Friday, 12 June 2015

ŃDÓJI






Ẹni tí ò kọrin ajé ìí jèrè
Ajé, dákun, jẹ́ n jèrè
N lorin wa nínú ilée wa nígbà ìwá ṣẹ̀
Ó wá mú mi rántí ọ̀rọ̀ tó ṣẹ̀ nígbà kàn
Erin wó, àwọn orúsagila ń yọ sagila            5
Ńdóji dé, afọ́nwókáyé
Gbogbo ayé kọrin ajé wọ́n jèrè
Bí wọ́n ti ń dójì níbí
Ni wọ́n ń dóji lòhùn-ún
Gbogbo irùgbọ̀n òtòsì bí ìgbálè lánàá  10
La jí lónìí ló ń bẹ yẹbẹ tó sì ń wu ni
Àṣówó tí ò bá bójú ọjọ́ wọlé bẹ́ẹ̀ ní í rí
Kẹ́ ẹ wá wo pẹpẹyẹyẹ tatagun-anran
Àwọn ènìyàn ná wábiwọ́sí owó Ńdóji
Àtohun ó tọ́ àtèyí ò tọ́                      15
Ṣówó sáà ti wà
Ká máa náwó lọ ńtiwa ni
“Ọmọ aláta, kọ́bọ̀ kan kó o pè é? Gba kọ́bọ̀ mẹ́fà”
Ẹ̀yìn là á nájà sí rí, iwájú ló kàn
Owó ti dé, ká máa ṣowó bó ti wuni ni                            20
Gbogbo wọ́n wá ń jóókọ nínálowó, orúkọ ọmọ ọlọ́mọ
Wọ́n já àwọn ọlọ́jà léèékán, àwọn náà ti gbọ́
Gbogbo ohun wáá gbówó lérí ge gee ge
Owó pọ̀, ọjà wáá kéré
Gbogbo nǹkan wá ròkè                      25
Ṣé tí lálá bá ròkè, a sì padà wálẹ̀
Bíi tọjà ilẹ̀ẹ wa kọ́
Ọjà tó ròkè kò sì káwọn èèyàn lọ́wọ́ kò
Ohun ribiribi la tún ń ṣe
Ìgbàwo ni bàbà àgbá kú ná?                        30
Ǹjẹ́ kò ti fẹ́ẹ̀ kádún?
Ẹ̀̀gbẹ́ ó ti máa ro ó, ó yẹ n pa á da ó tóó kẹ̀                        
Kí baba ẹni ó fire fún ni
Ǹjáya mẹ́fà pére tilẹ̀ yẹrú àwa báwọ̀nyí?
Jọ̀wọ́ ba n fi lọ̀ bó o délé                              35
Pẹ́ni tó lówó fẹ́ẹ́ fáyaa re
Àná ni mo sọmọ yìí lóókọ
Ó tún tóó gbà míìn
Bó bá tún dọjọ́ ajé
A tún máa tóókọ ọmọ sọ                            40
Tàwọn èyí ò dùn míí pọ̀
Bí àwọn tó sun Ńdóji níná
Rírú táwọn èyí rù
Wọ́n kúkú mohun wọ́n fara ṣe
Àwọ̀n tọ̀hún gọ̀ a à rírú ẹ̀ rí                45
Kódà, ẹnu ni wọ́n fi ń họra
Wọ́n ra fìlà tán wọ́n tún ń yọwó ìtẹ́nú
Ọ̀kan lọ kówó Ńdóji fáwọn ṣogúndogójì
Ó fẹ́ẹ́ sọ ọ́ dirún digba
Ẹni ń wáfà ń wófò                    50
Gẹ́gẹ́ bí òwe àwọn àgbà
Fúẹ́ bí afẹ́fẹ́ ni owó tó níye ṣe lọ
Wọ́n ní ẹni kan ta púù kò jẹ páà
Mo nírọ́ ni
Wọ́n lẹ́nit a tẹ́tẹ́ kò jẹ                          55
Mo lé ṣèèwọ̀
Mo ní a kì í ta tẹ́tẹ́ ká má jeẹ
Ẹni tí kò jẹwó a sì jẹ gbèsè bọ̀ ibẹ̀
Ọ̀kan ra tatapùpù tí kò gùn rí lọ́jọ́ aráyé ti dáyé
Àwé jọ̀wọ́ jẹ́  n y ẹàdá ẹ wò ni wọ́n fi gbàdá ọwọ́ àgbẹ̀ lọ                            60
Torí kò sí nọ́ńbà kò síhun a fi lè dá tapùpù mọ̀
Ńdóji gbólé dé, olé gbàgboro
Bí wọ́n ti ń kólé ńlé ni wọ́n ń kó lóko
Èèyàn ò wá lè dá rìn mọ́ láìpé mẹ́fà
Nítorí owó wọ́n fọ́n kale tó kóhun ibi báni                               65
Ẹ ò jẹ́ á rọ̀rọ̀ wò lọ́jọ́ míìn ọjọ́ọre
Ká tóó fánwó jáde tí yóò kó báàyàn

No comments:

Post a Comment