Friday, 12 June 2015

ÌJẸ́ OBÌNRIN TÀBiÍ ỌKÙNRIN (SEXUALITY)





Oríṣìí ènìyàn méjì lówà nílé ayé, ìkan ọkùnrin, ìkan obìnrin. Nígbà tí a bá rí obìnrin a ò lè dá a mọ̀ nípa ẹ̀yà ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọkùnrin. Oríṣìí ìgbésẹ̀ ni ó wà kí ẹ̀dá tó lè di ènìyàn. Àwọn òbí yóò kọ́kọ́ ní àjọṣepọ̀. Lẹ́yìn ìgbà yìí ni oyún yóò tó dúró lára obìnrin. Lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án ni obìnrin yóò bímọ tí wọ́n bá wo ọmọ náà fínnífínní, wọn ò lè mọ̀ bóyá ọkùnrin ni ọmọ náà àbí obìnrin.   
Bí ọmọ ọkùnrin tàbí obìnrin bá ṣé ń dàgbà ni àwọn ẹ̀yà ara tí a lè fi dá wọn mọ̀ yóò má a yọ síta. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ náà yóò máa gbọ́n sí i. Fún bíi àpẹẹrẹ, tí ènìyàn bá ti rí obìnrin tó ti dàgbà, ẹni náà lè mọ̀ wí pé obìnrin ni bí a bá wo ojú rẹ̀ nítorí irun obìnrin a máa sábà gùn ju irun ọkùnrin lọ. Obìnrin a má a wọ yẹtí okunrin kìí sìí sábàá wọ yẹtí.
Nígbà tí obìnrin tàbí ọkùnrin bá ti wá bálàgá tán, ìyàtọ̀ gédégbé yóò wá jẹyọ láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Lára obìnrin, bí a bá ti rí i, àwọn ọyàn àyà rẹ̀ ni yóò ti kọ́kọ́ sọ fún wà wí pé obìnrin nì. Tó bá sì jẹ́ ọkùnrin ni a rí, ohùn rẹ̀ tí a bá gbọ́ sábà máa ń sọ fún wa wí pé ọkùnrin ni nítorí ó máa ń kẹ̀ ju ti obìnrin lọ. Ó tún ṣeé ṣe kí ó ní irùngbọ̀n tí obìnrin kìí sabàá ní.
Bí ilé ayé se tóbi tó, oríṣìí ènìyàn méjì ló wà ní ibẹ̀. Àwọn náà ni obìnrin àti ọkùnrín.

No comments:

Post a Comment