(i) (adv/ọ̀rọ̀-àpọ́nlé): wà ní ipò tí ó ga ju ipò tí nǹkan mìíràn wà lọ. There is a cap above the table. Fìlà kan wà ní òkè tábìlì yẹn.
(ii) (1) pọ̀ jù ní iye tàbí ní ìwọ̀n. The book is for children aged three and above. Ìwé yẹn wà fún àwọn ọmọ ọdún mẹ́ta àti àwọn tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (2) above all. Ju gbogbo rẹ̀ lọ. Above all, I thank my friends. Jú gbogbo rẹ̀ lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi.
(iii) (adj/ọ̀rọ̀-àpèjúwe) (adv/ọ̀rọ̀-àpọ́nlé): ní ojú ìwé. Tí a bá lo ‘above’ ní ojú ìwé ti a ń kọ nǹkan sí, ohun tí a ń sọ ni pé ohun tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ wà ní òkè ìlà tí a ń kọ nǹkan sí tàbí ní ojú-ìwé tí ó ṣáájú èyí tí a ń kọ nǹkan sí lọ́wọ́. Send the money to the address given above. Fi owó náà ránṣẹ́ sí àdírẹ̀sì tí ó wà lókè yìí.
(iv) (adv/ọ̀rọ̀-àpọ́nlé) (prep/ọ̀rọ̀-atọ́kùn): ipò. tí ipò rẹ̀ ga ju ti ẹlòmíràn lọ. Adé is a grade above me. Ipò Adé fi ìgbésẹ̀ kan ga ju tèmi lọ.
(v) (adv/ọ̀rọ̀-àpọ́nlé) (prep/ọ̀rọ̀-atọ́kùn): dára gan-an. ṣe pàtàkì torí ìdí kan tàbí òmíràn. No one is above the law. Kò sí ẹni tí ó ṣe pàtàkì ju òfin lọ/Kò sí ẹni tí ó kọjá òfin/Kò sí ẹni tí ó ga ju òfin lọ/Kò sí ẹni tí òfin kò lègbé.
(vi) the above: gbogbo ènìyàn tàbí gbogbo nǹkan tí a tò sí òkè. All of the above should come. Gbogbo àwọn tí a ṣe àkọsílẹ̀ wọn sí òkè yìí ni kí ó wá/Gbogbo àwọn tí a ṣe àkọsílẹ̀ wọn sí òkè yìí ni kí wọ́n wá.
(vii) above board (adj (after verb)/ọ̀rọ̀-àpèjúwe (lẹ́yìn ọ̀rọ̀-ìṣe)): kò sí wùrùwúrú tàbí ojúṣàájú. The negotiation was above board. Ìdúnàádùrà náà kò ní wùrùwúrú nínú rárá.
(viii) (adj/ọ̀rọ̀-àpèjúwe): tọ́ka sí ohun tàbí ẹni tí a ti mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀. All of the above-mentioned industries made profit last year. Gbogbo àwọn ilé-iṣẹ́ ńláńlá tí a dárúkọ wọn lókè yìí ni wọ́n jèrè lọ́dún tí ó kọjá.
No comments:
Post a Comment