóó tún rérin, ó digbó àwé 55
Ká tóó tún réni
bí ìwọ̀nyí, ó dọ̀run alákeji
Ó ṣe púpọ̀ fún
ọ Aáfíríkà
O ò ní í rábìíkú
àgbà mọ́ - àṣẹ
Kólúwa ó wọmọ
fún ẹ - ẹ ṣàmín ẹ̀
No comments:
Post a Comment