A (N/OR): (i)
lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gẹ̀ẹ́sì.
(ii) máàkì tí a
máań gbà nínú ìdánwò tàbí iṣẹ́ kan láti fi hàn pé a pegedé
gan-an. She got an A for Yorùbá. Ó gba
A nínú Yorùbá.
(iii) Nóòti kan nínú orin àwọn Òyìnbó.
(iv)
(DET/Aṣàfihàn): máań ṣáájú ọ̀rọ̀-orúkọ láti tọ́ka sí ohun kan
tí a kò tíì mẹ́nu bà rí, ní pàtàkì, nígbà tí a kò bá retí pé
ẹni tí a ń bá sọ̀rọ̀ mọ ohun tí a ń tọ́ka sí. I just gave it to a
boy. Mo kàn mú un fún ọmọkùnrin
kan.
(v) ẹyọ ẹnì kan. I saw two boys and a girl. Mo rí ọmọkùnrin méjì àti ọmọbìnrin
kan.
(vi) mánń wáyé láàrin oríṣìí ìdá nǹkan kan àti
odidi nǹkan náà. He walked half a mile.
Ó rin ìlàjì ibùsọ̀.
(vii) máań wáyé nígbà tí a bá fẹ́ sọ nípa bí
nǹkan kan ṣe máań wáyé tẹ̀lé nǹkan mìíràn ní àkókò kan. Eat
thrice a day. Jẹun ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta
lójúmọ́.
(viii) máań wáyé nígbà tí a bá fẹ́sọ iye tí nǹkan
kan jẹ́ tàbí iye tí ẹni kan máań gbà. He pays each of his workers a
hundred naira. Ó máań san
ọgọ́rùn-ún náírà fún òṣìṣẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
(ix) From A to B.
Láti A sí B. From one place to another. Láti ibìkan sí ibòmíràn. Take the quickest route from A to B.
Gba ọ̀nà tí ó yá jù láti A sí B.
(ix) From A to Z. Láti
A sí Z. including everything. Láti
ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. He told the story of his life from A to Z. Ó sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ láti
ìbẹ̀rè dé òpin.
No comments:
Post a Comment