(i) (adv/ọ̀rọ̀-àpọ́nlé): tí ó kéré tàbí tí ó tóbi díẹ̀ ju ohun tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní nǹkan bí. ‘When are you leaving today?’ ‘About 5 p.m.’ Nígbà wo ni o máa lọ lónìí?’ ‘Ní nǹkan bí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́’.
(ii) (prep/ọ̀rọ̀-atọ́kùn) ohun tí nǹkan kan dá lé lórí. What is the story about? Kí ní ìtàn yẹn dá lé lorí/orí kí ni ìtàn yẹn dá le?
(iii) (adj/ọ̀rọ̀-àpèjúwe): Fẹ́ ṣe nǹkan láìpẹ́. I was about to sit down when he called me. Mo ti fẹ́ẹ́ jókòó nígbà tí ó pè mí.
(iv) (1. adv/ọ̀rọ̀-àpọ́nlé 2. prep/ọ̀rọ̀-atọ́kùn 3. adj (after verb)/ọ̀rọ̀-àpèjúwe (lẹ́yìn ọ̀rọ̀-ìṣe) wà ní ojú kan/máa rìn ní ojú kan/wà ní ẹ̀gbẹ́ ibi kan, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, láìní nǹkan kan pàtó tí ó ń darí ẹni tàbí kí a má ní nǹkan kan pàtó lọ́kàn tàbi kí ohun tí a ń ṣe má tẹ̀ lé ètò kan pàtó. He always leaves his books lying about on the tables. Ó kàn máań fi àwọn ìwé rẹ̀ sílẹ̀ káàkiri orí àwọn tábìlì ni. They saw somebody moving about in the room. Wọ́n rí ẹni kan tí ó ń rìn kiri nínú yàrá. I have been running about since morning looking for the money I owe him. Láti àárọ̀ ni mo ti ń sáré ká tí mo ń wá owó tí mo jẹ ẹ́ kiri.
Ìlò gbẹ̀fẹ́: Do you have such a thing as a pencil about you? Ǹjẹ́ o ní nǹkan tí ó jọ lẹ́ẹ̀dì ní ara rẹ níbẹ̀ yẹn? Is Olú about? Ǹjẹ́ Olú wà nítòsí? There is a lot of tuberculosis about right now. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ní ikọ́ọ fée báyìí.
No comments:
Post a Comment